Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Ni Wàá Ṣe Tí Kàkàkí Bá Dún?

Kí Ni Wàá Ṣe Tí Kàkàkí Bá Dún?

Ó DÁ gbogbo wa lójú pé Jèhófà ń bójú tó àwa èèyàn rẹ̀, òun ló sì ń darí wa láwọn “ọjọ́ ìkẹyìn” yìí. (2 Tím. 3:⁠1) Àmọ́ ọwọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ló kù sí bóyá a máa ṣègbọràn sí Jèhófà àbí a ò ní ṣe bẹ́ẹ̀. Ṣe lọ̀rọ̀ wa dà bíi tàwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n wà nínú aginjù. Wọ́n ní láti ṣe ohun pàtó kan tí kàkàkí bá dún.

Jèhófà ní kí Mósè fi fàdákà ṣe kàkàkí méjì kó lè ‘máa fi pe àwọn èèyàn náà jọ pọ̀, kó sì máa fi sọ fún wọn pé kí wọ́n tú àgọ́ wọn ká.’ (Nọ́ń. 10:⁠2) Ohun tí wọ́n bá fẹ́ káwọn èèyàn náà ṣe ló máa pinnu báwọn àlùfáà ṣe máa fun àwọn kàkàkí náà. (Nọ́ń. 10:​3-8) Bákan náà lónìí, onírúurú ọ̀nà ni Jèhófà gbà ń darí àwa èèyàn rẹ̀. Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa mẹ́ta lára wọn, ká sì rí bó ṣe jọra pẹ̀lú báwọn àlùfáà ṣe ń fun kàkàkí nígbà yẹn lọ́hùn-ún. Lónìí, Jèhófà máa ń pè wá sáwọn àpéjọ ńlá, ó máa ń dá àwọn alábòójútó lẹ́kọ̀ọ́, ó sì máa ń ṣàtúnṣe sí ọ̀nà tó gbà ń darí ìjọ.

JÈHÓFÀ PE ÀWỌN ÈÈYÀN RẸ̀ SÍ ÀPÉJỌ ŃLÁ

Nígbà tí Jèhófà bá fẹ́ kí “gbogbo àpéjọ náà” kóra jọ sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, ìyẹn lápá ìlà oòrùn, kàkàkí méjèèjì làwọn àlùfáà máa fun. (Nọ́ń. 10:⁠3) Apá mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àgọ́ ìpàdé náà làwọn ẹ̀yà méjìlá náà pàgọ́ sí. Gbogbo wọn ló sì máa gbọ́ ìró kàkàkí nígbà tí wọ́n bá fun ún. Kì í pẹ́ táwọn tó pàgọ́ sí apá ìlà oòrùn fi máa ń dé ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé náà. Àmọ́ ọ̀rọ̀ àwọn tó jìnnà díẹ̀ kò rí bẹ́ẹ̀, torí náà ó máa ṣe díẹ̀ kí wọ́n tó dé ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé. Èyí ó wù kó jẹ́, gbogbo wọn pátá ni Jèhófà fẹ́ kó pé jọ síbẹ̀ kí wọ́n lè gba ìtọ́ni tó máa fún wọn.

Lónìí, àwa èèyàn Jèhófà ò pàdé lẹ́nu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, àmọ́ Jèhófà máa ń pè wá sáwọn àpéjọ ńlá. Lára irú ìkórajọpọ̀ bẹ́ẹ̀ làwọn àpéjọ agbègbè àtàwọn àkànṣe ìpàdé míì níbi tá a ti máa ń gbọ́ àwọn ìsọfúnni pàtàkì àtàwọn ìtọ́ni tó ń ṣe wá láǹfààní. Ibi gbogbo kárí ayé làwa èèyàn Jèhófà ti ń gbádùn oúnjẹ tẹ̀mí kan náà. Torí náà, láìka ibi yòówù ká ti kóra jọ, ẹgbẹ́ ará kan ṣoṣo la jẹ́ kárí ayé, a sì ń láyọ̀. Lóòótọ́, ọ̀nà jíjìn làwọn kan ti ń wá sáwọn àpéjọ yẹn. Síbẹ̀, gbogbo àwọn tó pé jọ ló máa ń gbà pé ìsapá àwọn tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ.

Ṣé ó ṣeé ṣe fáwọn ará wa tó wà níbi àdádó láti gbádùn irú àwọn àpéjọ ńlá bẹ́ẹ̀ bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn fún wọn láti wà níbẹ̀? Bẹ́ẹ̀ ni. Ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ti mú kó ṣeé ṣe fáwọn ará wa láti máa gbádùn ètò kan náà bí wọ́n tiẹ̀ wà níbi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí aṣojú oríléeṣẹ́ kan ṣèbẹ̀wò sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tó wà lórílẹ̀-èdè Benin, wọ́n ta àtagbà ètò náà sí ìlú Arlit, ìyẹn ìlú kan tí wọ́n ti ń wa kùsà ní Aṣálẹ̀ Sàhárà lórílẹ̀-èdè Niger. Mọ́kànlélógún (21) làwọn ará àtàwọn olùfìfẹ́hàn tó pé jọ síbẹ̀. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ibi tí wọ́n wà jìnnà síbi tí àpéjọ náà ti wáyé, wọ́n mọyì bí wọ́n ṣe wà níṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlélógójì, ọgọ́rùn-ún kan ó lé mọ́kànlélọ́gbọ̀n (44,131) tó gbádùn ètò náà. Arákùnrin kan sọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára wọn, ó ní: “A dúpẹ́, a tọ́pẹ́ dá lọ́wọ́ yín pé ẹ ta àtagbà ètò náà dé ọ̀dọ̀ wa. Ó jẹ́ kó túbọ̀ dá wa lójú pé ìgbà gbogbo lẹ̀ ń ronú nípa wa.”

JÈHÓFÀ PE ÀWỌN ALÁBÒÓJÚTÓ

Tó bá jẹ́ pé kàkàkí kan ni àlùfáà fun, “àwọn ìjòyè, àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún ní Ísírẹ́lì nìkan” ló máa pé jọ síbi àgọ́ ìpàdé náà. (Nọ́ń. 10:⁠4) Wọ́n á rí ìsọfúnni gbà látẹnu Mósè, á sì dá wọn lẹ́kọ̀ọ́. Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n á lè bójú tó ojúṣe wọn. Ó dájú pé tó o bá jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìjòyè náà, wàá ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti wà níbẹ̀ kó o sì jàǹfààní látinú ìdálẹ́kọ̀ọ́ àti ìtọ́ni náà.

Àwọn tó ń múpò iwájú láàárín àwa èèyàn Jèhófà lónìí kì í ṣe “ìjòyè,” wọn kì í sì í jẹ gàba tàbí ṣe ọ̀gá lórí àwọn àgùntàn tí Jèhófà fi síkàáwọ́ wọn. (1 Pét. 5:​1-3) Síbẹ̀, wọ́n máa ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti bójú tó wọn. Torí náà, inú wọn máa ń dùn tí ètò Ọlọ́run bá ní kí wọ́n wá gba àfikún ìdálẹ́kọ̀ọ́ láwọn ilé ẹ̀kọ́ ètò Ọlọ́run bí Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́. Láwọn ilé ẹ̀kọ́ náà, wọ́n máa ń kọ́ àwọn alàgbà bí wọ́n ṣe lè túbọ̀ bójú tó ojúṣe wọn nínú ìjọ. Èyí sì ń mú káwọn alàgbà àtàwọn ará nínú ìjọ túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Ká tiẹ̀ ní o ò tíì gba irú ìdálẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀, ó dájú pé ò ń jàǹfààní látara àwọn tí wọ́n ti dá lẹ́kọ̀ọ́.

JÈHÓFÀ MÚ KÍ WỌ́N ṢE ÀWỌN ÀTÚNṢE

Látìgbàdégbà, àwọn àlùfáà máa ń fi kàkàkí náà fun ìró tó ń lọ sókè sódò. Èyí ni wọ́n fi máa ń sọ fáwọn èèyàn náà pé kí wọ́n ṣí ibùdó. (Nọ́ń. 10:​5, 6) Lóòótọ́, ọ̀pọ̀ nǹkan làwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń ṣe lákòókò yìí, síbẹ̀ ohun gbogbo máa ń wà létòlétò, wọ́n sì máa ń tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́. Nígbà míì, ó lè má fi bẹ́ẹ̀ rọrùn fáwọn kan lára wọn láti ṣí kúrò lọ síbòmíì. Kí nìdí?

Àwọn kan lè rò pé ìyípadà náà ti ń ṣe lemọ́lemọ́ jù, ó sì máa ń wá láìròtẹ́lẹ̀. “Nígbà míì, ó lè má ju ìrọ̀lẹ́ sí àárọ̀ tí ìkùukùu náà á fi dúró.” Nígbà míì sì rèé, ó lè “jẹ́ ọjọ́ méjì, oṣù kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ.” (Nọ́ń. 9:​21, 22) Ẹ̀ẹ̀melòó ni wọ́n ṣí kúrò láti ibì kan sí òmíì? Ìwé Nọ́ńbà orí 33 mẹ́nu ba ibi ogójì (40) ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí wọ́n pàgọ́ sí.

Nígbà míì, ó lè jẹ́ ibi tí ibòji wà lẹnì kan pàgọ́ sí, ìyẹn sì máa fi ẹni náà lọ́kàn balẹ̀ nínú “aginjù tí ó tóbi tó sì ń bani lẹ́rù” náà. (Diu. 1:19) Torí náà, onítọ̀hún lè máa ronú pé tóun bá kúrò níbẹ̀, òun lè má rí ibi tó máa tura tóyẹn.

Táwọn èèyàn bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í gbéra, ó lè má rọrùn fáwọn kan láti mú sùúrù títí tó fi máa kàn wọ́n. Òótọ́ ni pé gbogbo wọn ló gbọ́ ìró kàkàkí tó ń lọ sókè sódò, àmọ́ kì í ṣe ẹ̀ẹ̀kan náà ni gbogbo wọn máa gbéra. Ohun tí ìró kàkàkí náà ń sọ ni pé kí àwọn ẹ̀yà Júdà, Ísákà àti Sébúlúnì tí wọ́n wà ní apá ìlà oòrùn àgọ́ ìpàdé náà gbéra. (Nọ́ń. 2:​3-7; 10:​5, 6) Lẹ́yìn náà, àwọn àlùfáà á tún fun kàkàkí náà kí àwọn ẹ̀yà mẹ́ta tó wà ní gúúsù lè gbéra. Bí àwọn àlùfáà ṣe máa ṣe nìyẹn títí gbogbo wọn fi máa gbéra.

Ó lè má rọrùn fún ìwọ náà láti fara mọ́ àwọn àyípadà kan tó wáyé nínú ètò Ọlọ́run. Ó sì lè máa ṣe ẹ́ bíi pé àwọn àyípadà náà ti ń ṣe lemọ́lemọ́ jù. Tàbí kẹ̀, ó ṣeé ṣe kí àwọn nǹkan tó ò ń ṣe báyìí ti tẹ́ ẹ lọ́rùn, tó ò sì fẹ́ kí wọ́n yí pa dà. Ohun yòówù kó jẹ́, ó lè má rọrùn fún ẹ láti mú sùúrù títí àwọn àyípadà náà á fi bá ẹ lára mu. Àmọ́ tó o bá fara mọ́ ọn, tó o sì ṣe àwọn ìyípadà tó yẹ lásìkò, wàá rí ìbùkún Jèhófà.

Nígbà ayé Mósè, Jèhófà darí ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn lọ́kùnrin àti lóbìnrin gba inú aginjù kọjá, títí kan àwọn ọmọdé. Wọn ò bá ti kú sínú aginjù ká sọ pé Jèhófà ò bójú tó wọn. Bákan náà lọ̀rọ̀ rí lónìí, Jèhófà ló ń darí wa láwọn ọjọ́ ìkẹyìn tó léwu yìí. Kódà, ó ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú òun, ó sì ń mú kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára. Torí náà, ẹ jẹ́ kí gbogbo wa pinnu pé báwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ṣègbọràn sí ìró kàkàkí, àwa náà á máa ṣègbọràn sí Jèhófà nígbà gbogbo!