Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Rántí?

Ǹjẹ́ O Rántí?

Ṣó o gbádùn kíka àwọn Ilé Ìṣọ́ tó jáde lẹ́nu àìpẹ́ yìí? Wò ó bóyá wàá lè dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

Àwọn nǹkan mẹ́rin wo ló máa jẹ́ ká túbọ̀ mọ orin kọ?

Ó yẹ ká gbé ìwé orin wa sókè, ìyẹn á jẹ́ ká lè dúró dáadáa. Ká mí kanlẹ̀. Ó yẹ ká la ẹnu wa dáadáa, ká sì kọrin sókè, ìyẹn á jẹ́ kí ohùn wa túbọ̀ ròkè.​—w17.11, ojú ìwé 5.

Kí ló wúni lórí nípa ibi tí àwọn ìlú ààbò náà wà àti àwọn ọ̀nà téèyàn máa gbà débẹ̀?

Àwọn ìlú ààbò mẹ́fà náà wà káàkiri ilẹ̀ náà, àwọn ọ̀nà téèyàn lè gbà débẹ̀ sì dáa. Èyí máa ń jẹ́ kó rọrùn fẹ́nì kan láti tètè débẹ̀.​—w17.11, ojú ìwé 14.

Kí nìdí tí ẹ̀bùn ìràpadà tí Ọlọ́run fún wa nípasẹ̀ Jésù fi jẹ́ ẹ̀bùn tó ju gbogbo ẹ̀bùn lọ?

Ó mú ká láǹfààní láti wà láàyè títí láé, ó sì mú ká bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Torí pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ àwa àtọmọdọ́mọ Ádámù, ó pèsè ìràpadà Jésù fún wa nígbà tá a ṣì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀.​—wp17.6, ojú ìwé 6 àti 7.

Báwo la ṣe mọ̀ pé àjíǹde Jésù ni Sáàmù 118:22 ń tọ́ka sí?

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù ni Mèsáyà, síbẹ̀ wọ́n kọ ọ́ sílẹ̀, wọ́n sì pa á. Kí Jésù tó lè di “olórí igun ilé,” ó gbọ́dọ̀ jíǹde.​—w17.12, ojú ìwé 9 àti 10.

Ṣé ìgbà gbogbo ni ìlà ìdílé tí Mèsáyà ti wá máa ń gba ọ̀dọ̀ àkọ́bí ọkùnrin kọjá?

Nígbà míì, ìlà ìdílé Jésù máa ń wá látọ̀dọ̀ àkọ́bí, àmọ́ ọ̀rọ̀ kì í fìgbà gbogbo rí bẹ́ẹ̀. Dáfídì kì í ṣe àkọ́bí Jésè, síbẹ̀ ìlà ìdílé Dáfídì ni Mèsáyà ti wá.​—w17.12, ojú ìwé 14 àti 15.

Àwọn ìlànà wo ló wà nínú Bíbélì tó kan ọ̀rọ̀ ìṣègùn?

Lábẹ́ Òfin Mósè, wọ́n gbọ́dọ̀ ya àwọn tó ní irú àrùn kan sọ́tọ̀. Wọ́n gbọ́dọ̀ fọ ọwọ́ wọn lẹ́yìn tí wọ́n bá fọwọ́ kan òkú. Òfin náà tún sọ pé wọ́n gbọ́dọ̀ máa bo ìgbọ̀nsẹ̀ wọn mọ́lẹ̀. Ọjọ́ kẹjọ ni wọ́n gbọ́dọ̀ dádọ̀dọ́ fún ọmọ tuntun torí pé ìgbà yẹn ni ẹ̀jẹ̀ á lè tètè dá lára rẹ̀ bó ṣe yẹ.​—wp18.1, ojú ìwé 7.

Kí nìdí tó fi yẹ kí Kristẹni kan nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀ déwọ̀n àyè kan?

A gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò wa gẹ́gẹ́ bí ara wa. (Máàkù 12:31) Bákan náà, àwọn ọkọ gbọ́dọ̀ “nífẹ̀ẹ́ àwọn aya wọn gẹ́gẹ́ bí ara àwọn fúnra wọn.” (Éfé. 5:28) Àmọ́ téèyàn ò bá ṣọ́ra, ó lè nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀ ju bó ṣe yẹ lọ.​—w18.01, ojú ìwé 23.

Àwọn nǹkan wo la lè ṣe ká lè túbọ̀ dẹni tẹ̀mí?

Máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé, kó o sì máa ṣàṣàrò lórí rẹ̀. Lẹ́yìn náà, fi àwọn nǹkan tó o kọ́ sílò. Jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ máa darí rẹ, kó o sì máa gba ìmọ̀ràn táwọn míì bá fún ẹ.​—w18.02, ojú ìwé 26.

Kí nìdí táwọn awòràwọ̀ àtàwọn woṣẹ́woṣẹ́ kò fi lè mọ ọjọ́ ọ̀la?

Ọ̀pọ̀ ìdí ló wà, àmọ́ èyí tó ṣe pàtàkì jù ni pé Bíbélì dẹ́bi fún àṣà méjèèjì.​—wp18.2, ojú ìwé 4 àti 5.

Kí ló yẹ ká fi sọ́kàn tẹ́nì kan bá fẹ́ gbà wá lálejò?

Tá a bá ti ṣàdéhùn pé à ń bọ̀, kò yẹ ká yẹ àdéhùn náà. (Sm. 15:4) Ká má ṣe fọwọ́ rọ́ àdéhùn náà tì lórí ohun tí kò tó nǹkan. Ó ṣeé ṣe kẹ́ni tó fẹ́ gbà wá lálejò ti forí ṣe fọrùn ṣe kó lè pèsè nǹkan sílẹ̀ fún wa.​—w18.03, ojú ìwé 18.

Kí làwọn ọkùnrin tá a yàn sípò lè kọ́ lára Tímótì?

Tímótì nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn dénú, nǹkan tẹ̀mí ló sì gbà á lọ́kàn. Ó ṣiṣẹ́ kára lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, ó sì fi àwọn nǹkan tó ń kọ́ sílò. Yàtọ̀ síyẹn, ó túbọ̀ ń dá ara rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́, ó sì gbára lé ẹ̀mí Jèhófà. Ó yẹ kí gbogbo wa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Tímótì, pàápàá àwọn alàgbà.​—w18.04, ojú ìwé 13 àti 14.