Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 31

Mọyì Àǹfààní Tó O Ní Láti Máa Gbàdúrà sí Ọlọ́run

Mọyì Àǹfààní Tó O Ní Láti Máa Gbàdúrà sí Ọlọ́run

“Kí àdúrà mi dà bíi tùràrí tí a ṣètò sílẹ̀ níwájú rẹ.”​—SM. 141:2.

ORIN 47 Máa Gbàdúrà sí Jèhófà Lójoojúmọ́

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1. Báwo ni àǹfààní tí Jèhófà fún wa láti gbàdúrà sí òun ṣe rí lára wa?

 ẸNI tó ṣẹ̀dá ọ̀run àti ayé ti fún wa láǹfààní kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Ó fún wa láǹfààní láti máa gbàdúrà sí òun. Ẹ̀yin náà ẹ wò ó ná, kò sígbà tá ò lè bá Jèhófà sọ̀rọ̀, kò sì sí èdè tá ò lè fi bá a sọ̀rọ̀, kódà a lè gbàdúrà sí i láìsọ fún un tẹ́lẹ̀. A lè gbàdúrà sí i tá a bá wà lórí bẹ́ẹ̀dì nílé ìwòsàn tàbí tá a bá wà lẹ́wọ̀n, ó sì dá wa lójú pé Bàbá wa ọ̀run máa gbọ́ wa. Torí náà, ọwọ́ pàtàkì ló yẹ ká fi mú àǹfààní ńlá yìí.

2. Kí ni Ọba Dáfídì ṣe tó fi hàn pé ó mọyì àǹfààní tó ní láti gbàdúrà sí Ọlọ́run?

2 Ọba Dáfídì mọyì àǹfààní tó ní láti gbàdúrà sí Ọlọ́run. Ó sọ fún Jèhófà pé: “Kí àdúrà mi dà bíi tùràrí tí a ṣètò sílẹ̀ níwájú rẹ.” (Sm. 141:1, 2) Nígbà ayé Dáfídì, wọ́n máa ń fara balẹ̀ ṣe tùràrí táwọn àlùfáà máa ń lò. (Ẹ́kís. 30:34, 35) Bí Dáfídì ṣe mẹ́nu ba tùràrí yẹn jẹ́ ká mọ̀ pé bíi tàwọn tó ń fara balẹ̀ ṣe tùràrí, òun náà máa ń fara balẹ̀ ronú lórí ohun tó fẹ́ sọ nígbà tó bá fẹ́ gbàdúrà sí Jèhófà. Ohun táwa náà sì fẹ́ ṣe nìyẹn torí a fẹ́ kí inú Jèhófà dùn sí àdúrà wa.

3. Báwo ló ṣe yẹ ká máa bá Jèhófà sọ̀rọ̀ tá a bá ń gbàdúrà, kí sì nìdí?

3 Tá a bá ń gbàdúrà, kò yẹ ká máa bá Jèhófà sọ̀rọ̀ bíi pé ẹgbẹ́ ni wá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló yẹ ká bá a sọ̀rọ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. Ẹ jẹ́ ká ronú lórí ìran àgbàyanu tí Àìsáyà, Ìsíkíẹ́lì, Dáníẹ́lì àti Jòhánù rí. Àwọn ìran yìí yàtọ̀ síra lóòótọ́, àmọ́ nǹkan kan wà tá a kíyè sí nínú gbogbo wọn. Gbogbo wọn ló jẹ́ ká mọ̀ pé Ọba alágbára ńlá ni Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, Àìsáyà “rí Jèhófà tó jókòó sórí ìtẹ́ gíga, tó sì ta yọ.” (Àìsá. 6:1-3) Ìsíkíẹ́lì rí Jèhófà tó jókòó sórí kẹ̀kẹ́ ẹṣin, tí ‘ìmọ́lẹ̀ tó tàn yòò bí òṣùmàrè sì yí i ká.’ (Ìsík. 1:26-28) Dáníẹ́lì rí “Ẹni Ọjọ́ Àtayébáyé” tó wọ aṣọ funfun, iná sì ń jáde láti inú ìtẹ́ Rẹ̀. (Dán. 7:9, 10) Jòhánù náà rí Jèhófà tó jókòó sórí ìtẹ́, òṣùmàrè kan tó dà bí òkúta émírádì sì yí ìtẹ́ náà ká. (Ìfi. 4:2-4) Torí náà, bá a ṣe ń ronú lórí bí ọlá ńlá Jèhófà ṣe tóbi tó, ó yẹ ká máa rántí pé àǹfààní ńlá la ní láti gbàdúrà sí i, ó sì yẹ ká máa ṣe bẹ́ẹ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. Àmọ́ báwo ló ṣe yẹ ká máa gbàdúrà?

“TORÍ NÁÀ, Ẹ MÁA GBÀDÚRÀ LỌ́NÀ YÌÍ”

4. Kí la kọ́ nínú ọ̀rọ̀ tí Jésù fi bẹ̀rẹ̀ àdúrà tó kọ́ wa ní Mátíù 6:9, 10?

4 Ka Mátíù 6:9, 10. Nínú Ìwàásù orí Òkè, Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ bí wọ́n á ṣe máa gbàdúrà tó máa múnú Ọlọ́run dùn. Lẹ́yìn tí Jésù sọ pé “torí náà, ẹ máa gbàdúrà lọ́nà yìí,” àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì sí Jèhófà ló kọ́kọ́ mẹ́nu bà, ìyẹn bí orúkọ Jèhófà ṣe máa di mímọ́, bí Ìjọba Ọlọ́run ṣe máa dé, táá sì pa gbogbo àwọn ọ̀tá Ọlọ́run run àtàwọn ohun rere tí Ọlọ́run máa ṣe fún aráyé. Táwa náà bá ń sọ àwọn nǹkan yìí nínú àdúrà wa, à ń fi hàn pé bí ìfẹ́ Jèhófà ṣe máa ṣẹ ló ṣe pàtàkì jù sí wa.

5. Ṣé ó burú tá a bá gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ṣe àwọn nǹkan tá a fẹ́ fún wa?

5 Àwọn ohun tí Jésù sọ lẹ́yìn ìyẹn fi hàn pé kò burú tá a bá sọ fún Jèhófà pé kó ṣe àwọn nǹkan tá a fẹ́ fún wa. Torí náà, a lè sọ fún Jèhófà pé kó pèsè ohun tá a máa jẹ fún wa, kó dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, kó má jẹ́ ká kó sínú àdánwò, kó sì gbà wá lọ́wọ́ ẹni burúkú náà. (Mát. 6:11-13) Tá a bá ń bẹ Jèhófà pé kó ṣe àwọn nǹkan yìí fún wa, à ń jẹ́ kó mọ̀ pé a fẹ́ kó ràn wá lọ́wọ́, a sì fẹ́ múnú ẹ̀ dùn.

Àwọn nǹkan wo ni ọkọ kan lè bá Jèhófà sọ tó bá ń gbàdúrà pẹ̀lú ìyàwó ẹ̀? (Wo ìpínrọ̀ 6) *

6. Ṣé àwọn nǹkan tó wà nínú àdúrà tí Jésù kọ́ wa yẹn nìkan la lè gbàdúrà nípa ẹ̀? Ṣàlàyé.

6 Jésù ò fẹ́ kó jẹ́ pé ọ̀rọ̀ tó wà nínú àdúrà tó kọ́ wa yẹn gẹ́lẹ́ làwa ọmọlẹ́yìn ẹ̀ á máa lò tá a bá fẹ́ gbàdúrà. Ìdí sì ni pé nínú àwọn àdúrà míì tí Jésù gbà, ó mẹ́nu kan àwọn nǹkan míì tó ń jẹ ẹ́ lọ́kàn. (Mát. 26:39, 42; Jòh. 17:1-26) Lọ́nà kan náà, àwa náà lè sọ gbogbo àwọn nǹkan tó ń jẹ wá lọ́kàn fún Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá fẹ́ ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì kan, a lè bẹ Jèhófà pé kó fún wa lọ́gbọ́n àti òye. (Sm. 119:33, 34) Tí wọ́n bá gbé iṣẹ́ kan tó le fún wa, a lè gbàdúrà pé kí Jèhófà fún wa ní ìmọ̀ àti òye tá a máa fi ṣe iṣẹ́ náà. (Òwe 2:6) Bákan náà, ó yẹ káwọn òbí máa gbàdúrà fáwọn ọmọ wọn, káwọn ọmọ náà sì máa gbàdúrà fáwọn òbí wọn. Gbogbo wa ló sì yẹ ká máa gbàdúrà fáwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ àtàwọn tá à ń wàásù fún. Àmọ́ kò yẹ kó jẹ́ pé àwọn nǹkan tá a fẹ́ nìkan làá máa béèrè lọ́wọ́ Jèhófà o.

Àwọn nǹkan wo la lè sọ láti yin Jèhófà, ká sì dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀ tá a bá ń gbàdúrà? (Wo ìpínrọ̀ 7-9) *

7. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa yin Jèhófà tá a bá ń gbàdúrà?

7 Ó yẹ ká máa rántí yin Jèhófà tá a bá ń gbàdúrà. Ọlọ́run lẹni tó yẹ ká máa yìn jù lọ, ìdí sì ni pé ‘ẹni rere ni, ó sì ṣe tán láti dárí jini.’ Ó tún “jẹ́ Ọlọ́run aláàánú, tó ń gba tẹni rò, tí kì í tètè bínú, tí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ àti òdodo rẹ̀ sì pọ̀ gidigidi.” (Sm. 86:5, 15) Ẹ ò rí i pé ó yẹ ká máa yin Jèhófà torí ẹni tó jẹ́ àtàwọn nǹkan tó ń ṣe fún wa!

8. Àwọn nǹkan wo ni Jèhófà ṣe fún wa tó fi yẹ ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀? (Sáàmù 104:12-15, 24)

8 Yàtọ̀ sí pé ó yẹ ká máa yin Jèhófà tá a bá ń gbàdúrà, ó tún yẹ ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀ nítorí àwọn nǹkan rere tó ń pèsè fún wa. Bí àpẹẹrẹ, a lè dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀ pé ó fún wa ní àwọ̀ mèremère tá à ń rí lára àwọn òdòdó, oríṣiríṣi oúnjẹ aládùn àtàwọn ọ̀rẹ́ wa ọ̀wọ́n tó ń dúró tì wá. Gbogbo àwọn nǹkan yìí ni Bàbá wa ọ̀run ń pèsè fún wa torí pé ó fẹ́ ká máa láyọ̀. (Ka Sáàmù 104:12-15, 24.) Àmọ́ ohun tó yẹ ká máa torí ẹ̀ dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà jù ni pé ó ń fi Ọ̀rọ̀ rẹ̀ bọ́ wa yó àti pé ó máa fún wa láwọn ohun rere lọ́jọ́ iwájú.

9. Kí ni ò ní jẹ́ ká gbàgbé láti máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà? (1 Tẹsalóníkà 5:17, 18)

9 A máa ń gbàgbé láti dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà nígbà míì. Kí lá jẹ́ kó o máa rántí? O lè kọ àwọn nǹkan tó o fẹ́ kí Jèhófà ṣe fún ẹ sílẹ̀, kó o sì máa wò wọ́n látìgbàdégbà bí Jèhófà ṣe ń dáhùn wọn. Tó o bá kíyè sí pé Jèhófà ti dáhùn àwọn àdúrà ẹ kan, rí i pé o dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀. (Ka 1 Tẹsalóníkà 5:17, 18.) Rò ó wò ná, inú gbogbo wa máa ń dùn táwọn èèyàn bá dúpẹ́ oore tá a ṣe fún wọn. Lọ́nà kan náà, tá a bá ń rántí dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà nítorí àwọn nǹkan tó ti ṣe fún wa, inú ẹ̀ máa dùn gan-an. (Kól. 3:15) Àmọ́, kí ni nǹkan pàtàkì míì tí Ọlọ́run ṣe fún wa tó fi yẹ ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀?

MÁA DÚPẸ́ LỌ́WỌ́ JÈHÓFÀ PÉ Ó FÚN WA NÍ ỌMỌ RẸ̀ Ọ̀WỌ́N

10. Kí ni 1 Pétérù 2:21 sọ tó fi yẹ ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó rán Jésù wá sáyé?

10 Ka 1 Pétérù 2:21. Ó yẹ ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó rán Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n wá sáyé láti wá kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́. Tá a bá kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jésù, ọ̀pọ̀ nǹkan la máa mọ̀ nípa Jèhófà àti bá a ṣe lè múnú ẹ̀ dùn. Torí náà, tá a bá ní ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Kristi, a máa di ọ̀rẹ́ Jèhófà, àlàáfíà á sì wà láàárín àwa àti Ọlọ́run.​—Róòmù 5:1.

11. Kí nìdí tá a fi máa ń gbàdúrà sí Jèhófà lórúkọ Jésù?

11 A dúpẹ́ pé a lè gbàdúrà sí Jèhófà nípasẹ̀ Ọmọ ẹ̀. Jésù sì ni Jèhófà máa ń lò láti dáhùn àwọn àdúrà wa. Tá a bá gbàdúrà sí Jèhófà ní orúkọ Jésù, Jèhófà máa ń gbọ́, ó sì máa ń dáhùn àdúrà wa. Ìdí nìyẹn tí Jésù fi sọ pé: “Ohunkóhun tí ẹ bá béèrè ní orúkọ mi, màá ṣe é, ká lè tipasẹ̀ Ọmọ yin Baba lógo.”​—Jòh. 14:13, 14.

12. Kí ni ìdí míì tá a fi máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà torí Ọmọ ẹ̀?

12 Jèhófà máa ń dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá nítorí ẹbọ ìràpadà Jésù. Bíbélì sọ pé Jésù ni “àlùfáà àgbà [wa], ó sì ti jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún ìtẹ́ Ọba Ọlọ́lá ní ọ̀run.” (Héb. 8:1) Jésù tún ni ‘olùrànlọ́wọ́ tó ń bá wa bẹ̀bẹ̀ lọ́dọ̀ Baba.’ (1 Jòh. 2:1) A dúpẹ́, a tún ọpẹ́ dá lọ́wọ́ Jèhófà pé ó fún wa ní Àlùfáà Àgbà tó mọ àwọn àìlera wa, tó ń bá wa kẹ́dùn, “tó sì ń bá wa bẹ̀bẹ̀”! (Róòmù 8:34; Héb. 4:15) Tí kì í bá ṣe ẹbọ ìràpadà Jésù ni, kò bá má ṣeé ṣe fún wa láti gbàdúrà sí Jèhófà torí pé aláìpé ni wá. Torí náà, kò sí nǹkan tá a lè fi san oore bàǹtàbanta tí Jèhófà ṣe wá, ìyẹn Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n tó fún wa, àfi ká ṣáà máa dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀!

MÁA GBÀDÚRÀ FÁWỌN ARÁKÙNRIN ÀTÀWỌN ARÁBÌNRIN RẸ

13. Ní alẹ́ tó ṣáájú ikú Jésù, kí ló ṣe fáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ tó fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ wọn?

13 Ní alẹ́ tó ṣáájú ikú Jésù, àkókò tó fi gbàdúrà nítorí àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ gùn gan-an, ó sì sọ fún Bàbá ẹ̀ pé kó “máa ṣọ́ wọn torí ẹni burúkú náà.” (Jòh. 17:15) Ẹ ò rí i pé Jésù nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ gan-an! Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jésù máa tó dojú kọ àdánwò tó lágbára gan-an, bó ṣe máa bójú tó àwọn àpọ́sítélì ẹ̀ ló gbà á lọ́kàn.

Àwọn nǹkan wo la lè gbàdúrà pé kí Jèhófà ṣe fáwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa? (Wo ìpínrọ̀ 14-16) *

14. Kí la lè ṣe táá fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa?

14 Bíi ti Jésù, kì í ṣe tara wa nìkan ló yẹ ká gbájú mọ́. Dípò bẹ́ẹ̀, ó yẹ ká máa gbàdúrà fáwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa nígbà gbogbo. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ó máa fi hàn pé à ń tẹ̀ lé àṣẹ Jésù pé ká nífẹ̀ẹ́ ara wa, Jèhófà náà á sì rí i pé a nífẹ̀ẹ́ ara wa lóòótọ́. (Jòh. 13:34) A ò fi àkókò wa ṣòfò tá a bá ń gbàdúrà fáwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa torí Bíbélì sọ pé “ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ olódodo lágbára gan-an.”​—Jém. 5:16.

15. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa gbàdúrà fáwọn ará wa?

15 Ó yẹ ká máa gbàdúrà fáwọn ará wa torí pé wọ́n ń dojú kọ ọ̀pọ̀ ìṣòro. A lè bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kí wọ́n fara da àìsàn, àjálù, ogun, inúnibíni àtàwọn ìṣòro míì. Ó tún yẹ ká máa gbàdúrà fáwọn tó ń yọ̀ǹda ara wọn láti ṣèrànwọ́ fáwọn tí àjálù dé bá. Ó ṣeé ṣe kó o mọ àwọn kan tó nírú àwọn ìṣòro tá a mẹ́nu bà yìí. O ò ṣe dárúkọ ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn nínú àdúrà ẹ? Tá a bá ń bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kí wọ́n fara dà á, ìyẹn á fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ wọn dénú.

16. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa gbàdúrà fáwọn tó ń ṣàbójútó wa?

16 Àwọn tó ń ṣàbójútó wa nínú ìjọ máa ń mọyì ẹ̀ gan-an tá a bá gbàdúrà fún wọn, ó sì máa ń ṣe wọ́n láǹfààní. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà jẹ́ ká mọ̀ pé bọ́rọ̀ ṣe rí nìyẹn nígbà tó sọ pé: “Ẹ máa gbàdúrà fún èmi náà, kí a lè fún mi lọ́rọ̀ sọ tí mo bá la ẹnu mi, kí n lè fi ìgboyà sọ̀rọ̀ nígbà tí mo bá ń sọ àṣírí mímọ́ ìhìn rere.” (Éfé. 6:19) Bákan náà lónìí, ọ̀pọ̀ arákùnrin ló wà nínú ètò Ọlọ́run tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ kára, tí wọ́n sì ń ṣàbójútó wa. A máa fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ wọn tá a bá ń bẹ Jèhófà pé kó máa ràn wọ́n lọ́wọ́.

TÍ WỌ́N BÁ FÚN WA LÁǸFÀÀNÍ PÉ KÁ WÁ GBÀDÚRÀ

17-18. Àwọn ìgbà wo ni wọ́n lè fún wa láǹfààní pé ká wá gbàdúrà, kí ló sì yẹ ká máa rántí?

17 Nígbà míì, wọ́n lè fún wa láǹfààní pé ká gbàdúrà. Bí àpẹẹrẹ, arábìnrin kan tó fẹ́ darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lè sọ pé kí arábìnrin tí wọ́n jọ lọ gbàdúrà. Arábìnrin tí wọ́n ní kó gbàdúrà náà lè má mọ akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà dáadáa, torí náà, ó lè sọ pé á dáa kóun gbàdúrà ìparí. Tó bá ṣe bẹ́ẹ̀, á ti mọ akẹ́kọ̀ọ́ yẹn dé àyè kan kí wọ́n tó parí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, ìyẹn á sì jẹ́ kó mọ ohun tó máa sọ nínú àdúrà ẹ̀ táá ṣe akẹ́kọ̀ọ́ náà láǹfààní.

18 Wọ́n lè sọ pé kí arákùnrin kan gbàdúrà nípàdé iṣẹ́ ìwàásù tàbí nípàdé ìjọ. Kò yẹ káwọn arákùnrin tó láǹfààní yẹn gbàgbé ìdí tá a fi wà nípàdé. Kò yẹ kí wọ́n fi àdúrà yẹn ṣe ìfilọ̀ fáwọn ará tàbí kí wọ́n fi nà wọ́n lẹ́gba ọ̀rọ̀. Èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn ìpàdé wa ló jẹ́ pé ìṣẹ́jú márùn-ún péré ni ètò Ọlọ́run ní ká fi kọrin, ká sì fi gbàdúrà. Torí náà, kò yẹ kí arákùnrin tó máa gbàdúrà sọ “ọ̀rọ̀ púpọ̀,” pàápàá níbẹ̀rẹ̀ ìpàdé.​—Mát. 6:7.

JẸ́ KÓ MỌ́ Ẹ LÁRA LÁTI MÁA GBÀDÚRÀ

19. Kí ló yẹ ká máa ṣe láti múra sílẹ̀ de ọjọ́ ìdájọ́ Jèhófà?

19 Ó ṣe pàtàkì pé ká jẹ́ kó mọ́ wa lára láti máa gbàdúrà bí ọjọ́ ìdájọ́ Jèhófà ṣe ń sún mọ́lé. Nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa ọjọ́ yẹn, ó ní: “Torí náà, ẹ máa wà lójúfò, kí ẹ máa rawọ́ ẹ̀bẹ̀ nígbà gbogbo, kí ẹ lè bọ́ nínú gbogbo nǹkan tó gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ yìí.” (Lúùkù 21:36) Torí náà, tá a bá ń gbàdúrà nígbà gbogbo ìgbàgbọ́ wa máa lágbára, ọjọ́ náà ò sì ní dé bá wa lójijì.

20. Kí ló máa jẹ́ kí àdúrà wa dà bíi tùràrí olóòórùn dídùn?

20 Kí la ti kọ́? Ohun tá a ti kọ́ ni pé ká túbọ̀ mọyì àǹfààní tí Jèhófà fún wa pé ká máa gbàdúrà sí òun. Yàtọ̀ síyẹn, bí ìfẹ́ Jèhófà ṣe máa ṣẹ ló yẹ kó gbawájú nínú àdúrà wa. A tún ti kẹ́kọ̀ọ́ pé ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà torí ó fún wa ní Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n àti pé Ìjọba Ọmọ rẹ̀ ti ń ṣàkóso. Ohun míì tá a kọ́ ni pé ká máa gbàdúrà fáwọn ará wa. Àwa náà sì lè gbàdúrà pé kí Jèhófà pèsè àwọn nǹkan tá a nílò àtohun tó máa jẹ́ ká ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú ẹ̀. Tá a bá ń ronú nípa nǹkan tá a máa sọ nínú àdúrà wa, á fi hàn pé a mọyì àǹfààní tó ṣàrà ọ̀tọ̀ yìí. Ọ̀rọ̀ wa máa wá dà bíi tùràrí olóòórùn dídùn tó “ń múnú Rẹ̀ dùn.”​—Òwe 15:8.

ORIN 45 Àṣàrò Ọkàn Mi

^ Inú wa dùn pé Jèhófà fún wa láǹfààní láti máa gbàdúrà sí òun. A fẹ́ kí àdúrà wa dà bíi tùràrí tó ní òórùn dídùn, tó sì ń múnú Jèhófà dùn. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tá a lè bá Jèhófà sọ tá a bá ń gbàdúrà. A tún máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tó yẹ ká fi sọ́kàn tí wọ́n bá fún wa láǹfààní pé ká wá gbàdúrà.

^ ÀWÒRÁN: Baálé ilé kan ń gbàdúrà pẹ̀lú ìyàwó ẹ̀ pé kí Jèhófà ṣọ́ ọmọ wọn nílé ìwé, kí ara òbí wọn yá, kí ẹni tí wọ́n ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ sì tẹ̀ síwájú.

^ ÀWÒRÁN: Arákùnrin ọ̀dọ́ kan ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà nítorí ẹbọ ìràpadà Jésù, ayé yìí tó rẹwà gan-an àtàwọn oúnjẹ aṣaralóore tó fún wa.

^ ÀWÒRÁN: Arábìnrin kan ń gbàdúrà pé kí Jèhófà máa fi ẹ̀mí ẹ̀ ran Ìgbìmọ̀ Olùdarí lọ́wọ́, kó sì tún ran àwọn tí àjálù dé bá àtàwọn tí wọ́n ń ṣenúnibíni sí lọ́wọ́.