Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 5

ORIN 108 Ìfẹ́ Ọlọ́run Tí Kì Í Yẹ̀

Bá A Ṣe Ń Jàǹfààní Ìfẹ́ Tí Jèhófà Fi Hàn sí Wa

Bá A Ṣe Ń Jàǹfààní Ìfẹ́ Tí Jèhófà Fi Hàn sí Wa

“Kristi Jésù wá sí ayé láti gba àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ là.”1 TÍM. 1:15.

OHUN TÁ A MÁA KỌ́

A máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí ìràpadà ṣe ń ṣe wá láǹfààní àti bá a ṣe lè fi hàn pé a mọyì ìràpadà tí Jèhófà pèsè.

1. Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá fẹ́ múnú Jèhófà dùn?

 FOJÚ inú wò ó pé o fún ẹni tó o fẹ́ràn lẹ́bùn kan tó rẹwà, tó sì máa wúlò fún un. Ó máa dùn ẹ́ gan-an tó o bá rí i pé ẹni náà ju ẹ̀bùn náà síbì kan, tí ò sì lò ó! Àmọ́, ó dájú pé inú ẹ máa dùn tẹ́ni náà bá lo ẹ̀bùn náà dáadáa, tó sì tún dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ. Kí nìyẹn kọ́ wa? Jèhófà jẹ́ kí Ọmọ ẹ̀ kú nítorí wa. Ẹ ò rí i pé inú Jèhófà máa dùn gan-an tó bá rí i pé a mọyì ìràpadà àti ìfẹ́ tó ní sí wa tó mú kó pèsè ìràpadà náà!—Jòh. 3:16; Róòmù 5:7, 8.

2. Kí la máa kọ́ nínú àpilẹ̀kọ yìí?

2 Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ohun tó fi hàn pé a ò mọyì ìràpadà mọ́. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé inú wa dùn pé Ọlọ́run fún wa lẹ́bùn náà, ńṣe ló dà bí ìgbà tá a kàn ju ẹ̀bùn náà síbì kan. Tá ò bá fẹ́ kíyẹn ṣẹlẹ̀ sí wa, gbogbo ìgbà ló yẹ ká máa ronú nípa ohun tí Ọlọ́run àti Kristi ṣe fún wa. Ohun tá a máa kọ́ nínú àpilẹ̀kọ yìí nìyẹn. A máa sọ̀rọ̀ nípa àǹfààní tá à ń rí báyìí nínú ìràpadà àti àǹfààní tá a máa rí lọ́jọ́ iwájú. A tún máa sọ̀rọ̀ nípa bá a ṣe lè fi hàn pé a mọyì ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wa, pàápàá lásìkò Ìrántí Ikú Kristi yìí.

ÀǸFÀÀNÍ TÁ À Ń RÍ BÁYÌÍ

3. Sọ ọ̀kan lára àǹfààní tá à ń rí nínú ìràpadà báyìí.

3 A ti ń jàǹfààní ẹbọ ìràpadà Kristi báyìí. Bí àpẹẹrẹ, ìràpadà tí Jèhófà pèsè ló jẹ́ kó lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá. Kì í ṣe dandan pé kó ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́ ó wù ú kó dárí jì wá. Onísáàmù kan tó mọyì ohun tí Jèhófà ṣe fún un sọ pé: “Nítorí pé ẹni rere ni ọ́, Jèhófà, o sì ṣe tán láti dárí jini.”—Sm. 86:5; 103:3, 10-13.

4. Torí àwọn wo ni Jèhófà ṣe pèsè ìràpadà? (Lúùkù 5:32; 1 Tímótì 1:15)

4 Àwọn kan lè máa rò pé bóyá ni Jèhófà lè dárí jì wọ́n. Ká sòótọ́, kò sẹ́ni tó yẹ kí Jèhófà dárí jì nínú wa. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé òun ò “yẹ lẹ́ni tí à ń pè ní àpọ́sítélì” torí pé ó “ṣe inúnibíni sí ìjọ Ọlọ́run.” Àmọ́ ó tún sọ pé: “Nípa inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run, mo jẹ́ ohun tí mo jẹ́.” (1 Kọ́r. 15:9, 10) Tá a bá ronú pìwà dà ẹ̀ṣẹ̀ wa, Jèhófà máa dárí jì wá. Kí nìdí? Kì í ṣe torí pé ó tọ́ sí wa, àmọ́ torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wa. Tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé o ò wúlò, máa rántí pé torí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tó ronú pìwà dà ni Jèhófà ṣe pèsè ìràpadà, kì í ṣe torí àwọn ẹni pípé tí ò lè dẹ́ṣẹ̀.—Ka Lúùkù 5:32; 1 Tímótì 1:15.

5. Ṣé ó yẹ ká máa rò pé ẹ̀tọ́ wa ni pé kí Jèhófà ṣàánú wa? Ṣàlàyé.

5 Kò sẹ́nì kankan nínú wa tó yẹ kó máa rò pé àánú Jèhófà tọ́ sóun, kódà tó bá ti pẹ́ tó ti ń sin Jèhófà. Ó mọyì bá a ṣe jẹ́ olóòótọ́ látìgbà tá a ti ń sìn ín. (Héb. 6:10) Ó jẹ́ kí Ọmọ ẹ̀ kú nítorí wa láìgba ohunkóhun, kì í sì í ṣe torí kó lè san wá lérè pé a jẹ́ olóòótọ́ ló fi ṣe bẹ́ẹ̀. Tá a bá sọ pé àánú tọ́ sí wa tàbí tá a sọ pé àǹfààní pàtàkì kan tọ́ sí wa, ohun tá à ń sọ ni pé ikú Jésù ò wúlò fún wa nìyẹn.—Fi wé Gálátíà 2:21.

6. Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi ṣiṣẹ́ kára fún Jèhófà?

6 Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé kì í ṣe bí iṣẹ́ tá a ṣe fún Jèhófà ṣe pọ̀ tó ló máa jẹ́ ká rí ojú rere ẹ̀. Kí wá nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi ṣiṣẹ́ kára fún Jèhófà? Ìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ó mọyì inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run, kì í ṣe torí ó fẹ́ ká mọ̀ pé òun lẹ́tọ̀ọ́ sí i. (Éfé. 3:7) Torí náà bíi ti Pọ́ọ̀lù, ó yẹ káwa náà máa ṣiṣẹ́ kára fún Jèhófà torí pé a mọyì àánú ẹ̀, kì í ṣe torí kó lè ṣàánú wa.

7. Àǹfààní míì wo là ń rí nínú ìràpadà báyìí? (Róòmù 5:1; Jémíìsì 2:23)

7 Àǹfààní míì tá à ń rí nínú ìràpadà báyìí ni pé ó jẹ́ ká ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. a Bá a ṣe sọ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, nígbà tí wọ́n bí wa, a ò tíì di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. Àmọ́ ìràpadà ló jẹ́ ká ní “àlàáfíà pẹ̀lú Ọlọ́run,” ká sì di ọ̀rẹ́ ẹ̀.—Ka Róòmù 5:1; Jémíìsì 2:23.

8. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé a láǹfààní láti gbàdúrà?

8 Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ọ̀kan lára ohun tó ń jẹ́ kí àjọṣe àwa àti Jèhófà dáa, ìyẹn àǹfààní tá a ní láti gbàdúrà. Jèhófà máa ń gbọ́ àdúrà wa nígbà táwa èèyàn ẹ̀ bá ń jọ́sìn pa pọ̀, ó sì tún máa ń gbọ́ àdúrà tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa dá gbà. Àdúrà máa ń jẹ́ kọ́kàn wa balẹ̀, ó sì máa ń jẹ́ kí àníyàn wa dín kù, àmọ́ àwọn àǹfààní míì wà tá à ń rí tá a bá gbàdúrà. Ó máa ń jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run. (Sm. 65:2; Jém. 4:8; 1 Jòh. 5:14) Nígbà tí Jésù wà láyé, ó máa ń gbàdúrà déédéé torí ó mọ̀ pé Jèhófà máa gbọ́ òun, ó sì mọ̀ pé á jẹ́ kí àjọṣe àárín òun àti Bàbá ẹ̀ túbọ̀ lágbára. (Lúùkù 5:16) Inú wa dùn pé ẹbọ ìràpadà Jésù jẹ́ ká láǹfààní láti di ọ̀rẹ́ Jèhófà, ká sì máa gbàdúrà.

ÀǸFÀÀNÍ TÁ A MÁA RÍ LỌ́JỌ́ IWÁJÚ

9. Àǹfààní wo làwa èèyàn Jèhófà máa rí nínú ìràpadà lọ́jọ́ iwájú?

9 Àǹfààní wo làwa èèyàn Jèhófà máa rí nínú ìràpadà lọ́jọ́ iwájú? Jèhófà máa jẹ́ ká wà láàyè títí láé. Ọ̀pọ̀ èèyàn rò pé kò lè ṣeé ṣe torí pé ó ti pẹ́ gan-an táwa èèyàn ti ń kú. Àmọ́ ohun tí Jèhófà fẹ́ fáwa èèyàn látìbẹ̀rẹ̀ ni pé ká wà láàyè títí láé. Ká sọ pé Ádámù ò dẹ́ṣẹ̀ ni, àwa èèyàn ò ní máa rò pé àsọdùn ni pé a máa wà láàyè títí láé. Ó lè ṣòro fún wa báyìí láti gbà pé a máa wà láàyè títí láé, àmọ́ a gbà pé ó ṣeé ṣe torí pé Jèhófà fi Ọmọ ẹ̀ ọ̀wọ́n lélẹ̀ nítorí wa ká lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.—Róòmù 8:32.

10. Kí ni àwọn ẹni àmì òróró àtàwọn àgùntàn mìíràn ń retí?

10 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọjọ́ iwájú ni Jèhófà sọ pé a máa wà láàyè títí láé, ó fẹ́ kó máa wù wá báyìí. Inú àwọn ẹni àmì òróró ń dùn bí wọ́n ṣe ń retí láti gbé ọ̀run, kí wọ́n lè jọba pẹ̀lú Kristi láti ṣàkóso ayé. (Ìfi. 20:6) Àwọn àgùntàn mìíràn ń retí láti gbé ayé nínú Párádísè, níbi tí kò ti ní sí ìrora àti ìbànújẹ́ mọ́. (Ìfi. 21:3, 4) Ṣé ìwọ náà wà lára àwọn àgùntàn mìíràn tó ń retí láti gbé ayé títí láé? Ẹ̀bùn yìí kì í ṣe ẹ̀bùn gbà mápòóòrọ́wọ́mi torí ẹ̀bùn ńlá ni! Ó ṣe tán, nígbà tí Jèhófà dá wa, ayé yìí náà ló fẹ́ ká máa gbé títí láé. Torí náà, àwa tá a máa gbé ayé máa gbádùn ẹ̀ gan-an.

11-12. Kí ni díẹ̀ lára ohun rere tá a máa gbádùn nínú Párádísè? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

11 Fojú inú wo bí nǹkan ṣe máa rí fún ẹ nínú Párádísè. O ò ní ronú mọ́ pé lọ́jọ́ kan wàá ṣàìsàn tàbí pé wàá kú. (Àìsá. 25:8; 33:24) Gbogbo nǹkan tó o fẹ́ ni Jèhófà máa ṣe fún ẹ. Kí ló máa wù ẹ́ kó o kẹ́kọ̀ọ́ nípa ẹ̀? Ṣé ìmọ̀ ẹ̀rọ ni àbí ó wù ẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn nǹkan tó wà nínú ewéko, ẹranko àtèèyàn? Ṣé orin ni àbí bí wọ́n ṣe ń yàwòrán? Ó dájú pé àwọn ayàwòrán ilé, àwọn kọ́lékọ́lé àtàwọn àgbẹ̀ máa wà. Ó sì tún dájú pé àwọn tó ń tún nǹkan ṣe àtàwọn tó ń ṣiṣẹ́ ìrànwọ́ máa wà, irú bí àwọn tó ń se oúnjẹ, àwọn tó ń ṣe irinṣẹ́ àtàwọn tó ń tún àyíká ṣe kó lè rẹwà. (Àìsá. 35:1; 65:21) Torí pé a máa wà láàyè títí láé, àkókò máa wà fún ẹ láti ṣe àwọn nǹkan yìí àtàwọn nǹkan míì tó o fẹ́.

12 Ẹ wo bí inú wa ṣe máa dùn tó nígbà tá a bá ń kí àwọn tó jíǹde káàbọ̀! (Ìṣe 24:15) Tún ronú nípa ọ̀pọ̀ nǹkan tó o máa kọ́ nípa Jèhófà lára àwọn nǹkan tó dá. (Sm. 104:24; Àìsá. 11:9) Èyí tó dáa jù ni pé àá máa fayọ̀ sin Jèhófà torí pé kò ní sí ẹ̀ṣẹ̀ mọ́! Ṣé ó yẹ ká wá torí “ìgbádùn ẹ̀ṣẹ̀ tí kì í tọ́jọ́” pàdánù àwọn ohun rere tí Jèhófà máa fún wa lọ́jọ́ iwájú? (Héb. 11:25) Kò yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀! Tá a bá fi àwọn nǹkan táyé ń gbé lárugẹ sílẹ̀ nítorí àwọn ohun rere tá a máa gbádùn lọ́jọ́ iwájú, ó tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ọjọ́ pẹ́ tá a ti ń dúró kí Párádísè dé, àmọ́ máa rántí pé á dé lọ́jọ́ kan. Àwọn nǹkan tá a sọ yìí ò ní ṣeé ṣe ká ní Jèhófà ò nífẹ̀ẹ́ wa, kó sì fi Ọmọ ẹ̀ rà wá pa dà!

Àwọn ohun rere wo ni wàá fẹ́ gbádùn nínú Párádísè? (Wo ìpínrọ̀ 11-12)


MÁA ṢE OHUN TÓ FI HÀN PÉ O MỌYÌ ÌFẸ́ JÈHÓFÀ

13. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọyì ìfẹ́ tí Jèhófà fi hàn sí wa? (2 Kọ́ríńtì 6:1)

13 Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọyì ìràpadà tí Jèhófà pèsè? A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá fi iṣẹ́ Ọlọ́run ṣáájú láyé wa. (Mát. 6:33) Ó ṣe tán, ìdí tí Jésù fi kú ni “kí àwọn tó wà láàyè má ṣe tún wà láàyè fún ara wọn mọ́, bí kò ṣe fún ẹni tó kú fún wọn, tí a sì gbé dìde.” (2 Kọ́r. 5:15) Ó dájú pé a ò fẹ́ pàdánù inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí Jèhófà fi hàn sí wa yìí.—Ka 2 Kọ́ríńtì 6:1.

14. Tá a bá ń ṣe ohun tí Jèhófà sọ, báwo nìyẹn ṣe máa fi hàn pé a nígbàgbọ́?

14 A tún lè fi hàn pé a mọyì ìfẹ́ tí Jèhófà fi hàn sí wa tá a bá nígbàgbọ́ nínú ẹ̀ tá a sì ń ṣe ohun tó bá sọ. Báwo la ṣe lè ṣe é? Tá a bá fẹ́ ṣe àwọn ìpinnu kan, irú bíi bá a ṣe máa kàwé tó àti irú iṣẹ́ tá a máa ṣe, ó yẹ ká ronú nípa ohun tí Jèhófà fẹ́. (1 Kọ́r. 10:31; 2 Kọ́r. 5:7) Tá a bá ń ṣe ohun tó fi hàn pé a nígbàgbọ́, ìgbàgbọ́ wa máa túbọ̀ lágbára, àá sì sún mọ́ Jèhófà dáadáa. Á tún jẹ́ kọ́kàn wa balẹ̀ pé a máa wà láàyè títí láé.—Róòmù 5:3-5; Jém. 2:21, 22.

15. Nígbà Ìrántí Ikú Kristi, báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọrírì ohun tí Jèhófà ṣe fún wa?

15 Nǹkan míì wà tá a lè ṣe táá fi hàn pé a mọrírì ìfẹ́ tí Jèhófà fi hàn sí wa. Nǹkan náà ni pé ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe nígbà Ìrántí Ikú Kristi láti fi hàn pé a mọyì ìràpadà tí Jèhófà pèsè. Yàtọ̀ sí pé a máa wà níbẹ̀, ó yẹ ká tún pe àwọn èèyàn wá síbẹ̀. (1 Tím. 2:4) Ṣàlàyé àwọn nǹkan tá a máa gbádùn níbẹ̀ fáwọn tó o máa pè wá. Lọ sórí jw.org, wàá rí fídíò náà Kí Nìdí Tí Jésù Fi Kú? àti Ìrántí Ikú Jésù, kó o sì fi hàn wọ́n. Àwọn alàgbà gbọ́dọ̀ rí i dájú pé àwọn pe àwọn tí ò ṣe déédéé nínú ìjọsìn Ọlọ́run mọ́ wá síbi Ìrántí Ikú Kristi. Ẹ wo bí inú wa àtàwọn tó wà lọ́run ṣe máa dùn tó tá a bá rí i táwọn tí ò sin Jèhófà mọ́ bá pa dà sínú ètò ẹ̀! (Lúùkù 15:4-7) Nígbà Ìrántí Ikú Kristi, á dáa ká kí ara wa káàbọ̀, pàápàá àwọn àlejò àtàwọn tá a ti rí tipẹ́. Ká mára tù wọ́n, ká sì fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ wọn!—Róòmù 12:13.

16. Kí nìdí tó fi yẹ ká ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìwàásù nígbà Ìrántí Ikú Kristi?

16 Ṣé o lè ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìwàásù nígbà Ìrántí Ikú Kristi? Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá fi hàn pé o mọyì ohun tí Ọlọ́run àti Kristi ṣe fún wa. Bá a bá ṣe ń wàásù, bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà á máa tì wá lẹ́yìn, àá sì túbọ̀ máa gbẹ́kẹ̀ lé e. (1 Kọ́r. 3:9) Bákan náà, rí i pé ò ń ka àwọn ẹsẹ Bíbélì tá a ṣètò fún Ìrántí Ikú Kristi nínú Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́ tàbí èyí tó wà nínú ìwé ìpàdé. O tiẹ̀ lè lo ètò Bíbélì kíkà náà fún ìkẹ́kọ̀ọ́.

17. Kí ló máa ń múnú Jèhófà dùn? (Tún wo àpótí náà, “ Àwọn Nǹkan Táá Fi Hàn Pé A Mọyì Ìfẹ́ Jèhófà.”)

17 Ká sòótọ́, ó lè má rọrùn fún ẹ láti ṣe gbogbo nǹkan tá a sọ nínú àpilẹ̀kọ yìí. Àmọ́, máa rántí pé Jèhófà kì í fi ohun tó o ṣe wé ohun táwọn ẹlòmíì ṣe, ó mọyì ohun tágbára ẹ gbé, ó sì rí ọkàn ẹ. Inú ẹ̀ máa ń dùn tó bá rí i pé ò ń ṣe ohun tó fi hàn pé o mọyì ìràpadà.—1 Sám. 16:7; Máàkù 12:41-44.

18. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà àti Jésù Kristi?

18 Ìràpadà tí Jèhófà pèsè ló jẹ́ kó lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, òun ló jẹ́ ká di ọ̀rẹ́ ẹ̀, ká sì nírètí pé a máa wà láàyè títí láé. Ẹ jẹ́ ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà torí ó nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì pèsè àwọn ohun rere yìí fún wa. (1 Jòh. 4:19) Bákan náà, ẹ jẹ́ ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jésù tó nífẹ̀ẹ́ wa débi pé ó fi ẹ̀mí ẹ̀ rà wá pa dà!—Jòh. 15:13.

ORIN 154 Ìfẹ́ Kì Í Yẹ̀

a Kí Jésù tó wá sáyé láti san ìràpadà, Jèhófà máa ń dárí ji àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ ìgbà àtijọ́. Ìdí tí Jèhófà fi ń dárí jì wọ́n ni pé ó mọ̀ pé Ọmọ òun máa jẹ́ olóòótọ́ títí tó fi máa kú. Torí náà lójú Jèhófà, ńṣe ló dà bíi pé Jèhófà ti san ìràpadà náà kí Jésù tó kú.—Róòmù 3:25.