Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Rántí?

Ǹjẹ́ O Rántí?

Ṣé o ti fara balẹ̀ ka àwọn Ilé Ìṣọ́ tó jáde lẹ́nu àìpẹ́ yìí? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, wò ó bóyá wàá lè dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

Kí nìdí tí Jèhófà fi fọwọ́ sí àwọn ogun táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì jà?

Jèhófà jẹ́ onífẹ̀ẹ́. Àmọ́ láwọn ìgbà míì, ó máa ń fọwọ́ sí ogun nígbà táwọn ẹni burúkú bá ń halẹ̀ mọ́ àwọn èèyàn rẹ̀. Ọlọ́run nìkan ló ń pinnu àwọn tó máa lọ jagun àti ìgbà tógun máa jà.​—⁠w15 11/⁠1, ojú ìwé 4 sí 5.

Kí làwọn nǹkan pàtàkì tó dáa káwọn òbí ṣe láti kọ́ àwọn ọmọ wọn kí wọ́n lè sin Jèhófà?

Ó ṣe pàtàkì pé káwọn òbí nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ wọn, kí wọ́n sì máa ṣe àwọn ohun tó ń fi hàn pé wọ́n ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀. Ó tún ṣe pàtàkì pé káwọn òbí máa lo òye, kí wọ́n sì sapá láti mọ bí ọ̀rọ̀ ṣe ń rí lára àwọn ọmọ wọn.​—⁠w15 11/⁠15, ojú ìwé 9 sí 11.

Kí nìdí tí kò fi yẹ ká rò pé póòpù ló rọ́pò Pétérù?

Mátíù 16:​17, 18 kò sọ pé àpọ́sítélì Pétérù ló máa di orí ìjọ Kristẹni. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Pétérù kọ́ ni olórí nínú ìjọ, kàkà bẹ́ẹ̀, Jésù ni òkúta igun ilé fún ìjọ Kristẹni. (1 Pét. 2:​4-8)​—⁠w15 12/⁠1, ojú ìwé 12 sí 14.

Kí làwọn ohun tó yẹ ká fi sọ́kàn ká tó sọ̀rọ̀?

Ká tó lè lo ahọ́n wa lọ́nà tó dáa, a gbọ́dọ̀ mọ (1) ìgbà tó yẹ ká sọ̀rọ̀ (Oníw. 3:⁠7), (2) ohun tó yẹ ká sọ (Òwe 12:18), àti (3) bó ṣe yẹ ká sọ̀rọ̀ (Òwe 25:15).​—⁠w15 12/⁠15, ojú ìwé 19 sí 22.

Kí ni díẹ̀ lára àwọn ìwà àìṣòótọ́ táwa Kristẹni kì í hù?

Àwa Kristẹni kì í parọ́, a kì í sì í bani lórúkọ jẹ́. A kì í ṣòfófó, a kì í lu jìbìtì bẹ́ẹ̀ sì la ò kì í jalè.​—⁠wp16.1, ojú ìwé 5.

Àwọn wo ni “àwọn olórí àlùfáà” tí Bíbélì mẹ́nu kàn?

“Àwọn olórí àlùfáà” ni àwọn tó jẹ́ abẹnugan nínú ìdílé àwọn àlùfáà àtàwọn tó ti fìgbà kan rí jẹ́ àlùfáà àgbà àmọ́ tí wọ́n ti rọ̀ lóyè.​—⁠wp16.1, ojú ìwé 10.

Ojú wo ló yẹ kó o fi máa wo ẹni tó ń jẹ búrẹ́dì tó sì ń mu wáìnì níbi Ìrántí Ikú Kristi?

Àwa Kristẹni kì í gbé wọn gẹ̀gẹ̀. Àwọn ojúlówó ẹni àmì òróró kò sì ní fẹ́ káwọn èèyàn máa fáwọn láfiyèsí àrà ọ̀tọ̀. Wọn ò ní máa sọ fáwọn èèyàn pé ẹni àmì òróró làwọn. (Mát. 23:​8-12)​—⁠w16.01, ojú ìwé 22 sí 23.

Kí la rí kọ́ látinú bí Ábúráhámù ṣe di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run?

Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọ̀dọ̀ Ṣémù ni Ábúráhámù ti mọ̀ nípa Ọlọ́run. Ábúráhámù sì tún kẹ́kọ̀ọ́ látinú ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà bá òun àti ìdílé rẹ̀ lò. Àwa náà lè ṣe bẹ́ẹ̀.​—⁠w16.02, ojú ìwé 5.

Báwo ni orí àti ẹsẹ ṣe dé inú Bíbélì?

Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹtàlá, àlùfáà kan tó ń jẹ Stephen Langton pín Bíbélì sí àwọn orí. Àwọn adàwékọ Júù fi ẹsẹ sí Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, ìyẹn Jẹ́nẹ́sísì sí Málákì. Nígbà tó sì di ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrìndínlógún, ọ̀mọ̀wé kan tó ń jẹ́ Robert Estienne fi ẹsẹ sí Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, ìyẹn Mátíù sí Ìṣípayá.​—⁠wp16.2, ojú ìwé 14 sí 15.

Nígbà tí Sátánì dán Jésù wò, ṣé tẹ́ńpìlì gangan ló mú Jésù lọ àbí ṣe ló fi tẹ́ńpìlì hàn án nínú ìran?

A ò lè sọ. Bí ìwé Mátíù 4:5 àti Lúùkù 4:9 ṣe sọ, ó lè jẹ́ pé inú ìran ni Sátánì ti fi hàn án tàbí kó jẹ́ pé Jésù dúró lórí ibi tó ga gan-an ní tẹ́ńpìlì.​—⁠w16.03, ojú ìwé 31 sí 32.

Báwo ni iṣẹ́ ìwàásù wa ṣe lè dà bí ìrì?

Ìrì rọra máa ń sẹ̀, ó máa ń tuni lára, ó sì ń gbẹ̀mí là. Ìbùkún látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ìrì. (Diu. 33:13) Bẹ́ẹ̀ náà ni ìsapá ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run ṣe rí.​—⁠w16.04, ojú ìwé 31 sí 32.