ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 30
Túbọ̀ Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Àtàwọn Ará
“Ẹ jẹ́ kí ìfẹ́ máa mú ká dàgbà sókè nínú ohun gbogbo.”—ÉFÉ. 4:15.
ORIN 2 Jèhófà Ni Orúkọ Rẹ
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ a
1. Àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ wo lo kọ́ nígbà tó o bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
ṢÉ O rántí àwọn ohun tó o kọ́ nígbà tó o bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? Ó ṣeé ṣe kó yà ẹ́ lẹ́nu pé Ọlọ́run lórúkọ tàbí kọ́kàn ẹ balẹ̀ nígbà tó o mọ̀ pé Ọlọ́run kì í dá àwọn èèyàn lóró nínú iná ọ̀run àpáàdì. Yàtọ̀ síyẹn, ó ṣeé ṣe kínú ẹ dùn gan-an nígbà tó o mọ̀ pé wàá pa dà rí àwọn èèyàn ẹ tó ti kú, tí ẹ̀ẹ́ sì jọ máa gbé láyé nínú Párádísè.
2. Yàtọ̀ sáwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tó o kọ́, àwọn nǹkan wo lo tún ṣe láti tẹ̀ síwájú? (Éfésù 5:1, 2)
2 Bó o bá ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí i, bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ tó o ní fún Jèhófà á máa pọ̀ sí i. Ìfẹ́ tó o ní fún Jèhófà yìí ló ń jẹ́ kó o máa ṣe ohun tó fẹ́. Àwọn ìlànà Bíbélì tó o ti kọ́ ló ń jẹ́ kó o ṣèpinnu tó tọ́. Yàtọ̀ síyẹn, ìwà ẹ bẹ̀rẹ̀ sí í dáa sí i torí pé o fẹ́ ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́. Bí ọmọ kan ṣe máa ń fara wé òbí ẹ̀, bẹ́ẹ̀ nìwọ náà ń fara wé Baba rẹ ọ̀run.—Ka Éfésù 5:1, 2.
3. Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ ká bi ara wa?
3 A lè bi ara wa pé: ‘Ṣé ìfẹ́ tí mo ní fún Jèhófà ń lágbára sí i ju ti ìgbà tí mo ṣèrìbọmi? Látìgbà tí mo ti ṣèrìbọmi, ṣé ìwà àti èrò mi jọ ti Jèhófà, pàápàá tó bá dọ̀rọ̀ kí n fìfẹ́ hàn sáwọn ará?’ Tó o bá rí i pé “ìfẹ́ tí o ní níbẹ̀rẹ̀” fún Jèhófà àtàwọn ará ti ń di tútù, má jẹ́ kíyẹn kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá ẹ. Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sáwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ náà. Jésù ò pa wọ́n tì, ó sì dájú pé kò ní pa àwa náà tì. (Ìfi. 2:4, 7) Ó mọ̀ pé ìfẹ́ wa ṣì lè pa dà lágbára bíi tìgbà tá a kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́.
4. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
4 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa bí ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà àtàwọn èèyàn ṣe lè túbọ̀ lágbára. Lẹ́yìn náà, a máa sọ̀rọ̀ nípa ìbùkún tá a máa rí tá a bá túbọ̀ ń fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn àti àǹfààní tó máa ṣe wọ́n.
MÁA ṢE OHUN TÁÁ JẸ́ KÓ O TÚBỌ̀ NÍFẸ̀Ẹ́ JÈHÓFÀ
5-6. Àwọn ìṣòro wo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, àmọ́ kí ló ràn án lọ́wọ́ láti máa ṣe iṣẹ́ náà nìṣó?
5 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbádùn iṣẹ́ tó ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, àmọ́ ó ní àwọn ìṣòro kan. Ó máa ń rìnrìn àjò lọ sáwọn ibi tó jìnnà gan-an, bẹ́ẹ̀ sì rèé ìrìn àjò ò rọrùn nígbà yẹn. Nígbà míì, tó bá ń rìnrìn àjò, ẹ̀mí ẹ̀ máa ń wà nínú ewu nítorí àwọn “odò” àtàwọn “dánàdánà.” Àwọn ìgbà míì sì wà tó jẹ́ pé àwọn alátakò máa ń fìyà jẹ ẹ́. (2 Kọ́r. 11:23-27) Yàtọ̀ síyẹn, kì í ṣe gbogbo ìgbà làwọn ará máa ń mọyì ohun tí Pọ́ọ̀lù ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́.—2 Kọ́r. 10:10; Fílí. 4:15.
6 Kí ló jẹ́ kí Pọ́ọ̀lù máa bá iṣẹ́ ìsìn Jèhófà nìṣó? Ohun tó ràn án lọ́wọ́ ni pé ó máa ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ànímọ́ Jèhófà látinú Ìwé Mímọ́ àtàwọn ìrírí tóun fúnra ẹ̀ ní. Torí náà, ó dá Pọ́ọ̀lù lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ òun. (Róòmù 8:38, 39; Éfé. 2:4, 5) Ìyẹn mú kóun náà nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gan-an. Pọ́ọ̀lù fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ Jèhófà torí ó ń “ṣe ìránṣẹ́ fún àwọn ẹni mímọ́,” ó “sì ń bá a lọ láti ṣe ìránṣẹ́.”—Héb. 6:10.
7. Sọ ohun tá a lè ṣe táá jẹ́ ká túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà.
7 Tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé, ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà á túbọ̀ lágbára. Bó o ṣe ń ka Bíbélì, ronú jinlẹ̀ nípa ibi tó ò ń kà, kó o lè rí nǹkan kọ́ nípa Jèhófà. Bi ara ẹ pé: ‘Báwo lohun tí mo kà yìí ṣe jẹ́ kí n mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ mi? Báwo lohun tí mo kà yìí ṣe jẹ́ kí n rí i pé ó yẹ kí n nífẹ̀ẹ́ Jèhófà?’
8. Tá a bá ń gbàdúrà, báwo nìyẹn ṣe máa jẹ́ ká túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà?
8 Ohun míì tó máa jẹ́ ká túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ni pé ká máa sọ ohun tó wà lọ́kàn wa fún un tá a bá ń gbàdúrà. (Sm. 25:4, 5) Ó sì dájú pé Jèhófà máa gbọ́ wa. (1 Jòh. 3:21, 22) Arábìnrin Khanh tó ń gbé nílẹ̀ Éṣíà sọ pé: “Ohun tí mo kọ́ nípa Jèhófà ló jẹ́ kí n kọ́kọ́ nífẹ̀ẹ́ ẹ̀, àmọ́ mo wá túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ ẹ̀ gan-an nígbà tí mo rí i pé ó ń dáhùn àwọn àdúrà mi. Ohun tó ṣe fún mi yìí ló jẹ́ kí n máa ṣe ohun tó fẹ́.” b
MÁA ṢE OHUN TÁÁ JẸ́ KÓ O TÚBỌ̀ NÍFẸ̀Ẹ́ ÀWỌN ÈÈYÀN
9. Àwọn nǹkan wo ni Tímótì ṣe tó fi hàn pé ó túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ àwọn ará?
9 Lẹ́yìn ọdún díẹ̀ tí Pọ́ọ̀lù di Kristẹni, ó pàdé ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Tímótì. Tímótì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àtàwọn ará. Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn ará Fílípì pé: “Mi ò ní ẹlòmíì tó níwà bíi [Tímótì] tó máa fi òótọ́ inú bójú tó ọ̀rọ̀ yín.” (Fílí. 2:20) Kì í ṣe bí Tímótì ṣe mọ bí wọ́n ṣe ń ṣètò nǹkan tàbí bó ṣe jẹ́ sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ tó dáńtọ́ ni Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ nínú ẹsẹ Bíbélì yìí, àmọ́ bí Tímótì ṣe ń fìfẹ́ hàn sáwọn ará ló ń sọ nípa ẹ̀. Torí náà, ó dájú pé inú àwọn ará ìjọ máa ń dùn gan-an tí wọ́n bá gbọ́ pé Tímótì ń bọ̀ wá bẹ àwọn wò.—1 Kọ́r. 4:17.
10. Kí ni Arábìnrin Anna àti ọkọ ẹ̀ ṣe tó fi hàn pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wọn?
10 Àwa náà máa ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti ran àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa lọ́wọ́. (Héb. 13:16) Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Arábìnrin Anna tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ ní àpilẹ̀kọ tó ṣáájú. Lẹ́yìn tí ìjì líle kan ṣẹlẹ̀, òun àti ọkọ ẹ̀ lọ bẹ ìdílé Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan wò. Nígbà tí wọ́n débẹ̀, wọ́n rí i pé ìjì náà ti ba òrùlé ilé wọn jẹ́, ìyẹn sì ti jẹ́ kí gbogbo aṣọ wọn dọ̀tí. Arábìnrin Anna sọ pé: “A kó gbogbo aṣọ wọn, a bá wọn fọ̀ ọ́, a sì lọ àwọn aṣọ náà ká tó dá a pa dà fún wọn. Lójú tiwa, ṣe ló dà bíi pé ohun tá a ṣe fún wọn yẹn ò tó nǹkan, àmọ́ ó jẹ́ ká túbọ̀ di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ títí di báyìí.” Ìfẹ́ tí Anna àti ọkọ ẹ̀ ní sáwọn ará ló jẹ́ kí wọ́n ràn wọ́n lọ́wọ́.—1 Jòh. 3:17, 18.
11. (a) Tá a bá ṣe ohun tó fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn ará, báwo ló ṣe máa ń rí lára wọn? (b) Kí ni Òwe 19:17 sọ pé Jèhófà máa ṣe fún wa tá a bá ń fìfẹ́ hàn sáwọn ará?
11 Tá a bá ń ṣe ohun tó fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn ará, tá a sì ń fàánú hàn sí wọn, wọ́n á rí i pé a fìwà jọ Jèhófà, a sì ń ronú bó ṣe ń ronú. Wọ́n lè mọyì ohun tá a ṣe fún wọn ju bá a ṣe rò lọ. Nígbà tí Arábìnrin Khanh tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ níṣàájú rántí àwọn tó ràn án lọ́wọ́ nígbà tó wà lọ́dọ̀ọ́, ó sọ pé: “Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn arábìnrin mi ọ̀wọ́n tá a jọ máa ń lọ wàásù. Wọ́n máa ń wá sílé mi kí wọ́n lè fi mọ́tò wọn gbé mi, a jọ máa ń lọ jẹun ọ̀sán, wọ́n sì tún máa ń fi mọ́tò wọn gbé mi pa dà sílé. Mo wá rí i pé iṣẹ́ kékeré kọ́ ni wọ́n ṣe. Wọ́n ń ṣe bẹ́ẹ̀ torí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ mi.” Òótọ́ kan ni pé kì í ṣe gbogbo èèyàn ló máa dúpẹ́ oore tá a ṣe fún wọn. Arábìnrin Khanh tún sọ nípa àwọn tó ran òun lọ́wọ́, ó ní: “Ó wù mí kí n san oore pa dà fún gbogbo àwọn tó ràn mí lọ́wọ́, àmọ́ ní báyìí, mi ò mọ ibi tí gbogbo wọn ń gbé. Àmọ́, Jèhófà mọ ibi tí wọ́n ń gbé, mo sì máa ń gbàdúrà pé kí Jèhófà bá mi san èrè fún wọn.” Òótọ́ lohun tí Arábìnrin Khanh sọ yìí. Jèhófà máa ń rí gbogbo ohun rere tá a ṣe fáwọn èèyàn, bó ti wù kó kéré tó. Ohun tá a bá ṣe máa ń ṣeyebíye lójú Jèhófà, ó sì máa ń wò ó bíi gbèsè tóun máa san pa dà fún wa.—Ka Òwe 19:17.
12. Báwo làwọn arákùnrin ṣe lè máa fìfẹ́ hàn sáwọn ará ìjọ? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
12 Tó o bá jẹ́ arákùnrin, báwo lo ṣe lè máa fìfẹ́ hàn sáwọn ará, kó o sì máa sapá láti ràn wọ́n lọ́wọ́? Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Jordan bi alàgbà kan pé kí lòun lè máa ṣe láti túbọ̀ ran àwọn ará ìjọ lọ́wọ́. Alàgbà náà gbóríyìn fún un láwọn ibi tó ti ń tẹ̀ síwájú, ó sì tún gbà á nímọ̀ràn nípa bó ṣe lè ṣe púpọ̀ sí i. Bí àpẹẹrẹ, ó gba Jordan níyànjú pé kó tètè máa dé sípàdé kó lè kí àwọn ará kí ìpàdé tó bẹ̀rẹ̀, kó máa dáhùn nípàdé, kó máa wàásù déédéé pẹ̀lú àwùjọ iṣẹ́ ìwàásù ẹ̀, kó sì máa ronú nípa àwọn nǹkan tó lè ṣe láti ran àwọn ará lọ́wọ́. Nígbà tí Jordan ṣe bẹ́ẹ̀, ó túbọ̀ já fáfá. Yàtọ̀ síyẹn, ìfẹ́ tó ní sáwọn ará túbọ̀ pọ̀ sí i. Arákùnrin Jordan kọ́ ẹ̀kọ́ pàtàkì kan. Ẹ̀kọ́ náà ni pé kí arákùnrin kan tó di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ni á ti bẹ̀rẹ̀ sí í ran àwọn ará lọ́wọ́, tó bá sì ti di ìránṣẹ́, á máa ṣe bẹ́ẹ̀ nìṣó.—1 Tím. 3:8-10, 13.
13. Báwo ni ìfẹ́ tí Arákùnrin Christian ní sáwọn ará ṣe jẹ́ kó pa dà máa ṣiṣẹ́ alàgbà?
13 Ṣé o ti ṣiṣẹ́ alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ nínú ìjọ rí? Jèhófà ò gbàgbé iṣẹ́ tó o ṣe nígbà yẹn àti ìfẹ́ tó mú kó o ṣiṣẹ́ náà. (1 Kọ́r. 15:58) Bákan náà, ó ṣì ń kíyè sí bó o ṣe ń fìfẹ́ hàn sáwọn ará. Ó dun arákùnrin kan tó ń jẹ́ Christian nígbà tí wọ́n mú un kúrò nínú ìgbìmọ̀ alàgbà. Síbẹ̀, ó sọ pé: “Mo pinnu pé màá máa sin Jèhófà nìṣó torí mo nífẹ̀ẹ́ ẹ̀, bóyá alàgbà ni mí tàbí mi kì í ṣe alàgbà.” Nígbà tó yá, ó pa dà di alàgbà. Arákùnrin Christian sọ pé: “Ẹ̀rù bà mí láti tún pa dà máa ṣiṣẹ́ alàgbà. Àmọ́ mo pinnu pé tó bá jẹ́ ìfẹ́ Jèhófà ni pé kí n pa dà máa ṣiṣẹ́ náà, màá ṣe bẹ́ẹ̀ torí pé mo nífẹ̀ẹ́ ẹ̀ àtàwọn ará.”
14. Kí lo rí kọ́ nínú ohun tí arábìnrin kan tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Georgia sọ?
14 Àwa ìránṣẹ́ Jèhófà tún máa ń fìfẹ́ hàn sáwọn aládùúgbò wa. (Mát. 22:37-39) Bí àpẹẹrẹ, Arábìnrin Elena tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Georgia sọ pé: “Níbẹ̀rẹ̀, ìfẹ́ tí mo ní fún Jèhófà nìkan ló ń jẹ́ kí n máa wàásù. Àmọ́, bí ìfẹ́ tí mo ní fún Bàbá mi ọ̀run ṣe ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ náà ni ìfẹ́ tí mo ní fáwọn èèyàn ń pọ̀ sí i. Mo máa ń gbìyànjú láti ronú nípa àwọn ìṣòro tí wọ́n ní àtohun tí mo lè bá wọn sọ tó máa wọ̀ wọ́n lọ́kàn. Bí mo ṣe ń ronú nípa àwọn ìṣòro wọn, bẹ́ẹ̀ náà ló ń wù mí láti ràn wọ́n lọ́wọ́.”—Róòmù 10:13-15.
JÈHÓFÀ MÁA BÙ KÚN WA TÁ A BÁ Ń FÌFẸ́ HÀN SÁWỌN ÈÈYÀN
15-16. Bá a ṣe rí i nínú àwọn àwòrán yẹn, báwo ni Jèhófà ṣe máa ń bù kún wa tá a bá fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn?
15 Kì í ṣàwọn tá a fìfẹ́ hàn sí nìkan ló máa ń jàǹfààní ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí àjàkálẹ̀ àrùn kòrónà bẹ̀rẹ̀, arákùnrin kan tó ń jẹ́ Paolo àti ìyàwó ẹ̀ ran ọ̀pọ̀ àwọn arábìnrin tó ti dàgbà lọ́wọ́, kí wọ́n lè mọ bí wọ́n á ṣe máa fi fóònù wọn wàásù. Nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀, ó ṣòro fún ọ̀kan lára àwọn arábìnrin náà láti fi fóònù ẹ̀ wàásù, àmọ́ nígbà tó yá, ó mọ̀ ọ́n lò dáadáa. Kódà, fóònù yìí ló fi pe àwọn mọ̀lẹ́bí ẹ̀ wá sí Ìrántí Ikú Kristi. Ó máa yà yín lẹ́nu pé ọgọ́ta (60) lára àwọn mọ̀lẹ́bí ẹ̀ ló ṣe Ìrántí Ikú Kristi látorí fóònù! Ẹ ò rí i pé arábìnrin yẹn àtàwọn mọ̀lẹ́bí ẹ̀ ló jàǹfààní bí Paolo àtìyàwó ẹ̀ ṣe fìfẹ́ hàn sí i. Nígbà tó yá, arábìnrin yẹn kọ̀wé sí Paolo pé: “Mo dúpẹ́ pé ẹ kọ́ àwa àgbàlagbà bá a ṣe máa lo fóònù wa. Mi ò ní gbàgbé bí Jèhófà ṣe fìfẹ́ hàn sí wa àti bẹ́ ẹ ṣe ṣiṣẹ́ kára láti ràn wá lọ́wọ́.”
16 Irú àwọn ìrírí báyìí ti kọ́ Paolo ní ẹ̀kọ́ pàtàkì kan. Ó rí i pé ìfẹ́ ṣe pàtàkì ju kéèyàn ní ìmọ̀ àtàwọn ẹ̀bùn kan lọ. Ó sọ pé: “Alábòójútó àyíká ni mí tẹ́lẹ̀, àwọn ará ti lè gbàgbé àwọn àsọyé tí mo sọ, àmọ́ mo mọ̀ pé wọn ò ní gbàgbé àwọn nǹkan tí mo ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́.”
17. Tá a bá ń fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn, ta ló tún máa jàǹfààní?
17 Tá a bá ń fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn, àwa fúnra wa máa jàǹfààní lọ́nà tá ò lérò. Arákùnrin Jonathan tó ń gbé lórílẹ̀-èdè New Zealand rí i pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí. Ní ọ̀sán Saturday kan tí oòrùn mú gan-an, ó rí arákùnrin aṣáájú-ọ̀nà kan tó ń dá wàásù lójú ọ̀nà. Jonathan wá pinnu pé òun á máa bá arákùnrin náà ṣiṣẹ́ láwọn ọ̀sán Saturday. Nígbà tó ń ṣèpinnu yẹn, kò mọ̀ pé àǹfààní tóun máa rí máa pọ̀ gan-an. Jonathan sọ pé: “Nígbà yẹn, kì í wù mí láti máa wàásù. Àmọ́ bí mo ṣe ń kíyè sí ọ̀nà tí arákùnrin yẹn ń gbà kọ́ni, tó sì ń ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ẹ̀, mo bẹ̀rẹ̀ sí í gbádùn iṣẹ́ ìwàásù. Yàtọ̀ síyẹn, mo di ọ̀rẹ́ arákùnrin náà, ó sì ràn mí lọ́wọ́ kí n lè túbọ̀ máa gbádùn iṣẹ́ ìwàásù, kí n sì sún mọ́ Jèhófà.”
18. Kí ni Jèhófà fẹ́ ká ṣe?
18 Jèhófà fẹ́ ká nífẹ̀ẹ́ òun àtàwọn èèyàn. Àwọn nǹkan tá a ti kọ́ nínú àpilẹ̀kọ yìí jẹ́ ká rí i pé tá a bá ń ka Bíbélì, tá à ń ṣàṣàrò lórí ohun tá a kà, tá a sì ń gbàdúrà déédéé, ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà á túbọ̀ lágbára. Bá a ṣe lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa ni pé ká máa ṣe àwọn nǹkan tó máa ràn wọ́n lọ́wọ́. Bí ìfẹ́ tá a ní bá ṣe ń lágbára sí i, àá túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà àtàwọn ará, àá sì jọ máa ṣọ̀rẹ́ títí láé.
ORIN 109 Ní Ìfẹ́ Tó Ti Ọkàn Wá
a Bóyá a ṣẹ̀ṣẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ tàbí ó ti pẹ́ tá a ti ń sin Jèhófà, gbogbo wa ló yẹ ká máa tẹ̀ síwájú. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa nǹkan táá jẹ́ ká máa tẹ̀ síwájú. Nǹkan náà ni pé ká jẹ́ kí ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà àtàwọn èèyàn máa pọ̀ sí i. Bó o ṣe ń ṣàṣàrò lórí àpilẹ̀kọ yìí, máa ronú nípa ohun tó o ti ṣe láti tẹ̀ síwájú àtohun tó o lè ṣe kó o lè túbọ̀ tẹ̀ síwájú.
b A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.