Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 30

Bí Àsọtẹ́lẹ̀ Kan Tó Ti Pẹ́ Ṣe Kàn Ẹ́

Bí Àsọtẹ́lẹ̀ Kan Tó Ti Pẹ́ Ṣe Kàn Ẹ́

“Màá mú kí ìwọ àti obìnrin náà di ọ̀tá ara yín.”​—JẸ́N. 3:15.

ORIN 15 Ẹ Yin Àkọ́bí Jèhófà!

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1. Kí ni Jèhófà ṣe kété lẹ́yìn tí Ádámù àti Éfà dẹ́ṣẹ̀? (Jẹ́nẹ́sísì 3:15)

 KÒ PẸ́ lẹ́yìn tí Ádámù àti Éfà dẹ́ṣẹ̀, Jèhófà sọ àsọtẹ́lẹ̀ kan tó máa jẹ́ káwọn ọmọ wọn rí i pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa. Àsọtẹ́lẹ̀ náà wà nínú Jẹ́nẹ́sísì 3:15.​—Kà á.

2. Kí nìdí tí àsọtẹ́lẹ̀ náà fi ṣàrà ọ̀tọ̀?

2 Inú ìwé àkọ́kọ́ nínú Bíbélì ni àsọtẹ́lẹ̀ náà wà. Àmọ́ gbogbo àwọn ìwé Bíbélì yòókù ló mẹ́nu kan àsọtẹ́lẹ̀ yìí. Bí okùn ṣe máa ń so igi pọ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Jẹ́nẹ́sísì 3:15 ṣe so gbogbo àwọn ìwé Bíbélì yòókù pọ̀, wọ́n sì dá lórí ọ̀rọ̀ pàtàkì kan. Ọ̀rọ̀ pàtàkì náà ni pé Jèhófà máa rán Ẹnì kan tó máa gba aráyé, tó sì máa pa Èṣù àti àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ run. * Ẹ ò rí i pé ìtura máa dé bá gbogbo àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà!

3. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

3 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa dáhùn àwọn ìbéèrè tó dá lórí àsọtẹ́lẹ̀ inú Jẹ́nẹ́sísì 3:15. Àwọn ìbéèrè náà ni: Àwọn wo ni àsọtẹ́lẹ̀ náà sọ nípa wọn? Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣe ṣẹ? Báwo la sì ṣe ń jàǹfààní àsọtẹ́lẹ̀ náà?

ÀWỌN WO NI ÀSỌTẸ́LẸ̀ NÁÀ SỌ NÍPA WỌN?

4. Ta ni “ejò náà,” báwo la sì ṣe mọ̀?

4 Àwọn tí àsọtẹ́lẹ̀ inú Jẹ́nẹ́sísì 3:14, 15 sọ nípa wọn ni, “ejò” kan, “ọmọ” ejò náà, “obìnrin” kan àti “ọmọ” obìnrin náà. Bíbélì jẹ́ ká mọ ohun tí wọ́n ṣàpẹẹrẹ. * Ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa “ejò náà.” Tó bá jẹ́ pé ejò gidi ni ejò náà, ó dájú pé ohun tí Jèhófà sọ ní ọgbà Édẹ́nì kò ní yé e. Torí náà, ẹni tí Ọlọ́run dá lẹ́jọ́ yẹn ní láti jẹ́ ẹ̀dá kan tó gbọ́n. Ta wá ni ejò náà? Ìfihàn 12:9 jẹ́ ká mọ ẹni tí ejò náà jẹ́. Ó sọ pé “ejò àtijọ́ náà” ni Sátánì Èṣù. Àmọ́ àwọn wo ni ọmọ ejò náà?

EJÒ NÁÀ

Sátánì Èṣù ni ejò náà. Ìwé Ìfihàn 12:9 pè é ní “ejò àtijọ́” (Wo ìpínrọ̀ 4)

5. Àwọn wo ni ọmọ ejò náà?

5 Tí Bíbélì bá lo ọ̀rọ̀ náà “ọmọ,” ó túmọ̀ sí àwọn tó ń ronú, tí wọ́n sì ń hùwà bí ẹnì kan tí wọ́n lè pè ní bàbá wọn. Torí náà, ọmọ ejò náà ni àwọn áńgẹ́lì àtàwọn èèyàn tí wọ́n ń hùwà bíi Sátánì, tí wọ́n sì ń ta ko Jèhófà Ọlọ́run àtàwọn èèyàn ẹ̀. Àwọn áńgẹ́lì tí wọ́n fi iṣẹ́ wọn sílẹ̀ lọ́run nígbà ayé Nóà wà lára wọn. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn èèyàn burúkú tí wọ́n ń hùwà bí Èṣù bàbá wọn wà lára wọn.​—Jẹ́n. 6:1, 2; Jòh. 8:44; 1 Jòh. 5:19; Júùdù 6.

ỌMỌ EJÒ NÁÀ

Àwọn áńgẹ́lì burúkú àtàwọn èèyàn tí wọ́n ń ta ko Jèhófà Ọlọ́run àtàwọn èèyàn Rẹ̀ (Wo ìpínrọ̀ 5)

6. Kí nìdí tá a fi sọ pé “obìnrin náà” kì í ṣe Éfà?

6 Ẹni tọ́rọ̀ kàn ni “obìnrin náà.” Ta ni obìnrin yìí? Kò lè jẹ́ Éfà. Kí nìdí? Ẹ jẹ́ ká wo ìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀. Àsọtẹ́lẹ̀ náà sọ pé ọmọ obìnrin náà máa “fọ́” orí ejò náà. Bá a ṣe sọ tẹ́lẹ̀, Sátánì ni ejò yẹn, kò sì sí èèyàn aláìpé tó jẹ́ ọmọ Éfà tó lè fọ́ orí Èṣù. Ta lẹni tó máa wá pa Èṣù run?

7.Ìfihàn 12:1, 2, 5, 10 ṣe sọ, ta ni obìnrin tí Jẹ́nẹ́sísì 3:15 sọ nípa ẹ̀?

7 Ìwé Ìfihàn jẹ́ ká mọ obìnrin tí Jẹ́nẹ́sísì 3:15 sọ nípa ẹ̀. (Ka Ìfihàn 12:1, 2, 5, 10.) Obìnrin yìí kì í ṣe èèyàn! Òṣùpá wà ní ẹsẹ̀ rẹ̀, adé oníràwọ̀ méjìlá (12) sì wà ní orí rẹ̀. Ó bí ọmọ kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ gan-an, Ìjọba Ọlọ́run sì ni ọmọ náà. Ọ̀run ni Ìjọba náà wà, torí náà ọ̀run ni obìnrin náà gbọ́dọ̀ wà. Obìnrin náà ṣàpẹẹrẹ apá ti ọ̀run lára ètò Jèhófà, ìyẹn àwọn áńgẹ́lì olóòótọ́.​—Gál. 4:26.

OBÌNRIN NÁÀ

Apá ti ọ̀run lára ètò Jèhófà, ìyẹn àwọn áńgẹ́lì olóòótọ́ (Wo ìpínrọ̀ 7)

8. Ta lẹni àkọ́kọ́ nínú ọmọ obìnrin náà, ìgbà wo ló sì di ọmọ ẹ̀? (Jẹ́nẹ́sísì 22:15-18)

8 Bíbélì jẹ́ ká mọ ẹni àkọ́kọ́ nínú ọmọ obìnrin náà. Ó sọ pé ọmọ náà máa jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù. (Ka Jẹ́nẹ́sísì 22:15-18.) Bí àsọtẹ́lẹ̀ náà sì ṣe sọ, bẹ́ẹ̀ gan-an ló rí torí Jésù jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù. (Lúùkù 3:23, 34) Àmọ́, ọmọ náà gbọ́dọ̀ lágbára ju èèyàn lọ torí òun ló máa pa Sátánì Èṣù run pátápátá. Torí náà, nígbà tí Jésù fẹ́rẹ̀ẹ́ pé ẹni ọgbọ̀n (30) ọdún, Ọlọ́run fẹ̀mí yàn án. Ìgbà tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn án ló di ẹni àkọ́kọ́ nínú ọmọ obìnrin náà. (Gál. 3:16) Lẹ́yìn tí Jésù kú tó sì jíǹde, Ọlọ́run fi “ògo àti ọlá dé e ládé,” ó sì fún un ní “gbogbo àṣẹ ní ọ̀run àti ayé.” Yàtọ̀ síyẹn, ó fún un lágbára láti “fọ́ àwọn iṣẹ́ Èṣù túútúú.”​—Héb. 2:7; Mát. 28:18; 1 Jòh. 3:8.

ỌMỌ OBÌNRIN NÁÀ

Jésù Kristi àtàwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) tó máa bá a ṣàkóso (Wo ìpínrọ̀ 8-9)

9-10. (a) Àwọn wo ló tún jẹ́ ọmọ obìnrin náà, ìgbà wo ni wọ́n sì di ọmọ rẹ̀? (b) Kí la máa sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ báyìí?

9 Yàtọ̀ sí Jésù, àwọn míì wà lára ọmọ obìnrin náà. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ ẹni tí wọ́n jẹ́ nígbà tó ń bá àwọn Júù àtàwọn Kèfèrí tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró sọ̀rọ̀, ó ní: “Bí ẹ bá jẹ́ ti Kristi, ẹ jẹ́ ọmọ Ábúráhámù lóòótọ́, ajogún nípasẹ̀ ìlérí.” (Gál. 3:28, 29) Tí Jèhófà bá fẹ̀mí yan Kristẹni kan, ẹni náà ti di ara ọmọ obìnrin náà nìyẹn. Torí náà, Jésù Kristi àtàwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) tó máa bá a ṣàkóso ni ọmọ obìnrin náà. (Ìfi. 14:1) Gbogbo wọn ló sì fìwà jọ Jèhófà Bàbá wọn.

10 Ní báyìí tá a ti mọ àwọn tí àsọtẹ́lẹ̀ inú Jẹ́nẹ́sísì 3:15 sọ nípa wọn, ẹ jẹ́ ká wá wo bí Jèhófà ṣe ń jẹ́ kí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ náà máa ṣẹ tẹ̀ lé ara wọn àti bí àwa náà ṣe ń jàǹfààní àsọtẹ́lẹ̀ náà.

BÁWO NI ÀSỌTẸ́LẸ̀ NÁÀ ṢE Ń ṢẸ?

11. Bí àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣe sọ, báwo ni Sátánì ṣe ṣe ọmọ obìnrin náà léṣe “ní gìgísẹ̀”?

11 Bí àsọtẹ́lẹ̀ tó wà ní Jẹ́nẹ́sísì 3:15 ṣe sọ, ejò náà máa ṣe ọmọ obìnrin náà léṣe “ní gìgísẹ̀.” Àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣẹ nígbà tí Sátánì mú kí àwọn Júù àtàwọn ará Róòmù pa Ọmọ Ọlọ́run. (Lúùkù 23:13, 20-24) Téèyàn bá ṣèṣe lẹ́sẹ̀, ó lè má jẹ́ kí ẹni náà rìn dáadáa fún ọjọ́ mélòó kan. Lọ́nà kan náà, Jésù ò lè ṣe nǹkan kan ní gbogbo ọjọ́ mẹ́ta tó fi wà nínú ibojì.​—Mát. 16:21.

12. Báwo ni Jésù ṣe máa fọ́ orí ejò náà, ìgbà wo sì ni?

12 Kí àsọtẹ́lẹ̀ tó wà ní Jẹ́nẹ́sísì 3:15 tó lè ṣẹ, Jésù gbọ́dọ̀ jíǹde. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé bí àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣe sọ, ọmọ náà máa fọ́ orí ejò yẹn. Torí náà, Jésù gbọ́dọ̀ jíǹde. Ó sì jíǹde lóòótọ́! Nígbà tó di ọjọ́ kẹta tí Jésù kú, Jèhófà jí i dìde, ó sì di ẹni ẹ̀mí tí ò lè kú mọ́. Tó bá tó àkókò lójú Ọlọ́run, ó máa lo Jésù láti pa Sátánì run ráúráú. (Héb. 2:14) Kristi àtàwọn tó máa bá a ṣàkóso máa pa gbogbo àwọn ọ̀tá Ọlọ́run run ráúráú, ìyẹn ọmọ ejò náà.​—Ìfi. 17:14; 20:4, 10. *

BÁWO LA ṢE Ń JÀǸFÀÀNÍ ÀSỌTẸ́LẸ̀ NÁÀ?

13. Báwo la ṣe ń jàǹfààní nínú bí àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣe ń ṣẹ?

13 Tó o bá jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó o sì ti ya ara ẹ sí mímọ́, ìwọ náà ń jàǹfààní àsọtẹ́lẹ̀ tó ń ṣẹ yìí. Nígbà tí Jésù wá sáyé, àwọn nǹkan tó ṣe fi hàn pé ó fìwà jọ Bàbá rẹ̀. (Jòh. 14:9) Torí náà, àwọn nǹkan tá a kọ́ nípa Jésù ló jẹ́ ká mọ Jèhófà ká sì nífẹ̀ẹ́ ẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, à ń jàǹfààní látinú ẹ̀kọ́ tí Jésù ń kọ́ wa àti bó ṣe ń tọ́ wa sọ́nà nínú ìjọ lónìí. Ó tún ń jẹ́ ká mọ àwọn ohun tó yẹ ká ṣe, kí inú Jèhófà lè dùn sí wa. Gbogbo wa tún ń jàǹfààní ikú Jésù. Lọ́nà wo? Lẹ́yìn tí Jèhófà jí i dìde, ó gba ẹbọ pípé tí Jésù rú láti “wẹ̀ wá mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀.”​—1 Jòh. 1:7.

14. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká rò pé ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni àsọtẹ́lẹ̀ tá a sọ ní ọgbà Édẹ́nì máa ṣẹ? Ṣàlàyé.

14 Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ ní ọgbà Édẹ́nì fi hàn pé ó máa gba àkókò kí àsọtẹ́lẹ̀ náà tó ṣẹ. Ó máa gba àkókò kí ọmọ obìnrin tí Jèhófà ṣèlérí náà tó fara hàn. Ó tún máa gba àkókò kí Èṣù tó kó àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ jọ àti kí àwùjọ méjèèjì yìí tó di ọ̀tá ara wọn. Tá a bá lóye àsọtẹ́lẹ̀ yìí, a máa jàǹfààní gan-an torí àsọtẹ́lẹ̀ náà kìlọ̀ fún wa pé ayé tí Sátánì ń darí máa kórìíra àwa èèyàn Jèhófà. Nígbà tó yá, Jésù kìlọ̀ ohun kan náà fáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀. (Máàkù 13:13; Jòh. 17:14) Ẹ̀rí tó dájú wà pé apá kan àsọtẹ́lẹ̀ náà ti ṣẹ, pàápàá ní ọgọ́rùn-ún ọdún (100) tó kọjá yìí. Kí ló jẹ́ ká sọ bẹ́ẹ̀?

15. Kí nìdí tí aráyé fi túbọ̀ ń kórìíra wa, àmọ́ kí nìdí tí kò fi yẹ ká bẹ̀rù Sátánì?

15 Kò pẹ́ lẹ́yìn tí Jésù di Mèsáyà Ọba lọ́dún 1914, a lé Sátánì kúrò lọ́run wá sí ayé. Ní báyìí, kò lè pa dà sọ́run mọ́, ó sì ń dúró de ìgbà tó máa pa run. (Ìfi. 12:9, 12) Àmọ́ bó ṣe ń dúró yẹn, kò sinmi, ọwọ́ ẹ̀ dí gan-an. Inú ń bí Sátánì gan-an, ó sì ń gbógun ti àwọn èèyàn Ọlọ́run. (Ìfi. 12:13, 17) Ìdí nìyẹn tí aráyé fi túbọ̀ ń kórìíra wa. Àmọ́ ṣá o, kò yẹ ká máa bẹ̀rù Sátánì àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó dá wa lójú bó ṣe dá àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lójú, ó sọ pé: “Tí Ọlọ́run bá wà lẹ́yìn wa, ta ló lè dènà wa?” (Róòmù 8:31) Torí náà, àwọn nǹkan tá a jíròrò ti jẹ́ ká rí i pé, a lè gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá torí pé ọ̀pọ̀ lára àsọtẹ́lẹ̀ inú Jẹ́nẹ́sísì 3:15 ti ṣẹ.

16-18. Báwo ni Curtis, Ursula àti Jessica ṣe jàǹfààní nígbà tí wọ́n lóye àsọtẹ́lẹ̀ inú Jẹ́nẹ́sísì 3:15?

16 Ìlérí tí Jèhófà ṣe ní Jẹ́nẹ́sísì 3:15 máa jẹ́ ká lè fara da ìṣòro èyíkéyìí tó bá dé bá wa. Arákùnrin Curtis tó ń ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì ní Guam sọ pé: “Nígbà kan, mo ti dojú kọ àwọn ìṣòro àti ìjákulẹ̀ tó dán ìgbàgbọ́ mi wò. Àmọ́ nígbà tí mo ronú lórí àsọtẹ́lẹ̀ inú Jẹ́nẹ́sísì 3:15, ó jẹ́ kí n fọkàn tán Jèhófà Bàbá mi ọ̀run.” Curtis ń fojú sọ́nà láti rí ìgbà tí Jèhófà máa mú gbogbo ìṣòro wa kúrò.

17 Arábìnrin Ursula tó ń gbé nílùú Bavaria sọ pé bóun ṣe lóye Jẹ́nẹ́sísì 3:15 ti jẹ́ kóun gbà pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì. Nígbà tó rí bí gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ yòókù nínú Bíbélì ṣe so mọ́ àsọtẹ́lẹ̀ inú Jẹ́nẹ́sísì 3:15, ó wú u lórí gan-an. Ó tún sọ pé: “Mo wá túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gan-an nígbà tí mo mọ̀ pé ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló dá sí ọ̀rọ̀ aráyé kí ọjọ́ ọ̀la wa lè dáa.”

18 Ẹlòmíì ni Arábìnrin Jessica tó wá láti Micronesia, ó sọ pé: “Mo ṣì rántí bó ṣe rí lára mi nígbà tí mo kọ́kọ́ mọ̀ pé mo ti rí òtítọ́! Mo rí i pé àsọtẹ́lẹ̀ inú Jẹ́nẹ́sísì 3:15 ti ń ṣẹ. Ó jẹ́ kí n mọ̀ pé ìgbésí ayé tá à ń gbé lónìí kì í ṣe ìgbésí ayé tí Jèhófà fẹ́ fún wa. Àsọtẹ́lẹ̀ yìí tún jẹ́ kí ìgbàgbọ́ mi túbọ̀ lágbára, ó sì jẹ́ kí n rí i pé tí mo bá sin Jèhófà, ayé mi á dáa ní báyìí àti lọ́jọ́ iwájú.”

19. Kí ló jẹ́ kó dá wa lójú pé apá tó kù lára àsọtẹ́lẹ̀ náà máa ṣẹ?

19 Àwọn ohun tá a ti jíròrò jẹ́ ká rí i pé Jẹ́nẹ́sísì 3:15 ti ń ṣẹ. A ti wá mọ ọmọ obìnrin náà àti ọmọ ejò náà báyìí. Jésù tó jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ lára ọmọ obìnrin náà ti jíǹde, ó sì ti di Ọba tá a ṣe lógo lọ́run, kò sì lè kú mọ́. Àwọn tí Jèhófà yàn láti bá Jésù jọba, ìyẹn àwọn tó jẹ́ apá kejì ọmọ obìnrin náà ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pé. Apá àkọ́kọ́ nínú àsọtẹ́lẹ̀ náà ti ṣẹ, ó sì dá wa lójú pé apá kejì, ìyẹn bí a ṣe máa fọ́ orí ejò náà máa ṣẹ. Ẹ ò rí i pé ìtura máa dé bá àwọn tó jẹ́ olóòótọ́ nígbà tí Sátánì bá pa run! Àmọ́ kó tó dìgbà yẹn, má jẹ́ kó sú ẹ torí pé Ọlọ́run wa ṣeé fọkàn tán. Torí náà, Jèhófà máa lo ọmọ obìnrin náà láti ṣe ọ̀pọ̀ ohun rere fún “gbogbo orílẹ̀-èdè tó wà láyé.”​—Jẹ́n. 22:18.

ORIN 23 Jèhófà Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Ṣàkóso

^ A ò lè mọyì ohun tó wà nínú Bíbélì tá ò bá lóye àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Jẹ́nẹ́sísì 3:15. Tá a bá gbé àsọtẹ́lẹ̀ yìí yẹ̀ wò, á mú kí ìgbàgbọ́ wa nínú Jèhófà lágbára, á sì jẹ́ kó túbọ̀ dá wa lójú pé ó máa mú gbogbo ìlérí ẹ̀ ṣẹ.

^ Wo Àfikún B1, “Ohun Tó Wà Nínú Bíbélì,” nínú Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.

^ Wo àpótí náà “Àwọn Tí Jẹ́nẹ́sísì 3:14, 15 Sọ Nípa Wọn.”