Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Máa Fi Àwọn Òfin àti Ìlànà Jèhófà Kọ́ Ẹ̀rí Ọkàn Rẹ

Máa Fi Àwọn Òfin àti Ìlànà Jèhófà Kọ́ Ẹ̀rí Ọkàn Rẹ

“Àwọn ìránnilétí rẹ ni ìdàníyàn mi.”​—SM. 119:99.

ORIN: 127, 88

1. Kí ni Jèhófà fún wa tó mú ká yàtọ̀ sáwọn ẹranko?

ÀTÌGBÀ tí Jèhófà ti dá àwa èèyàn ló ti fún wa lóhun kan tó mú ká yàtọ̀ sáwọn ẹranko, ìyẹn sì ni ẹ̀rí ọkàn. Lẹ́yìn tí Ádámù àti Éfà ṣàìgbọràn sí Jèhófà, ṣe ni wọ́n sá pa mọ́. Èyí fi hàn pé ẹ̀rí ọkàn wọn ń dà wọ́n láàmú lẹ́yìn tí wọ́n dẹ́ṣẹ̀.

2. Báwo la ṣe lè fi ẹ̀rí ọkàn wa wé kọ́ńpáàsì kan? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

2 Tí ẹ̀rí ọkàn ẹnì kan ò bá ṣiṣẹ́ dáadáa, ńṣe lẹni náà dà bí ọkọ̀ ojú omi tó wà lójú agbami àmọ́ tí ẹ̀rọ atọ́nisọ́nà ìyẹn kọ́ńpáàsì tó ní kò ṣiṣẹ́ dáadáa. Ó léwu gan-an tí awakọ̀ kan bá ń fi kọ́ńpáàsì tí kò ṣiṣẹ́ dáadáa darí ọkọ̀ ojú omi rẹ̀ torí pé atẹ́gùn àti ìgbì òkun lè darí ọkọ̀ náà gba ibòmíì. Àmọ́ tí kọ́ńpáàsì ọkọ̀ kan bá ń ṣiṣẹ́ dáadáa, ìyẹn á jẹ́ kí ọkọ̀ ojú omi náà gba ojú ọ̀nà tó tọ́. Lọ́nà kan náà, ẹ̀rí ọkàn wa dà bíi kọ́ńpáàsì tó ń darí ọkọ̀ ojú omi kan. Ẹ̀rí ọkàn wa máa ń jẹ́ ká mọ ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́, ó sì máa ń darí wa sí ọ̀nà tó yẹ. Àmọ́ kí ẹ̀rí ọkàn wa tó lè tọ́ wa sọ́nà, kò sí darí wa síbi tó yẹ, ó gbọ́dọ̀ máa ṣiṣẹ́ bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ.

3. Kí ló lè ṣẹlẹ̀ tẹ́nì kan ò bá kọ́ ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ dáadáa?

3 Tí ẹnì kan ò bá kọ́ ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ dáadáa, ẹ̀rí ọkàn náà ò ní kìlọ̀ fún un tó bá fẹ́ ṣe ohun tí kò tọ́. (1 Tím. 4:​1, 2) Irú ẹ̀rí ọkàn bẹ́ẹ̀ lè mú kó dà bíi pé “ohun tí ó burú dára.” (Aísá. 5:20) Jésù kìlọ̀ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Wákàtí náà ń bọ̀ nígbà tí olúkúlùkù ẹni tí ó bá pa yín yóò lérò pé òun ti ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún Ọlọ́run.” (Jòh. 16:2) Bọ́rọ̀ sì ṣe rí lára àwọn tó pa Sítéfánù nìyẹn torí wọ́n rò pé Ọlọ́run làwọn ń jà fún. (Ìṣe 6:​8, 12; 7:​54-60) Bákan náà lónìí, àwọn agbawèrèmẹ́sìn kan máa ń hùwàkiwà, wọ́n sì máa ń pààyàn, wọ́n á ní Ọlọ́run làwọn ń ṣe é fún. Àmọ́ ohun tí wọ́n ń ṣe yẹn tako òfin Ọlọ́run tí wọ́n láwọn ń jà fún. (Ẹ́kís. 20:13) Ó hàn gbangba pé ibi tí kò yẹ ni ẹ̀rí ọkàn wọn ń darí wọn sí.

4. Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá fẹ́ kí ẹ̀rí ọkàn wa máa ṣiṣẹ́ dáadáa?

4 Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá fẹ́ kí ẹ̀rí ọkàn wa máa ṣiṣẹ́ dáadáa? Àwọn òfin àtàwọn ìlànà tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run “ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, fún fífi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, fún mímú àwọn nǹkan tọ́, fún bíbániwí nínú òdodo.” (2 Tím. 3:16) Torí náà, a gbọ́dọ̀ máa fara balẹ̀ ka Bíbélì déédéé, ká máa ṣàṣàrò lórí ohun tá a kà, ká sì máa fi àwọn ẹ̀kọ́ inú rẹ̀ sílò. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ṣe là ń kọ́ ẹ̀rí ọkàn wa kó lè máa tọ́ wa sọ́nà, ká sì lè máa fojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan wò ó. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká jíròrò bá a ṣe lè fi àwọn òfin àti ìlànà Jèhófà kọ́ ẹ̀rí ọkàn wa.

JẸ́ KÍ ÀWỌN ÒFIN ỌLỌ́RUN MÁA DARÍ RẸ

5, 6. Báwo làwọn òfin Jèhófà ṣe ń ṣe wá láǹfààní?

5 Kí àwọn òfin Jèhófà tó lè ṣe wá láǹfààní, ó yẹ ká máa kà wọ́n, ká sì lóye wọn. Ìyẹn nìkan kọ́ o, a tún gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ àwọn òfin Jèhófà, ká sì mọyì wọn. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Ẹ kórìíra ohun búburú, kí ẹ sì nífẹ̀ẹ́ ohun rere.” (Ámósì 5:15) Báwo la ṣe lè ṣe é? Ọ̀nà kan tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ká kọ́ bá a ṣe lè máa fi ojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan wò ó. Bí àpẹẹrẹ: Ká sọ pé o kì í rí oorun sùn dáadáa, o wá lọ rí dókítà. Dókítà wá ka àwọn oúnjẹ aṣaralóore tó yẹ kó o máa jẹ, ó ní kó o máa ṣe eré ìdárayá, kó o sì ṣe àwọn àyípadà kan. Nígbà tó o ṣe àwọn nǹkan yẹn, o bẹ̀rẹ̀ sí í rí oorun sùn. Ó dájú pé inú rẹ máa dùn gan-an, wàá sì mọyì ohun tí dókítà náà ṣe fún ẹ.

6 Lọ́nà kan náà, àwọn òfin tí Ẹlẹ́dàá fún wa máa ń jẹ́ kí ìgbésí ayé wa nítumọ̀, ó sì ń dáàbò bò wá ká má bàa kó sí páńpẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ ká sì jìyà àbájáde rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ẹ ronú nípa àǹfààní tó wà nínú pípa òfin Ọlọ́run mọ́ tó bá dọ̀rọ̀ kéèyàn máa gbèrò ibi, irọ́ pípa, olè jíjà, ìṣekúṣe, ìwà ipá àti ìbẹ́mìílò. (Ka Òwe 6:​16-19; Ìṣí. 21:8) Nígbà táwa náà bá ń rí àǹfààní tó wà nínú pípa òfin Ọlọ́run mọ́, ìyẹn á jẹ́ ká túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ká sì mọyì àwọn òfin tó fún wa.

7. Tá a bá ń ka àwọn ìtàn inú Bíbélì, tá a sì ń ronú lórí wọn, àǹfààní wo ló máa ṣe wá?

7 Kò dìgbà táwa fúnra wa bá jìyà ká tó mọ̀ pé àbámọ̀ ló máa ń gbẹ̀yìn ẹ̀ téèyàn bá rú òfin Ọlọ́run. A lè kẹ́kọ̀ọ́ látinú àṣìṣe àwọn tí Bíbélì sọ̀rọ̀ wọn, ó ṣe tán, wọ́n ní àgbà tó jìn sí kòtò, ó kọ́ ará yòókù lọ́gbọ́n. Bí àpẹẹrẹ, Òwe 1:5 sọ pé: “Ọlọ́gbọ́n yóò fetí sílẹ̀, yóò sì gba ìtọ́ni púpọ̀ sí i.” Ọ̀dọ́ Jèhófà la ti lè rí ìtọ́ni tó dáa jù lọ, a sì lè rí àwọn ìtọ́ni yìí tá a bá ń ka àwọn ìtàn inú Bíbélì, tá a sì ń ronú lórí àwọn ẹ̀kọ́ tí wọ́n kọ́ wa. Bí àpẹẹrẹ, ronú nípa ìyà tí Ọba Dáfídì jẹ àti ẹ̀dùn ọkàn tó ní lẹ́yìn tó rú òfin Jèhófà tó sì ṣe panṣágà pẹ̀lú Bátí-ṣébà. (2 Sám. 12:​7-14) Bá a ṣe ń ronú lórí ìtàn yìí, a lè bi ara wa pé: ‘Kí ló yẹ kí Ọba Dáfídì ti ṣe kó má bàa kó sínú wàhálà yìí? Témi náà bá kojú irú àdánwò yìí, kí ni màá ṣe? Ṣé màá ṣe bíi Jósẹ́fù kí n sì sá fún ẹ̀ṣẹ̀, àbí màá ṣe bíi ti Dáfídì?’ (Jẹ́n. 39:​11-15) Tá a bá ń ronú lórí àbámọ̀ tó máa ń gbẹ̀yìn ẹ̀ṣẹ̀, á jẹ́ kí ìpinnu wa láti “kórìíra ohun búburú” túbọ̀ lágbára.

8, 9. (a) Iṣẹ́ wo ni ẹ̀rí ọkàn wa máa ń ṣe? (b) Kí ni àwọn ìlànà Bíbélì máa ń ṣe fún ẹ̀rí ọkàn wa?

8 A máa ń sapá gan-an láti yẹra fún àwọn nǹkan tí Ọlọ́run kórìíra. Àmọ́ àwọn ipò míì máa ń yọjú tó jẹ́ pé Bíbélì ò sọ ohun tó yẹ ká ṣe ní pàtó. Ní irú àwọn àsìkò bẹ́ẹ̀, báwo la ṣe lè mọ ohun tó yẹ ká ṣe ká lè múnú Ọlọ́run dùn? Ẹ̀rí ọkàn tá a fi Bíbélì kọ́ ló máa ràn wá lọ́wọ́.

9 Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, ìdí nìyẹn tó fi fún wa láwọn ìlànà tá a lè fi kọ́ ẹ̀rí ọkàn wa. Jèhófà sọ pé: “Èmi, Jèhófà, ni Ọlọ́run rẹ, Ẹni tí ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní, Ẹni tí ń mú kí o tọ ọ̀nà tí ó yẹ kí o máa rìn.” (Aísá. 48:​17, 18) Tá a bá ń ronú jinlẹ̀ lórí àwọn ìlànà Bíbélì, à ń fi Bíbélì kọ́ ẹ̀rí ọkàn wa nìyẹn. Èyí á sì jẹ́ ká lè ṣe àwọn ìpinnu tó tọ́.

JẸ́ KÍ ÀWỌN ÌLÀNÀ ỌLỌ́RUN MÁA TỌ́ Ẹ SỌ́NÀ

10. Kí ni ìlànà, báwo sì ni Jésù ṣe lò ó láti kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́?

10 Ìlànà ni òótọ́ ọ̀rọ̀ tó máa ń mú ká ronú lọ́nà tó tọ́, ká lè ṣèpinnu tó dáa. Àwọn ìlànà tí Jèhófà fún wa máa ń jẹ́ ká mọ bó ṣe ń ronú àti ìdí tó fi fún wa láwọn òfin kan. Nígbà tí Jésù wà láyé, ó kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láwọn ìlànà kan tó jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ó yẹ kí wọ́n yẹra fún àwọn èrò àti ìwà tó lè mú kéèyàn kó sí páńpẹ́ ẹ̀ṣẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ó sọ pé ìkórìíra lè mú kẹ́nì kan hùwà ipá, èròkerò sì lè mú kéèyàn ṣèṣekúṣe. (Mát. 5:​21, 22, 27, 28) Tá a bá fẹ́ kí ẹ̀rí ọkàn wa máa ṣiṣẹ́ dáadáa, a gbọ́dọ̀ jẹ́ kí àwọn ìlànà Jèhófà máa darí wa ká lè mú ìyìn àti ògo wa fún Ọlọ́run.​—1 Kọ́r. 10:31.

Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú rẹ̀ máa ń gba tàwọn míì rò (Wo ìpínrọ̀ 11 àti 12)

11. Ọ̀nà wo ni ẹ̀rí ọkàn wa lè gbà yàtọ̀ síra?

11 Láwọn ìgbà míì, àwọn Kristẹni méjì tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn lè ṣèpinnu tó yàtọ̀ síra lórí àwọn ọ̀rọ̀ kan. Àpẹẹrẹ kan ni ọ̀rọ̀ ọtí mímu. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì ò dẹ́bi fún mímu ọtí níwọ̀nba, àmọ́ ó kìlọ̀ pé a ò gbọ́dọ̀ mutí lámujù tàbí ká mu àmupara. (Òwe 20:1; 1 Tím. 3:8) Ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé kò sí àwọn ìlànà míì tó yẹ kí Kristẹni kan ronú lé tó bá fẹ́ mutí kódà tó bá jẹ́ pé ìwọ̀nba ló fẹ́ mu? Rárá o. Ìdí ni pé tí ẹ̀rí ọkàn ẹnì kan bá tiẹ̀ gbà á láyè láti mutí, ó ṣì gbọ́dọ̀ ronú nípa bí ìpinnu rẹ̀ ṣe lè ṣàkóbá fún ẹ̀rí ọkàn àwọn míì.

12. Báwo ni ọ̀rọ̀ tó wà nínú Róòmù 14:21 ṣe máa mú ká gba tàwọn míì rò tá a bá ń ṣèpinnu?

12 Pọ́ọ̀lù jẹ́ kó ṣe kedere pé a gbọ́dọ̀ máa gba tàwọn míì rò tá a bá ń ṣèpinnu, ó ní: “Ó dára láti má ṣe jẹ ẹran tàbí mú wáìnì tàbí ṣe ohunkóhun tí yóò mú arákùnrin rẹ kọsẹ̀.” (Róòmù 14:21) Torí náà, tá a bá mọ̀ pé arákùnrin kan lè kọsẹ̀ tá a bá mu ọtí, ǹjẹ́ a lè pinnu pé a ò ní mu ọtí lásìkò yẹn ká má bàa mú arákùnrin náà kọsẹ̀? Ó dájú pé àá ṣe bẹ́ẹ̀. Ọ̀mùtí paraku làwọn kan kí wọ́n tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, àmọ́ ní báyìí wọ́n ti pinnu pé àwọn ò ní fẹnu kan ọtí mọ́. Ó dájú pé a ò ní fẹ́ ṣe ohun táá mú kí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ pa dà sídìí ìwà tó lè ṣàkóbá fún wọn. (1 Kọ́r. 6:​9, 10) Torí náà, kò ní dáa ká máa rọ àwọn míì pé kí wọ́n mutí lẹ́yìn tí wọ́n bá ti sọ pé àwọn ò fẹ́.

13. Kí ni Tímótì ṣe kó lè wàásù fáwọn Júù, kí la sì rí kọ́?

13 Nígbà tí Tímótì wà ní nǹkan bí ọmọ ogún ọdún, ó gbà láti dádọ̀dọ́ bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìrora tí ìyẹn máa fà kì í ṣe kékeré. Ó ṣe bẹ́ẹ̀ torí ó mọ̀ pé àwọn Júù fọwọ́ pàtàkì mú ìdádọ̀dọ́, kò sì fẹ́ mú wọn kọsẹ̀. Bíi ti Pọ́ọ̀lù, òun náà gba tàwọn míì rò. (Ìṣe 16:3; 1 Kọ́r. 9:​19-23) Ṣé ìwọ náà lè ṣe bíi Tímótì kó o yááfì àwọn nǹkan kan torí ẹ̀rí ọkàn àwọn míì?

“TẸ̀ SÍWÁJÚ SÍ ÌDÀGBÀDÉNÚ”

14, 15. (a) Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá fẹ́ kí òtítọ́ túbọ̀ jinlẹ̀ lọ́kàn wa? (b) Ki ló yẹ ká máa ṣe tá a bá fẹ́ fi hàn pé òtítọ́ jinlẹ̀ lọ́kàn wa?

14 Kò yẹ kó jẹ́ “àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ nípa Kristi” nìkan la ṣì máa mọ̀, kàkà bẹ́ẹ̀ ó yẹ ká “tẹ̀ síwájú sí ìdàgbàdénú,” ìyẹn ni pé ká jẹ́ kí òtítọ́ túbọ̀ jinlẹ̀ lọ́kàn wa. (Héb. 6:1) Àmọ́, ti pé a ti pẹ́ nínú òtítọ́ kò túmọ̀ sí pé òtítọ́ máa jinlẹ̀ lọ́kàn wa, a gbọ́dọ̀ máa “tẹ̀ síwájú.” Kí òtítọ́ tó lè jinlẹ̀ lọ́kàn wa, ìmọ̀ àti òye tá a ní gbọ́dọ̀ máa pọ̀ sí i. Ìdí nìyẹn tí ètò Ọlọ́run fi ń rọ̀ wá látìgbàdégbà pé ká máa ka Bíbélì lójoojúmọ́. (Sm. 1:​1-3) Ṣé o ti pinnu láti máa ṣe bẹ́ẹ̀? Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wàá túbọ̀ lóye àwọn òfin àtàwọn ìlànà Jèhófà, ìmọ̀ rẹ á sì pọ̀ sí i.

15 Òfin tó ṣe pàtàkì jù lọ táwa Kristẹni ń tẹ̀ lé ni òfin ìfẹ́. Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.” (Jòh. 13:35) Jákọ́bù àbúrò Jésù pe ìfẹ́ ní “ọba òfin.” (Ják. 2:8) Pọ́ọ̀lù náà sọ pé: “Ìfẹ́ ni ìmúṣẹ òfin.” (Róòmù 13:10) Kò yà wá lẹ́nu pé ìfẹ́ ṣe pàtàkì gan-an torí Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” (1 Jòh. 4:8) Ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí wa kì í ṣe ìfẹ́ orí ahọ́n lásán. Jòhánù sọ pé: “Nípa èyí ni a fi ìfẹ́ Ọlọ́run hàn kedere nínú ọ̀ràn tiwa, nítorí Ọlọ́run rán Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo jáde sínú ayé kí a lè jèrè ìyè nípasẹ̀ rẹ̀.” (1 Jòh. 4:9) Ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní ló mú kó rán Jésù wá sáyé. Torí náà, tá a bá ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ àti pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa àtàwọn míì, á jẹ́ pé òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wa nìyẹn.​—Mát. 22:​37-39.

Tá a bá ń ronú lórí àwọn ìlànà Bíbélì, ẹ̀rí ọkàn wa á túbọ̀ máa ṣiṣẹ́ dáadáa (Wo ìpínrọ̀ 16)

16. Kí nìdí tá a fi túbọ̀ máa mọyì àwọn ìlànà Jèhófà bí òtítọ́ ṣe ń jinlẹ̀ lọ́kàn wa sí i?

16 Bí òtítọ́ ṣe ń jinlẹ̀ lọ́kàn wa, àá túbọ̀ máa mọyì àwọn ìlànà Jèhófà. Ìdí ni pé ohun kan pàtó ni òfin máa ń dá lé, àmọ́ ìlànà gbòòrò gan-an, a sì lè lò ó ní onírúurú ọ̀nà. Bí àpẹẹrẹ, ọmọ kékeré kan lè má mọ̀ pé ó léwu téèyàn bá ń kó ẹgbẹ́kẹ́gbẹ́, torí náà àwọn òbí rẹ̀ máa fún un lófin kó má bàa kó sí wàhálà. (1 Kọ́r. 15:33) Ṣùgbọ́n bí ọmọ náà ṣe ń dàgbà tó sì ń gbọ́n sí i, á bẹ̀rẹ̀ sí í ronú lórí àwọn ìlànà Bíbélì. Tó bá yà, àwọn ìlànà yìí á jẹ́ kó lè fọgbọ́n yan àwọn táá máa bá kẹ́gbẹ́. (Ka 1 Kọ́ríńtì 13:11; 14:20.) Torí náà, tá a bá ń ronú lórí àwọn ìlànà Bíbélì, ẹ̀rí ọkàn wa á túbọ̀ máa ṣiṣẹ́ dáadáa, ìyẹn á sì jẹ́ ká máa ṣe àwọn ìpinnu tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu.

17. Ǹjẹ́ a ní àwọn nǹkan tá a nílò ká lè ṣèpinnu tó tọ́? Kí nìdí tó o fi gbà bẹ́ẹ̀?

17 Ǹjẹ́ a ní gbogbo ohun tá a nílò ká lè ṣèpinnu tó tọ́ ká sì múnú Jèhófà dùn? Bẹ́ẹ̀ ni. Àwọn òfin àtàwọn ìlànà tó wà nínú Bíbélì máa jẹ́ ká ‘pegedé ní kíkún, ká sì gbára dì pátápátá fún iṣẹ́ rere gbogbo.’ (2 Tím. 3:​16, 17) Torí náà, máa ronú lórí àwọn ìlànà tó wà nínú Ìwé Mímọ́ kó o lè ‘fòye mọ ohun tí ìfẹ́ Jèhófà jẹ́.’ (Éfé. 5:17) Máa lo àwọn ohun èlò ìwádìí tí ètò Ọlọ́run ti pèsè irú bí ìwé atọ́ka Watch Tower Publications Index, Ìwé Ìwádìí fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, Watchtower Library, Àká Ìwé Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì àti JW Library. Tá a bá ń lo àwọn ohun èlò ìwádìí yìí nígbà ìjọsìn ìdílé àti ìdákẹ́kọ̀ọ́, àá túbọ̀ ní òye kíkún nípa àwọn ìlànà Jèhófà.

BÍ Ẹ̀RÍ ỌKÀN TÁ A FI BÍBÉLÌ KỌ́ ṢE Ń ṢE WÁ LÁǸFÀÀNÍ

18. Àǹfààní wo la máa rí tá a bá ń pa àwọn òfin àti ìlànà Jèhófà mọ́?

18 Ọ̀pọ̀ ìbùkún la máa rí tá a bá ń pa àwọn òfin àti ìlànà Jèhófà mọ́. Sáàmù 119:​97-100 sọ pé: “Mo mà nífẹ̀ẹ́ òfin rẹ o! Òun ni mo fi ń ṣe ìdàníyàn mi láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀. Àṣẹ rẹ mú mi gbọ́n ju àwọn ọ̀tá mi, nítorí pé tèmi ni ó jẹ́ fún àkókò tí ó lọ kánrin. Mo ti wá ní ìjìnlẹ̀ òye ju gbogbo àwọn olùkọ́ mi, nítorí pé àwọn ìránnilétí rẹ ni ìdàníyàn mi. Èmi ń fi òye tí ó ju ti àwọn àgbà hùwà, nítorí pé mo ti pa àwọn àṣẹ ìtọ́ni rẹ mọ́.” Tá a bá ń fi àwọn òfin àti ìlànà Jèhófà ṣe “ìdàníyàn” wa, tá à ń ronú jinlẹ̀ lórí wọn, àá túbọ̀ ní òye, àá sì máa fọgbọ́n ṣèpinnu. Tá a bá sì ń fi àwọn òfin àti ìlànà Ọlọ́run kọ́ ẹ̀rí ọkàn wa, a máa “dé orí ìwọ̀n ìdàgbàsókè tí ó jẹ́ ti ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Kristi.”​—Éfé. 4:13.