Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 4

ORIN 18 A Mọyì Ìràpadà

Kí La Kọ́ Nínú Ìràpadà Tí Jésù Ṣe?

Kí La Kọ́ Nínú Ìràpadà Tí Jésù Ṣe?

“Bí a ṣe fi ìfẹ́ Ọlọ́run hàn kedere . . . nìyí.”1 JÒH. 4:9.

OHUN TÁ A MÁA KỌ́

Ohun tí ìràpadà kọ́ wa nípa ànímọ́ Jèhófà àti Jésù.

1. Àǹfààní wo là ń rí bá a ṣe ń lọ síbi Ìrántí Ikú Kristi lọ́dọọdún?

 ÌWỌ náà máa gbà pé ẹ̀bùn tó ṣeyebíye gan-an ni ìràpadà! (2 Kọ́r. 9:15) Kí nìdí? Ìdí ni pé Jésù fi ẹ̀mí ẹ̀ lélẹ̀, ìyẹn ló sì jẹ́ ká di ọ̀rẹ́ Jèhófà Ọlọ́run. Wàá tún láǹfààní láti wà láàyè títí láé. Ẹ ò rí i pé ó yẹ ká mọyì ìràpadà yìí, ká sì máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà tó pèsè ẹ̀ fún wa! (Róòmù 5:8) Ìdí tí Jésù fi ní ká máa ṣe Ìrántí Ikú òun lọ́dọọdún ni pé ó fẹ́ ká fọwọ́ pàtàkì mú ìràpadà, ká sì mọyì ẹ̀.—Lúùkù 22:19, 20.

2. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

2 Saturday, April 12, 2025 la máa ṣe Ìrántí Ikú Kristi lọ́dún yìí. Ó sì dájú pé gbogbo wa la ti ń ṣètò bá a ṣe máa wà níbẹ̀. Lásìkò Ìrántí Ikú Kristi yìí, a máa jàǹfààní gan-an tá a bá wáyè láti ṣàṣàrò a nípa ohun tí Jèhófà àti Ọmọ ẹ̀ ṣe fún wa. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa ohun tí ìràpadà kọ́ wa nípa Jèhófà àti Jésù. Nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e, a máa sọ̀rọ̀ nípa àǹfààní tá à ń rí torí pé Jèhófà pèsè ìràpadà àti bá a ṣe lè fi hàn pé a mọyì ẹ̀.

OHUN TÍ ÌRÀPADÀ KỌ́ WA NÍPA JÈHÓFÀ

3. Báwo ni ikú ọkùnrin kan ṣoṣo ṣe lè ra ọ̀pọ̀ èèyàn pa dà? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

3 Ìràpadà jẹ́ ká mọ̀ pé onídàájọ́ òdodo ni Jèhófà. (Diu. 32:4) Báwo la ṣe mọ̀ bẹ́ẹ̀? Rò ó wò ná: Torí Ádámù ṣàìgbọràn, a di ẹlẹ́ṣẹ̀, a sì ń kú. (Róòmù 5:12) Àmọ́, ká lè bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú, Jèhófà gbà kí Jésù kú kó lè san ìràpadà náà. Ṣùgbọ́n, báwo ni ikú ẹni pípé kan ṣoṣo ṣe máa gba ọ̀pọ̀ èèyàn sílẹ̀ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé: “Bó ṣe jẹ́ pé àìgbọràn èèyàn kan [ìyẹn Ádámù] ló mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn di ẹlẹ́ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni ìgbọràn èèyàn kan [ìyẹn Jésù] á ṣe mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn di olódodo.” (Róòmù 5:19; 1 Tím. 2:6) Ohun tá à ń sọ ni pé àìgbọràn ẹnì kan ló mú kí gbogbo wa di ẹlẹ́ṣẹ̀, tá a sì ń kú. Bákan náà ló ṣe jẹ́ pé ìgbọràn ẹni pípé kan ṣoṣo ló máa mú ká bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú.

Ádámù sọ wá di ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Àmọ́, Jésù dá wa sílẹ̀ (Wo ìpínrọ̀ 3)


4. Kí nìdí tí Jèhófà ò kàn fi gbà pé káwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù tó ṣègbọràn máa wà láàyè títí láé?

4 Ṣé dandan ni kí Jésù kú kó tó lè rà wá pa dà? Ṣé Jèhófà ò lè fi àwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù tó ń ṣègbọràn sílẹ̀ kí wọ́n máa wà láàyè títí láé ni? Lójú àwa èèyàn aláìpé, ó lè jọ pé ohun tó yẹ kí Jèhófà ṣe nìyẹn. Àmọ́ ìyẹn ò ní fi hàn pé onídàájọ́ òdodo ni Jèhófà. Torí pé gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń ṣe ohun tó tọ́, kò kàn lè gbójú fo ìwà àìgbọràn Ádámù bẹ́ẹ̀.

5. Kí ló mú kó dá wa lójú pé gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń ṣe ohun tó tọ́?

5 Ká sọ pé Jèhófà ò pèsè ìràpadà, tí ò sì ṣe ìdájọ́ òdodo, tó wá jẹ́ káwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù máa wà láàyè títí láé ńkọ́? Ó ṣeé ṣe káwọn èèyàn máa wò ó pé bóyá ni Ọlọ́run máa lè ṣèdájọ́ òdodo nínú àwọn ọ̀rọ̀ míì. Bí àpẹẹrẹ, àwọn èèyàn lè máa ṣiyèméjì pé ó lè má mú àwọn ìlérí ẹ̀ kan ṣẹ. Àmọ́ a kì í da ara wa láàmú nípa ìyẹn. Ìdí sì ni pé ohun tó tọ́ ni Jèhófà ṣe bó tiẹ̀ jẹ́ pé nǹkan ńlá ló san kó lè fi Ọmọ ẹ̀ rà wá pa dà. Ohun tó sì ṣe yẹn ló jẹ́ kọ́kàn wa balẹ̀ pé gbogbo ìgbà ló máa ń ṣohun tó tọ́.

6. Báwo ni ìràpadà ṣe jẹ́ ká mọ bí Jèhófà ṣe nífẹ̀ẹ́ wa tó? (1 Jòhánù 4:9, 10)

6 Òótọ́ ni pé ìràpadà jẹ́ ká mọ̀ pé onídàájọ́ òdodo ni Jèhófà, àmọ́ ní pàtàkì, ó jẹ́ ká mọ bí Jèhófà ṣe nífẹ̀ẹ́ wa tó. (Jòh. 3:16; ka 1 Jòhánù 4:9, 10.) Ìràpadà jẹ́ ká mọ̀ pé kì í ṣe pé Jèhófà fẹ́ ká wà láàyè títí láé nìkan ni, ó tún fẹ́ ká wà lára ìdílé ẹ̀. Rò ó wò ná: Nígbà tí Ádámù dẹ́ṣẹ̀, Jèhófà mú un kúrò nínú ìdílé ẹ̀, ìyẹn ni pé kò sí lára àwọn tó ń jọ́sìn ẹ̀ mọ́. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé kò sí ìkankan nínú wa tí wọ́n bí sínú ìdílé Ọlọ́run. Àmọ́ lọ́lá ìràpadà náà, Jèhófà ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, ó máa mú gbogbo èèyàn tó nígbàgbọ́, tó sì ń ṣègbọràn wá sínú ìdílé ẹ̀. Kódà ní báyìí, a ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà àtàwọn tá a jọ ń sìn ín. Ó dájú pé à ń jọlá ìfẹ́ Jèhófà!—Róòmù 5:10, 11.

7. Báwo ni ìyà tí Jésù jẹ ṣe jẹ́ ká mọ bí Jèhófà ṣe nífẹ̀ẹ́ wa tó?

7 Tá a bá ronú nípa ohun tí Jèhófà san nítorí ìràpadà, a máa túbọ̀ lóye bó ṣe nífẹ̀ẹ́ wa tó. Sátánì sọ pé kò sẹ́nì kankan tó máa jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà tí nǹkan bá nira fún wa. Kí Jèhófà lè fi hàn pé irọ́ ńlá gbáà ni Sátánì pa, ó gbà kí Jésù jìyà kó tó kú. (Jóòbù 2:1-5; 1 Pét. 2:21) Jèhófà ń wo bí àwọn olórí ẹ̀sìn tó kórìíra Jésù ṣe ń fi ṣẹ̀sín, ó rí báwọn ọmọ ogun ṣe bọ́ aṣọ ẹ̀, tí wọ́n sì lù ú nílùkulù, níkẹyìn wọ́n kàn án mọ́gi oró. Lẹ́yìn ìyẹn, Jèhófà ń wo bí Jésù Ọmọ ẹ̀ ọ̀wọ́n ṣe ń jẹ̀rora títí tó fi gbẹ́mìí mì. (Mát. 27:28-31, 39) Jèhófà lè ṣe é kí Jésù má jìyà púpọ̀ kó tó kú. Bí àpẹẹrẹ, nígbà táwọn alátakò sọ pé: “Kí [Jèhófà] gbà á sílẹ̀ báyìí tí Ó bá fẹ́ ẹ,” Jèhófà lè ṣe bẹ́ẹ̀ lóòótọ́. (Mát. 27:42, 43) Àmọ́, ká sọ pé ohun tí Ọlọ́run ṣe nìyẹn, Jésù ò ní lè san ìràpadà náà, kò sì ní sírètí kankan fún wa. Torí náà, Jèhófà gbà kí Ọmọ ẹ̀ fara da ìyà yẹn títí tó fi gbẹ́mìí mì.

8. Ṣé ó dun Jèhófà bó ṣe ń wo Ọmọ ẹ̀ tó ń jìyà? Ṣàlàyé. (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

8 Ẹ má jẹ́ ká rò pé torí pé Jèhófà ni Olódùmarè, kò sí nǹkan tó lè dùn ún. Ẹ rántí pé Jèhófà dá àwa èèyàn ní àwòrán ara ẹ̀, àwa èèyàn sì máa ń mọ nǹkan lára. Torí náà, ó bọ́gbọ́n mu tá a bá sọ pé ó máa ń dun Jèhófà tí nǹkan burúkú bá ṣẹlẹ̀. Bíbélì sọ pé àwọn èèyàn “bà á nínú jẹ́” wọ́n sì “kó ẹ̀dùn ọkàn” bá a. (Sm. 78:40, 41) Ẹ tún jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Ábúráhámù àti Ísákì. Ṣé ẹ rántí pé Jèhófà ní kí Ábúráhámù fi ọmọ ẹ̀ kan ṣoṣo rúbọ sóun? (Jẹ́n. 22:9-12; Héb. 11:17-19) Ẹ fojú inú wo bó ṣe máa rí lára Ábúráhámù nígbà tó fẹ́ fi ọ̀bẹ pa ọmọ ẹ̀. Ẹ wá wo bó ṣe máa rí lára Jèhófà bó ṣe ń wò ó táwọn èèyàn burúkú ń fìyà jẹ Ọmọ ẹ̀, tó sì jẹ̀rora títí tó fi gbẹ́mìí mì!—Wo fídíò yìí lórí jw.org, Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn—Ábúráhámù, Apá Kejì.

Nígbà tí Jèhófà rí bí Ọmọ ẹ̀ ṣe ń jìyà, ó dùn ún gan-an (Wo ìpínrọ̀ 8)


9. Kí ni Róòmù 8:32, 38, 39 sọ tó jẹ́ ká mọ bí ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wa àtàwọn tá a jọ ń sìn ín ṣe jinlẹ̀ tó?

9 Ìràpadà kọ́ wa pé kò sẹ́ni tó nífẹ̀ẹ́ wa tó Jèhófà, kódà kò sí mọ̀lẹ́bí wa tàbí ọ̀rẹ́ wa tímọ́tímọ́ tó nífẹ̀ẹ́ wa tó o. (Ka Róòmù 8:32, 38, 39.) Torí náà, ó dájú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa ju bá a ṣe nífẹ̀ẹ́ ara wa lọ. Ṣé ó wù ẹ́ kó o wà láàyè títí láé? Ó dájú pé ó wu Jèhófà ju bó ṣe ń wù ẹ́ lọ. Ṣé o fẹ́ kí Jèhófà dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ẹ jì ẹ́? Mọ̀ dájú pé ó wu Jèhófà pé kó dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ẹ jì ẹ́ ju bó ṣe ń wù ẹ́ lọ. Gbogbo ohun tí Jèhófà fẹ́ ká ṣe ò ju pé ká mọyì ẹ̀bùn ìràpadà yìí, ká nígbàgbọ́ nínú òun, ká sì máa ṣègbọràn sóun. Ẹ ò rí i pé ìràpadà jẹ́ ká mọ bí Jèhófà ṣe nífẹ̀ẹ́ wa tó! Tá a bá sì dénú ayé tuntun, ọ̀pọ̀ nǹkan la ṣì máa mọ̀ nípa ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wa.—Oníw. 3:11.

OHUN TÍ ÌRÀPADÀ KỌ́ WA NÍPA JÉSÙ

10. (a) Kí ló dun Jésù jù nípa ikú ẹ̀? (b) Báwo ni Jésù ṣe dá orúkọ Jèhófà láre? (Tún wo àpótí náà “ Bí Jésù Ṣe Jẹ́ Olóòótọ́ Fi Hàn Pé Òpùrọ́ Ni Sátánì.”)

10 Jésù ò fẹ́ káwọn èèyàn sọ nǹkan tí ò dáa nípa orúkọ Bàbá òun. (Jòh. 14:31) Inú Jésù ò dùn torí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án. Wọ́n fẹ̀sùn kàn án pé ó ń sọ̀rọ̀ òdì sí orúkọ Ọlọ́run àti pé ó ń dìtẹ̀ síjọba, ìyẹn sì máa kó ẹ̀gàn bá orúkọ Jèhófà. Ìdí nìyẹn tó fi gbàdúrà pé: “Baba mi, tó bá ṣeé ṣe, jẹ́ kí ife yìí ré mi kọjá.” (Mát. 26:39) Ó dájú pé bí Jésù ṣe jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà títí tó fi kú dá orúkọ Jèhófà láre.

11. Báwo ni Jésù ṣe fìfẹ́ tó jinlẹ̀ hàn sáwa èèyàn? (Jòhánù 13:1)

11 Ìràpadà tún kọ́ wa pé Jésù ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ sáwa èèyàn, pàápàá àwa ọmọlẹ́yìn ẹ̀. (Òwe 8:31; ka Jòhánù 13:1.) Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Jésù wà láyé, ó mọ̀ pé díẹ̀ lára àwọn nǹkan tóun máa ṣe máa nira gan-an, pàápàá ikú tóun máa kú. Síbẹ̀, Jésù ṣe gbogbo nǹkan tó yẹ kó ṣe. Kì í ṣe torí pé Jèhófà ló ní kó ṣe é, àmọ́ torí pé ó nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn. Ìdí nìyẹn tí Jésù fi lo gbogbo okun ẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, ó ń kọ́ni, ó sì ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Kódà ní alẹ́ tó ṣáájú ikú Jésù, ó ṣì fọ ẹsẹ̀ àwọn àpọ́sítélì ẹ̀, ó sọ̀rọ̀ tó máa tù wọ́n nínú, ó sì sọ ohun tí wọ́n máa ṣe fún wọn. (Jòh. 13:12-15) Lẹ́yìn náà nígbà tó wà lórí òpó igi, Jésù sọ̀rọ̀ ìtùnú fún ọ̀daràn tó ń kú lọ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹ̀, ó sì ṣètò bí wọ́n ṣe máa bójú tó ìyá òun. (Lúùkù 23:42, 43; Jòh. 19:26, 27) Torí náà, kò sí àní-àní pé kì í ṣe ikú Jésù nìkan ló jẹ́ ká mọ̀ pé ó ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ sí wa, gbogbo ohun tó ṣe nígbà tó wà láyé ló fi hàn bẹ́ẹ̀.

12. Àwọn nǹkan wo ni Jésù ń ṣe fún wa báyìí?

12 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Kristi kú “lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láìtún ní kú mọ́ láé,” ọ̀pọ̀ nǹkan ló ṣì ń ṣe fún wa títí di báyìí. (Róòmù 6:10) Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ó ń ṣiṣẹ́ kára ká lè jàǹfààní gbogbo ohun rere tí ìràpadà náà mú kó ṣeé ṣe fún wa. Ẹ jẹ́ ká wo díẹ̀ lára nǹkan tó ń ṣe lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí. Òun ni Ọba wa, ó tún jẹ́ Àlùfáà Àgbà wa, òun sì ni orí ìjọ. (1 Kọ́r. 15:25; Éfé. 5:23; Héb. 2:17) Òun ló ń kó àwọn ẹni àmì òróró àtàwọn ogunlọ́gọ̀ èèyàn jọ, á sì máa bá iṣẹ́ yìí lọ títí dìgbà tó bá ku díẹ̀ kí ìpọ́njú ńlá parí. b (Mát. 25:32; Máàkù 13:27) Ó tún ń rí i pé àwa olóòótọ́ ìránṣẹ́ ẹ̀ ní ohun táá jẹ́ ká máa sin Jèhófà láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí. (Mát. 24:45) Ó sì dájú pé jálẹ̀ Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso ẹ̀, á máa ṣohun tá a fẹ́ fún wa. Ẹ ò rí i pé ọ̀pọ̀ nǹkan là ń gbádùn bí Jèhófà ṣe fún wa ní Ọmọ ẹ̀!

MÁA KẸ́KỌ̀Ọ́ SÍ I

13. Báwo ni àṣàrò ṣe lè jẹ́ kó o túbọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìfẹ́ tí Jèhófà àti Kristi ní sí wa?

13 Wàá túbọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìfẹ́ tí Jèhófà àti Kristi ní sí wa tó o bá ń ronú jinlẹ̀ nípa ohun tí wọ́n ṣe fún wa. Tó bá ṣeé ṣe lásìkò Ìrántí Ikú Kristi tọdún yìí, o lè fara balẹ̀ ka ọ̀kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lára àwọn Ìwé Ìhìn Rere. Má ka orí tó pọ̀ jù lẹ́ẹ̀kan náà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣàṣàrò nípa ibi tó o kà kó o lè rí àwọn nǹkan míì tó máa jẹ́ kó o nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti Jésù. Bákan náà, rí i pé ò ń sọ ohun tó o kọ́ fáwọn èèyàn.

14. Tá a bá ń ṣàṣàrò, báwo nìyẹn ṣe máa jẹ́ ká túbọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìràpadà àtàwọn nǹkan míì? (Sáàmù 119:97) (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

14 Tó bá jẹ́ pé o ti pẹ́ nínú ètò Ọlọ́run, o lè máa wò ó pé ṣé ó ṣeé ṣe ká mọ àwọn nǹkan míì nípa ohun tá a ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ irú bí ìdájọ́ òdodo Jèhófà, ìfẹ́ tó ní sí wa àti ìràpadà? Òótọ́ ibẹ̀ ni pé a ò lè mọ gbogbo nǹkan yẹn tán. Torí náà, kí lo lè ṣe? Máa ka àwọn ìwé ètò Ọlọ́run dáadáa, kó o sì máa kẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀ jinlẹ̀. Tó o bá ka nǹkan tí ò fi bẹ́ẹ̀ yé ẹ, ṣèwádìí nípa ẹ̀. Jálẹ̀ ọjọ́ yẹn, máa ronú nípa nǹkan tuntun tó o kọ́ àtohun tó kọ́ ẹ nípa Jèhófà, Ọmọ ẹ̀ àti ìfẹ́ tí wọ́n ní sí ẹ.—Ka Sáàmù 119:97.

Tó bá tiẹ̀ ti pẹ́ tá a ti ń sin Jèhófà, ó yẹ ká túbọ̀ máa ṣe àwọn nǹkan tó fi hàn pé a mọyì ìràpadà (Wo ìpínrọ̀ 14)


15. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa wá àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye nínú Bíbélì?

15 Má jẹ́ kó sú ẹ tí o ò bá rí nǹkan tuntun kọ́ nígbà tó ò ń ka Bíbélì tàbí nígbà tó ò ń ṣèwádìí. A lè fi ẹ́ wé ẹni tó ń wa góòlù. Àwọn tó ń wa góòlù máa ń ní sùúrù gan-an. Ọ̀pọ̀ wákàtí ni wọ́n máa ń lò, kódà ó máa ń gba ọ̀pọ̀ ọjọ́ kí wọ́n tó rí góòlù kékeré kan. Síbẹ̀, wọn kì í jáwọ́ nínú iṣẹ́ náà, wọ́n á tẹra mọ́ ọn, ìdí sì ni pé bó tiẹ̀ jẹ́ góòlù kékeré ni wọ́n rí, ó ṣeyebíye gan-an. Àmọ́ ṣá o, ẹ̀kọ́ òtítọ́ inú Bíbélì ṣeyebíye jùyẹn lọ! (Sm. 119:127; Òwe 8:10) Torí náà, má jẹ́ kó sú ẹ láti máa ka Bíbélì bó o ṣe ṣètò ẹ̀.—Sm. 1:2.

16. Báwo la ṣe lè fara wé Jèhófà àti Jésù?

16 Bó o ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́, máa wá bó o ṣe máa lo ohun tó ò ń kọ́. Bí àpẹẹrẹ, máa ṣe ohun tó tọ́ sáwọn èèyàn, ìyẹn á fi hàn pé ò ń fara wé Jèhófà tó ń ṣe ohun tó tọ́. Tó o bá pinnu pé wàá ṣe ohunkóhun kó o lè gbé orúkọ Jèhófà ga, wàá sì máa ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ bí ò tiẹ̀ rọrùn fún ẹ rárá, á fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àtàwọn èèyàn bí Jésù ti ṣe. Bákan náà, máa wàásù fáwọn èèyàn bí Jésù ti ṣe káwọn náà lè jàǹfààní ìràpadà àtàwọn nǹkan rere míì tí Jèhófà ń ṣe fún wa.

17. Kí la máa kọ́ nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e?

17 Bá a bá ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìràpadà, tá a sì ń mọyì ẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ tá a ní sí Jèhófà àti Ọmọ ẹ̀ á máa pọ̀ sí i. Àá wá rí i pé Jèhófà àti Jésù á túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ wa. (Jòh. 14:21; Jém. 4:8) Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa lo gbogbo nǹkan tí Jèhófà ń pèsè ká lè túbọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìràpadà. Nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e, a máa sọ̀rọ̀ nípa bá a ṣe lè jàǹfààní ìràpadà àti bá a ṣe lè fi hàn pé a mọyì ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wa.

ORIN 107 Ìfẹ́ Ọlọ́run Jẹ́ Àpẹẹrẹ fún Wa

a ÀLÀYÉ Ọ̀RỌ̀: “Àṣàrò” ni kéèyàn máa ronú jinlẹ̀ nípa ohun tó ń kọ́.

b “Àwọn ohun tó wà ní ọ̀run” tí Pọ́ọ̀lù sọ ní Éfésù 1:10 pé a máa kó jọ yàtọ̀ sí “àwọn àyànfẹ́” tí Jésù sọ ní Mátíù 24:31 àti Máàkù 13:27 pé a máa kó jọ. Ìgbà tí Jèhófà fi ẹ̀mí mímọ́ yan àwọn ẹni àmì òróró ni Pọ́ọ̀lù ń sọ. Àmọ́ ìgbà tá a máa àwọn ẹni àmì òróró tó kù láyé lọ sọ́run nígbà ìpọ́njú ńlá ni Jésù ń sọ.