Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Jèhófà Ọlọ́run Wa, Jèhófà Kan Ṣoṣo Ni”

“Jèhófà Ọlọ́run Wa, Jèhófà Kan Ṣoṣo Ni”

“Fetí sílẹ̀, ìwọ Ísírẹ́lì: Jèhófà Ọlọ́run wa, Jèhófà kan ṣoṣo ni.”​—DIU. 6:4.

ORIN: 138, 112

1, 2. (a) Kí ló mú káwọn èèyàn mọ ohun tó wà nínú Diutarónómì 6:4 dáadáa? (b) Kí nìdí tí Mósè fi sọ̀rọ̀ yìí?

ỌJỌ́ pẹ́ táwọn onísìn Júù ti máa ń ka gbólóhùn tá a fà yọ nínú Diutarónómì 6:⁠4. Wọ́n máa ń kà á gẹ́gẹ́ bí apá kan àdúrà pàtàkì tí wọ́n máa ń gbà lóòrèkóòrè. Kódà, àràárọ̀ àti alaalẹ́ ni wọ́n máa ń gba àdúrà náà. Wọ́n máa ń pe àdúrà yìí ní Shema, ìyẹn ọ̀rọ̀ àkọ́kọ́ nínú ẹsẹ Bíbélì yẹn lédè Hébérù. Àwọn onísìn Júù máa ń gba àdúrà yìí kí wọ́n lè fi hàn pé kò sẹ́lòmíì tí àwọn ń sìn àfi Ọlọ́run.

2 Gbólóhùn yẹn wà lára ọ̀rọ̀ ìdágbére tí Mósè sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Móábù lọ́dún 1473 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Nígbà yẹn, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fẹ́ sọdá odò Jọ́dánì kí wọ́n sì gba Ilẹ̀ Ìlérí. (Diu. 6:⁠1) Mósè tó ti jẹ́ aṣáájú wọn fún ogójì [40] ọdún ló ń rọ àwọn èèyàn náà pé kí wọ́n nígboyà torí wọ́n máa tó dojú kọ ọ̀pọ̀ ìṣòro. Èyí á gba pé kí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, kí wọ́n sì jẹ́ olóòótọ́ sí i. Torí náà, ó dájú pé ọ̀rọ̀ ìdágbére tí Mósè sọ máa wọ àwọn èèyàn náà lọ́kàn gan-an. Lẹ́yìn tí Mósè ti mẹ́nu ba àwọn Òfin Mẹ́wàá àtàwọn àṣẹ míì tí Jèhófà pa fún wọn, ó sọ ọ̀rọ̀ tó fakíki tó wà nínú Diutarónómì 6:​4, 5. (Kà á.)

3. Àwọn ìbéèrè wo la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

3 Ṣé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wà níbẹ̀ lọ́jọ́ yẹn ò mọ̀ pé Jèhófà Ọlọ́run wọn jẹ́ “Jèhófà kan ṣoṣo” ni? Ó dájú pé wọ́n mọ̀. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ olóòótọ́ mọ̀ pé Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo làwọn ń sìn, ìyẹn Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọn Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù. Kí wá nìdí tí Mósè tún fi rán wọn létí pé Jèhófà Ọlọ́run wọn jẹ́ “Jèhófà kan ṣoṣo”? Ǹjẹ́ èyí ní nǹkan ṣe pẹ̀lú ẹsẹ 5 tó tẹ̀ lé e tó sọ pé ká nífẹ̀ẹ́ Jèhófà pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà wa, ọkàn wa àti okun wa? Ẹ̀kọ́ wo lọ̀rọ̀ tó wà nínú Diutarónómì 6:​4, 5 kọ́ wa lónìí?

BÍ JÈHÓFÀ ṢE JẸ́ ỌLỌ́RUN KAN ṢOṢO

4, 5. (a) Kí ni ọ̀rọ̀ náà “Jèhófà kan ṣoṣo” túmọ̀ sí? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe yàtọ̀ sáwọn ọlọ́run míì?

4 Ó Yàtọ̀ Sáwọn Ọlọ́run Míì. Ọ̀rọ̀ náà “ọ̀kan ṣoṣo” lédè Hébérù àti láwọn èdè míì máa ń nítumọ̀ tó pọ̀. Ó lè túmọ̀ sí ohun tó ṣàrà ọ̀tọ̀ tàbí ohun tí kò lẹ́gbẹ́. Kò jọ pé ẹ̀kọ́ mẹ́talọ́kan tó jẹ́ ẹ̀kọ́ èké ni Mósè ń já nírọ́. Jèhófà ni Olùṣẹ̀dá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé, Ọba Aláṣẹ láyé àti lọ́run. Kò sí Ọlọ́run tòótọ́ mìíràn àfi òun; kò sí ọlọ́run bíi rẹ̀. (2 Sám. 7:22) Torí náà, Mósè ń rán àwọn ọmọ Ísírẹ́lì létí pé wọn ò gbọ́dọ̀ sin Ọlọ́run míì yàtọ̀ sí Jèhófà. Wọn ò gbọ́dọ̀ ṣe bí àwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká tó ń bọ onírúurú òrìṣà. Àwọn orílẹ̀-èdè yẹn gbà pé àwọn òrìṣà yẹn ló ń darí àwọn ohun àdáyébá kan bí omi, afẹ́fẹ́ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Wọ́n sì tún gbà pé àwọn òrìṣà míì jẹ́ amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn òrìṣà kan.

5 Bí àpẹẹrẹ, àwọn ọmọ Íjíbítì máa ń bọ òrìṣà Ra, tí wọ̀n gbà pé ó ń darí oòrùn; Nut ni wọ́n gbà pé ó ń darí òfuurufú, Geb ni wọ́n kà sí òòṣà ilẹ̀ àti Hapi tí wọ́n pè ní òrìṣà Náílì yàtọ̀ sí àwọn ẹranko onírúurú tí wọ́n ń bọ. Àwọn Ìyọnu Mẹ́wàá tí Jèhófà mú wá sórí ilẹ̀ Íjíbítì mú kó ṣe kedere pé òtúbáńtẹ́ lásán làsàn làwọn òrìṣà wọn. Báálì ni òléwájú lára àwọn òòṣà tí àwọn ọmọ Kénáánì ń bọ, wọ́n sì gbà pé òun ni òrìṣà ìbímọlémọ, tó ń darí òfuurufú, òjò àti ìjì. Báálì yìí kan náà ni ọ̀pọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè tó yí Ísírẹ́lì ká ń bọ. (Núm. 25:⁠3) Torí náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbọ́dọ̀ máa rántí pé “Jèhófà kan ṣoṣo” ni Ọlọ́run táwọn ń sìn, òun sì ni “Ọlọ́run tòótọ́.”​—⁠Diu. 4:​35, 39.

6, 7. Kí ló tún lè túmọ̀ sí tá a bá sọ pé Jèhófà jẹ́ “ọ̀kan ṣoṣo”? Báwo ni Jèhófà ṣe fi hàn pé òun jẹ́ “ọ̀kan ṣoṣo”?

6 Ó Jẹ́ Adúróṣinṣin, Kò sì Yí Pa Dà. Tá a bá sọ pé Jèhófà jẹ́ “ọ̀kan ṣoṣo,” ó túmọ̀ sí pé kò yí pa dà, irú ẹni tó jẹ́ lánàá náà ni lónìí. Bọ̀rọ̀ ṣe rí gẹ́lẹ́ nìyẹn, A-wí-bẹ́ẹ̀-ṣe-bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà. Ó jẹ́ olóòótọ́, adúróṣinṣin, kò sì yí pa dà. Ó ṣèlérí fún Ábúráhámù pé àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀ máa jogún Ilẹ̀ Ìlérí, ó sì ṣe àwọn ohun àgbàyanu láti mú ìlérí yẹn ṣẹ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé irinwó ó lé ọgbọ̀n [430] ọdún kọjá lẹ́yìn tí Ọlọ́run ṣe ìlérí yẹn, síbẹ̀ Ọlọ́run mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ.​—⁠Jẹ́n. 12:​1, 2, 7; Ẹ́kís. 12:​40, 41.

7 Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, Jèhófà yan àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìí rẹ̀. Ó wá sọ fún wọn pé: “Ẹnì kan náà ni mí. Ṣáájú mi, kò sí Ọlọ́run kankan tí a ṣẹ̀dá, àti lẹ́yìn mi, kò sí ìkankan tí ó ṣì wà nìṣó.” Kó lè fi dá wọn lójú pé òun kò yí pa dà, Jèhófà fi kún un pé: “Ní gbogbo ìgbà, Ẹnì kan náà ni mí.” (Aísá. 43:​10, 13; 44:6; 48:12) Ẹ ò rí i pé ohun iyì gbáà ló jẹ́ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti fún àwa náà lónìí pé a jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà, Ọlọ́run tí kì í yí pa dà, tó sì ṣeé gbára lé!​—⁠Mál. 3:6; Ják. 1:⁠17.

8, 9. (a) Kí ni Jèhófà ní kí àwọn olùjọsìn rẹ̀ ṣe? (b) Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé ọ̀rọ̀ pàtàkì ni Mósè sọ?

8 Mósè rán àwọn èèyàn náà létí pé ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wọn àti ìtọ́jú tó ń fún wọn kò dín kù bẹ́ẹ̀ sì ni kò yí pa dà. Torí náà, ó bọ́gbọ́n mu pé káwọn náà sin Jèhófà láìlábùlà, kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ tọkàntara kí wọ́n sì fi gbogbo okun wọn sìn ín. Kódà àwọn ọmọ wọn kéékèèké náà gbọ́dọ̀ sin Ọlọ́run tọkàntara torí pé ó yẹ kí àwọn òbí lo gbogbo àǹfààní tí wọ́n ní láti kọ́ wọn.​—⁠Diu. 6:​6-9.

9 Torí pé ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn láti ṣe fún aráyé kò yí pa dà, ó ṣe kedere pé ohun tó ní kí àwọn olùjọsìn rẹ̀ láyé ọjọ́un ṣe náà ló ní káwa tòde òní ṣe. Kí Jèhófà tó lè tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wa, ó gbọ́dọ̀ ṣe kedere pé òun nìkan là ń sìn, ká sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ọkàn wa, èrò-inú wa àti agbára wa. Kódà, ohun kan náà ni Jésù sọ fún ẹnì kan tó béèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ rẹ̀. (Ka Máàkù 12:​28-31.) Báwo ló ṣe lè hàn nínú ìwà wa pé a gbà lóòótọ́ pé “Jèhófà Ọlọ́run wa, Jèhófà kan ṣoṣo ni”?

JÈHÓFÀ NÌKAN NI KÓ O MÁA SÌN

10, 11. (a) Báwo la ṣe lè fi hàn pé Jèhófà nìkan là ń sìn? (b) Báwo làwọn ọ̀dọ́ Hébérù tó wà ní Bábílónì ṣe fi hàn pé Jèhófà nìkan làwọn ń sìn?

10 Ká lè fi hàn pé Jèhófà nìkan ni Ọlọ́run wa, a ò gbọ́dọ̀ ní ohun míì tá à ń júbà, àfi òun nìkan. Ìyẹn túmọ̀ sí pé a ò gbọ́dọ̀ mú nǹkan míì mọ́ ìjọsìn wa, bẹ́ẹ̀ la ò sì gbọ́dọ̀ lọ́wọ́ nínú àwọn àṣà ìbọ̀rìṣà èyíkéyìí. Ó yẹ ká fi sọ́kàn pé Jèhófà kì í ṣe ọ̀kan lára ọ̀pọ̀ ọlọ́run tó wà tàbí pé òun ló lágbára jù láàárín wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, òun nìkan ṣoṣo ló yẹ ká máa jọ́sìn.​—⁠Ka Ìṣípayá 4:⁠11.

11 Ìwé Dáníẹ́lì sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọ̀dọ́ Hébérù mẹ́rin tó ń jẹ́ Dáníẹ́lì, Hananáyà, Míṣáẹ́lì àti Asaráyà. Àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin fi hàn pé Jèhófà nìkan làwọn ń sìn nígbà tí wọ́n kọ̀ láti jẹ oúnjẹ tí Jèhófà kà sí aláìmọ́. Bákan náà, wọ́n kọ̀ láti tẹrí ba fún ère wúrà tí Nebukadinésárì gbé kalẹ̀. Ó hàn gbangba pé wọn kò figbá kan bọ̀kan nínú tó bá kan ọ̀rọ̀ ìjọsìn wọn.​—⁠Dán. 2:1–3:⁠30.

12. Torí pé Jèhófà nìkan là ń sìn, kí la gbọ́dọ̀ ṣọ́ra fún?

12 Kó lè ṣe kedere pé Jèhófà nìkan là ń sìn, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra kí ohunkóhun mìíràn má ṣe gba ipò àkọ́kọ́ láyé wa. Àwọn nǹkan wo la gbọ́dọ̀ ṣọ́ra fún? Nínú Òfin Mẹ́wàá, Jèhófà pàṣẹ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé wọn ò gbọ́dọ̀ ní ọlọ́run mìíràn yàtọ̀ sí òun, wọn ò sì gbọ́dọ̀ lọ́wọ́ nínú ìbọ̀rìṣà èyíkéyìí. (Diu. 5:​6-10) Èèyàn lè bẹ̀rẹ̀ sí í lọ́wọ́ nínú ìbọ̀rìṣà láìfura torí pé onírúurú ọ̀nà ni ìbọ̀rìṣà pín sí lóde òní. Àmọ́, torí pé Ọlọ́run wa jẹ́ “Jèhófà kan ṣoṣo,” ohun tó ní ká ṣe kò tíì yí pa dà. Ẹ jẹ́ ká wo bí ìyẹn ṣe kàn wá.

13. Àwọn nǹkan wo ló lè paná ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run?

13 Nínú ìwé Kólósè 3:5 (kà á), a rí àwọn nǹkan táwa Kristẹni gbọ́dọ̀ yẹra fún torí wọ́n lè mú ká má jọ́sìn Jèhófà tọkàntọkàn mọ́. Kíyè sí i pé ẹsẹ Bíbélì yìí so ojúkòkòrò pọ̀ mọ́ ìbọ̀rìṣà. Ìdí ni pé ohun téèyàn ń fi ojúkòkòrò wá lè gbani lọ́kàn débi pé onítọ̀hún ò ní rójú ráyè fún ìjọsìn Ọlọ́run mọ́, lára àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ ni owó tàbí ọrọ̀. Tá a bá wo gbogbo ìwà búburú tí ẹsẹ Bíbélì yẹn tọ́ka sí, àá rí i pé gbogbo wọn ló tan mọ́ ojúkòkòrò, ojúkòkòrò ẹ̀wẹ̀ sì tan mọ́ ìbọ̀rìṣà. Torí náà, téèyàn bá ń jẹ́ kí ọkàn òun máa fà sí àwọn nǹkan yìí, ó lè paná ìfẹ́ téèyàn ní fún Ọlọ́run. Ǹjẹ́ ó yẹ ká jẹ́ kí àwọn nǹkan yìí nípa lórí wa débi tí Jèhófà kò fi ní jẹ́ “Jèhófà kan ṣoṣo” sí wa mọ́? Rárá o, kò yẹ ká fàyè gbà á.

14. Ìkìlọ̀ wo ni àpọ́sítélì Jòhánù fún wa?

14 Àpọ́sítélì Jòhánù náà fún wa nírú ìkìlọ̀ yìí nígbà tó sọ pé ká má ṣe nífẹ̀ẹ́ àwọn ohun tó wà nínú ayé. Lára wọn ni “ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú àti fífi àlùmọ́ọ́nì ìgbésí ayé ẹni hàn sóde lọ́nà ṣekárími.” Ó sọ pé téèyàn bá nífẹ̀ẹ́ àwọn nǹkan yìí, “ìfẹ́ fún Baba kò sí nínú rẹ̀.” (1 Jòh. 2:​15, 16) Èyí fi hàn pé a gbọ́dọ̀ máa yẹ ara wa wò lóòrèkóòrè ká lè mọ̀ bóyá a ti ń nífẹ̀ẹ́ àwọn eré ìnàjú tí ayé ń gbé lárugẹ, bóyá a ti ń kó ẹgbẹ́kẹ́gbẹ́, títí kan àwọn aṣọkáṣọ àti ìwọ̀kuwọ̀ tó wọ́pọ̀ lóde òní. Ọ̀nà míì téèyàn tún lè gbà nífẹ̀ẹ́ ohun tó wà nínú ayé ni pé kéèyàn máa lépa àtilọ yunifásítì kó bàa lè ní “àwọn ohun ńláńlá.” (Jer. 45:​4, 5) Ní báyìí, a ti wà ní bèbè àtiwọ ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí. Torí náà, ó ṣe pàtàkì ká fi ọ̀rọ̀ tí Mósè sọ sọ́kàn. Tá a bá gbà pé “Jèhófà Ọlọ́run wa, Jèhófà kan ṣoṣo ni,” a máa ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti rí i pé òun nìkan là ń sìn, a sì ń jọ́sìn rẹ̀ lọ́nà tó fẹ́.​—⁠Héb. 12:​28, 29.

WÀ NÍṢỌ̀KAN PẸ̀LÚ ÀWỌN KRISTẸNI BÍI TÌẸ

15. Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi rán àwọn Kristẹni létí pé Jèhófà kan ṣoṣo ni wọ́n ń sìn?

15 Torí pé Jèhófà jẹ́ ọ̀kan ṣoṣo, ó yẹ káwa Kristẹni náà jẹ́ ọ̀kan ṣoṣo ní ti pé ká ṣe ara wa ní òṣùṣù ọwọ̀, ká wà níṣọ̀kan. Bí àpẹẹrẹ, onírúurú ẹ̀yà làwọn tó wà nínú ìjọ Kristẹni ìgbàanì, àwọn kan jẹ́ Júù, àwọn míì jẹ́ ọmọ Róòmù, Gíríìkì àtàwọn ẹ̀yà míì. Ẹ̀sìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni kálukú ń ṣe tẹ́lẹ̀, àṣà wọn àtohun tí wọ́n fẹ́ràn sì yàtọ̀ síra. Torí náà, ó ṣòro fún àwọn kan láti fi àwọn àṣà wọn àtijọ́ sílẹ̀ kí wọ́n sì fara mọ́ ọ̀nà ìjọsìn tuntun. Ìdí nìyẹn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi rán wọn létí pé Ọlọ́run kan ṣoṣo ni àwọn Kristẹni ń sìn, ìyẹn Jèhófà.​—⁠Ka 1 Kọ́ríńtì 8:​5, 6.

16, 17. (a) Àsọtẹ́lẹ̀ wo ló ń nímùúṣẹ lónìí, kí sì ni àbájáde rẹ̀? (b) Kí ló lè ba ìṣọ̀kan tó wà láàárín wa jẹ́?

16 Báwo ni nǹkan ṣe rí nínú ìjọ Kristẹni lónìí? Wòlíì Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé “ní apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́,” àwọn èèyàn láti ibi gbogbo máa rọ́ wá sínú ètò rẹ̀, tá a fi wé ibi ìjọsìn mímọ́ tó ga fíofío. Wọ́n á sọ pé: ‘[Jèhófà] yóò fún wa ní ìtọ́ni nípa àwọn ọ̀nà rẹ̀, àwa yóò sì máa rìn ní àwọn ipa ọ̀nà rẹ̀.’ (Aísá. 2:​2, 3) Inú wa mà dùn o pé à ń fojú ara wa rí bí àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣe ń nímùúṣẹ! Àbájáde rẹ̀ ni pé àwọn èèyàn láti onírúurú ẹ̀yà, èdè àti àṣà ló wà nínú ìjọ, síbẹ̀ wọ́n jùmọ̀ ń fìyìn fún Jèhófà. Bó ti wù kó rí, ìyàtọ̀ yìí lè fa àwọn ìṣòro kan, ó sì yẹ ká fún wọn láfiyèsí.

Ǹjẹ́ ò ń pa kún ìṣọ̀kan tó wà nínú ìjọ Kristẹni? (Wo ìpínrọ̀ 16 sí 19)

17 Bí àpẹẹrẹ, ojú wo lo fi máa ń wo àwọn Kristẹni tó wá láti ẹ̀yà míì? Bí wọ́n ṣe ń sọ̀rọ̀, ìmúra wọn, ìwà wọn àti oúnjẹ wọn lè yàtọ̀ sí tìẹ. Ṣé o máa ń fọgbọ́n yẹ̀ wọ́n sílẹ̀, tó fi jẹ́ pé àwọn tí ẹ jọ mọwọ́ ara yín nìkan lo máa ń bá ṣe? Kí lo máa ṣe tó bá jẹ́ pé àwọn alábòójútó tí ètò Ọlọ́run yàn sípò kéré sí ẹ lọ́jọ́ orí tàbí tí wọ́n bá wá láti ẹ̀yà míì tàbí tí àwọ̀ wọn bá yàtọ̀ sí tìẹ? Kí ni wàá ṣe tí wọ́n bá jẹ́ alábòójútó nínú ìjọ rẹ tàbí ní àyíká yín tàbí tí wọn bá wà nínú ìgbìmọ̀ ẹ̀ka? Ṣé wàá jẹ́ kí irú àwọn ìyàtọ̀ bẹ́ẹ̀ ba ìṣọ̀kan tó wà láàárín àwa èèyàn Jèhófà jẹ́?

18, 19. (a) Ìmọ̀ràn wo ló wà nínú Éfésù 4:​1-3? (b) Kí la lè ṣe láti mú kí ìjọ wà ní ìṣọ̀kan?

18 Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ tá ò fi ní fàyè gba èrò tí kò tọ́ yìí? Ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù fún àwọn Kristẹni tó wà ní Éfésù tó jẹ́ ìlú tí onírúurú ẹ̀yà ń gbé lè ràn wá lọ́wọ́. (Ka Éfésù 4:​1-3.) Wàá kíyè sí i pé Pọ́ọ̀lù kọ́kọ́ mẹ́nu kan àwọn ànímọ́ bí ìrẹ̀lẹ̀, ìwà tútù, ìpamọ́ra àti ìfẹ́. A lè fi àwọn ànímọ́ yìí wé àwọn òpó tó mú ilé ró. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ilé kan lè ní àwọn òpó tó lágbára, síbẹ̀ wọ́n gbọ́dọ̀ máa tún ilé náà ṣe déédéé, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, kò ní ṣeé rí. Torí náà, Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni tó wà ní Éfésù níyànjú pé kí wọ́n sapá láti “pa ìṣọ̀kanṣoṣo ẹ̀mí mọ́.”

19 Ó yẹ kí kálukú wa mọ̀ pé ojúṣe wa ni láti pa ìṣọ̀kan tó wà nínú ìjọ mọ́. Kí ló yẹ ká ṣe? Lákọ̀ọ́kọ́, ó yẹ ká sapá láti ní àwọn ànímọ́ tí Pọ́ọ̀lù mẹ́nu kàn, ìyẹn ìrẹ̀lẹ̀, ìwà tútù, ìpamọ́ra àti ìfẹ́. Lẹ́yìn náà, ká sapá láti pa kún ‘àlàáfíà tó jẹ́ ìdè tó so wá pọ̀ ṣọ̀kan.’ Bákan náà, a ò gbọ́dọ̀ fàyè gba ohunkóhun tó lè dá ìyapa sílẹ̀ nínú ìjọ. Tá a bá ń fi àwọn ìmọ̀ràn yìí sílò, àá máa pa kún àlàáfíà àti ìṣọ̀kan tó wà láàárín wa.

20. Kí la gbọ́dọ̀ máa ṣe ká lè fi hàn pé “Jèhófà Ọlọ́run wa, Jèhófà kan ṣoṣo ni”?

20 “Jèhófà Ọlọ́run wa, Jèhófà kan ṣoṣo ni.” Ọ̀rọ̀ yìí fakíki lóòótọ́! Ìránnilétí yìí mú káwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbára dì láti kojú àwọn ìṣòro tí wọ́n bá pà dé bí wọ́n ṣe ń múra láti wọ Ilẹ̀ Ìlérí. Táwa náà bá fi ọ̀rọ̀ yìí sọ́kàn, àá lè kojú ìpọ́njú ńlá tó ń bọ̀, àá sì gbádùn Párádísè lẹ́yìn náà. Torí náà, ẹ jẹ́ ká rí i dájú pé Jèhófà nìkan là ń jọ́sìn. A sì lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, tá à ń sìn ín tọkàntọkàn, tá a sì ń sapá láti pa ìṣọ̀kan tó wà nínú ìjọ Kristẹni mọ́. Tá a bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí, ó dájú pé a máa rí ìmúṣẹ ìlérí tí Jésù ṣe fún àwọn ẹni bí àgùntàn pé: “Ẹ wá, ẹ̀yin tí Baba mi ti bù kún, ẹ jogún ìjọba tí a ti pèsè sílẹ̀ fún yín láti ìgbà pípilẹ̀ ayé.”​—⁠Mát. 25:⁠34.