Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 31

“Ẹ Dúró Gbọn-in, Ẹ Má Yẹsẹ̀”

“Ẹ Dúró Gbọn-in, Ẹ Má Yẹsẹ̀”

“Ẹ̀yin ará mi ọ̀wọ́n, ẹ dúró gbọn-in, ẹ má yẹsẹ̀.” ​—1 KỌ́R. 15:58.

ORIN 122 Ẹ Fẹsẹ̀ Múlẹ̀ Ṣinṣin

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ a

1-2. Báwo làwa Kristẹni ṣe dà bí ilé gogoro? (1 Kọ́ríńtì 15:58)

 LỌ́DÚN 1978, wọ́n kọ́ ilé tó ní ọgọ́ta (60) àjà sílùú Tokyo, lórílẹ̀-èdè Japan, òun sì ni ilé tó ga jù nílùú yẹn. Àmọ́, nítorí ìmìtìtì ilẹ̀ tó máa ń ṣẹlẹ̀ nílùú yẹn, àwọn èèyàn rò pé ilé náà máa wó. Báwo ni wọ́n ṣe kọ́ ilé náà tí kò fi wó nígbà tí ìmìtìtì ilẹ̀ ṣẹlẹ̀? Àwọn tó kọ́ ilé náà ṣe ìpìlẹ̀ ẹ̀ lọ́nà tó dúró digbí, ó sì lè fì sọ́tùn-ún fì sósì débi pé tí ìmìtìtì ilẹ̀ bá ṣẹlẹ̀ ilé náà ò ní wó. Àwa Kristẹni náà dà bí ilé gogoro yẹn. Lọ́nà wo?

2 Àwa Kristẹni gbọ́dọ̀ dúró gbọin-in, a ò sì gbọ́dọ̀ fọwọ́ tó le jù mú nǹkan. Ó yẹ ká jẹ́ adúróṣinṣin tó bá dọ̀rọ̀ ká tẹ̀ lé òfin àtàwọn ìlànà Jèhófà. (Ka 1 Kọ́ríńtì 15:58.) Ó tún yẹ ká “ṣe tán láti ṣègbọràn,” ká má sì yí ìpinnu wa pa dà. Àmọ́ ṣá o, ó yẹ ká jẹ́ ẹni tó ń “fòye báni lò” tàbí ẹni tó máa ń gba tàwọn ẹlòmíì rò tá a bá rí ibi tó yẹ ká ti ṣe bẹ́ẹ̀. (Jém. 3:17) Tí Kristẹni kan bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, kò ní jẹ́ ẹni tó ń fọwọ́ tó le jù mú nǹkan, kò sì ní jẹ́ ẹni tó ń fọwọ́ yẹpẹrẹ mú nǹkan. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa ohun tá a lè ṣe tí ò ní jẹ́ ká yí ìpinnu wa pa dà. A tún máa mọ nǹkan márùn-ún tí Sátánì ń lò tó lè mú ká ṣàìgbọràn sí Jèhófà àtohun tá a lè ṣe tí ò fi ní rí wa mú.

BÁWO LA ṢE LÈ JẸ́ ADÚRÓṢINṢIN?

3. Àwọn òfin wo ni Afúnnilófin Tó Ga Jù Lọ fún wa nínú Ìṣe 15:28, 29?

3 Torí pé Jèhófà ni Afúnnilófin Tó Ga Jù Lọ, léraléra ló máa ń fún àwa èèyàn ẹ̀ lófin tí ò lọ́jú pọ̀. (Àìsá. 33:22) Bí àpẹẹrẹ, ìgbìmọ̀ olùdarí ìgbà ayé àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ sọ nǹkan mẹ́ta tó yẹ ká máa ṣe ká lè jẹ́ adúróṣinṣin: (1) ká sá fún ìbọ̀rìṣà, ká sì máa sin Jèhófà nìkan, (2) ká máa pa òfin Jèhófà mọ́ lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀jẹ̀ àti (3) ká máa sá fún ìṣekúṣe. (Ka Ìṣe 15:28, 29.) Báwo làwa Kristẹni ṣe lè jẹ́ adúróṣinṣin nínú nǹkan mẹ́ta yìí?

4. Tá a bá fẹ́ fi hàn pé Jèhófà nìkan là ń jọ́sìn, kí ni ò yẹ ká máa ṣe? (Ìfihàn 4:11)

4 Ó yẹ ká máa sá fún ìbọ̀rìṣà, ká sì máa sin Jèhófà nìkan. Jèhófà pàṣẹ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé òun nìkan ni wọ́n gbọ́dọ̀ máa jọ́sìn. (Diu. 5:6-10) Kódà, nígbà tí Èṣù dán Jésù wò, ó sọ fún un pé Jèhófà nìkan la gbọ́dọ̀ jọ́sìn. (Mát. 4:8-10) Torí náà, àwa Kristẹni kì í lo ère nínú ìjọsìn wa. Bákan náà, a kì í sọ àwọn èèyàn di ọlọ́run, bóyá olórí ẹ̀sìn ni wọ́n, olóṣèlú, ìlúmọ̀ọ́ká eléré ìdárayá tàbí gbajúgbajà òṣèré. Dípò bẹ́ẹ̀, Jèhófà nìkan ló yẹ ká máa ṣègbọràn sí, òun nìkan ló sì yẹ ká máa jọ́sìn torí pé òun ló “dá ohun gbogbo.”​—Ka Ìfihàn 4:11.

5. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ṣègbọràn sí òfin Jèhófà tó sọ pé ohun mímọ́ ni ẹ̀mí àti ẹ̀jẹ̀?

5 A máa ń ṣègbọràn sí òfin Jèhófà tó sọ pé ohun mímọ́ ni ẹ̀mí àti ẹ̀jẹ̀. Kí nìdí? Ìdí ni pé Jèhófà sọ pé ẹ̀jẹ̀ ni ẹ̀mí, òun ló sì fún wa ní ẹ̀bùn pàtàkì náà. (Léf. 17:14) Nígbà tí Jèhófà kọ́kọ́ sọ fáwọn èèyàn pé wọ́n lè jẹ ẹran, ó ní wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀. (Jẹ́n. 9:4) Ó tún sọ òfin yìí fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì nínú Òfin Mósè. (Léf. 17:10) Bákan náà, ẹ̀mí mímọ́ darí ìgbìmọ̀ olùdarí ìgbà ayé àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ láti sọ fáwọn Kristẹni pé kí wọ́n “ta kété sí ẹ̀jẹ̀.” (Ìṣe 15:28, 29) Torí náà, ó yẹ ká ṣègbọràn sí òfin yìí tó bá kan irú ìtọ́jú tá a máa gbà nílé ìwòsàn. b

6. Kí la lè ṣe táá jẹ́ ká ṣègbọràn sí òfin Ọlọ́run tó sọ pé ìṣekúṣe ò dáa?

6 À ń ṣègbọràn sí òfin Ọlọ́run tó sọ pé ìṣekúṣe ò dáa. (Héb. 13:4) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lo àfiwé kan tó fi gbà wá níyànjú pé ká sọ àwọn ẹ̀yà ara wa “di òkú,” ìyẹn ni pé ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti mú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ kúrò lọ́kàn wa. A ò ní máa wo ohunkóhun tàbí ṣe ohunkóhun tó lè mú ká ṣèṣekúṣe. (Kól. 3:5; Jóòbù 31:1) Tí ọkàn wa bá ń fà sí nǹkan burúkú, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló yẹ ká gbé èrò náà kúrò lọ́kàn, ká má bàa ṣe ohun tó máa ba àjọṣe àwa àti Jèhófà jẹ́.

7. Kí ló yẹ ká pinnu pé a máa ṣe, kí sì nìdí?

7 Jèhófà retí pé ká “ṣègbọràn látọkàn wá.” (Róòmù 6:17) Ó máa ń tọ́ wa sọ́nà torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wa. Torí náà, a ò gbọ́dọ̀ pa àwọn òfin ẹ̀ kan mọ́ ká wá pa àwọn kan tì, gbogbo ẹ̀ la gbọ́dọ̀ pa mọ́. (Àìsá. 48:17, 18; 1 Kọ́r. 6:9, 10) Ó yẹ ká sapá láti máa ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́, ká sì fara wé onísáàmù tó sọ pé: “Mo ti pinnu láti máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà rẹ nígbà gbogbo, màá sì ṣe bẹ́ẹ̀ délẹ̀délẹ̀.” (Sm. 119:112) Àmọ́, Sátánì ò ní fẹ́ ká máa ṣègbọràn sí Jèhófà. Àwọn nǹkan wo ló máa ń lò láti mú ká ṣàìgbọràn?

ÀWỌN NǸKAN WO NI SÁTÁNÌ MÁA Ń LÒ LÁTI MÚ KÁ ṢÀÌGBỌRÀN?

8. Báwo ni Sátánì ṣe ń lo inúnibíni láti mú ká ṣàìgbọràn?

8 Inúnibíni. Èṣù máa ń lo àwọn èèyàn láti fìyà jẹ wá, kí wọ́n sì fúngun mọ́ wa ká lè ṣe ohun tí Jèhófà ò fẹ́. Ohun tó ń wá ni bó ṣe máa ‘pa wá jẹ,’ kí àjọṣe àwa àti Jèhófà lè bà jẹ́. (1 Pét. 5:8) Nígbà ayé àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀, àwọn èèyàn halẹ̀ mọ́ wọn, wọ́n nà wọ́n lẹ́gba, wọ́n sì pa àwọn kan lára wọn torí pé wọ́n jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. (Ìṣe 5:27, 28, 40; 7:54-60) Sátánì ṣì ń lo inúnibíni lónìí. Ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sáwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà àtàwọn orílẹ̀-èdè míì jẹ́ ká rí i pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn alátakò tún máa ń ṣenúnibíni sáwọn ará wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan.

9. Báwo la ṣe lè yẹra fún ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ Sátánì? Ṣàlàyé.

9 Ọgbọ́n ẹ̀wẹ́. Yàtọ̀ sí inúnibíni tó le, Sátánì tún máa ń lo “àrékérekè” láti mú ká ṣe ohun tí Jèhófà ò fẹ́. (Éfé. 6:11) Bí àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Arákùnrin Bob nígbà tí wọ́n fẹ́ ṣiṣẹ́ abẹ tó gbẹgẹ́ fún un nílé ìwòsàn. Ó sọ fáwọn dókítà pé ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀, òun ò ní gbẹ̀jẹ̀. Dókítà tó fẹ́ ṣiṣẹ́ abẹ náà fún un fara mọ́ ohun tó sọ. Àmọ́, ní alẹ́ tó ṣáájú ọjọ́ tí wọ́n fẹ́ ṣiṣẹ́ abẹ náà, ọ̀kan lára àwọn dókítà tó fẹ́ tọ́jú Bob wá sọ́dọ̀ ẹ̀ lẹ́yìn táwọn ìdílé ẹ̀ ti lọ sílé, ó sì sọ fún un pé wọn ò ní fa ẹ̀jẹ̀ sí i lára, àmọ́ ẹ̀jẹ̀ máa wà lárọ̀ọ́wọ́tó tó bá máa gba pé kí wọ́n fà á sí i lára. Dókítà náà rò pé Bob máa yí ìpinnu ẹ̀ pa dà táwọn ará ilé ẹ̀ ò bá sí níbẹ̀. Àmọ́ Bob ò yí ìpinnu ẹ̀ pa dà, ó sì sọ pé ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀, òun ò ní gbẹ̀jẹ̀.

10. Báwo ni ìrònú èèyàn ṣe lè dẹkùn mú wa? (1 Kọ́ríńtì 3:19, 20)

10 Ìrònú èèyàn. Tá a bá ń ronú bí àwọn tí kì í tẹ̀ lé ìlànà Jèhófà ṣe ń ronú, ó lè jẹ́ ká pa Jèhófà àtàwọn ìlànà ẹ̀ tì. (Ka 1 Kọ́ríńtì 3:19, 20.) “Ọgbọ́n ayé yìí” máa ń jẹ́ káwọn èèyàn ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run. Àwọn Kristẹni kan tó wà nílùú Págámù àti Tíátírà ń bọ̀rìṣà, wọ́n sì ń ṣèṣekúṣe bíi tàwọn ará ìlú náà. Jésù bá ìjọ méjèèjì yìí wí lọ́nà tó le torí pé wọ́n gba ìṣekúṣe láyè. (Ìfi. 2:14, 20) Bákan náà lónìí, àwọn èèyàn ń fúngun mọ́ wa pé ká ṣàìgbọràn sí Jèhófà, àwọn ará ilé wa àtàwọn ọ̀rẹ́ wa sì lè fẹ́ ká ṣe ohun tí Jèhófà ò fẹ́. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n lè sọ pé kò sóhun tó burú tá a bá ṣèṣekúṣe àti pé àwọn ìlànà Bíbélì ò bóde mu mọ́.

11. Bá a ṣe jẹ́ olóòótọ́, kí ni ò yẹ ká ṣe?

11 Nígbà míì, a lè máa rò pé Jèhófà ò sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa ohun tó fẹ́ ká ṣe. Kódà, ó lè máa ṣe wá bíi pé ká “kọjá àwọn ohun tó wà lákọsílẹ̀.” (1 Kọ́r. 4:6) Àwọn olórí ẹ̀sìn ìgbà ayé Jésù ò tẹ̀ lé ìlànà yìí. Yàtọ̀ sí Òfin Mósè, wọ́n gbé ìlànà tara wọn kalẹ̀, kí wọ́n lè máa fi ni àwọn tálákà lára. (Mát. 23:4) Lónìí, Jèhófà ń tọ́ àwa náà sọ́nà nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti ètò rẹ̀. Kò yẹ ká fi kún ohun tí Jèhófà ń sọ fún wa. (Òwe 3:5-7) Torí náà, kò yẹ ká kọjá ohun tó wà lákọsílẹ̀ nínú Bíbélì, kò sì yẹ ká máa ṣòfin fáwọn ará wa lórí ọ̀rọ̀ tí Bíbélì ò sọ nǹkan kan nípa ẹ̀.

12. Báwo ni Sátánì ṣe ń lo “ìtànjẹ” láti mú wa?

12 Ìtànjẹ. Sátánì máa ń lo “ìtànjẹ” àti “àwọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀ ayé” láti ṣi àwọn èèyàn lọ́nà, kó sì dá ìyapa sáàárín wọn. (Kól. 2:8) Nígbà ayé àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀, lára ohun tí Sátánì máa ń lò láti tan àwọn èèyàn jẹ ni ọgbọ́n orí tí wọ́n fi ń kọ́ àwọn èèyàn, ẹ̀kọ́ àwọn Júù tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu àti pé dandan ni káwọn Kristẹni máa pa Òfin Mósè mọ́. Ìtànjẹ ni gbogbo ẹ̀ torí àwọn nǹkan yìí kì í jẹ́ káwọn èèyàn ṣe ìfẹ́ Jèhófà, ẹni tí ọgbọ́n tòótọ́ wá látọ̀dọ̀ ẹ̀. Lónìí, Sátánì máa ń lo ilé iṣẹ́ ìròyìn àti ìkànnì àjọlò láti tan irọ́ kálẹ̀, ó sì tún máa ń lo ìròyìn tí ò jóòótọ́ táwọn olórí olóṣèlú máa ń gbé jáde nílé iṣẹ́ ìròyìn. Wọ́n gbé irú ìròyìn bẹ́ẹ̀ jáde nígbà àjàkálẹ̀ àrùn kòrónà. c Ọkàn àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó tẹ̀ lé ohun tí ètò Ọlọ́run sọ balẹ̀, àmọ́ wàhálà bá àwọn tó fetí sí ìròyìn èké táwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn gbé jáde.​—Mát. 24:45.

13. Kí nìdí tí ò fi yẹ ká jẹ́ kí ohunkóhun pín ọkàn wa níyà?

13 Ìpínyà ọkàn. Ó yẹ ká gbájú mọ́ “àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù.” (Fílí. 1:9, 10) Ìpínyà ọkàn lè jẹ́ ká máa fi àkókò wa ṣòfò, dípò ká máa fi ṣe àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù. Bí àpẹẹrẹ, ohun tá a máa jẹ, tá a máa mu, eré ìnàjú àti iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wa lè má jẹ́ ká ráyè mọ́ láti ṣe àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì jù. (Lúùkù 21:34, 35) Yàtọ̀ síyẹn, ojoojúmọ́ là ń gbọ́ ìròyìn nípa ọ̀rọ̀ òṣèlú àti ọ̀rọ̀ táwọn èèyàn ń bá ara wọn fà láàárín ìlú. Torí náà, a gbọ́dọ̀ rí i dájú pé a ò dá sí àríyànjiyàn tó ń lọ láàárín àwọn ará ìlú. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í gbè sẹ́yìn àwọn kan nínú ọkàn wa. Gbogbo àwọn nǹkan tá a ti sọ yìí ni Sátánì máa ń lò láti mú ká ṣe ohun tí Jèhófà ò fẹ́. Torí náà ní báyìí, ẹ jẹ́ ká wo àwọn nǹkan tá a lè ṣe ká lè jẹ́ olóòótọ́, kí Sátánì má bàa rí wa mú.

KÍ LÁ JẸ́ KÁ MÁA SIN JÈHÓFÀ NÌṢÓ?

Ká lè jẹ́ adúróṣinṣin, ó yẹ ká máa ronú nípa ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi tá a ṣe, ká máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé ká sì máa ṣàṣàrò, ká má ṣe yí ìpinnu wa pa dà, ká sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà (Wo ìpínrọ̀ 14-18)

14. Kí lá jẹ́ ká máa sin Jèhófà nìṣó?

14 Máa ronú nípa ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi tó o ṣe. Ìdí tó o fi ya ara ẹ sí mímọ́ tó o sì ṣèrìbọmi ni pé Jèhófà ló wù ẹ́ pé kó o máa ṣègbọràn sí. Máa rántí àwọn nǹkan tó jẹ́ kó o gbà pé o ti rí òtítọ́. Ẹ̀kọ́ Bíbélì tó o kọ́ ló jẹ́ kó o mọ Jèhófà Bàbá rẹ ọ̀run, ó ti jẹ́ kó o máa bọ̀wọ̀ fún un, kó o sì nífẹ̀ẹ́ ẹ̀. Ẹ̀kọ́ tó o kọ́ tún jẹ́ kó o nígbàgbọ́, kó o sì ronú pìwà dà. O ti fi àwọn ìwà tí inú Ọlọ́run ò dùn sí sílẹ̀, o sì ń ṣe ohun tó fẹ́. Ara tù ẹ́ nígbà tó o mọ̀ pé Ọlọ́run ti dárí jì ẹ́. (Sm. 32:1, 2) O bẹ̀rẹ̀ sí í wá sípàdé ìjọ, o sì ń sọ àwọn nǹkan àgbàyanu tó o ti kọ́ fáwọn èèyàn. Ní báyìí tó o ti ya ara ẹ sí mímọ́, tó o sì ti ṣèrìbọmi, o ti bẹ̀rẹ̀ sí í rìn ní ọ̀nà ìyè, o sì ti pinnu pé o ò ní kúrò níbẹ̀.​—Mát. 7:13, 14.

15. Àǹfààní wo la máa rí tá a bá ń dá kẹ́kọ̀ọ́, tá a sì ń ṣàṣàrò?

15 Máa dá kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kó o sì máa ṣàṣàrò. Igi kan máa lágbára tí gbòǹgbò ẹ̀ bá fìdí múlẹ̀. Lọ́nà kan náà, ìgbàgbọ́ wa máa lágbára tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Bí igi náà bá ṣe ń dàgbà, bẹ́ẹ̀ náà ni gbòǹgbò ẹ̀ á máa fìdí múlẹ̀, táá sì máa tóbi sí i. Táwa náà bá ń dá kẹ́kọ̀ọ́, tá a sì ń ṣàṣàrò, ìgbàgbọ́ wa á máa lágbára sí i, á sì túbọ̀ dá wa lójú pé àwọn ìlànà Ọlọ́run ló dáa jù lọ. (Kól. 2:6, 7) Máa ronú nípa bí ìtọ́sọ́nà, ìmọ̀ràn àti ààbò Jèhófà ṣe ran àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ lọ́wọ́ nígbà àtijọ́. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Ìsíkíẹ́lì rí ìran, ó rí áńgẹ́lì kan tó ń wọn tẹ́ńpìlì, ó sì fọkàn sí gbogbo àlàyé tí áńgẹ́lì náà ṣe. Ìran yìí fún Ìsíkíẹ́lì lókun, ó sì jẹ́ káwa náà mọ bá a ṣe lè tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà nínú ìjọsìn mímọ́. d (Ìsík. 40:1-4; 43:10-12) Àwa náà máa jàǹfààní tá a bá ń dá kẹ́kọ̀ọ́, tá a sì ń ṣàṣàrò nípa àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tó jinlẹ̀.

16. Torí pé Bob ò yí ìpinnu ẹ̀ pa dà, báwo nìyẹn ṣe dáàbò bò ó? (Sáàmù 112:7)

16 Má ṣe yí ìpinnu ẹ pa dà. Ọba Dáfídì sọ pé òun ò ní fi Jèhófà sílẹ̀ láé torí pé òun nífẹ̀ẹ́ ẹ̀. Ó ní: “Ọkàn mi dúró ṣinṣin, Ọlọ́run.” (Sm. 57:7) Àwa náà lè jẹ́ adúróṣinṣin, ká sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. (Ka Sáàmù 112:7.) Ẹ jẹ́ ká wo bí ìdúróṣinṣin ṣe ran Bob tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan lọ́wọ́. Nígbà tí wọ́n sọ fún un pé wọ́n máa tọ́jú ẹ̀jẹ̀ pa mọ́ síbì kan tó bá ṣẹlẹ̀ pé wọ́n máa nílò ẹ̀, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló sọ pé tí wọ́n bá fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀, òun máa kúrò nílé ìwòsàn náà láì jáfara. Lẹ́yìn náà Bob sọ pé, “Ohun tí màá ṣe dá mi lójú, mi ò sì bẹ̀rù ohun tó lè ṣẹlẹ̀.”

Tá a bá jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa lágbára, àá jẹ́ adúróṣinṣin láìka ìṣòro yòówù kó dé bá wa sí (Wo ìpínrọ̀ 17)

17. Kí la rí kọ́ lára Bob? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

17 Kó tó di pé Bob lọ sílé ìwòsàn, ó ti pinnu tipẹ́ pé òun ò ní gbẹ̀jẹ̀, ìyẹn ló mú kó jẹ́ adúróṣinṣin. Ohun àkọ́kọ́ tó ràn án lọ́wọ́ ni pé ó fẹ́ múnú Jèhófà dùn. Ohun kejì ni pé ó fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí Bíbélì sọ nípa bí ẹ̀mí àti ẹ̀jẹ̀ ṣe jẹ́ mímọ́, ó sì ṣèwádìí nípa ẹ̀ nínú àwọn ìwé ètò Ọlọ́run. Ìkẹta, ó dá a lójú pé tóun bá pa àṣẹ Jèhófà mọ́, òun máa jàǹfààní títí láé. Torí náà, ìṣòro yòówù kó dé bá wa, àwa náà lè jẹ́ adúróṣinṣin.

Torí pé Bárákì àtàwọn ọmọ ogun ẹ̀ nígboyà, wọ́n lé àwọn ọmọ ogun Sísérà bá (Wo ìpínrọ̀ 18)

18. Báwo lohun tó ṣẹlẹ̀ sí Bárákì ṣe jẹ́ ká rí i pé ó yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà? (Wo àwòrán iwájú ìwé.)

18 Gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Ẹ jẹ́ ká wo bí Bárákì ṣe ṣàṣeyọrí torí pé ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ó sì ṣe ohun tó sọ. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò ní apata àti aṣóró kankan, Jèhófà sọ fún Bárákì pé kí wọ́n lọ dojú ìjà kọ Sísérà olórí ọmọ ogun Kénáánì tí wọ́n ní ohun ìjà tó pọ̀. (Oníd. 5:8) Wòlíì obìnrin kan tó ń jẹ́ Dèbórà sọ fún Bárákì pé kó lọ kojú Sísérà àti ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án (900) kẹ̀kẹ́ ogun ẹ̀ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ tó tẹ́jú. Bárákì mọ̀ pé kò ní rọrùn láti bá wọn jà torí pé àwọn kẹ̀kẹ́ ogun wọn máa sáré dáadáa lórí pẹ̀tẹ́lẹ̀ tó tẹ́jú, síbẹ̀ ó ṣe ohun tí Jèhófà sọ. Bí àwọn ọmọ ogun Bárákì ṣe ń sọ̀ kalẹ̀ láti orí Òkè Tábórì, Jèhófà jẹ́ kí ọ̀yamùúmùú òjò rọ̀. Bí àwọn kẹ̀kẹ́ ogun Sísérà ṣe rì sínú ẹrẹ̀ nìyẹn, Jèhófà sì jẹ́ kí Bárákì ṣẹ́gun. (Oníd. 4:1-7, 10, 13-16) Bákan náà, tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, tá a sì ń ṣe ohun tí ètò ẹ̀ sọ, àwa náà máa ṣẹ́gun.​—Diu. 31:6.

PINNU PÉ WÀÁ MÁA SIN JÈHÓFÀ NÌṢÓ

19. Kí nìdí tó o fi pinnu pé wàá máa sin Jèhófà nìṣó?

19 Tí ayé tí Sátánì ń darí yìí bá ṣì wà, àá ṣì máa ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti jẹ́ adúróṣinṣin. (1 Tím. 6:11, 12; 2 Pét. 3:17) Torí náà, ẹ jẹ́ ká pinnu pé a ò ní jẹ́ kí inúnibíni, ọgbọ́n ẹ̀wẹ́, ìrònú èèyàn, ìtànjẹ àti ìpínyà ọkàn mú ká ṣe ohun tí Jèhófà ò fẹ́. (Éfé. 4:14) Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló yẹ ká dúró gbọn-in, ká máa sin Jèhófà tọkàntọkàn, ká sì máa pa àwọn àṣẹ ẹ̀ mọ́. Lẹ́sẹ̀ kan náà, ká jẹ́ olóye, ká má sì fọwọ́ tó le jù mú nǹkan. Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa sọ̀rọ̀ nípa bí Jèhófà ṣe fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ tó bá dọ̀rọ̀ ká fòye báni lò.

ORIN 129 A Ó Máa Fara Dà Á Nìṣó

a Àtìgbà ayé Ádámù àti Éfà ni Sátánì ti jẹ́ káwọn èèyàn gbà pé àwọn fúnra wọn ló yẹ kó máa pinnu ohun tó tọ́ àtohun tí ò tọ́. Ohun tí Sátánì fẹ́ káwa náà máa rò nípa àwọn ìlànà Jèhófà àtohun tí ètò Ọlọ́run bá ní ká ṣe nìyẹn. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa rí bá a ṣe lè yẹra fún ìwà tinú mi ni màá ṣe tó kúnnú ayé tí Sátánì ń darí yìí, àá sì tún rí bá a ṣe lè máa ṣègbọràn sí Jèhófà nígbà gbogbo.

b Kó o lè mọ̀ nípa bí Kristẹni kan ṣe lè pa òfin Ọlọ́run mọ́ lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀jẹ̀, wo ẹ̀kọ́ 39 nínú ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!