ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 32
Máa Fòye Báni Lò Bíi Ti Jèhófà
“Ẹ jẹ́ kí gbogbo èèyàn rí i pé ẹ̀ ń fòye báni lò.”—FÍLÍ. 4:5.
ORIN 89 Gbọ́, Ṣègbọràn, Kó O sì Gba Ìbùkún
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ a
1. Báwo làwa Kristẹni ṣe dà bí igi? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
ÒWE Gẹ̀ẹ́sì kan sọ pé: “Atẹ́gùn ò lè wó igi tó ń tẹ̀ síbí tẹ̀ sọ́hùn-ún.” Òwe yìí jẹ́ ká rí i pé tí igi kan ò bá fẹ́ wó lulẹ̀ nígbà tí atẹ́gùn bá ń fẹ́, ó gbọ́dọ̀ lè tẹ̀ síbí tẹ̀ sọ́hùn-ún. Lọ́nà kan náà, táwa Kristẹni bá fẹ́ kí àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà dáa sí i, a gbọ́dọ̀ lè tẹ̀ síbí tẹ̀ sọ́hùn-ún, ká má sì máa rin kinkin mọ́ nǹkan. Báwo la ṣe lè ṣe é? A gbọ́dọ̀ máa fòye báni lò. Táwọn àyípadà kan bá ṣẹlẹ̀ nígbèésí ayé wa, ká má ṣe máa rin kinkin mọ́ èrò wa, ká má sì máa dá àwọn èèyàn lẹ́jọ́ nítorí ìpinnu tí wọ́n bá ṣe.
2. Táwọn àyípadà kan bá ṣẹlẹ̀ nígbèésí ayé wa, àwọn ànímọ́ wo ló máa ràn wá lọ́wọ́, kí la sì máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
2 Ó yẹ káwa ìránṣẹ́ Jèhófà máa fòye báni lò. Ó tún yẹ ká jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, ká sì máa fàánú hàn. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa rí bí àwọn ànímọ́ yìí ṣe ran àwọn Kristẹni kan lọ́wọ́ nígbà tí àwọn àyípadà kan ṣẹlẹ̀ nígbèésí ayé wọn. A tún máa rí bí àwọn ànímọ́ yìí ṣe lè ran gbogbo wa lọ́wọ́. Àmọ́ lákọ̀ọ́kọ́ ná, ẹ jẹ́ ká kẹ́kọ̀ọ́ lára Jèhófà àti Jésù tí wọ́n fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ tó bá dọ̀rọ̀ ká fòye báni lò.
JÈHÓFÀ ÀTI JÉSÙ MÁA Ń FÒYE BÁNI LÒ
3. Àwọn ẹ̀rí wo ló fi hàn pé Jèhófà máa ń fòye báni lò?
3 Bíbélì pe Jèhófà ní “Àpáta náà” torí pé adúróṣinṣin ni, ó sì máa ń ṣe ìdájọ́ òdodo. (Diu. 32:4) Síbẹ̀, ó tún máa ń fòye báni lò. Bí nǹkan ṣe ń yí pa dà láyé, bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà ń ṣe àwọn àyípadà kan kó lè mú àwọn ìlérí ẹ̀ ṣẹ. Torí pé Jèhófà dá wa ní àwòrán ara ẹ̀, ó máa ń rọrùn fún wa láti ṣe àwọn àyípadà tó yẹ, táwọn nǹkan kan bá ṣẹlẹ̀ nígbèésí ayé wa. Nínú Bíbélì, Jèhófà fún wa láwọn ìlànà tó máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè ṣe ìpinnu tó tọ́ láìka ìṣòro yòówù kó dé bá wa sí. Àpẹẹrẹ tó dáa tí Jèhófà fi lélẹ̀ àtàwọn ìlànà tó fún wa ti jẹ́ ká rí i pé bó tiẹ̀ jẹ́ pé òun ni “Àpáta náà,” ó máa ń fòye báni lò.
4. Sọ àpẹẹrẹ kan tó fi hàn pé Jèhófà máa ń fòye báni lò. (Léfítíkù 5:7, 11)
4 Jèhófà máa ń ṣe nǹkan lọ́nà tó tọ́, ó sì máa ń fòye báni lò. Kì í le koko tó bá ń bá àwa èèyàn lò. Ẹ jẹ́ ká wo bí Jèhófà ṣe fi òye bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lò. Bí àpẹẹrẹ, kì í ṣe ohun kan náà ni Jèhófà ní káwọn ọmọ Ísírẹ́lì mú wá tí wọ́n bá fẹ́ rúbọ bóyá wọ́n jẹ́ olówó tàbí tálákà. Nígbà míì, ó máa ń gba ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn láyè láti fi ohun tí wọ́n ní rúbọ bí ipò kálukú bá ṣe rí.—Ka Léfítíkù 5:7, 11.
5. Sọ àpẹẹrẹ kan tó fi hàn pé Jèhófà nírẹ̀lẹ̀, ó sì láàánú.
5 Torí pé Jèhófà nírẹ̀lẹ̀, tó sì láàánú, ó máa ń fòye báni lò. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà fi hàn pé òun nírẹ̀lẹ̀ nígbà tó fẹ́ pa àwọn èèyàn búburú tó wà nílùú Sódómù run. Jèhófà rán àwọn áńgẹ́lì ẹ̀ pé kí wọ́n sọ fún Lọ́ọ̀tì ìránṣẹ́ ẹ̀ olóòótọ́ pé kó sá kúrò nílùú yẹn lọ sórí òkè ńlá kan. Àmọ́, ẹ̀rù ń ba Lọ́ọ̀tì láti sá lọ síbẹ̀. Torí náà, ó bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kóun àti ìdílé òun sá lọ sí Sóárì, ìyẹn ìlú kékeré kan tí Jèhófà ti sọ pé òun máa pa run. Jèhófà lè sọ pé dandan ni kí Lọ́ọ̀tì ṣe ohun tóun sọ fún un. Àmọ́ kò ṣe bẹ́ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó gba tiẹ̀ rò, ó sì dá ìlú Sóárì sí torí tiẹ̀. (Jẹ́n. 19:18-22) Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, Jèhófà tún fàánú hàn sáwọn ará ìlú Nínéfè. Ó ní kí wòlíì Jónà lọ sọ fáwọn ará ìlú náà pé òun máa pa àwọn àti ìlú náà run nítorí ìwà burúkú wọn. Àmọ́ nígbà táwọn ará Nínéfè ronú pìwà dà, Jèhófà ṣàánú wọn, kò sì pa ìlú náà run.—Jónà 3:1, 10; 4:10, 11.
6. Sọ àwọn àpẹẹrẹ tó fi hàn pé Jésù náà máa ń fòye báni lò bíi ti Jèhófà.
6 Jésù náà máa ń fòye báni lò bíi ti Jèhófà. Jèhófà rán an wá sáyé kó lè wàásù fún “àwọn àgùntàn ilé Ísírẹ́lì tó sọ nù.” Síbẹ̀, ó máa ń fòye báni lò bó ṣe ń wàásù fáwọn èèyàn. Nígbà kan, obìnrin kan tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì bẹ̀ ẹ́ pé kó wo ọmọbìnrin òun sàn torí pé ‘ẹ̀mí èṣù ń yọ ọ́ lẹ́nu gidigidi.’ Àánú obìnrin yẹn ṣe Jésù, ó ṣe ohun tó sọ, ó sì wo ọmọbìnrin ẹ̀ sàn. (Mát. 15:21-28) Ẹ jẹ́ ká tún wo àpẹẹrẹ míì. Lẹ́yìn tí Jésù bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, ó sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tó bá sẹ́ mi . . . , èmi náà máa sẹ́ ẹ.” (Mát. 10:33) Àmọ́ nígbà tí Pétérù sẹ́ ẹ lẹ́ẹ̀mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ṣé ó pa á tì? Rárá. Jésù mọ̀ pé Pétérù kábàámọ̀ ohun tó ṣe, olóòótọ́ sì ni. Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, ó fara han Pétérù, ó sì ṣeé ṣe kó fi dá a lójú pé òun ti dárí jì í àti pé òun ṣì nífẹ̀ẹ́ ẹ̀.—Lúùkù 24:33, 34.
7. Bí Fílípì 4:5 ṣe sọ, ojú wo la fẹ́ káwọn èèyàn máa fi wò wá?
7 A ti rí i báyìí pé Jèhófà àti Jésù máa ń fòye báni lò. Àwa ńkọ́? Jèhófà fẹ́ káwa náà máa fòye báni lò. (Ka Fílípì 4:5.) Bí Bíbélì kan ṣe túmọ̀ ẹsẹ yìí ni pé: “Jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé o máa ń fòye báni lò.” Torí náà, ó yẹ ká bi ara wa pé: ‘Ṣé àwọn èèyàn mọ̀ mí sẹ́ni tó máa ń fòye báni lò, tí kì í rin kinkin mọ́ nǹkan, tó sì máa ń rára gba nǹkan sí? Ṣé kì í ṣe ẹni tó le koko tó sì lágídí làwọn èèyàn mọ̀ mí sí? Ṣé mo máa ń rin kinkin pé káwọn èèyàn ṣe nǹkan bí mo ṣe lérò pé ó yẹ ká ṣe é gẹ́lẹ́? Ṣé mo máa ń tẹ́tí sáwọn ẹlòmíì, tí mo sì máa ń gba èrò wọn nígbà tí mo bá rí i pé ó yẹ kí n ṣe bẹ́ẹ̀?’ Bá a bá ṣe túbọ̀ ń fòye bá àwọn èèyàn lò, bẹ́ẹ̀ làá túbọ̀ máa fara wé Jèhófà àti Jésù. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká wo apá ibi méjì tó ti yẹ ká máa fòye bá àwọn èèyàn lò. Àkọ́kọ́, tí nǹkan bá yí pa dà nígbèésí ayé wa àti ìkejì, tí ojú táwọn èèyàn fi ń wo nǹkan tàbí tí ìpinnu tí wọ́n ṣe bá yàtọ̀ sí tiwa.
MÁA FÒYE BÁNI LÒ TÍ NǸKAN BÁ YÍ PA DÀ NÍGBÈÉSÍ AYÉ Ẹ
8. Kí ló máa jẹ́ ká máa fòye báni lò tí nǹkan bá yí pa dà nígbèésí ayé wa? (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
8 Tá a bá fẹ́ fi hàn pé à ń fòye báni lò, kò yẹ ká máa rin kinkin mọ́ èrò wa tí nǹkan bá yí pa dà nígbèésí ayé wa. Irú àwọn àyípadà bẹ́ẹ̀ lè mú ká láwọn ìṣòro tá ò rò tẹ́lẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, àìsàn tá ò rò tẹ́lẹ̀ lè ṣe wá. Ohun míì ni pé lójijì, ọrọ̀ ajé lè dẹnu kọlẹ̀ tàbí kí ọ̀rọ̀ òṣèlú dá wàhálà sílẹ̀ lórílẹ̀-èdè wa, gbogbo ìyẹn sì lè mú kí nǹkan tojú súni. (Oníw. 9:11; 1 Kọ́r. 7:31) Kódà, nǹkan lè nira tí iṣẹ́ tí ètò Ọlọ́run gbé fún wa bá yí pa dà. Ìṣòro yòówù ká bá pàdé, àá lè borí ẹ̀ tá a bá ń ṣe àwọn nǹkan mẹ́rin yìí, (1) gbà pé nǹkan ti yí pa dà báyìí, (2) má ṣe máa ronú nípa ohun tó ò ń ṣe tẹ́lẹ̀, ohun tó o máa ṣe sọ́rọ̀ náà ni kó o máa rò, (3) máa ronú nípa àwọn nǹkan rere tí Jèhófà ti ṣe fún ẹ àti (4) máa ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. b Torí náà ní báyìí, ẹ jẹ́ ká wo bí àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa ṣe jàǹfààní nígbà tí wọ́n ṣe àwọn nǹkan yìí.
9. Kí ni tọkọtaya míṣọ́nnárì kan ṣe nígbà tí ìṣòro tí wọn ò rò tẹ́lẹ̀ dé bá wọn?
9 Gbà pé nǹkan ti yí pa dà báyìí. Ètò Ọlọ́run rán tọkọtaya kan tó ń jẹ́ Emanuele àti Francesca lọ ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì lórílẹ̀-èdè míì. Àmọ́ bí wọ́n ṣe ń kọ́ èdè tuntun, tí wọ́n sì ń gbìyànjú pé kí ara wọn mọlé nínú ìjọ tuntun tí wọ́n wà ni àrùn kòrónà bẹ̀rẹ̀, ìyẹn sì gba pé kí wọ́n ya ara wọn sọ́tọ̀, kí wọ́n má sì sún mọ́ ẹnikẹ́ni. Lẹ́yìn náà, ìyá Francesca kú lójijì. Ó wu Francesca gan-an pé kó lọ wo ìdílé ẹ̀, àmọ́ àrùn kòrónà náà ò jẹ́ kó lè lọ. Báwo ló ṣe fara da nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sí i yìí? Ohun àkọ́kọ́ tí Emanuele àti Francesca ṣe ni pé wọ́n jọ gbàdúrà sí Jèhófà pé kó fún àwọn lọ́gbọ́n táwọn á máa fi borí àníyàn ọjọ́ kọ̀ọ̀kan. Jèhófà sì dáhùn àdúrà wọn nípasẹ̀ àwọn nǹkan tí ètò Ọlọ́run ń pèsè lásìkò tó yẹ. Bí àpẹẹrẹ, ohun tí arákùnrin kan sọ nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò inú fídíò kan fún wọn níṣìírí, ó ní: “Tá a bá tètè gbà pé nǹkan ti yí pa dà, àá tún tètè máa láyọ̀, àá sì mọ nǹkan tá a lè ṣe nínú ipò tuntun tá a bá ara wa.” c Ìkejì, wọ́n túbọ̀ já fáfá nínú bí wọ́n ṣe ń fi fóònù wàásù. Kódà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan. Ìkẹta, wọ́n gbà káwọn ará ìjọ ran àwọn lọ́wọ́, wọ́n sì mọyì ìfẹ́ tí wọ́n fi hàn sí wọn. Bí àpẹẹrẹ, arábìnrin kan tó ń ronú nípa wọn máa ń fi ọ̀rọ̀ àti ẹsẹ Bíbélì kan ránṣẹ́ sí wọn lójoojúmọ́ fún ọdún kan gbáko. Táwa náà bá gbà pé ipò wa ti yí pa dà, ọkàn wa máa balẹ̀, àwọn nǹkan tá à ń ṣe báyìí á sì máa fún wa láyọ̀.
10. Kí ni arábìnrin kan ṣe nígbà tí àyípadà ńlá kan dé bá a?
10 Má ṣe máa ronú nípa ohun tó ò ń ṣe tẹ́lẹ̀, àwọn ohun rere tí Jèhófà ti ṣe fún ẹ ni kó o máa rò. Orílẹ̀-èdè Romania ni arábìnrin kan tó ń jẹ́ Christina ti wá, àmọ́ Japan ló ń gbé. Inú ẹ̀ ò dùn nígbà tí wọ́n ní kí ìjọ Gẹ̀ẹ́sì tó wà lọ dara pọ̀ mọ́ àwọn ìjọ míì. Àmọ́, kò bẹ̀rẹ̀ sí í ronú ṣáá nípa nǹkan tó ṣẹlẹ̀ yẹn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó pinnu pé òun á ṣe gbogbo ohun tóun lè ṣe nínú ìjọ tó ń sọ èdè Japanese tó wà báyìí. Ó ní kí obìnrin kan tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ tẹ́lẹ̀ kọ́ òun lédè náà kóun lè mọ̀ ọ́n sọ dáadáa. Obìnrin náà gbà pé òun máa lo Bíbélì àti ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! láti fi kọ́ Christina lédè Japanese. Kì í ṣe pé Christina wá túbọ̀ mọ èdè yẹn sọ nìkan ni, àmọ́ obìnrin yẹn tún bẹ̀rẹ̀ sí í nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́. Torí náà, tá ò bá ronú nípa ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn, tá a sì gbà pé nǹkan ṣì máa dáa, àwọn àyípadà tó dé bá wa lè yọrí sí ọ̀pọ̀ ohun rere tá ò retí.
11. Kí ni tọkọtaya kan ṣe nígbà tí ọrọ̀ ajé wọn dẹnu kọlẹ̀?
11 Máa ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Nígbà tí ọrọ̀ ajé dẹnu kọlẹ̀ lórílẹ̀-èdè kan tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ wa, tọkọtaya kan pàdánù iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wọn. Kí ló ràn wọ́n lọ́wọ́ láti fara dà á? Ohun tí wọ́n kọ́kọ́ ṣe ni pé wọ́n dín ìnáwó wọn kù. Lẹ́yìn náà, dípò kí wọ́n máa ronú ṣáá nípa ìṣòro wọn, wọ́n pinnu pé àwọn á túbọ̀ máa wàásù fáwọn èèyàn. (Ìṣe 20:35) Ọkọ sọ pé: “Bá a ṣe túbọ̀ tẹra mọ́ iṣẹ́ ìwàásù kì í jẹ́ ká ráyè ronú nípa ìṣòro wa, ó sì ń jẹ́ ká gbájú mọ́ ohun tí Jèhófà fẹ́ ká ṣe.” Torí náà, tí àyípadà bá dé bá wa, ó yẹ ká rántí pé ó ṣe pàtàkì ká máa ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, pàápàá jù lọ ká máa wàásù fún wọn.
12. Báwo ni àpẹẹrẹ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe jẹ́ ká rí i pé ó yẹ ká máa wàásù fún onírúurú èèyàn?
12 Ó yẹ ká mọ bá a ṣe máa bá onírúurú èèyàn sọ̀rọ̀ tá a bá ń wàásù. Lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, a máa ń pàdé àwọn tó wá láti ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, tí ìwà wọn àti ohun tí wọ́n gbà gbọ́ sì yàtọ̀ síra. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù máa ń bá onírúurú èèyàn sọ̀rọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, ó sì yẹ ká kẹ́kọ̀ọ́ lára ẹ̀. Jésù yàn án pé kó jẹ́ “àpọ́sítélì fún àwọn orílẹ̀-èdè.” (Róòmù 11:13) Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń ṣe iṣẹ́ tí Jésù gbé fún un yìí, ó wàásù fáwọn Júù, àwọn Gíríìkì, àwọn ọ̀mọ̀wé, àwọn tálákà, àwọn èèyàn pàtàkì láwùjọ àtàwọn ọba. Kí Pọ́ọ̀lù lè wàásù fún gbogbo àwọn tá a sọ yìí, ó “di ohun gbogbo nítorí gbogbo èèyàn.” (1 Kọ́r. 9:19-23) Ó kíyè sí ibi tí wọ́n ti wá, àṣà ìbílẹ̀ wọn àtohun tí wọ́n gbà gbọ́. Ìyẹn jẹ́ kó lè wàásù fún wọn lọ́nà tó wọ̀ wọ́n lọ́kàn. Táwa náà bá jẹ́ kí ọ̀nà tá à ń gbà wàásù dáa sí i, àá lè wàásù fún onírúurú èèyàn.
MÁ ṢE MÁA DÁ ÀWỌN ÈÈYÀN LẸ́JỌ́
13. Tá ò bá fẹ́ máa dá àwọn èèyàn lẹ́jọ́, kí ni 1 Kọ́ríńtì 8:9 sọ pé ó yẹ ká yẹra fún?
13 Tá a bá ń fòye báni lò, a ò ní máa dá àwọn èèyàn lẹ́jọ́. Bí àpẹẹrẹ, àwọn arábìnrin wa kan fẹ́ràn kí wọ́n máa tọ́jú tọ́tè, àwọn arábìnrin kan ò sì fẹ́ràn kí wọ́n máa ṣe bẹ́ẹ̀. Àwọn ará wa kan máa ń mutí níwọ̀nba, àwọn kan kì í sì í mu ún rárá. Gbogbo àwa Kristẹni ló máa ń wù pé ká ní ìlera tó jí pépé, àmọ́ ìtọ́jú tá a máa ń gbà yàtọ̀ síra. Tá a bá ń fipá mú àwọn ará nínú ìjọ pé kí wọ́n ṣe ohun tá a fẹ́, a lè mú àwọn ará kọsẹ̀, ó sì lè dá ìyapa sílẹ̀ láàárín wa. Ó dájú pé a ò ní fẹ́ kírú ẹ̀ ṣẹlẹ̀! (Ka 1 Kọ́ríńtì 8:9; 10:23, 24) Ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ méjì yẹ̀ wò tó máa jẹ́ ká rí i pé tá a bá ń tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì, a ò ní máa dá àwọn èèyàn lẹ́jọ́, àlàáfíà á sì wà láàárín wa.
14. Ìlànà Bíbélì wo ló yẹ ká tẹ̀ lé tó bá dọ̀rọ̀ aṣọ àti irun wa?
14 Aṣọ àti irun wa. Kàkà kí Jèhófà ṣòfin nípa irú aṣọ tá a máa wọ̀, ṣe ló fún wa láwọn ìlànà tí àá máa tẹ̀ lé. Ó yẹ ká máa múra lọ́nà tó yẹ àwọn òjíṣẹ́ Ọlọ́run, kó fi hàn pé à ń fòye báni lò, a mọ̀wọ̀n ara wa, a sì ní “àròjinlẹ̀.” (1 Tím. 2:9, 10; 1 Pét. 3:3) Torí náà, tí ìmúra wa ò bá bójú mu, ó lè jẹ́ káwọn èèyàn máa wò wá láwò yanu. Bákan náà, táwọn alàgbà bá ń tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì, wọn ò ní máa gbé ìlànà tara wọn kalẹ̀ nípa irú aṣọ táwọn ará máa wọ̀ àti irú irun tó yẹ kí wọ́n ṣe. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ọ̀dọ́kùnrin nínú ìjọ kan sábà máa ń gẹ irun kan tó gbajúmọ̀ lágbègbè wọn. Wọ́n máa ń gẹ irun náà lọlẹ̀, àmọ́ wọn kì í yà á, ó sì máa ń rí wúruwùru. Torí náà, àwọn alàgbà ìjọ wọn fẹ́ ràn wọ́n lọ́wọ́. Báwo ni wọ́n ṣe máa ṣe é láì ṣòfin irú irun tí wọ́n máa gẹ̀? Alábòójútó àyíká wọn gba àwọn alàgbà náà níyànjú pé kí wọ́n sọ fáwọn ọ̀dọ́ náà pé, “Tó o bá ń kọ́ni lórí pèpéle, tó wá jẹ́ pé aṣọ tó o wọ̀ àti irun tó o gẹ̀ làwọn èèyàn ń wò dípò kí wọ́n máa gbọ́ ohun tó ò ń sọ, á jẹ́ pé aṣọ tó o wọ̀ àti irun tó o gẹ̀ ò dáa tó nìyẹn.” Àlàyé ṣókí tí ò lọ́jú pọ̀ yìí jẹ́ káwọn ọ̀dọ́ yẹn mọ ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe láìjẹ́ pé àwọn alàgbà ṣòfin fún wọn. d
15. Àwọn òfin àti ìlànà Bíbélì wo ló yẹ ká tẹ̀ lé tá a bá fẹ́ gba ìtọ́jú? (Róòmù 14:5)
15 Ìtọ́jú ara. Kristẹni kọ̀ọ̀kan ló máa pinnu irú ìtọ́jú tóun máa gbà. (Gál. 6:5) Àmọ́ àwọn òfin kan wà nínú Bíbélì táwa Kristẹni gbọ́dọ̀ pa mọ́ tá a bá fẹ́ gbàtọ́jú. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé ká ta kété sí ẹ̀jẹ̀ àti ìbẹ́mìílò. (Ìṣe 15:20; Gál. 5:19, 20) Yàtọ̀ sáwọn òfin tí Bíbélì sọ yẹn, Kristẹni kan lè pinnu irú ìtọ́jú tóun máa gbà. Àwọn kan máa ń lọ gba ìtọ́jú nílé ìwòsàn, àwọn míì sì máa ń lo egbòogi ìbílẹ̀. Tá a bá tiẹ̀ rò pé irú ìtọ́jú tá a mọ̀ ló dáa jù, ó yẹ ká fi àwọn ará wa lọ́rùn sílẹ̀, kí wọ́n pinnu irú ìtọ́jú tí wọ́n máa gbà. Torí náà, kò yẹ ká gbàgbé àwọn nǹkan pàtàkì yìí: (1) Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló lè mú àìsàn kúrò pátápátá. (Àìsá. 33:24) (2) Ó gbọ́dọ̀ ‘dá Kristẹni kọ̀ọ̀kan lójú hán-ún hán-ún’ pé ìtọ́jú tóun fẹ́ gbà ló dáa jù fóun. (Ka Róòmù 14:5.) (3) A ò gbọ́dọ̀ dá àwọn èèyàn lẹ́jọ́ nítorí ìpinnu tí wọ́n ṣe tàbí ká ṣe ohun tó máa mú kí wọ́n kọṣẹ̀. (Róòmù 14:13) (4) Àwa Kristẹni máa fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn ará, tá ò bá jẹ́ kí òmìnira tá a ní láti yan ohun tó wù wá ba àlàáfíà ìjọ jẹ́. (Róòmù 14:15, 19, 20) Tá a bá ń rántí àwọn nǹkan yìí, àjọṣe tó wà láàárín àwa àtàwọn ará wa ò ní bà jẹ́, àlàáfíà á sì wà nínú ìjọ.
16. Báwo ni alàgbà kan ṣe lè fi hàn pé òun ń fòye báni lò tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀ nínú ìgbìmọ̀ alàgbà? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
16 Àwọn alàgbà gbọ́dọ̀ fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ tó bá dọ̀rọ̀ ká fòye báni lò. (1 Tím. 3:2, 3) Bí àpẹẹrẹ, kò yẹ kí alàgbà kan máa retí pé gbogbo ìgbà ni káwọn alàgbà yòókù gba ohun tóun bá sọ torí òun dàgbà jù wọ́n lọ, òun sì nírìírí jù wọ́n lọ. Ó yẹ kó gbà pé ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà lè lo alàgbà èyíkéyìí láti sọ ohun tó máa mú kí wọ́n ṣe ìpinnu tó dáa. Tí ìgbìmọ̀ alàgbà bá ṣe ìpinnu tí ò ta ko ìlànà Bíbélì, táwọn tó pọ̀ jù nínú ìgbìmọ̀ náà sì fọwọ́ sí i, ó yẹ káwọn alàgbà yòókù fòye báni lò, kí wọ́n sì fara mọ́ ọn, kódà tí ìpinnu náà ò bá wù wọ́n.
A MÁA JÀǸFÀÀNÍ TÁ A BÁ Ń FÒYE BÁNI LÒ
17. Àǹfààní wo la máa rí tá a bá ń fòye báni lò?
17 Tá a bá ń fòye báni lò, a máa jàǹfààní tó pọ̀. A máa ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn ará wa, àlàáfíà sì máa wà nínú ìjọ. Inú wa á máa dùn torí ìwà tó dáa táwọn ará wa ní àti àṣà ìbílẹ̀ wọn lóríṣiríṣi, ìyẹn á sì jẹ́ ká máa jọ́sìn Jèhófà níṣọ̀kan. Èyí tó ṣe pàtàkì jù ni pé inú wa á máa dùn torí a mọ̀ pé à ń fara wé Jèhófà Ọlọ́run tó ń fòye báni lò.
ORIN 90 Ẹ Máa Gba Ara Yín Níyànjú
a Jèhófà àti Jésù máa ń fòye báni lò, wọ́n sì fẹ́ káwa náà máa ṣe bẹ́ẹ̀. Tá a bá ń fòye báni lò, ó máa rọrùn fún wa láti ṣe àwọn àyípadà tó yẹ táwọn nǹkan kan bá ṣẹlẹ̀ nígbèésí ayé wa, irú bí àìlera àti ìṣòro àìrówóná. Yàtọ̀ síyẹn, àá tún jẹ́ kí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan wà nínú ìjọ.
b Wo àpilẹ̀kọ náà “Ohun Tó O Lè Ṣe Tí Àyípadà Bá Ṣẹlẹ̀” nínú Jí! No. 4 2016.
c Wo fídíò A Gbọ́rọ̀ Látẹnu Arákùnrin Dmitriy Mikhaylov tó wà fún àpilẹ̀kọ náà, “Jèhófà Máa Ń Ràn Wá Lọ́wọ́ Ká Lè Wàásù Lójú Àtakò” nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni ti March-April 2021.
d Kó o lè mọ púpọ̀ sí i nípa aṣọ àti irun wa, wo ẹ̀kọ́ 52 nínú ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!