Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 2

ORIN 132 A Ti Di Ọ̀kan Ṣoṣo

Ẹ̀yin Ọkọ, Ẹ Máa Bọlá fún Ìyàwó Yín

Ẹ̀yin Ọkọ, Ẹ Máa Bọlá fún Ìyàwó Yín

‘Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa bọlá fún wọn.’1 PÉT. 3:7.

OHUN TÁ A MÁA KỌ́

Bí ọkọ ṣe lè máa nífẹ̀ẹ́ ìyàwó ẹ̀ kó sì máa bọlá fún un.

1. Kí nìdí tí Jèhófà fi dá ìgbéyàwó sílẹ̀?

 “ỌLỌ́RUN aláyọ̀” ni Jèhófà, ó sì fẹ́ káwa náà máa láyọ̀. (1 Tím. 1:11) Ó fún wa láwọn ẹ̀bùn tó máa jẹ́ ká gbádùn ayé wa. (Jém. 1:17) Ọ̀kan lára àwọn ẹ̀bùn náà ni ìgbéyàwó. Nígbà tí ọkùnrin kan àti obìnrin kan bá ṣègbéyàwó, wọ́n máa ń jẹ́jẹ̀ẹ́ pé àwọn á nífẹ̀ẹ́ ẹnì kejì àwọn, àwọn á máa bọ̀wọ̀ fún un, àwọn á sì máa ṣìkẹ́ ẹ̀. Tí wọ́n bá nífẹ̀ẹ́ ara wọn dénú, wọ́n máa láyọ̀ gan-an.—Òwe 5:18.

2. Kí ló ń ṣẹlẹ̀ nínú ọ̀pọ̀ ìgbéyàwó lónìí?

2 Ó ṣeni láàánú pé lónìí, ọ̀pọ̀ ọkọ àtaya ti gbàgbé ìlérí tí wọ́n ṣe lọ́jọ́ ìgbéyàwó wọn. Torí náà, wọn ò láyọ̀. Ìròyìn tá a gbọ́ láìpẹ́ yìí látọ̀dọ̀ Àjọ Ìlera Àgbáyé sọ pé ọ̀pọ̀ ọkọ máa ń lu ìyàwó wọn, wọ́n máa ń bú wọn, wọn kì í sì í gba tiwọn rò. Àwọn ọkọ tó ń hu ìwà burúkú yìí lè máa bọ̀wọ̀ fún ìyàwó wọn lójú àwọn èèyàn, àmọ́ tí wọ́n bá dénú ilé, wọ́n á máa hùwà ìkà sí wọn. Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ ọkọ ló ń wo àwòrán tàbí fíìmù ìṣekúṣe, ìyẹn mú kí ìyàwó wọn máa rò pé wọn ò nífẹ̀ẹ́ àwọn mọ́, inú wọn kì í sì í dùn.

3. Àwọn nǹkan wo ló ń mú káwọn ọkọ kan máa hùwà burúkú síyàwó wọn?

3 Àwọn nǹkan wo ló ń mú káwọn ọkọ kan máa hùwà burúkú síyàwó wọn? Ó lè jẹ́ pé bàbá wọn máa ń lu ìyá wọn, wọ́n sì rò pé kò sóhun tó burú nínú ẹ̀. Àṣà ìbílẹ̀ àwọn kan ni pé “ọkùnrin lọ̀gá obìnrin” torí náà, ohun tó bá wu ọkùnrin ló lè ṣe sóbìnrin. Bí wọ́n sì ṣe tọ́ àwọn ọkùnrin míì ò jẹ́ kí wọ́n rí ohun tó burú nínú kéèyàn máa bínú fùfù. Àwọn ọkùnrin kan máa ń wo àwòrán tàbí fíìmù ìṣekúse, ìyẹn sì mú kí wọ́n máa rò pé àwọn obìnrin ò wúlò fún nǹkan míì ju ìbálòpọ̀. Bákan náà, ẹ̀rí fi hàn pé àjàkálẹ̀ àrùn kòrónà ti dá kún àwọn ìṣòro yìí. Àmọ́ ṣá o, kò sídìí kankan tó fi yẹ kí ọkùnrin máa hùwà burúkú síyàwó ẹ̀.

4. Kí ni ọkọ tó jẹ́ Kristẹni ò gbọ́dọ̀ ṣe, kí sì nìdí?

4 Ọkọ tó jẹ́ Kristẹni ò gbọ́dọ̀ máa fojú tí ò dáa wo obìnrin. a Kí nìdí? Ìdí ni pé ohun téèyàn bá ń rò ló máa ń ṣe. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ fáwọn ẹni àmì òróró tó wà ní Róòmù pé ‘ẹ má jẹ́ kí ètò àwọn nǹkan yìí máa darí yín.’ (Róòmù 12:1, 2) Nígbà tí Pọ́ọ̀lù kọ̀wé yìí sáwọn ará Róòmù, ó ti pẹ́ díẹ̀ táwọn ará ìjọ yẹn ti di Kristẹni. Síbẹ̀, ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ yẹn fi hàn pé àwọn kan nínú ìjọ yẹn ṣì ń tẹ̀ lé àṣà ìbílẹ̀, wọ́n sì ń ronú báwọn èèyàn ayé ṣe ń ronú. Ìdí nìyẹn tó fi gbà wọ́n nímọ̀ràn pé kí wọ́n yí èrò àti ìwà wọn pa dà. Ìmọ̀ràn tó fún wọn yẹn kan àwọn ọkọ tó jẹ́ Kristẹni lónìí. Ó bani nínú jẹ́ pé àwọn ọkọ kan ti ń ronú báwọn èèyàn ayé ṣe ń ronú, wọ́n sì ń hùwà burúkú síyàwó wọn. b Báwo ni Jèhófà ṣe fẹ́ kí ọkọ máa ṣe síyàwó ẹ̀? Ìdáhùn ẹ̀ wà nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí àpilẹ̀kọ yìí dá lé.

5. Báwo ló ṣe yẹ kí ọkọ máa hùwà síyàwó ẹ̀ bí 1 Pétérù 3:7 ṣe sọ?

5 Ka 1 Pétérù 3:7. Jèhófà pàṣẹ fáwọn ọkọ pé kí wọ́n máa bọlá fún ìyàwó wọn. Ẹni tá a kà séèyàn pàtàkì la máa ń bọlá fún. Ọkọ tó ń bọlá fún ìyàwó ẹ̀ máa ń ṣìkẹ́ ẹ̀. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ bí ọkọ ṣe lè máa bọlá fún ìyàwó ẹ̀. Àmọ́, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tí ọkọ ò gbọ́dọ̀ ṣe síyàwó ẹ̀.

MÁ HÙWÀ TÍ Ò DÁA SÍYÀWÓ Ẹ

6. Kí ni Jèhófà sọ nípa àwọn ọkùnrin tó ń lu ìyàwó wọn? (Kólósè 3:19)

6 Kò gbọ́dọ̀ lu ìyàwó ẹ̀. Jèhófà kórìíra ẹni tó bá ń hùwà ipá. (Sm. 11:5) Jèhófà sọ pé ọkọ ò gbọ́dọ̀ hùwà ìkà síyàwó ẹ̀. (Mál. 2:16; ka Kólósè 3:19.)1 Pétérù 3:7 tí àpilẹ̀kọ yìí dá lé ṣe sọ, tí ọkọ ò bá hùwà tó dáa síyàwó ẹ̀, inú Ọlọ́run ò ní dùn sí i. Jèhófà sì lè má gbọ́ àdúrà ẹ̀.

7. Irú àwọn ọ̀rọ̀ wo ni ọkọ ò gbọ́dọ̀ sọ síyàwó ẹ̀ bí Éfésù 4:31, 32 ṣe sọ? (Tún wo “Àlàyé Ọ̀rọ̀.”)

7 Kò gbọ́dọ̀ bú ìyàwó ẹ̀. Àwọn ọkọ kan máa ń bínú síyàwó wọn, wọ́n sì máa ń bú wọn. Àmọ́ Jèhófà kórìíra “ìrunú, ariwo àti ọ̀rọ̀ èébú.” c (Ka Éfésù 4:31, 32.) Jèhófà máa ń gbọ́ ohun tá a sọ sáwọn èèyàn. Ó máa ń kíyè sí ohun tọ́kọ bá ń sọ síyàwó ẹ̀ kódà nígbà táwọn èèyàn ò sí lọ́dọ̀ wọn. Ọkọ tó máa ń sọ̀rọ̀ ṣàkàṣàkà síyàwó ẹ̀ máa ba àárín òun àtìyàwó ẹ̀ jẹ́, ó sì tún máa sọ ara ẹ̀ di ọ̀tá Ọlọ́run.—Jém. 1:26.

8. Ṣé inú Jèhófà máa dùn téèyàn bá ń wo àwòrán tàbí fíìmù ìṣekúṣe, kí nìdí?

8 Kò gbọ́dọ̀ wo àwòrán tàbí fíìmù ìṣekúṣe. Ṣé inú Jèhófà máa dùn téèyàn bá ń wo àwòrán tàbí fíìmù ìṣekúṣe? Rárá, ó kórìíra ẹ̀. Torí náà, tí ọkọ kan bá ń wo ìwòkuwò, á ba àárín òun àti Jèhófà jẹ́, á sì tún bu ìyàwó ẹ̀ kù. d Jèhófà fẹ́ kí ọkọ jẹ́ olóòótọ́ sí ìyàwó ẹ̀, kó sì máa ṣe bẹ́ẹ̀ nínú ìwà àti èrò ẹ̀. Jésù sọ pé ọkùnrin tó bá ń tẹjú mọ́ obìnrin kan lọ́nà táá fi wù ú láti bá a ṣe ìṣekúṣe ti ṣe àgbèrè “nínú ọkàn” ẹ̀. eMát. 5:28, 29.

9. Kí nìdí tí Jèhófà fi kórìíra kí ọkọ máa ṣe ohun tí ìyàwó ẹ̀ ò fẹ́ nígbà ìbálòpọ̀?

9 Kò gbọ́dọ̀ ṣe ohun tí ìyàwó ẹ̀ ò fẹ́ nígbà ìbálòpọ̀. Àwọn ọkọ kan máa ń fipá mú ìyàwó wọn láti ṣe ohun tí ò fẹ́ nígbà ìbálòpọ̀ tàbí ohun tí ẹ̀rí ọkàn ẹ̀ ò gbà láyè. Jèhófà kórìíra ìwà ìkà àti àìgbatẹnirò yìí. Jèhófà fẹ́ kí ọkọ nífẹ̀ẹ́ ìyàwó ẹ̀, kó máa ṣìkẹ́ ẹ̀, kó sì máa gba tiẹ̀ rò. (Éfé. 5:28, 29) Kí ló yẹ kí ọkọ tó ń ṣe ohun tí ìyàwó ẹ̀ ò fẹ́ nígbà ìbálòpọ̀ ṣe? Kí ló sì yẹ kí ọkọ tó ń wo àwòrán tàbí fíìmù ìṣekúṣe ṣe? Kí ló máa jẹ́ kó yí èrò àti ìṣe ẹ̀ pa dà?

BÍ ỌKỌ ṢE LÈ JÁWỌ́ NÍNÚ ÌWÀ TÍ Ò DÁA

10. Kí làwọn ọkọ lè kọ́ lára Jésù?

10 Kí ló máa jẹ́ kí ọkọ jáwọ́ nínú ìwà burúkú tó ń hù síyàwó ẹ̀ àtohun tó lè tàbùkù sí i? Ó yẹ kó ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti fara wé Jésù. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jésù ò fẹ́yàwó, bó ṣe hùwà sáwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ jẹ́ káwọn ọkọ mọ bó ṣe yẹ kí wọ́n máa hùwà síyàwó wọn. (Éfé. 5:25) Bí àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ka wo ohun táwọn ọkọ lè kọ́ lára Jésù, bó ṣe hùwà sáwọn àpọ́sítélì ẹ̀ àti bó ṣe bá wọn sọ̀rọ̀.

11. Báwo ni Jésù ṣe hùwà sáwọn àpọ́sítélì ẹ̀?

11 Jésù máa ń hùwà pẹ̀lẹ́ sáwọn àpọ́sítélì ẹ̀, ó sì máa ń buyì kún wọn. Kì í kanra mọ́ wọn, kì í sì í jọ̀gá lé wọn lórí. Lóòótọ́, Ọ̀gá àti Olúwa wọn ni Jésù, àmọ́ kò lo agbára ẹ̀ nílòkulò kó lè fi hàn pé òun láṣẹ lórí wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó rẹ ara ẹ̀ sílẹ̀, ó sì ràn wọ́n lọ́wọ́. (Jòh. 13:12-17) Ó sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ pé: ‘Ẹ kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ mi, torí oníwà tútù àti ẹni tó rẹlẹ̀ ní ọkàn ni mí, ara sì máa tù yín.’ (Mát. 11:28-30) Kíyè sí i pé oníwà tútù ni Jésù. Ẹni tó níwà tútù kì í ṣe ọ̀dẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó gbọ́n, ó sì lè kó ara ẹ̀ níjàánú. Tí wọ́n bá mú un bínú, kì í fara ya, ó sì lámùúmọ́ra.

12. Báwo ni Jésù ṣe máa ń báwọn èèyàn sọ̀rọ̀?

12 Ọ̀rọ̀ Jésù máa ń tu àwọn èèyàn lára. Kì í sọ̀rọ̀ ṣàkàṣàkà sáwọn èèyàn. (Lúùkù 8:47, 48) Kódà nígbà táwọn alátakò kàn án lábùkù, tí wọ́n sì mú un bínú, “kò sọ̀rọ̀ àbùkù sí wọn pa dà.” (1 Pét. 2:21-23) Nígbà míì, Jésù máa ń mọ̀ọ́mọ̀ dákẹ́ dípò kó fìbínú dá wọn lóhùn. (Mát. 27:12-14) Ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ àtàtà tó yẹ káwọn ọkọ máa tẹ̀ lé nìyẹn!

13. Báwo ni ọkọ ṣe lè “fà mọ́ ìyàwó rẹ̀” bí Mátíù 19:4-6 ṣe sọ? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

13 Jésù sọ fáwọn ọkọ pé kí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ síyàwó wọn. Ohun tí Bàbá ẹ̀ sọ lòun náà sọ fún wọn, nígbà tó ní kí ọkọ “fà mọ́ ìyàwó rẹ̀.” (Ka Mátíù 19:4-6.) Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà, “fà mọ́” tí wọ́n lò nínú ẹsẹ yìí túmọ̀ sí “lẹ̀ pọ̀.” Torí náà, àjọṣe àárín ọkọ àti ìyàwó gbọ́dọ̀ lágbára bí ìgbà téèyàn lẹ nǹkan méjì pọ̀. Tí nǹkan kan bá ṣẹlẹ̀ tó fẹ́ yà wọ́n sọ́tọ̀, àwọn méjèèjì ló máa jìyà ẹ̀. Torí náà, ọkọ tí àjọṣe òun àtìyàwó ẹ̀ lágbára kò ní máa wo àwòrán tàbí fíìmù ìṣekúṣe. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló máa gbójú ẹ̀ kúrò kó má bàa “wo ohun tí kò ní láárí.” (Sm. 119:37) Bákan náà, á pinnu pé yàtọ̀ síyàwó òun, òun ò ní wo obìnrin míì débi táá fi wu òun láti bá a lò pọ̀.—Jóòbù 31:1.

Torí pé ọkọ kan jẹ́ olóòótọ́ sí ìyàwó ẹ̀, kò wo àwòrán ìṣekúṣe (Wo ìpínrọ̀ 13) g


14. Àwọn nǹkan wo ni ọkọ tó ń hùwà burúkú síyàwó ẹ̀ gbọ́dọ̀ ṣe kí àjọṣe ẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà àtìyàwó ẹ̀ lè pa dà dára?

14 Kí làwọn nǹkan tí ọkọ tó ń lu ìyàwó ẹ̀ tàbí tó ń bú u gbọ́dọ̀ ṣe kí àjọṣe ẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà àtìyàwó ẹ̀ lè pa dà dára? Àkọ́kọ́, ó gbọ́dọ̀ gbà pé ìṣòro ńlá lòun ní àti pé kò sóhun tó pa mọ́ lójú Jèhófà. (Sm. 44:21; Oníw. 12:14; Héb. 4:13) Ìkejì, kò gbọ́dọ̀ lu ìyàwó ẹ̀ mọ́, kò sì gbọ́dọ̀ bú u mọ́. (Òwe 28:13) Ìkẹta, kó tọrọ àforíjì lọ́dọ̀ ìyàwó ẹ̀ àti Jèhófà pé kí wọ́n dárí ji òun. (Ìṣe 3:19) Ó tún yẹ kó bẹ Jèhófà pé kó wu òun láti yí pa dà, kóun sì lè máa ṣọ́ èrò, ọ̀rọ̀ àti ìṣe òun. (Sm. 51:10-12; 2 Kọ́r. 10:5; Fílí. 2:13) Ìkẹrin, ó yẹ kó máa ṣe nǹkan táá jẹ́ kí àdúrà ẹ̀ gbà, ìyẹn ni pé kó kórìíra ìwà ipá àti ọ̀rọ̀ èébú. (Sm. 97:10) Ìkarùn-ún, kó sọ fún àwọn alàgbà kí wọ́n lè tètè ràn án lọ́wọ́. (Jém. 5:14-16) Ìkẹfà, kó máa ṣe àwọn nǹkan tí ò ní jẹ́ kó pa dà sídìí ìwà náà mọ́. Ọkọ tó bá ń wo àwòrán tàbí fíìmù ìṣekúṣe gbọ́dọ̀ ṣe àwọn nǹkan tá a sọ yìí. Ó dájú pé Jèhófà máa ràn án lọ́wọ́ kó lè yí ìwà ẹ̀ pa dà. (Sm. 37:5) Àmọ́, kì í ṣe pé kí ọkọ jáwọ́ nínú ìwà tí ò dáa nìkan ni. Ó tún yẹ kó mọ bá á ṣe máa bọlá fún ìyàwó ẹ̀. Báwo ló ṣe máa ṣe é?

BÍ ỌKỌ ṢE LÈ MÁA BỌLÁ FÚN ÌYÀWÓ Ẹ̀

15. Àwọn nǹkan wo ló yẹ kí ọkọ máa ṣe tó máa fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ ìyàwó ẹ̀ lóòótọ́?

15 Jẹ́ kó mọ̀ pé o nífẹ̀ẹ́ ẹ̀. Àwọn arákùnrin táwọn àtìyàwó wọn ń láyọ̀ máa ń ṣe ohun kan fún ìyàwó wọn lójoojúmọ́ láti fi hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ ẹ̀. (1 Jòh. 3:18) Ọkọ lè fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ ìyàwó òun tó bá ń ṣe àwọn nǹkan kéékèèké fún un, bíi kó máa dì í lọ́wọ́ mú, kó sì máa gbá a mọ́ra. Ó lè máa fi àtẹ̀jíṣẹ́ ránṣẹ́ sí i, kó sọ pé, “Àárò ẹ ń sọ mí” tàbí kó bi í pé “Báwo ni, ṣó o wà?” Látìgbàdégbà, ó lè máa fi hàn póun nífẹ̀ẹ́ ẹ̀, kó sì máa kọ ọ̀rọ̀ ìfẹ́ sínú káàdì fún un. Tí ọkọ bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí, á fi hàn pé ó ń bọlá fún ìyàwó ẹ̀, àwọn méjèèjì á sì túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ ara wọn.

16. Kí nìdí tó fi yẹ kí ọkọ máa yin ìyàwó ẹ̀?

16 Sọ fún un pé o mọyì ẹ̀ gan-an. Ọkọ tó ń bọlá fún ìyàwó ẹ̀ máa ń fún un níṣìírí, ó sì máa ń jẹ́ kórí ẹ̀ wú. Ó máa ń rántí láti dúpẹ́ lọ́wọ́ ìyàwó ẹ̀ torí gbogbo ohun tó ń ṣe láti tì í lẹ́yìn. (Kól. 3:15) Tí ọkọ bá ń yin ìyàwó ẹ̀ látọkàn wá, ó máa múnú ìyàwó ẹ̀ dùn gan-an. Ọkàn ìyàwó ẹ̀ á balẹ̀, á mọ̀ pé ó nífẹ̀ẹ́ òun, ó sì ń bọlá fóun.—Òwe 31:28.

17. Báwo ni ọkọ ṣe lè máa bọ̀wọ̀ fún ìyàwó ẹ̀?

17 Máa bọ̀wọ̀ fún un, kó o sì máa ṣìkẹ́ ẹ̀. Ọkọ tó nífẹ̀ẹ́ ìyàwó ẹ̀ máa ń mọyì ẹ̀, ó máa ń ṣìkẹ́ ẹ̀, ó sì gbà pé ẹ̀bùn iyebíye ló jẹ́ látọ̀dọ̀ Jèhófà. (Òwe 18:22; 31:10) Torí ẹ̀, ó máa ń ṣe é jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́, ó sì máa ń bọ̀wọ̀ fún un kódà nígbà tí wọ́n bá ń ní ìbálòpọ̀. Kò ní fipá mú ìyàwó ẹ̀ láti ṣe ohun tí ò fẹ́ nígbà ìbálòpọ̀ tàbí ohun tí ẹ̀rí ọkàn ẹ̀ ò gbà láyè. f Ó sì yẹ kí ọkọ ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́ níwájú Jèhófà.—Ìṣe 24:16.

18. Kí ló yẹ káwọn ọkọ pinnu láti ṣe? (Wo àpótí náà, “ Nǹkan Mẹ́rin Táá Jẹ́ Kí Ọkọ Máa Bọ̀wọ̀ fún Ìyàwó Ẹ̀.”)

18 Ẹ̀yin ọkọ, ó dájú pé Jèhófà ń rí gbogbo ohun tẹ́ ẹ̀ ń ṣe láti bọlá fún ìyàwó yín, ó sì mọyì ẹ̀. Bó o ṣe lè máa bọlá fún ìyàwó ẹ ni pé kó o má ṣe hùwà burúkú sí i, kó o máa ṣìkẹ́ ẹ̀, kó o máa bọ̀wọ̀ fún un, kó o sì máa fìfẹ́ hàn sí i. Ìyẹn lá jẹ́ kí ìyàwó ẹ mọ̀ pé o nífẹ̀ẹ́ òun, o sì mọyì òun. Torí náà, máa bọlá fún ìyàwó ẹ, tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wàá máa jẹ́ ọ̀rẹ́ Jèhófà títí lọ, ìyẹn ló sì ṣe pàtàkì jù.—Sm. 25:14.

ORIN 131 “Ohun Tí Ọlọ́run So Pọ̀”

a Àwọn ọkọ máa jàǹfààní tí wọ́n bá ka àpilẹ̀kọ náà, “Ṣé Ojú Tí Jèhófà Fi Ń Wo Àwọn Obìnrin Lo Fi Ń Wò Wọ́n?” nínú Ilé Ìṣọ́ January 2024.

b Àwọn ìyàwó tí wọ́n hùwà ìkà sí máa jàǹfààní tí wọ́n bá ka àpilẹ̀ko náà, “Ìrànlọ́wọ́ fún Àwọn Tí Wọ́n Ń Fìyà Jẹ Nínú Ilé” ní abala “Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò” lórí jw.org àti JW Library®.

c ÀLÀYÉ Ọ̀RỌ̀: “Ọ̀rọ̀ èébú” ni kéèyàn máa pe ẹnì kan lórúkọ tó máa dójú tì í tàbí kó máa ṣàríwísí ẹni náà ṣáá. Tí ọkọ bá sọ ohun tó bu ìyàwó ẹ̀ kù tàbí tó ń fi ṣe yẹ̀yẹ́, ó ti sọ̀rọ̀ èébú sí i nìyẹn.

d Wo àpilẹ̀kọ náà “Wíwo Àwòrán Ìṣekúṣe Lè Tú Ìgbéyàwó Rẹ Ká” lórí jw.org. Wàá tún rí àpilẹ̀kọ yìí lórí JW Library ní abala Ohun Tó Wà Lórí Ìkànnì, wo “Ìrànlọ́wọ́ fún Ìdílé.”

e Tí ọkọ ẹ bá ń wo àwòrán ìṣekúṣe, wàá rí ohun tó o lè ṣe tó o bá ka àpilẹ̀kọ náà “Tí Ọkọ Tàbí Aya Kan Bá Ń Wo Àwòrán Ìṣekúṣe” nínú Ilé Ìṣọ́ August 2023.

f Bíbélì ò sọ ọ̀nà tó tọ́ tàbí èyí tí kò tọ́ tó yẹ kí tọkọtaya máa gbà ní ìbálòpọ̀. Tọkọtaya ló máa pinnu ohun tí wọ́n máa ṣe táá múnú Jèhófà dùn, táá jẹ́ kí wọ́n tẹ́ ara wọn lọ́rùn, táá sì jẹ́ kí wọ́n ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́. Àmọ́ o, tọkọtaya ò ní sọ ohun tí wọ́n bá ń ṣe nígbà ìbálòpọ̀ fún ẹnikẹ́ni.

g ÀWÒRÁN: Àwọn ọkùnrin kan tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà fẹ́ fipá mú arákùnrin kan tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ pé kó wo àwòrán ìṣekúṣe.