Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

Tá A Bá Ń Ran Àwọn Èèyàn Lọ́wọ́, A Máa Jàǹfààní Ẹ̀ Títí Láé

Tá A Bá Ń Ran Àwọn Èèyàn Lọ́wọ́, A Máa Jàǹfààní Ẹ̀ Títí Láé

Èmi àti ìyá mi pẹ̀lú Pat àbúrò mi obìnrin lọ́dún 1948

“ṢỌ́Ọ̀ṢÌ Anglican kò fi òtítọ́ kọ́ni. Wá òtítọ́ lọ síbòmíì.” Lẹ́yìn tí ìyá màmá mi tó ń lọ ṣọ́ọ̀ṣì Anglican sọ ọ̀rọ̀ yìí, ìyá mi bẹ̀rẹ̀ sí í wá ẹ̀sìn tòótọ́ kiri. Àmọ́ kò gba àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láyè nílé wa ní Toronto, lórílẹ̀-èdè Kánádà, ó sì sọ fún mi pé tí wọ́n bá wá sílé wa kí n sá pa mọ́. Ṣùgbọ́n nígbà tí àbúrò ìyá mi obìnrin bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́dún 1950, ìyá mi náà bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú wọn. Ilé àbúrò ìyá mi làwọn méjèèjì ti máa ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, nígbà tó sì yá, wọ́n ṣèrìbọmi.

Alàgbà ìjọ ni bàbá mi ní United Church of Canada tó wà lágbègbè wa, torí náà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ni wọ́n máa ń sọ pé kí èmi àti àbúrò mi obìnrin kọ́kọ́ lọ síbi tí wọ́n ti ń kọ́ àwọn ọmọdé ní ṣọ́ọ̀ṣì. Lẹ́yìn náà, bàbá wa máa mú wa lọ sínú ṣọ́ọ̀ṣì nígbà tí ìsìn bá fẹ́ bẹ̀rẹ̀ ní aago mọ́kànlá (11) àárọ̀. Tó bá wá di ọ̀sán, àá wá tẹ̀ lé ìyá wa lọ sí Ilé Ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ìyẹn jẹ́ ká rí i kedere pé ìyàtọ̀ wà láàárín àwọn ẹ̀sìn méjèèjì.

Èmi àti ìdílé Hutcheson ní Àpéjọ Àgbáyé Ìfẹ́ Àtọ̀runwá lọ́dún 1958

Ó ti pẹ́ tí ìyá mi pẹ̀lú tọkọtaya kan tó ń jẹ́ Bob àti Marion Hutcheson ti ń ṣọ̀rẹ́. Torí náà, ó sọ ohun tó kọ́ nínú Bíbélì fún wọn, àwọn náà sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Lọ́dún 1958, Arákùnrin Hutcheson àtìyàwó ẹ̀ mú èmi àti ọmọ wọn ọkùnrin mẹ́ta lọ sí Àpéjọ Àgbáyé Ìfẹ́ Àtọ̀runwá ọlọ́jọ́ mẹ́jọ tá a ṣe nílùú New York. Tí mo bá ń rántí ìgbà yẹn, mo rí i pé iṣẹ́ ńlá ni wọ́n ṣe bí wọ́n ṣe mú mi lọ, àmọ́ àpéjọ yẹn wà lára ohun tí mo gbádùn jù lọ láyé mi.

ÀWỌN ARÁ RÀN MÍ LỌ́WỌ́ KÍ N LÈ FAYÉ MI SIN JÈHÓFÀ

Nígbà tí mi ò tíì pé ọmọ ogún (20) ọdún, oko tá a ti ń sin màlúù, ẹlẹ́dẹ̀, àgùntàn àtàwọn adìyẹ là ń gbé, mo sì ń gbádùn iṣẹ́ náà. Ó wù mí gan-an kí n lọ kàwé, kí n lè di dókítà tó ń tọ́jú àwọn ẹranko. Ìyá mi wá sọ ohun tí mo fẹ́ ṣe yìí fún alàgbà kan nínú ìjọ wa. Alàgbà náà fìfẹ́ rán mi létí pé “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” là ń gbé, ó sì bi mí pé tí mo bá lọ fi ọdún tó pọ̀ kàwé ní yunifásítì, ṣé ìyẹn ò ní ba àjọṣe àárín èmi àti Jèhófà jẹ́? (2 Tím. 3:1) Torí náà, mo pinnu pé mi ò ní lọ sí yunifásítì.

Mo ṣì máa ń ronú nípa ohun tí màá ṣe lẹ́yìn tí mo bá parí ilé ẹ̀kọ́ girama. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé gbogbo òpin ọ̀sẹ̀ ni mo máa ń lọ wàásù, iṣẹ́ náà kì í gbádùn mọ́ mi, ìyẹn sì jẹ́ kí n máa rò pé mi ò lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà. Àmọ́ bàbá mi àti àbúrò bàbá mi ọkùnrin fẹ́ kí n lọ ṣiṣẹ́ níléeṣẹ́ abánigbófò kan tó lókìkí nílùú Toronto. Àbúrò bàbá mi wà lára àwọn ọ̀gá ilé iṣẹ́ náà, torí náà mo gbà láti ṣiṣẹ́ níbẹ̀.

Nígbà tí mo dé ìlú Toronto, mo máa ń ṣe àṣekún iṣẹ́ nígbà gbogbo, àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mò ń bá kẹ́gbẹ́, ìyẹn kì í sì í jẹ́ kí n lọ sípàdé àti òde ìwàásù déédéé. Ọ̀dọ̀ bàbá bàbá mi tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mo kọ́kọ́ gbé, àmọ́ nígbà tí wọ́n kú, mo wá ibòmíì tí màá máa gbé.

Arákùnrin Hutcheson àtìyàwó ẹ̀ tí wọ́n mú mi lọ sí àpéjọ ọdún 1958 mú mi bí ọmọ wọn. Wọ́n ní kí n wá máa gbé ilé àwọn, wọ́n sì ràn mí lọ́wọ́ kí n lè túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Lọ́dún 1960, èmi àti John ọmọ wọn ṣèrìbọmi. Lẹ́yìn tá a ṣèrìbọmi, John bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, ìyẹn sì jẹ́ kémi náà máa wàásù déédéé. Àwọn ará ìjọ ń kíyè sí i pé àjọṣe èmi àti Jèhófà ń dáa sí i, torí náà nígbà tó yá, wọ́n sọ mí di ìránṣẹ́ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run. a

MO FẸ́ ÌYÀWÓ ÀTÀTÀ, MO SÌ DI AṢÁÁJÚ-Ọ̀NÀ

Ọjọ́ ìgbéyàwó wa rèé lọ́dún 1966

Lọ́dún 1966, mo gbé Randi Berge níyàwó, aṣáájú-ọ̀nà tó nítara ni, ó sì ṣe tán láti lọ síbi tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù. Alábòójútó àyíká wa máa ń bá wa sọ̀rọ̀ gan-an, ó gbà wá níyànjú pé ká lọ ran ìjọ tó wà nílùú Orillia ní agbègbè Ontario lọ́wọ́. Torí náà, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ la lọ síbẹ̀.

Nígbà tá a dé ìlú Orillia, ojú ẹsẹ̀ ni mo dara pọ̀ mọ́ Randi láti máa ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Èmi náà wá bẹ̀rẹ̀ sí í nítara lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù bíi tiẹ̀. Nígbà tí mo gbájú mọ́ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, tí mò ń fi Bíbélì kọ́ àwọn èèyàn, tí ohun tí wọ́n ń kọ́ sì ń yé wọn, mo bẹ̀rẹ̀ sí í láyọ̀. Inú wa dùn gan-an nígbà tá a ran tọkọtaya kan lọ́wọ́ nílùú Orillia láti ṣe àwọn àyípadà tó yẹ nígbèésí ayé wọn, tí wọ́n sì di ìránṣẹ́ Jèhófà.

A KỌ́ ÈDÈ TUNTUN, A SÌ YÍ ÈRÒ WA PA DÀ

Nígbà tá a lọ sí ìlú Toronto, a pàdé Arákùnrin Arnold MacNamara tó wà lára àwọn alábòójútó ní Bẹ́tẹ́lì. Ó bi wá pé, ṣé a máa fẹ́ ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe? Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni mo dá a lóhùn pé: “Bẹ́ẹ̀ ni! A ṣe tán láti lọ síbi tí wọ́n bá rán wa lọ, àmọ́ a ò fẹ́ Quebec!” Ìdí tá ò fi fẹ́ lọ síbẹ̀ ni pé àwọn tó ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì ní Kánádà máa ń ṣe ẹ̀tanú àwọn tó ń sọ èdè Faransé lágbègbè Quebec, wọ́n sì máa ń sọ pé rògbòdìyàn máa ń ṣẹlẹ̀ níbẹ̀. Lásìkò yẹn, àwọn èèyàn ń wọ́de torí wọ́n fẹ́ kí agbègbè Quebec gbòmìnira kúrò lábẹ́ ìjọba Kánádà.

Arákùnrin Arnold wá sọ pé: “Agbègbè Quebec nìkan ni ẹ̀ka ọ́fíìsì ń rán àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe lọ báyìí.” Torí náà, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni mo gbà láti lọ. Mo mọ̀ pé Randi ní tiẹ̀ máa fẹ́ lọ sìn níbẹ̀. Nígbà tó yá, mo rí i pé ọ̀kan lára ìpinnu tó dáa jù lọ tá a ṣe nígbèésí ayé wa nìyẹn!

Lẹ́yìn tá a fi ọ̀sẹ̀ márùn-ún kọ́ èdè Faransé, èmi àti Randi pẹ̀lú tọkọtaya kan lọ sílùú Rimouski tó wà ní ìlà oòrùn ìlú Montreal, a sì rìnrìn àjò tó tó nǹkan bí ọgọ́rùn-ún márùn-ún ó lé ogójì (540) kìlómítà. Mo rí i pé ó ṣì yẹ ká kọ́ èdè Faransé dáadáa ká lè túbọ̀ mọ̀ ọ́n sọ. Ìdí ni pé nígbà tí mo ka ìfilọ̀ kan nípàdé, dípò kí n sọ pé “ọ̀pọ̀ àwọn ará láti Ọsirélíà” máa wá sí àpéjọ tá a fẹ́ ṣe, mo sọ pé “ọ̀pọ̀ ògòǹgò” máa wá torí bí wọ́n ṣe ń pe Ọsirélíà lédè Faransé jọ bí wọ́n ṣe ń pe ògòǹgò lédè Gẹ̀ẹ́sì.

Ilé “White House” tá à ń gbé ní Rimouski

Nígbà tá a dé ìlú Rimouski, àwọn arábìnrin mẹ́rin kan tí ò lọ́kọ, tí wọ́n sì nítara wá dara pọ̀ mọ́ àwa mẹ́rẹ̀ẹ̀rin. Yàtọ̀ síyẹn, Arákùnrin Huberdeau àtìyàwó ẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin wọn méjì tún dara pọ̀ mọ́ wa. Arákùnrin Huberdeau àtìyàwó ẹ̀ ń gbé ilé ńlá oníyàrá méje kan, gbogbo àwọn aṣáájú-ọ̀nà yòókù kó wá síbẹ̀, wọ́n sì ń san lára owó ilé náà. À ń pe ilé náà ní White House torí pé ọ̀dà funfun ni wọ́n fi kun iwájú ilé náà àtàwọn òpó ẹ̀. Àwa èèyàn bíi méjìlá (12) sí mẹ́rìnlá (14) ló ń gbébẹ̀. Torí pé aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe ni èmi àti Randi, a máa ń lọ wàásù láàárọ̀, lọ́sàn-án àti nírọ̀lẹ́. Torí náà, a mọyì ẹ̀ gan-an pé a máa ń rí ẹnì kan lára àwọn tá a jọ ń gbé tó máa tẹ̀ lé wa lọ wàásù, kódà tí yìnyín bá ń já bọ́ nírọ̀lẹ́.

Àwa àtàwọn aṣáájú-ọ̀nà yẹn wá di ọ̀rẹ́ débi pé gbogbo wa ń ṣe bí ọmọ ìyá. Nígbà míì, a máa ń jókòó yíká iná igi lálẹ́ tàbí kí gbogbo wa se oúnjẹ tá a máa jẹ pa pọ̀. Ọ̀kan lára àwọn arákùnrin wa mọ orin kọ dáadáa, torí náà alaalẹ́ Saturday la máa ń kọrin, tá a sì máa ń jó.

Ọ̀pọ̀ èèyàn tó wà ní Rimouski ló fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Láàárín ọdún márùn-ún péré, inú wa dùn bá a ṣe ń rí i pé àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ń tẹ̀ síwájú tí wọ́n sì ṣèrìbọmi. Iye àwọn akéde ìjọ wa sì di márùndínlógójì (35).

Nígbà tá a wà ní Quebec, ètò Ọlọ́run dá wa lẹ́kọ̀ọ́ ká lè máa wàásù lọ́nà tó túbọ̀ já fáfá. A rí bí Jèhófà ṣe ràn wá lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, tó sì tún pèsè ohun tá a nílò fún wa. Yàtọ̀ síyẹn, a wá nífẹ̀ẹ́ àwọn tó ń sọ èdè Faransé, a nífẹ̀ẹ́ èdè wọn àti àṣà wọn, ìyẹn ló sì jẹ́ ká nífẹ̀ẹ́ àṣà ìbílẹ̀ àwọn ẹlòmíì náà.​—2 Kọ́r. 6:13.

Láìrò tẹ́lẹ̀, ètò Ọlọ́run ní ká lọ sílùú Tracadie ní etíkun ìlà oòrùn New Brunswick. Kò rọrùn fún mi rárá torí a ṣẹ̀ṣẹ̀ gba ilé tá à ń gbé ni àti pé mò ń ṣiṣẹ́ olùkọ́ nílé ìwé kan, ọjọ́ mélòó kan láàárín ọ̀sẹ̀ ni mo sì fi ń ṣiṣẹ́ náà. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn kan lára àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣẹ̀ṣẹ̀ di akéde ni, a sì tún ń kọ́ Ilé Ìpàdé wa lọ́wọ́.

Gbogbo òpin ọ̀sẹ̀ yẹn la fi gbàdúrà nípa ìlú Tracadie tí wọ́n ní ká lọ, a ṣèbẹ̀wò síbẹ̀, a sì rí i pé ibẹ̀ yàtọ̀ sí ìlú Rimouski. Àmọ́ torí pé ibẹ̀ ni Jèhófà fẹ́ ká lọ, a pinnu pé a máa lọ síbẹ̀. A fa gbogbo ẹ̀ lé Jèhófà lọ́wọ́, a rí i pé ó bójú tó wa, ó sì bá wa yanjú gbogbo ìṣòro wa. (Mál. 3:10) Torí pé Randi nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gan-an, kò mọ tara ẹ̀ nìkan, ó sì máa ń ṣàwàdà, ó rọrùn fún wa láti kó lọ síbi tí wọ́n ní ká lọ.

Níjọ tá a kó lọ, Arákùnrin Robert Ross nìkan ni alàgbà tó wà níbẹ̀. Ó ti pẹ́ tóun àtìyàwó ẹ̀ ti ń ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà níbẹ̀, wọ́n sì pinnu pé àwọn máa dúró síbẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n bí àkọ́bí wọn ọkùnrin. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ṣì ń tọ́ ọmọ wọn lọ́wọ́, wọ́n gbà wá tọwọ́tẹsẹ̀, wọ́n máa ń fún wa ní nǹkan, wọ́n sì nítara lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Ohun tí wọ́n ṣe yìí fún wa níṣìírí gan-an.

À Ń LÁYỌ̀ NÍBIKÍBI TÍ WỌ́N BÁ NÍ KÁ LỌ

Ìgbà òtútù rèé nígbà tá a bẹ àyíká àkọ́kọ́ wò

Lẹ́yìn tá a ti ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe fún ọdún méjì nílùú Tracadie, ó yà wá lẹ́nu gan-an nígbà tí wọ́n ní ká bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ alábòójútó àyíká. Ọdún méje la fi bẹ àwọn àyíká tó ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì wò. Lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n ní ká máa lọ bẹ àyíká tó ń sọ èdè Faransé wò ní agbègbè Quebec. Arákùnrin Léonce Crépeault ni alábòójútó agbègbè wa ní Quebec, wọ́n sì máa ń gbóríyìn fún mi nígbàkigbà tí mo bá sọ àsọyé. Lẹ́yìn tí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n á wá bi mí pé, “Ṣé o lè jẹ́ kí àwọn ará túbọ̀ rí ẹ̀kọ́ kọ́ nínú àsọyé ẹ?” b Ohun tí wọ́n máa ń sọ fún mi yìí ràn mí lọ́wọ́ gan-an torí ó ń jẹ́ kí àsọyé mi túbọ̀ yé àwọn ará dáadáa, wọ́n sì máa ń rí ẹ̀kọ́ kọ́ níbẹ̀.

Mi ò lè gbàgbé iṣẹ́ tí mo ṣe ní Àpéjọ Àgbáyé tí àkòrí ẹ̀ jẹ́ “Ìgbàgbọ́ Aṣẹ́gun” nílùú Montreal lọ́dún 1978. Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Oúnjẹ ni mo ti ṣiṣẹ́. Àwọn ará tí iye wọn jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́rin (80,000) là ń retí, bá a sì ṣe máa ṣètò oúnjẹ fún wọn yàtọ̀ sí bá a ṣe máa ń ṣe é tẹ́lẹ̀. Gbogbo nǹkan ló ti yàtọ̀ sí ti tẹ́lẹ̀, bí àpẹẹrẹ, àwọn nǹkan tá a fi ń dáná, oúnjẹ tá a máa sè àti bá a ṣe máa sè é ti yàtọ̀ sí ti tẹ́lẹ̀. A ní nǹkan bí ogún (20) fìríìjì ńláńlá tó ṣeé gbé kiri, àmọ́ nígbà míì, wọn kì í ṣiṣẹ́ dáadáa. Ní ọjọ́ tó ṣáájú ọjọ́ tá a máa bẹ̀rẹ̀ àpéjọ náà, wọ́n ń ṣeré ìdárayá ní pápá ìṣeré tá a fẹ́ lò. Torí náà, ọ̀gànjọ́ òru la tó lè wọlé síbẹ̀, ká lè ṣètò àwọn nǹkan tá a fẹ́ lò. A tún gbọ́dọ̀ dáná kí ilẹ̀ tó mọ́, káwọn ará lè jẹun àárọ̀. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ti rẹ̀ wá gan-an, mo kọ́ ọ̀pọ̀ nǹkan lára àwọn tá a jọ ṣiṣẹ́ torí wọ́n ṣiṣẹ́ kára, wọ́n níwà ọmọlúwàbí, wọ́n sì máa ń ṣàwàdà. Torí náà, a di ọ̀rẹ́, a sì ń ṣọ̀rẹ́ títí di báyìí. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ṣenúnibíni tó le gan-an sáwọn ará wa lágbègbè Quebec láti ọdún 1940 sí 1950, àpéjọ àgbáyé yẹn múnú wa dùn gan-an, ó sì jẹ́ kára tù wá!

Èmi àti Randi ń múra àpéjọ tá a fẹ́ ṣe nílùú Montreal lọ́dún 1985

Ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ ni mo kọ́ lára àwọn tá a jọ jẹ́ alábòójútó ní àwọn àpéjọ tá a ṣe ní Montreal. Ní àpéjọ tá a ṣe lọ́dún kan, Arákùnrin David Splane tó wà lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí báyìí ni wọ́n ní kó bójú tó àpéjọ náà. Ní àpéjọ míì tá a ṣe, èmi ni wọ́n ní kí n bójú tó o, Arákùnrin David sì ràn mí lọ́wọ́ gan-an.

Lọ́dún 2011, lẹ́yìn tá a ti gbádùn iṣẹ́ alábòójútó àyíká fún ọdún mẹ́rìndínlógójì (36), wọ́n fún mi ní iṣẹ́ míì pé kí n máa dá àwọn alàgbà lẹ́kọ̀ọ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Alàgbà Ìjọ. Orí bẹ́ẹ̀dì márùndínlọ́gọ́rin (75) ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lèmi àti Randi sùn sí láàárín ọdún méjì, àmọ́ a ò jẹ́ kíyẹn kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wa torí iṣẹ́ yẹn ló ṣe pàtàkì jù sí wa. Lópin ọ̀sẹ̀ kọ̀ọ̀kan, inú àwọn alàgbà yẹn máa ń dùn torí wọ́n rí i pé Ìgbìmọ̀ Olùdarí nífẹ̀ẹ́ àwọn gan-an, wọ́n sì fẹ́ káwọn ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà.

Nígbà tó yá, mo tún dá àwọn ará lẹ́kọ̀ọ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere Ìjọba Ọlọ́run. Ó máa ń rẹ àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ gan-an torí pé lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan, wọ́n máa ń jókòó ní kíláàsì fún nǹkan bíi wákàtí méje, nírọ̀lẹ́ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan, wọ́n máa ń lo wákàtí mẹ́ta láti fi ṣiṣẹ́ àṣetiléwá, wọ́n sì máa ń ṣiṣẹ́ mẹ́rin sí márùn-ún nínú kíláàsì lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Èmi àti olùkọ́ kejì máa ń sọ fún àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ náà pé Jèhófà nìkan ló lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣàṣeyọrí. Mi ò lè gbàgbé bó ṣe máa ń ya àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ yẹn lẹ́nu pé Jèhófà ń ran àwọn lọ́wọ́ torí pé àwọn gbẹ́kẹ̀ lé e, ó sì ń mú káwọn ṣe ju ohun táwọn rò pé àwọn lè ṣe.

TÁ A BÁ Ń RAN ÀWỌN ÈÈYÀN LỌ́WỌ́, TÍTÍ LÁÉ LÀÁ MÁA JÀǸFÀÀNÍ Ẹ̀

Torí pé ó wu ìyá mi láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, ìyẹn jẹ́ káwọn tí wọ́n ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tẹ̀ síwájú dáadáa, ó sì tún jẹ́ kí bàbá mi nífẹ̀ẹ́ òtítọ́. Ọjọ́ kẹta lẹ́yìn tí ìyá mi kú, ó yà wá lẹ́nu pé bàbá mi wá gbọ́ àsọyé ní Ilé Ìpàdé wa. Àtìgbà yẹn ni wọ́n ti ń wá sípàdé, ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n (26) ni wọ́n sì fi wá. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé bàbá mi ò ṣèrìbọmi, àwọn alàgbà sọ fún mi pé àwọn ló máa ń kọ́kọ́ dé ìpàdé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀.

Ìyá mi tún fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fún èmi àtàwọn àbúrò mi obìnrin. Àwọn àbúrò mi obìnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta àtàwọn ọkọ wọn ló ń sin Jèhófà tọkàntọkàn. Àwọn méjì ló ń sìn ní ẹ̀ka ọ́fíìsì wa. Ẹnì kan wà ní ẹ̀ka ọ́fíìsì Pọ́túgà, ẹnì kejì sì wà ní ẹ̀ka ọ́fíìsì Haiti.

Ní báyìí, èmi àti Randi ń ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe nílùú Hamilton, lágbègbè Ontario. Nígbà tá à ń ṣiṣẹ́ alábòójútó àyíká, a máa ń gbádùn bá a ṣe ń tẹ̀ lé àwọn ará wa lọ sọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ wàásù fún àtàwọn tí wọ́n ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àmọ́ ní báyìí, inú tiwa náà ń dùn bá a ṣe ń rí i táwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ń ṣe ohun tó fi hàn pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Inú wa ń dùn bí àwa àtàwọn ará ìjọ tuntun tá a wà ṣe túbọ̀ di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́, tá a sì rí bí Jèhófà ṣe ń ràn wọ́n lọ́wọ́ nígbà tí nǹkan rọrùn àtìgbà tí nǹkan le.

Nígbàkigbà tá a bá rántí àwọn nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn, a máa ń mọyì bí ọ̀pọ̀ èèyàn ṣe ràn wá lọ́wọ́. Ìyẹn ti jẹ́ kí ‘ọ̀rọ̀ àwọn ẹlòmíì jẹ wá lọ́kàn,’ a sì ń fún wọn níṣìírí káwọn náà lè fayé wọn sin Jèhófà débi tí agbára wọn bá gbé e dé. (2 Kọ́r. 7:6, 7) Bí àpẹẹrẹ, nínú ìdílé kan, aṣáájú-ọ̀nà ni ìyá, aṣáájú-ọ̀nà sì ni ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin wọn. Mo bi bàbá wọn bóyá òun náà ń ronú nípa iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Ó sọ fún mi pé àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta lòun ń ràn lọ́wọ́. Mo wá bi í pé, “Ṣé o lè ràn wọ́n lọ́wọ́ ju Jèhófà lọ ni?” Lẹ́yìn ìyẹn, mo fún un níṣìírí pé kó tọ́ ọ wò, kóun náà lè máa láyọ̀ bíi tiwọn. Oṣù mẹ́fà lẹ́yìn náà, òun náà bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà.

Èmi àti Randi ti pinnu pé a ò ní yéé sọ “fún ìran tó ń bọ̀” nípa “àwọn iṣẹ́ àgbàyanu” Jèhófà, ó sì dá wa lójú pé àwọn náà máa gbádùn iṣẹ́ ìsìn Jèhófà báwa náà ṣe gbádùn ẹ̀.​—Sm. 71:17, 18.

a Ní báyìí, à ń pè é ní alábòójútó Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́.

b Wo ìtàn ìgbésí ayé Arákùnrin Léonce Crépeault nínú Ilé Ìṣọ́ February 2020, ojú ìwé 26-30.