Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Mọyì Jèhófà Tó Jẹ́ Amọ̀kòkò Wa

Mọyì Jèhófà Tó Jẹ́ Amọ̀kòkò Wa

“Jèhófà, . . . ìwọ ni Ẹni tí ó mọ wá; gbogbo wa jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.”​—AÍSÁ. 64:8.

ORIN: 89, 26

1. Kí nìdí tí Jèhófà fi jẹ́ Amọ̀kòkò tó ga jù lọ?

OHUN kan wáyé nílùú London, nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, lóṣù November ọdún 2010. Àwọn èèyàn ń dúnàá-dúrà ìkòkò amọ̀ kan tí àwọn ará Ṣáínà ṣe lóhun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ọdún sẹ́yìn. Kódà, iye owó tó tó àádọ́rin [70] mílíọ̀nù owó Amẹ́ríkà ni wọ́n dá lé e. Àpẹẹrẹ yìí jẹ́ ká rí i pé amọ̀kòkò kan lè sọ ohun téèyàn ò kà sí, bí amọ̀, di ohun iyebíye tó jẹ́ àrímáleèlọ. Síbẹ̀, tó bá di ká fi amọ̀ dárà, kò sí amọ̀kòkò tá a lè fi wé Jèhófà. Nígbà tí ọjọ́ kẹfà ìṣẹ̀dá ń parí lọ, Jèhófà fi “ekuru ilẹ̀” tàbí amọ̀ mọ ọkùnrin pípé kan, ó sì ṣẹ̀dá rẹ̀ lọ́nà táá fi gbé àwọn ànímọ́ rere Ẹlẹ́dàá rẹ̀ yọ. (Jẹ́n. 2:⁠7) Abájọ tí Bíbélì fi pe ọkùnrin pípé náà, Ádámù tá a fi amọ̀ ṣe ní ‘ọmọ Ọlọ́run.’​—Lúùkù 3:⁠38.

2, 3. Báwo la ṣe lè fìwà jọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó ronú pìwà dà?

2 Àmọ́ Ádámù pàdánù àǹfààní tó ní láti jẹ́ ọmọ Ọlọ́run nígbà tó ṣàìgbọràn sí Ẹlẹ́dàá rẹ̀. Síbẹ̀, bí ọmọ aráyé ṣe ń gbilẹ̀ sí i, a rí lára àwọn ọmọ Ádámù tó yàn láti fi ara wọn sábẹ́ àkóso Ọlọ́run, kódà wọ́n pọ̀ gan-an, bí “àwọsánmà.” (Héb. 12:⁠1) Bí wọ́n ṣe fara wọn sábẹ́ àkóso Ẹlẹ́dàá wọn yìí fi hàn pé òun ni wọ́n gbà ní Baba àti Amọ̀kòkò wọn, kì í ṣe Sátánì. (Jòh. 8:44) Bí wọ́n ṣe jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run jẹ́ ká rántí ọ̀rọ̀ tí wòlíì Aísáyà sọ nípa àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó ronú pìwà dà, pé: “Jèhófà, ìwọ ni Baba wa. Àwa ni amọ̀, ìwọ sì ni Ẹni tí ó mọ wá; gbogbo wa jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.”​—⁠Aísá. 64:⁠8.

3 Lóde òní, gbogbo àwọn tó ń jọ́sìn Jèhófà ní ẹ̀mí àti òtítọ́ ń sapá láti ní irú ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní yìí, wọ́n sì tún ń fara wọn sábẹ́ Ọlọ́run. Wọ́n gbà pé ohun iyì gbáà ni pé káwọn máa pe Jèhófà ní Baba àwọn, káwọn sì mọ̀ ọ́n ní Amọ̀kòkò àwọn. Ǹjẹ́ o ka ara rẹ sí amọ̀ rírọ̀ lọ́wọ́ Ọlọ́run, ṣó wù ẹ́ pé kí Ọlọ́run mọ ẹ́, kó o sì di ohun èlò tó fani mọ́ra, tínú rẹ̀ dùn sí? Ṣé ojú kan náà lo fi ń wo àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin, pé àwọn náà dà bí amọ̀ lọ́wọ́ Jèhófà, àti pé ó ṣì ń mọ wọ́n lọ́wọ́? Ká lè máa fi irú ojú bẹ́ẹ̀ wo ara wa àtàwọn ará wa, ẹ jẹ́ ká jíròrò apá mẹ́ta lára iṣẹ́ tí Jèhófà ń ṣe gẹ́gẹ́ bí Amọ̀kòkò: Kí ló ń pinnu àwọn tí Jèhófà máa mọ? Kí nìdí tó fi ń mọ wọ́n? Báwo ló ṣe ń mọ wọ́n?

JÈHÓFÀ LÓ Ń PINNU ÀWỌN TÓ MÁA MỌ

4. Báwo ni Jèhófà ṣe ń pinnu àwọn tó máa fà wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀? Sọ àpẹẹrẹ kan.

4 Bí Jèhófà ṣe ń kíyè sí ọmọ aráyé, kì í ṣe ẹwà tàbí ìrísí wa ló ń wò. Kàkà bẹ́ẹ̀, ọkàn wa ló ń wò, ìyẹn irú ẹni tá a jẹ́ gan-an. (Ka 1 Sámúẹ́lì 16:7b.) Ọ̀rọ̀ yìí túbọ̀ ṣe kedere nígbà tí Ọlọ́run dá ìjọ Kristẹni sílẹ̀. Onírúurú èèyàn tí àwọn èèyàn ò kà sí ni Jèhófà mú kó wá sọ́dọ̀ Jésù, ọmọ rẹ̀. (Jòh. 6:44) Ọ̀kan lára irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ni Sọ́ọ̀lù tó jẹ́ Farisí tẹ́lẹ̀. Nígbà yẹn, ó jẹ́ “asọ̀rọ̀ òdì àti onínúnibíni àti aláfojúdi.” (1 Tím. 1:13) Àmọ́, Jèhófà tó jẹ́ ‘olùṣàyẹ̀wò ọkàn,’ mọ̀ pé amọ̀ tó ṣì máa wúlò ni Sọ́ọ̀lù. (Òwe 17:⁠3) Ohun tí Ọlọ́run rí lára ọkùnrin yìí yàtọ̀ pátápátá, Ọlọ́run rí i pé amọ̀ táá ṣeé fi mọ ohun èlò tó fani mọ́ra ni Sọ́ọ̀lù. Àní sẹ́, “ohun èlò tí a ti yàn ni” láti jẹ́rìí fún “àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn ọba àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.” (Ìṣe 9:15) Àwọn míì tí Ọlọ́run rí i pé wọ́n máa jẹ́ ohun èlò “fún ìlò ọlọ́lá” ni àwọn tó ti fìgbà kan jẹ́ ọ̀mùtí, oníṣekúṣe àti olè. (Róòmù 9:21; 1 Kọ́r. 6:​9-11) Bí wọ́n ṣe túbọ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n ń lo ìgbàgbọ́, wọ́n sì gbà kí Jèhófà mọ àwọn bí amọ̀kòkò ṣe máa ń mọ amọ̀.

5, 6. Tá a bá gbà pé Jèhófà ni Amọ̀kòkò wa, irú ojú wo ló yẹ ká máa fi wo (a) àwọn èèyàn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa? (b) àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin?

5 Kí la rí kọ́ nínú àwọn àpẹẹrẹ tá a sọ tán yìí? Ó ṣe kedere pé Jèhófà lágbára láti mọ ohun tó wà lọ́kàn èèyàn, a sì mọ̀ pé òun fúnra rẹ̀ ló ń pinnu ẹni tó máa fà wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀. Torí náà, kò yẹ ká máa dá àwọn èèyàn lẹ́jọ́, yálà àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa tàbí àwọn tá a jọ wà nínú ìjọ. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Michael. Ó sọ pé, “Nígbàkigbà táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá fẹ́ wàásù fún mi, mi ò kì í fún wọn láyè, ṣe ni mo máa ń pa wọ́n tì bíi pé wọn kì í ṣèèyàn. Mo máa ń rí wọn fín gan-an! Kò pẹ́ sígbà yẹn, mo bá ìdílé kan pàdé níbì kan tí mo lọ, bí ìdílé yẹn ṣe ń ṣe wú mi lórí gan-an. Kò pẹ́ ni mo wá mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wọ́n, ó sì yà mí lẹ́nu gan-an! Ìwà wọn jọ mí lójú débi pé mo gbà pé á dáa kí n tún inú rò nípa ojú tí mo fi ń wo àwọn Ẹlẹ́rìí. Mo wá rí i pé àìmọ̀kan àti àhesọ lásán ló fà á tí mo fi ń fojú burúkú wò wọ́n, mi ò mọ irú ẹni tí wọ́n jẹ́ gan-an.” Torí pé Michael fẹ́ mọ irú ẹni tí wọ́n jẹ́ gan-an, ó gbà kí wọ́n máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nígbà tó yá, ó di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó sì di òjíṣẹ́ alákòókò kíkún.

6 Bákan náà, tá a bá gbà pé Jèhófà ni Amọ̀kòkò wa lóòótọ́, ó máa hàn nínú bá a ṣe ń hùwà sáwọn ará wa. Ó yẹ ká bi ara wa pé, Ṣé ojú tí Jèhófà fi ń wo àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin lèmi náà fi ń wò wọ́n, pé Jèhófà ò tíì mọ wọ́n tán, ó ṣì ń mọ wọ́n lọ́wọ́? Ó mọ irú ẹni tá a jẹ́ nínú, ó sì mọ irú ẹni tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa máa jẹ́ bí òun ṣe ń mọ wá nìṣó. Torí náà, Jèhófà kì í wo àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ wa, ibi tá a dáa sí àti bá a ṣe máa rí nígbà tó bá mọ wá tán ló máa ń wò. (Sm. 130:⁠3) Ẹ jẹ́ ká fìwà jọ Jèhófà, ká máa wo ibi táwọn ará wa dáa sí. Ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, á dáa ká máa bá Amọ̀kòkò wa ṣiṣẹ́. Lọ́nà wo? Ká máa ti àwọn ará wa lẹ́yìn bí wọ́n ti ń sapá láti túbọ̀ fìwà jọ Ọlọ́run wa. (1 Tẹs. 5:​14, 15) Àwọn alàgbà la retí pé kó múpò iwájú nínú ṣíṣe bẹ́ẹ̀, torí pé “ẹ̀bùn [tí ó jẹ́] ènìyàn” ni wọ́n.​—⁠Éfé. 4:​8, 11-13.

KÍ NÌDÍ TÍ JÈHÓFÀ FI Ń MỌ WÁ?

7. Ṣó o mọyì ìbáwí Jèhófà? Kí nìdí?

7 Ó ṣeé ṣe kó o ti gbọ́ tẹ́nì kan sọ pé: ‘Mi ò mọyì gbogbo ìbáwí táwọn òbí mi ń fún mi bí mo ṣe ń dàgbà, àfìgbà témi náà wá ní àwọn ọmọ tèmi.’ Bá a ṣe ń dàgbà tá a sì ń gbọ́n sí i, á túbọ̀ máa yé wa pé ìbáwí máa ń mú kéèyàn gbọ́n, àá wá rí i pé ìfẹ́ ló ń mú kí Jèhófà bá wa wí. (Ka Hébérù 12:​5, 6, 11.) Torí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwa ọmọ rẹ̀, sùúrù ló fi máa ń mọ wá bí àwọn amọ̀kòkò ṣe rọra ń mọ amọ̀. Ó fẹ́ ká gbọ́n, ká láyọ̀, ká sì nífẹ̀ẹ́ òun bó ṣe nífẹ̀ẹ́ wa. (Òwe 23:15) Inú Jèhófà kì í dùn tá a bá ń jìyà; bẹ́ẹ̀ sì ni kò fẹ́ ká kú ikú “ọmọ ìrunú,” torí ohun tí Ádámù sọ wá dà nìyẹn nígbà tó ṣẹ̀.​—⁠Éfé. 2:​2, 3.

8, 9. Báwo ni Jèhófà ṣe ń kọ́ wa lónìí? Báwo ni ẹ̀kọ́ náà á ṣe máa bá a nìṣó lọ́jọ́ iwájú?

8 Kó tó di pé a mọ Jèhófà, a máa ń hu àwọn ìwà kan tí kò dùn mọ́ Ọlọ́run nínú, kódà ìwà tó jọ ti ẹranko làwọn kan ń hù tẹ́lẹ̀. Ọpẹ́lọpẹ́ Jèhófà lára wa, a ti yíwà pa dà, a sì ti wá dà bí àgùntàn báyìí. (Aísá. 11:​6-8; Kól. 3:​9, 10) Torí náà, ní báyìí tí Jèhófà ń mọ wá ká lè fìwà jọ ọ́, ṣe ló dà bíi pé a wà nínú Párádísè tẹ̀mí tó ń gbèrú sí i lójoojúmọ́. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ayé èṣù là ń gbé, ọkàn wa balẹ̀, a sì ń láyọ̀ nínú Párádísè yìí. Yàtọ̀ síyẹn, inú àwọn kan lára wa ń dùn gan-an, torí pé ìfẹ́ tí wọn ò rí nínú ìdílé tí wọ́n ti wá ni wọ́n ń rí báyìí. (Jòh. 13:35) A sì ti kọ́ bá a ṣe ń fìfẹ́ hàn sáwọn ẹlòmíì. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, a ti wá mọ Jèhófà, a sì ń gbádùn ìfẹ́ tó ń fi hàn sí wa.​—⁠Ják. 4:⁠8.

9 Nínú ayé tuntun, ṣe ni òjò ìbùkún Párádísè tẹ̀mí yìí á máa rọ̀ sórí wa. Láfikún sí Párádísè tẹ̀mí tá à ń gbádùn báyìí, nígbà yẹn a tún máa gbádùn Párádísè tó ṣeé fojú rí lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run. Ìgbà ọ̀tun ni ìgbà yẹn máa jẹ́ níbi gbogbo. Lásìkò yẹn, Jèhófà Amọ̀kòkò wa á ṣì máa mọ aráyé nìṣó, á máa kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́, ẹ̀kọ́ náà á gadabú débi pé kò ní láfiwé. (Aísá. 11:⁠9) Yàtọ̀ síyẹn, Ọlọ́run máa sọ wá di pípé lérò àti lára, tó fi jẹ́ pé bí ẹni fẹran jẹ̀kọ la ó máa lóye ẹ̀kọ́ tí wọ́n bá ń kọ́ wa nígbà yẹn, àá sì máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run lọ́nà tó pé pérépéré. Torí náà, ẹ jẹ́ ká pinnu pé ohun tí Jèhófà fẹ́ la ó máa ṣe, àti pé a gbà pé ìfẹ́ tó ní sí wa ló mú kó máa mọ wá.​—⁠Òwe 3:​11, 12.

BÍ JÈHÓFÀ ṢE Ń MỌ WÁ

10. Kí ni Jésù ṣe tó fi hàn pé ó ní sùúrù, ó sì mọṣẹ́ bíi ti Jèhófà, Amọ̀kòkò Ńlá náà?

10 Àwọn amọ̀kòkò tó mọṣẹ́ mọ̀ pé amọ̀ yàtọ̀ síra, lọ́nà kan náà Jèhófà mọ irú “amọ̀” tí kálukú wa jẹ́, ó sì máa ń fìyẹn sọ́kàn nígbà tó bá ń mọ wá. (Ka Sáàmù 103:​10-14.) Ọwọ́ tó fi ń mú kálukú wa yàtọ̀ síra, ó mọ ibi tẹ́nì kọ̀ọ̀kan wa kù sí, ibi tágbára wa mọ àti bí òye òtítọ́ tá a ní ṣe pọ̀ tó. Jésù Kristi jẹ́ ká mọ ojú tí Jèhófà fi ń wo àìpé wa. Bí àpẹẹrẹ, ronú nípa ojú tí Jésù fi wo kùdìẹ̀-kudiẹ àwọn àpọ́sítélì rẹ̀, pàápàá jù lọ lórí ọ̀rọ̀ ta lọ̀gá tí wọ́n máa ń fà láàárín ara wọn. Tó o bá wà níbẹ̀ nígbà táwọn àpọ́sítélì ń bá ara wọn jiyàn, ṣé wàá sọ pé onírẹ̀lẹ̀ ni wọ́n àti pé wọ́n á ṣeé tẹ̀ síbí tẹ̀ sọ́hùn-ún? Síbẹ̀, Jésù ò gbà pé ọ̀rọ̀ wọn kọjá àtúnṣe. Ó mọ̀ pé tóun bá ń fi sùúrù gbà wọ́n nímọ̀ràn, tí òun jẹ́ onínúure, tí wọ́n sì ń rí bóun ṣe jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, wọ́n á ṣàtúnṣe tó yẹ. (Máàkù 9:​33-37; 10:​37, 41-45; Lúùkù 22:​24-27) Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, táwọn àpọ́sítélì náà sì gba ẹ̀mí mímọ́, bí wọ́n ṣe máa ṣe iṣẹ́ tí Jésù gbé lé wọn lọ́wọ́ ló gbà wọ́n lọ́kàn, wọn ò tún sọ̀rọ̀ nípa ta lọ̀gá mọ́.​—⁠Ìṣe 5:⁠42.

11. Báwo ni Dáfídì ṣe fi hàn pé òun ṣeé mọ? Báwo la ṣe lè fara wé e?

11 Lásìkò wa yìí, Jèhófà ń lo Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ àti ìjọ Kristẹni láti mọ wá. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run á mọ wá tá a bá ń kà á bíi pé àwa gan-an ni wọ́n kọ ọ́ fún, tá à ń ṣàṣàrò lórí ohun tá a kà, tá a sì ń bẹ Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́ láti fi ohun tá a kà sílò. Dáfídì sọ pé, “Mo rántí rẹ lórí àga ìrọ̀gbọ̀kú gbọọrọ mi, mo ń ṣe àṣàrò nípa rẹ ní àwọn ìṣọ́ òru.” (Sm. 63:⁠6) Ó tún sọ pé: “Èmi yóò fi ìbùkún fún Jèhófà, ẹni tí ó ti fún mi ní ìmọ̀ràn. Ní ti tòótọ́, kíndìnrín mi ti tọ́ mi sọ́nà ní òru.” (Sm. 16:⁠7) Ó ṣe kedere pé Dáfídì jẹ́ kí ìmọ̀ràn Ọlọ́run wọ òun lọ́kàn ṣinṣin, ó jẹ́ kó yí bí òun ṣe ń ronú àti ojú tí òun fi ń wo nǹkan pa dà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìmọ̀ràn náà lè nira. (2 Sám. 12:​1-13) Ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ àtàtà ni Dáfídì jẹ́ tó bá di pé kéèyàn jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ àtẹni tó ń fi ara rẹ̀ sábẹ́ àkóso Ọlọ́run! Ṣé ìwọ náà máa ń ṣàṣàrò lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ṣé o sì ń jẹ́ kó wọnú ọkàn rẹ̀ ṣinṣin? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ṣé o lè túbọ̀ fi kún ìsapá rẹ?​—⁠Sm. 1:​2, 3.

12, 13. Báwo ni Jèhófà ṣe ń lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ àti ìjọ Kristẹni láti mọ wá?

12 Onírúurú ọ̀nà ni ẹ̀mí mímọ́ lè gbà mọ wá. Bí àpẹẹrẹ, ó lè mú ká ní àwọn ìwà tó yẹ Kristẹni, ní pàtàkì ká máa fi èso ti ẹ̀mí Ọlọ́run ṣèwàhù. (Gál. 5:​22, 23) Ọ̀kan lára èso yìí ni ìfẹ́. A nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, ó ń wù wá ká máa ṣègbọràn sí i, a fẹ́ kó mọ wá, a sì gbà pé òfin rẹ̀ kò ni wá lára. Ẹ̀mí mímọ́ máa fún wa lágbára tí a ò fi ní jẹ́ kí ayé sọ wá dà bó ṣe dà. (Éfé. 2:⁠2) Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wà lọ́dọ̀ọ́, ẹ̀mí ìgbéraga táwọn aṣáájú ìsìn Júù ní wọ òun náà lẹ́wù, àmọ́ nígbà tó yá ó sọ pé: “Mo ní okun fún ohun gbogbo nípasẹ̀ agbára ìtóye ẹni tí ń fi agbára fún mi.” (Fílí. 4:13) Torí náà, ẹ jẹ́ káwa náà máa bẹ Jèhófà pé kó fún wa lẹ́mìí mímọ́ rẹ̀, bí Pọ́ọ̀lù ti ṣe. Jèhófà máa ń gbọ́ irú àdúrà bẹ́ẹ̀.​—⁠Sm. 10:⁠17.

Jèhófà ń lo ìjọ Kristẹni àtàwọn alàgbà láti mọ wá, àmọ́ àwa náà gbọ́dọ̀ ṣe ipá tiwa (Wo ìpínrọ̀ 12 àti 13)

13 Jèhófà máa ń lo ìjọ Kristẹni àtàwọn alábòójútó láti mọ wá lẹ́nì kọ̀ọ̀kàn. Bí àpẹẹrẹ, táwọn alàgbà bá kíyè sí i pé à ń jó àjórẹ̀yìn nípa tẹ̀mí, wọ́n máa ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti ràn wá lọ́wọ́. Àmọ́, wọn kì í lo ọgbọ́n ara wọn. (Gál. 6:⁠1) Kàkà bẹ́ẹ̀, torí pé onírẹ̀lẹ̀ ni wọ́n, Ọlọ́run ni wọ́n máa ń bẹ̀ pé kó fún àwọn ní ìjìnlẹ̀ òye àti ọgbọ́n. Wọ́n máa ń ronú nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí wa, wọ́n á gbàdúrà nípa rẹ̀, wọ́n á sì tún ṣèwádìí nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àtàwọn ìtẹ̀jáde ètò Ọlọ́run. Ìwádìí yìí á jẹ́ kí wọ́n lè ràn wá lọ́wọ́ bó ṣe yẹ. Tí wọ́n bá wá gbà ẹ́ níyànjú tìfẹ́tìfẹ́, bóyá nípa àwọn aṣọ tó ò ń wọ̀ tàbí bó o ṣe ń múra, ṣé wàá gbà pé ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí ẹ ló mú kí àwọn alàgbà yẹn wá ràn ẹ́ lọ́wọ́? Tó o bá gbà bẹ́ẹ̀, ṣe lo dà bí amọ̀ tó rọ̀ lọ́wọ́ Jèhófà, àti pé o fẹ́ kí Jèhófà fi ẹ́ mọ ohun èlò tó máa ṣe ìwọ alára láǹfààní.

14. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà lágbára láti fi wá mọ ohun tó fẹ́, báwo ló ṣe ń fún wa lómìnira láti yan ohun tá a fẹ́?

14 Ní báyìí tá a ti mọ bí Ọlọ́run ṣe ń mọ wá, á jẹ́ ká ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn ará, á tún jẹ́ ká mọ bó ṣe yẹ ká máa hùwà sáwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa títí kan àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, àwọn amọ̀kòkò kì í kàn wa amọ̀ jọ, kí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í mọ ọ́n. Ohun tí wọ́n á kọ́kọ́ ṣe ni pé, wọ́n á ṣa gbogbo pàǹtírí àti òkúta tó wà nínú ẹ̀ kúrò. Bí Jèhófà ṣe máa ń ran àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ náà nìyẹn kó lè mọ wọ́n. Kì í mú ẹnikẹ́ni ní ọ̀ranyàn pé kó yí pa dà, ṣe ló máa kọ́ onítọ̀hún láwọn ìlànà òdodo rẹ̀. Bí onítọ̀hún bá sì fẹ́, á ṣe àwọn ìyípadà tó yẹ.

15, 16. Báwo làwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe máa ń fi hàn pé àwọn fẹ́ kí Jèhófà mọ àwọn? Sọ àpẹẹrẹ kan.

15 Ronú nípa àpẹẹrẹ arábìnrin Tessie, tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Ọsirélíà. Arábìnrin tó kọ́ Tessie lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sọ pé: “Wẹ́rẹ́ báyìí ni Tessie lóye ẹ̀kọ́ òtítọ́ nígbà tó ń kẹ́kọ̀ọ́. Àmọ́, kò sí ẹ̀rí pé ó ń tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí, kò tiẹ̀ dé ẹnu ọ̀nà Gbọ̀ngàn Ìjọba rí! Lẹ́yìn ti mo ronú lórí ọ̀rọ̀ náà tàdúràtàdúrà, mo pinnu pé màá dá ìkẹ́kọ̀ọ́ náà dúró. Àmọ́, ohun kan ṣẹlẹ̀ tó yà mí lẹ́nu. Lọ́jọ́ tí mo pinnu pé màá dá ìkẹ́kọ̀ọ́ náà dúró, Tessie sọ ohun tó ń dí i lọ́wọ́ fún mi. Ó ní ojú ayé lòun ń ṣe torí pé òun fẹ́ràn àtimáa ta tẹ́tẹ́. Àmọ́ ní báyìí, òun ti pinnu pé òun á jáwọ́ nínú ẹ̀.”

16 Kò pẹ́ sígbà yẹn, Tessie bẹ̀rẹ̀ sí í wá sípàdé ó sì ń fi àwọn ohun tó ń kọ sílò, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ àtijọ́ máa ń fi í ṣe yẹ̀yẹ́. Arábìnrin tó ń kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ wá sọ pé: “Nígbà tó yá, Tessie ṣèrìbọmi ó sì di aṣáájú-ọ̀nà déédéé bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọ mẹ́rin ló ń tọ́ lọ́wọ́.” Kò sí àní-àní pé táwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàtúnṣe kí wọ́n lè múnú Ọlọ́run dùn, Jèhófà máa ń sún mọ́ wọn, á sì mọ wọ́n lọ́nà tí wọ́n á fí wúlò fún ara wọn àti fún Jèhófà.

17. (a) Kí ló múnú rẹ dùn nípa bí Jèhófà, Amọ̀kòkò wa ṣe ń mọ wá? (b) Àwọn nǹkan míì wo la tún máa jíròrò nípa bí Jèhófà ṣe ń mọ wá nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?

17 Títí dòní olónìí, àwọn amọ̀kòkò kan ṣì ń fi ọwọ́ mọ ìkòkò tó lẹ́wà gan-an. Lọ́nà kan náà, Jèhófà Amọ̀kòkò wa ń fi sùúrù mọ wá, ó ń fìfẹ́ gbà wá nímọ̀ràn, ó sì ń kíyè sí bá a ṣe ń fi ìmọ̀ràn rẹ̀ sílò. (Ka Sáàmù 32:⁠8.) Ǹjẹ́ ò ń rí ọwọ́ Jèhófà láyé rẹ àti pé lóòótọ́ ló nífẹ̀ẹ́ rẹ? Ṣé ò ń kíyè sí bó ṣe ń fìfẹ́ mọ ẹ́? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, àwọn ànímọ́ míì wo ló yẹ kó o ní táá jẹ́ kó o dà bí amọ̀ tó rọ̀ tó sì ṣeé tẹ̀ síbí tẹ̀ sọ́hùn-ún lọ́wọ́ Jèhófà? Àwọn ìwà wo ló yẹ kó o yẹra fún kó o má bàa dà bí amọ̀ tó le tàbí tí kò ṣeé lò láti mọ nǹkan? Ọ̀nà wo làwọn òbí sì lè gbà máa bá Jèhófà ṣiṣẹ́ bó ṣe ń mọ àwọn ọmọ wọn? A máa jíròrò àwọn kókó yìí nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.