Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

Ohun Tó Yẹ Kí N Ṣe Ni Mo Ṣe

Ohun Tó Yẹ Kí N Ṣe Ni Mo Ṣe

OHUN tó lé ní ọgbọ̀n (30) ọdún ni Donald Ridley fi gbèjà àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílé ẹjọ́. Ó sapá gan-an láti jẹ́ kí àwọn dókítà, àwọn adájọ́ àtàwọn míì mọ̀ pé àwọn tó ń ṣàìsàn lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ pé àwọn ò gbẹ̀jẹ̀. Ìyẹn sì ti jẹ́ ká jàre ọ̀pọ̀ ẹjọ́ nílé ẹjọ́ gíga. Don làwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ máa ń pè é. Èèyàn jẹ́jẹ́ ni, ó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, ó sì máa ń fi ara ẹ̀ jìn nítorí àwọn míì.

Ní 2019, àwọn dókítà sọ pé Don ní àìsàn kan tó máa ń ba iṣan ara jẹ́, àìsàn náà ò sì gbóògùn. Kò pẹ́ tí àìsàn náà fi le gan-an, nígbà tó sì máa di August 16, 2019, Don kú. Ìtàn ìgbésí ayé ẹ̀ rèé.

Ìpínlẹ̀ St. Paul ní Minnesota lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni wọ́n bí mi sí lọ́dún 1954. Ìdílé wa rí já jẹ déwọ̀n àyè kan, Kátólíìkì ni wá, èmi sì ni ọmọ kejì nínú ọmọ márùn-ún táwọn òbí mi bí. Nígbà tí mo wà ní kékeré, ilé ìwé àwọn ẹlẹ́sìn Kátólíìkì kan ni mo lọ, mo sì máa ń bá àlùfáà ṣiṣẹ́ nídìí pẹpẹ. Síbẹ̀, ìwọ̀nba lohun tí mo mọ̀ nínú Bíbélì. Lóòótọ́, mo gbà pé Ọlọ́run kan wà tó dá gbogbo nǹkan, àmọ́ mi ò gbà pé ẹ̀sìn Kátólíìkì lè mú kí n sún mọ́ Ọlọ́run.

BÍ MO ṢE KẸ́KỌ̀Ọ́ ÒTÍTỌ́

Lọ́dún àkọ́kọ́ tí mo lò nílé ìwé William Mitchell College of Law, tọkọtaya Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan wá sílé mi. Mò ń fọṣọ lọ́wọ́ nígbà tí wọ́n dé, àmọ́ wọ́n sọ pé àwọn máa pa dà wá. Nígbà tí wọ́n pa dà wá, mo bi wọ́n ní ìbéèrè méjì kan: “Kí nìdí táwọn èèyàn dáadáa kì í fi í rọ́wọ́ mú nínú ayé?” àti pé “Kí ló lè mú kéèyàn láyọ̀?” Mo gba ìwé Otitọ ti Nsinni Lọ si Iye Aiyeraiye àti Bíbélì Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun. Àwọ̀ ewé tó wà lára Bíbélì náà jẹ́ kó fani mọ́ra gan-an. Mo gbà kí wọ́n máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìyẹn ló sì mú kí n lóye ọ̀pọ̀ nǹkan nínú Bíbélì. Inú mi dùn nígbà tí mo gbọ́ pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló máa yanjú gbogbo ìṣòro tó wà láyé yìí. Mo sì ti rí i pé ìjọba èèyàn ti kùnà àti pé ìrora, ìyà, ìrẹ́jẹ àti ẹ̀dùn ọkàn ni wọ́n ń fà fáwọn èèyàn.

Ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1982 ni mo ya ara mi sí mímọ́ fún Jèhófà, Àpéjọ Agbègbè “Òtítọ́ Ìjọba” tá a ṣe ní St. Paul Civic Center lópin ọdún yẹn ni mo sì ti ṣèrìbọmi. Ní ọ̀sẹ̀ tó tẹ̀ lé e, mo lọ ṣe ìdánwò tó máa sọ mí di agbẹjọ́rò níbì kan náà tá a ti ṣe àpéjọ yẹn. Níbẹ̀rẹ̀ oṣù October, wọ́n sọ fún mi pé mo yege ìdánwò náà, mo sì di agbẹjọ́rò.

Níbi Àpéjọ “Òtítọ́ Ìjọba” yẹn, mo pàdé Mike Richardson tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Brooklyn, ó sì sọ fún mi pé wọ́n ti dá ẹ̀ka kan sílẹ̀ táwọn agbẹjọ́rò á ti máa ṣiṣẹ́ fún ètò Ọlọ́run ní orílé iṣẹ́ wa. Mo rántí ọ̀rọ̀ tí ìwẹ̀fà ará Etiópíà sọ nínú ìwé Ìṣe 8:​36, mo wá bi ara mi pé, ‘Kí ló ń dí mi lọ́wọ́ láti lọ ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka yìí?’ Torí náà, mo kọ̀rọ̀ kún fọ́ọ̀mù pé mo fẹ́ sìn ní Bẹ́tẹ́lì.

Inú àwọn òbí mi ò dùn nígbà tí mo di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Bàbá mi bi mí pé kí ni èmi tí mo jẹ́ agbẹjọ́rò fẹ́ lọ ṣe níbẹ̀, àǹfààní wo sì nìyẹn máa ṣe mí? Mo sọ fún wọn pé mo fẹ́ lọ yọ̀ǹda ara mi ni. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n á máa fún mi ní dọ́là márùndínlọ́gọ́rin (75) lóṣooṣù, iye tí wọ́n sì máa ń fún àwọn tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì nígbà yẹn nìyẹn.

Mo ti ń ṣiṣẹ́ níbì kan tẹ́lẹ̀, àwọn nǹkan kan sì wà tí mo gbọ́dọ̀ ṣe kí n tó fiṣẹ́ náà sílẹ̀. Torí náà, ọdún 1984 ni mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì ní Brooklyn, New York. Ọ́fíìsì àwọn agbẹjọ́rò ni wọ́n ti ní kí n lọ ṣiṣẹ́. Ìgbà tí mo lọ yẹn ló dáa jù torí mo ti nírìírí díẹ̀ níbi tí mo ti ṣiṣẹ́ tẹ́lẹ̀.

WỌ́N TÚN ILÉ ÌWÒRAN STANLEY THEATER ṢE

Ilé ìwòran Stanley Theater rèé nígbà tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ rà á

Ní November 1983, ètò Ọlọ́run ra ilé ìwòran kan tó ń jẹ́ Stanley Theater nílùú New Jersey. A fẹ́ gba ìwé àṣẹ láti ṣe àwọn àtúnṣe sí iná mànàmáná àti omi ẹ̀rọ tó wà nínú ilé náà. Torí náà, nígbà táwọn arákùnrin wa lọ bá àwọn aláṣẹ, wọ́n ṣàlàyé pé àpéjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la fẹ́ máa lo ibẹ̀ fún. Ọ̀rọ̀ yẹn ló dá ìṣòro sílẹ̀. Àárín ibi tí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ ajé nilé ìwòran náà wà, bẹ́ẹ̀ sì rèé ohun tí òfin sọ ni pé ibi táwọn èèyàn ń gbé nìkan ni ilé ìjọsìn lè wà. Bí wọn ò ṣe fún àwọn arákùnrin wa níwèé àṣẹ nìyẹn. Torí náà, àwọn ará pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn, àmọ́ ibì kan náà ló já sí.

Ní ọ̀sẹ̀ àkọ́kọ́ tí mo dé Bẹ́tẹ́lì, ètò Ọlọ́run gbé ẹjọ́ náà lọ sílé ẹjọ́ ìjọba àpapọ̀. Torí pé ọdún méjì ni mo ti fi ṣiṣẹ́ ní ilé ẹjọ́ ìjọba àpapọ̀ nílùú St. Paul ìpínlẹ̀ Minnesota, irú ẹjọ́ bẹ́ẹ̀ ò ṣàjèjì sí mi. Ọ̀kan lára àwọn agbẹjọ́rò wa sọ nílé ẹjọ́ pé ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn tó ń kọrin aláriwo, àwọn onísinimá àtàwọn míì ti lo ilé ìwòran náà. Torí náà, kí nìdí tá ò fi lè lò ó fún ilé ìjọsìn? Ilé ẹjọ́ náà sọ pé kò bójú mu bí ìlú Jersey City ò ṣe fún wa lómìnira láti ṣe ẹ̀sìn wa, torí náà wọ́n rú òfin. Ilé ẹjọ́ wá dájọ́ pé kí wọ́n fún wa níwèé àṣẹ tá a béèrè, ìgbà àkọ́kọ́ nìyẹn tí mo máa rí bí Jèhófà ṣe ń gbèjà ètò rẹ̀ lọ́nà òfin tíyẹn sì ń mú kí iṣẹ́ náà tẹ̀ síwájú. Inú mi dùn gan-an pé mo kópa nínú iṣẹ́ náà.

Bí iṣẹ́ àtúnṣe ilé ìwòran náà ṣe bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹu nìyẹn. Nǹkan bí ọdún kan lẹ́yìn náà, a ṣe ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege kíláàsì kọkàndínlọ́gọ́rin (79) ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì ní Jersey City Assembly Hall ní September 8, 1985. Inú mi dùn gan-an pé mo ṣiṣẹ́ fún Jèhófà lọ́nà yìí. Ayọ̀ tí mo rí kọjá ayọ̀ tí mo ní nígbà tí mò ń ṣiṣẹ́ agbẹjọ́rò kí n tó wá sí Bẹ́tẹ́lì. Mi ò sì mọ̀ pé ọ̀pọ̀ nǹkan ni Jèhófà ṣì máa jẹ́ kí n gbé ṣe nínú ètò rẹ̀.

A GBÈJÀ Ẹ̀TỌ́ WA LÁTI MÁ ṢE GBA Ẹ̀JẸ̀

Láwọn ọdún 1980, àwọn dókítà kì í gbà láti tọ́jú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà láìlo ẹ̀jẹ̀ kódà tí Ẹlẹ́rìí náà bá sọ pé òun ò gbẹ̀jẹ̀. Tàwọn aláboyún ló le jù, torí àwọn adájọ́ yẹn rò pé tí wọn ò bá gbẹ̀jẹ̀, wọ́n á kú, wọ́n á wá sọ ọmọ náà di aláìníyàá. Torí náà, wọ́n gbà pé wọn ò lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ pé àwọn ò gbẹ̀jẹ̀.

Ní December 29, 1988, ẹ̀jẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í ya lára arábìnrin kan tó ń jẹ́ Denise Nicoleau lẹ́yìn tó bímọ. Nígbà tó yá, ẹ̀jẹ̀ ẹ̀ lọlẹ̀ gan-an, kódà èròjà hemoglobin tó wà nínú ẹ̀jẹ̀ náà ò tó 5.0. Torí náà, dókítà tó ń tọ́jú ẹ̀ sọ pé àfi káwọn fa ẹ̀jẹ̀ sí i lára, àmọ́ Arábìnrin Nicoleau kọ̀ jálẹ̀. Láàárọ̀ ọjọ́ kejì, àwọn aṣojú ilé ìwòsàn náà lọ gbàṣẹ nílé ẹjọ́ láti fa ẹ̀jẹ̀ sí arábìnrin náà lára. Wọn ò gbọ́ ẹjọ́ náà nílé ẹjọ́ débi tí wọ́n fi máa gbọ́ tẹnu Arábìnrin Nicoleau àti ọkọ ẹ̀. Ohun tá a kàn gbọ́ ni pé wọ́n ti fọwọ́ sí i pé kí wọ́n lọ fẹ̀jẹ̀ sí i lára.

Ní Friday, December 30, àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìwòsàn náà fa ẹ̀jẹ̀ sí Arábìnrin Nicoleau lára láìka ti pé ọkọ ẹ̀ àtàwọn mọ̀lẹ́bí míì tó wà lọ́dọ̀ ẹ̀ kọ̀ jálẹ̀. Nírọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn, àwọn ọlọ́pàá mú àwọn mọ̀lẹ́bí wọn kan àtàwọn alàgbà bíi méjì kan pé wọ́n dí àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìwòsàn náà lọ́wọ́ láti fẹ̀jẹ̀ sí i lára. Nígbà tó fi máa di àárọ̀ ọjọ́ kejì, àwọn ìwé ìròyìn, ilé iṣẹ́ rédíò àti tẹlifíṣọ̀n tó wà ní New York City gbé ìròyìn náà jáde.

Èmi àti Arákùnrin Philip Brumley rèé

Láàárọ̀ Monday, mo lọ sí ọ́fíìsì adájọ́ àgbà kan tó ń jẹ́ Milton Mollen. Mo ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀ fún un, mo sì sọ fún un pé adájọ́ tó kọ́kọ́ dá ẹjọ́ náà fọwọ́ sí i pé kí wọ́n fẹ̀jẹ̀ sí arábìnrin náà lára láìgbọ́ ẹjọ́ lẹ́nu ẹ̀ rárá. Adájọ́ àgbà Mollen sọ pé kí n pa dà wá sí ọ́fíìsì òun nírọ̀lẹ́ ọjọ́ náà ká lè jọ sọ̀rọ̀ náà kúnná, ká sì wo ohun tí òfin sọ nípa ẹ̀. Èmi àti Arákùnrin Philip Brumley tó jẹ́ alábòójútó ẹ̀ka tí mo ti ń ṣiṣẹ́ la jọ lọ síbẹ̀ nírọ̀lẹ́ ọjọ́ náà. Adájọ́ yẹn sì ní kí agbẹjọ́rò fún ilé ìwòsàn náà wá síbẹ̀. Ṣe la gbéná wojú ara wa, kódà nígbà tọ́rọ̀ náà dójú ẹ̀, Arákùnrin Brumley ní láti kọ ọ̀rọ̀ kan sí mi pé kí n kà á. Ohun tó kọ síbẹ̀ ni pé “rọra gbé ohùn ẹ wálẹ̀.” Ìmọ̀ràn yẹn bọ́ sákòókò gan-an, torí pé gbogbo ara ni mo fi ń sọ̀rọ̀ kí agbẹjọ́rò ilé ìwòsàn yẹn lè mọ̀ pé ohun tóun ṣe ò tọ́.

Láti apá òsì sí apá ọ̀tún: Richard Moake, Gregory Olds, Paul Polidoro, Philip Brumley, èmi àti Mario Moreno​—àwa agbẹjọ́rò tá a lọ sí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà nígbà tí wọ́n ṣe ẹjọ́ Watchtower pẹ̀lú Abúlé Stratton.​—Wo Jí! January 8, 2003

Lẹ́yìn nǹkan bíi wákàtí kan, Adájọ́ Àgbà Mollen sọ pé ẹjọ́ yẹn lòun máa kọ́kọ́ gbọ́ láàárọ̀ ọjọ́ kejì. Bá a ṣe ń kúrò ní ọ́fíìsì rẹ̀, ó sọ fún agbẹjọ́rò ilé ìwòsàn náà pé “ẹjọ́ yìí ò ní rọrùn fún ẹ lọ́la o.” Ṣe lohun tó sọ yẹn dà bí ìgbà tí Jèhófà ń sọ fún wa pé ká fọkàn balẹ̀, àwa la máa borí. Inú mi dùn bí mo ṣe ń rí i pé Jèhófà ń tì wá lẹ́yìn ká lè mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ.

Àṣedòru la ṣe lọ́jọ́ náà ká lè múra sílẹ̀ fún ohun tá a máa sọ láàárọ̀ ọjọ́ kejì. Ilé ẹjọ́ yẹn ò fi bẹ́ẹ̀ jìnnà sí Bẹ́tẹ́lì, torí náà ọ̀pọ̀ lára àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ ní ọ́fíìsì àwọn amòfin ló fẹsẹ̀ rìn lọ síbẹ̀. Ìgbìmọ̀ ìdájọ́ ẹlẹ́ni mẹ́rin ló gbọ́ ẹjọ́ náà, wọ́n sì fagi lé ìpinnu tí adájọ́ àkọ́kọ́ ṣe. Ilé ẹjọ́ gíga náà dá Arábìnrin Nicoleau láre, ó sì fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé ó lòdì sófin láti fún àwọn oníṣègùn láṣẹ pé kí wọ́n fa ẹ̀jẹ̀ sí ẹnì kan lára láìsọ fún un tàbí láìgbọ́ tẹnu ẹ̀.

Kò pẹ́ sígbà yẹn nilé ẹjọ́ tó ga jù lọ ní New York tún dá ẹjọ́ pé Arábìnrin Nicoleau lẹ́tọ̀ọ́ láti gba ìtọ́jú láìlo ẹ̀jẹ̀. Ẹjọ́ yìí ni àkọ́kọ́ nínú ẹjọ́ mẹ́rin tó ní í ṣe pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ tí ilé ẹjọ́ gíga ìpínlẹ̀ dá, tí mo sì lọ́wọ́ sí. (Wo àpótí náà “ Àwọn Ẹjọ́ Tá A Jàre ní Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ.”) Lẹ́yìn ìyẹn, èmi àtàwọn agbẹjọ́rò míì ní Bẹ́tẹ́lì ti ṣe àwọn ẹjọ́ míì tó ní í ṣe pẹ̀lú àwọn tọkọtaya tí wọ́n fẹ́ kọ ara wọn sílẹ̀, ibi táwọn ọmọ wọn á máa gbé, ọ̀rọ̀ nípa ilẹ̀ àti ilé àti òfin tó jẹ mọ́ ilé kíkọ́.

MO ṢÈGBÉYÀWÓ

Èmi àti Dawn ìyàwó mi

Nígbà tí mo kọ́kọ́ pàdé Dawn ìyàwó mi, ọkọ rẹ̀ ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀, òun nìkan ló sì ń dá tọ́mọ mẹ́ta. Aṣáájú ọ̀nà ni, ó sì ń ṣiṣẹ́ kó lè fi gbọ́ bùkátà òun àtàwọn ọmọ ẹ̀. Nǹkan ò rọrùn fún un, àmọ́ bó ṣe ń ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti sin Jèhófà wú mi lórí gan-an. Lọ́dún 1992, a lọ sí Àpéjọ Agbègbè “Àwọn Olùtan Ìmọ́lẹ̀” ní New York City, mo sì sọ fún un pé kó jẹ́ ká máa fẹ́ra. Ọdún kan lẹ́yìn ìyẹn la ṣègbéyàwó. Mo gbà pé ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Jèhófà ni ìyàwó mi, torí pé ó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ara rẹ̀ sì yá mọ́ èèyàn gan-an. Ohun rere ni Dawn máa ń ṣe fún mi látìgbà tá a ti fẹ́ra.​—Òwe 31:12.

Nígbà tá a ṣègbéyàwó, ọmọ ọdún mọ́kànlá (11), mẹ́tàlá (13) àti mẹ́rìndínlógún (16) làwọn ọmọ náà. Torí pé mo fẹ́ jẹ́ bàbá dáadáa fún wọn, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ka àwọn nǹkan tí ètò Ọlọ́run ti sọ nípa àwọn òbí tó tún ìgbéyàwó ṣe, mo sì ń fi gbogbo ẹ̀ sílò. Kò rọrùn láti tọ́jú àwọn ọmọ náà, àmọ́ inú mi dùn pé àwọn ọmọ yẹn ti wá fọkàn tán mi. A gba àwọn ọmọ wa láyè láti mú àwọn ọ̀rẹ́ wọn wá sílé, inú wa sì máa ń dùn láti rí wọn.

Ní 2013, èmi àti Dawn kó lọ sí Wisconsin ká lè tọ́jú àwọn òbí wa tó ti ń dàgbà. Ó yà mí lẹ́nu pé wọ́n tún ní kí n máa ràn wọ́n lọ́wọ́ ní Bẹ́tẹ́lì. Wọ́n ní kí n máa ran àwọn lọ́wọ́ lórí ohun tó jẹ mọ́ ọ̀rọ̀ òfin láwọn ọjọ́ kan láàárín ọ̀sẹ̀.

NǸKAN YÍ PA DÀ LÓJIJÌ

Nígbà tó di September 2018, mo kíyè sí i pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo máa ń gbẹ́kọ́. Mo lọ rí dókítà, àmọ́ kò mọ ohun tó fà á. Nígbà tó yá, dókítà míì ní kí n lọ rí àwọn onímọ̀ nípa àrùn iṣan. Ní January 2019, àyẹ̀wò fi hàn pé mo ní àrùn inú iṣan kan tí wọ́n ń pè ní Progressive Supranuclear Palsy (PSP).

Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta tí mo ṣe àyẹ̀wò náà, mo fọwọ́ rọ́ nígbà tí mò ń ṣe eré ìmárale. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ọjọ́ pẹ́ tí mo ti ń ṣe é torí pé mo máa ń gbádùn ẹ̀ gan-an. Mo wá rí i pé ohun tó ń ṣe mí yẹn ti ń ba àwọn iṣan ara mi jẹ́. Ó yà mí lẹ́nu pé àìsàn náà ò mú un ní kékeré rárá torí kò pẹ́ tó fi ba gbogbo iṣan ara mi jẹ́. Ká tó ṣẹ́jú pẹ́, mi ò lè sọ̀rọ̀ dáadáa mọ́, ìrìn mi ò já gaara, ó sì ń nira fún mi láti gbé nǹkan mì.

Síbẹ̀, inú mi dùn gan-an pé bí mi ò tiẹ̀ já mọ́ nǹkan kan, Jèhófà mú kí n lo òye iṣẹ́ tí mo kọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Mo láǹfààní láti gbèjà ẹ̀tọ́ táwa èèyàn Jèhófà ní láti yan ìtọ́jú ìṣègùn tí kò la ẹ̀jẹ̀ lọ. Ìyẹn mú kí n kọ ọ̀pọ̀ àpilẹ̀kọ nínú ìwé ìròyìn àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n, kí n sì sọ̀rọ̀ nípàdé àwọn oníṣègùn àtàwọn amòfin lọ́pọ̀ ibi kárí ayé. Síbẹ̀, bó ṣe wà nínú Lúùkù 17:10: ‘Ẹrú tí kò dáa fún ohunkóhun ni mí. Ohun tó yẹ kí n ṣe ni mo ṣe.’