Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 28

Ẹ Má Ṣe Máa Bá Ara Yín Díje, Àlàáfíà Ni Kí Ẹ Máa Wá

Ẹ Má Ṣe Máa Bá Ara Yín Díje, Àlàáfíà Ni Kí Ẹ Máa Wá

“Ẹ má ṣe jẹ́ kí a di agbéraga, kí a má ṣe máa bá ara wa díje, kí a má sì máa jowú ara wa.”​—GÁL. 5:26.

ORIN 101 À Ń Ṣiṣẹ́ Níṣọ̀kan

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1. Kí ni ẹ̀mí ìdíje máa ń jẹ́ káwọn èèyàn ṣe, kí nìyẹn sì lè yọrí sí?

LÓNÌÍ, ọ̀pọ̀ èèyàn ló fẹ́ yọrí ọlá ju àwọn míì lọ, kò sì sí ohun tí wọn ò lè ṣe torí pé tara wọn nìkan ni wọ́n mọ̀. Oníṣòwò kan lè máa dá ọgbọ́nkọ́gbọ́n kí ilé iṣẹ́ ẹ̀ lè gbayì ju tàwọn míì lọ. Agbábọ́ọ̀lù kan lè mọ̀ọ́mọ̀ ṣe agbábọ́ọ̀lù míì tó wà nínú ẹgbẹ́ tí wọ́n ń bá díje léṣe kí ẹgbẹ́ tiẹ̀ lè borí. Akẹ́kọ̀ọ́ kan lè jíwèé wò kó lè yege ìdánwò láti wọ yunifásítì kan tó lóókọ. Àwa Kristẹni mọ̀ pé irú àwọn ìwà bẹ́ẹ̀ ò dáa torí pé wọ́n jẹ́ apá kan “iṣẹ́ ti ara.” (Gál. 5:19-21) Àmọ́, ṣé ó ṣeé ṣe káwọn kan bẹ̀rẹ̀ sí í bá ara wọn díje nínú ìjọ láìfura? Ìbéèrè yìí ṣe pàtàkì torí pé irú ìwà bẹ́ẹ̀ lè da ìjọ rú, kó sì mú káwọn ará kẹ̀yìn síra wọn.

2. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

2 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò àwọn ìwà tí ò dáa tó lè mú ká bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn ará wa díje. Àá tún rí àpẹẹrẹ àwọn olóòótọ́ tó wà nínú Bíbélì tí wọ́n fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ yìí. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká jíròrò bá a ṣe lè yẹ ara wa wò ká lè mọ̀ bóyá a lẹ́mìí ìbánidíje.

YẸ ARA Ẹ WÒ

3. Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ ká bi ara wa?

3 Ó yẹ ká máa yẹ ara wa wò látìgbàdégbà. A lè bi ara wa pé: ‘Ṣé mo máa ń fi ara mi wé àwọn míì, ṣé mo sì máa ń ronú pé mo dáa jù wọ́n lọ? Ṣé torí káwọn míì lè gbà pé èmi ni mo dáa jù ni mo ṣe ń ṣe gbogbo ohun tí mò ń ṣe nínú ìjọ àbí mò ń ṣe bíi pé mo sàn ju arákùnrin kan tàbí arábìnrin kan lọ? Àbí torí kí n lè múnú Jèhófà dùn ni mo ṣe ń ṣiṣẹ́ kára?’ Kí nìdí tó fi yẹ ká bi ara wa láwọn ìbéèrè yìí? Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ.

4. Gálátíà 6:3, 4 ṣe sọ, kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa fi ara wa wé àwọn míì?

4 Bíbélì gbà wá níyànjú pé ká má ṣe máa fi ara wa wé àwọn míì. (Ka Gálátíà 6:3, 4.) Kí nìdí? Ìdí kan ni pé tá a bá ronú pé a sàn ju arákùnrin kan lọ, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í gbéra ga. Ìdí míì ni pé tá a bá ń fi ara wa wé àwọn míì, tá a sì ronú pé wọ́n sàn jù wá lọ, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í rẹ̀wẹ̀sì. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn ò ní fi hàn pé a láròjinlẹ̀. (Róòmù 12:3) Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Katerina * tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Greece sọ pé: “Mo máa ń fi ara mi wé àwọn tí mo rò pé wọ́n rẹwà jù mí lọ, tí wọ́n já fáfá lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, tí wọ́n sì tètè máa ń lọ́rẹ̀ẹ́. Torí náà mo máa ń ronú pé mi ò já mọ́ nǹkan kan.” Ó yẹ ká rántí pé kì í ṣe torí pé a rẹwà, a mọ̀rọ̀ sọ tàbí torí pé àwọn èèyàn mọ̀ wá gan-an ni Jèhófà fi fà wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀. Dípò bẹ́ẹ̀, ó fà wá torí ó mọ̀ pé a nífẹ̀ẹ́ òun, a sì ṣe tán láti tẹ́tí sí Jésù Ọmọ òun.​—Jòh. 6:44; 1 Kọ́r. 1:26-31.

5. Kí lo rí kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí arákùnrin kan tó ń jẹ́ Hyun?

5 Ìbéèrè míì tó yẹ ká bi ara wa ni pé, ‘Ṣé ẹni tó máa ń wá àlàáfíà làwọn èèyàn mọ̀ mí sí àbí gbogbo ìgbà ni mo máa ń níṣòro pẹ̀lú àwọn míì?’ Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Arákùnrin Hyun tó ń gbé lórílẹ̀-èdè South Korea. Ìgbà kan wà tó ń fojú burúkú wo àwọn alàgbà míì torí àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tí wọ́n ní. Ó sọ pé, “Mo máa ń ṣàríwísí àwọn arákùnrin yìí, mo sì máa ń ta ko ohunkóhun tí wọ́n bá sọ.” Kí nìyẹn yọrí sí? Ó sọ pé, “Ìwà tí mò ń hù yẹn mú káwọn ará kẹ̀yìn síra wọn nínú ìjọ.” Nígbà tó yá, àwọn kan lára àwọn ọ̀rẹ́ arákùnrin yìí bá a sọ̀rọ̀, wọ́n sì tún èrò ẹ̀ ṣe. Arákùnrin Hyun ṣe àyípadà tó yẹ, ìyẹn mú kó dẹni tó ṣeé sún mọ́, ó sì ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn alàgbà yòókù. Tá a bá yẹ ara wa wò, tá a sì rí i pé a lẹ́mìí ìbánidíje dípò ẹ̀mí àlàáfíà, a gbọ́dọ̀ ṣàtúnṣe láìjáfara.

MÁ GBÉRA GA MÁ SÌ JOWÚ

6. Àwọn ìwà wo ni Gálátíà 5:26 sọ pé ó lè mú ká máa ronú pé a sàn ju àwọn míì lọ?

6 Ka Gálátíà 5:26. Àwọn ìwà wo ló lè mú ká lẹ́mìí ìbánidíje tàbí tó lè mú ká máa ronú pé a sàn ju àwọn míì lọ? Àkọ́kọ́ ni ìgbéraga. Ẹni tó ń gbéra ga máa ń ka ara ẹ̀ sí ju bó ṣe yẹ lọ, tara ẹ̀ nìkan ló sì máa ń mọ̀. Ìkejì ni owú. Ẹni tó bá ń jowú tàbí tó ń ṣe ìlara máa ń fẹ́ ní ohun táwọn míì ní. Yàtọ̀ síyẹn, ó tún máa ń fẹ́ kí ohun táwọn míì ní bọ́ mọ́ wọn lọ́wọ́. Ó ṣe kedere pé irú ẹni bẹ́ẹ̀ ò nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì ẹ̀, ṣe ló kórìíra ẹ̀. Torí náà, ó yẹ ká yẹra fún àwọn ìwà yìí bí ẹni sá fún wèrèpè tàbí àrùn tó ń ranni!

7. Àpèjúwe wo ló lè mú ká lóye bí ìgbéraga àti owú ṣe léwu tó?

7 A lè fi ìgbéraga àti owú wé ikán tó ń jẹ igi. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé igi náà lè gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀, kó sì dùn ún wò lójú, bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, tí wọn ò bá ṣe nǹkan kan sí igi náà, ó máa wó lulẹ̀ ni. Lọ́nà kan náà, ẹnì kan lè máa sin Jèhófà kó sì dà bí ẹni tẹ̀mí. Àmọ́ tó bá ń gbéra ga tàbí tó ń jowú, kò ní pẹ́ tó fi máa ṣubú. (Òwe 16:18) Kó tó mọ̀, ó máa fi Jèhófà sílẹ̀ á sì ṣàkóbá fún ara ẹ̀ àtàwọn míì. Bọ́rọ̀ ṣe rí yìí, kí la lè ṣe tá ò fi ní máa jowú tàbí ká máa gbéra ga?

8. Kí la lè ṣe tí ìgbéraga ò fi ní wọ̀ wá lẹ́wù?

8 Ìgbéraga ò ní wọ̀ wá lẹ́wù tá a bá fi ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù fún àwọn ará Fílípì sílò. Ó ní: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí ìbínú tàbí ìgbéraga mú yín ṣe ohunkóhun, àmọ́ ẹ jẹ́ kí ìrẹ̀lẹ̀ máa mú kí ẹ gbà pé àwọn míì sàn jù yín lọ.” (Fílí. 2:3) Tá a bá gbà pé àwọn míì sàn jù wá lọ, a ò ní máa fi ara wa wé àwọn míì tí wọ́n ní ẹ̀bùn táwa ò ní. Dípò bẹ́ẹ̀, ṣe làá mọyì wọn pàápàá tí wọ́n bá ń lo ẹ̀bùn wọn lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Lọ́wọ́ kejì, táwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó ní ẹ̀bùn yìí bá ń fi ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù sílò, àwọn náà á kíyè sí ẹ̀bùn tá a ní, wọ́n á sì mọyì wa. Nípa bẹ́ẹ̀, àlàáfíà, ìfẹ́ àti ìṣọ̀kan máa jọba nínú ìjọ.

9. Kí la lè ṣe tá ò fi ní máa jowú tàbí ṣe ìlara?

9 Tá ò bá fẹ́ máa jowú tàbí ṣe ìlara, ó ṣe pàtàkì ká mọ̀wọ̀n ara wa. Tá a bá mọ̀wọ̀n ara wa, a ò ní máa ṣe bíi pé àwa la gbọ́n jù tàbí pé a mọ nǹkan ṣe ju àwọn míì lọ. Dípò bẹ́ẹ̀, àá máa wá bá a ṣe lè kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn míì. Bí àpẹẹrẹ, ká ní arákùnrin kan mọ bí wọ́n ṣe ń sọ àsọyé tó máa ń wọni lọ́kàn, a lè bi í nípa bó ṣe máa ń múra sílẹ̀. Tí arábìnrin kan bá mọ oúnjẹ sè, a lè ní kó kọ́ wa káwa náà lè sunwọ̀n sí i. Tó bá sì jẹ́ pé ọ̀dọ́kùnrin kan máa ń tijú, tí kì í sì í yá mọ́ọ̀yàn, ó lè ní kẹ́ni tí ara ẹ̀ yá mọ́ọ̀yàn ran òun lọ́wọ́ kóun náà lè lọ́rẹ̀ẹ́. Tá a bá fi àwọn ìmọ̀ràn yìí sílò, a ò ní máa jowú. Kódà, ṣe làá máa sunwọ̀n sí i.

KẸ́KỌ̀Ọ́ LÁTINÚ ÀPẸẸRẸ ÀWỌN TÓ WÀ NÍNÚ BÍBÉLÌ

Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tí Gídíónì ní ló mú kó wá àlàáfíà pẹ̀lú àwọn ọmọ Éfúrémù (Wo ìpínrọ̀ 10 sí 12)

10. Ìṣòro wo ni Gídíónì kojú?

10 Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ láàárín Gídíónì tó wá látinú ẹ̀yà Mánásè àtàwọn ọkùnrin ẹ̀yà Éfúrémù. Jèhófà mú kí Gídíónì àtàwọn ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) ọmọ ogun rẹ̀ ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá lọ́nà tó kàmàmà, ìyẹn sì lè mú kí wọ́n gbéra ga. Nígbà táwọn ọkùnrin Éfúrémù lọ bá Gídíónì, dípò kí wọ́n gbóríyìn fún un, ṣe ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í bá a fa wàhálà. Kí nìdí? Wọ́n ronú pé ó yẹ kí Gídíónì kàn sí àwọn kó tó lọ bá àwọn ọ̀tá Jèhófà jà. Bí ẹ̀yà wọn ṣe máa gbayì ló jẹ wọ́n lógún dípò kí wọ́n máa yọ̀ pé Jèhófà lo Gídíónì láti gba àwọn èèyàn ẹ̀ là, tó sì gbé orúkọ Jèhófà ga.​—Oníd. 8:1.

11. Èsì wo ni Gídíónì fún àwọn ọkùnrin Éfúrémù?

11 Gídíónì fìrẹ̀lẹ̀ dá wọn lóhùn, ó sọ pé: “Ṣé ohun tí mo ṣe wá tó nǹkan kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ tiyín?” Ó wá rán wọn létí bí Jèhófà ṣe lò wọ́n láti gbé àwọn nǹkan ribiribi ṣe. Ohun tí Gídíónì sọ yìí mú kí “ara wọn balẹ̀.” (Oníd. 8:2, 3) Dípò kí Gídíónì bínú, ó ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe kí àlàáfíà lè wà láàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run.

12. Kí la rí kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn ọkùnrin Éfúrémù àti Gídíónì?

12 Kí la rí kọ́ látinú ìtàn yìí? Látinú ohun táwọn ọmọ Éfúrémù ṣe, a kẹ́kọ̀ọ́ pé bá a ṣe máa gbé orúkọ Jèhófà ga ló yẹ kó jẹ wá lógún, kì í ṣe bá a ṣe máa gbayì lójú àwọn míì. Àwọn olórí ìdílé àtàwọn alàgbà lè kẹ́kọ̀ọ́ lára Gídíónì. Tẹ́nì kan bá bínú sí wa, dípò tá a fi máa bínú, ṣe ló yẹ ká gbìyànjú láti lóye ẹni yẹn. Kódà, a lè kíyè sí àwọn nǹkan dáadáa tónítọ̀hún ṣe, ká sì gbóríyìn fún un. Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ló máa jẹ́ ká lè ṣe bẹ́ẹ̀, pàápàá tó bá ṣe kedere pé ohun tó sọ kò tọ̀nà. Ó ṣe tán, bí àlàáfíà ṣe máa jọba ṣe pàtàkì ju iyì ara ẹni lọ.

Ọkàn Hánà balẹ̀ torí ó gbà pé Jèhófà máa dá sí ọ̀rọ̀ òun lásìkò tó yẹ (Wo ìpínrọ̀ 13 sí 14)

13. Ìṣòro wo ni Hánà kojú, kí ló sì ṣe nípa ẹ̀?

13 Ẹ jẹ́ ká tún wo àpẹẹrẹ Hánà. Ẹlikénà tó jẹ́ ọmọ Léfì lọkọ ẹ̀, ó sì nífẹ̀ẹ́ Hánà gan-an. Àmọ́ Ẹlikénà ní ìyàwó míì tó ń jẹ́ Pẹ̀nínà. Ẹlikénà nífẹ̀ẹ́ Hánà ju Pẹ̀nínà lọ, bó ti wù kó rí “Pẹ̀nínà bí àwọn ọmọ, ṣùgbọ́n Hánà kò bímọ.” Ìyẹn mú kí Pẹ̀nínà máa “pẹ̀gàn rẹ̀ ṣáá kó lè múnú bí i.” Kí wá ni Hánà ṣe? Ọ̀rọ̀ náà dùn ún. Kódà, Bíbélì sọ pé “ńṣe ló máa ń sunkún, tí kò sì ní jẹun.” (1 Sám. 1:2, 6, 7) Síbẹ̀, kò sí àkọsílẹ̀ kankan tó fi hàn pé Hánà wá bó ṣe máa gbẹ̀san lára Pẹ̀nínà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló sọ gbogbo bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ̀ fún Jèhófà, ó sì gbà pé Jèhófà máa dá sọ́rọ̀ náà lásìkò tó yẹ. Ṣéyẹn wá mú kí Pẹ̀nínà yíwà pa dà? Bíbélì ò sọ. Àmọ́ a mọ̀ pé ara tu Hánà lẹ́yìn ìgbà yẹn, ọkàn ẹ̀ sì balẹ̀. Kódà Bíbélì sọ pé ‘kò kárí sọ mọ́.’​—1 Sám. 1:10, 18.

14. Kí la rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ Hánà?

14 Kí la lè kọ́ látinú àpẹẹrẹ Hánà? Tẹ́nì kan bá ń ṣe bíi pé òun sàn jù wá lọ tàbí tó ń fojú kéré wa, ṣe ni ká fọ̀rọ̀ náà sílẹ̀ dípò ká máa bá onítọ̀hún díje. Torí náà, kò ní dáa ká gbẹ̀san tàbí ká fi ibi san ibi. (Róòmù 12:17-21) Kàkà bẹ́ẹ̀, á dáa ká wá àlàáfíà pẹ̀lú ẹni náà. Kódà tẹ́ni náà ò bá yíwà pa dà, ọkàn tiwa máa balẹ̀, ara á sì tù wá.

Àpólò àti Pọ́ọ̀lù ò jowú ara wọn torí wọ́n gbà pé Jèhófà ló ń mú kí iṣẹ́ náà tẹ̀ síwájú (Wo ìpínrọ̀ 15 sí 18)

15. Kí ni Àpólò àti Pọ́ọ̀lù fi jọra?

15 Àpẹẹrẹ tó kẹ́yìn tá a máa gbé yẹ̀ wò ni ti ọmọ ẹ̀yìn náà Àpólò àti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Àwọn méjèèjì mọ Ìwé Mímọ́ dunjú, wọ́n mọ̀ọ̀yàn kọ́ gan-an, àwọn ará sì mọ̀ wọ́n dáadáa. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn méjèèjì ti ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ láti di ọmọ ẹ̀yìn, síbẹ̀ wọn ò jowú ara wọn.

16. Irú èèyàn wo ni Àpólò?

16 “Ọmọ ìbílẹ̀ Alẹkisáńdíríà” ni Àpólò, ibẹ̀ sì wà lára àwọn ìlú táwọn ọ̀mọ̀wé pọ̀ sí ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní. Sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ ni, ó sì “mọ Ìwé Mímọ́ dunjú.” (Ìṣe 18:24) Nígbà tí Àpólò wà ní Kọ́ríńtì, àwọn kan nínú ìjọ jẹ́ kó hàn pé àwọn gba tiẹ̀ ju ti àwọn arákùnrin míì lọ títí kan Pọ́ọ̀lù. (1 Kọ́r. 1:12, 13) Ṣé Àpólò ló mú kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀? Kò dájú pé ó lè ṣerú ẹ̀. Kódà, lẹ́yìn tí Àpólò fi Kọ́ríńtì sílẹ̀, Pọ́ọ̀lù tún rọ̀ ọ́ pé kó pa dà síbẹ̀. (1 Kọ́r. 16:12) Pọ́ọ̀lù ò ní ṣe bẹ́ẹ̀ tó bá ronú pé Àpólò ló dá ìyapa sílẹ̀ nínú ìjọ. Ó dájú pé ọ̀nà tó dáa ni Àpólò gbà lo ẹ̀bùn tó ní, ó wàásù ìhìn rere, ó sì fún àwọn ará lókun. Yàtọ̀ síyẹn, onírẹ̀lẹ̀ èèyàn ni. Bí àpẹẹrẹ, kò sí àkọsílẹ̀ kankan tó fi hàn pé ó bínú nígbà tí Ákúílà àti Pírísílà “ṣàlàyé ọ̀nà Ọlọ́run fún un lọ́nà tó túbọ̀ péye.”​—Ìṣe 18:24-28.

17. Kí ni Pọ́ọ̀lù ṣe kí àlàáfíà lè jọba nínú ìjọ?

17 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mọ àwọn iṣẹ́ rere tí Àpólò ṣe, àmọ́ kò jowú ẹ̀. Ó hàn nínú ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù fún àwọn ará Kọ́ríńtì pé ó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, kò sì jọ ara ẹ̀ lójú. Kò jẹ́ kí ohun táwọn ará kan ń sọ pé “èmi jẹ́ ti Pọ́ọ̀lù” kó sí òun lórí. Kàkà bẹ́ẹ̀, Jèhófà àti Jésù Kristi ló fìyìn fún.​—1 Kọ́r. 3:3-6.

18. Kí la rí kọ́ lára Àpólò àti Pọ́ọ̀lù bó ṣe wà nínú 1 Kọ́ríńtì 4:6, 7?

18 Kí la kọ́ látinú àpẹẹrẹ Àpólò àti Pọ́ọ̀lù? A lè máa ṣiṣẹ́ kára lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, ká sì ran ọ̀pọ̀ lọ́wọ́ láti ṣèrìbọmi. Àmọ́, a gbọ́dọ̀ fi sọ́kàn pé àṣeyọrí èyíkéyìí tá a bá ṣe, Jèhófà ló mú kó ṣeé ṣe. Ẹ̀kọ́ míì tún wà tá a lè kọ́ lára Àpólò àti Pọ́ọ̀lù. Ẹ̀kọ́ náà ni pé bí ojúṣe tá a ní nínú ìjọ bá ṣe pọ̀ tó, bẹ́ẹ̀ ló ṣe yẹ ká lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, ká sì ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti mú kí àlàáfíà wà nínú ìjọ. Ẹ ò rí bó ṣe máa dáa tó táwọn tá a yàn sípò bá ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti mú kí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan wà nínú ìjọ. Wọ́n sì lè ṣe bẹ́ẹ̀ tí wọ́n bá ń gbé ìmọ̀ràn wọn ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Yàtọ̀ síyẹn, wọn kì í wá bí wọ́n ṣe máa gbayì lójú àwọn ará, kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe ni wọ́n máa ń rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù.​—Ka 1 Kọ́ríńtì 4:6, 7.

19. Kí ló yẹ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ṣe? (Tún wo àpótí náà, “ Ẹ Má Ṣe Máa Bá Ara Yín Díje.”)

19 Gbogbo wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ni Jèhófà fún lẹ́bùn. A sì lè lò ó láti “ṣe ìránṣẹ́ fún ara [wa].” (1 Pét. 4:10) A lè ronú pé ojúṣe tá a ní nínú ìjọ ò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì. Bó ti wù kí ojúṣe tẹ́nì kọ̀ọ̀kan wa ní kéré tó, gbogbo wa la lè ṣe ipa tiwa láti mú kí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan wà nínú ìjọ. Ó ṣe tán, àgbájọ ọwọ́ la fi ń sọ̀yà. Torí náà, ẹ jẹ́ kí gbogbo wa ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti yẹra fún ẹ̀mí ìbánidíje, ká sì pinnu pé àá sa ipá wa láti mú kí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan gbilẹ̀ nínú ìjọ.​—Éfé. 4:3.

ORIN 80 ‘Tọ́ Ọ Wò, Kó O sì Rí I Pé Ẹni Rere Ni Jèhófà’

^ ìpínrọ̀ 5 Wọ́n máa ń sọ pé bí ògiri ò bá lanu, aláǹgbá kò lè ráyè wọbẹ̀. Lọ́nà kan náà, táwọn kan bá ń bá ara wọn díje nínú ìjọ, ìyẹn máa mú káwọn ará kẹ̀yìn síra wọn. Tí àwọn ará bá sì kẹ̀yìn síra wọn, kò ní sí àlàáfíà nínú ìjọ, ẹ̀mí Ọlọ́run ò sì ní ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò ìdí tí kò fi yẹ ká máa bá ara wa díje, àá sì tún rí bá a ṣe lè jẹ́ kí ìjọ wà níṣọ̀kan.

^ ìpínrọ̀ 4 A ti yí orúkọ rẹ̀ pa dà.