Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 29

Máa Ti Jésù Alábòójútó Wa Lẹ́yìn

Máa Ti Jésù Alábòójútó Wa Lẹ́yìn

“Gbogbo àṣẹ ní ọ̀run àti ayé la ti fún mi.”—MÁT. 28:18.

ORIN 13 Kristi, Àwòkọ́ṣe Wa

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1. Kí ni Jèhófà fẹ́ ká máa ṣe lónìí?

 ỌLỌ́RUN fẹ́ káwa ìránṣẹ́ rẹ̀ máa wàásù ìhìn rere Ìjọba rẹ̀ níbi gbogbo láyé. (Máàkù 13:10; 1 Tím. 2:3, 4) Iṣẹ́ Jèhófà ni iṣẹ́ yìí, ó sì ṣe pàtàkì gan-an. Ìdí nìyẹn tó fi ní kí Jésù Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n máa bójú tó iṣẹ́ náà. Torí pé Jésù ló ń bójú tó iṣẹ́ ìwàásù yìí, ó dájú pé kí òpin tó dé, a máa ṣiṣẹ́ náà parí bí Jèhófà ṣe fẹ́.​—Mát. 24:14.

2. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

2 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa rí i bí Jésù ṣe ń lo “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” tó yàn láti máa fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀, kí ẹrú náà sì tún ṣètò bí wọ́n ṣe máa wàásù kárí ayé lọ́nà tó gbòòrò jù lọ. (Mát. 24:45) A tún máa rí ohun tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lè ṣe láti ti Jésù àti ẹrú olóòótọ́ lẹ́yìn.

JÉSÙ LÓ Ń DARÍ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ TÁ À Ń ṢE

3. Àṣẹ wo ni Ọlọ́run fún Jésù?

3 Ó dá wa lójú pé Jésù ló ń darí iṣẹ́ ìwàásù wa. Kí ló jẹ́ ká sọ bẹ́ẹ̀? Kí Jésù tó pa dà sọ́run, ó ṣèpàdé pẹ̀lú àwọn kan lára àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ olóòótọ́ lórí òkè kan ní Gálílì. Ó sọ fún wọn pé: “Gbogbo àṣẹ ní ọ̀run àti ayé la ti fún mi.” Àmọ́ kíyè sí ohun tó sọ tẹ̀ lé e, ó ní: “Torí náà, ẹ lọ, kí ẹ máa sọ àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn.” (Mát. 28:18, 19) Ọ̀rọ̀ yìí fi hàn pé ara iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé fún Jésù ni àṣẹ tó fún un pé kó máa darí iṣẹ́ ìwàásù.

4. Kí nìdí tó fi dá wa lójú pé Jésù ló ń darí iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe?

4 Jésù sọ pé àwọn ọmọlẹ́yìn òun máa ṣe iṣẹ́ ìwàásù ní “gbogbo orílẹ̀-èdè” àti pé òun máa wà pẹ̀lú wọn “ní gbogbo ọjọ́ títí dé ìparí ètò àwọn nǹkan.” (Mát. 28:20) Àwọn ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ ká mọ̀ pé Jésù ló ń darí iṣẹ́ ìwàásù títí di àkókò wa yìí.

5. Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ tó wà ní Sáàmù 110:3 ṣe ń ṣẹ sí wa lára?

5 Jésù ò bẹ̀rù pé àwọn tó máa ṣiṣẹ́ ìwàásù ò ní tó nǹkan ní àkókò òpin yìí. Ó mọ̀ pé àsọtẹ́lẹ̀ tí onísáàmù sọ máa ṣẹ pé: “Àwọn èèyàn rẹ máa yọ̀ǹda ara wọn tinútinú ní ọjọ́ ìjáde ogun rẹ.” (Sm. 110:3) Tó o bá wà lára àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ìwàásù, ìwọ náà ń ti Jésù àti ẹrú olóòótọ́ lẹ́yìn nìyẹn, o sì ń jẹ́ kí àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣẹ sí ẹ lára. Iṣẹ́ náà ń tẹ̀ síwájú, àmọ́ à ń dojú kọ àwọn ìṣòro kan.

6. Ìṣòro wo là ń dojú kọ bá a ṣe ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run?

6 Ọ̀kan lára ìṣòro tá à ń dojú kọ bá a ṣe ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ni àtakò. Àwọn apẹ̀yìndà, àwọn olórí ẹ̀sìn àtàwọn olóṣèlú ń parọ́ mọ́ wa pé iṣẹ́ ìwàásù wa ò dáa. Tí àwọn mọ̀lẹ́bí wa, àwọn ọ̀rẹ́ wa àtàwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ bá gba irọ́ yìí gbọ́, wọ́n lè fúngun mọ́ wa pé ká má sin Jèhófà mọ́, ká má sì wàásù mọ́. Láwọn orílẹ̀-èdè kan, ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ta kò wá ni pé wọ́n máa ń halẹ̀ mọ́ wa, wọ́n ń gbéjà kò wá, wọ́n ń fi ọlọ́pàá mú wa, wọ́n sì máa ń sọ wá sẹ́wọ̀n. Torí náà, kò yà wá lẹ́nu pé àwọn èèyàn ń ṣe irú nǹkan báyìí sí wa. Jésù ti sọ tẹ́lẹ̀ pé: ‘Gbogbo orílẹ̀-èdè máa kórìíra yín nítorí orúkọ mi.’ (Mát. 24:9) Báwọn èèyàn ṣe kórìíra wa yìí fi hàn pé ọ̀rọ̀ Jésù ń ṣẹ, Jèhófà sì fọwọ́ sí ohun tá à ń ṣe. (Mát. 5:11, 12) Èṣù ló ń lo àwọn èèyàn láti máa ta kò wá. Àmọ́ Jésù lágbára ju Èṣù lọ! Bí Jésù ṣe ń tì wá lẹ́yìn ń jẹ́ ká lè máa wàásù fún àwọn èèyàn ní gbogbo orílẹ̀-èdè. Ẹ jẹ́ ká gbé ẹ̀rí kan yẹ̀ wò.

7. Ẹ̀rí wo lo rí tó fi hàn pé Ìfihàn 14:6, 7 ti ń ṣẹ?

7 Ìṣòro míì tá à ń dojú kọ bá a ṣe ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ni bá a ṣe máa wàásù fáwọn èèyàn ní èdè wọn. Nínú ìfihàn tí àpọ́sítélì Jòhánù gbà látọ̀dọ̀ Jésù, ó jẹ́ ká mọ̀ pé lákòókò wa yìí, àwọn èèyàn máa gbọ́ ìwàásù ní èdè wọn. (Ka Ìfihàn 14:6, 7.) Kí ló máa jẹ́ kí èyí ṣeé ṣe? Èdè táwọn èèyàn gbọ́ la fi ń wàásù fún wọn, ìyẹn sì ń jẹ́ kí ọ̀pọ̀ èèyàn nífẹ̀ẹ́ láti máa gbọ́ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Lónìí, kárí ayé làwọn èèyàn ti lè ka àwọn ìwé tó dá lórí Bíbélì tó wà lórí ìkànnì jw.org torí pé àwọn ìwé náà wà ní èdè tó ju ẹgbẹ̀rún kan (1,000) lọ! Ètò Ọlọ́run fọwọ́ sí i pé ká túmọ̀ ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! sí èdè tó ju ọgọ́rùn-ún méje (700) lọ. Ìwé yìí la sì fi ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kí wọ́n lè di ọmọ ẹ̀yìn! Wọ́n tún ṣe fídíò fáwọn adití àti ìwé àwọn afọ́jú. À ń rí i bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣe ń ṣẹ. Àwọn èèyàn “láti inú gbogbo èdè àwọn orílẹ̀-èdè” ń kọ́ bí wọ́n á ṣe máa sọ “èdè mímọ́” tó jẹ́ ẹ̀kọ́ òtítọ́ Bíbélì. (Sek. 8:23; Sef. 3:9) Ohun tó ń jẹ́ ká lè máa ṣe àwọn nǹkan yìí láṣeyọrí ni pé Jésù Kristi ló ń darí iṣẹ́ náà.

8. Àwọn àṣeyọrí wo la ti ṣe látìgbà tá a ti ń wàásù ìhìn rere Ìjọba náà?

8 Bá a ṣe ń sọ̀rọ̀ yìí, ní orílẹ̀-èdè igba ó lé ogójì (240), iye àwọn tó wà nínú ètò Ọlọ́run ju mílíọ̀nù mẹ́jọ (8,000,000) lọ, àwọn tó ju ọ̀kẹ́ márùn-ún (100,000) èèyàn ló sì ń ṣèrìbọmi lọ́dọọdún! Kì í ṣe bí iye wa ṣe pọ̀ tó ló ṣe pàtàkì, àmọ́ bí àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di Kristẹni ṣe ń fi “ìwà tuntun,” wọ ara wọn láṣọ ló ṣe pàtàkì jù. (Kól. 3:8-10) Ọ̀pọ̀ lára wọn ló jáwọ́ nínú ìṣekúṣe, ìwà ipá, ìkórìíra àti èrò pé orílẹ̀-èdè tèmi lọ̀gá. Àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Àìsáyà 2:4 ti ń ṣẹ, ó sọ pé, ‘wọn ò ní kọ́ṣẹ́ ogun mọ́.’ Bá a ṣe ń ṣiṣẹ́ kára, tá à ń gbé ìwà tuntun wọ̀, ìyẹn ń mú káwọn èèyàn máa wá sínú ètò Ọlọ́run, àwa náà sì ń fi hàn pé à ń tẹ̀ lé Jésù Kristi tó ń darí wa. (Jòh. 13:35; 1 Pét. 2:12) Àwọn nǹkan yìí ò ṣèèṣì ṣẹlẹ̀ o, ìdí ni pé Jésù ló ń ràn wá lọ́wọ́.

JÉSÙ YAN ẸRÚ KAN

9.Mátíù 24:45-47 ṣe sọ, kí ni Jésù sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ ní àkókò òpin?

9 Ka Mátíù 24:45-47. Jésù sọ pé tó bá di àkókò òpin, òun máa yan “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” láti máa fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bọ́ wa. Torí náà, kò yà wá lẹ́nu pé ẹrú náà ń ṣiṣẹ́ kára lónìí. Jésù ń lo àwùjọ kéréje àwọn ọkùnrin tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn yìí láti máa fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bọ́ àwa àtàwọn tó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ “ní àkókò tó yẹ.” Àwọn ọkùnrin yìí ò jọ̀gá lórí ìgbàgbọ́ wa. (2 Kọ́r. 1:24) Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n gbà pé Jésù Kristi ni “aṣáájú àti aláṣẹ” àwa èèyàn Ọlọ́run.​—Àìsá. 55:4.

10. Èwo nínú àwọn ìwé tó wà nínú àwòrán yẹn lo fi kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ tó jẹ́ kó o máa sin Jèhófà?

10 Láti ọdún 1919, ẹrú olóòótọ́ ti ṣe oríṣiríṣi ìwé tó fún àwọn tó fẹ́ mọ Ọlọ́run láǹfààní láti kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kí wọ́n lè mọ òtítọ́. Lọ́dún 1921, ẹrú náà ṣe ìwé Duru Ọlọrun lédè Gẹ̀ẹ́sì (èyí tá a tẹ̀ lédè Yorùbá lọ́dún 1930) láti ran àwọn tó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ àwọn ìbẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ Bíbélì. Nígbà tó yá, wọ́n ṣe àwọn ìwé míì. Èwo nínú àwọn ìwé yìí ló ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti mọ Bàbá wa ọ̀run tó sì jẹ́ kó o nífẹ̀ẹ́ rẹ̀? Ṣé ìwé “Jẹki Ọlọrun Jẹ Olõtọ” ni àbí Otitọ ti Nsinni Lọ si Iye Aiyeraiye, Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye, Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun, Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?, Kí Ni Bíbélì Kọ́ Wa? tàbí ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe? A ṣe àwọn ìwé yìí ká lè fi kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́, ohun tí wọ́n sì nílò nìyẹn láti lóye òtítọ́ nígbà tá a tẹ̀ wọ́n.

11. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí gbogbo wa máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ká lè mọ Jèhófà dáadáa?

11 Kì í ṣe àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìkan ló yẹ kó máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀. Gbogbo wa ló yẹ ká máa ṣe bẹ́ẹ̀. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Àwọn tó dàgbà ni oúnjẹ líle wà fún.” Pọ́ọ̀lù fi kún un pé tá a bá ń tẹ̀ lé nǹkan tá à ń kọ́ nínú Bíbélì, á jẹ́ ká lè “fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.” (Héb. 5:14) Ó ṣòro gan-an lákòókò tá a wà yìí láti máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà torí ìwà ìbàjẹ́ pọ̀ gan-an láyé. Àmọ́ Jésù ń rí i dájú pé à ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn nǹkan tó máa jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa lágbára. Inú Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run la ti ń kẹ́kọ̀ọ́ àwọn nǹkan yìí. Jésù ló sì ń darí ẹrú olóòótọ́ láti máa fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bọ́ wa.

12. Báwo la ṣe ń bọ̀wọ̀ fún orúkọ Ọlọ́run bí Jésù ti ṣe?

12 Bíi ti Jésù, àwa náà ti jẹ́ káwọn èèyàn mọ orúkọ Ọlọ́run. (Jòh. 17:6, 26) Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún 1931, a bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ́ orúkọ náà Ẹlẹ́rìí Jèhófà, a sì ń fẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé à ń jẹ́ orúkọ mọ́ Bàbá wa ọ̀run. (Àìsá. 43:10-12) Torí náà, láti October ọdún 1931 ni orúkọ Ọlọ́run ti ń fara hàn níwájú ìwé yìí. Yàtọ̀ síyẹn, Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ti dá orúkọ Ọlọ́run pa dà sí gbogbo ibi tó yẹ kó wà. Ẹ ò rí i pé a ò dà bí àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì tí wọ́n yọ orúkọ Ọlọ́run kúrò nínú Bíbélì!

JÉSÙ ṢÈTÒ ÀWỌN ỌMỌLẸ́YÌN RẸ̀

13. Kí ló jẹ́ kó o gbà pé “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ni Jésù ń lò lákòókò wa yìí? (Jòhánù 6:68)

13 Jésù ń lo “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” láti kó àwọn èèyàn jọ sínú ètò Ọlọ́run kí wọ́n lè máa jọ́sìn Ọlọ́run lọ́nà tó mọ́. Ṣé inú ẹ ń dùn pé o wà nínú ètò náà? Èsì rẹ lè dà bíi ti àpọ́sítélì Pétérù tó sọ fún Jésù pé: “Ọ̀dọ̀ ta la máa lọ? Ìwọ lo ní àwọn ọ̀rọ̀ ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòh. 6:68) Kí ni ò bá ti ṣẹlẹ̀ sí wa ká sọ pé a ò sí nínú ètò Ọlọ́run? Ètò yìí ni Kristi ń lò láti máa pèsè ohun tá a nílò ká lè jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run. Jésù tún máa ń dá wa lẹ́kọ̀ọ́ ká lè túbọ̀ já fáfá lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Yàtọ̀ síyẹn, Jésù tún máa ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè gbé “ìwà tuntun” wọ̀, ìyẹn sì ń jẹ́ kí inú Jèhófà dùn sí wa.​—Éfé. 4:24.

14. Torí pé o wà nínú ètò Ọlọ́run, àǹfààní wo lo ti rí lásìkò àjàkálẹ̀ àrùn Kòrónà?

14 Jésù ń lo ẹrú olóòótọ́ àti olóye láti máa tọ́ wa sọ́nà lákòókò wàhálà. Bí Jésù ṣe ń tọ́ wa sọ́nà máa ń ṣe wá láǹfààní. Ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà àjàkálẹ̀ àrùn Kòrónà jẹ́ ká mọ̀ pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ èèyàn ni ò mọ ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe nígbà yẹn, àmọ́ Jésù rí i pé a rí ìtọ́sọ́nà gbà, ìyẹn sì dáàbò bò wá. Wọ́n sọ fún wa pé ká máa bo imú wa, ká sì máa jìnnà síra wa dáadáa. Wọ́n rán àwọn alàgbà létí láti máa kàn sí gbogbo àwọn ará ìjọ, kí wọ́n lè mọ àwọn ohun tí wọ́n nílò, kí wọ́n sì lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti sún mọ́ Jèhófà dáadáa. (Àìsá. 32:1, 2) Ìròyìn tí Ìgbìmọ̀ Olùdarí máa ń sọ fún wa tún ń jẹ́ ká mọ ohun tó yẹ ká ṣe, ó sì ń fi wá lọ́kàn balẹ̀.

15. Kí ni ètò Ọlọ́run sọ fún wa nípa ọ̀nà tá ó máa gbà ṣe ìpàdé àti iṣẹ́ ìwàásù lásìkò àjàkálẹ̀ àrùn Kòrónà, àǹfààní wo la sì rí?

15 Nígbà àjàkálẹ̀ àrùn Kòrónà, ètò Ọlọ́run sọ fún wa nípa ọ̀nà tá ó máa gbà ṣe ìpàdé àti iṣẹ́ ìwàásù. Kíákíá la bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìpàdé ìjọ, àpéjọ àyíká àti àpéjọ agbègbè lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Kíákíá la tún bẹ̀rẹ̀ sí í lo fóònù àti lẹ́tà láti fi wàásù fáwọn èèyàn. Jèhófà mú ká ṣàṣeyọrí. Ìdí ni pé ọ̀pọ̀ ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ròyìn pé àwọn tó ṣèrìbọmi ń pọ̀ sí i. Kódà, ọ̀pọ̀ àwọn ará wa ròyìn pé àwọn ohun rere tó ń mórí ẹni wú ṣẹlẹ̀ lásìkò àjàkálẹ̀ àrùn Kòrónà yìí.​—Wo àpótí náà, “ Jèhófà Mú Kí Iṣẹ́ Ìwàásù Wa Yọrí Sí Rere.”

16. Kí ló dá wa lójú?

16 Àwọn kan lè máa rò pé ọwọ́ tí ètò Ọlọ́run fi mú ọ̀rọ̀ àjàkálẹ̀ àrùn yìí ti le jù. Àmọ́ ìgbà gbogbo là ń rí ẹ̀rí tó fi hàn pé òótọ́ ni ohun tí wọ́n ń sọ fún wa. (Mát. 11:19) Torí náà, tá a bá ń ronú lórí bí Jésù ṣe ń fìfẹ́ darí wa, ó dá wa lójú pé ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀ sí wa, Jèhófà àti Jésù Ọmọ rẹ̀ ò ní fi wá sílẹ̀.​—Ka Hébérù 13:5, 6.

17. Ṣé inú ẹ ń dùn pé Jésù ló ń darí wa?

17 Inú wa ń dùn pé Jésù ló ń darí wa! Nínú ètò tá a wà yìí, a ò jẹ́ kí orílẹ̀-èdè tá a ti wá, àṣà ìbílẹ̀ wa àti èdè tá à ń sọ dá ìyapa sáàárín wa. Ọ̀pọ̀ nǹkan ni wọ́n ti kọ́ wa nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n sì ti dá wa lẹ́kọ̀ọ́ nípa bá a ṣe máa ṣe iṣẹ́ ìwàásù wa. Wọ́n tún kọ́ wa bá a ṣe lè máa hùwà tó dáa àti bá a ṣe lè nífẹ̀ẹ́ ara wa. Ẹ ò rí i pé ọ̀pọ̀ nǹkan ló ń múnú wa dùn torí pé Jésù Aṣáájú wa ṣeé gbára lé!

ORIN 16 Ẹ Yin Jáà Nítorí Ọmọ Rẹ̀ Tó Fòróró Yàn

^ Àìmọye èèyàn lọ́kùnrin, lóbìnrin, lọ́mọdé àti lágbà ló ń fìtara wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run lásìkò wa yìí. Ṣé o wà lára wọn? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, á jẹ́ pé Jésù Kristi Olúwa wa lò ń bá ṣiṣẹ́. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa gbé ẹ̀rí kan yẹ̀ wò tó fi hàn pé Jésù ló ń darí iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe. Tá a bá ronú lórí ohun tá a máa jíròrò, á jẹ́ ká túbọ̀ pinnu pé Jèhófà làá máa sìn nìṣó bí Kristi ṣe ń darí wa.