Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 29

Ṣé Ò Ń Múra Sílẹ̀ De Ìpọ́njú Ńlá?

Ṣé Ò Ń Múra Sílẹ̀ De Ìpọ́njú Ńlá?

‘Ẹ múra sílẹ̀.’​—MÁT. 24:44.

ORIN 150 Wá Ọlọ́run Kó O Lè Rí Ìgbàlà

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ a

1. Kí nìdí tó fi bọ́gbọ́n mu pé ká múra sílẹ̀ de àjálù?

 TÉÈYÀN bá múra sílẹ̀ de ohun kan, ó lè gba ẹ̀mí ẹ̀ là. Bí àpẹẹrẹ, tí àjálù bá ṣẹlẹ̀, ó máa ń rọrùn fáwọn tó ti múra sílẹ̀ láti là á já, kí wọ́n sì ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́. Àjọ kan tó máa ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ nílẹ̀ Yúróòpù sọ pé: “Téèyàn bá múra sílẹ̀ dáadáa, ó lè gba ẹ̀mí ẹ̀ là.”

2. Kí nìdí tó fi yẹ ká múra sílẹ̀ de ìpọ́njú ńlá? (Mátíù 24:44)

2 Òjijì ni “ìpọ́njú ńlá” máa bẹ̀rẹ̀. (Mát. 24:21) Àwọn àjálù tó ń ṣẹlẹ̀ máa ń dé bá àwọn èèyàn lójijì, àmọ́ ìpọ́njú ńlá ò ní dé bá àwa kan lójijì torí a ti mọ̀ pé ó máa ṣẹlẹ̀. Kódà, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún méjì (2,000) sẹ́yìn ni Jésù ti kìlọ̀ fáwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ pé kí wọ́n máa múra sílẹ̀ de ọjọ́ yẹn. (Ka Mátíù 24:44.) Torí náà, tá a bá múra sílẹ̀, ó máa rọrùn fún wa láti fara da àkókò tó máa nira yẹn, àá sì lè ran àwọn míì lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀.​—Lúùkù 21:36.

3. Báwo ni ìfaradà, àánú àti ìfẹ́ ṣe máa mú ká múra sílẹ̀ de ìpọ́njú ńlá?

3 Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ànímọ́ mẹ́ta tó máa jẹ́ ká múra sílẹ̀ de ìpọ́njú ńlá. Kí la máa ṣe tí ètò Ọlọ́run bá ní ká lọ kéde ọ̀rọ̀ ìdájọ́ tó le fáwọn èèyàn, táwọn aláìgbàgbọ́ sì ń ta kò wá nítorí ìkéde náà? (Ìfi. 16:21) A máa nílò ìfaradà ká tó lè ṣe ohun tí Jèhófà sọ, ká sì gbà pé ó máa dáàbò bò wá. Kí la máa ṣe táwọn ará wa bá pàdánù díẹ̀ tàbí gbogbo nǹkan tí wọ́n ní? (Háb. 3:17, 18) Ó máa gba pé ká jẹ́ alàánú ká tó lè pèsè àwọn nǹkan tí wọ́n nílò. Nígbà tí àgbájọ àwọn orílẹ̀-èdè bá kọ lu àwa èèyàn Jèhófà, báwo la ṣe máa hùwà sáwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa tó bá ṣẹlẹ̀ pé inú ilé kékeré kan ni gbogbo wa jọ máa gbé fúngbà díẹ̀? (Ìsík. 38:10-12) Ó máa gba pé ká fi ìfẹ́ tó lágbára hàn sí wọn kí gbogbo wa lè la àkókò tí nǹkan nira yẹn já.

4. Kí ni Bíbélì sọ tó jẹ́ ká mọ̀ pé ó yẹ ká túbọ̀ máa nífaradà, àánú àti ìfẹ́?

4 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbà wá níyànjú pé ká ní ìfaradà, ká máa ṣàánú, ká sì ní ìfẹ́. Lúùkù 21:19 sọ pé: “Tí ẹ bá ní ìfaradà, ẹ máa lè pa ẹ̀mí yín mọ́.” Kólósè 3:12 náà sọ pé: ‘Ẹ fi àánú wọ ara yín láṣọ.’ 1 Tẹsalóníkà 4:9, 10 náà tún sọ pé: “Ọlọ́run ti kọ́ yín láti máa nífẹ̀ẹ́ ara yín. . . . Àmọ́, ẹ̀yin ará, a rọ̀ yín pé kí ẹ máa ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ.” Àwọn ọmọ ẹ̀yìn tí wọ́n ti fi hàn pé àwọn nífaradà, pé àwọn ń ṣàánú, àwọn sì nífẹ̀ẹ́ la kọ gbogbo ẹsẹ Bíbélì yìí sí. Síbẹ̀, ó pọn dandan pé kí wọ́n túbọ̀ máa fi àwọn ànímọ́ yìí hàn. Ohun tó sì yẹ káwa náà máa ṣe nìyẹn. Ká lè mọ bá a ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa bí àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ ṣe fi àwọn ànímọ́ yìí hàn. Lẹ́yìn náà, a máa rí bá a ṣe lè fara wé wọn, ìyẹn á sì jẹ́ ká lè múra sílẹ̀ de ìpọ́njú ńlá.

MÁA ṢE NǸKAN TÁÁ JẸ́ KÓ O TÚBỌ̀ NÍFARADÀ

5. Báwo làwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ ṣe fara da ìṣòro wọn?

5 Àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sáwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ gba pé kí wọ́n nífaradà. (Héb. 10:36) Wọ́n láwọn ìṣòro tó ń bá gbogbo èèyàn fínra nígbà yẹn, wọ́n tún láwọn ìṣòro míì torí pé Kristẹni ni wọ́n. Ọ̀pọ̀ lára wọn làwọn aṣáájú ẹ̀sìn àwọn Júù àtàwọn aláṣẹ Róòmù ṣenúnibíni sí. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn mọ̀lẹ́bí wọn náà tún ṣenúnibíni sí wọn. (Mát. 10:21) Bákan náà láwọn ìgbà míì, wọ́n tún gbọ́dọ̀ rí i pé àwọn ò jẹ́ kí ẹ̀kọ́ àwọn apẹ̀yìndà fa ìpínyà nínú ìjọ. (Ìṣe 20:29, 30) Síbẹ̀, àwọn Kristẹni yẹn fara dà á. (Ìfi. 2:3) Báwo ni wọ́n ṣe ṣe é? Wọ́n ronú lórí àwọn àpẹẹrẹ tó wà nínú Ìwé Mímọ́, irú bíi ti Jóòbù. (Jém. 5:10, 11) Wọ́n tún gbàdúrà pé kí Jèhófà fún àwọn lókun. (Ìṣe 4:29-31) Wọ́n sì fi sọ́kàn pé Jèhófà máa bù kún àwọn táwọn bá fara dà á.​—Ìṣe 5:41.

6. Kí lo kọ́ nínú bí Merita ṣe fara da àtakò?

6 Àwa náà lè fara dà á tá a bá ń kà nípa àwọn tó fara da ìṣòro nínú Bíbélì àtàwọn ìwé wa, tá a sì ń ronú lórí wọn. Ohun tó jẹ́ kí Arábìnrin Merita tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Alibéníà fara dà á nìyẹn nígbà tí ìdílé ẹ̀ ń fìyà jẹ ẹ́. Ó sọ pé: “Ìtàn Jóòbù tí mo kà nínú Bíbélì wọ̀ mí lọ́kàn gan-an. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó jìyà gan-an, tí ò sì mọ ẹni tó ń fa ìṣòro òun, ó sọ pé: ‘Títí màá fi kú, mi ò ní fi ìwà títọ́ mi sílẹ̀!’ (Jóòbù 27:5) Nígbà tí mo ronú nípa ẹ̀ dáadáa, mo rí i pé ìṣòro mi ò tó nǹkan kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ ti Jóòbù. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jóòbù ò mọ ẹni tó fa àwọn ìṣòro ẹ̀, èmi mọ ẹni tó ń fa àwọn ìṣòro mi.”

7. Tá ò bá tiẹ̀ láwọn ìṣòro tó le báyìí, kí ló yẹ ká máa ṣe?

7 Ohun tó máa jẹ́ ká túbọ̀ nífaradà ni pé ká máa gbàdúrà sí Jèhófà tọkàntọkàn nígbà gbogbo, ká sì máa sọ bí nǹkan ṣe rí lọ́kàn wa fún un. (Fílí. 4:6; 1 Tẹs. 5:17) O lè má ní àwọn ìṣòro tó ń bá ẹ fínra báyìí, àmọ́ ṣé o máa ń sọ pé kí Jèhófà ràn ẹ́ lọ́wọ́ tí inú bá ń bí ẹ, tó ò bá mọ nǹkan tó yẹ kó o ṣe tàbí tí nǹkan bá tojú sú ẹ? Tó bá ti mọ́ ẹ lára báyìí láti máa bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ tó o bá láwọn ìṣòro kéékèèké, á rọrùn fún ẹ láti ṣe bẹ́ẹ̀ tó o bá láwọn ìṣòro ńlá lọ́jọ́ iwájú. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, á dá ẹ lójú pé Jèhófà mọ bó ṣe máa ràn ẹ́ lọ́wọ́, ó sì mọ ìgbà tó yẹ kó ṣe bẹ́ẹ̀.​—Sm. 27:1, 3.

ÌFARADÀ

Tá a bá fara da ìṣòro èyíkéyìí tó dé bá wa, á jẹ́ ká lè fara da ìṣòro míì lọ́jọ́ iwájú (Wo ìpínrọ̀ 8)

8. Báwo ni àpẹẹrẹ Mira ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé tá a bá fara da ìṣòro báyìí, àá lè fara da ìṣòro lọ́jọ́ iwájú? (Jémíìsì 1:2-4) (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

8 Tá a bá ń fara da àwọn ìṣòro wa báyìí, á túbọ̀ rọrùn fún wa láti fara da àwọn ìṣòro tá a máa ní nígbà ìpọ́njú ńlá. (Róòmù 5:3) Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ọ̀pọ̀ àwọn ará ló sọ pé táwọn bá fara da ìṣòro kan, ó máa ń jẹ́ káwọn fara da àwọn ìṣòro míì tó bá yọjú. Gbogbo ìgbà tí Jèhófà bá ràn wọ́n lọ́wọ́ láti fara da ìṣòro ni ìgbàgbọ́ wọn túbọ̀ ń lágbára, ó sì dá wọn lójú pé Jèhófà máa ran àwọn lọ́wọ́ lọ́jọ́ iwájú. Ìgbàgbọ́ yìí ló ń jẹ́ kí wọ́n fara da ìṣòro míì tó bá yọjú. (Ka Jémíìsì 1:2-4.) Arábìnrin Mira tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà lórílẹ̀-èdè Alibéníà ti rí i pé bóun ṣe fara da àwọn ìṣòro tóun ní nígbà kan ti jẹ́ kóun máa fara da àwọn ìṣòro míì tóun ní báyìí. Ó sọ pé nígbà míì, ó máa ń ṣe òun bíi pé òun nìkan lòun níṣòro tó pọ̀. Àmọ́, ó máa ń rántí bí Jèhófà ṣe ń ran òun lọ́wọ́ láti nǹkan bí ogún (20) ọdún sẹ́yìn. Torí náà, ó máa ń sọ fún ara ẹ̀ pé: ‘Má fi Jèhófà sílẹ̀ torí pé ọ̀pọ̀ ọdún ló ti ń ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti fara da àwọn ìṣòro ẹ.’ Ìwọ náà lè ronú nípa bí Jèhófà ṣe ń ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti fara da àwọn ìṣòro ẹ. Mọ̀ dájú pé Jèhófà máa ń kíyè sí ẹ ní gbogbo ìgbà tó o bá fara da ìṣòro, ó sì máa bù kún ẹ. (Mát. 5:10-12) Tí ìpọ́njú ńlá bá fi máa bẹ̀rẹ̀, wàá ti kọ́ bó o ṣe lè fara da ọ̀pọ̀ nǹkan, o ò sì ní fẹ́ ṣe ohunkóhun tó máa jẹ́ kó o fi Jèhófà sílẹ̀.

MÁA FÀÁNÚ HÀN

9. Báwo làwọn ará tó wà ní ìjọ Áńtíókù ti Síríà ṣe fàánú hàn?

9 Ẹ jẹ́ ká wo nǹkan tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí ìyàn ńlá mú àwọn ará ní Jùdíà. Nígbà táwọn ará tó wà ní ìjọ Áńtíókù ti Síríà gbọ́ nípa ìyàn náà, ó dájú pé àánú àwọn ará tó wà ní Jùdíà ṣe wọ́n gan-an. Àmọ́, wọ́n ṣe ohun tó fi hàn pé àwọn káàánú wọn lóòótọ́. Torí náà wọ́n “pinnu, gẹ́gẹ́ bí ohun tí agbára kálukú wọn gbé, láti fi nǹkan ìrànwọ́ ránṣẹ́ sí àwọn ará tó ń gbé ní Jùdíà.” (Ìṣe 11:27-30) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ibi táwọn ará tí ìyàn náà mú ń gbé jìnnà gan-an, àwọn ará to wà ní Áńtíókù pinnu pé àwọn gbọ́dọ̀ ràn wọ́n lọ́wọ́.​—1 Jòh. 3:17, 18.

ÀÁNÚ

Tí àjálù bá ṣẹlẹ̀, a máa ń lo àsìkò yẹn láti fàánú hàn sáwọn èèyàn (Wo ìpínrọ̀ 10)

10. Báwo la ṣe lè fàánú hàn sáwọn ará wa tí àjálù bá ṣẹlẹ̀ sí wọn? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

10 Àwa náà lè fàánú hàn sáwọn ará wa lónìí tá a bá gbọ́ pé àjálù ṣẹlẹ̀ sí wọn. Bá a ṣe lè fi hàn pé à ń káàánú àwọn ará wa ni pé tí àjálù bá ṣẹlẹ̀ sí wọn, ká tètè béèrè lọ́wọ́ àwọn alàgbà bóyá a lè yọ̀ǹda ara wa láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn tó ń ṣèrànwọ́ nígbà àjálù. Yàtọ̀ síyẹn, a lè fowó ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ ìwàásù kárí ayé tàbí ká gbàdúrà fáwọn tí àjálù dé bá. b (Òwe 17:17) Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún 2020, kí ètò Ọlọ́run lè bójú tó àwọn ará wa kárí ayé nígbà àjàkálẹ̀ àrùn kòrónà, iye Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù tí ètò Ọlọ́run yàn ju ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án ó lé àádọ́ta (950) lọ. Ẹ ò rí i pé ó yẹ ká gbóríyìn fún gbogbo àwọn tó wà nínú ìgbìmọ̀ yìí àtàwọn tó bá wọn ṣiṣẹ́! Torí pé wọ́n fẹ́ fàánú hàn sáwọn ará, wọ́n pín àwọn nǹkan tí wọ́n nílò fún wọn, wọ́n ṣètò ìpàdé àtàwọn àsọyé tó máa gbé àwọn ará ró. Kódà láwọn ibì kan, wọ́n tún ilé àwọn ará kọ́ àti Ilé Ìpàdé, wọ́n sì tún àwọn míì ṣe.​—Fi wé 2 Kọ́ríńtì 8:1-4.

11. Tá a bá ń ṣàánú àwọn èèyàn, báwo nìyẹn ṣe ń fògo fún Jèhófà?

11 Tá a bá fàánú hàn sáwọn tí àjálù ṣẹlẹ̀ sí, àwọn èèyàn máa kíyè sí ohun tá a ṣe. Bí àpẹẹrẹ lọ́dún 2019, ìjì líle kan tó ń jẹ́ Hurricane Dorian ba Ilé Ìpàdé wa kan jẹ́ lórílẹ̀-èdè Bahamas. Nígbà táwọn ará wa ń tún Ilé Ìpàdé náà kọ́, wọ́n ní kí agbaṣẹ́ṣe kan tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ iye tó máa gbà láti bá wọn ṣe àwọn iṣẹ́ kan níbẹ̀. Ó sọ fún wọn pé: “Màá yá yín láwọn irinṣẹ́ tẹ́ ẹ máa lò, . . . màá kó àwọn òṣìṣẹ́ wá, màá sì tún fún yín láwọn ohun tẹ́ ẹ máa fi ṣiṣẹ́ náà. . . . Ó kàn wù mí kí n ran ẹ̀yin Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́wọ́ ni. Iṣẹ́ tẹ́ ẹ̀ ń ṣe níbí àti bẹ́ ẹ ṣe ń ran ara yín lọ́wọ́ wú mi lórí gan-an.” Ọ̀pọ̀ èèyàn nínú ayé ni ò mọ Jèhófà rárá. Àmọ́ ọ̀pọ̀ lára wọn ló ń rí báwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá ló jẹ́ pé àánú tá à ń fi hàn sáwọn èèyàn lè mú kí wọ́n wá jọ́sìn “Ọlọ́run tí àánú rẹ̀ pọ̀”!​—Éfé. 2:4.

12. Tá a bá ń fàánú hàn sáwọn èèyàn báyìí, báwo nìyẹn ṣe máa múra wa sílẹ̀ de ìpọ́njú ńlá? (Ìfihàn 13:16, 17)

12 Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká fàánú hàn sáwọn èèyàn tó bá dìgbà ìpọ́njú ńlá? Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn tí ò bá ti àwọn olóṣèlú lẹ́yìn máa ní ìṣòro lákòókò yìí àti nígbà ìpọ́njú ńlá. (Ka Ìfihàn 13:16, 17.) Ó lè pọn dandan pé ká ran àwọn ará wa lọ́wọ́ kí wọ́n lè rí oúnjẹ àtàwọn nǹkan míì tí wọ́n nílò. Torí náà, tí Jésù Kristi Ọba wa bá dé láti ṣèdájọ́ ayé burúkú yìí, ó máa rí i pé à ń fàánú hàn sáwọn èèyàn, á sì pè wá pé ká wá “jogún Ìjọba” náà.​—Mát. 25:34-40.

TÚBỌ̀ MÁA FÌFẸ́ HÀN SÁWỌN ARÁ

13. Kí ni Róòmù 15:7 sọ pé àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ ṣe tó jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ ara wọn?

13 Nígbà ayé àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀, gbogbo èèyàn ló mọ̀ pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn. Àmọ́ ṣé ó rọrùn láti máa fìfẹ́ hàn síra wọn? Ẹ jẹ́ ká wo irú àwọn èèyàn tó wà nínú ìjọ Róòmù. Báwọn Júù tó mọ Òfin Mósè láti kékeré ṣe wà níbẹ̀ náà ni àwọn Kèfèrí tí àṣà wọn yàtọ̀ sí tàwọn Júù wà níbẹ̀. Ó ṣeé ṣe káwọn Kristẹni kan jẹ́ ẹrú, àwọn Kristẹni míì kì í sì í ṣe ẹrú. Kódà, àwọn Kristẹni kan láwọn ẹrú tó ń ṣiṣẹ́ fún wọn. Torí náà, báwo làwọn Kristẹni yẹn á ṣe máa fìfẹ́ hàn síra wọn bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n lówó ju ara wọn lọ, tí àṣà wọn sì yàtọ̀ síra? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbà wọ́n níyànjú pé: “Ẹ tẹ́wọ́ gba ara yín.” (Ka Róòmù 15:7.) Kí ló ní lọ́kàn? Ọ̀rọ̀ tá a tú sí “tẹ́wọ́ gbà” túmọ̀ sí pé ká gba ẹnì kan sílé wa, ká fún un lóúnjẹ tàbí ká máa bá a ṣọ̀rẹ́. Bí àpẹẹrẹ, Pọ́ọ̀lù sọ fún Fílémónì pé kó “fi ìfẹ́ gba” Ónísímù ìránṣẹ́ ẹ̀ tó sá kúrò lọ́dọ̀ ẹ̀ tọwọ́tẹsẹ̀. (Fílém. 17) Pírísílà àti Ákúílà náà gba Àpólò tọwọ́tẹsẹ̀, wọ́n sì “mú un wọ àwùjọ wọn” bó tiẹ̀ jẹ́ pé nǹkan tó mọ̀ nípa ẹ̀sìn Kristẹni ò tó nǹkan. (Ìṣe 18:26) Àwọn Kristẹni yẹn ò jẹ́ kí àṣà ìbílẹ̀ wọn àtàwọn nǹkan míì fa ìpínyà láàárín wọn, dípò bẹ́ẹ̀ ṣe ni wọ́n fìfẹ́ gba ara wọn tọwọ́tẹsẹ̀.

ÌFẸ́

Ìfẹ́ táwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa fi hàn sí wa máa ń jẹ́ ká fara da ìṣòro (Wo ìpínrọ̀ 15)

14. Báwo ni Arábìnrin Anna àti ọkọ ẹ̀ ṣe fìfẹ́ hàn sáwọn ará?

14 Àwa náà lè fìfẹ́ hàn sáwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa tá a bá ń bá wọn ṣọ̀rẹ́. Tí wọ́n bá rí bá a ṣe ń fìfẹ́ hàn sí wọn, àwọn náà máa fìfẹ́ hàn sí wa. (2 Kọ́r. 6:11-13) Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Arábìnrin Anna àti ọkọ ẹ̀. Iṣẹ́ míṣọ́nnárì ni wọ́n ń ṣe, àmọ́ kò pẹ́ tí wọ́n dé Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà ni àrùn kòrónà bẹ̀rẹ̀. Torí pé àjàkálẹ̀ àrùn náà ń jà ràn-ìn, wọn ò lè ṣèpàdé pẹ̀lú àwọn ará lójúkojú, ìyẹn ò sì jẹ́ kí wọ́n mọ àwọn ará náà dáadáa. Àmọ́ báwo ni tọkọtaya yìí á ṣe fìfẹ́ hàn sáwọn ará? Wọ́n máa ń bá àwọn ará sọ̀rọ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, wọ́n máa ń tan fídíò wọn kí wọ́n lè ríra wọn, wọ́n sì máa ń sọ fún wọn pé ó wu àwọn láti mọ̀ wọ́n sí i. Àwọn ìdílé tí wọ́n ń pè mọyì ẹ̀ gan-an, torí náà, àwọn náà máa ń pè wọ́n, wọ́n sì máa ń fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí wọn lórí fóònù. Kí nìdí tí tọkọtaya yìí fi ṣe gbogbo ohun tí wọ́n ṣe yìí? Anna sọ pé: “Ìfẹ́ táwọn ará fi hàn sí èmi àti ìdílé mi nígbà dídùn àti nígbà kíkan wú mi lórí gan-an. Torí náà, mo pinnu pé gbogbo ìgbà lèmi náà á máa fìfẹ́ hàn sáwọn ará.”

15. Kí lo rí kọ́ lára Vanessa nípa bó ṣe yẹ ká nífẹ̀ẹ́ gbogbo àwọn ará? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

15 Ọ̀pọ̀ lára wa ló wà nínú ìjọ tí ìwà àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa yàtọ̀ síra, tí wọ́n sì wá láti ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ìfẹ́ tá a ní sí wọn á túbọ̀ máa lágbára tá a bá ń wo ibi tí wọ́n dáa sí. Kò rọrùn fún Arábìnrin Vanessa tó ń sìn ní New Zealand láti máa bá àwọn kan nínú ìjọ ẹ̀ ṣọ̀rẹ́. Àmọ́ ó pinnu pé dípò tóun á fi máa yẹra fáwọn tí ìwà wọn máa ń bí òun nínú, òun á túbọ̀ lo àkókò pẹ̀lú wọn. Nígbà tó ṣe bẹ́ẹ̀, ó rí i pé àwọn nǹkan kan wà tí Jèhófà rí lára wọn tó jẹ́ kó nífẹ̀ẹ́ wọn. Ó sọ pé: “Látìgbà tí ọkọ mi ti di alábòójútó àyíká, a ti láǹfààní láti wà pẹ̀lú ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tí ìwà wọn yàtọ̀ síra, mo máa ń bá wọn ṣe nǹkan pa pọ̀, mo sì ń gbádùn ẹ̀. Ní báyìí, mo nífẹ̀ẹ́ gbogbo àwọn ará wa tí wọ́n wá láti ibi tó yàtọ̀ síra. Jèhófà náà nífẹ̀ẹ́ wọn torí gbogbo èèyàn ló pè láti wá jọ́sìn òun.” Torí náà, tá a bá ń wo àwọn èèyàn bí Jèhófà ṣe ń wò wọ́n, à ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ wọn nìyẹn.​—2 Kọ́r. 8:24.

Jèhófà ṣèlérí pé nígbà ìpọ́njú ńlá, òun máa dáàbò bò wá tá a bá ń jọ́sìn nìṣó pẹ̀lú àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa (Wo ìpínrọ̀ 16)

16. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa nígbà ìpọ́njú ńlá? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

16 Ó ṣe pàtàkì pé ká nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa nígbà ìpọ́njú ńlá. Nígbà tí ìpọ́njú ńlá bá bẹ̀rẹ̀, báwo ni Jèhófà ṣe máa dáàbò bò wá? Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí Jèhófà ní káwọn èèyàn òun ṣe nígbà táwọn kan gbógun ja ìlú Bábílónì àtijọ́. Ó sọ pé: “Ẹ lọ, ẹ̀yin èèyàn mi, ẹ wọnú yàrá yín tó wà ní inú, kí ẹ sì ti àwọn ilẹ̀kùn yín mọ́ ara yín. Ẹ fi ara yín pa mọ́ fúngbà díẹ̀, títí ìbínú náà fi máa kọjá lọ.” (Àìsá. 26:20) Ó ṣeé ṣe káwa náà tẹ̀ lé irú ìmọ̀ràn yìí nígbà ìpọ́njú ńlá. ‘Yàrá inú lọ́hùn-ún’ tí ẹsẹ Bíbélì yìí sọ lè jẹ́ àwọn ìjọ wa. Jèhófà ṣèlérí pé tó bá dìgbà ìpọ́njú ńlá, òun máa dáàbò bò wá tá a bá ń jọ́sìn nìṣó pẹ̀lú àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa. Torí náà, a gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ kára báyìí kí ìfẹ́ tá a ní fáwọn ará wa lè túbọ̀ lágbára láìka ìwà wọn sí. Ó lè jẹ́ ohun tó máa gba ẹ̀mí wa là nìyẹn!

MÁA MÚRA SÍLẸ̀ BÁYÌÍ

17. Tá a bá ń múra sílẹ̀ báyìí, kí nìyẹn máa jẹ́ ká ṣe nígbà ìpọ́njú ńlá?

17 Tí “ọjọ́ ńlá Jèhófà” bá dé, nǹkan máa nira fún gbogbo èèyàn. (Sef. 1:14, 15) Nǹkan sì máa nira fáwa èèyàn Jèhófà náà. Àmọ́ tá a bá ń múra sílẹ̀ báyìí, ọkàn wa máa balẹ̀, àá sì tún lè ran àwọn ará wa lọ́wọ́. Á tún jẹ́ ká lè fara da ìṣòro yòówù kó dé bá wa. Táwọn ará wa bá níṣòro, ó yẹ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́, ká fàánú hàn sí wọn, ká sì fún wọn lóhun tí wọ́n nílò. Torí náà, tá a bá nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa báyìí, ó máa rọrùn fún wa láti ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà máa jẹ́ ká ní ìyè àìnípẹ̀kun nínú ayé tuntun, níbi tí kò ti ní sí àjálù àti ìpọ́njú mọ́.​—Àìsá. 65:17.

ORIN 144 Tẹjú Mọ́ Èrè Náà

a Láìpẹ́, ìpọ́njú ńlá máa bẹ̀rẹ̀. Irú ìpọ́njú ńlá yìí ò tíì wáyé rí, àmọ́ tá a bá fẹ́ fi hàn pé à ń múra sílẹ̀, a gbọ́dọ̀ ní ìfaradà, ká jẹ́ aláàánú, ká sì nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa rí bí àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ ṣe ṣe ohun tó fi hàn pé wọ́n láwọn ànímọ́ yìí, a tún máa rí bá a ṣe lè fara wé wọn àti báwọn ànímọ́ yẹn ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti múra sílẹ̀ de ìpọ́njú ńlá.

b Àwọn tó bá fẹ́ ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù máa kọ́kọ́ gba fọ́ọ̀mù Local Design/Construction Volunteer Application (DC-50) tàbí fọ́ọ̀mù Application for Volunteer Program (A-19), wọ́n á sì ní sùúrù dìgbà tí wọ́n máa pè wọ́n.