Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 1

ORIN 2 Jèhófà Ni Orúkọ Rẹ

Ẹ Máa Yin Jèhófà Lógo

Ẹ Máa Yin Jèhófà Lógo

ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́ TI ỌDÚN 2025: “Ẹ fún Jèhófà ní ògo tí ó yẹ orúkọ rẹ̀.”SM. 96:8.

OHUN TÁ A MÁA KỌ́

A máa kẹ́kọ̀ọ́ bá a ṣe lè máa yin Jèhófà lógo.

1. Kí lọ̀pọ̀ èèyàn máa ń ṣe lónìí?

 Ó ṢEÉ ṣe kó o ti kíyè sí i pé lásìkò wa yìí, àwọn èèyàn ò mọ̀ ju tara wọn lọ. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n máa ń ṣe àṣehàn lórí ìkànnì àjọlò, wọ́n sì máa ń gbé ara wọn gẹ̀gẹ̀ káwọn èèyàn lè mọ ohun tí wọ́n ti gbé ṣe. Àmọ́, àwọn tó ń yin Jèhófà Ọlọ́run lógo lónìí ò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa bá a ṣe lè máa yin Jèhófà lógo àti ìdí tó fi yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀. A tún máa mọ bá a ṣe lè máa yin Ọlọ́run lógo bó ṣe yẹ àti bóun fúnra ẹ̀ ṣe máa ya orúkọ ẹ̀ sí mímọ́ láìpẹ́.

BÁWO LA ṢE LÈ MÁA YIN JÈHÓFÀ LÓGO?

2. Báwo ni Jèhófà ṣe fi agbára ẹ̀ hàn ní Òkè Sínáì? (Tún wo àwòrán.)

2 Kí ni ògo? Nínú Bíbélì, ọ̀rọ̀ náà “ògo” túmọ̀ sí ohunkóhun tó máa jẹ́ kí ẹnì kan gbayì. Lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀ tí Jèhófà gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sílẹ̀ lóko ẹrú Íjíbítì, ó jẹ́ kí wọ́n rí bí agbára òun ṣe pọ̀ tó. Ẹ fojú inú wo ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ yẹn. Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kóra jọ sítòsí Òkè Sínáì kí wọ́n lè gbọ́ ohun tí Jèhófà fẹ́ sọ fún wọn. Ìkùukùu tó ṣú dùdù bo orí òkè náà. Lójijì, ìmìtìtì ilẹ̀ ṣẹlẹ̀, òkè náà ń yọ iná àti èéfín, mànàmáná kọ, àrá ń sán, ìwo sì ń dún sókè gan-an. (Ẹ́kís. 19:16-18; 24:17; Sm. 68:8) Ẹ wo bí ẹnu ṣe máa ya àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n rí bí agbára Jèhófà ṣe pọ̀ tó.

Ní Òkè Sínáì, Jèhófà ṣe ohun tó jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì rí i pé agbára òun pọ̀ gan-an (Wo ìpínrọ̀ 2)


3. Báwo la ṣe lè máa yin Jèhófà lógo?

3 Ṣé àwa èèyàn lè yin Jèhófà lógo? Bẹ́ẹ̀ ni, a lè ṣe bẹ́ẹ̀. Ọ̀nà kan tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ká máa sọ fáwọn èèyàn nípa bí agbára Jèhófà ṣe pọ̀ tó àtàwọn ànímọ́ tó dáa tó ní. Bákan náà, a lè yin Ọlọ́run lógo tá a bá ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé òun ló ń ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe gbogbo nǹkan tá à ń ṣe. (Àìsá. 26:12) Ọba Dáfídì yin Jèhófà lógo, àpẹẹrẹ tó dáa ló sì jẹ́ fún wa. Nígbà tó ń gbàdúrà níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó sọ fún Ọlọ́run pé: “Jèhófà, tìrẹ ni títóbi àti agbára ńlá àti ẹwà àti ògo àti ọlá ńlá, nítorí gbogbo ohun tó wà ní ọ̀run àti ní ayé jẹ́ tìrẹ.” Lẹ́yìn tí Dáfídì gbàdúrà tán, ‘gbogbo ìjọ náà yin Jèhófà lógo.’—1 Kíró. 29:11, 20.

4. Báwo ni Jésù ṣe yin Jèhófà lógo?

4 Nígbà tí Jésù wà láyé, ó máa ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé Bàbá òun ló fún òun lágbára tóun fi ń ṣiṣẹ́ ìyanu. (Máàkù 5:18-20) Ohun míì tí Jésù ṣe tó fi hàn pé ó yin Jèhófà lógo ni pé ó máa ń sọ̀rọ̀ nípa Bàbá ẹ̀ fáwọn èèyàn, ó sì máa ń hùwà dáadáa sí wọn. Lọ́jọ́ kan tí Jésù ń kọ́ àwọn èèyàn nínú sínágọ́gù, obìnrin kan tí ẹ̀mí èṣù ń dà láàmú fún ọdún méjìdínlógún (18) wà lára àwọn tó ń gbọ́rọ̀ ẹ̀. Ẹ̀mí èṣù yẹn ti jẹ́ kí ẹ̀yìn obìnrin náà tẹ̀ débi tí kò fi lè nàró rárá. Ẹ ò rí i pé ìnira yẹn máa pọ̀ gan-an! Àánú obìnrin náà ṣe Jésù, ó sún mọ́ ọn, ó sì bá a sọ̀rọ̀ lọ́nà pẹ̀lẹ́, ó sọ pé: “Obìnrin, a tú ọ sílẹ̀ kúrò nínú àìlera rẹ.” Jésù wá gbé ọwọ́ lé obìnrin náà, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ó nàró ṣánṣán “ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í yin Ọlọ́run lógo” torí pé ara ẹ̀ ti yá! (Lúùkù 13:10-13) Ó yẹ kí obìnrin yẹn yin Ọlọ́run lógo lóòótọ́, ohun tó sì yẹ káwa náà máa ṣe nìyẹn.

KÍ NÌDÍ TÓ FI YẸ KÁ MÁA YIN JÈHÓFÀ LÓGO?

5. Àwọn nǹkan wo ló ń jẹ́ ká máa bọ̀wọ̀ fún Jèhófà?

5 Tá a bá ń bọ̀wọ̀ fún Jèhófà, à ń yìn ín lógo nìyẹn. Ọ̀pọ̀ nǹkan ni Jèhófà ti ṣe tó fi yẹ ká máa bọ̀wọ̀ fún un. Alágbára ńlá ni Jèhófà, agbára ẹ̀ ò sì láàlà. (Sm. 96:4-7) À ń rí ọgbọ́n Ọlọ́run lára àwọn ohun tó dá. Òun ló dá wa, tó sì fún wa ní gbogbo ohun táá jẹ́ ká gbádùn ayé wa. (Ìfi. 4:11) Ó tún jẹ́ adúróṣinṣin. (Ìfi. 15:4) Kò sóun tí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ tí ò ní parí, ó sì máa ń mú gbogbo ìlérí ẹ̀ ṣẹ. (Jóṣ. 23:14) Abájọ tí wòlíì Jeremáyà fi sọ nípa Jèhófà pé: “Láàárín gbogbo ọlọ́gbọ́n tó wà ní àwọn orílẹ̀-èdè àti ní gbogbo ìjọba wọn, kò sí ẹnì kankan tó dà bí rẹ”! (Jer. 10:6, 7) Ká sòótọ́, àwọn nǹkan tí Baba wa ọ̀run ti ṣe fún wa yìí yẹ kó mú ká máa bọ̀wọ̀ fún un. Àmọ́ kì í ṣe pé à ń bọ̀wọ̀ fún Jèhófà nìkan ni, a tún nífẹ̀ẹ́ ẹ̀.

6. Kí nìdí tá a fi nífẹ̀ẹ́ Jèhófà?

6 Tá a bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tọkàntọkàn, à ń yìn ín lógo nìyẹn. Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa àwọn ànímọ́ Jèhófà tó jẹ́ ká nífẹ̀ẹ́ ẹ̀. Aláàánú ni, ó sì máa ń gba tẹni rò. (Sm. 103:13; Àìsá. 49:15) Tá a bá ń jìyà, ó máa ń dùn ún. (Sek. 2:8) Jèhófà tún mú kó rọrùn fún wa láti sún mọ́ òun, ká sì di ọ̀rẹ́ ẹ̀. (Sm. 25:14; Ìṣe 17:27) Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà nírẹ̀lẹ̀ torí “ó tẹ̀ ba láti wo ọ̀run àti ayé, ó ń gbé aláìní dìde látinú eruku.” (Sm. 113:6, 7) Tá a bá ronú nípa àwọn nǹkan tá a sọ yìí, kò sẹ́ni tí ò ní fẹ́ yin Ọlọ́run lógo nínú wa.—Sm. 86:12.

7. Àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ wo la ní?

7 Tá a bá ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ ẹni tí Jèhófà jẹ́, à ń yìn ín lógo nìyẹn. Ọ̀pọ̀ èèyàn ni ò mọ ẹni tí Jèhófà jẹ́. Kí nìdí? Ìdí ni pé Sátánì ti pa oríṣiríṣi irọ́ mọ́ Jèhófà, àwọn èèyàn sì gba irọ́ náà gbọ́. (2 Kọ́r. 4:4) Sátánì ti mú káwọn èèyàn gbà pé òǹrorò ni Jèhófà, pé kò láàánú àti pé òun ló fa ìyà tó ń jẹ àwa èèyàn. Àmọ́ àwa mọ ẹni tí Jèhófà jẹ́ gan-an! A tún láǹfààní láti jẹ́ káwọn èèyàn mọ ẹni tó jẹ́, ká sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti máa yìn ín lógo. (Àìsá. 43:10) Ohun tí Sáàmù kẹrìndínlọ́gọ́rùn-ún (96) dá lé ni bá a ṣe lè máa yin Jèhófà lógo. Bá a ṣe ń jíròrò ohun tó wà nínú Sáàmù yìí, kíyè sí àwọn ohun tó o lè ṣe kó o lè máa yin Jèhófà lógo bó ṣe yẹ.

BÁWO LA ṢE LÈ MÁA YIN JÈHÓFÀ LÓGO BÓ ṢE YẸ?

8. Sọ ọ̀kan lára ọ̀nà tá a lè gbà fògo fún Jèhófà. (Sáàmù 96:1-3)

8 Ka Sáàmù 96:1-3. Tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà, à ń yìn ín lógo nìyẹn. Àwọn ẹsẹ yìí rọ àwọn èèyàn Jèhófà pé kí wọ́n “kọrin sí Jèhófà,” kí wọ́n “yin orúkọ rẹ̀,” kí wọ́n “máa kéde ìhìn rere ìgbàlà rẹ̀,” kí wọ́n sì “máa kéde ògo rẹ̀ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè.” Tá a bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí, à ń yin Baba wa ọ̀run nìyẹn. Àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà nígbà àtijọ́ àtàwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ máa ń sọ ẹni tí Jèhófà jẹ́ fáwọn èèyàn àtàwọn nǹkan rere tó ṣe fún wọn. (Dán. 3:16-18; Ìṣe 4:29) Báwo làwa náà ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀?

9-10. Kí la kọ́ lára Angelena? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

9 Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Arábìnrin Angelena a tó ń gbé orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ó fìgboyà sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà níbi tó ti ń ṣiṣẹ́. Torí pé wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ gba Angelena síṣẹ́, wọ́n pe òun àtàwọn míì tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà síṣẹ́ sípàdé kan kí wọ́n lè túbọ̀ mọ̀ wọ́n dáadáa, kí wọ́n sì sọ ẹni tí wọ́n jẹ́. Torí náà, Angelena kó àwọn fọ́tò ẹ̀ kan sórí kọ̀ǹpútà kí wọ́n lè wò ó, kí wọ́n sì lè mọ̀ pé òun máa ń láyọ̀ torí pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà lòun. Àmọ́ kọ́rọ̀ tó kàn án, ọkùnrin kan tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ sọ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn òbí òun. Ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í sọ ohun tí ò dáa nípa ohun táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́. Angelena sọ pé: “Ẹ̀rù bà mí gan-an. Ṣùgbọ́n mo bi ara mi pé: ‘Ṣé bí màá ṣe káwọ́ gbera nìyí, tí màá sì jẹ́ kí ọkùnrin yìí máa sọ ohun tí ò dáa nípa Jèhófà? Àbí màá jẹ́ kí wọ́n mọ ẹni tí Jèhófà jẹ́ gan-an?’”

10 Nígbà tẹ́ni náà sọ̀rọ̀ tán, Angelena gbàdúrà sí Jèhófà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Dípò kó bínú, ṣe ló rọra sọ fún un pé: “Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn tó tọ́ èmi náà dàgbà, mi ò sì fi Jèhófà sílẹ̀ títí di báyìí.” Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àyà Angelena ń já, ó fara balẹ̀ ṣàlàyé ohun tó gbà gbọ́ fún wọn, ó tún fi fọ́tò tóun àtàwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ yà láwọn àpéjọ wa hàn wọ́n. (1 Pét. 3:15) Kí ló wá ṣẹlẹ̀? Nígbà tí Angelena máa fi parí ọ̀rọ̀ ẹ̀, ara ọkùnrin náà ti balẹ̀ gan-an. Kódà, ó sọ pé òun rántí àwọn nǹkan dáadáa tóun ṣe nígbà tóun wà lọ́dọ̀ọ́ tóun ṣì jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Angelena sọ pé: “Ó yẹ ká máa sọ ohun tó dáa nípa Jèhófà táwọn èèyàn bá tiẹ̀ ń sọ ohun tí ò jóòótọ́ nípa ẹ̀. Àǹfààní ńlá la ní pé à ń sọ òtítọ́ nípa Jèhófà.” Torí náà, ó yẹ káwa náà máa yin Jèhófà lógo, ká sì máa bọ̀wọ̀ fún un táwọn èèyàn bá tiẹ̀ ń parọ́ mọ́ ọn.

A lè fi ọ̀rọ̀ ẹnu wa, àwọn ohun ìní wa àti ìwà wa yin Ọlọ́run lógo (Wo ìpínrọ̀ 9-10) b


11. Báwo làwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà láti ọjọ́ tó ti pẹ́ ṣe ń fi ohun tó wà ní Sáàmù 96:8 sílò?

11 Ka Sáàmù 96:8. A lè fi ohun ìní wa yin Jèhófà. Ó ti pẹ́ táwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà ti máa ń fi ohun ìní wọn yìn ín. (Òwe 3:9) Bí àpẹẹrẹ, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kó owó àtàwọn ohun ìní wọn wá kí wọ́n lè fi kọ́ tẹ́ńpìlì, kí wọ́n sì fi tún un ṣe. (2 Ọba 12:4, 5; 1 Kíró. 29:3-9) Bákan náà, àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù fi “àwọn ohun ìní wọn” ṣe ìránṣẹ́ fún un àtàwọn àpọ́sítélì ẹ̀. (Lúùkù 8:1-3) Yàtọ̀ síyẹn, àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ fi àwọn nǹkan ìrànwọ́ ránṣẹ́ sáwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wọn tó ń gbé níbi tí ìyàn ti mú. (Ìṣe 11:27-29) Torí náà, lónìí àwa náà lè yin Jèhófà lógo tá a bá ń lo àwọn ohun ìní wa nínú ìjọsìn ẹ̀.

12. Báwo ni owó tá a fi ń ṣètìlẹyìn ṣe ń yin Jèhófà lógo? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

12 Ẹ jẹ́ ká wo bí owó tá a fi ń ṣètìlẹyìn ṣe ń yin Jèhófà lógo. Ìrírí kan rèé. Lọ́dún 2020, ìròyìn kan sọ pé ọ̀gbẹlẹ̀ kan wáyé lórílẹ̀-èdè Sìǹbábúwè tó fìyà jẹ àwọn èèyàn, ó sì pẹ́ kó tó lọ. Ọ̀pọ̀ èèyàn lebi fẹ́rẹ̀ẹ́ pa kú títí kan arábìnrin kan tó ń jẹ́ Prisca. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀gbẹlẹ̀ náà mú gan-an, Arábìnrin Prisca ṣì máa ń wàásù ní gbogbo ọjọ́ Wednesday àti Friday, kódà ó ń ṣe bẹ́ẹ̀ lásìkò tí wọ́n ń gbin nǹkan. Àwọn aládùúgbò ẹ̀ máa ń bú u torí pé ó ń lọ wàásù dípò kó máa lọ sóko lójoojúmọ́, wọ́n máa ń sọ fún un pé, “Ebi ló máa pa ẹ́ kú.” Prisca máa ń sọ fún wọn pé, “Jèhófà ò já àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ kulẹ̀ rí.” Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, ètò Ọlọ́run kó àwọn nǹkan ìrànwọ́ wá fún un. Àwọn owó tẹ́nì kọ̀ọ̀kan wa fi ń ṣètìlẹyìn ló jẹ́ kí wọ́n lè ṣerú ètò bẹ́ẹ̀. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn wú àwọn aládùúgbò Prisca lórí gan-an, wọ́n wá sọ fún un pé, “Ọlọ́run ẹ ò já ẹ kulẹ̀ lóòótọ́, àwa náà fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run yẹn.” Kí ló wá ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ìyẹn? Méje lára àwọn aládùúgbò ẹ̀ ló bẹ̀rẹ̀ sí í wá sípàdé.

A lè fi àwọn ohun ìní wa yin Jèhófà lógo (Wo ìpínrọ̀ 12) c


13. Báwo la ṣe ń fi ìwà wa yin Jèhófà lógo? (Sáàmù 96:9)

13 Ka Sáàmù 96:9. A lè fi ìwà wa yin Jèhófà lógo. Ó ṣe pàtàkì gan-an pé káwọn àlùfáà tó ń ṣiṣẹ́ nínú tẹ́ńpìlì Jèhófà wẹ̀, kí gbogbo ara wọn sì mọ́ tónítóní. (Ẹ́kís. 40:30-32) Síbẹ̀, ìwà mímọ́ ṣe pàtàkì jùyẹn lọ. (Sm. 24:3, 4; 1 Pét. 1:15, 16) Torí náà, a gbọ́dọ̀ ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti bọ́ “ìwà àtijọ́” sílẹ̀, ìyẹn àwọn ìwà tínú Jèhófà ò dùn sí, ká sì fi “ìwà tuntun” wọ ara wa láṣọ. Ìyẹn ni pé ká jẹ́ kí èrò wa àti ìwà wa fi hàn pé à ń yin Jèhófà lógo. (Kól. 3:9, 10) Kò sẹ́ni tí Jèhófà ò lè ràn lọ́wọ́, kódà àwọn oníjàgídíjàgan àtàwọn tí ìṣekúṣe ti mọ́ lára lè yí pa dà, kí wọ́n sì gbé ìwà tuntun wọ̀.

14. Kí lo kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jack? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

14 Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jack. Ọ̀daràn ni, ó sì burú gan-an, kódà Èṣù ni wọ́n máa ń pè é. Nígbà tó yá, wọ́n dájọ́ ikú fún un torí àwọn ìwà burúkú tó ń hù. Àmọ́, kó tó dìgbà tí wọ́n máa pa á, arákùnrin kan tó ń wàásù lọ́gbà ẹ̀wọ̀n dé ọ̀dọ̀ wọn, Jack sì gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Láìka gbogbo ìwà burúkú tí Jack ń hù sí, ó yí pa dà, nígbà tó sì yá, ó ṣèrìbọmi. Jack yí pa dà débi pé lọ́jọ́ tí wọ́n fẹ́ pa á, ṣe làwọn ẹ̀ṣọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n kan ń sunkún nígbà tí wọ́n ń mú un lọ. Ọ̀kan lára àwọn ọlọ́pàá tó ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀ sọ pé: “Nígbà kan, Jack ló burú jù nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n yìí. Àmọ́, ní báyìí, ó wà lára àwọn tó dáa jù.” Ọ̀sẹ̀ kan lẹ́yìn tí wọ́n pa Jack, àwọn arákùnrin tó máa ń darí ìpàdé lọ́gbà ẹ̀wọ̀n yẹn lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ rí ọkùnrin kan tó wá sípàdé nígbà àkọ́kọ́. Kí ló jẹ́ kó wá síbẹ̀? Bí Jack ṣe yí pa dà wú u lórí gan-an, ó sì fẹ́ mọ ohun tóun náà máa ṣe láti jọ́sìn Jèhófà. Ẹ ò rí i pé a lè fi ìwà wa yin Jèhófà Baba wa ọ̀run lógo!—1 Pét. 2:12.

A lè fi ìwà wa yin Jèhófà lógo (Wo ìpínrọ̀ 14) d


BÁWO NI JÈHÓFÀ ṢE MÁA YA ORÚKỌ Ẹ̀ SÍ MÍMỌ́ LÁÌPẸ́?

15. Báwo ni Jèhófà ṣe máa ya orúkọ ẹ̀ sí mímọ́ láìpẹ́? (Sáàmù 96:10-13)

15 Ka Sáàmù 96:10-13. Àwọn ẹsẹ tó parí Sáàmù 96 jẹ́ ká mọ̀ pé Ọba àti Onídàájọ́ òdodo ni Jèhófà. Àmọ́ báwo ni Jèhófà ṣe máa ya orúkọ ẹ̀ sí mímọ́ lọ́jọ́ iwájú tí kò jìnnà mọ́? Ó máa ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tó bá pa àwọn èèyàn burúkú run torí onídàájọ́ òdodo ni. Láìpẹ́, ó máa pa Bábílónì Ńlá run torí ó ti ba orúkọ mímọ́ ẹ̀ jẹ́. (Ìfi. 17:5, 16; 19:1, 2) Ó ṣeé ṣe káwọn kan tó rí i pé Bábílónì Ńlá ti pa run náà wá jọ́sìn Jèhófà. Níkẹyìn, Jèhófà máa pa ayé burúkú tí Sátánì ń darí yìí run nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì, títí kan gbogbo àwọn tó ń ta kò ó, tí wọ́n sì ń ba orúkọ ẹ̀ jẹ́. Àmọ́ ó máa gba gbogbo àwọn tó nífẹ̀ẹ́ ẹ̀ là àtàwọn tó ń ṣègbọràn, tí wọ́n sì ń yìn ín lógo. (Máàkù 8:38; 2 Tẹs. 1:6-10) Lẹ́yìn àdánwò ìkẹyìn tó máa wáyé lẹ́yìn tí Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi bá parí, Jèhófà á ti dá orúkọ ẹ̀ láre pátápátá. (Ìfi. 20:7-10) Tó bá dìgbà yẹn, “gbogbo ayé yóò ní ìmọ̀ nípa ògo Jèhófà bí ìgbà tí omi bo òkun.”—Háb. 2:14.

16. Kí lo pinnu pé wàá ṣe? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

16 Ẹ wo bí inú wa ṣe máa dùn tó nígbà tí gbogbo àwọn tó wà láyé bá ń yin orúkọ Jèhófà lógo bó ṣe yẹ! Àmọ́ kó tó dìgbà yẹn, ẹ jẹ́ ká máa ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti máa yin Jèhófà lógo nígbà gbogbo. Ká lè túbọ̀ mọ bí ọ̀rọ̀ yìí ti ṣe pàtàkì tó, Ìgbìmọ̀ Olùdarí sọ pé Sáàmù 96:8 ni Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Ti Ọdún 2025. Ó ní: Ẹ fún Jèhófà ní ògo tí ó yẹ orúkọ rẹ̀.”

Láìpẹ́, gbogbo àwọn tó bá wà láàyè lá máa yin orúkọ Jèhófà lógo bó ṣe yẹ! (Wo ìpínrọ̀ 16)

ORIN 12 Jèhófà, Ọlọ́run Atóbilọ́lá

a A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.

b ÀLÀYÉ ÀWÒRÁN: Àwòrán tó jẹ́ ká rí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Angelena.

c ÀLÀYÉ ÀWÒRÁN: Àwòrán tó jẹ́ ká rí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Prisca.

d ÀLÀYÉ ÀWÒRÁN: Àwòrán tó jẹ́ ká rí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jack.