Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ó Pàdánù Ojú Rere Ọlọ́run

Ó Pàdánù Ojú Rere Ọlọ́run

GBOGBO àwa tá à ń sin Jèhófà la fẹ́ rí ojú rere rẹ̀, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Àmọ́ àwọn wo ni Jèhófà máa fi ojú rere hàn sí táá sì bù kún? Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, àwọn kan rí ojú rere Jèhófà bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti fìgbà kan rí dá àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì. Àwọn míì sì láwọn ànímọ́ tó dáa, síbẹ̀ wọn ò rí ojú rere Jèhófà. Èyí lè mú ká máa ronú pé, “Kí ni Jèhófà ń retí lọ́wọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan wa gan-an?” Àpẹẹrẹ Rèhóbóámù tó jẹ́ ọba Júdà máa jẹ́ ká rí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí.

Ó ṢÈPINNU TÍ KÒ BỌ́GBỌ́N MU

Sólómọ́nì tó jẹ́ bàbá Rèhóbóámù ṣàkóso Ísírẹ́lì fún ogójì [40] ọdún. (1 Ọba 11:42) Àmọ́ nígbà tí Sólómọ́nì kú lọ́dún 997 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Rèhóbóámù rìnrìn-àjò láti Jerúsálẹ́mù lọ sí Ṣékémù kó lè jọba. (2 Kíró. 10:1) Ṣé ó ṣeé ṣe kẹ́rù máa ba Rèhóbóámù pé bóyá lòun á lè ṣàkóso bíi ti Sólómọ́nì tí ọgbọ́n rẹ̀ tayọ? Rèhóbóámù ò mọ̀ pé bóun bá ṣe dórí àlééfà lọ̀rọ̀ kan tó gbẹgẹ́ máa jẹyọ, ọ̀rọ̀ ọ̀hún sì máa gba kó fọgbọ́n yanjú ẹ̀.

Ó ṣeé ṣe kí Rèhóbóámù rí i pé inú àwọn aráàlú ò dùn, wọ́n sì ń kùn lábẹ́lẹ̀. Nígbà tó yá, àwọn èèyàn náà rán àwọn aṣojú sí Rèhóbóámù kí wọ́n lè sọ ohun tó ń jẹ wọ́n lọ́kàn. Wọ́n sọ fún un pé: “Baba rẹ, ní tirẹ̀, mú kí àjàgà wa nira; wàyí o, mú kí iṣẹ́ ìsìn nínira ti baba rẹ àti àjàgà wíwúwo tí ó fi bọ̀ wá lọ́rùn fúyẹ́, àwa yóò sì máa sìn ọ́.”​—2 Kíró. 10:3, 4.

Ọ̀rọ̀ ńlá ló délẹ̀ fún Rèhóbóámù yìí o! Tó bá ṣe ohun táwọn èèyàn náà fẹ́, á jẹ́ pé owó díẹ̀ láá máa wọlé fún òun, ìdílé rẹ̀ àtàwọn tí wọ́n jọ ń ṣàkóso torí pé wọn ò ní lè béèrè nǹkan púpọ̀ lọ́wọ́ àwọn èèyàn náà. Àmọ́ tí kò bá ṣe ohun táwọn èèyàn náà fẹ́, wọ́n lè ṣọ̀tẹ̀, kí wọ́n sì kọ̀ ọ́ lọ́ba. Kí ló máa wá ṣe? Rèhóbóámù kọ́kọ́ lọ sọ́dọ̀ àwọn àgbààgbà tó jẹ́ agbaninímọ̀ràn Sólómọ́nì, kí wọ́n lè fún un nímọ̀ràn. Àmọ́ ó tún lọ gbàmọ̀ràn lọ́dọ̀ àwọn ọ̀dọ́kùnrin tí wọ́n jọ jẹ́ ẹgbẹ́. Dípò kó tẹ̀ lé ìmọ̀ràn àwọn àgbààgbà, ìmọ̀ràn táwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ fún un ló tẹ̀ lé. Ó wá pinnu láti fi kún ìnira àwọn èèyàn náà, ó sọ fún wọn pé: “Èmi yóò mú kí àjàgà yín túbọ̀ wúwo sí i, àti pé èmi, ní tèmi, yóò fi kún un. Baba mi, ní tirẹ̀, fi pàṣán nà yín, ṣùgbọ́n èmi, ní tèmi, yóò lo bílálà oníkókó.”​—2 Kíró. 10:6-14.

Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ nínú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí? Ìtàn yìí jẹ́ ká rí i pé ìwà ọgbọ́n ni tá a bá ń gbàmọ̀ràn lọ́dọ̀ àwọn àgbà tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn. Torí pé wọ́n nírìírí jù wá lọ, ó ṣeé ṣe kí wọ́n mọ ohun tó lè tẹ̀yìn ọ̀rọ̀ kan yọ, kí wọ́n sì fún wa ní ìmọ̀ràn tó máa ṣe wá láǹfààní.​—Jóòbù 12:12.

“WỌ́N ṢÈGBỌRÀN SÍ Ọ̀RỌ̀ JÈHÓFÀ”

Inú bí Rèhóbóámù nígbà táwọn èèyàn náà ṣọ̀tẹ̀ sí i, ló bá kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jọ. Àmọ́ Jèhófà rán wòlíì Ṣemáyà sí i pé: “Ẹ kò gbọ́dọ̀ gòkè lọ bá àwọn arákùnrin yín, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, jà. Kí olúkúlùkù padà sí ilé rẹ̀, nítorí èmi ni ó mú kí nǹkan yìí ṣẹlẹ̀.”​—1 Ọba 12:21-24. *

Kó má jagun kẹ̀? Ẹ wo bí ọ̀rọ̀ yìí ṣe máa rí lára Rèhóbóámù. Irú ojú wo làwọn èèyàn á fi máa wo ọba tó ti halẹ̀ pé òun á fi “bílálà oníkókó” na àwọn èèyàn, àmọ́ tí ò rí nǹkan ṣe sáwọn tó ṣọ̀tẹ̀ sí i? (Fi wé 2 Kíróníkà 13:7.) Síbẹ̀, Rèhóbóámù àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ “ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ Jèhófà, wọ́n sì padà sí ilé ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Jèhófà.”

Kí la rí kọ́ nínú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí? Ó yẹ ká máa ṣègbọràn sí Jèhófà kódà táwọn èèyàn bá ń fi wá ṣe yẹ̀yẹ́. Tá a bá ń ṣègbọràn sí Jèhófà, a máa rí ojú rere rẹ̀, ó sì máa bù kún wa.​—Diu. 28:2.

Kí ni ohun tí Rèhóbóámù ṣe yìí yọrí sí? Torí pé ó ṣègbọràn ti kò sì jagun, ó ráyè gbájú mọ́ nǹkan míì. Ó kọ́ àwọn ìlú ńlá sáwọn àgbègbè Júdà àti Bẹ́ńjámínì tó wà lábẹ́ àkóso rẹ̀. Ó sì mú kí ọ̀pọ̀ àwọn ìlú yìí lágbára “dé ìwọ̀n púpọ̀ gan-an.” (2 Kíró. 11:5-12) Èyí tó ṣe pàtàkì jù ni pé, ó pa àwọn òfin Jèhófà mọ́ lásìkò yẹn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìbọ̀rìṣà ni Jèróbóámù ń gbé lárugẹ ní ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá tó ti ń ṣàkóso, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ abẹ́ rẹ̀ ni wọ́n ṣì ń lọ sí Jerúsálẹ́mù kí wọ́n lè máa ṣe ìjọsìn tòótọ́. Wọ́n sì ń tipa bẹ́ẹ̀ “fìdí ipò Rèhóbóámù” múlẹ̀. (2 Kíró. 11:​16, 17) Torí pé Rèhóbóámù ṣègbọràn, ìjọba rẹ̀ túbọ̀ fìdí múlẹ̀ dáadáa.

Ó DẸ́ṢẸ̀, ÀMỌ́ Ó RONÚ PÌWÀ DÀ DÉWỌ̀N ÀYÈ KAN

Lẹ́yìn tí ìjọba rẹ̀ fìdí múlẹ̀ dáadáa, Rèhóbóámù ṣe ohun kan tó yani lẹ́nu. Ṣe ló fi Jèhófà sílẹ̀ tó sì bẹ̀rẹ̀ sí í bọ̀rìṣà! Kí ló mú kó ṣe bẹ́ẹ̀? Ṣé ìyá rẹ̀ tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Ámónì ló sún un débẹ̀? (1 Ọba 14:21) Èyí ó wù kó jẹ́, ohun tó ṣe mú kí àwọn èèyàn náà bẹ̀rẹ̀ sí í bọ̀rìṣà. Jèhófà wá jẹ́ kí Ṣíṣákì ọba Íjíbítì gba ọ̀pọ̀ àwọn ìlú Júdà láìka bí Rèhóbóámù ṣe mú káwọn ìlú náà lágbára sí.​—1 Ọba 14:22-24; 2 Kíró. 12:1-4.

Ọ̀rọ̀ dójú ẹ̀ nígbà tí Ṣíṣákì kógun dé Jerúsálẹ́mù níbi tí Rèhóbóámù ti ń ṣàkóso. Jèhófà wá rán wòlíì Ṣemáyà sí Rèhóbóámù àtàwọn ọmọ aládé rẹ̀ pé: “Ẹ̀yin, ní tiyín, ti fi mí sílẹ̀, èmi náà, ní tèmi, sì ti fi yín sílẹ̀ sí ọwọ́ Ṣíṣákì.” Kí ni Rèhóbóámù ṣe nígbà tó gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà? Ohun tó ṣe wúni lórí, Bíbélì sọ pé: “Àwọn ọmọ aládé Ísírẹ́lì àti ọba rẹ ara wọn sílẹ̀, wọ́n sì wí pé: ‘Olódodo ni Jèhófà.’ ” Nípa bẹ́ẹ̀, Jèhófà gba Rèhóbóámù sílẹ̀, kò sì jẹ́ kí Jerúsálẹ́mù pa run.​—2 Kíró. 12:5-7, 12.

Lẹ́yìn ìgbà yẹn, Rèhóbóámù ń bá ìṣàkóso rẹ̀ lọ lórí ilẹ̀ Júdà. Kó tó kú, ó fún àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ ní ẹ̀bùn rẹpẹtẹ torí pé kò fẹ́ kí wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí Ábíjà arákùnrin wọn tó máa jọba lẹ́yìn rẹ̀. (2 Kíró. 11:21-23) Rèhóbóámù lo òye àti ọgbọ́n nínú ọ̀rọ̀ yìí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti fìgbà kan rí ṣe ohun tó kù díẹ̀ káàtó.

ÀPẸẸRẸ RERE ÀBÍ BÚBURÚ?

Láìka gbogbo ohun tó ṣe sí, Rèhóbóámù ò rí ojú rere Jèhófà. Nígbà tí Bíbélì máa sọ̀rọ̀ nípa ìṣàkóso rẹ̀, ó ní: “Ó ṣe ohun tí ó burú.” Kí nìdí? Ìdí ni pé ‘kò fi tọkàntọkàn wá Jèhófà.’​—2 Kíró. 12:14.

Rèhóbóámù ò ṣe bíi ti Ọba Dáfídì, kò ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà

Ẹ rò ó wò ná: Àwọn ìgbà kan wà tí Rèhóbóámù ṣègbọràn sí Jèhófà tó sì ṣe àwọn nǹkan tó dáa fáwọn èèyàn Ọlọ́run. Síbẹ̀, kò ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, kò sì wù ú látọkàn láti ṣe ohun tó máa múnú rẹ̀ dùn. Torí náà, ó dẹ́ṣẹ̀, ó sì ń bọ̀rìṣà. O lè wá bi ara rẹ pé: ‘Nígbà tí Rèhóbóámù gba ìbáwí tí Jèhófà fún un, ṣé torí àwọn míì ló fi ṣe bẹ́ẹ̀ àbí ó wù ú pé kó ṣe ohun tó máa múnú Jèhófà dùn?’ (2 Kíró. 11:3, 4; 12:6) Lẹ́yìn tó ti ṣe dáadáa fúngbà díẹ̀, ó pa dà sídìí ìwà burúkú. Ẹ ò rí i pé ó yàtọ̀ pátápátá sí Ọba Dáfídì bàbá-bàbá rẹ̀! Lóòótọ́, àwọn ìgbà kan wà tí Dáfídì ṣàṣìṣe, síbẹ̀ bó ṣe gbé ìgbésí ayé rẹ̀ fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ó fẹ́ràn ìjọsìn mímọ́, ó sì kábàámọ̀ àwọn àṣìṣe tó ṣe.​—1 Ọba 14:8; Sm. 51:1, 17; 63:1.

Ó dájú pé ọ̀pọ̀ nǹkan la lè kọ́ lára Rèhóbóámù. Lóòótọ́, ó dáa téèyàn bá ń pèsè fún ìdílé rẹ̀, tó sì ń sapá láti gbé àwọn nǹkan ribiribi ṣe. Síbẹ̀, ká tó lè rí ojú rere Ọlọ́run, ìjọsìn Jèhófà ló gbọ́dọ̀ gba iwájú láyé wa, a ò sì gbọ́dọ̀ fi Jèhófà sílẹ̀ láé.

Ká tó lè fi ìjọsìn Jèhófà sípò àkọ́kọ́, a gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gan-an. Bó ṣe jẹ́ pé téèyàn bá ń dáná igi tí kò sì fẹ́ kó kú, ó gbọ́dọ̀ máa koná mọ́ ọn, bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ tiwa náà rí. Tá ò bá fẹ́ kí ìfẹ́ tá a ní sí Jèhófà kú, àfi ká máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́, ká máa ṣàṣàrò lórí ohun tá a kà, ká sì máa gbàdúrà nígbà gbogbo. (Sm. 1:2; Róòmù 12:12) Tá a bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, á máa wù wá láti ṣe ohun tínú rẹ̀ dùn sí nígbà gbogbo. Tá a bá sì ṣi ẹsẹ̀ gbé, ìfẹ́ yìí á mú ká ronú pìwà dà látọkàn wá. Ká má ṣe fìwà jọ Rèhóbóámù tó fi Jèhófà sílẹ̀, ẹ jẹ́ ká pinnu pé a ò ní fi Jèhófà sílẹ̀ jálẹ̀ ìgbésí ayé wa.​—Júúdà 20, 21.

^ ìpínrọ̀ 9 Torí pé Sólómọ́nì di aláìṣòótọ́, Ọlọ́run sọ tẹ́lẹ̀ pé ìjọba náà máa pín sí méjì.​—1 Ọba 11:31.