Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Má Ṣe Jẹ́ Kí Àṣìṣe Àwọn Míì Mú Ẹ Kọsẹ̀

Má Ṣe Jẹ́ Kí Àṣìṣe Àwọn Míì Mú Ẹ Kọsẹ̀

‘Ẹ máa bá a lọ ní dídárí ji ara yín fàlàlà lẹ́nì kìíní-kejì.’​—KÓL. 3:13.

ORIN: 121, 75

1, 2. Kí ni Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ nípa bí àwa èèyàn Jèhófà ṣe máa pọ̀ tó?

INÚ ètò kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tá a jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé wà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé aláìpé ni wá, a sì máa ń ṣàṣìṣe, síbẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ń ràn wá lọ́wọ́ níbi gbogbo láyé láti máa gbèrú sí i. Ẹ jẹ́ ká wo díẹ̀ lára àwọn nǹkan àgbàyanu tí Jèhófà ti lo àwa èèyàn rẹ̀ láti ṣe, bó tilẹ̀ jẹ́ pé aláìpé ni wá.

2 Nígbà tí òpin ètò nǹkan yìí bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1914, ìwọ̀nba díẹ̀ làwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó wà nígbà yẹn. Àmọ́ Jèhófà bù kún iṣẹ́ ìwàásù wọn. Bọ́dún ti ń gorí ọdún, ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn ló kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tí wọ́n sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Jèhófà ti sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn èèyàn òun máa pọ̀ gan-an, ó ní: “Ẹni tí ó kéré yóò di ẹgbẹ̀rún, ẹni kékeré yóò sì di alágbára ńlá orílẹ̀-èdè. Èmi tìkára mi, Jèhófà, yóò mú un yára kánkán ní àkókò rẹ̀.” (Aísá. 60:22) Ó hàn gbangba pé àsọtẹ́lẹ̀ yìí ti nímùúṣẹ láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí. Ìdí ni pé tá a bá fi iye àwa èèyàn Jèhófà kárí ayé báyìí wé àwọn orílẹ̀-èdè tó ń bẹ láyé, ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ló jẹ́ pé àwọn èèyàn inú wọn kò tó iye wa.

3. Ọ̀nà wo làwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run gbà fi hàn pé àwọn ní ìfẹ́?

3 Ní gbogbo àsìkò yìí, Jèhófà tún ran àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́wọ́ láti máa fi ìfẹ́ tó jẹ́ ànímọ́ rẹ̀ tó ta yọ jù lọ hàn lọ́nà tó ga. (1 Jòh. 4:⁠8) Jésù tóun náà tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìfẹ́ Bàbá rẹ̀ sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Èmi ń fún yín ní àṣẹ tuntun kan, pé kí ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì . . . Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.” (Jòh. 13:​34, 35) Ó túbọ̀ ṣe pàtàkì pé ká pa àṣẹ yìí mọ́, pàápàá jù lọ torí bí àwọn orílẹ̀-èdè ṣe ń bára wọn jagun tó ń bani lẹ́rù láwọn ọdún mélòó kan sẹ́yìn. Bí àpẹẹrẹ, nǹkan bíi mílíọ̀nù márùndínlọ́gọ́ta [55] èèyàn ni wọ́n pa nígbà Ogun Àgbáyé Kejì nìkan. Àmọ́, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò lọ́wọ́ sí bí wọ́n ṣe pààyàn ní ìpakúpa yẹn. (Ka Míkà 4:​1, 3.) Èyí mú kí “ọrùn [wa] mọ́ kúrò nínú ẹ̀jẹ̀ ènìyàn gbogbo.”​—⁠Ìṣe 20:⁠26.

4. Kí nìdí tí ìtẹ̀síwájú tó ń bá àwọn èèyàn Jèhófà fi jọni lójú?

4 Àwa èèyàn Ọlọ́run ń gbèrú sí i bó tilẹ̀ jẹ́ pé inú ayé burúkú tí Sátánì ń darí là ń gbé. Bíbélì pe Sátánì ní “ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí.” (2 Kọ́r. 4:⁠4) Òun ló ń darí ètò ìṣèlú ayé bó ṣe ń darí àwọn ètò orí tẹlifíṣọ̀n àti rédíò. Àmọ́ kò lè dá iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe dúró. Sátánì mọ̀ pé àkókò kúkúrú ló kù fún òun, torí náà ó ń sa gbogbo ipá rẹ̀ láti mú káwọn èèyàn pa ìjọsìn tòótọ́ tì. Onírúurú ọ̀nà ló sì ń gbà ṣe bẹ́ẹ̀.​—⁠Ìṣí. 12:⁠12.

OHUN TÓ LÈ DÁN ÌDÚRÓṢINṢIN WA WÒ

5. Kí ló lè mú káwọn kan ṣe ohun tó dùn wá? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

5 Nínú ìjọ Kristẹni, a mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àtàwọn èèyàn. Jésù ti sọ tẹ́lẹ̀ pé bó ṣe máa rí nìyẹn. Nígbà tó ń dáhùn ìbéèrè kan nípa àṣẹ tó tóbi jù lọ, ó ní: “ ‘Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò inú rẹ.’ Èyí ni àṣẹ títóbi jù lọ àti èkíní. Èkejì, tí ó dà bí rẹ̀, nìyí, ‘Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.’ ” (Mát. 22:​35-39) Síbẹ̀, Bíbélì mú kó ṣe kedere pé gbogbo wa la jẹ́ aláìpé nítorí ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù. (Ka Róòmù 5:​12, 19.) Torí náà, àwọn kan nínú ìjọ lè sọ ohun kan tàbí ṣe ohun tó máa dùn wá nígbà míì. Irú àwọn àkókò yìí la máa ń mọ̀ bóyá lóòótọ́ la nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àtàwọn èèyàn rẹ̀. Kí la máa ṣe tírú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀? Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run láyé àtijọ́ náà ṣe ohun tó dun àwọn míì, kí la lè kọ́ látinú àwọn ìtàn tí Bíbélì mẹ́nu kàn yìí?

Ká sọ pé ìgbà ayé Élì àtàwọn ọmọ rẹ̀ lo gbáyé, kí lo ò bá ṣe? (Wo ìpínrọ̀ 6)

6. Báwo ni Élì ṣe gbọ̀jẹ̀gẹ́ fáwọn ọmọkùnrin rẹ̀?

6 Bí àpẹẹrẹ, Élì tó jẹ́ Àlùfáà Àgbà ní àwọn ọmọkùnrin méjì tí kò ka òfin Jèhófà sí. Bíbélì sọ pé: “Àwọn ọmọkùnrin Élì jẹ́ aláìdára fún ohunkóhun; wọn kò ka Jèhófà sí.” (1 Sám. 2:12) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ pàtàkì ni Élì ń ṣe láti gbé ìjọsìn mímọ́ lárugẹ, síbẹ̀ ìwà burúkú làwọn ọmọ rẹ̀ ń hù. Kàkà kí Élì bá wọn wí, ńṣe ló gbọ̀jẹ̀gẹ́ fún wọn. Torí náà, Ọlọ́run dá gbogbo ilé Élì lẹ́jọ́. (1 Sám. 3:​10-14) Nígbà tó yá, àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀ ò láǹfààní láti sìn gẹ́gẹ́ bí àlùfáà àgbà mọ́. Ká sọ pé ìgbà ayé Élì ni ìwọ náà gbáyé, kí lo máa ṣe bó o ṣe rí i tí Élì ń gbójú fo ìwà burúkú táwọn ọmọkùnrin rẹ̀ ń hù? Ṣé wàá jẹ́ kíyẹn bí ẹ nínú débi tí wàá fi fi ètò Ọlọ́run sílẹ̀?

7. Ẹ̀ṣẹ̀ burúkú wo ni Dáfídì dá, kí sì ni Ọlọ́run ṣe nípa rẹ̀?

7 Jèhófà nífẹ̀ẹ́ Dáfídì gan-an, kódà ó sọ pé ó jẹ́ ọkùnrin “tí ó tẹ́ ọkàn-àyà [òun] lọ́rùn.” (1 Sám. 13:​13, 14; Ìṣe 13:22) Àmọ́, Dáfídì ṣe panṣágà pẹ̀lú Bátí-ṣébà, obìnrin náà sì lóyún. Ojú ogun ni Ùráyà ọkọ obìnrin náà wà nígbà tí ọ̀rọ̀ yìí ṣẹlẹ̀. Nígbà tí Ùráyà wálé fírí, Dáfídì gbìyànjú láti mú kó ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú Bátí-ṣébà kó lè dà bíi pé Ùráyà ló fún un lóyún. Àmọ́ Ùráyà kọ̀ láti ṣe ohun tí Dáfídì fẹ́, ni Dáfídì bá ṣètò bó ṣe máa kú sójú ogun. Dáfídì jìyà ohun tó ṣe torí pé àjálù dé bá òun àti gbogbo ìdílé rẹ̀. (2 Sám. 12:​9-12) Síbẹ̀, Ọlọ́run fi àánú hàn sí i torí pé Dáfídì bá Jèhófà rìn “pẹ̀lú ìwà títọ́ ọkàn-àyà.” (1 Ọba 9:⁠4) Ká sọ pé ìwọ náà gbáyé nígbà yẹn, kí lo ò bá ṣe? Ṣé ìwà burúkú tí Dáfídì hù máa mú ẹ kọsẹ̀?

8. (a) Báwo ni àpọ́sítélì Pétérù ṣe yẹhùn lórí ohun tó sọ? (b) Kí nìdí tí Jèhófà fi ń bá a lọ láti lo Pétérù fún ọ̀pọ̀ iṣẹ́ kódà lẹ́yìn tó ṣàṣìṣe?

8 Àpẹẹrẹ míì tí Bíbélì mẹ́nu kàn ni ti àpọ́sítélì Pétérù. Jésù yàn án gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn àpọ́sítélì rẹ̀, síbẹ̀ àwọn ìgbà kan wà tí Pétérù sọ ohun kan tàbí ṣe ohun tóun fúnra rẹ̀ pa dà kábàámọ̀. Bí àpẹẹrẹ, gbogbo àwọn àpọ́sítélì ló pa Jésù tì nígbà tó nílò wọn jù. Pétérù ti fọ́nnu tẹ́lẹ̀ pé tí gbogbo àwọn yòókù bá tiẹ̀ fi Jésù sílẹ̀, òun ò ní ṣe bẹ́ẹ̀. (Máàkù 14:​27-31, 50) Àmọ́, nígbà tí wọ́n mú Jésù, gbogbo àwọn àpọ́sítélì títí kan Pétérù ló pa Jésù tì. Ẹ̀ẹ̀mẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Pétérù tún sọ pé òun ò mọ Jésù rí. (Máàkù 14:​53, 54, 66-72) Síbẹ̀, Pétérù kábàámọ̀ ohun tó ṣe, Jèhófà sì lò ó fún ọ̀pọ̀ iṣẹ́. Ká sọ pé ìwọ náà wà lára àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù nígbà yẹn, ṣé wàá jẹ́ kí ohun tí Pétérù ṣe ba àjọṣe rẹ pẹ̀lú Jèhófà jẹ́?

9. Kí ló mú kó dá ẹ lójú pé onídàájọ́ òdodo ni Ọlọ́run?

9 Ìwọ̀nyí jẹ́ àpẹẹrẹ díẹ̀ lára àwọn tó ṣe ohun tó dun àwọn míì. Ọ̀pọ̀ ìgbà nirú nǹkan báyìí ti ṣẹlẹ̀ láyé àtijọ́ àti lóde òní pàápàá. Lọ́nà wo? Àwọn kan lára wa ti hùwà àìdáa tí wọ́n sì kó ẹ̀dùn ọkàn bá àwọn míì. Kókó ibẹ̀ ni pé, kí lo máa ṣe tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀? Ṣé wàá jẹ́ kí àṣìṣe àwọn míì mú ẹ kọsẹ̀ débi tí wàá fi fi Jèhófà àtàwọn èèyàn rẹ̀ sílẹ̀? Àbí wàá gbà pé Jèhófà lè fẹ́ fàyè sílẹ̀ fún ẹlẹ́ṣẹ̀ náà láti ronú pìwà dà, àti pé á mú àwọn nǹkan tọ́ lásìkò tó tọ́, á sì ṣe ìdájọ́ òdodo? Nígbà míì sì rèé, àwọn tó hùwà burúkú náà lè kọ ìbáwí Jèhófà, kí wọ́n má sì ronú pìwà dà. Tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, ṣé wàá gbà pé Jèhófà máa dá àwọn oníwà burúkú náà lẹ́jọ́ lákòókò tó yẹ, àti pé ó lè yọ wọ́n kúrò nínú ìjọ?

JẸ́ ADÚRÓṢINṢIN SÍ JÈHÓFÀ

10. Kí ni Jésù mọ̀ nípa àṣìṣe tí Júdásì Ísíkáríótù àti Pétérù ṣe?

10 Bíbélì sọ nípa àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà àtàwọn èèyàn rẹ̀ láìka àìdáa táwọn míì ṣe. Bí àpẹẹrẹ, lẹ́yìn tí Jésù gbàdúrà sí Bàbá rẹ̀ lóru mọ́jú, ó yan àwọn àpọ́sítélì méjìlá. Júdásì Ísíkáríótù wà lára àwọn tó yàn. Àmọ́ Júdásì dalẹ̀ Jésù, síbẹ̀ Jésù ò jẹ́ kí ìyẹn ba àjọṣe tó wà láàárín òun àti Jèhófà Bàbá rẹ̀ jẹ́. Bákan náà, kò jẹ́ kí àṣìṣe Pétérù ba àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà jẹ́. (Lúùkù 6:​12-16; 22:​2-6, 31, 32) Jésù mọ̀ pé kì í ṣe Jèhófà tàbí àwọn èèyàn rẹ̀ ló lẹ̀bi ohun táwọn ẹni yẹn ṣe. Torí náà, Jésù ń bá iṣẹ́ pàtàkì tó ń ṣe lọ láìka ohun táwọn kan lára àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ṣe sí. Jèhófà san Jésù lẹ́san nígbà tó jí i kúrò nínú òkú, èyí sì ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún Jésù láti di Ọba Ìjọba Ọlọ́run.​—⁠Mát. 28:​7, 18-20.

11. Àsọtẹ́lẹ̀ wo ni Bíbélì sọ nípa àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lákòókò yìí?

11 Títí dòní, Jésù ṣì fọkàn tán Jèhófà àtàwọn èèyàn rẹ̀. Tá a bá ronú lórí ohun tí Jèhófà ń tipasẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ gbé ṣe láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, a máa rí i pé ó kàmàmà. Kò sí àwùjọ míì tó ń wàásù òtítọ́ kárí ayé, torí pé Jèhófà ò darí wọn bó ṣe ń darí ìjọ rẹ̀ tó wà níṣọ̀kan lónìí. Ìwé Aísáyà 65:14 sọ nípa bí ipò tẹ̀mí àwọn èèyàn Ọlọ́run ṣe máa rí, ó ní: “Wò ó! Àwọn ìránṣẹ́ tèmi yóò fi ìdùnnú ké jáde nítorí ipò rere ọkàn-àyà.”

12. Ọwọ́ wo ló yẹ ká fi mú àṣìṣe àwọn míì?

12 Àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ń yọ̀ nítorí àwọn nǹkan rere tí wọ́n ń gbé ṣe bí Jèhófà ṣe ń darí wọn. Àmọ́, àwọn tó wà lábẹ́ ìdarí Sátánì ń kérora bí nǹkan ṣe túbọ̀ ń burú sí i nínú ayé. Torí náà, kò ní bọ́gbọ́n mu pé ká máa dá Jèhófà tàbí ìjọ rẹ̀ lẹ́bi nítorí àṣìṣe tí ìwọ̀nba kéréje àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run bá ṣe. A gbọ́dọ̀ jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà àti ètò rẹ̀, ká sì kọ́ ara wa ká lè mọ ohun tó yẹ ká ṣe táwọn míì bá ṣàṣìṣe.

ỌWỌ́ TÓ YẸ KÁ FI MÚ ÀṢÌṢE ÀWỌN MÍÌ

13, 14. (a) Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ṣe sùúrù fún ara wa? (b) Ìlérí wo ló yẹ ká máa rántí?

13 Kí la lè ṣe nígbà tí ẹnì kan tá a jọ ń sin Jèhófà bá sọ ohun kan tàbí ṣe ohun tó dùn wá? Ìlànà Bíbélì kan sọ pé: “Má ṣe kánjú nínú ẹ̀mí rẹ láti fara ya, nítorí pé fífara ya sinmi ní oókan àyà àwọn arìndìn.” (Oníw. 7:⁠9) A tún gbọ́dọ̀ fi sọ́kàn pé ó ti tó nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́fà [6,000] ọdún táwa èèyàn ti jẹ́ aláìpé. Èèyàn aláìpé ò sì lè má ṣàṣìṣe. Torí náà, kò bọ́gbọ́n mu ká máa rétí pé káwọn tá a jọ ń sin Jèhófà jẹ́ ẹni pípé, àti pé kò yẹ kí wọ́n ṣàṣìṣe. Bákan náà, kò yẹ ká jẹ́ kí àṣìṣe wọn paná ayọ̀ tá à ń rí bá a ṣe wà lára àwọn èèyàn Ọlọ́run láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí. Kò sì ní dáa tá a bá lọ jẹ́ kí àṣìṣe wọn mú wa kọsẹ̀, ká wá torí ìyẹn fi ètò Jèhófà sílẹ̀. Tíyẹn bá lọ ṣẹlẹ̀ sí wa pẹ́nrẹ́n, a máa pàdánù àǹfààní tá a ní láti máa ṣèfẹ́ Ọlọ́run báyìí, àá sì tún pàdánù àǹfààní láti wà nínú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí.

14 Kí ayọ̀ tá a ní má bàa dín kù, kí ìrètí wa sì fẹsẹ̀ múlẹ̀, ó yẹ ká máa rántí ìlérí tó ń mọ́kàn yọ̀ tí Jèhófà ṣe, ó ní: “Kíyè sí i, èmi yóò dá ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun; àwọn ohun àtijọ́ ni a kì yóò sì mú wá sí ìrántí, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò wá sí ọkàn-àyà.” (Aísá. 65:17; 2 Pét. 3:13) Torí náà, má ṣe jẹ́ kí àṣìṣe àwọn míì mú kó o pàdánù àwọn ìbùkún yìí.

15. Kí ni Jésù ní ká ṣe táwọn míì bá ṣe ohun tó dùn wá?

15 Ní báyìí náà, a ò tíì dé inú ayé tuntun. Torí náà, ó yẹ ká tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tí Ọlọ́run fún wa lórí ohun tá a lè ṣe táwọn kan bá sọ ohun kan tàbí ṣe ohun tó dùn wá. Bí àpẹẹrẹ, Jésù sọ ìlànà kan tó yẹ ká máa rántí, ó ní: “Bí ẹ bá dárí àṣemáṣe àwọn ènìyàn jì wọ́n, Baba yín ọ̀run yóò dárí jì yín pẹ̀lú; nígbà tí ó jẹ́ pé, bí ẹ kò bá dárí àṣemáṣe àwọn ènìyàn jì wọ́n, Baba yín kì yóò dárí àwọn àṣemáṣe yín jì yín.” Bákan náà, nígbà tí Pétérù bi Jésù pé ṣó yẹ ká dárí jini “títí dé ìgbà méje.” Jésù dá a lóhùn pé: “Mo wí fún ọ, kì í ṣe, títí dé ìgbà méje, bí kò ṣe, títí dé ìgbà àádọ́rin lé méje.” Jésù jẹ́ kó ṣe kedere pé ó yẹ ká múra tán láti máa dárí jini, kódà ohun tó yẹ kó máa wù wá láti ṣe nígbà gbogbo nìyẹn.​—⁠Mát. 6:​14, 15; 18:​21, 22.

16. Àpẹẹrẹ tó dáa wo ni Jósẹ́fù fi lélẹ̀ fún wa?

16 Ẹnì kan wà tó fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fún wa nípa ohun tó yẹ ká ṣe táwọn míì bá ṣẹ̀ wá. Ẹni náà ni Jósẹ́fù tó jẹ́ àkọ́bí nínú ọmọ méjì tí Rákélì bí fún Jékọ́bù. Àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ mẹ́wẹ̀ẹ̀wá jowú rẹ̀ torí pé òun ni bàbá wọn fẹ́ràn jù. Ni wọ́n bá ta Jósẹ́fù sóko ẹrú. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún, Jósẹ́fù di igbá kejì ọba ilẹ̀ Íjíbítì torí àwọn ohun rere tó ń ṣe nílùú náà. Nígbà tí ìyàn mú ní gbogbo àgbègbè yẹn, àwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù wá sí Íjíbítì kí wọ́n lè ra oúnjẹ, àmọ́ wọn kò dá Jósẹ́fù mọ̀. Jósẹ́fù lè lo agbára tó ní láti gbẹ̀san lára àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ fún ìwà ìkà tí wọ́n hù sí i. Àmọ́ kàkà kó ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe ló dán àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ wò kó lè mọ̀ bóyá wọ́n ti yí pa dà. Nígbà tó rí i pé wọ́n ti yí pa dà, Jósẹ́fù fi ara rẹ̀ hàn. Nígbà tó yá, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ má fòyà. Èmi fúnra mi yóò máa pèsè oúnjẹ fún ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín kéékèèké.” Àkọsílẹ̀ náà fi kún un pé: “Nípa báyìí, ó tù wọ́n nínú, ó sì bá wọn sọ̀rọ̀ lọ́nà ìfinilọ́kànbalẹ̀.”​—⁠Jẹ́n. 50:⁠21.

17. Kí lo máa ṣe táwọn míì bá ṣẹ̀ ọ́?

17 Ó yẹ ká rántí pé aláìpé làwa náà, a sì lè ṣẹ àwọn míì. Tá a bá kíyè sí i pé a ti ṣẹ ẹnì kan, ó yẹ ká tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì tó sọ pé ká lọ bá ẹni tá a ṣẹ̀, ká sì wá bá a ṣe máa yanjú ọ̀rọ̀ náà. (Ka Mátíù 5:​23, 24.) Inú wa máa ń dùn táwọn míì bá dárí jì wá, torí náà ó yẹ káwa náà máa dárí ji àwọn míì. Ìwé Kólósè 3:13 gbà wá níyànjú pé: “Ẹ máa bá a lọ ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà lẹ́nì kìíní-kejì bí ẹnikẹ́ni bá ní ìdí fún ẹjọ́ lòdì sí ẹlòmíràn. Àní gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti dárí jì yín ní fàlàlà, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe.” Ìwé 1 Kọ́ríńtì 13:5 sọ pé ìfẹ́ tó wà láàárín àwa Kristẹni “kì í kọ àkọsílẹ̀ ìṣeniléṣe.” Tá a bá ń dárí ji àwọn míì, Jèhófà máa dárí ji àwa náà. Torí náà, táwọn míì bá ṣe ohun tó dùn wá, ó yẹ ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Bàbá wa onífẹ̀ẹ́ tó máa ń fi àánú hàn sí wa tá a bá ṣàṣìṣe.​—⁠Ka Sáàmù 103:​12-14.