Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Wàá Jẹ́ Kí Amọ̀kòkò Ńlá Náà Mọ Ẹ́?

Ṣé Wàá Jẹ́ Kí Amọ̀kòkò Ńlá Náà Mọ Ẹ́?

“Wò ó! Bí amọ̀ ní ọwọ́ amọ̀kòkò, bẹ́ẹ̀ ni ẹ rí ní ọwọ́ mi.”​—JER. 18:6.

ORIN: 60, 22

1, 2. Kí nìdí tí Ọlọ́run fi pe Dáníẹ́lì ní “ọkùnrin fífani-lọ́kàn-mọ́ra gidigidi”? Báwo la ṣe lè jẹ́ onígbọràn bíi ti Dáníẹ́lì?

NÍGBÀ táwọn Júù tí wọ́n kó nígbèkùn dé ìlú Bábílónì, kò síbi tí wọ́n yíjú sí tí wọn ò rí ère òrìṣà táwọn èèyàn náà ń bọ, bẹ́ẹ̀ sì làwọn èèyàn náà kò yé bẹ̀rù àwọn ẹ̀mí èṣù. Síbẹ̀, àwọn Júù tó jẹ́ adúróṣinṣin kò jẹ́ kí àwọn èèyàn ìlú Bábílónì sọ wọ́n dà bí wọ́n ṣe dà. Lára àwọn Júù bẹ́ẹ̀ ni Dáníẹ́lì àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ mẹ́ta. (Dán. 1:​6, 8, 12; 3:​16-18) Dáníẹ́lì àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ pinnu pé Jèhófà tó jẹ́ Amọ̀kòkò àwọn nìkan làwọn máa jọ́sìn tọkàntara. Ohun tí wọ́n sì ṣe nìyẹn! Ó fẹ́ẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ìgbésí ayé Dáníẹ́lì ló lò nílùú Bábílónì, síbẹ̀ áńgẹ́lì Ọlọ́run pè é ní “ọkùnrin fífani-lọ́kàn-mọ́ra gidigidi.”​—⁠Dán. 10:​11, 19.

2 Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, amọ̀kòkò kan ló máa ń pinnu ohun tó fẹ́ fi amọ̀ mọ, ohun tó bá sì fẹ́ ló máa ṣe. Àwa tá à ń fòótọ́ inú sin Jèhófà lónìí mọ̀ pé Jèhófà ni Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run àti pé òun ló lẹ́tọ̀ọ́ láti pinnu ohun tó máa fi àwọn orílẹ̀-èdè àtàwọn èèyàn inú rẹ̀ mọ. (Ka Jeremáyà 18:⁠6.) Ọlọ́run tún láṣẹ láti fi ẹnì kọ̀ọ̀kan wa mọ ohun tó bá fẹ́. Àmọ́, kì í mú wa lọ́ranyàn láti ṣe ohun tó bá fẹ́, ṣe ló máa ń fún wa láǹfààní láti yan ohun tó wù wá. Torí náà, ẹ jẹ́ ká jíròrò àwọn kókó mẹ́ta táá jẹ́ ká dà bí amọ̀ rírọ̀ lọ́wọ́ Ọlọ́run: (1) Kí la lè ṣe tá ò fi ní máa kọtí ikún sáwọn ìmọ̀ràn Ọlọ́run? (2) Báwo la ṣe lè ní àwọn ànímọ́ táá jẹ́ ká dà bí amọ̀ tó rọ̀ lọ́wọ́ Amọ̀kòkò wa, ká sì máa fi ara wa sábẹ́ rẹ̀? (3) Báwo làwọn òbí ṣe lè gbà kí Ọlọ́run máa darí wọn bí wọ́n ṣe ń tọ́ àwọn ọmọ wọn?

ṢỌ́RA FÚN ÀWỌN ÌWÀ TÍ KÌ Í JẸ́ KÉÈYÀN ṢE ÌFẸ́ ỌLỌ́RUN

3. Àwọn ìwà wo ló lè mú kí ọkàn wa le? Sọ àpẹẹrẹ kan.

3 Ìwé Òwe 4:23 sọ pé, “Ju gbogbo ohun mìíràn tí a ní láti ṣọ́, fi ìṣọ́ ṣọ́ ọkàn-àyà rẹ, nítorí láti inú rẹ̀ ni àwọn orísun ìyè ti wá.” Àwọn nǹkan tó lè mú kí ọkàn wa le wo ló yẹ ká ṣọ́ra fún? Lára ẹ̀ ni ìgbéraga, kéèyàn máa dẹ́ṣẹ̀ tàbí kéèyàn jẹ́ aláìnígbàgbọ́. Àwọn ìwà yìí lè sọni di aláìgbọràn, ó sì lè mú kéèyàn ya ọlọ̀tẹ̀. (Dán. 5:​1, 20; Héb. 3:​13, 18, 19) Àpẹẹrẹ ẹnì kan tó lẹ́mìí ìgbéraga ni Ùsáyà Ọba Júdà. (Ka 2 Kíróníkà 26:​3-5, 16-21.) Níbẹ̀rẹ̀, Bíbélì ròyìn pé Ùsáyà ṣe “ohun tí ó tọ́ ní ojú Jèhófà,” àti pé ó ‘ń bá a lọ ní wíwá Ọlọ́run.’ Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run ló fún Ùsáyà lágbára, Bíbélì sọ pé “gbàrà tí ó di alágbára, ọkàn-àyà rẹ̀ di onírera.” Ìgbéraga náà wọ̀ ọ́ lẹ́wù débi pé ó lọ sí tẹ́ńpìlì láti sun tùràrí. Ìkọjá ayé gbáà, iṣẹ́ tó jẹ́ pé àwọn àlùfáà ọmọ Áárónì nìkan ló máa ń ṣe é. Nígbà táwọn àlùfáà sì sọ fún un pé ohun tó ń ṣe kò dáa, ńṣe ni Ùsáyà gbaná jẹ! Ibo lọ̀rọ̀ náà wá já sí? Ìtìjú ló bá kúrò níbẹ̀, Ọlọ́run sọ ọ́ di adẹ́tẹ̀, bó sì ṣe wà nìyẹn tó fi kú.​—⁠Òwe 16:⁠18.

4, 5. Kí ló lè ṣẹlẹ̀ tá a bá gbà kí ìgbéraga wọ̀ wá lẹ́wù? Sọ àpẹẹrẹ kan.

4 Tá ò bá kíyè sára, tá a jẹ́ kí ìgbéraga wọ̀ wá lẹ́wù, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í “ro ara [wa] ju bí ó ti yẹ ní rírò lọ,” débi pé a ò ní gba ìbáwí tí wọ́n bá fún wa látinú Bíbélì. (Róòmù 12:3; Òwe 29:⁠1) Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ alàgbà kan tó ń jẹ́ Jim, ẹnu òun àtàwọn alàgbà yòókù ò kò lórí ọ̀rọ̀ kan nínú ìjọ, ló bá fárígá. Jim sọ pé: “Mo sọ fáwọn arákùnrin náà pé wọn ò nífẹ̀ẹ́, mo sì fìbínú kúrò láàárín wọn.” Lẹ́yìn oṣù mẹ́fà, Jim lọ sí ìjọ míì tí kò jìnnà púpọ̀ síbẹ̀, àmọ́ wọ́n ò sọ ọ́ di alàgbà níbẹ̀. Ó sọ pé: “Inú bí mi. Lójú ara mi, mo gbà pé èmi ni mò ń ṣe ohun tó tọ́. Torí náà, mo fi ètò Ọlọ́run sílẹ̀.” Ọdún mẹ́wàá gbáko ni Jim ò fi sin Jèhófà. Ó wá sọ pé: “Mo sọ ara mi di òrìṣà àkúnlẹ̀bọ, mo wá ń dá Jèhófà lẹ́bi pé òun ló fa ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí mi. Láwọn ọdún yẹn, àwọn ará ò yé bẹ̀ mí wò, wọ́n á bá mi sọ̀rọ̀, àmọ́ ẹ̀yìn etí mi ni gbogbo ohun tí wọ́n ń sọ bọ́ sí.”

5 Àpẹẹrẹ arákùnrin Jim jẹ́ ká rí i pé ìgbéraga lè mú kéèyàn máa dá ara rẹ̀ láre, ìyẹn sì lè mú kéèyàn ṣòro tẹ̀ síbí tẹ̀ sọ́hùn-ún. (Jer. 17:⁠9) Jim sọ pé, “Ṣe ni mò ń sọ fúnra mi pé àwọn arákùnrin yẹn ni ò ṣe ohun tó tọ́.” Ǹjẹ́ inú ti bí ẹ rí torí ohun tí ará kan ṣe sí ẹ tàbí torí àǹfààní iṣẹ́ ìsìn kan tó bọ́ mọ́ ẹ lọ́wọ́? Nígbà tó ṣẹlẹ̀, kí lo ṣe? Ṣé o wá bẹ̀rẹ̀ sí í gbéra ga ni, àbí ohun tó gbà ẹ́ lọ́kàn jù ni bó o ṣe máa yanjú ọ̀rọ̀ náà tí wàá sì jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà?​—⁠Ka Sáàmù 119:165; Kólósè 3:⁠13.

6. Kí ló lè ṣẹlẹ̀ tá a bá ń dẹ́ṣẹ̀?

6 Téèyàn bá ń mu ẹ̀ṣẹ̀ bí ẹní mu omi, bóyá tó tiẹ̀ ń yọ́ ẹ̀ṣẹ̀ dá, ṣe nirú ẹni bẹ́ẹ̀ á máa kọtí ikún sí ìmọ̀ràn Ọlọ́run. Tó bá yá, ẹ̀ṣẹ̀ á wá di bárakú sí i lára. Arákùnrin kan sọ pé òun bá ìwàkiwà tòun débi pé ẹ̀rí ọkàn òun ò gún òun ní kẹ́ṣẹ́ mọ́. (Oníw. 8:11) Arákùnrin míì tó máa ń wo àwòrán oníhòòhò sọ pé: “Mo dẹni tó ń ṣàríwísí àwọn alàgbà.” Ìwòkuwò tó ń wò náà wá mú kó máa jó rẹ̀yìn nínú ìjọsìn Ọlọ́run. Nígbà tí ohun tó ń ṣe lu síta, àwọn alàgbà ràn án lọ́wọ́. Ká sòótọ́, ẹlẹ́ran ara ni gbogbo wa. Àmọ́, tó bá di pé a bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàríwísí àwọn ará tàbí tá à ń ronú pé kò sóhun tó burú nínú ìwàkiwà tá à ń hù, tá ò tọ́rọ̀ ìdáríjì lọ́wọ́ Ọlọ́run, tá ò sì jẹ́ káwọn alàgbà ràn wá lọ́wọ́, a jẹ́ pé ọkàn wa ti ń le nìyẹn.

7, 8. (a) Báwo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe jẹ́ kí àìnígbàgbọ́ sọ wọ́n di alágídí? (b) Kí la rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn?

7 Àpẹẹrẹ kan tó jẹ́ ká mọ̀ pé téèyàn ò bá nígbàgbọ́, ọkàn ẹ̀ lè bẹ̀rẹ̀ sí í le ni tàwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí Jèhófà dá nídè kúrò ní Íjíbítì. Wọ́n fojú ara wọn rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ ìyanu tí Jèhófà ṣe nítorí wọn, kódà, àwòdami-ẹnu làwọn kan lára àwọn iṣẹ́ ìyanu náà! Síbẹ̀, nígbà tó ku díẹ̀ kí wọ́n wọ Ilẹ̀ Ìlérí, wọ́n sọ ìgbàgbọ́ nù. Kàkà kí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ṣe ni wọ́n ń bẹ̀rù tí wọ́n sì ń ráhùn sí Mósè. Àní wọ́n tiẹ̀ tún fẹ́ pa dà sí Íjíbítì, níbi tí wọ́n ti ń lò wọ́n nílò ẹrú! Ohun tí wọ́n ṣe yẹn dun Jèhófà gan-an. Jèhófà sọ pé, “Yóò ti pẹ́ tó tí àwọn ènìyàn yìí yóò máa hùwà àìlọ́wọ̀ sí mi?” (Núm. 14:​1-4, 11; Sm. 78:​40, 41) Torí pé wọ́n ya alágídí tí wọn ò sì lo ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, ìran yẹn ṣègbé sínú aginjù.

8 Ní báyìí táwa náà ti ń sún mọ́ ayé tuntun, a máa dán ìgbàgbọ́ tiwa náà wò. Torí náà, á dáa ká ronú lórí bí ìgbàgbọ́ wa ṣe lágbára tó. Bí àpẹẹrẹ, a lè ronú lórí ojú tá a fi ń wo ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nínú Mátíù 6:33. Bi ara rẹ pé: ‘Ṣé àwọn nǹkan tí mo kà sí pàtàkì àtàwọn ìpinnu tí mò ń ṣe fi hàn pé lóòótọ́ ni mo gba ohun tí Jésù sọ gbọ́? Tó bá di pé kí n máa pa ìpàdé tàbí òde ẹ̀rí jẹ kí owó tó ń wọlé fún mi lè túbọ̀ gbé pẹ́ẹ́lí sí i, kí ni màá ṣe? Tí iṣẹ́ tí mò ń ṣe ò bá jẹ́ kí n ráyè ńkọ́? Ṣé màá gbà kí ayé sọ mí dà bó ṣe dà, kó sì fà mí kúrò nínú ètò Ọlọ́run?’

9. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa “dán” ara wa wò bóyá a ṣì wà nínú ìgbàgbọ́, ọ̀nà wo la sì lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀?

9 Àpẹẹrẹ míì ni ti ìránṣẹ́ Jèhófà kan tí kì í fẹ́ fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò lórí irú ẹni tó yẹ kó máa bá ṣọ̀rẹ́, irú eré ìnàjú tó yẹ kí Kristẹni máa ṣe àti ìtọ́ni Bíbélì tó ní ká má ṣe kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú ẹni tá a yọ lẹ́gbẹ́. Wá bi ara rẹ pé, ‘Ṣé bọ́rọ̀ tèmi náà ṣe rí nìyẹn?’ Tá a bá rí i pé bó ṣe rí nìyẹn, ó yẹ ká tètè yá a wá bí ìgbàgbọ́ wa ṣe máa túbọ̀ lágbára! Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbà wá níyànjú pé, “Ẹ máa dán ara yín wò bóyá ẹ wà nínú ìgbàgbọ́, ẹ máa wádìí ohun tí ẹ̀yin fúnra yín jẹ́.” (2 Kọ́r. 13:⁠5) Ó yẹ ká máa fi ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ yẹ ara wa wò nígbà gbogbo.

JẸ́ KÍ JÈHÓFÀ MÁA MỌ Ẹ́ NÌṢÓ

10. Kí ló máa mú ká dà bí amọ̀ rírọ̀ lọ́wọ́ Jèhófà?

10 Lára àwọn nǹkan tí Jèhófà fún wa ká lè dà bí amọ̀ tó rọ̀ ni Bíbélì, ìjọ Kristẹni àti iṣẹ́ ìwàásù. Bí omi ṣe máa ń mú kí amọ̀ rọ̀, bẹ́ẹ̀ ni kíka Bíbélì lójoojúmọ́ àti ṣíṣàṣàrò ṣe ń mú ká dà bí amọ̀ tó ṣeé mọ lọ́wọ́ Jèhófà. Jèhófà pàṣẹ fún àwọn ọba Ísírẹ́lì pé kí wọ́n kọ ẹ̀dà Òfin Ọlọ́run fún ara wọn, kí wọ́n sì máa kà á lójoojúmọ́. (Diu. 17:​18, 19) Àwọn àpọ́sítélì náà mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì pé káwọn máa ka Ìwé Mímọ́, káwọn sì máa ṣàṣàrò káwọn lè ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn. Tí wọ́n bá ń kọ̀wé sí ìjọ, àìmọye ìgbà ni wọ́n máa ń tọ́ka sí Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù tàbí kí wọ́n fa ọ̀rọ̀ yọ nínú wọn. Wọ́n sì máa ń rọ àwọn tí wọ́n ń wàásù fún pé káwọn náà máa ṣe bẹ́ẹ̀. (Ìṣe 17:11) Lóde òní, àwa náà gbà pé ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́, ká sì máa ṣàṣàrò lé e lórí tàdúràtàdúrà. (1 Tím. 4:15) Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, inú Jèhófà á dùn pé a jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, àá sì dà bí amọ̀ tó ṣeé mọ lọ́wọ́ rẹ̀.

Máa lo àwọn ohun tí Ọlọ́run fún wa kó o lè dà bí amọ̀ tó ṣeé mọ lọ́wọ́ rẹ̀ (Wo ìpínrọ̀ 10 sí 13)

11, 12. Báwo ni Jèhófà ṣe máa ń lo ìjọ Kristẹni láti mọ ẹnì kan bí ipò onítọ̀hún bá ṣe gbà? Sọ àpẹẹrẹ kan.

11 Jèhófà ń tipasẹ̀ ìjọ Kristẹni mọ ẹnì kọ̀ọ̀kan wa bí ipò oníkálukú wa ṣe gbà. Arákùnrin Jim tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lókè ṣàtúnṣe nígbà tí alàgbà kan mú un lọ́rẹ̀ẹ́ tó sì ràn án lọ́wọ́, nípa bẹ́ẹ̀ Jim di ẹni pẹ̀lẹ́. Jim wá sọ pé, “Alàgbà yẹn ò kàn mí lábùkù, bẹ́ẹ̀ sì ni kò bẹnu àtẹ́ lù mí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó fi dá mi lójú pé mo lè ṣàtúnṣe tó yẹ, ó sì jẹ́ kí n mọ̀ pé òun á ràn mí lọ́wọ́.” Lẹ́yìn nǹkan bí oṣù mẹ́ta, alàgbà yẹn ní kí Jim wá sípàdé ìjọ. Ó sọ pé, “Àwọn ará inú ìjọ gbà mí tọwọ́tẹsẹ̀, ìfẹ́ tí wọ́n fi hàn sí mi ló mú kí n yí èrò mi pa dà. Mo wá rí i pé kò yẹ kí n kàn máa ro tèmi nìkan ṣáá. Àwọn ará ò fi mí sílẹ̀ rárá títí mo fi dẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú rẹ̀. Ìyàwó mi náà ò sì kẹ̀rẹ̀, kódà òpómúléró ló jẹ́ fún mi nípa tẹ̀mí. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn àpilẹ̀kọ bíi ‘Kò Yẹ Kí A Dẹ́bi fun Jehofa’ àti ‘Ẹ Fi Iduroṣinṣin Ṣiṣẹsin Jehofa,’ tó wà nínú Ilé Ìṣọ́nà November 15, 1992, fún mi níṣìírí gan-an.”

12 Nígbà tó yá, arákùnrin Jim di alàgbà. Látìgbà yẹn, òun náà ti ṣèrànwọ́ fáwọn ará tó nírú ìṣòro bíi tiẹ̀, ó sì ti mú kí wọ́n máa ṣe dáadáa nínú ètò Ọlọ́run. Jim wá sọ pé: “Mo rò pé ohun tí Jèhófà fẹ́ ni mò ń ṣe nígbà yẹn, láìmọ̀ pé òdìkejì pátápátá ni mò ń ṣe! Ó dùn mí gan-an pé mo jẹ́ kí ìgbéraga wọ̀ mí lẹ́wù débi pé mi ò kọbi ara sóhun tó ṣe pàtàkì jù, àṣìṣe àwọn ẹni ẹlẹ́ni ni mò ń rán.”​—⁠1 Kọ́r. 10:⁠12.

13. Àwọn ànímọ́ wo ni iṣẹ́ ìwàásù ń mú ká ní, àǹfààní wo nìyẹn sì máa ń mú wá?

13 Báwo ni iṣẹ́ ìwàásù ṣe máa ń sọ wá di amọ̀ tó wúlò fún Ọlọ́run? Iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe máa ń mú ká lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ àtàwọn ànímọ́ rere míì tó para pọ̀ jẹ́ èso tẹ̀mí. (Gál. 5:​22, 23) Ìwọ náà ronú nípa àwọn ìwà rere tí iṣẹ́ ìwàásù ti jẹ́ kó o ní. Àwa náà kúkú mọ̀ pé, bá a ṣe ń hùwà tó yẹ Kristẹni lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, ó ń buyì kún ọ̀rọ̀ wa, ó sì wà lára ohun tó máa ń jẹ́ káwọn èèyàn tẹ́tí sọ́rọ̀ wa. Bí àpẹẹrẹ, lórílẹ̀-èdè Ọsirélíà, àwọn Ẹlẹ́rìí méjì wàásù fún obìnrin kan, àmọ́ obìnrin yẹn sọ kòbákùngbé ọ̀rọ̀ sí wọn, síbẹ̀ àwọn méjèèjì ò gbin. Lẹ́yìn tí wọ́n lọ, obìnrin náà da ọ̀rọ̀ yẹn rò, ó rí i pé ohun tóun ṣe ò dáa, ló bá kọ lẹ́tà sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa. Díẹ̀ lára ohun tó kọ rèé: “Ẹ jọ̀ọ́ ẹ bá mi bẹ àwọn méjì tó wá wàásù fún mi, èèyàn jẹ́jẹ́ ni wọ́n, wọ́n sì lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀. Ìwà àìlójútì gbáà ni mo hù, mo sì jọ ara mi lójú. Ohun tí mo ṣe kò bọ́gbọ́n mu rárá, káwọn èèyàn wá wàásù Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún mi, kí n sì lé wọn bí ẹni lé ajá, ó kù díẹ̀ káàtó.” Ẹ gbọ́ ná, ká ní ńṣe làwọn ará yẹn tiẹ̀ bínú díẹ̀ lọ́jọ́ yẹn, ṣé obìnrin yìí á lè kọ irú ohun tó kọ yẹn? Kò dájú pé á ṣe bẹ́ẹ̀. Ẹ ò rí i pé lóòótọ́ ni iṣẹ́ ìwàásù ń ṣe wá láǹfààní, àwa nìkan sì kọ́, ó tún ń ṣàǹfààní fáwọn tá à ń wàásù fún.

JẸ́ KÍ ỌLỌ́RUN MÁA DARÍ Ẹ BÓ O ṢE Ń TỌ́ ÀWỌN ỌMỌ RẸ

14. Kí làwọn òbí gbọ́dọ̀ ṣe tí wọ́n bá fẹ́ kí àwọn ọmọ wọn gbẹ̀kọ́?

14 Ó máa ń yá ọ̀pọ̀ ọmọdé lára láti kẹ́kọ̀ọ́, wọ́n sì sábà máa ń lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀. (Mát. 18:​1-4) Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn òbí tó gbọ́n máa ń sapá láti kọ́ àwọn ọmọ wọn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, wọ́n sì máa ń ṣe ohun táá mú káwọn ọmọ náà nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ tọkàntara. (2 Tím. 3:​14, 15) Àmọ́ o, káwọn òbí tó lè ṣèyẹn láṣeyọrí, àwọn alára gbọ́dọ̀ jẹ́ kí òtítọ́ jinlẹ̀ lọ́kàn tiwọn, kó hàn pé òtítọ́ ló ń darí ìgbésí ayé wọn. Nípa bẹ́ẹ̀, kì í ṣe nínú ọ̀rọ̀ nìkan làwọn ọmọ á ti máa kẹ́kọ̀ọ́, wọ́n á tún máa kọ́ ọ nínú ìwà àwọn òbí wọn. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n á mọ̀ pé ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí àwọn ló mú káwọn òbí àwọn máa bá àwọn wí.

15, 16. Báwo làwọn òbí ṣe lè fi hàn pé àwọn fọkàn tán Ọlọ́run tó bá di pé a yọ ọmọ wọn lẹ́gbẹ́?

15 Láìka báwọn òbí ti gbìyànjú tó, àwọn ọmọ kan ṣì máa ń fi ètò Ọlọ́run sílẹ̀ tàbí kí wọ́n yọ wọ́n lẹ́gbẹ́, ìyẹn sì máa ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá ìdílé wọn. Arábìnrin kan tó ń gbé lórílẹ̀-èdè South Africa sọ pé, “Nígbà tí wọ́n yọ ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin lẹ́gbẹ́, ṣe ló dà bíi pé ó kú. Nǹkan ìbànújẹ́ gbáà ni!” Kí ni arábìnrin náà àtàwọn òbí rẹ̀ wá ṣe? Ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ ni wọ́n ṣe. (Ka 1 Kọ́ríńtì 5:​11, 13.) Àwọn òbí náà sọ pé: “A pinnu pé ohun tí Bíbélì sọ la máa ṣe, a gbà pé béèyàn bá ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́, ire ló máa já sí. A gbà pé Jèhófà ló ń bá ẹni tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́ wí, ó sì dá wa lójú pé ìfẹ́ tí Jèhófà ní sáwa èèyàn ló mú kó máa bá wa wí, ó sì máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ déwọ̀n tó yẹ. Torí bẹ́ẹ̀, a kì í bá ọmọ náà ṣe wọléwọ̀de àyàfi tó bá pọn dandan pé ká sọ àwọn ọ̀rọ̀ pàtàkì tó jẹ mọ́ ti ìdílé.”

16 Báwo lọ̀rọ̀ yìí ṣe rí lára ọmọ náà? Lẹ́yìn tí wọ́n gbà á pa dà, ó sọ pé: “Mo mọ̀ pé àwọn ẹbí mi ò kórìíra mi, ìlànà Jèhófà àti ti ètò rẹ̀ ni wọ́n ń tẹ̀ lé.” Ó tún sọ pé: “Nígbà tíwọ náà bá rí i pé o ò rẹ́ni fojú jọ, tó wá di dandan pé kó o bẹ Jèhófà pé kó ṣàánú ẹ, kó sì dárí jì ẹ́, wàá mọ̀ pé kò sóhun tó o lè ṣe láìsí ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run.” Ẹ wo bí inú àwọn ìdílé ọ̀dọ́kùnrin yẹn ṣe máa dùn tó nígbà tí wọ́n gbà á pa dà sínú ìjọ! Láìsí àní-àní, tá a bá ń yíjú sí Jèhófà ní gbogbo ọ̀nà wa, àá rí i pé ire lọ̀rọ̀ wa máa já sí.​—⁠Òwe 3:​5, 6; 28:⁠26.

17. Kí nìdí tó fi yẹ ká jẹ́ kí Jèhófà máa darí gbogbo ohun tá a bá ń ṣe nígbèésí ayé wa? Àǹfààní wo nìyẹn sì máa ṣe wá?

17 Wòlíì Aísáyà sọ àsọtẹ́lẹ̀ ohun táwọn Júù tó ronú pìwà dà máa sọ nígbà tí wọ́n bá ti ìgbèkùn dé, wọ́n á ní: “Jèhófà, ìwọ ni Baba wa. Àwa ni amọ̀, ìwọ sì ni Ẹni tí ó mọ wá; gbogbo wa jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.” Wọ́n á wá bẹ̀bẹ̀ pé: “Má sì rántí ìṣìnà wa títí láé. Jọ̀wọ́, wò ó, nísinsìnyí: ènìyàn rẹ ni gbogbo wa jẹ́.” (Aísá. 64:​8, 9) Táwa náà bá fi ara wa sábẹ́ Jèhófà tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀, tá a sì jẹ́ kó hàn nínú bá a ṣe ń gbé ìgbésí ayé wa, Jèhófà máa kà wá sẹ́ni ọ̀wọ́n bó ṣe ka wòlíì Dáníẹ́lì sẹ́ni ọ̀wọ́n. Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà á máa mọ wá nìṣó nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ àti ètò rẹ̀ débi pé lọ́jọ́ kan, àwa náà á máa jọ́sìn rẹ̀ láìní àbùkù kankan, torí pé àá ti di “ọmọ Ọlọ́run.”​—⁠Róòmù 8:⁠21.