Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìwà Rere Tó Ṣeyebíye Ju Dáyámọ́ǹdì Lọ

Ìwà Rere Tó Ṣeyebíye Ju Dáyámọ́ǹdì Lọ

Ọjọ́ pẹ́ táwọn èèyàn ti ka dáyámọ́ǹdì sí ìṣúra tó ṣeyebíye. Owó gọbọi làwọn èèyàn sì máa ń dá lé e. Àmọ́, ṣé àwọn nǹkan míì wà tó ṣeyebíye lójú Ọlọ́run ju dáyámọ́ǹdì àtàwọn òkúta iyebíye míì lọ?

Akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi ni Haykanush tó ń gbé ní orílẹ̀-èdè Armenia. Lọ́jọ́ kan ó rí ìwé àṣẹ ìrìnnà kan nítòsí ilé rẹ̀. Wọ́n kó owó rẹpẹtẹ àti káàdì téèyàn fi ń gba owó ní báńkì sínú ìwé ìrìnnà náà. Ó sọ ohun tó rí fún ọkọ rẹ̀ tí òun náà jẹ́ akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi.

Kẹ́ ẹ sì máa wò ó, nǹkan ò fi bẹ́ẹ̀ lọ dáadáa fún tọkọtaya yìí, wọ́n sì láwọn gbèsè tó yẹ kí wọ́n san. Síbẹ̀, wọ́n pinnu pé àwọn á wá ẹni náà lọ sí àdírẹ́sì tó wà lórí ìwé ìrìnnà náà, wọ́n á sì kó gbogbo ohun tí wọ́n rí fún un. Ohun tí wọ́n ṣe yìí ya ọkùnrin tó ni ìwé ìrìnnà náà lẹ́nu àtàwọn ìdílé rẹ̀. Haykanush àti ọkọ rẹ̀ ṣàlàyé fún wọn pé ohun táwọn ń kọ́ nínú Bíbélì ló mú káwọn jẹ́ olóòótọ́. Wọ́n jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ohun tó yẹ káwọn ṣe nìyẹn, wọ́n lo àǹfààní yẹn láti ṣàlàyé fún ìdílé náà nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n sì fún wọn láwọn ìwé wa.

Ohun tí Haykanush ṣe yìí wú ìdílé náà lórí débi pé wọ́n fẹ́ fún un lówó, àmọ́ kò gbà á. Nígbà tó dọjọ́ kejì, ìyàwó ọkùnrin yẹn lọ sílé Haykanush àti ọkọ rẹ̀, ó sì rọ Haykanush títí tó fi gba òrùka dáyámọ́ǹdì kan láti jẹ́ kó mọ̀ pé àwọn mọrírì ohun tó ṣe fún wọn.

Ohun tí Haykanush àti ọkọ rẹ̀ ṣe yẹn máa ya ọ̀pọ̀ èèyàn lẹ́nu bó ṣe ya ìdílé yẹn lẹ́nu. Àmọ́ ṣó máa ya Jèhófà lẹ́nu? Ojú wo ni Jèhófà fi wo bí wọ́n ṣe jẹ́ olóòótọ́? Ṣé ohun tí wọ́n ṣe yẹn tiẹ̀ bọ́gbọ́n mu?

ÀWỌN ÌWÀ TÓ ṢEYEBÍYE JU ÀWỌN NǸKAN TARA LỌ

Kò ṣòro rárá láti dáhùn àwọn ìbéèrè yẹn. Ìdí ni pé àwa èèyàn Jèhófà gbà pé kéèyàn ní àwọn ànímọ́ tó ń múnú Jèhófà dùn ṣeyebíye ju dáyámọ́ǹdì, góòlù tàbí wúrà àtàwọn nǹkan míì lọ. Ó ṣe kedere pé ohun tí Jèhófà kà sí iyebíye yàtọ̀ sóhun tí ọ̀pọ̀ èèyàn kà sí iyebíye. (Aísá. 55:​8, 9) Ní tàwa ìránṣẹ́ Jèhófà, a gbà pé téèyàn bá lè fìwà jọ Jèhófà ní gbogbo ọ̀nà, àṣeyọrí ńlá lèèyàn ṣe yẹn.

Ẹ̀yin náà ẹ wo ohun tí Bíbélì sọ nípa ọgbọ́n àti ìfòyemọ̀. Ìwé Òwe 3:​13-15 sọ pé: “Aláyọ̀ ni ènìyàn tí ó ti wá ọgbọ́n rí, àti ènìyàn tí ó ní ìfòyemọ̀, nítorí níní in gẹ́gẹ́ bí èrè sàn ju níní fàdákà gẹ́gẹ́ bí èrè, níní in gẹ́gẹ́ bí èso sì sàn ju níní wúrà pàápàá. Ó ṣe iyebíye ju iyùn, a kò sì lè mú gbogbo àwọn nǹkan mìíràn tí í ṣe inú dídùn rẹ bá a dọ́gba.” Kò sí àní-àní pé Jèhófà mọyì kéèyàn ní ọgbọ́n àti ìfòyemọ̀ ju kéèyàn ní àwọn nǹkan tara.

Àmọ́ ojú wo ni Jèhófà fi ń wo kéèyàn jẹ́ olóòótọ́?

Ó dájú pé olóòótọ́ ni Jèhófà, kò sì “lè purọ́.” (Títù 1:⁠2) Ó mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti kọ̀wé sáwọn Kristẹni tó jẹ́ Hébérù ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní pé: “Ẹ máa bá a lọ ní gbígbàdúrà fún wa, nítorí àwa ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé a ní ẹ̀rí-ọkàn aláìlábòsí, gẹ́gẹ́ bí a ti dàníyàn láti máa hùwà láìṣàbòsí nínú ohun gbogbo.”​—⁠Héb. 13:⁠18.

Àpẹẹrẹ rere ni Jésù Kristi jẹ́ tó bá di pé ká jẹ́ olóòótọ́. Ẹ rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Káyáfà Àlùfáà Àgbà sọ fún Jésù pé: “Mo fi Ọlọ́run alààyè mú kí o wá sábẹ́ ìbúra láti sọ fún wa yálà ìwọ ni Kristi Ọmọ Ọlọ́run!” Jésù ò parọ́, ó sọ fún wọn pé òun ni Mèsáyà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Sànhẹ́dírìn lè di ohun tó sọ yẹn mú, kí wọ́n sì dájọ́ ikú fún un torí wọ́n gbà pé ó ti sọ̀rọ̀ òdì.​—⁠Mát. 26:​63-67.

Àwa ńkọ́? Kí la máa ṣe ká sọ pé a bára wa nípò tó jẹ́ pé nǹkan á ṣẹnuure fún wa tá a bá parọ́ díẹ̀ tàbí ká yí ọ̀rọ̀ po? Ṣé àá lè sọ òótọ́?

KÍ LÓ MÁA Ń JẸ́ KÓ NIRA LÁTI JẸ́ OLÓÒÓTỌ́?

Ká sòótọ́, kò rọrùn láti jẹ́ olóòótọ́ láwọn ọjọ́ ìkẹyìn tí ọ̀pọ̀ èèyàn ti jẹ́ ‘olùfẹ́ ara wọn àti olùfẹ́ owó.’ (2 Tím. 3:⁠2) Àìríná àti àìrílò tàbí ìbẹ̀rù pé iṣẹ́ lè bọ́ mọ́ni lọ́wọ́ máa ń mú káwọn èèyàn ṣe ohun tí kò tọ́. Ọ̀pọ̀ gbà pé kò sóhun tó burú táwọn bá jalè, táwọn bá yí ìwé tàbí hu àwọn ìwà àìṣòótọ́ míì. Èrò tó gbayé kan nìyẹn, pàápàá tọ́rọ̀ bá dọ̀rọ̀ owó, wọ́n á ní òótọ́ dọ́jà ó kùtà, owó lọ́wọ́ là ń ra èké. Ó bani nínú jẹ́ pé àwọn Kristẹni kan ti jìn sínú ọ̀fìn yìí torí pé wọ́n ń lé “èrè àbòsí,” wọn ò sì ní orúkọ rere mọ́ nínú ìjọ.​—⁠1 Tím. 3:8; Títù 1:⁠7.

Àmọ́ inú wa dùn pé èyí tó pọ̀ jù lára àwa Kristẹni ló ń fara wé Jésù. A mọ̀ pé ìwà rere lẹ̀ṣọ́ èèyàn, ó ṣe pàtàkì ju ọrọ̀ tàbí àǹfààní tara èyíkéyìí. Torí náà, àwọn ọmọ wa kì í jí ìwé wò níléèwé kí wọ́n lè mókè láàárín àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn. (Òwe 20:23) Ní ti gidi, tá a bá jẹ́ olóòótọ́, wọ́n lè má fún wa lẹ́bùn bíi ti Haykanush. Síbẹ̀, a mọ̀ pé bá a ṣe jẹ́ olóòótọ́ ń múnú Ọlọ́rùn dùn, ó ń jẹ́ ká ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́, ìyẹn sì ju owó tàbí ẹ̀bùn èyíkéyìí lọ.

Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Gagik gan-an nìyẹn. Ó sọ pé: “Kí n tó di Kristẹni, iléeṣẹ́ ńlá kan ni mò ń bá ṣiṣẹ́, ẹni tó ni ilé iṣẹ́ náà kì í nà tán fún ìjọba nípa iye èrè tó ń wọlé, torí náà ìwọ̀nba lowó orí tó máa ń san. Torí pé èmi ni máníjà iléeṣẹ́ náà, ọ̀gá mi retí pé kí n máa fáwọn aṣojú ìjọba ní ẹ̀gúnjẹ kí wọ́n lè gbójú fo èrú tá à ń ṣe nílé iṣẹ́ náà. Torí náà, ojú oníjìbìtì làwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ àtàwọn aṣojú ìjọba fi ń wò mí. Nígbà tí mo kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, mo jẹ́ kí ọ̀gá mi mọ̀ pé mi ò ní lè máa ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ mọ́, bí mo ṣe fiṣẹ́ náà sílẹ̀ nìyẹn bó tilẹ̀ jẹ́ pé owó gidi ni wọ́n ń san fún mi. Mo dá iṣẹ́ ara mi sílẹ̀. Látọjọ́ àkọ́kọ́ pàá, mo fi orúkọ ilé iṣẹ́ mi sílẹ̀ lọ́dọ̀ ìjọba, mo sì ń san gbogbo owó tó yẹ kí n san.”​—⁠2 Kọ́r. 8:⁠21.

Gagik sọ pé: “Owó tó ń wọlé fún mi kò tó nǹkan, torí náà àtijẹ àtimu nira díẹ̀ nínu ìdílé mi. Àmọ́, mò ń láyọ̀ gan-an báyìí. Ìdí sì ni pé mo lẹ́rìí ọkàn rere lọ́dọ̀ Jèhófà. Àwọn ọmọkùnrin mi méjèèjì rí ẹ̀kọ́ rere kọ́ lára mi, mo sì ti láǹfààní láti máa bójú tó àwọn iṣẹ́ kan nínú ìjọ. Àwọn aṣojú ìjọba tó máa ń ṣàyẹ̀wò àkọsílẹ̀ owó orí àtàwọn tá a jọ ń ṣòwò sì ti wá mọyì mi torí wọ́n mọ̀ pé mo ti di olóòótọ́ èèyàn báyìí.”

JÈHÓFÀ Ń RAN ÀWỌN OLÓÒÓTỌ́ LỌ́WỌ́

Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn tó ń fi ẹ̀kọ́ Bíbélì ṣèwàhù, tí wọ́n sì ń hùwà rere bíi jíjẹ́ olóòótọ́. (Títù 2:10) Ó mí sí Dáfídì Ọba láti fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé: “Èmi ti jẹ́ ọ̀dọ́ rí, mo sì ti darúgbó, síbẹ̀síbẹ̀, èmi kò tíì rí i kí a fi olódodo sílẹ̀ pátápátá, tàbí kí ọmọ rẹ̀ máa wá oúnjẹ kiri.”​—⁠Sm. 37:⁠25.

Ìrírí Rúùtù jẹ́ ká rí i pé òótọ́ ni Dáfídì sọ. Kò fi Náómì ìyá ọkọ rẹ̀ sílẹ̀, ó dúró tì í kódà nígbà tí Náómì darúgbó. Rúùtù tẹ̀ lé ìyá ọkọ rẹ̀ lọ sí Ísírẹ́lì, níbi táá ti lè máa jọ́sìn Ọlọ́run tòótọ́. (Rúùtù 1:​16, 17) Nígbà tí wọ́n dé ọ̀hún, Rúùtù ò ṣọ̀lẹ, ó fòótọ́ inú ṣiṣẹ́ bó ṣe ń pèéṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí Òfin Ọlọ́run ti sọ. Ó ṣe kedere pé Jèhófà kò fi Rúùtù àti Náómì sílẹ̀ bó ṣe wá rí nínú ọ̀rọ̀ Dáfídì náà nígbà tó yá. (Rúùtù 2:​2-18) Kì í ṣe ọ̀rọ̀ ohun tí Rúùtù máa jẹ nìkan ni Jèhófà ṣe fún un. Pabanbarì rẹ̀ ni pé, Jèhófà yàn án láti jẹ́ ìyá ńlá Dáfídì Ọba, kódà ó tún di ìyá ńlá Mèsáyà tá a ṣèlérí!​—⁠Rúùtù 4:​13-17; Mát. 1:​5, 16.

Nǹkan lè má fi bẹ́ẹ̀ ṣẹnuure fáwọn kan lára àwa ìránṣẹ́ Jèhófà, kí awọ má sì kájú ìlù. Dípò tí wọ́n á fi dọ́gbọ́n sọ́rọ̀ ara wọn, ṣe ni wọ́n máa ń ṣiṣẹ́ kára. Wọ́n gbà pé ó yẹ káwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run máa hùwà rere ká sì jẹ́ olóòótọ́, dípò ká máa wá àǹfààní táwọn nǹkan tara lè fúnni.​—⁠Òwe 12:24; Éfé. 4:⁠28.

Bíi ti Rúùtù, àwa Kristẹni kárí ayé gbà pé Jèhófà ń ràn wá lọ́wọ́. A gbà pé Ọlọ́run máa mú ìlérí tó ṣe nínú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ pé: “Dájúdájú, èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà tàbí kọ̀ ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà.” (Héb. 13:⁠5) Léraléra ni Jèhófà jẹ́ ká mọ̀ pé òun máa ṣèrànwọ́ fún àwọn tí nǹkan ò fi bẹ́ẹ̀ ṣẹnuure fún tí wọ́n sì jẹ́ olóòótọ́ nígbà gbogbo. A sì ń rí i pé ó ń mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ pé òun á máa pèsè ohun tá a nílò nípa tara fún wa.​—⁠Mát. 6:⁠33.

Lóòótọ́, àwọn èèyàn ka dáyámọ́ǹdì àtàwọn ohun ìṣúra míì sí ohun tó ṣeyebíye gan-an. Àmọ́, ká jẹ́ kó dá wa lójú pé Baba wa ọ̀run mọyì bá a ṣe jẹ́ olóòótọ́ tá a sì ń hùwà rere. Èyí ṣeyebíye lójú rẹ̀ ju ohunkóhun téèyàn lè kà sí iyebíye lọ!

Torí pé a jẹ́ olóòótọ́, a ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́, a sì lẹ́nu ọ̀rọ̀ nígbà tá a bá ń wàásù fáwọn èèyàn