ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 26
“Ẹ Pa Dà Sọ́dọ̀ Mi”
“Ẹ pa dà sọ́dọ̀ mi, èmi yóò sì pa dà sọ́dọ̀ yín.”—MÁL. 3:7.
ORIN 102 “Ran Àwọn Aláìlera Lọ́wọ́”
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *
1. Báwo ló ṣe máa ń rí lára Jèhófà tí àgùntàn kan tó sọ nù bá pa dà sínú agbo?
BÁ A ṣe jíròrò rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, Jèhófà fi ara rẹ̀ wé olùṣọ́ àgùntàn tó nífẹ̀ẹ́ àwọn àgùntàn rẹ̀ tó sì ń bójú tó ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn. Bákan náà, ó máa ń wá àgùntàn tó bá sọ nù, kó lè pa dà sínú agbo. Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n fi í sílẹ̀ pé: “Ẹ pa dà sọ́dọ̀ mi, èmi yóò sì pa dà sọ́dọ̀ yín.” Bí ọ̀rọ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ṣe rí lára ẹ̀ nígbà yẹn náà ló ṣì rí lónìí, torí ó sọ pé: “Èmi kì í yí pa dà.” (Mál. 3:6, 7) Jésù sọ pé inú Jèhófà àtàwọn áńgẹ́lì máa ń dùn gan-an tí àwọn ìránṣẹ́ Rẹ̀ tó ṣáko lọ bá pa dà sínú agbo, kódà bó tiẹ̀ jẹ́ ọ̀kan péré.—Lúùkù 15:10, 32.
2. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
2 Ẹ jẹ́ ká jíròrò mẹ́ta lára àwọn àpèjúwe tí Jésù lò tó jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè ṣèrànwọ́ fáwọn tó jẹ́ aláìṣiṣẹ́mọ́ kí wọ́n lè pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà. A tún máa jíròrò àwọn ànímọ́ táá jẹ́ ká lè ṣe bẹ́ẹ̀. Àá sì rí ìdí tó fi yẹ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ká lè ran àwọn ará wa yìí lọ́wọ́.
ẸYỌ OWÓ TÓ SỌ NÙ
3-4. Kí nìdí tí obìnrin tí Jésù sọ̀rọ̀ ẹ̀ nínú Lúùkù 15:8-10 fi fara balẹ̀ wá owó rẹ̀ tó sọ nù?
3 Ó gba ọ̀pọ̀ ìsapá ká tó lè rí àwọn aláìṣiṣẹ́mọ́, ká sì mú kí wọ́n pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà. Nínú Ìhìn Rere Lúùkù, Jésù ṣàpèjúwe bí obìnrin kan ṣe wá ẹyọ owó dírákímà rẹ̀ tó sọ nù. Torí pé owó náà ṣeyebíye, ó wá a títí tó fi rí i. Ohun tó ṣe pàtàkì nínú àpèjúwe yìí ni bí obìnrin náà ṣe sapá kó lè rí owó rẹ̀.—Ka Lúùkù 15:8-10.
4 Jésù sọ pé inú obìnrin náà dùn nígbà tó rí owó rẹ̀ tó sọ nù. Nígbà ayé Jésù, àwọn Júù ní àṣà kan. Tí ọmọbìnrin wọn bá ń lọ sílé ọkọ, wọ́n sábà máa ń fún un ní ìdìpọ̀ owó dírákímà mẹ́wàá lọ́jọ́ ìgbéyàwó rẹ̀. Torí náà, ó ṣeé ṣe
kó jẹ́ ọ̀kan lára ìdìpọ̀ yẹn ló sọ nù. Obìnrin náà sì ronú pé ibì kan lowó yẹn máa wà, ó ṣeé ṣe kó ti já bọ́ síbì kan nínú ilé. Ó tan àtùpà rẹ̀ láti wá a, àmọ́ kò rí i. Bóyá àtùpà náà ò mọ́lẹ̀ tó ni kò jẹ́ kó rí ẹyọ owó fàdákà náà. Nígbà tó yá, ó fara balẹ̀ gbá gbogbo inú ilé náà. Lẹ́yìn tó gbá ilẹ̀ náà jọ, ǹjẹ́ ẹ mọ ohun tó rí? Ẹyọ owó fàdákà tó ti ń wá láti ẹ̀ẹ̀kan. Ẹ wo bí inú rẹ̀ ṣe máa dùn tó! Ló bá pe àwọn ọ̀rẹ́ àtàwọn aládùúgbò rẹ̀ pé kí wọ́n bá òun yọ̀.5. Kí nìdí tó fi máa ń gba ọ̀pọ̀ ìsapá ká tó lè rí àwọn aláìṣiṣẹ́mọ́?
5 Àpèjúwe Jésù yìí jẹ́ ká rí i pé tá a bá sọ nǹkan nù, ó máa ń gba ọ̀pọ̀ ìsapá ká tó lè rí i. Lọ́nà kan náà, ó máa ń gba ọ̀pọ̀ ìsapá ká tó lè rí àwọn aláìṣiṣẹ́mọ́. Kí nìdí? Ìdí kan ni pé ó ṣeé ṣe kí ọ̀pọ̀ ọdún ti kọjá táwọn kan ti di aláìṣiṣẹ́mọ́. Wọ́n sì ti lè kó lọ sí agbègbè míì níbi táwọn ará ò ti mọ̀ wọ́n. Àmọ́ ní báyìí, àwọn kan lára wọn lè máa wá bí wọ́n á ṣe pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà. Ó wù wọ́n pé kí wọ́n pa dà máa jọ́sìn Jèhófà pẹ̀lú àwọn ará, àmọ́ wọn ò lè dá a ṣe láìjẹ́ pé a ràn wọ́n lọ́wọ́.
6. Báwo lọ̀rọ̀ wíwá àwọn aláìṣiṣẹ́mọ́ ṣe kan gbogbo wa?
6 Ta ló yẹ kó wá àwọn aláìṣiṣẹ́mọ́? Iṣẹ́ gbogbo wa ni, yálà a jẹ́ alàgbà, aṣáájú-ọ̀nà, ẹbí tàbí ọ̀rẹ́, títí kan àwọn akéde. Ṣé o mọ ẹnì kan tó ti di aláìṣiṣẹ́mọ́? Ṣé o ti pàdé ẹnì kan tó ti di aláìṣiṣẹ́mọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé tàbí níbi ìpàtẹ ìwé wa? Tẹ́ni náà bá fẹ́ kí àwọn alàgbà ran òun lọ́wọ́, gba àdírẹ́sì àti nọ́ńbà fóònù rẹ̀, kó o si fún àwọn alàgbà ìjọ rẹ.
7. Kí la rí kọ́ látinú ohun tí alàgbà kan tó ń jẹ́ Thomas sọ?
7 Àwọn alàgbà ní pàtàkì ló yẹ kó máa wá àwọn aláìṣiṣẹ́mọ́ kí wọ́n lè pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà. Báwo ni wọ́n ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀? Ẹ gbọ́ ohun tí alàgbà kan tó ń jẹ́ Thomas sọ. * Orílẹ̀-èdè Sípéènì ló ń gbé, ó sì ti ran àwọn ará tó lé ní ogójì (40) lọ́wọ́ láti pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà. Thomas sọ pé: “Mo máa ń kọ́kọ́ wádìí lọ́wọ́ àwọn ará bóyá wọ́n mọ ibi tí àwọn aláìṣiṣẹ́mọ́ ń gbé. Mo sì lè bi wọ́n bóyá wọ́n mọ ẹnì kan tí kò wá sípàdé mọ́. Inú àwọn ará máa ń dùn láti fún mi láwọn ìsọfúnni yẹn torí wọ́n gbà pé ṣe la jọ ń ṣe iṣẹ́ náà. Tí mo bá wá lọ sọ́dọ̀ àwọn ẹni yẹn, mo máa ń béèrè nípa àwọn ọmọ wọn àtàwọn mọ̀lẹ́bí wọn. Nígbà tí wọ́n bá sì bẹ̀rẹ̀ sí í wá sípàdé, wọ́n máa ń mú àwọn ọmọ wọn dání. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn ọmọ náà ti fìgbà kan rí jẹ́ akéde. Èyí sì máa ń béèrè pé ká ran àwọn náà lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa ṣe dáadáa nínú ètò Ọlọ́run.”
Ẹ RAN ÀWỌN ỌMỌ JÈHÓFÀ LỌ́WỌ́ KÍ WỌ́N LÈ PA DÀ SÍNÚ ÌJỌ
8. Nínú àpèjúwe tó wà nínú Lúùkù 15:17-24 nípa ọmọ kan tó filé sílẹ̀, kí ni bàbá náà ṣe nígbà tí ọmọ rẹ̀ ronú pìwà dà?
8 Àwọn ànímọ́ wo lá jẹ́ ká lè ṣèrànwọ́ fáwọn tó fẹ́ pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà? Ẹ jẹ́ ká wo àwọn nǹkan tá a lè rí kọ́ látinú àpèjúwe ọmọ kan tó filé sílẹ̀. (Ka Lúùkù 15:17-24.) Jésù ṣàlàyé nípa bí ọmọ náà ṣe pe orí ara rẹ̀ wálé tó sì pinnu pé òun máa pa dà sílé. Nígbà tí bàbá rẹ̀ rí i lọ́ọ̀ọ́kán, ó sáré lọ pàdé rẹ̀, ó gbá a mọ́ra, ó sì jẹ́ kó dá a lójú pé òun nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ẹ̀rí ọkàn ọmọ náà dà á láàmú, ó sì gbà pé òun ò yẹ lẹ́ni tí bàbá náà lè kà sí ọmọ. Bàbá yìí káàánú ọmọ tó ronú pìwà dà náà, ó sì ṣe àwọn nǹkan tó jẹ́ kó mọ̀ pé òun ti yọ́nú sí i. Ó jẹ́ kó mọ̀ pé òun ò ní kà á sí ẹrú bí kò ṣe ọmọ ọ̀wọ́n. Bàbá náà wá ní kí wọ́n wọ aṣọ tó dáa sí i lọ́rùn, ó sì filé pọntí fọ̀nà rokà nítorí rẹ̀.
9. Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá máa ṣèrànwọ́ fáwọn aláìṣiṣẹ́mọ́ kí wọ́n lè pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà? (Wo àpótí náà, “ Bá A Ṣe Lè Ṣèrànwọ́ Fáwọn Tó Fẹ́ Pa Dà Sọ́dọ̀ Jèhófà.”)
9 Jèhófà ni bàbá inú àpèjúwe yẹn ń tọ́ka sí. Ó nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa tí wọ́n jẹ́ aláìṣiṣẹ́mọ́, ó sì fẹ́ kí wọ́n pa dà sọ́dọ̀ òun. Bíi ti Jèhófà, ẹ jẹ́ káwa náà ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè pa dà sínú ìjọ. Àmọ́ èyí máa gba pé ká mú sùúrù fún wọn, ká gba tiwọn rò, ká sì nífẹ̀ẹ́ wọn dénú. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀, báwo la sì ṣe lè ṣe é?
10. Kí nìdí tó fi yẹ ká ní sùúrù tá a bá ń ran ẹnì kan tó jẹ́ aláìṣiṣẹ́mọ́ lọ́wọ́?
10 Ó yẹ ká mú sùúrù torí pé kì í ṣe ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni wọ́n máa kọ́fẹ pa dà nípa tẹ̀mí. Ọ̀pọ̀ àwọn tó ti fìgbà kan rí jẹ́ aláìṣiṣẹ́mọ́ sọ pé, léraléra làwọn alàgbà àtàwọn míì bẹ àwọn wò káwọn tó pa dà sínú ìjọ. Bí àpẹẹrẹ, Arábìnrin Nancy tó ń gbé nílẹ̀ Éṣíà sọ pé: “Kì í ṣe iṣẹ́ kékeré ni ọ̀rẹ́ mi kan ṣe kí n tó pa dà sínú ìjọ. Ṣe ló mú mi bí ọmọ ìyá. Ó máa ń rán mi létí àwọn nǹkan dáadáa tá a ti ṣe sẹ́yìn. Ó máa ń mú sùúrù, ó sì máa ń tẹ́tí sí mi tí mo bá ń sọ ẹ̀dùn ọkàn mi. Yàtọ̀ síyẹn kì í fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ, ó sì máa ń fún mi nímọ̀ràn nígbà tó bá yẹ. Ká sòótọ́, ọ̀rẹ́ gidi tó ṣe tán láti ranni lọ́wọ́ nígbàkigbà ni arábìnrin náà.”
11. Kí nìdí tó fi yẹ ká fi ìgbatẹnirò hàn sí àwọn tó ní ẹ̀dùn ọkàn?
11 Ṣe lọ̀rọ̀ ẹni tó ní ẹ̀dùn ọkàn dà bíi tẹni tó fara pa, tá a bá fi ìgbatẹnirò hàn sí i, ṣe ló dà bí ìgbà tá a fún ẹni náà ní oògùn táá mú kára tù ú. Ẹnì kan tó jẹ́ aláìṣiṣẹ́mọ́ ṣì lè máa rántí ohun tẹ́nì kan ṣe sí i lọ́pọ̀ Jém. 1:19) Arábìnrin María tó ti fìgbà kan rí jẹ́ aláìṣiṣẹ́mọ́ sọ pé: “Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, mo nílò ẹnì kan tó máa fara balẹ̀ gbọ́rọ̀ mi, tó máa gba tèmi rò, táá sì tọ́ mi sọ́nà.”
ọdún sẹ́yìn, kíyẹn sì máa bí i nínú. Nípa bẹ́ẹ̀, ó lè ṣòro fún un láti pa dà sínú ìjọ. Àwọn kan lè ronú pé àwọn alàgbà ò bójú tó ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn bó ṣe yẹ. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ nílò ẹni tó máa fara balẹ̀ tẹ́tí sí wọn táá sì gba tiwọn rò. (12. Báwo ni ìfẹ́ tí Jèhófà ní fáwa èèyàn rẹ̀ ṣe dà bí okùn?
12 Bíbélì fi ìfẹ́ tí Jèhófà ní fáwa èèyàn rẹ̀ wé okùn. Báwo ló ṣe rí bẹ́ẹ̀? Ẹ jẹ́ ká ṣàkàwé ẹ̀ báyìí: Jẹ́ ká sọ pé o wà lójú agbami tó ń ru gùdù, ohun kan wá ṣẹlẹ̀ tó mú kó o máa rì, o ò sì fi bẹ́ẹ̀ mọ̀wẹ̀. Lẹnì kan bá ju ohun kan sí ẹ táá jẹ́ kó o léfòó lójú omi. Kò sí àní-àní pé wàá mọyì ẹ̀ gan-an, wàá sì di ohun náà mú kó o má bàa rì. Àmọ́ ìyẹn nìkan ò tó, torí tó o bá pẹ́ jù lójú omi, o lè kú torí pé òtútù lè mú ẹ kọjá bó ṣe yẹ. Báwo ló ṣe máa rí lára ẹ ká sọ pé ẹnì kan ju okùn sí ẹ, tó sì ń fà ẹ́ kó o lè bọ́ sínú ọkọ̀ tí wọ́n fi ń gbẹ̀mí là? Ó dájú pé inú ẹ máa dùn, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Ohun tí Jèhófà ṣe fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó ṣáko lọ gẹ́lẹ́ nìyẹn, ó sọ pé: “Mo fi okùn . . . ìfẹ́ fà wọ́n mọ́ra.” (Hós. 11:4) Lónìí, bọ́rọ̀ àwọn tó fi ìjọ sílẹ̀ tí wọ́n sì ń tinú ìṣòro kan bọ́ sí òmíì ṣe rí lára Jèhófà nìyẹn. Ó fẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé òun nífẹ̀ẹ́ wọn gan-an, òun sì ń fẹ́ kí wọ́n pa dà sọ́dọ̀ òun. Ṣé wàá jẹ́ kí Jèhófà lò ẹ́ láti fìfẹ́ hàn sí wọn?
13. Sọ ìrírí kan tó jẹ́ ká mọ̀ pé ìfẹ́ tá a fi hàn sẹ́nì kan lè mú kó pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà.
13 Ó ṣe pàtàkì ká jẹ́ káwọn aláìṣiṣẹ́mọ́ rí i pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wọn àti pé àwa náà
mọyì wọn. Ohun tó lé lọ́gbọ̀n (30) ọdún ni Arákùnrin Pablo tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú fi jẹ́ aláìṣiṣẹ́mọ́. Nígbà tó ń sọ ohun tó jẹ́ kó pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà, ó ní: “Bí mo ṣe ń jáde nílé láàárọ̀ ọjọ́ kan, mo pàdé arábìnrin àgbàlagbà kan tó jẹ́ onínúure. Arábìnrin náà fìfẹ́ hàn sí mi, ó sì bá mi sọ̀rọ̀ bí ìyá sọ́mọ. Ṣe ni mo bú sẹ́kún, tí mo sì ń hu bí ọmọdé. Mo sọ fún un pé ṣe ló dà bíi pé Jèhófà dìídì rán an sí mi. Ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ yẹn ló mú kí n pinnu pé màá pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà.”Ẹ FÌFẸ́ RAN ÀWỌN ALÁÌLERA LỌ́WỌ́
14. Bí Jésù ṣe ṣàkàwé nínú Lúùkù 15:4, 5, kí ni olùṣọ́ àgùntàn kan ṣe lẹ́yìn tó rí àgùntàn rẹ̀ tó sọ nù?
14 Lẹ́yìn tá a bá ti rí ẹnì kan tó jẹ́ aláìṣiṣẹ́mọ́, kò yẹ ká pa á tì, ṣe ló yẹ ká ràn án lọ́wọ́ ká sì máa fún un níṣìírí. Ẹni náà lè ní ẹ̀dùn ọkàn bíi ti ọmọ tó filé sílẹ̀ nínú àkàwé Jésù. Ohun tójú rẹ̀ sì ti rí nígbà tó wà nínú ayé Sátánì ti lè mú kó di aláìlera nípa tẹ̀mí. Torí náà, ẹ jẹ́ ká ran irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n lè pa dà ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. Nínú àkàwé tí Jésù ṣe nípa àgùntàn tó sọ nù, ó sọ pé olùṣọ́ àgùntàn náà gbé àgùntàn yẹn lé èjìká rẹ̀, ó sì gbé e pa dà sínú agbo. Lóòótọ́, olùṣọ́ àgùntàn náà ti wá àgùntàn tó sọ nù náà káàkiri, ó sì ṣeé ṣe kó ti rẹ̀ ẹ́. Síbẹ̀, ó rí i pé á dáa kóun gbé àgùntàn náà torí pé kò ní lè dá rìn pa dà sínú agbo.—Ka Lúùkù 15:4, 5.
15. Báwo la ṣe lè ṣèrànwọ́ fáwọn aláìlera tó fẹ́ pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà? (Wo àpótí náà, “ Ìwé Kan Tó Wúlò Gan-an.”)
15 Ó lè gba ọ̀pọ̀ àkókò àti ìsapá ká tó lè ran àwọn aláìlera lọ́wọ́. Ìdí sì ni pé ó ṣeé ṣe kí wọ́n láwọn ìṣòro kan tó ń mú kó nira fún wọn láti máa fayọ̀ sin Jèhófà. Báwo la ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́? Ó ṣe pàtàkì ká gbára Róòmù 15:1) Ẹ gbọ́ ohun tí alàgbà kan sọ lórí kókó yìí, ó ní: “Lọ́pọ̀ ìgbà, tí aláìṣiṣẹ́mọ́ kan bá pa dà sínú ìjọ, ó lè gba pé ká ṣètò pé kẹ́nì kan bá a kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.” * Táwọn alàgbà bá ní kó o darí ìkẹ́kọ̀ọ́ ẹni náà, ṣé inú ẹ máa dùn láti ṣe bẹ́ẹ̀? Alàgbà yẹn tún fi kún un pé: “Ṣe ló yẹ kẹ́ni tó fẹ́ darí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà mú onítọ̀hún lọ́rẹ̀ẹ́ kó lè ṣeé ṣe fún un láti sọ ohun tó wà lọ́kàn ẹ̀.”
lé ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà, ká sì ṣàyẹ̀wò Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àtàwọn ìtẹ̀jáde ètò Ọlọ́run. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, àá lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti pa dà ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. (INÚ ÀWỌN TÓ WÀ LỌ́RUN ÀTI AYÉ DÙN
16. Báwo la ṣe mọ̀ pé àwọn áńgẹ́lì ń tì wá lẹ́yìn?
16 Ọ̀pọ̀ ìrírí ló fi hàn pé àwọn áńgẹ́lì ń tì wá lẹ́yìn bá a ṣe ń wá àwọn aláìṣiṣẹ́mọ́ tá a sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà. (Ìfi. 14:6) Àpẹẹrẹ kan ni ti Silvio tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Ecuador. Tọkàntọkàn ló fi gbàdúrà pé kí Jèhófà ran òun lọ́wọ́ kóun lè pa dà sínú ìjọ. Àdúrà yẹn ló ń gbà lọ́wọ́ táwọn alàgbà méjì fi kan ilẹ̀kùn rẹ̀. Inú àwọn alàgbà náà dùn nígbà tí wọ́n rí i, wọ́n sì jẹ́ kó mọ àwọn nǹkan tó máa ṣe kó lè pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà.
17. Báwo ló ṣe máa rí lára wa tá a bá ran ẹnì kan tó jẹ́ aláìlera nípa tẹ̀mí lọ́wọ́?
17 Inú wa máa dùn gan-an tá a bá ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà. Aṣáájú-ọ̀nà kan tó ń jẹ́ Salvador fẹ́ràn kó máa ran àwọn aláìṣiṣẹ́mọ́ lọ́wọ́. Nígbà tó sọ bó ṣe máa ń rí lára ẹ̀, ó ní: “Lọ́pọ̀ ìgbà, ṣe lomijé ayọ̀ máa ń dà lójú mi. Inú mi máa ń dùn pé mò ń bá Jèhófà ṣiṣẹ́ láti já àwọn àgùntàn rẹ̀ gbà lọ́wọ́ Sátánì.”—Ìṣe 20:35.
18. Kí ni Jèhófà fẹ́ kó dá ẹ lójú tó o bá tiẹ̀ jẹ́ aláìṣiṣẹ́mọ́?
18 Tó o bá tiẹ̀ jẹ́ aláìṣiṣẹ́mọ́, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà ṣì nífẹ̀ẹ́ rẹ gan-an. Ó fẹ́ kó o pa dà sọ́dọ̀ òun. Lóòótọ́, àwọn ìgbésẹ̀ kan wà tó o gbọ́dọ̀ gbé. Àmọ́ bíi ti bàbá inú àkàwé Jésù, Jèhófà ń dúró dè ẹ́ pé kó o pa dà sọ́dọ̀ òun. Tó o bá sì ṣe bẹ́ẹ̀, tayọ̀tayọ̀ ló fi máa gbà ẹ́ pa dà.
ORIN 103 Ẹ̀bùn Ni Àwọn Olùṣọ́ Àgùntàn
^ ìpínrọ̀ 5 Jèhófà fẹ́ káwọn tó ti di aláìṣiṣẹ́mọ́ pa dà sọ́dọ̀ òun. Ìdí nìyẹn tó fi ń rọ̀ wọ́n pé: “Ẹ pa dà sọ́dọ̀ mi.” Ǹjẹ́ ohunkóhun wà tá a lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́? Bẹ́ẹ̀ ni! Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò àwọn ohun tá a lè ṣe kí wọ́n lè pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà.
^ ìpínrọ̀ 7 A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.
^ ìpínrọ̀ 15 Àwọn alàgbà lè ṣètò pé kẹ́nì kan jíròrò àwọn orí kan pàtó nínú ìwé ‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run’ tàbí Sún Mọ́ Jèhófà pẹ̀lú ẹnì kan tó jẹ́ aláìṣiṣẹ́mọ́ àmọ́ tó ti pa dà sínú ìjọ. Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn ló máa pinnu ẹni táá darí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà.
^ ìpínrọ̀ 68 ÀWÒRÁN: Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn arákùnrin mẹ́ta yìí ló ṣèrànwọ́ fún arákùnrin tó fẹ́ pa dà sínú ìjọ. Ọ̀kan bá a sọ̀rọ̀ lórí fóònù, èkejì fi dá a lójú pé Jèhófà àtàwọn ará nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, ẹnì kẹta sì fara balẹ̀ tẹ́tí sí i.