Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ṣé ó yẹ káwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa lo ìkànnì àwọn tó ń wá ọkọ tàbí ìyàwó láti wá ẹni tá a máa fẹ́?

Jèhófà fẹ́ káwọn tọkọtaya láyọ̀, ó sì fẹ́ kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn títí dọjọ́ alẹ́. (Mát. 19:4-6) Tó bá wù ẹ́ láti ṣègbéyàwó, báwo lo ṣe lè rí ọkọ tàbí aya rere? Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá wa, ó sì mọ ohun tá a lè ṣe kí ìgbéyàwó wa lè dùn bí oyin. Torí náà, tó o bá fi àwọn ìlànà rẹ̀ sílò, wàá rí ọkọ tàbí aya tẹ́ ẹ jọ máa bá ara yín kalẹ́. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká wo díẹ̀ lára àwọn ìlànà tó fún wa.

Lákọ̀ọ́kọ́, a gbọ́dọ̀ gbà pé: “Ọkàn ń tanni jẹ ju ohunkóhun lọ, kò sóhun tí kò lè ṣe.” (Jer. 17:9) Táwọn méjì bá bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ra wọn láìtíì mọ ara wọn dáadáa, ọkàn wọn máa tètè fà síra, ìyẹn sì lè mú kí wọ́n ṣe ìpinnu tí kò bọ́gbọ́n mu. Táwọn méjì bá ṣègbéyàwó torí bí nǹkan ṣe rí lára wọn, lọ́pọ̀ ìgbà, irú ìgbéyàwó bẹ́ẹ̀ kì í tọ́jọ́. (Òwe 28:26) Torí náà, táwọn méjì bá ṣẹ̀ṣẹ̀ pàdé ara wọn, kò ní bọ́gbọ́n mu kí wọ́n tètè máa sọ bí nǹkan ṣe rí lára wọn tàbí kí wọ́n ṣèlérí fún ara wọn pé àwọn á fẹ́ra láìtíì mọ ara wọn dáadáa.

Òwe 22:3 sọ pé: “Ọlọ́gbọ́n rí ewu, ó sì fara pa mọ́, àmọ́ aláìmọ̀kan kọrí síbẹ̀, ó sì jìyà rẹ̀.” Ewu wo ló wà níbẹ̀ tá a bá ń wá ẹni tá a máa fẹ́ lórí ìkànnì àwọn tó ń wá ọkọ tàbí aya? Ó ṣeni láàánú pé àwọn kan ti pàdé ẹni tí wọn ò mọ̀ rí lórí ìkànnì, lẹ́yìn tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ra ni wọ́n tó mọ̀ pé ẹni náà ń tan àwọn ni. Bákan náà, àwọn oníjìbìtì máa ń díbọ́n lórí ìkànnì kí wọ́n lè ja àwọn èèyàn lólè. Nígbà míì sì rèé, irú àwọn èèyàn burúkú bẹ́ẹ̀ máa ń sọ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn.

Ẹ jẹ́ ká tún wo ewu míì tó wà níbẹ̀. Àwọn ìkànnì kan tó máa ń bá èèyàn wá ọkọ tàbí ìyàwó máa ń lo ìṣirò láti mọ àwọn tó máa bá ara wọn mu. Àmọ́ kò sí ẹ̀rí tó fi hàn pé irú àwọn tó fẹ́ra wọn lọ́nà yìí máa ń bára wọn kalẹ́. Ẹ gbọ́ ná, ṣé ó máa bọ́gbọ́n mu kó jẹ́ pé ìṣirò orí kọ̀ǹpútà la máa fi pinnu ẹni tá a máa fẹ́? Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ìgbéyàwó kì í ṣọ̀rọ̀ ṣeréṣeré. Ṣé a tiẹ̀ lè fi ìṣirò orí kọ̀ǹpútà wé àwọn ìlànà tó ṣeé gbára lé tó wà nínú Bíbélì?​—Òwe 1:7; 3:5-7.

Òwe 14:15 sọ pé: “Aláìmọ̀kan máa ń gba gbogbo ọ̀rọ̀ gbọ́, àmọ́ aláròjinlẹ̀ máa ń ronú lórí ìgbésẹ̀ kọ̀ọ̀kan.” Kó o tó pinnu pé ẹnì kan lo máa fẹ́, ó yẹ kó o mọ ẹni náà dáadáa. Àmọ́ ṣé ìyẹn máa rọrùn tó bá jẹ́ pé orí ìkànnì àjọlò nìkan lẹ ti ń bára yín sọ̀rọ̀? Kódà, tẹ́ ẹ bá gbé ìsọfúnni nípa ara yín sórí ìkànnì, tẹ́ ẹ sì ń fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ síra yín ní gbogbo ìgbà, ṣé ìyẹn túmọ̀ sí pé ẹ ti mọ ara yín dáadáa? Lẹ́yìn táwọn kan ti yófẹ̀ẹ́, ẹ̀rù bà wọ́n nígbà tí wọ́n rí ẹni tí wọ́n ń bá sọ̀rọ̀ lórí ìkànnì lójúkojú.

Onísáàmù kan sọ pé: “Èmi kì í bá àwọn ẹlẹ́tàn kẹ́gbẹ́, mo sì máa ń yẹra fún àwọn tó ń fi ẹni tí wọ́n jẹ́ pa mọ́.” (Sm. 26:4) Ọ̀pọ̀ ló máa ń parọ́ lórí ìkànnì àjọlò káwọn èèyàn lè rò pé èèyàn gidi ni wọ́n. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ máa ń fi irú ẹni tí wọ́n jẹ́ pa mọ́ tí wọ́n bá ń bá àwọn míì sọ̀rọ̀ lórí ìkànnì. Tẹ́nì kan bá sọ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà lòun, ṣé ó dá ẹ lójú pé ó ti ṣèrìbọmi? Ṣé òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀? Ṣé ó ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà? Ojú wo làwọn ará ìjọ ẹ̀ fi ń wò ó? Ṣé àpẹẹrẹ tó dáa ló jẹ́ fáwọn míì àbí “ẹgbẹ́ búburú” ló jẹ́? (1 Kọ́r. 15:33; 2 Tím. 2:20, 21) Ṣé ó lómìnira tó bá Ìwé Mímọ́ mu láti ṣègbéyàwó? Àwọn ìbéèrè yìí ṣe pàtàkì gan-an. Àmọ́, o ò lè rí ìdáhùn àfi tó o bá béèrè lọ́wọ́ Ẹlẹ́rìí míì tó mọ ẹni náà dáadáa. (Òwe 15:22) Yàtọ̀ síyẹn, kò sí Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀ tó máa fẹ́ fi “àìdọ́gba so pọ̀” pẹ̀lú aláìgbàgbọ́.​—2 Kọ́r. 6:14; 1 Kọ́r. 7:39.

Níbi tá a bọ́rọ̀ dé yìí, a ti rí i pé ó léwu kéèyàn máa wá ẹni tó máa fẹ́ lórí ìkànnì àwọn tó ń wá ọkọ tàbí aya. Àmọ́ àwọn ọ̀nà míì wà tá a lè gbà mọ ẹnì kan dáadáa, ká sì pinnu bóyá ẹni tá a lè fẹ́ ni tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Ibo lo ti lè rí ẹni tó máa jẹ́ ọkọ tàbí aya rere? Láwọn ìgbà tí kò bá sí òfin kónílégbélé, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń láǹfààní láti mọ ara wa tá a bá ríra láwọn ìpàdé ìjọ, àpéjọ àyíká àti agbègbè tàbí láwọn ibòmíì.

Bẹ́ ẹ ṣe túbọ̀ ń lo àkókò pa pọ̀, ẹ̀ẹ́ mọ̀ bóyá ohun kan náà lẹ fẹ́ fi ìgbésí ayé yín ṣe àti bóyá ìwà yín bára mu

Nígbà tí kò bá ṣeé ṣe láti pàdé pọ̀, irú bíi lásìkò àrùn Corona, a máa ń ṣèpàdé látorí ẹ̀rọ, a sì lè lo àǹfààní yẹn láti mọ àwọn Ẹlẹ́rìí míì tí ò tíì ṣègbéyàwó. Àá lè rí bí wọ́n ṣe ń bójú tó iṣẹ́ tí wọ́n bá yàn fún wọn, àá sì tún rí bí òtítọ́ ṣe jinlẹ̀ tó nínú wọn tí wọ́n bá ń dáhùn. (1 Tím. 6:11, 12) Ẹ tún lè bá ara yín sọ̀rọ̀ tí wọ́n bá pín yín sí àwọn àwùjọ kéékèéké lẹ́yìn ìpàdé. Yàtọ̀ síyẹn, táwọn ará bá ṣètò ìkórajọ kan lórí ẹ̀rọ, o lè kíyè sí bí ẹnì kan tó o nífẹ̀ẹ́ sí ṣe ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ àti ìṣesí rẹ̀, ìyẹn á jẹ́ kó o lè mọ irú ẹni tó jẹ́ gan-an. (1 Pét. 3:4) Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́ tẹ́ ẹ sì ń mọ ara yín sí i, ẹ̀ẹ́ mọ̀ bóyá ohun kan náà lẹ fẹ́ fi ìgbésí ayé yín ṣe àti bóyá ìwà yín bára mu.

Tí àwọn tó ń wá ọkọ tàbí aya bá ń fi ìlànà Bíbélì sílò, wọ́n á rí ẹni tí wọ́n á jọ bára wọn kalẹ́. Ọ̀rọ̀ Bíbélì yìí á sì ṣẹ sí wọn lára tó sọ pé: “Ẹni tó bá rí aya [tàbí ọkọ] rere fẹ́ ti rí ohun rere, ó sì rí ojú rere Jèhófà.”​—Òwe 18:22.