A Jẹ́ ti Jèhófà
“Aláyọ̀ ni orílẹ̀-èdè tí Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run rẹ̀, àwọn ènìyàn tí ó yàn gẹ́gẹ́ bí ogún rẹ̀.”—SM. 33:12.
1. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé Jèhófà ló ni ohun gbogbo? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
JÈHÓFÀ ló ni ohun gbogbo. Òun ló “ni ọ̀run, àní ọ̀run àwọn ọ̀run, ilẹ̀ ayé àti gbogbo ohun tí ó wà nínú rẹ̀.” (Diu. 10:14; Ìṣí. 4:11) Jèhófà ló dá gbogbo èèyàn, torí náà gbogbo wa pátá jẹ́ tirẹ̀. (Sm. 100:3) Síbẹ̀, látìgbà táláyé ti dáyé ni Ọlọ́run ti máa ń dìídì ya àwọn kan sọ́tọ̀ bí ohun ìní tó jẹ́ àkànṣe.
2. Àwọn wo ni Bíbélì sọ pé wọ́n jẹ́ àkànṣe ìní fún Jèhófà?
2 Sáàmù 135 pe àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà ní Ísírẹ́lì ìgbàanì ní “àkànṣe dúkìá rẹ̀.” (Sm. 135:4) Bákan náà, ìwé Hóséà sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn kan tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì máa di èèyàn Jèhófà. (Hós. 2:23) Àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣẹ nígbà tí Jèhófà yan àwọn tí kì í ṣe Júù láti wà lára àwọn tó máa bá Kristi jọba lọ́run. (Ìṣe 10:45; Róòmù 9:23-26) Bíbélì pe àwọn tí Jèhófà fi ẹ̀mí mímọ́ yàn yìí ní “orílẹ̀-èdè mímọ́” àti “àkànṣe ìní” fún Jèhófà. (1 Pét. 2:9, 10) Àmọ́, àwọn Kristẹni olóòótọ́ tí wọ́n ń retí àtigbé lórí ilẹ̀ ayé ńkọ́? Jèhófà pe àwọn náà ní “ènìyàn mi,” ó sì tún pè wọ́n ní “àwọn àyànfẹ́ mi.”—Aísá. 65:22.
3. (a) Àwọn wo ló para pọ̀ jẹ́ èèyàn Jèhófà lónìí? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
Lúùkù 12:32; Jòh. 10:16) Ó dájú pé a máa fẹ́ kí Jèhófà rí i pé a mọyì àǹfààní ńlá tó fún wa láti jẹ́ èèyàn rẹ̀. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò onírúurú ọ̀nà tá a lè gbà fi hàn pé a mọyì àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ tí Jèhófà fún wa yìí.
3 Lónìí, “agbo kékeré” tó nírètí àtigbé lọ́run àtàwọn “àgùntàn mìíràn” tí wọ́n nírètí àtigbé lórí ilẹ̀ ayé ló para pọ̀ di “agbo kan” tí Jèhófà kà sí àwọn èèyàn rẹ̀. (KÁ YA ARA WA SÍ MÍMỌ́ FÚN JÈHÓFÀ
4. Ọ̀nà wo la lè gbà dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún àǹfààní tó fún wa láti jẹ́ èèyàn rẹ̀, báwo ni Jésù ṣe ṣe ohun tó jọ bẹ́ẹ̀?
4 Ọ̀nà kan tá a lè gbà fi hàn pé a mọyì àǹfààní tí Jèhófà fún wa yìí ni pé ká ya ara wa sí mímọ́ fún un. Nígbà tá a ṣèrìbọmi, ṣe là ń jẹ́ kó ṣe kedere sí gbogbo èèyàn pé a ti di ti Jèhófà àti pé ìfẹ́ rẹ̀ làá máa ṣe. (Heb. 12:9) Jésù ṣe ohun kan náà nígbà tó ṣèrìbọmi, ṣe ló dà bí ìgbà tó sọ fún Jèhófà pé: “Láti ṣe ìfẹ́ rẹ, ìwọ Ọlọ́run mi, ni mo ní inú dídùn sí.” (Sm. 40:7, 8) Jésù fi hàn pé ó wu òun láti ṣe ìfẹ́ Jèhófà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé orílẹ̀-èdè tí Jèhófà ti yà sí mímọ́ ni wọ́n bí i sí.
5, 6. (a) Báwo ló ṣe rí lára Jèhófà nígbà tí Jésù ṣèrìbọmi? (b) Ṣàpèjúwe ìdí tí inú Jèhófà fi máa ń dùn nígbà tá a bá ya ara wa sí mímọ́ fún un bó tilẹ̀ jẹ́ pé òun ló ni ohun gbogbo.
5 Báwo ló ṣe rí lára Jèhófà nígbà tí Jésù ṣèrìbọmi? Bíbélì sọ pé: “Lẹ́yìn tí a batisí rẹ̀, Jésù jáde lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ láti inú omi; sì wò ó! ọ̀run ṣí sílẹ̀, ó sì rí tí ẹ̀mí Ọlọ́run ń sọ̀kalẹ̀ bí àdàbà bọ̀ wá sórí rẹ̀. Wò ó! Pẹ̀lúpẹ̀lù, ohùn kan wá láti ọ̀run tí ó wí pé: ‘Èyí ni Ọmọ mi, olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹni tí mo ti tẹ́wọ́ gbà.’ ” (Mát. 3:16, 17) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ti Jèhófà náà ni Jésù jẹ́ tẹ́lẹ̀, síbẹ̀ inú Jèhófà dùn nígbà tó rí bí Ọmọ rẹ̀ ṣe múra tán láti ṣe ìfẹ́ òun látọkànwá. Bákan náà, inú Jèhófà máa ń dùn tá a bá ya ara wa sí mímọ́ fún un, ó sì dájú pé á bù kún wa.—Sm. 149:4.
6 Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé ọkùnrin kan gbin onírúurú òdòdó tó rẹwà sínú ọgbà rẹ̀. Lọ́jọ́ kan, ọmọbìnrin rẹ̀ já ọ̀kan nínú àwọn òdòdó náà, ó sì fún bàbá rẹ̀. Ó dájú pé bàbá náà ò ní ronú pé, ‘Ṣebí èmi náà ni mo ni gbogbo àwọn òdòdó yìí tẹ́lẹ̀? Báwo lọmọ mi ṣe máa fún mi ní nǹkan tó jẹ́ tèmi?’ Kàkà bẹ́ẹ̀, inú rẹ̀ máa dùn láti gba ẹ̀bùn náà, torí ìyẹn máa jẹ́ kó mọ̀ pé ọmọ náà nífẹ̀ẹ́ òun. Ó sì máa mọyì òdòdó tí ọmọbìnrin rẹ̀ fún un ju àwọn òdòdó tó kù nínú ọgbà rẹ̀ lọ. Táwa náà bá ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà, ó dájú pé inú rẹ̀ máa dùn gan-an sí wa.—Ẹ́kís. 34:14.
7. Báwo ni Málákì ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé inú Jèhófà máa ń dùn sáwọn tó bá ń fínnúfíndọ̀ ṣe ìfẹ́ rẹ̀?
7 Ka Málákì 3:16. Tó bá jẹ́ pé o ò tíì ya ara rẹ sí mímọ́, tó ò sì tíì ṣèrìbọmi, á dáa kó o ronú nípa ìdí pàtàkì tó fi yẹ kó o gbé ìgbésẹ̀ yìí. Òótọ́ ni pé látìgbà tí wọ́n ti lóyún rẹ lo ti jẹ́ ti Jèhófà bíi ti gbogbo èèyàn tó wà láyé. Síbẹ̀ ronú nípa bí inú Jèhófà ṣe máa dùn tó tó o bá ya ara rẹ sí mímọ́ fún un, tó o sì ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀ torí pé ó fẹ́ jẹ́ kó ṣe kedere pé òun ni Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run. (Òwe 23:15) Ó dájú pé Jèhófà máa fojúure hàn sáwọn tó bá ń fínnúfíndọ̀ ṣe ìfẹ́ rẹ̀, á sì kọ orúkọ wọn sínú “ìwé ìrántí” rẹ̀.
8, 9. Kí làwọn nǹkan tá a gbọ́dọ̀ ṣe tá ò bá fẹ́ kí Jèhófà yọ orúkọ wa kúrò nínú “ìwé ìrántí” rẹ̀?
8 Ó láwọn nǹkan tá a gbọ́dọ̀ ṣe tá ò bá fẹ́ kí Jèhófà yọ orúkọ wa kúrò nínú “ìwé ìrántí” rẹ̀. Málákì dìídì sọ pé a gbọ́dọ̀ ‘bẹ̀rù Jèhófà, ká sì máa ronú lórí orúkọ rẹ̀.’ Tá a bá ń jọ́sìn ẹnikẹ́ni tàbí ohunkóhun míì, èyí máa mú kí Jèhófà yọ orúkọ wa kúrò nínú ìwé ìyè lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ.—9 Ká ya ara wa sí mímọ́ kọjá ká kàn ṣèlérí fún Jèhófà pé àá máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀, ká sì ṣèrìbọmi. Ẹ̀ẹ̀kan la máa ń ṣe àwọn nǹkan yìí. Àmọ́, ìyàsímímọ́ wa gba pé ká máa ṣègbọràn sí Jèhófà lójoojúmọ́ jálẹ̀ ìgbésí ayé wa.—1 Pét. 4:1, 2.
KÁ MÁ ṢE FÀYÈ GBA ÌFẸ́KÚFẸ̀Ẹ́ AYÉ
10. Ìyàtọ̀ wo ló gbọ́dọ̀ wà láàárín ẹni tó ń sin Jèhófà àtẹni tí kò sìn ín?
10 Nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, a sọ̀rọ̀ nípa Kéènì, Sólómọ́nì àtàwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Gbogbo wọn sọ pé Jèhófà làwọn ń sìn, àmọ́ ìjọsìn wọn ò tọkàn wá. Èyí jẹ́ ká rí i pé àwọn tó bá jẹ́ ti Jèhófà gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ ohun rere, kí wọ́n sì kórìíra ohun búburú. (Róòmù 12:9) Èyí sì bá a mu torí pé lẹ́yìn tí Málákì mẹ́nu kan “ìwé ìrántí” yẹn, Jèhófà sọ̀rọ̀ nípa “ìyàtọ̀ láàárín olódodo àti ẹni burúkú, láàárín ẹni tí ń sin Ọlọ́run àti ẹni tí kò sìn ín.”—Mál. 3:18.
11. Kí nìdí tó fi yẹ kó hàn kedere sáwọn míì pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wá?
11 Ọ̀nà míì tá a lè gbà fi hàn pé a mọyì àǹfààní tí Jèhófà fún wa láti jẹ́ èèyàn rẹ̀ ni pé ká jẹ́ kí ìtẹ̀síwájú wa nípa tẹ̀mí “fara hàn kedere fún gbogbo ènìyàn.” (1 Tím. 4:15; Mát. 5:16) Bi ara rẹ pé: ‘Táwọn míì bá rí mi, ṣé wọ́n máa gbà pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mí? Ṣé mo máa ń lo àǹfààní tó bá yọjú láti jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mí?’ Ó máa dun Jèhófà gan-an tó bá rí i pé lẹ́yìn tóun yàn wá láti jẹ́ èèyàn rẹ̀, ṣe là ń díbọ́n tá ò sì jẹ́ káwọn míì mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí rẹ̀ la jẹ́.—Sm. 119:46; ka Máàkù 8:38.
12, 13. Kí làwọn kan máa ń ṣe tó máa ń mú kó ṣòro láti dá wọn mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wọ́n?
1 Kọ́r. 2:12) Ẹ̀mí burúkú yìí sì máa ń jẹ́ káwọn èèyàn lépa “ìfẹ́-ọkàn ti ẹran ara.” (Éfé. 2:3) Bí àpẹẹrẹ, láìka gbogbo ìkìlọ̀ tá a ti gbà lórí ọ̀rọ̀ ìmúra, àwọn Kristẹni kan ṣì nífẹ̀ẹ́ sáwọn aṣọ tí kò yẹ ọmọlúàbí. Wọ́n máa ń wọ àwọn aṣọ tó fún mọ́ra pinpin àtèyí tó ṣí ara sílẹ̀, kódà wọ́n máa ń wọ̀ ọ́ lọ sípàdé àtàwọn àpéjọ Kristẹni míì. Àwọn míì máa ń gẹ irun tàbí ṣe irun bíi tàwọn èèyàn ayé. (1 Tím. 2:9, 10) Tí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ bá wà láàárín èrò, ẹ ò ní mọ̀ bóyá èèyàn Jèhófà ni wọ́n tàbí “ọ̀rẹ́ ayé.”—Ják. 4:4.
12 Ó bani nínú jẹ́ pé àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà kan ti jẹ́ kó ṣòro láti ‘fìyàtọ̀ sáàárín àwọn tó ń sin Ọlọ́run àtàwọn tí kò sìn ín.’ Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ń jẹ́ kí “ẹ̀mí ayé” máa darí wọn débi pé wọn ò yàtọ̀ sáwọn èèyàn ayé. (13 Àwọn Kristẹni kan tún máa ń fara wé àwọn èèyàn ayé láwọn ọ̀nà míì. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ijó tí kò yẹ Kristẹni àtàwọn ìwà tí kò dáa làwọn kan máa ń hù láwọn àpèjẹ. Àwọn míì máa ń gbé fọ́tò àtàwọn ọ̀rọ̀ tí kò yẹ ọmọlúàbí sórí ìkànnì àjọlò. Wọ́n lè má tíì bá irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ wí nínú ìjọ fún ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì, àmọ́ wọn kì í ṣàpẹẹrẹ tó dáa, wọ́n sì lè kéèràn ran àwọn míì tó ń sapá láti máa hùwà rere nínú ìjọ.—Ka 1 Pétérù 2:11, 12.
14. Kí ló yẹ ká ṣe tá ò bá fẹ́ kí àjọṣe àwa àti Jèhófà bà jẹ́?
14 Ohun tí ayé yìí ń gbé lárugẹ ni “ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú àti fífi àlùmọ́ọ́nì ìgbésí ayé ẹni hàn sóde lọ́nà ṣekárími.” (1 Jòh. 2:16) Àmọ́ torí pé a jẹ́ ti Jèhófà, Bíbélì gbà wá níyànjú pé ká ‘kọ àìṣèfẹ́ Ọlọ́run sílẹ̀ àti àwọn ìfẹ́-ọkàn ti ayé, ká sì gbé pẹ̀lú ìyèkooro èrò inú àti òdodo àti fífọkànsin Ọlọ́run nínú ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí.’ (Títù 2:12) Ó yẹ kó hàn nínú gbogbo ohun tá à ń ṣe pé èèyàn Jèhófà la jẹ́, yálà nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe wa, ìmúra wa, bá a ṣe ń jẹ, bá a ṣe ń mu, ọwọ́ tá a fi mú iṣẹ́ wa àtàwọn nǹkan míì.—Ka 1 Kọ́ríńtì 10:31, 32.
KÁ ‘NÍ ÌFẸ́ GBÍGBÓNÁ JANJAN FÚN ARA WA LẸ́NÌ KÌÍNÍ-KEJÌ’
15. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa fi ìfẹ́ àti inúure hàn sáwọn ará wa?
15 Ọwọ́ tá a bá fi mú àwọn ará wa máa fi hàn bóyá á mọyì àǹfààní tá a ní láti jẹ́ èèyàn Jèhófà. Tá a bá ń fi sọ́kàn pé èèyàn Jèhófà làwọn ará wa, gbogbo ìgbà làá máa fi ìfẹ́ àti inúure hàn sí wọn. (1 Tẹs. 5:15) Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.”—Jòh. 13:35.
16. Àpẹẹrẹ wo nínú Òfin Mósè ló jẹ́ ká mọ bí Jèhófà ṣe ka àwọn èèyàn rẹ̀ sí pàtàkì tó?
16 Ká lè mọ ọwọ́ tó yẹ ká fi mú àwọn ará wa nínú ìjọ, ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ yìí. Nínú tẹ́ńpìlì Jèhófà, wọ́n dìídì ya àwọn ohun èlò tó wà níbẹ̀ sí mímọ́ fún ìjọsìn tòótọ́. Òfin Mósè ṣe àlàyé kíkún nípa bó ṣe yẹ kí wọ́n lo àwọn nǹkan yìí, kódà ṣe ni wọ́n máa pa ẹni tó bá rú òfin náà. (Núm. 1:50, 51) Tí Jèhófà bá lè fọwọ́ pàtàkì bẹ́ẹ̀ mú àwọn ohun èlò aláìlẹ́mìí tí wọ́n ń lò nínú ìjọsìn rẹ̀, mélòómélòó ni àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ tó ti yàn tá a sì ti ya ara wa sí mímọ́ fún un! Jèhófà jẹ́ ká mọ bá a ti ṣe pàtàkì tó nígbà tó sọ pé: “Ẹni tí ó bá fọwọ́ kàn yín ń fọwọ́ kan ẹyinjú mi.”—Sek. 2:8.
17. Kí ni Jèhófà ń ‘fiyè sí, tó sì ń fetí sílẹ̀’ sí?
17 Málákì sọ ohun kan tó gbàfiyèsí, ó sọ pé báwọn èèyàn Jèhófà ṣe ń bá ara wọn sọ̀rọ̀, Jèhófà ń “fiyè sí i, ó sì ń fetí sílẹ̀.” (Mál. 3:16) Ó dájú pé Jèhófà “mọ àwọn tí í ṣe tirẹ̀.” (2 Tím. 2:19) Gbogbo ohun tá à ń sọ, tá a sì ń ṣe pátápátá ló mọ̀. (Héb. 4:13) Ká fi sọ́kàn pé tá ò bá fi inúure hàn sáwọn ará wa, Jèhófà ń “fiyè sí i, ó sì ń fetí sílẹ̀.” Bákan náà, Jèhófà máa ń mọ̀ tá a bá ṣe inúure sáwọn ará, tá a ràn wọ́n lọ́wọ́, tá a dárí jì wọ́n, tá a sì ń fìfẹ́ hàn sí wọn.—Héb. 13:16; 1 Pét. 4:8, 9.
“JÈHÓFÀ KÌ YÓÒ ṢÁ ÀWỌN ÈNÌYÀN RẸ̀ TÌ”
18. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọyì àǹfààní tí Jèhófà fún wa láti jẹ́ èèyàn rẹ̀?
18 Ó dájú pé ó ń wù wá láti fi hàn pé a mọyì àǹfààní tí Jèhófà fún wa láti jẹ́ èèyàn rẹ̀. Ọ̀kan nínú ohun tó yẹ ká ṣe ni pé ká ya ara wa sí mímọ́ fún un. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àárín àwọn èèyàn tó jẹ́ “oníwà wíwọ́ àti onímàgòmágó” là ń gbé, síbẹ̀ a fẹ́ káwọn èèyàn rí i pé “aláìlẹ́bi àti ọlọ́wọ́-mímọ́” ni wá, a sì ń “tàn bí atànmọ́lẹ̀ nínú ayé.” (Fílí. 2:15) Torí náà, a ti pinnu láti kórìíra ohun búburú. (Ják. 4:7) Yàtọ̀ síyẹn, à ń fìfẹ́ hàn sáwọn ará wa, a sì ń bọ̀wọ̀ fún wọn torí pé àwọn náà jẹ́ ti Jèhófà.—Róòmù 12:10.
19. Báwo ni Jèhófà ṣe ń bù kún àwọn tó jẹ́ tirẹ̀?
19 Bíbélì ṣèlérí pé: “Jèhófà kì yóò ṣá àwọn ènìyàn rẹ̀ tì.” (Sm. 94:14) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tá ò lérò lè ṣẹlẹ̀ sí wa, síbẹ̀ ìlérí tí Jèhófà ṣe yìí dájú. Kódà tá a bá kú, Jèhófà ò ní gbàgbé wa. (Róòmù 8:38, 39) Bíbélì sọ pé: “Bí a bá wà láàyè, a wà láàyè fún Jèhófà, bí a bá sì kú, a kú fún Jèhófà. Nítorí náà, bí a bá wà láàyè àti bí a bá kú, a jẹ́ ti Jèhófà.” (Róòmù 14:8) À ń fojú sọ́nà fún ìgbà tí Jèhófà máa jí gbogbo àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ tó ti kú dìde lọ́jọ́ iwájú. (Mát. 22:32) Kódà ní báyìí, ọ̀pọ̀ ìbùkún là ń gbádùn. Bí Bíbélì ṣe sọ ọ́ ló rí, pé “aláyọ̀ ni orílẹ̀-èdè tí Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run rẹ̀, àwọn ènìyàn tí ó yàn gẹ́gẹ́ bí ogún rẹ̀.”—Sm. 33:12.