Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 23

Fọkàn Balẹ̀, Jèhófà Wà Pẹ̀lú Rẹ

Fọkàn Balẹ̀, Jèhófà Wà Pẹ̀lú Rẹ

“Jèhófà wà nítòsí gbogbo àwọn tó ń ké pè é.”​—SM. 145:18.

ORIN 28 Bá A Ṣe Lè Jẹ́ Ọ̀rẹ́ Jèhófà

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1. Kí ló lè mú káwọn ará wa kan máa rò pé àwọn ò rẹ́ni fojú jọ?

LẸ́Ẹ̀KỌ̀Ọ̀KAN ó máa ń ṣe ọ̀pọ̀ nínú wa bíi pé a ò rẹ́ni fojú jọ tàbí pé a ò ní alábàárò. Àwọn kan lára wa máa ń tètè borí ìṣòro yìí, àmọ́ fáwọn míì kì í lọ bọ̀rọ̀. Kódà bí irú àwọn bẹ́ẹ̀ bá wà láàárín àwọn èèyàn, ó lè ṣe wọ́n bíi pé wọ́n dá wà. Àwọn kan wà tó tún jẹ́ pé ara wọn kì í tètè mọlé tí wọ́n bá dénú ìjọ kan. Ìdílé tí wọ́n ti máa ń ṣe nǹkan pa pọ̀ làwọn míì ti wá, torí náà tí wọ́n bá kó lọ síbòmíì, ó máa ń ṣe wọ́n bíi pé wọn ò rẹ́ni fojú jọ. Ní tàwọn míì, àárò èèyàn wọn tó kú ló máa ń sọ wọ́n. Ó máa ń ṣe àwọn kan lára wa, pàápàá àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ bíi pé wọn ò rẹ́ni fojú jọ. Kí nìdí? Ìdí ni pé àwọn mọ̀lẹ́bí wọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí àtàwọn ọ̀rẹ́ wọn àtijọ́ ti pa wọ́n tì tàbí kí wọ́n máa ta kò wọ́n.

2. Àwọn ìbéèrè wo la máa dáhùn?

2 Jèhófà mọ̀ wá dáadáa, ó sì mọ bọ́rọ̀ ṣe máa ń rí lára wa. Ó máa ń mọ̀ tó bá ń ṣe wá bíi pé a ò rẹ́ni fojú jọ, ó sì ṣe tán láti ràn wá lọ́wọ́. Báwo ni Jèhófà ṣe máa ń ràn wá lọ́wọ́? Kí làwa fúnra wa lè ṣe láti borí ìṣòro yìí? Kí la sì lè ṣe láti ran àwọn ará wa tó nírú ìṣòro yìí lọ́wọ́? Ẹ jẹ́ ká dáhùn àwọn ìbéèrè yìí.

JÈHÓFÀ MỌ BÍ NǸKAN ṢE Ń RÍ LÁRA WA

Jèhófà rán áńgẹ́lì kan sí Èlíjà kó lè fi í lọ́kàn balẹ̀ pé òun nìkan kọ́ ni wòlíì Jèhófà tó ṣẹ́ kù (Wo ìpínrọ̀ 3)

3. Báwo ni Jèhófà ṣe fi hàn pé òun mọ bí nǹkan ṣe rí lára Èlíjà?

3 Jèhófà nífẹ̀ẹ́ gbogbo àwa ìránṣẹ́ rẹ̀, ó sì fẹ́ ká máa láyọ̀. Jèhófà wà nítòsí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa, ó sì máa ń mọ̀ tínú wa ò bá dùn tàbí tá a rẹ̀wẹ̀sì. (Sm. 145:18, 19) Ẹ jẹ́ ká wo bí Jèhófà ṣe ran Èlíjà lọ́wọ́ nígbà tó rẹ̀wẹ̀sì. Àsìkò tí nǹkan ò rọgbọ nílẹ̀ Ísírẹ́lì ni wòlíì yẹn gbáyé. Àwọn ọ̀tá tó wà nípò àṣẹ ń ṣe inúnibíni tó gbóná janjan sáwọn ìránṣẹ́ Jèhófà, kódà wọ́n dìídì dájú sọ Èlíjà. (1 Ọba 19:1, 2) Ohun míì tó ṣeé ṣe kó dákún ìṣòro Èlíjà ni pé ó ronú pé òun nìkan ni wòlíì Jèhófà tó ṣẹ́ kù. (1 Ọba 19:10) Jèhófà tètè dá sọ́rọ̀ Èlíjà. Ó rán áńgẹ́lì kan sí i láti tù ú nínú, kó sì fi í lọ́kàn balẹ̀ pé òun nìkan kọ́ ni ìránṣẹ́ Jèhófà tó ṣẹ́ kù, àwọn míì náà wà tí wọ́n ń fòótọ́ ọkàn sin Jèhófà!​—1 Ọba 19:5, 18.

4. Kí ni Máàkù 10:29, 30 sọ tó fi hàn pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ bí wọn ò tiẹ̀ rẹ́ni fojú jọ?

4 Jèhófà mọ̀ pé ọ̀pọ̀ nǹkan la máa yááfì tá a bá yàn láti sin òun. Lára àwọn tó lè kẹ̀yìn sí wa ni àwọn mọ̀lẹ́bí wa tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí àtàwọn ọ̀rẹ́ wa àtijọ́. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé irú ohun tó wà lọ́kàn àpọ́sítélì Pétérù náà nìyẹn nígbà tó bi Jésù pé: “A ti fi ohun gbogbo sílẹ̀, a sì tẹ̀ lé ọ; kí ló máa wá jẹ́ tiwa?” (Mát. 19:27) Jésù wá fi àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ lọ́kàn balẹ̀, ó sì jẹ́ kó dá wọn lójú pé wọ́n máa ní ọ̀pọ̀ àwọn ará tó máa dà bí ọmọ ìyá. (Ka Máàkù 10:29, 30.) Bákan náà, Jèhófà Baba wa ọ̀run ṣèlérí pé òun máa ti gbogbo àwọn tó ń sin òun lẹ́yìn. (Sm. 9:10) Ní báyìí, jẹ́ ká wo àwọn nǹkan pàtó tó o lè ṣe táá jẹ́ kí Jèhófà ràn ẹ́ lọ́wọ́ kọ́kàn ẹ lè balẹ̀ láàárín àwọn ará, kó o sì rẹ́ni fojú jọ.

OHUN TÓ O LÈ ṢE

5. Àǹfààní wo lo máa rí tó o bá ń ronú lórí bí Jèhófà ṣe ń ràn ẹ́ lọ́wọ́?

5 Máa ronú lórí bí Jèhófà ṣe ń ràn ẹ́ lọ́wọ́. (Sm. 55:22) Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, kò ní máa ṣe ẹ́ bíi pé o ò rẹ́ni fojú jọ. Arábìnrin Carol * tí kò tíì lọ́kọ, tí mọ̀lẹ́bí ẹ̀ kankan ò sì sí nínú òtítọ́ sọ pé: “Tí n bá ń ronú lórí bí Jèhófà ṣe ràn mí lọ́wọ́, tó sì dúró tì mí nígbà ìṣòro, kì í jẹ́ kó dà bíi pé mi ò rẹ́ni fojú jọ. Ìyẹn sì jẹ́ kó dá mi lójú pé Jèhófà ò ní fi mí sílẹ̀ lọ́jọ́ iwájú.”

6. Kí ni 1 Pétérù 5:9, 10 sọ tó lè fi wá lọ́kàn balẹ̀ tó bá ń ṣe wá bíi pé a ò rẹ́ni fojú jọ?

6 Máa ronú nípa bí Jèhófà ṣe ń ṣèrànwọ́ fáwọn ará tó ronú pé àwọn ò rẹ́ni fojú jọ. (Ka 1 Pétérù 5:9, 10.) Arákùnrin Hiroshi, tó jẹ́ pé òun nìkan ni Ẹlẹ́rìí nínú ìdílé ẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún sọ pé: “Nínú ìjọ, mo kíyè sí i pé kò sẹ́ni tí ò níṣòro. Àmọ́ báwọn ará ṣe ń fara dà á tí wọ́n sì ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ń fún àwa tá ò ní ẹbí nínú òtítọ́ níṣìírí.”

7. Báwo ni àdúrà ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́?

7 Máa ṣe ohun táá jẹ́ kó o túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Èyí gba pé kó o máa sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ fún un. (1 Pét. 5:7) Arábìnrin Massiel táwọn mọ̀lẹ́bí ẹ̀ pa tì nígbà tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ sọ pé: “Lára ohun tó ràn mí lọ́wọ́ tí ò jẹ́ kí n máa ronú ṣáá pé mi ò rẹ́ni fojú jọ ni àdúrà àtọkànwá tí mo máa ń gbà sí Jèhófà. Baba tó ju baba lọ ló jẹ́ fún mi, ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo máa ń bá a sọ̀rọ̀ lójoojúmọ́, tí mo sì máa ń sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára mi fún un.”

Tó o bá ń tẹ́tí sí Bíbélì àtàwọn ìtẹ̀jáde tá a kà sórí ẹ̀rọ, kò ní máa ṣe ẹ́ bíi pé o dá wà (Wo ìpínrọ̀ 8) *

8. Tó o bá ń ka Bíbélì, tó o sì ń ṣàṣàrò lé e, báwo nìyẹn ṣe máa ràn ẹ́ lọ́wọ́?

8 Máa ka Bíbélì lójoojúmọ́, kó o sì máa ṣàṣàrò lórí àwọn apá táá jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ẹ. Arábìnrin Bianca táwọn mọ̀lẹ́bí ẹ̀ máa ń sọ̀rọ̀ kòbákùngbé sí sọ pé: “Bí mo ṣe ń ka Bíbélì, tí mò ń ṣàṣàrò lé e lórí, tí mo sì tún ń ka ìtàn àwọn ará tó kojú irú ìṣòro yìí máa ń ràn mí lọ́wọ́ gan-an.” Àwọn Kristẹni kan máa ń há àwọn ẹsẹ Bíbélì tó lè tuni nínú sórí, bíi Sáàmù 27:10 àti Àìsáyà 41:10. Ohun táwọn míì máa ń ṣe ni pé wọ́n máa ń tẹ́tí sí Bíbélì àtàwọn àpilẹ̀kọ tá a kà sórí ẹ̀rọ tí wọ́n bá ń múra ìpàdé sílẹ̀, ìyẹn kì í jẹ́ kí wọ́n ronú pé àwọn dá wà.

9. Àǹfààní wo lo máa rí tó o bá ń lọ sípàdé déédéé?

9 Ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti máa lọ sípàdé déédéé. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá rí ìṣírí gbà, wàá sì túbọ̀ mọ àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin. (Héb. 10:24, 25) Massiel tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Bó tiẹ̀ jẹ́ pé mo máa ń tijú, mo pinnu pé mi ò ní pa ìpàdé kankan jẹ, màá sì máa lóhùn sípàdé. Èyí jẹ́ kí n túbọ̀ sún mọ́ àwọn ará nínú ìjọ.”

10. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kó o mú àwọn tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn lọ́rẹ̀ẹ́?

10 Mú àwọn tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn lọ́rẹ̀ẹ́. Máa kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn tó o lè kẹ́kọ̀ọ́ lára wọn, yálà wọ́n kéré sí ẹ lọ́jọ́ orí tàbí wọ́n dàgbà jù ẹ́ lọ, tàbí kó jẹ́ pé àṣà wọn yàtọ̀ sí tìẹ. Bíbélì sọ pé: “Ọ̀dọ̀ àwọn àgbà la ti ń rí ọgbọ́n.” (Jóòbù 12:12) Kódà, àwọn àgbàlagbà lè kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn ọmọdé tó wà nínú ìjọ. Bí àpẹẹrẹ, Dáfídì kéré gan-an lọ́jọ́ orí sí Jónátánì, síbẹ̀ ọ̀rẹ́ kòríkòsùn ni wọ́n. (1 Sám. 18:1) Àwọn méjèèjì sì ran ara wọn lọ́wọ́ láti máa sin Jèhófà kódà lójú ìṣòro. (1 Sám. 23:16-18) Arábìnrin Irina tó jẹ́ pé òun nìkan ni Ẹlẹ́rìí nínú ìdílé rẹ̀ sọ pé: “Àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin lè dà bí òbí tàbí ọmọ ìyá wa. Jèhófà sì lè lò wọ́n láti ràn wá lọ́wọ́.”

11. Kí la lè ṣe táá mú kí àárín àwa àtàwọn ará túbọ̀ wọ̀ dáadáa?

11 Kì í sábà rọrùn láti ní àwọn ọ̀rẹ́ tuntun pàápàá téèyàn bá ń tijú. Onítìjú èèyàn ni Arábìnrin Ratna, ó sì kojú àtakò gan-an nígbà tó ń kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Nígbà tó ń sọ bí nǹkan ṣe rí fún un nígbà yẹn, ó sọ pé: “Mo rí i pé ó ṣe pàtàkì kí n jẹ́ káwọn ará nínú ìjọ ràn mí lọ́wọ́.” Ó lè má rọrùn láti sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ fún ẹlòmíì, àmọ́ tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn á jẹ́ kí àárín ìwọ àti ẹni náà túbọ̀ gún. Àwọn ará ṣe tán láti dúró tì ẹ́, kí wọ́n sì ràn ẹ́ lọ́wọ́. Àmọ́, o gbọ́dọ̀ sọ ohun tó ò ń bá yí fún wọn kí wọ́n tó lè ṣe bẹ́ẹ̀.

12. Báwo lo ṣe lè láwọn ọ̀rẹ́ gidi?

12 Ọ̀kan lára ọ̀nà tó dáa jù tó o lè gbà láwọn ọ̀rẹ́ gidi ni pé kó o máa bá àwọn ará ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí. Arábìnrin Carol tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Bí mo ṣe ń bá àwọn arábìnrin ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí, tá a sì tún jọ ń ṣe àwọn nǹkan míì lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ti jẹ́ kí n ní ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́. Jèhófà ló fi àwọn ọ̀rẹ́ yìí kẹ́ mi torí pé wọ́n dúró tì mí nígbà ìṣòro.” Àǹfààní téèyàn máa rí tó bá mú àwọn ará tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn lọ́rẹ̀ẹ́ kì í ṣe kékeré. Jèhófà máa ń lo àwọn ọ̀rẹ́ yìí láti ràn wá lọ́wọ́ pàápàá nígbà tó bá ń ṣe wá bíi pé a ò rẹ́ni fojú jọ.​—Òwe 17:17.

BÁ A ṢE LÈ MÚ KÁRA TU ÀWỌN MÍÌ NÍNÚ ÌJỌ

13. Ojúṣe wo ni gbogbo wa ní nínú ìjọ?

13 Ojúṣe gbogbo wa ni láti rí i pé ìfẹ́ àti àlàáfíà jọba nínú ìjọ, kó má sì ṣe ẹnikẹ́ni bíi pé òun ò rẹ́ni fojú jọ. (Jòh. 13:35) Èyí fi hàn pé ohun tá a bá ṣe àtohun tá a bá sọ lè fún àwọn míì níṣìírí gan-an. Ẹ kíyè sí ohun tí arábìnrin kan sọ, ó ní: “Nígbà tí mo kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, ṣe làwọn ará nínú ìjọ mú mi bí ọmọ ìyá. Tí kì í bá ṣe tàwọn ará yìí, mi ò bá má di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.” Ìbéèrè náà ni pé kí la lè ṣe táá mú kára tu àwọn tí kò ní ẹbí nínú òtítọ́?

14. Báwo lo ṣe lè mú àwọn ẹni tuntun lọ́rẹ̀ẹ́?

14 Mú àwọn ẹni tuntun lọ́rẹ̀ẹ́. A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá kí àwọn ẹni tuntun dáadáa tí wọ́n bá wá sípàdé wa. (Róòmù 15:7) Àmọ́, kò yẹ ká fi mọ síbẹ̀ o. Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, ó tún yẹ ká mú wọn lọ́rẹ̀ẹ́. Torí náà, sún mọ́ àwọn ẹni tuntun kó o lè túbọ̀ mọ̀ wọ́n. A tún lè sapá láti mọ ohun tí wọ́n ń kojú láìtojú bọ ọ̀rọ̀ wọn. Ó lè má rọrùn fáwọn kan láti sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára wọn. Torí náà, kò ní dáa kó o lọ́ wọn nífun. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni kó o fọgbọ́n béèrè àwọn ìbéèrè táá jẹ́ kí wọ́n sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn, kó o sì tẹ́tí sí wọn dáadáa. Bí àpẹẹrẹ, o lè bi wọ́n pé, báwo lẹ ṣe rí òtítọ́?

15. Báwo ni àwọn tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn ṣe lè ran àwọn míì lọ́wọ́ nínú ìjọ?

15 Gbogbo àwọn tó wà nínú ìjọ máa tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí tí àwọn tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn, pàápàá àwọn alàgbà, bá ń fìfẹ́ hàn sí wọn. Melissa, tí màmá ẹ̀ tọ́ dàgbà nínú òtítọ́ sọ pé: “Mo dúpẹ́, mo tọ́pẹ́ dá lọ́wọ́ àwọn arákùnrin tó dà bíi bàbá fún mi látọdún yìí wá. Kò sígbà tí mo fẹ́ sọ ohun tó wà lọ́kàn mi tí wọn kì í tẹ́tí sí mi.” Inú ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Mauricio bà jẹ́ nígbà tí ẹni tó kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ fi òtítọ́ sílẹ̀, ó ní: “Ìfẹ́ táwọn alàgbà fi hàn sí mi mú kára tù mí gan-an. Gbogbo ìgbà ni wọ́n máa ń bá mi sọ̀rọ̀. Wọ́n máa ń bá mi ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí, wọ́n sì máa ń sọ àwọn ohun tí wọ́n kọ́ nínú Bíbélì kíkà wọn fún mi. Kódà, a jọ máa ń ṣeré ìdárayá.” Ní báyìí, Bẹ́tẹ́lì ni Melissa àti Mauricio wà.

Ṣé ẹnì kan wà nínú ìjọ yín tó máa mọrírì ẹ̀ gan-an tẹ́ ẹ bá fi ẹ̀mí aájò àlejò hàn sí i? (Wo ìpínrọ̀ 16-19) *

16-17. Àwọn nǹkan pàtó wo la lè ṣe láti ran àwọn míì lọ́wọ́?

16 Ṣe àwọn nǹkan pàtó láti ràn wọ́n lọ́wọ́. (Gál. 6:10) Arákùnrin Leo tó ń ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì lórílẹ̀-èdè kan tó jìnnà sáwọn ẹbí ẹ̀ sọ pé: “Lọ́pọ̀ ìgbà, ohun tó máa ṣèrànwọ́ fún ẹnì kan ni pé ká fún un lóhun tó nílò lásìkò tó nílò ẹ̀ gan-an. Mo rántí ọjọ́ kan tí mo ní ìjàǹbá ọkọ̀. Nígbà tí mo jàjà délé, ṣe ni mo wó síbì kan. Àmọ́ tọkọtaya kan ní kí n wá jẹun lọ́dọ̀ àwọn. Mi ò rántí ohun tá a jẹ lọ́jọ́ yẹn, àmọ́ mo rántí pé wọ́n fara balẹ̀ tẹ́tí sí mi, ìyẹn sì jẹ́ kára tù mí pẹ̀sẹ̀!”

17 Gbogbo wa la máa ń gbádùn àwọn àpéjọ wa gan-an torí pé ó máa ń jẹ́ ká wà pẹ̀lú àwọn ará wa, ká sì jọ sọ̀rọ̀ nípa ohun tá a gbádùn. Àmọ́ Arábìnrin Carol tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Ó máa ń ṣòro fún mi gan-an tí n bá wà láwọn àpéjọ wa.” Kí nìdí? Ó sọ pé: “Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àárín ọ̀pọ̀ àwọn ará ni mo wà, lọ́pọ̀ ìgbà àwọn àti ìdílé wọn ni wọ́n jọ máa ń sọ̀rọ̀ tí wọ́n sì jọ máa ń jẹun. Nírú àsìkò yẹn, ó máa ń ṣe mí gan-an bíi pé mo dá wà.” Kì í rọrùn fáwọn míì láti lọ sí àpéjọ lẹ́yìn tí ọkọ tàbí ìyàwó wọn bá kú. Ṣé o mọ ẹnì kan tó nírú ìṣòro yìí? O ò ṣe sọ fún un pé kó wá jókòó ti ìwọ àti ìdílé ẹ nígbà àpéjọ míì tẹ́ ẹ máa ṣe?

18. Báwo la ṣe lè fi ohun tó wà nínú 2 Kọ́ríńtì 6:11-13 sílò?

18 Máa lo àkókò pẹ̀lú àwọn ará. Máa pe àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ wá sílé ẹ, pàápàá àwọn tó bá ń ronú pé àwọn dá wà. O sì lè pè wọ́n síbi ìkórajọ èyíkéyìí tẹ́ ẹ bá ṣètò. Ẹ jẹ́ ká “ṣí ọkàn wa sílẹ̀ pátápátá” fún irú àwọn bẹ́ẹ̀. (Ka 2 Kọ́ríńtì 6:11-13.) Melissa tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Inú mi máa ń dùn gan-an táwọn ọ̀rẹ́ wa bá ní ká wá ṣeré nílé àwọn tàbí ká jọ lọ gbafẹ́.” Ṣé ẹnì kan wà ní ìjọ yín tẹ́ ẹ lè ṣe lálejò nílé yín?

19. Ìgbà wo ló dáa jù ká lo àkókò pẹ̀lú àwọn ará wa?

19 Àwọn ìgbà kan wà tínú àwọn ará wa máa dùn gan-an tá a bá wà pẹ̀lú wọn. Bí àpẹẹrẹ, ó máa ń ṣòro fáwọn kan láti wà nílé nígbà táwọn mọ̀lẹ́bí wọn bá ń ṣọdún. Inú àwọn míì sì máa ń bà jẹ́ gan-an ní àyájọ́ ọjọ́ téèyàn wọn kan kú. Torí náà, tá a bá ń wà pẹ̀lú àwọn ará wa nírú àwọn àsìkò yìí, ṣe là ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ wọn látọkàn wá.​—Fílí. 2:20.

20. Kí ni Jésù sọ nínú Mátíù 12:48-50 tó lè fi wá lọ́kàn balẹ̀ tó bá ń ṣe wá bíi pé a dá wà?

20 Ọ̀pọ̀ nǹkan ló lè mú kí Kristẹni kan ronú pé òun ò rẹ́ni fojú jọ tàbí pé òun dá wà. Àmọ́ ẹ jẹ́ ká fi sọ́kàn pé Jèhófà mọ bí nǹkan ṣe rí lára wa, ó sì nífẹ̀ẹ́ wa gan-an. Lọ́pọ̀ ìgbà, ó máa ń lo àwọn ará wa láti pèsè ohun tá a nílò. (Ka Mátíù 12:48-50.) Àwa náà lè fi hàn pé a mọyì ohun tí Jèhófà ṣe fún wa tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti ran àwọn ará wa lọ́wọ́. Torí náà, tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé o dá wà tàbí pé o ò rẹ́ni fojú jọ, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà wà pẹ̀lú ẹ, kò sì ní fi ẹ́ sílẹ̀ láé!

ORIN 46 A Dúpẹ́, Jèhófà

^ ìpínrọ̀ 5 Ṣé ó máa ń ṣe ẹ́ bíi pé kò sẹ́ni tó rí tìẹ rò tàbí pé o ò rẹ́ni fojú jọ? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà mọ ohun tó ò ń bá yí, ó sì ṣe tán láti ràn ẹ́ lọ́wọ́. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò ohun tó o lè ṣe. Àá tún jíròrò ohun tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lè ṣe láti ran àwọn ará tó nírú ìṣòro yìí lọ́wọ́.

^ ìpínrọ̀ 5 A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.

^ ìpínrọ̀ 60 ÀWÒRÁN: Arákùnrin kan tí ìyàwó ẹ̀ kú máa ń tẹ́tí sí Bíbélì àtàwọn ìtẹ̀jáde tá a kà sórí ẹ̀rọ, ìyẹn sì máa ń jẹ́ kọ́kàn ẹ̀ balẹ̀.

^ ìpínrọ̀ 62 ÀWÒRÁN: Arákùnrin kan àti ọmọbìnrin rẹ̀ ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ arákùnrin àgbàlagbà kan, wọ́n sì gbé nǹkan wá fún un.