Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 3

ORIN 35 Máa Ṣe “Àwọn Ohun Tó Ṣe Pàtàkì Jù”

Máa Ṣe Ìpinnu Táá Múnú Jèhófà Dùn

Máa Ṣe Ìpinnu Táá Múnú Jèhófà Dùn

“Ìbẹ̀rù Jèhófà ni ìbẹ̀rẹ̀ ọgbọ́n, ìmọ̀ Ẹni Mímọ́ Jù Lọ sì ni òye.”ÒWE 9:10.

OHUN TÁ A MÁA KỌ́

Bá a ṣe lè fi ìmọ̀, òye àti ìfòyemọ̀ ṣe ìpinnu tó dáa.

1. Ìṣòro wo ni gbogbo wa máa ń ní?

 OJOOJÚMỌ́ la máa ń ṣe ìpinnu. Ó máa ń rọrùn fún wa láti ṣe àwọn ìpinnu kan, irú bí oúnjẹ tá a máa jẹ láàárọ̀ tàbí ìgbà tá a máa sùn lálẹ́. Àmọ́ kì í rọrùn láti ṣe àwọn ìpinnu kan, irú bí ìpinnu tó kan ìlera wa, ohun tó máa jẹ́ ká láyọ̀, ọ̀rọ̀ ìdílé àti ìjọsìn wa. Torí náà, ìpinnu tó máa ṣe àwa àti ìdílé wa láǹfààní ló máa ń wù wá ká ṣe. Àmọ́ èyí tó ṣe pàtàkì jù ni pé ó máa ń wù wá ká ṣe ìpinnu tó máa múnú Jèhófà dùn.—Róòmù 12:1, 2.

2. Báwo lo ṣe lè ṣèpinnu tó dáa?

2 Wàá lè ṣèpinnu tó dáa (1) tó o bá mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀rọ̀ náà, (2) tó o bá mọ ohun tí Jèhófà fẹ́ kó o ṣe àti (3) tó o bá ro ibi tọ́rọ̀ náà máa já sí. A máa sọ̀rọ̀ nípa nǹkan mẹ́ta yìí nínú àpilẹ̀kọ yìí, á sì tún jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè kọ́ agbára ìfòyemọ̀ wa.—Òwe 2:11.

MỌ KÚLẸ̀KÚLẸ̀ Ọ̀RỌ̀ NÁÀ

3. Sọ àpèjúwe tó jẹ́ ká mọ ìdí tó fi yẹ ká mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀rọ̀ ká tó ṣèpinnu.

3 Tó o bá fẹ́ ṣèpinnu tó dáa, ohun àkọ́kọ́ tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ ni pé kó o mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀rọ̀ náà. Kí nìdí tó fi yẹ kó o ṣe bẹ́ẹ̀? Ẹ jẹ́ ká sọ pé ẹnì kan tó ń ṣàìsàn tó le gan-an lọ sọ́dọ̀ dókítà kó lè mọ àìsàn tó ń ṣe òun. Ṣé dókítà náà kàn máa bẹ̀rẹ̀ sí í tọ́jú ẹ̀ láìjẹ́ pé ó kọ́kọ́ ṣe àwọn àyẹ̀wò kan tàbí kó bi í láwọn ìbéèrè kan? Ó dájú pé kò ní ṣe bẹ́ẹ̀. Lọ́nà kan náà, ìwọ náà máa ṣèpinnu tó dáa tó o bá kọ́kọ́ mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀rọ̀ náà. Báwo lo ṣe lè ṣe é?

4.Òwe 18:13 ṣe sọ, kí ló yẹ kó o ṣe tó o bá fẹ́ mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀rọ̀ kan? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

4 Kó o lè mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀rọ̀ kan, ó yẹ kó o béèrè àwọn ìbéèrè kan. Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé ẹnì kan pè ẹ́ síbi àpèjẹ, o lè bi ara ẹ pé: Ṣé kí n lọ? Tí o ò bá mọ ẹni tó fẹ́ ṣe àpèjẹ yẹn, tí o ò sì mọ àwọn nǹkan tó fẹ́ ṣe níbẹ̀, o lè bi ẹni tó pè ẹ́ pé: “Ibo ni wọ́n ti fẹ́ ṣe àpèjẹ náà, ìgbà wo ni wọ́n sì máa ṣe é? Báwo ni èrò ṣe máa pọ̀ tó? Ta ló máa bójú tó ètò náà? Àwọn wo ló máa wá? Àwọn nǹkan wo ni wọ́n máa ṣe níbẹ̀? Ṣé ọtí tó le máa wà níbẹ̀?” Tó o bá mọ ìdáhùn àwọn ìbéèrè yìí, á jẹ́ kó o lè ṣe ìpinnu tó tọ́.—Ka Òwe 18:13.

Ṣèwádìí, kó o sì bi ara ẹ láwọn ìbéèrè kan (Wo ìpínrọ̀ 4) a


5. Tó o bá ti mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀rọ̀ náà, kí ló yẹ kó o ṣe?

5 Tó o bá ti mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀rọ̀ náà, ó yẹ kó o ronú dáadáa nípa ẹ̀ kó o tó ṣèpinnu. Bí àpẹẹrẹ, tó o bá gbọ́ pé àwọn kan tí kì í tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì máa wá síbi àpèjẹ náà ńkọ́ tàbí pé wọ́n máa mutí tó le níbẹ̀, tí kò sì sẹ́ni tó máa ṣàbójútó àwọn èèyàn kí wọ́n má bàa mutí yó? Ṣé wọn ò ní sọ ibi àpèjẹ náà di ibi àríyá tí wọ́n ti ń hùwà tí ò dáa? (1 Pét. 4:3) Yàtọ̀ síyẹn, tí àkókò tí wọ́n fẹ́ ṣe àpèjẹ náà bá bọ́ sákòókò ìpàdé tàbí àkókò tó o fẹ́ lọ wàásù ńkọ́? Tó o bá ronú jinlẹ̀ dáadáa, wàá lè ṣe ìpinnu tó tọ́. Àmọ́ ṣá o, nǹkan míì wà tó o máa ṣe. O lè ti mọ ohun tó o fẹ́ ṣe, àmọ́ ṣóhun tí Jèhófà fẹ́ kó o ṣe nìyẹn?—Òwe 2:6.

MỌ OHUN TÍ JÈHÓFÀ FẸ́ KÓ O ṢE

6.Jémíìsì 1:5 ṣe sọ, kí nìdí tó fi yẹ ká gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́?

6 Bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè mọ ohun tó fẹ́ kó o ṣe. Jèhófà ṣèlérí pé òun máa fún wa ní ọgbọ́n táá jẹ́ ká mọ̀ bóyá ohun tá a fẹ́ ṣe máa múnú òun dùn. Ó sì máa fún wa nírú ọgbọ́n bẹ́ẹ̀ torí ó “lawọ́ sí gbogbo èèyàn, kì í sì í pẹ̀gàn.”—Ka Jémíìsì 1:5.

7. Báwo lo ṣe lè mọ ohun tí Jèhófà fẹ́ kó o ṣe? Ṣàpèjúwe.

7 Lẹ́yìn tó o bá ti gbàdúrà sí Jèhófà pé kó tọ́ ẹ sọ́nà, máa kíyè sí bó ṣe ń dáhùn àdúrà ẹ. Wo àpèjúwe yìí ná: Ká sọ pé o ṣìnà nígbà tó ò ń rìnrìn àjò, o lè ní kí ẹni tó ń gbé lágbègbè yẹn fọ̀nà hàn ẹ́. Ṣé wàá kúrò lọ́dọ̀ ẹni náà kó tó sọ ibi tí wàá gbà? Rárá o. Ńṣe ni wàá fara balẹ̀ gbọ́ bó ṣe ń júwe ọ̀nà náà. Lọ́nà kan náà, lẹ́yìn tó o bá ti gbàdúrà pé kí Jèhófà tọ́ ẹ sọ́nà, lo àwọn òfin àti ìlànà inú Bíbélì tó bá ipò ẹ mu, kó o lè mọ ohun tí Jèhófà fẹ́ kó o ṣe. Bí àpẹẹrẹ, tó o bá fẹ́ pinnu bóyá kó o lọ síbi àpèjẹ tá a sọ níṣàájú, o lè ronú lórí ohun tí Bíbélì sọ nípa àríyá aláriwo, ẹgbẹ́ búburú àti ìdí tó fi yẹ kó o fi Ìjọba Ọlọ́run ṣáájú ohunkóhun tó o bá ń ṣe.—Mát. 6:33; Róòmù 13:13; 1 Kọ́r. 15:33.

8. Nǹkan míì wo ló máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè ṣèpinnu tó tọ́? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

8 Nígbà míì, ó lè gba pé kẹ́nì kan ràn ẹ́ lọ́wọ́ tàbí kó o ṣèwádìí kó o lè ṣèpinnu tó tọ́. Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó nírìírí lè fún ẹ nímọ̀ràn tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. Bákan náà, wàá jàǹfààní tó o bá ṣèwádìí nínú ìwé ètò Ọlọ́run. Wàá rí àwọn àbá tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ nínú Ìwé Ìwádìí fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti nínú ìwé Àwọn Ẹsẹ Bíbélì Tó Lè Ran Àwa Kristẹni Lọ́wọ́. Má gbàgbé pé ìdí tó o fi ń ṣe gbogbo nǹkan yìí ni kó o lè ṣèpinnu tó máa múnú Jèhófà dùn.

Mọ ohun tí Jèhófà fẹ́ (Wo ìpínrọ̀ 8) b


9. Báwo la ṣe lè mọ̀ bóyá ìpinnu tá a fẹ́ ṣe máa múnú Jèhófà dùn? (Éfésù 5:17)

9 Báwo la ṣe lè mọ̀ bóyá ìpinnu tá a fẹ́ ṣe máa múnú Jèhófà dùn? Ohun àkọ́kọ́ ni pé ká mọ Jèhófà dáadáa. Bíbélì sọ pé: “Ìmọ̀ Ẹni Mímọ́ Jù Lọ . . . ni òye.” (Òwe 9:10) Tá a bá mọ àwọn ànímọ́ Jèhófà, àwọn nǹkan tó fẹ́ ṣe fáráyé, ohun tó fẹ́ àtohun tí kò fẹ́, ìyẹn máa fi hàn pé a ní òye. Torí náà, bi ara ẹ pé: ‘Báwo làwọn nǹkan tí mo mọ̀ nípa Jèhófà yìí ṣe lè jẹ́ kí n ṣèpinnu tó máa múnú ẹ̀ dùn?’—Ka Éfésù 5:17.

10. Kí nìdí tí ìlànà Bíbélì fi ṣe pàtàkì ju àṣà ìbílẹ̀ wa lọ?

10 Tá a bá máa ṣe ohun táá múnú Jèhófà dùn, nígbà míì á gba pé ká já àwọn tó nífẹ̀ẹ́ wa kulẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, àwọn òbí kan máa ń sọ pé dandan ni kí ọmọ wọn fẹ́ arákùnrin tó tó ẹrù ẹ̀ gbé tàbí tó máa lè sanwó orí tó pọ̀, kódà tí arákùnrin náà ò bá tiẹ̀ ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. Òótọ́ ni pé wọn ò fẹ́ kí ìyà jẹ ọmọ wọn, àmọ́ ó yẹ kí ọmọbìnrin náà bi ara ẹ̀ pé, ṣé arákùnrin yìí máa jẹ́ kí n túbọ̀ ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà? Kí ni Jèhófà máa fẹ́ kí n ṣe? Ìdáhùn ìbéèrè yìí wà ní Mátíù 6:33. Níbẹ̀, Jésù rọ̀ wá pé ká ‘máa wá Ìjọba náà lákọ̀ọ́kọ́.’ Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a máa ń bọ̀wọ̀ fáwọn òbí wa àtàwọn tá a jọ ń gbé ládùúgbò, ohun tó ṣe pàtàkì jù ni bá a ṣe máa múnú Jèhófà dùn.

RO IBI TỌ́RỌ̀ NÁÀ MÁA JÁ SÍ

11. Ànímọ́ wo ló wà ní Fílípì 1:9, 10 táá jẹ́ kó o mọ ohun tó máa gbẹ̀yìn ìpinnu tó o bá ṣe?

11 Tó o bá ti ronú lórí ìlànà Bíbélì tó bá ipò ẹ mu, ohun tó kàn ni pé kó o ro ibi tọ́rọ̀ náà máa já sí. (Ka Fílípì 1:9, 10; wo àlàyé ọ̀rọ̀ full discernment nínú nwtsty-E.) Ìfòyemọ̀ máa jẹ́ kó o mọ ohun tó máa gbẹ̀yìn ìpinnu tó o bá ṣe. Ó máa ń rọrùn láti ṣe àwọn ìpinnu kan, àmọ́ nígbà míì kì í rọrùn láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ìfòyemọ̀ á jẹ́ kó o ṣèpinnu tó tọ́, kódà tó bá ṣòro fún ẹ láti ṣèpinnu yẹn.

12-13. Tó o bá fẹ́ yan iṣẹ́ tó o máa ṣe, báwo ni ìfòyemọ̀ ṣe máa jẹ́ kó o ṣèpinnu tó tọ́?

12 Ká sọ pé ò ń wá iṣẹ́ tó o máa fi bójú tó ìdílé ẹ. Kò pẹ́ sígbà yẹn lo ríṣẹ́ síbi méjì. Kí ló yẹ kó o ṣe? Ó yẹ kó o ronú nípa ohun tí iṣẹ́ kọ̀ọ̀kan máa gbà, bó ṣe jìnnà sílé tó, iye ọjọ́ àti wákàtí tí wàá fi máa ṣiṣẹ́ àtàwọn nǹkan míì. Ká sọ pé o wá rí i pé iṣẹ́ méjèèjì ni Kristẹni lè ṣe ńkọ́? Àmọ́, ọ̀kan wù ẹ́ torí pé o nífẹ̀ẹ́ iṣẹ́ náà tàbí torí pé owó tí wọ́n máa san fún ẹ ju ti ìkejì lọ. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, àwọn nǹkan míì wo ló yẹ kó o ronú nípa ẹ̀ kó o tó ṣèpinnu?

13 O lè bi ara ẹ pé: Ṣé iṣẹ́ náà á jẹ́ kí n máa ráyè wá sípàdé? Ṣé á jẹ́ kí n máa wà pẹ̀lú ìdílé mi, kí n sì tún máa bójú tó wọn kí wọ́n lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà? Tó o bá bi ara ẹ láwọn ìbéèrè yìí, “àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù,” ìyẹn ìjọsìn Jèhófà àti ìdílé ẹ ni wàá fi ṣáájú àwọn nǹkan tara. Ó sì dájú pé ìpinnu tó máa múnú Jèhófà dùn lo máa ṣe.

14. Tá a bá ní ìfòyemọ̀ tá a sì nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, báwo ni ò ṣe ní jẹ́ ká mú àwọn ẹlòmíì kọsẹ̀?

14 Ìfòyemọ̀ máa jẹ́ ká mọ̀ bóyá ìpinnu tá a ṣe máa pa àwọn ẹlòmíì lára, ìyẹn ò sì ní jẹ́ ká “mú àwọn ẹlòmíì kọsẹ̀.” (Fílí. 1:10) Ìfòyemọ̀ ṣe pàtàkì tó bá dọ̀rọ̀ irú aṣọ tá a máa wọ̀ àti irun tá a máa ṣe. Bí àpẹẹrẹ, ó máa ń wù wá ká rán aṣọ wa bá a ṣe fẹ́, ó sì máa ń wù wá ká ṣe irun tàbí ká gẹrun wa bá a ṣe fẹ́. Àmọ́ ṣé ohun tó wù wá yìí ò ní bí àwọn ará wa àtàwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà nínú? Ìfòyemọ̀ máa jẹ́ ká gba tiwọn rò. Ìfẹ́ á jẹ́ ká máa wá ire àwọn “ẹlòmíì,” ká sì mọ̀wọ̀n ara wa. (1 Kọ́r. 10:23, 24, 32; 1 Tím. 2:9, 10) Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, àá ṣèpinnu táá fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, a sì bọ̀wọ̀ fún wọn.

15. Kó o tó ṣèpinnu pàtàkì, àwọn nǹkan wo ló yẹ kó o ṣe?

15 Tó o bá fẹ́ ṣèpinnu pàtàkì, ronú dáadáa nípa ohun tó o máa ṣe kọ́wọ́ ẹ lè tẹ ohun tó ò ń wá. Jésù kọ́ wa pé ká “ṣírò ohun tó máa ná” wa. (Lúùkù 14:28) Torí náà, á dáa kó o ronú nípa àkókò tó máa gbà ẹ́, ohun tó máa ná ẹ àti bó o ṣe máa sapá tó kọ́wọ́ ẹ lè tẹ ohun tó ò ń wá. Nígbà míì, àwọn ìpinnu kan lè gba pé kó o fọ̀rọ̀ lọ àwọn tẹ́ ẹ jọ wà nínú ìdílé, kí wọ́n lè mọ bí wọ́n á ṣe ràn ẹ́ lọ́wọ́. Kí nìdí tó fi yẹ kó o ṣe bẹ́ẹ̀? Ó máa jẹ́ kó o mọ̀ bóyá kó o ṣàtúnṣe ìpinnu tó o fẹ́ ṣe tàbí kó o yan nǹkan míì tó o máa ṣe. Tó o bá jẹ́ káwọn ará ilé ẹ mọ ìpinnu tó o fẹ́ ṣe, tó o sì gbọ́ èrò wọn, wọ́n á ràn ẹ́ lọ́wọ́ kọ́wọ́ ẹ lè tẹ ohun tó ò ń wá.—Òwe 15:22.

ṢÈPINNU TÓ MÁA YỌRÍ SÍ RERE

16. Àwọn nǹkan wo ló máa jẹ́ kó o ṣèpinnu táá yọrí sí rere? (Tún wo àpótí náà “ Bó O Ṣe Lè Ṣèpinnu Tó Dáa.”)

16 Tó o bá ṣe àwọn nǹkan tá a sọ yìí, wàá ṣèpinnu tó dáa. O ti mọ àwọn ohun tó yẹ kó o ṣe àtàwọn ìlànà Bíbélì tó yẹ kó o ronú lé kó o lè ṣèpinnu táá múnú Jèhófà dùn. Ohun tó kàn báyìí ni pé kó o bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kí ìpinnu tó o bá ṣe yọrí sí rere.

17. Kí ló máa jẹ́ kó o ṣe ìpinnu tó dáa?

17 Ká tiẹ̀ sọ pé o ti ṣe àwọn ìpinnu tó dáa kan sẹ́yìn, máa rántí pé ohun tó máa jẹ́ kó o ṣe àwọn ìpinnu míì tó dáa ni pé kó o gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, kì í ṣe òye tara ẹ tàbí àwọn ìrírí tó o ní. Jèhófà nìkan ló lè fún ẹ ní ìmọ̀, òye àti ìfòyemọ̀, àwọn nǹkan yìí ló sì máa sọ ẹ́ di ọlọ́gbọ́n. (Òwe 2:1-5) Torí náà, mọ̀ dájú pé Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè ṣèpinnu tó máa múnú ẹ̀ dùn.—Sm. 23:2, 3.

ORIN 28 Bá A Ṣe Lè Jẹ́ Ọ̀rẹ́ Jèhófà

a ÀWÒRÁN: Ẹnì kan pe àwọn ọ̀dọ́ kan wá síbi àpèjẹ, àwọn ọ̀dọ́ náà sì ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀.

b ÀWÒRÁN : Arákùnrin kan lára àwọn ọ̀dọ́ yẹn ń ṣèwádìí, kó lè mọ̀ bóyá kóun lọ síbi àpèjẹ yẹn.