ILÉ ÌṢỌ́—Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ June 2020

Àwọn àpilẹ̀kọ tá a máa kẹ́kọ̀ọ́ láti August 3-30, 2020 ló wà nínú Ilé Ìṣọ́ yìí.

“Kí Orúkọ Rẹ Di Mímọ́”

Àpilẹ̀kọ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ 23: August 3-9, 2020. Ọ̀rọ̀ wo ló ṣe pàtàkì jù lọ sáwa èèyàn àtàwọn áńgẹ́lì? Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀, báwo ló sì ṣe kàn wá? Tá a bá lóye ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yìí àtàwọn ìbéèrè mí ì tó jẹ mọ́ ọn, á jẹ́ kí àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà túbọ̀ lágbára.

“Fún Mi Ní Ọkàn Tó Pa Pọ̀ Kí N Lè Máa Bẹ̀rù Orúkọ Rẹ”

Àpilẹ̀kọ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ 24: August 10-16, 2020. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò Sáàmù 86:​11, 12 tó jẹ́ apá kan àdúrà tí Ọba Dáfídì gbà. Kí ló túmọ̀ sí pé kéèyàn bẹ̀rù orúkọ Jèhófà? Kí nìdí tó fi yẹ ká bẹ̀rù orúkọ Jèhófà? Báwo ni ìbẹ̀rù Jèhófà ò ṣe ní jẹ́ ká kó sínú ìdẹwò?

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ṣé àwọn ànímọ́ mẹ́sàn-án tó wà nínú Gálátíà 5:​22, 23 nìkan ni “èso ti ẹ̀mí”?

“Èmi Fúnra Mi Yóò Wá Àwọn Àgùntàn Mi”

Àpilẹ̀kọ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ 25: August 17-23, 2020. Àwọn kan tí wọ́n ti ń fòótọ́ ọkàn sin Jèhófà fún ọ̀pọ̀ ọdún ti ń rẹ̀wẹ̀sì báyìí, kódà àwọn mí ì ti fi ètò Ọlọ́run sílẹ̀. Kí ló fà á? Báwo lọ̀rọ̀ wọn ṣe rí lára Jèhófà? A máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ yìí. A tún máa sọ̀rọ̀ nípa bí Jèhófà ṣe ran àwọn olóòótọ́ kan lọ́wọ́ láyé àtijọ́ nígbà tí wọ́n rẹ̀wẹ̀sì, àá sì rí ohun tíyẹn kọ́ wa.

“Ẹ Pa Dà Sọ́dọ̀ Mi”

Àpilẹ̀kọ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ 26: August 24-30, 2020. Jèhófà fẹ́ káwọn tó ti di aláìṣiṣẹ́mọ́ pa dà sọ́dọ̀ òun. Ìdí nìyẹn tó fi ń rọ̀ wọ́n pé: “Ẹ pa dà sọ́dọ̀ mi.” Ǹjẹ́ ohunkóhun wà tá a lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́? Bẹ́ẹ̀ ni! Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò àwọn ohun tá a lè ṣe kí wọ́n lè pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà.