Ǹjẹ́ O Mọ̀?
Nígbà ayé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, báwo ni wọ́n ṣe ń ka oṣù àti ọdún?
NÍGBÀ táwọn ọmọ Ísírẹ́lì dé Ilẹ̀ Ìlérí, ìgbà tí wọ́n bá ń túlẹ̀ tí wọ́n sì ń gbin nǹkan ni wọ́n máa ń bẹ̀rẹ̀ sí í ka ọdún, èyí sì sábà máa ń jẹ́ oṣù September tàbí October lórí kàlẹ́ńdà wa.
Oṣù méjìlá ló máa ń wà nínú ọdún tí wọ́n ń fi òṣùpá kà, ọjọ́ mọ́kàndínlọ́gbọ̀n (29) tàbí ọgbọ̀n (30) ọjọ́ ló sì máa ń wà nínú oṣù kọ̀ọ̀kan. Iye ọjọ́ tó wà nínú ọdún tí wọ́n ń fi òṣùpá kà kì í tó èyí tó wà nínú ọdún tí wọ́n ń fi oòrùn kà. Wọ́n ti lo onírúurú ọ̀nà láti mú kí kàlẹ́ńdà méjèèjì yìí bára mu. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé wọ́n máa ń fi àwọn ọjọ́ tàbí oṣù kan kún un kí ọdún tó tẹ̀ lé e tó bẹ̀rẹ̀, kí kàlẹ́ńdà méjèèjì lè bára mu. Ìyẹn máa ń jẹ́ kí kàlẹ́ńdà náà bá àwọn oṣù tí wọ́n máa ń gbin nǹkan tí wọ́n sì máa ń kórè mu.
Nígbà ayé Mósè, Ọlọ́run sọ fún àwọn èèyàn ẹ̀ pé oṣù Ábíbù tàbí Nísàn ni kí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí í ka ọdún wọn, ìyẹn sì máa ń bọ́ sí oṣù March tàbí April lórí kàlẹ́ńdà wa. (Ẹ́kís. 12:2; 13:4) Àjọyọ̀ tí wọ́n máa ń ṣe lóṣù yẹn máa ń bọ́ sígbà ìkórè ọkà báálì.—Ẹ́kís. 23:15, 16.
Ọ̀mọ̀wé kan tó ń jẹ́ Emil Schürer tó kọ ìwé The History of the Jewish People in the Age of Jesus Christ, (175 Ṣ.S.K.–135 S.K.) sọ pé: “Ó máa ń rọrùn láti mọ ìgbà tí wọ́n máa fi oṣù míì kún kàlẹ́ńdà náà. Ìgbà tí òṣùpá bá dégbá ní oṣù Nísàn (Nísàn 14) ni wọ́n máa ń ṣe Àjọyọ̀ Ìrékọjá, wọ́n sì gbọ́dọ̀ ṣe é ní ọjọ́ kejì ọjọ́ tí ọ̀sán àti òru bá gùn dọ́gba nígbà ìrúwé . . . Tí ọdún bá ti ń parí lọ, tí wọ́n wá kíyè sí i pé ọjọ́ Ìrékọjá yẹn máa ṣáajú ọjọ́ tí ọ̀sán àti òru máa gùn dọ́gba, wọ́n máa fi oṣù kẹtàlá kún ọdún yẹn kí oṣù Nísàn tó bẹ̀rẹ̀.”
Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń tẹ̀ lé ìlànà yìí láti fi mọ ọjọ́ tí Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa máa bọ́ sí. Ó máa ń jẹ́ oṣù March tàbí April lórí kàlẹ́ńdà wa, ó sì máa ń jẹ́ Nísàn 14 lórí kàlẹ́ńdà àwọn Hébérù. Ọ̀pọ̀ oṣù ṣáájú ọjọ́ náà ni ètò Ọlọ́run ti máa ń sọ déètì náà fún gbogbo ìjọ kárí ayé. *
Ṣùgbọ́n báwo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe máa ń mọ ìgbà tí oṣù kan máa parí àti ìgbà tí oṣù tuntun máa bẹ̀rẹ̀? Tó bá jẹ́ àkókò wa yìí ni, wàá kàn wo kàlẹ́ńdà bóyá ti orí bébà tàbí èyí tó wà lórí fóònù. Àmọ́ lákòókò tí wọ́n ń kọ Bíbélì, kò sóhun tó jọ bẹ́ẹ̀.
Nígbà Ìkún Omi, ọgbọ̀n (30) ọjọ́ ló máa ń wà nínú oṣù kan. (Jẹ́n. 7:11, 24; 8:3, 4) Àmọ́ nígbà ayé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wọn kì í fi ọgbọ̀n ọjọ́ ka oṣù lórí kàlẹ́ńdà wọn, ìgbà tí òṣùpá bá yọ ni oṣù tuntun máa ń bẹ̀rẹ̀. Ìyẹn sì máa ń jẹ́ ọjọ́ mọ́kàndínlọ́gbọ̀n tàbí ọgbọ̀n ọjọ́ lẹ́yìn tí oṣù ti tẹ́lẹ̀ bẹ̀rẹ̀.
Ìgbà kan wà tí Dáfídì àti Jónátánì ń sọ̀rọ̀ nípa oṣù, wọ́n sọ pé: “Ọ̀la ni òṣùpá tuntun.” (1 Sám. 20:5, 18) Torí náà, ó jọ pé nígbà tó fi máa di 1100 Ṣ.S.K., wọ́n ti ń mọ iye ọjọ́ tó máa wà nínú oṣù kọ̀ọ̀kan káwọn oṣù náà tó bẹ̀rẹ̀. Báwo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe máa ń mọ ìgbà tí oṣù tuntun máa bẹ̀rẹ̀? Ìwé kan tó ń jẹ́ Mishnah tí wọ́n kọ òfin àti àṣà àwọn Júù sí sọ ohun tí wọ́n máa ń ṣe. Ó sọ pé lẹ́yìn táwọn Júù pa dà láti ìgbèkùn ní Bábílónì, ìgbìmọ̀ Sànhẹ́dírìn (ìyẹn ilé ẹjọ́ gíga ti àwọn Júù) ló máa ń bójú tó ọ̀rọ̀ náà. Ìgbìmọ̀ ilé ẹjọ́ náà máa ń ṣèpàdé ní ọgbọ̀n ọjọ́ oṣù, bí wọ́n sì ṣe máa ṣe é nìyẹn ní gbogbo oṣù méje tí wọ́n fi ń ṣe oríṣiríṣi àjọyọ̀. Ìgbìmọ̀ yìí ló máa ń pinnu ọjọ́ tí oṣù tó tẹ̀ lé e máa bẹ̀rẹ̀. Báwo ni wọ́n ṣe ń ṣèpinnu náà?
Wọ́n máa ń ní káwọn ọkùnrin kan dúró sórí àpáta ńlá lágbègbè Jerúsálẹ́mù. Wọ́n máa ń tẹjú mọ́ ojú ọ̀run lálẹ́ kí wọ́n lè tètè rí i tí òṣùpá tuntun bá ti lé. Tí wọ́n bá ti rí i, wọ́n máa ń tètè sọ fún ìgbìmọ̀ Sànhẹ́dírìn. Tí ìgbìmọ̀ náà bá ti rí ẹ̀rí tó dájú pé òṣùpá tuntun ti lé, wọ́n á kéde pé oṣù tuntun ti bẹ̀rẹ̀. Tó bá ṣẹlẹ̀ pé ìkùukùu ò jẹ́ káwọn ọkùnrin náà rí
òṣùpá tuntun náà ńkọ́? Wọ́n á kéde pé ọgbọ̀n ọjọ́ ló wà nínú oṣù tí wọ́n wà yẹn, oṣù tuntun á sì bẹ̀rẹ̀ lọ́jọ́ kejì.Ìwé Mishnah sọ pé iná ni ìgbìmọ̀ Sànhẹ́dírìn máa ń dá sórí Òkè Ólífì nítòsí Jerúsálẹ́mù láti fi kéde pé oṣù tuntun ti bẹ̀rẹ̀. Wọ́n tún máa ń dáná sórí àwọn òkè ńlá míì káàkiri ilẹ̀ Ísírẹ́lì kí gbogbo èèyàn lè mọ̀. Nígbà tó yá, àwọn òjíṣẹ́ ni wọ́n máa ń rán láti sọ fáwọn èèyàn. Torí náà, àwọn Júù tó wà ní Jerúsálẹ́mù àti gbogbo ilẹ̀ Ísírẹ́lì títí kan àwọn ìlú tó wà lágbègbè ibẹ̀ máa ń mọ̀ tí oṣù tuntun bá ti bẹ̀rẹ̀. Ìyẹn ló sì máa jẹ́ kí gbogbo wọn jọ ṣe àwọn àjọyọ̀ àtìgbàdégbà lásìkò kan náà.
Àtẹ tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ kó o túbọ̀ mọ bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ń ka oṣù, ìgbà tí wọ́n ń ṣe àwọn àjọyọ̀ wọn àti ìgbà òjò pẹ̀lú ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn.
^ Wo Ilé-Ìṣọ́nà February 15, 1990, ojú ìwé 15 àti “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” nínú Ile-Iṣọ Na December 15, 1977.