Àwọn Àpilẹ̀kọ Míì Nínú Ilé Ìṣọ́
Ọ̀pọ̀ àwọn ará ló máa ń lo JW Library® láti múra ìpàdé sílẹ̀, wọ́n sì máa ń mọyì bó ṣe máa ń gbé wọn lọ sí àpilẹ̀kọ Ilé Ìṣọ́ kọ̀ọ̀kan tá a máa kẹ́kọ̀ọ́. Àmọ́ Ilé Ìṣọ́ tá à ń lò fún ìkẹ́kọ̀ọ́ tún máa ń ní àwọn àpilẹ̀kọ míì tá a lè kẹ́kọ̀ọ́ nínú ẹ̀ àmọ́ tá à kì í kà nípàdé. Torí náà, báwo lo ṣe lè rí àwọn àpilẹ̀kọ yìí lórí JW Library, kó o sì jàǹfààní nínú ẹ̀?
Ní ìsàlẹ̀ àpilẹ̀kọ Ilé Ìṣọ́ kọ̀ọ̀kan tá a máa kẹ́kọ̀ọ́, a máa rí “Àfikún.” Lábẹ́ àfikún yẹn, tẹ “Àwọn àpilẹ̀kọ míì nínú ìtẹ̀jáde yìí.” Wo àwọn àkòrí tó wà nínú ìwé yẹn àtàwọn nọ́ńbà àpilẹ̀kọ náà. Lẹ́yìn náà, tẹ àwọn àpilẹ̀kọ míì tó o fẹ́ kà nínú Ilé Ìṣọ́ yẹn.
Tó o bá ti wà ní Ojú Ìwé Àkọ́kọ́ lórí JW Library, lọ sí “Ohun Tuntun” kó o sì wa Ilé Ìṣọ́ tuntun tó bá wà níbẹ̀ jáde. Lẹ́yìn náà, ṣí Ilé Ìṣọ́ tó o wà jáde, lọ sí apá ohun tó wà nínú ìwé yìí kó o lè jàǹfààní nínú gbogbo àpilẹ̀kọ tó wà níbẹ̀.