Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 24

O Lè Bọ́ Lọ́wọ́ Ìdẹkùn Èṣù!

O Lè Bọ́ Lọ́wọ́ Ìdẹkùn Èṣù!

‘Kí wọ́n bọ́ lọ́wọ́ ìdẹkùn Èṣù.’​—2 TÍM. 2:26.

ORIN 36 À Ń Dáàbò Bo Ọkàn Wa

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1. Kí nìdí tá a fi fi Sátánì wé ọdẹ kan?

OHUN tó máa ń jẹ àwọn ọdẹ lọ́kàn ni bí wọ́n ṣe máa rí ẹran mú tàbí kí wọ́n rí ẹran pa. Wọ́n lè lo onírúurú páńpẹ́ láti fi dẹkùn mú ẹran, ìyẹn sì bá ohun tí ọ̀kan lára àwọn ọ̀rẹ́ Jóòbù sọ mu. (Jóòbù 18:8-10) Ọgbọ́n wo ni àwọn ọdẹ máa ń dá kí wọ́n lè tan ẹran sínú páńpẹ́? Wọ́n máa ń kíyè sí ìṣe ẹran tí wọ́n fẹ́ mú. Ibo ló máa ń gbà? Kí ló nífẹ̀ẹ́ sí? Irú páńpẹ́ wo ló lè mú un? Ohun tí Sátánì máa ń ṣe gan-an nìyẹn. Ó máa ń kíyè sí ohun tá à ń ṣe, ibi tá a máa ń lọ àtohun tá a nífẹ̀ẹ́ sí. Á wá dẹ páńpẹ́ kan tó ronú pé á mú wa láìfura. Síbẹ̀, Bíbélì fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé tí ọwọ́ Sátánì bá tiẹ̀ bà wá, a ṣì lè bọ́ mọ́ ọn lọ́wọ́. Yàtọ̀ síyẹn, ó sọ ohun tá a lè ṣe tá ò fi ní kó sí i lọ́wọ́.

Àwọn nǹkan méjì tí Sátánì fi ń rí àwọn èèyàn mú jù ni ìgbéraga àti ojúkòkòrò (Wo ìpínrọ̀ 2) *

2. Àwọn páńpẹ́ méjì wo ni Sátánì fi ń rí àwọn èèyàn mú jù?

2 Àwọn nǹkan méjì tí Sátánì fi ń rí àwọn èèyàn mú jù ni ìgbéraga àti ojúkòkòrò. * Ọjọ́ pẹ́ tí Sátánì ti ń lo àwọn páńpẹ́ yìí, ó sì ti rí ọ̀pọ̀ èèyàn mú. Kódà, Bíbélì fi Sátánì wé pẹyẹpẹyẹ tó máa ń tan àwọn tó fẹ́ mú sínú páńpẹ́ rẹ̀. (Sm. 91:3) Àmọ́ kò sídìí tó fi yẹ ká kó sínú páńpẹ́ Sátánì torí pé Jèhófà ti jẹ́ ká mọ àwọn ọgbọ́nkọ́gbọ́n rẹ̀.​—2 Kọ́r. 2:11.

A lè kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn àpẹẹrẹ inú Bíbélì, ká sì tipa bẹ́ẹ̀ bọ́ lọ́wọ́ Sátánì tàbí ká má tiẹ̀ kó sí i lọ́wọ́ rárá (Wo ìpínrọ̀ 3) *

3. Kí nìdí tí Jèhófà fi jẹ́ kí àkọsílẹ̀ àwọn tó gbéra ga àtàwọn tó ṣojúkòkòrò wà nínú Bíbélì?

3 Jèhófà jẹ́ kí àkọsílẹ̀ àwọn tó gbéra ga tàbí tó ṣojúkòkòrò wà lákọọ́lẹ̀ nínú Bíbélì, ká lè kẹ́kọ̀ọ́ lára wọn, ká má bàa ṣe bíi tiwọn. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa rí i pé àwọn tó ti ń sin Jèhófà bọ̀ látọjọ́ tó ti pẹ́ náà kó sínú páńpẹ́ Sátánì yìí. Ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé kò sí bá a ṣe lè ṣe é tá ò ní kó sọ́wọ́ Sátánì? Rárá o. Ṣe ni Jèhófà jẹ́ káwọn àkọsílẹ̀ yìí wà nínú Bíbélì “gẹ́gẹ́ bí ìkìlọ̀ fún” wa. (1 Kọ́r. 10:11) Ó mọ̀ pé a lè kẹ́kọ̀ọ́ lára wọn, ká sì tipa bẹ́ẹ̀ bọ́ lọ́wọ́ Sátánì tàbí ká má tiẹ̀ kó sí i lọ́wọ́ rárá.

SÁTÁNÌ LÈ MÚ KÁ MÁA GBÉRA GA

Wo ìpínrọ̀ 4

4. Kí ló lè ṣẹlẹ̀ sí wa tá a bá ń gbéra ga?

4 Sátánì fẹ́ ká máa gbéra ga. Ó mọ̀ pé tá a bá jẹ́ kí ìgbéraga wọ̀ wá lẹ́wù, ṣe la máa fìwà jọ òun, àá sì tipa bẹ́ẹ̀ pàdánù ìyè àìnípẹ̀kun. (Òwe 16:18) Abájọ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi kìlọ̀ pé èèyàn lè “bẹ̀rẹ̀ sí í gbéra ga, kó sì ṣubú sínú ìdájọ́ tí a ṣe fún Èṣù.” (1 Tím. 3:6, 7) Kò sẹ́ni tíyẹn ò lè ṣẹlẹ̀ sí, ì bá jẹ́ pé a ṣẹ̀ṣẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ tàbí ọjọ́ pẹ́ tá a ti wà nínú ètò.

5. Kí ni Oníwàásù 7:16, 20 sọ pé ẹnì kan lè máa ṣe táá fi hàn pé ó ń gbéra ga?

5 Ẹni tó bá ń gbéra ga máa ń jọ ara ẹ̀ lójú, tara ẹ̀ nìkan ló sì máa ń rò. Tara wa nìkan ni Sátánì máa ń fẹ́ ká máa rò dípò ká máa ro ti Jèhófà, pàápàá tá a bá bára wa nínú ìṣòro. Bí àpẹẹrẹ, ṣé ẹnì kan ti fẹ̀sùn èké kàn ẹ́ rí tàbí wọ́n ti hùwà àìdáa sí ẹ lọ́nà kan rí? Sátánì máa fẹ́ kó o bínú sí Jèhófà tàbí kó o bínú sáwọn ará. Sátánì máa fẹ́ kó o ronú pé ohun kan ṣoṣo tó lè yanjú ọ̀rọ̀ náà ni pé kó o ṣe ohun tó o rò pé ó dáa lójú ara ẹ dípò kó o tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Jèhófà tó wà nínú Bíbélì.​—Ka Oníwàásù 7:16, 20.

6. Kí lo rí kọ́ látinú ìrírí arábìnrin kan lórílẹ̀-èdè Netherlands?

6 Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ arábìnrin kan lórílẹ̀-èdè Netherlands tó máa ń bínú torí kùdìẹ̀-kudiẹ àwọn ará. Nígbà tó yá, ó ronú pé òun ò lè fara dà á mọ́. Arábìnrin náà sọ pé: “Ọ̀rọ̀ náà le débi pé mi ò bá wọn ṣe mọ́, mo sì wà láyè ara mi. Mo wá sọ fún ọkọ mi pé, á dáa ká lọ síjọ míì.” Àsìkò yẹn ló wo ètò JW Broadcasting® ti March 2016. Nínú ètò yẹn, wọ́n sọ ohun tá a lè ṣe tí kùdìẹ̀-kudiẹ àwọn míì bá ń bí wa nínú. Arábìnrin náà sọ pé: “Mo rí i pé ó yẹ kí n fara balẹ̀ yẹ ara mi wò, kí n sì ronú lórí àwọn àṣìṣe mi dípò tí màá fi gbájú mọ́ kùdìẹ̀-kudiẹ àwọn míì nínú ìjọ. Ètò yẹn jẹ́ kí n rí i pé ó ṣe pàtàkì kí n máa ronú nípa Jèhófà, kí n sì gbà pé òun ló lẹ́tọ̀ọ́ láti pinnu ohun tó tọ́ àtohun tí ò tọ́, kì í ṣe èmi.” Kí la rí kọ́ nínú ìrírí yìí? Ẹ̀kọ́ ibẹ̀ ni pé ìṣòro yòówù kó o kojú, Jèhófà ni kó o máa ronú nípa ẹ̀. Bẹ̀ ẹ́ pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè máa wo àwọn míì bóun náà ṣe ń wò wọ́n. Ó ṣe tán, Baba wa ọ̀run ń rí àṣìṣe wọn, síbẹ̀ ó ń dárí jì wọ́n. Ohun tó sì fẹ́ kíwọ náà ṣe nìyẹn.​—1 Jòh. 4:20.

Wo ìpínrọ̀ 7

7. Àṣìṣe wo ni Ọba Ùsáyà ṣe, kí ló sì gbẹ̀yìn ẹ̀?

7 Ìgbéraga mú kí Ọba Ùsáyà kọtí ikún sí ìmọ̀ràn tí wọ́n fún un, ìyẹn sì mú kó ṣe ohun tí ò lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe. Kó tó dìgbà yẹn, ọ̀pọ̀ nǹkan ni Ùsáyà gbé ṣe. Bí àpẹẹrẹ, akínkanjú ni lójú ogun, ó ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìkọ́lé, ó sì ní oko rẹpẹtẹ. Kódà, Bíbélì ròyìn pé: “Ọlọ́run tòótọ́ mú kí ó láásìkí.” (2 Kíró. 26:3-7, 10) Bíbélì wá fi kún un pé: “Àmọ́, bó ṣe di alágbára tán, ìgbéraga wọ̀ ọ́ lẹ́wù débi tó fi fa àjálù bá ara rẹ̀.” Ọjọ́ pẹ́ tí Jèhófà ti pàṣẹ pé àwọn àlùfáà nìkan ló lè sun tùràrí nínú tẹ́ńpìlì. Àmọ́ Ọba Ùsáyà kọjá àyè ẹ̀, ó sì lọ sun tùràrí nínú tẹ́ńpìlì. Inú bí Jèhófà sí ohun tó ṣe yìí, ó sì fi ẹ̀tẹ̀ kọ lù ú. Bí Ùsáyà ṣe di adẹ́tẹ̀ nìyẹn títí tó fi kú.​—2 Kíró. 26:16-21.

8. Kí ni 1 Kọ́ríńtì 4:6, 7 sọ tí ò ní jẹ́ ká di agbéraga?

8 Ṣé ìgbéraga lè wọ̀ wá lẹ́wù, ká sì kọjá àyè wa bíi ti Ùsáyà? Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí José. Alàgbà táwọn èèyàn bọ̀wọ̀ fún ni, owó sì ń wọlé fún un dáadáa. Ó máa ń sọ àsọyé láwọn àpéjọ àyíká àti agbègbè, kódà àwọn alábòójútó àyíká máa ń gbàmọ̀ràn lọ́dọ̀ ẹ̀. Arákùnrin José sọ pé: “Kí n tó mọ̀, mo bẹ̀rẹ̀ sí í gbára lé òye ara mi àti ìrírí tí mo ní dípò kí n gbára lé Jèhófà. Mo ronú pé ẹni tẹ̀mí ni mí torí náà mi kì í fiyè sí ìmọ̀ràn Jèhófà àtàwọn ìkìlọ̀ rẹ̀ mọ́.” Kò pẹ́ lẹ́yìn náà ni José dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì, wọ́n sì yọ ọ́ lẹ́gbẹ́. Ọdún mélòó kan sẹ́yìn ni wọ́n gbà á pa dà, ó wá sọ pé: “Jèhófà ti jẹ́ kí n rí i pé kì í ṣe àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tá a ní ló ṣe pàtàkì, bí kò ṣe ká máa ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́.” Ká máa rántí pé ẹ̀bùn tàbí àǹfààní iṣẹ́ ìsìn èyíkéyìí tá a bá ní, Jèhófà ló fún wa. (Ka 1 Kọ́ríńtì 4:6, 7.) Torí náà, tá a bá ń gbéra ga, a ò ní wúlò fún Jèhófà.

SÁTÁNÌ LÈ MÚ KÁ MÁA ṢOJÚKÒKÒRÒ

Wo ìpínrọ̀ 9

9. Kí ni ojúkòkòrò mú kí Sátánì àti Éfà ṣe?

9 Tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó lójú kòkòrò, Sátánì Èṣù ló máa kọ́kọ́ wá sí wa lọ́kàn. Ó dájú pé Sátánì ní ọ̀pọ̀ àǹfààní tẹ́lẹ̀ torí pé ọ̀kan lára àwọn áńgẹ́lì Jèhófà ni. Àmọ́, ìyẹn ò tó o. Ó fẹ́ káwọn míì máa jọ́sìn òun, bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà nìkan ni ìjọsìn tọ́ sí. Sátánì fẹ́ ká dà bí òun, ó fẹ́ ká máa ṣojúkòkòrò, kí ohun tá a ní má sì tẹ́ wa lọ́rùn. Àtorí Éfà ló ti bẹ̀rẹ̀. Jèhófà pèsè gbogbo ohun tí Éfà àti ọkọ rẹ̀ nílò lọ́pọ̀ yanturu. Kódà, ó sọ fún wọn pé wọ́n lè jẹ “èso gbogbo igi tó wà nínú ọgbà” Édẹ́nì àyàfi ẹyọ kan. (Jẹ́n. 2:16) Síbẹ̀, Sátánì mú kí ojú Éfà wọ èso tí Ọlọ́run kà léèwọ̀ náà, ìyẹn sì mú kó ronú pé òun gbọ́dọ̀ jẹ nínú ẹ̀. Éfà ò mọyì gbogbo ohun tí Jèhófà ṣe fún un, ṣe ló tún ń nàgà fún ohun tí ò lẹ́tọ̀ọ́ sí. Àwa náà mọ ohun tíyẹn yọrí sí. Éfà dẹ́ṣẹ̀, ó sì kú nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín.​—Jẹ́n. 3:6, 19.

Wo ìpínrọ̀ 10

10. Báwo ni ojúkòkòrò ṣe mú kí Ọba Dáfídì dẹ́ṣẹ̀?

10 Ojúkòkòrò mú kí Ọba Dáfídì gbàgbé gbogbo ohun tí Jèhófà ṣe fún un. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà dá a lọ́lá, ó mú kó gbayì, ó sì mú kó ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá rẹ̀. Kódà, Dáfídì fúnra ẹ̀ sọ pé àwọn ohun tí Jèhófà ṣe fún òun “pọ̀ ju ohun tí [òun] lè ròyìn!” (Sm. 40:5) Àmọ́ ìgbà kan wà tí Dáfídì gbàgbé àwọn nǹkan tí Jèhófà ṣe fún un. Kò ní ìtẹ́lọ́rùn, ohun tó ní ò sì tó o. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Dáfídì ní ju ìyàwó kan lọ, ó jẹ́ kí ọkàn ẹ̀ fà sí ìyàwó oníyàwó. Bátí-ṣébà lorúkọ obìnrin náà, Ùráyà ọmọ Hétì sì lọkọ ẹ̀. Dáfídì bá obìnrin náà sùn, ó sì lóyún. Àfi bíi pé ìyẹn nìkan ò tó, Dáfídì tún ṣètò bí wọ́n ṣe pa ọkọ obìnrin náà! (2 Sám. 11:2-15) Ẹ gbọ́ ná, ṣé Dáfídì rò pé Jèhófà ò rí òun ni? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọjọ́ pẹ́ tí Dáfídì ti ń fòótọ́ ọkàn sin Jèhófà, ó ṣojúkòkòrò, ó sì jìyà ẹ̀. Àmọ́ nígbà tó yá, Dáfídì jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀, ó sì ronú pìwà dà. Ẹ wo bí inú ẹ̀ ṣe máa dùn tó pé Jèhófà dárí ji òun, ó sì fi ojúure hàn sóun!​—2 Sám. 12:7-13.

11. Kí ni Éfésù 5:3, 4 sọ tó máa jẹ́ ká yẹra fún ojúkòkòrò?

11 Kí la rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Dáfídì? Tá a bá mọyì ohun tí Jèhófà ṣe fún wa, tá a sì ń dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀ nígbà gbogbo, a ò ní ṣojúkòkòrò. (Ka Éfésù 5:3, 4.) Yàtọ̀ síyẹn, a gbọ́dọ̀ ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú ohunkóhun tá a bá ní. A sábà máa ń kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa pé kí wọ́n máa ronú lórí àwọn nǹkan tí Jèhófà ṣe fún wọn, kí wọ́n sì dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀. Tẹ́nì kan bá ń ṣe bẹ́ẹ̀ lójoojúmọ́, tó bá máa fi tó ọ̀sẹ̀ kan, ó kéré tán, á ti dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún ohun méje ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. (1 Tẹs. 5:18) Ṣé àwa náà máa ń ṣe bẹ́ẹ̀? Wọ́n ṣáà sọ pé, ẹni bá mọnú rò, á mọpẹ́ dá. Torí náà, tó o bá ń ronú lórí gbogbo ohun tí Jèhófà ṣe fún ẹ, ìyẹn á jẹ́ kó o máa dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀. Téèyàn bá moore, á ní ìtẹ́lọ́rùn. Tó bá sì ní ìtẹ́lọ́rùn, kò ní ṣojúkòkòrò.

Wo ìpínrọ̀ 12

12. Kí ni ojúkòkòrò mú kí Júdásì Ìsìkáríọ́tù ṣe?

12 Ojúkòkòrò mú kí Júdásì Ìsìkáríọ́tù dalẹ̀ Jésù. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, èèyàn dáadáa ni tẹ́lẹ̀. (Lúùkù 6:13, 16) Ìyẹn ló mú kí Jésù yàn án ní àpọ́sítélì. Kò sí àní-àní pé Júdásì Ìsìkáríọ́tù kúnjú ìwọ̀n, ó sì ṣeé fọkàn tán torí òun ni Jésù ní kó máa bójú tó àpótí owó. Owó inú àpótí yẹn ni Jésù àtàwọn àpọ́sítélì fi ń bójú tó ohun tí wọ́n nílò lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Ṣe lowó náà dà bí ọrẹ kárí ayé tá à ń ṣe lónìí. Àmọ́ nígbà tó yá, Júdásì bẹ̀rẹ̀ sí í jalè láìka àwọn ìkìlọ̀ tí Jésù ti ṣe nípa ojúkòkòrò. (Máàkù 7:22, 23; Lúùkù 11:39; 12:15) Síbẹ̀, Júdásì kọtí ikún sáwọn ìkìlọ̀ yẹn.

13. Ìgbà wo ló hàn sí àwọn yòókù pé olójúkòkòrò ni Júdásì?

13 Kò pẹ́ sígbà tí wọ́n máa pa Jésù ni ohun kan ṣẹlẹ̀ tó mú kó hàn gbangba sáwọn yòókù pé olójúkòkòrò ni Júdásì. Lọ́jọ́ tá à ń sọ yìí, Símónì adẹ́tẹ̀ ló gba Jésù àtàwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ títí kan Màríà àti Màtá lálejò. Nígbà tí wọ́n ń jẹun lọ́wọ́, Màríà dìde, ó sì da òróró onílọ́fínńdà tí owó ẹ̀ wọ́n gan-an sórí Jésù. Inú bí Júdásì àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn yòókù. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn yòókù ronú pé àwọn ò bá ta òróró yẹn káwọn sì lo owó ẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Àmọ́ ohun tó wà lọ́kàn Júdásì yàtọ̀ pátápátá síyẹn. Bíbélì sọ pé “olè ni” àti pé ṣe ló ń wá bó ṣe máa jí owó inú àpótí náà. Nígbà tó yá, ojúkòkòrò mú kí Júdásì dalẹ̀ Jésù, ó sì ta Jésù fún iye tí wọ́n fi ń ra ẹrú lásánlàsàn.​—Jòh. 12:2-6; Mát. 26:6-16; Lúùkù 22:3-6.

14. Báwo ni tọkọtaya kan ṣe fi ìmọ̀ràn tó wà nínú Lúùkù 16:13 sílò?

14 Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ pé: “Ẹ ò lè jẹ́ ẹrú Ọlọ́run àti Ọrọ̀.” (Ka Lúùkù 16:13.) Òótọ́ yìí ò sì yí pa dà títí dòní olónìí. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ tọkọtaya kan lórílẹ̀-èdè Ròmáníà tó fi ìmọ̀ràn yìí sílò. Wọ́n ríṣẹ́ sí orílẹ̀-èdè kan tí nǹkan ti rọ̀ṣọ̀mù. Wọ́n sọ pé: “Torí pé a jẹ báǹkì ní gbèsè tó pọ̀ gan-an, a ronú pé Jèhófà ló mú kí iṣẹ́ yìí bọ́ sí i.” Àmọ́ ìṣòro kan wà níbẹ̀. Iṣẹ́ yẹn ò ní jẹ́ kí wọ́n ráyè sin Jèhófà bó ṣe yẹ. Lẹ́yìn tí wọ́n ka àpilẹ̀kọ náà “Máa Bá A Nìṣó Láti Jẹ́ Adúróṣinṣin Pẹ̀lú Ọkàn Tó Ṣọ̀kan” nínú Ilé Ìṣọ́ August 15, 2008, wọ́n dórí ìpinnu. Wọ́n sọ pé: “Tó bá jẹ́ torí owó la fi fẹ́ lọ sórílẹ̀-èdè míì, á jẹ́ pé a ka owó sí pàtàkì ju àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà lọ nìyẹn. Ó dá wa lójú pé tá a bá gba iṣẹ́ yẹn, ìgbàgbọ́ wa máa jó rẹ̀yìn.” Torí náà, wọn ò gba iṣẹ́ náà. Kí ló wá ṣẹlẹ̀? Ọkọ náà rí iṣẹ́ tó kájú àìní wọn lórílẹ̀-èdè tí wọ́n ń gbé. Ìyàwó náà sọ pé: “Kò sígbà tí Jèhófà kì í ran àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́.” Inú tọkọtaya yìí dùn pé àwọn fi Jèhófà ṣíwájú dípò owó.

MÁ ṢE JẸ́ KÍ PÁŃPẸ́ SÁTÁNÌ MÚ Ẹ

15. Kí ló jẹ́ kó dá wa lójú pé a lè bọ́ mọ́ Sátánì lọ́wọ́?

15 Kí la lè ṣe tá a bá kíyè sí i pé ìgbéraga ti ń wọ̀ wá lẹ́wù tàbí pé a ti ń ṣojúkòkòrò? Ṣe ló yẹ ká tètè ṣàtúnṣe! Pọ́ọ̀lù sọ pé àwọn tí Èṣù ti ‘mú láàyè’ lè jàjà bọ́ lọ́wọ́ ìdẹkùn rẹ̀. (2 Tím. 2:26) Ó ṣe tán, Dáfídì gba ìbáwí tí Nátánì fún un, ó ronú pìwà dà, ó sì ṣe ohun tó mú kí àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà pa dà gún régé. Má gbàgbé pé Jèhófà lágbára ju Sátánì lọ. Torí náà, tó o bá jẹ́ kí Jèhófà ràn ẹ́ lọ́wọ́, wàá bọ́ lọ́wọ́ ìdẹkùn tàbí páńpẹ́ Sátánì.

16. Kí ni ò ní jẹ́ ká kó sínú páńpẹ́ Sátánì?

16 Ohun tó dáa jù ni pé ká má tiẹ̀ kó sọ́wọ́ Sátánì rárá dípò ká máa wá bá a ṣe máa bọ́ lọ́wọ́ ìdẹkùn rẹ̀. Àmọ́ o, Jèhófà nìkan ló lè ràn wá lọ́wọ́ tá ò fi ní kó sí i lọ́wọ́. Torí náà, má ṣe dẹra nù, ṣe ni kó o wà lójúfò! Rántí pé Sátánì ti fi ìgbéraga àti ojúkòkòrò dẹkùn mú àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà kan, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọjọ́ pẹ́ tí wọ́n ti ń sìn ín. Torí náà, máa bẹ Jèhófà lójoojúmọ́ pé kó jẹ́ kó o mọ̀ bóyá o ti fẹ́ máa gbéra ga tàbí ṣojúkòkòrò. (Sm. 139:23, 24) Má jẹ́ kí Sátánì rí ẹ mú!

17. Kí ló máa tó ṣẹlẹ̀ sí Èṣù ọ̀tá wa?

17 Ọjọ́ pẹ́ tí Sátánì ti ń dọdẹ àwa ìránṣẹ́ Jèhófà. Àmọ́ láìpẹ́, wọ́n máa jù ú sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀, níkẹyìn wọ́n á pa á run. (Ìfi. 20:1-3, 10) Ṣe ló ń ṣe wá bíi pé kọ́jọ́ náà ti dé. Àmọ́ títí dìgbà yẹn, ẹ jẹ́ ká máa wà lójúfò ká má bàa kó sínú páńpẹ́ rẹ̀. Ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe kí Sátánì má bàa fi ìgbéraga tàbí ojúkòkòrò dẹkùn mú ẹ. Torí náà, pinnu pé wàá “dojú ìjà kọ Èṣù.” Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ‘ó máa sá kúrò lọ́dọ̀ rẹ.’​—Jém. 4:7.

ORIN 127 Irú Èèyàn Tó Yẹ Kí N Jẹ́

^ ìpínrọ̀ 5 A lè fi Sátánì wé ọdẹ kan tó gbówọ́ gan-an. Gbogbo ọ̀nà ló ń wá láti dẹkùn mú wa láìka bó ṣe pẹ́ tó tá a ti ń sin Jèhófà. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò bí Sátánì ṣe ń lo ìgbéraga àti ojúkòkòrò láti ba àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́. Àá tún kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn kan tí wọ́n gbéra ga, tí wọ́n sì ṣojúkòkòrò, àá sì rí ohun tá a lè ṣe tá ò fi ní dà bíi wọn.

^ ìpínrọ̀ 2 ÀLÀYÉ Ọ̀RỌ̀: Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa ìgbéraga, ìyẹn ni pé kéèyàn máa ronú pé òun sàn ju àwọn míì lọ. A tún máa sọ̀rọ̀ nípa ojúkòkòrò, ìyẹn kéèyàn máa wá bí á ṣe ní owó rẹpẹtẹ, kó má ní àmójúkúrò nínú àwọn nǹkan tara títí kan ìbálòpọ̀. Ó tún kan kéèyàn máa wá ipò lójú méjèèjì.

^ ìpínrọ̀ 53 ÀWÒRÁN: Ìgbéraga ò jẹ́ kí arákùnrin kan gba ìmọ̀ràn táwọn alàgbà fún un látinú Bíbélì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé arábìnrin kan ti ra nǹkan tó pọ̀, àwọn nǹkan míì ṣì tún ń wọ̀ ọ́ lójú.

^ ìpínrọ̀ 55 ÀWÒRÁN: Ìgbéraga ló mú kí áńgẹ́lì kan àti Ọba Ùsáyà ṣìwà hù. Ojúkòkòrò ló mú kí Éfà jẹ èso igi tí Ọlọ́run kà léèwọ̀, òun ló mú kí Dáfídì bá Bátí-ṣébà ìyàwó oníyàwó sùn, òun náà ló sì mú kí Júdásì máa jalè.