Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 25

Ẹ̀yin Alàgbà, Ẹ Kẹ́kọ̀ọ́ Lára Gídíónì

Ẹ̀yin Alàgbà, Ẹ Kẹ́kọ̀ọ́ Lára Gídíónì

“Àkókò ò ní tó tí n bá ní kí n máa sọ̀rọ̀ nípa Gídíónì.”​—HÉB. 11:32.

ORIN 124 Jẹ́ Adúróṣinṣin

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ a

1. Àǹfààní wo ni 1 Pétérù 5:2 sọ pé àwọn alàgbà ní?

 ÀWA èèyàn Jèhófà ṣeyebíye lójú ẹ̀, àwọn alàgbà ló sì yàn pé kí wọ́n máa bójú tó wa. Àwọn ọkùnrin tó ń sin Jèhófà tọkàntọkàn yìí mọyì àǹfààní tí wọ́n ní láti máa bójú tó àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wọn, wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ kára láti jẹ́ “olùṣọ́ àgùntàn . . . tí á máa bójú tó wọn dáadáa.” (Jer. 23:4; ka 1 Pétérù 5:2.) A mà dúpẹ́ o pé a nírú àwọn alàgbà yìí láwọn ìjọ wa!

2. Kí ló lè ṣẹlẹ̀ tó máa dán alàgbà kan wò?

2 Àwọn alàgbà máa ń bá ọ̀pọ̀ ìṣòro pàdé bí wọ́n ṣe ń ṣiṣẹ́ tí Jèhófà gbé fún wọn. Ká sòótọ́, kéèyàn máa bójú tó ìjọ kì í ṣe iṣẹ́ kékeré. Arákùnrin Tony tó jẹ́ alàgbà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ní láti kọ́ bó ṣe yẹ kó mọ̀wọ̀n ara ẹ̀ tó bá di pé kó gba àwọn iṣẹ́ kan nínú ètò Ọlọ́run. Ó ní: “Nígbà tí àjàkálẹ̀ àrùn kòrónà bẹ̀rẹ̀, iṣẹ́ tí mò ń ṣe nínú ìjọ pọ̀ sí i torí èmi ni wọ́n ní kí n máa ṣètò ìpàdé àti iṣẹ́ ìwàásù fáwọn ará. Àmọ́ bí mo ṣe ń parí iṣẹ́ kan ni òmíì ń dé. Kí n tó mọ̀, mi ò fi bẹ́ẹ̀ ráyè ka Bíbélì mọ́, mi ò dá kẹ́kọ̀ọ́ déédéé mọ́, mi ò sì fi bẹ́ẹ̀ ráyè gbàdúrà mọ́.” Ọ̀tọ̀ lohun tó ṣẹlẹ̀ sí alàgbà kan tó ń jẹ́ Ilir lórílẹ̀-èdè Kosovo. Nígbà tí wọ́n ń jagun lórílẹ̀-èdè wọn, kò rọrùn fún un láti ṣe ohun tí ètò Ọlọ́run sọ fún wọn. Ó sọ pé: “Nígbà tí ẹ̀ka ọ́fíìsì ní kí n lọ ran àwọn ará lọ́wọ́ ní agbègbè kan tó léwu, ìgbà yẹn ni mo mọ̀ pé mi ò nígboyà. Ẹ̀rù bà mí, kò sì jọ pé ohun tí wọ́n ní kí n ṣe bọ́gbọ́n mu.” Bákan náà, kò rọrùn fún Arákùnrin Tim tó jẹ́ míṣọ́nnárì nílẹ̀ Éṣíà láti máa ṣe gbogbo iṣẹ́ tó yẹ kó ṣe lójoojúmọ́. Ó sọ pé: “Nígbà míì, ó máa ń rẹ̀ mí gan-an débi pé mi kì í lókun láti bójú tó àwọn ará bó ṣe yẹ.” Torí náà, kí ló máa ran ẹ̀yin alàgbà lọ́wọ́ tírú ìṣòro yìí bá dé bá yín?

3. Àǹfààní wo ni gbogbo wa máa rí tá a bá kẹ́kọ̀ọ́ lára Gídíónì onídàájọ́?

3 Ẹ̀yin alàgbà lè kẹ́kọ̀ọ́ lára Gídíónì onídàájọ́. (Héb. 6:12; 11:32) Ó dáàbò bo àwọn èèyàn Ọlọ́run, ó sì tún bójú tó wọn. (Oníd. 2:16; 1 Kíró. 17:6) Bíi ti Gídíónì, Jèhófà ti yan àwọn alàgbà pé kí wọ́n máa bójú tó àwọn èèyàn òun lásìkò tí nǹkan le gan-an yìí. (Ìṣe 20:28; 2 Tím. 3:1) Torí náà, ẹ lè kẹ́kọ̀ọ́ lára Gídíónì nípa bó ṣe mọ̀wọ̀n ara ẹ̀, bó ṣe nírẹ̀lẹ̀ àti bó ṣe jẹ́ onígbọràn. Iṣẹ́ tí Jèhófà gbé fún un jẹ́ kó mọ̀ bóyá òun ní ìfaradà tàbí òun ò ní. Bóyá alàgbà ni wá tàbí a kì í ṣe alàgbà, gbogbo wa ló yẹ ká mọyì iṣẹ́ takuntakun táwọn alàgbà ń ṣe nínú ìjọ, ká sì máa ràn wọ́n lọ́wọ́.​—Héb. 13:17.

TÍ KÒ BÁ RỌRÙN FÚN Ẹ LÁTI MỌ̀WỌ̀N ARA Ẹ, KÓ O SÌ NÍRẸ̀LẸ̀

4. Báwo ni Gídíónì ṣe fi hàn pé òun mọ̀wọ̀n ara òun, òun sì nírẹ̀lẹ̀?

4 Gídíónì mọ̀wọ̀n ara ẹ̀, ó sì nírẹ̀lẹ̀. b Nígbà tí áńgẹ́lì Jèhófà sọ fún Gídíónì pé òun ni Jèhófà yàn pé kó lọ gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Mídíánì, ìrẹ̀lẹ̀ tó ní mú kó sọ pé: “Agbo ilé mi ló kéré jù ní Mánásè, èmi ló sì kéré jù ní ilé bàbá mi.” (Oníd. 6:15) Ó rò pé òun ò kúnjú ìwọ̀n láti ṣiṣẹ́ náà, àmọ́ Jèhófà mọ̀ pé ó lè ṣe é. Torí náà, Jèhófà ràn án lọ́wọ́, Gídíónì sì ṣe iṣẹ́ náà láṣeyọrí.

5. Kí ló lè ṣẹlẹ̀ tó lè mú kó má rọrùn fún alàgbà kan láti nírẹ̀lẹ̀, kó sì mọ̀wọ̀n ara ẹ̀?

5 Ó yẹ kẹ́yin alàgbà máa fi hàn pé ẹ mọ̀wọ̀n ara yín, ẹ sì nírẹ̀lẹ̀ nínú gbogbo ohun tẹ́ ẹ bá ń ṣe. (Míkà 6:8; Ìṣe 20:18, 19) Wọn kì í fọ́nnu torí àwọn nǹkan tí wọ́n gbé ṣe, wọn kì í sì í ro ara wọn pin tí wọ́n bá ṣàṣìṣe. Síbẹ̀, àwọn nǹkan kan lè ṣẹlẹ̀ tó máa dán alàgbà kan wò. Bí àpẹẹrẹ, ó lè gba iṣẹ́ tó pọ̀, kó wá ṣòro fún un láti ṣe àwọn iṣẹ́ náà tán. Wọ́n sì lè ṣàríwísí bó ṣe bójú tó àwọn iṣẹ́ kan tàbí kí wọ́n yìn ín pé ó ṣe àwọn iṣẹ́ kan dáadáa. Torí náà, kí lẹ̀yin alàgbà lè kọ́ lára Gídíónì tírú nǹkan báyìí bá ṣẹlẹ̀ sí yín?

Bíi tí Gídíónì, alàgbà tó mọ̀wọ̀n ara ẹ̀ máa ń ní káwọn ẹlòmíì ran òun lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, ó lè ní kí ẹlòmíì máa bá òun bójú tó iṣẹ́ ìwàásù níbi tá à ń pàtẹ ìwé wa sí (Wo ìpínrọ̀ 6)

6. Kí lẹ̀yin alàgbà lè kọ́ lára Gídíónì nípa bó ṣe yẹ kẹ́ ẹ mọ̀wọ̀n ara yín? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

6 Ní káwọn ẹlòmíì ràn ẹ́ lọ́wọ́. Ẹni tó mọ̀wọ̀n ara ẹ̀ mọ̀ pé àwọn nǹkan kan wà tóun ò lè ṣe. Nígbà tí Jèhófà gbéṣẹ́ fún Gídíónì, ó ní káwọn ẹlòmíì wá ran òun lọ́wọ́. (Oníd. 6:27, 35; 7:24) Ohun táwọn alàgbà tó gbọ́n náà máa ń ṣe nìyẹn. Tony tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Torí bí wọ́n ṣe tọ́ mi dàgbà, gbogbo iṣẹ́ tí wọ́n bá gbé fún mi ni mo máa ń gbà, bẹ́ẹ̀ sì rèé, mi ò lè ṣe gbogbo ẹ̀ tán. Torí náà, mo ní kí èmi àtìyàwó mi jọ sọ̀rọ̀ nípa béèyàn ṣe lè mọ̀wọ̀n ara ẹ̀ nígbà ìjọsìn ìdílé wa, kó sì sọ bí mo ṣe ń ṣe sí. Mo tún lọ sórí ìkànnì jw.org láti wo fídíò Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Jésù​—Dá Àwọn Míì Lẹ́kọ̀ọ́, Fọkàn Tán Wọn, Mú Kí Wọ́n Gbára Dì.” Lẹ́yìn náà, Tony ní káwọn arákùnrin míì bẹ̀rẹ̀ sí í ran òun lọ́wọ́ kíṣẹ́ náà lè rọrùn. Kí nìyẹn wá yọrí sí? Tony sọ pé: “Gbogbo iṣẹ́ tó wà nínú ìjọ là ń bójú tó, mo sì túbọ̀ ń ráyè ka Bíbélì, mò ń dá kẹ́kọ̀ọ́, mo sì ń gbàdúrà.”

7. Báwo lẹ̀yin alàgbà ṣe lè fara wé Gídíónì tí wọ́n bá ṣàríwísí yín? (Jémíìsì 3:13)

7 Má gbaná jẹ tí wọ́n bá ṣàríwísí ẹ. Nǹkan míì tó lè dán ẹ̀yin alàgbà wò ni tí wọ́n bá ṣàríwísí yín. Tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, àpẹẹrẹ Gídíónì tún máa ràn yín lọ́wọ́. Gídíónì mọ̀ pé òun kì í ṣe ẹni pípé, torí náà nígbà táwọn ọmọ Éfúráímù bínú sí i gidigidi, kò gbaná jẹ, kò sì fìbínú sọ̀rọ̀ sí wọn. (Oníd. 8:1-3) Ó fi hàn pé òun nírẹ̀lẹ̀ torí ó fara balẹ̀ tẹ́tí sí wọn, ó sì fọgbọ́n yanjú ọ̀rọ̀ náà. Àwọn alàgbà tó gbọ́n máa ń fara wé Gídíónì. Táwọn èèyàn bá ṣàríwísí wọn, wọ́n máa ń fara balẹ̀ tẹ́tí sí wọn, wọn kì í sì í gbaná jẹ. (Ka Jémíìsì 3:13.) Ohun tí wọ́n ń ṣe yìí ló ń mú kí àlàáfíà wà nínú ìjọ.

8. Kí ló yẹ kẹ́yin alàgbà ṣe táwọn èèyàn bá yìn yín? Sọ àpẹẹrẹ kan.

8 Jèhófà ni kó o fìyìn fún. Nígbà táwọn èèyàn ń yin Gídíónì torí pé ó ṣẹ́gun àwọn ará Mídíánì, Jèhófà ló fìyìn fún. (Oníd. 8:22, 23) Báwo lẹ̀yin alàgbà ṣe lè fara wé Gídíónì? Ẹ lè ṣe bẹ́ẹ̀ tẹ́ ẹ bá ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé Jèhófà ló ń ràn yín lọ́wọ́ láti ṣe àwọn nǹkan tẹ́ ẹ̀ ń ṣe. (1 Kọ́r. 4:6, 7) Bí àpẹẹrẹ, tí wọ́n bá gbóríyìn fún alàgbà kan torí àsọyé tó sọ, ó yẹ kó jẹ́ káwọn ará mọ̀ pé inú Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lòun ti mú ohun tóun sọ tàbí kó sọ pé àwọn ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí ètò Ọlọ́run ń fún wa ló ran òun lọ́wọ́. Ó yẹ kẹ́yin alàgbà máa kíyè sára tẹ́ ẹ bá ń kọ́ni, kó má jẹ́ pé ẹ̀yin làwọn èèyàn á máa kan sárá sí, dípò kí wọ́n fògo fún Jèhófà. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Arákùnrin Timothy. Nígbà tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di alàgbà, ó fẹ́ràn kó máa sọ àsọyé. Ó sọ pé: “Tí mo bá ń sọ àsọyé, ọ̀rọ̀ ìbẹ̀rẹ̀ mi máa ń gùn, àwọn àpèjúwe kàbìtì-kàbìtì ni mo sì máa ń lò. Ìyẹn máa ń jẹ́ káwọn ará yìn mí, dípò kí wọ́n rí i pé inú Bíbélì ni mo ti mú ohun tí mo sọ, kí wọ́n sì fògo fún Jèhófà.” Nígbà tó yá, Arákùnrin Timothy rí i pé á dáa kóun yí ọ̀nà tóun ń gbà kọ́ni pa dà, kí wọ́n má bàa gbé ìyìn tí kò yẹ fún òun. (Òwe 27:21) Kí nìyẹn wá yọrí sí? Ó sọ pé: “Àwọn èèyàn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló máa ń sọ pé àsọyé mi máa ń jẹ́ káwọn fara da ìṣòro, káwọn sì túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Ayọ̀ tí mò ń ní báyìí ju ayọ̀ tí mo máa ń ní lọ́dún mélòó kan sẹ́yìn nígbà táwọn ará máa ń gbé ìyìn tí kò yẹ fún mi.”

TÓ BÁ ṢÒRO FÚN Ẹ LÁTI ṢE OHUN TÍ ÈTÒ ỌLỌ́RUN SỌ TÀBÍ TÓ Ò NÍGBOYÀ

Nígbà tí Jèhófà ní kí Gídíónì dín iye ọmọ ogun tó wà pẹ̀lú ẹ̀ kù, ó ṣe bẹ́ẹ̀. Àwọn ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) ọkùnrin tó fi hàn pé àwọn wà lójúfò nìkan ló yàn (Wo ìpínrọ̀ 9)

9. Kí ni Jèhófà sọ pé kí Gídíónì ṣe tó máa gba pé kó jẹ́ onígbọràn, kó sì nígboyà? (Wo àwòrán iwájú ìwé.)

9 Lẹ́yìn tí Gídíónì di onídàájọ́, Jèhófà gbé iṣẹ́ kan fún un tó máa gba pé kó jẹ́ onígbọràn àti onígboyà. Jèhófà ní kó lọ wó pẹpẹ Báálì bàbá rẹ̀ lulẹ̀. (Oníd. 6:25, 26) Lẹ́yìn ìyẹn, Gídíónì lọ kó àwọn ọmọ ogun jọ, àmọ́ ẹ̀ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Jèhófà ní kó dín iye àwọn ọmọ ogun náà kù. (Oníd. 7:2-7) Níkẹyìn, Jèhófà sọ fún un pé ọ̀gànjọ́ òru ni kó lọ gbéjà ko àwọn ọ̀tá ní ibùdó wọn.​—Oníd. 7:9-11.

10. Kí ló lè mú kó nira fún alàgbà kan láti jẹ́ onígbọràn?

10 Ẹ̀yin alàgbà gbọ́dọ̀ “ṣe tán láti ṣègbọràn.” (Jém. 3:17) Alàgbà tó jẹ́ onígbọràn máa ń ṣe ohun tí Ìwé Mímọ́ àti ètò Ọlọ́run sọ. Tó bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, àpẹẹrẹ rere ló máa jẹ́ fáwọn ará. Síbẹ̀, àwọn nǹkan kan lè mú kó ṣòro fún un láti jẹ́ onígbọràn. Bí àpẹẹrẹ, ètò Ọlọ́run lè sọ pé ká ṣe àwọn nǹkan kan, àwọn nǹkan náà sì lè yí pa dà léraléra, kó sì nira fún alàgbà náà láti ṣe ohun tí ètò Ọlọ́run sọ. Àwọn ìgbà míì wà tó lè máa wò ó pé ohun tí ètò Ọlọ́run ní ká ṣe ò bọ́gbọ́n mu. Wọ́n sì lè ní kó lọ ṣiṣẹ́ kan tó lè jẹ́ káwọn aláṣẹ ìjọba sọ pé kí wọ́n lọ mú un. Torí náà, báwo lẹ̀yin alàgbà ṣe lè jẹ́ onígbọràn bíi ti Gídíónì tírú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀?

11. Kí ló máa jẹ́ káwọn alàgbà jẹ́ onígbọràn?

11 Máa fara balẹ̀ tẹ́tí sí ohun tí ètò Ọlọ́run sọ, kó o sì ṣe é. Jèhófà sọ bí Gídíónì ṣe máa wó pẹpẹ Báálì bàbá rẹ̀ lulẹ̀, ó sì sọ ibi tó máa kọ́ pẹpẹ tuntun Jèhófà sí àti irú ẹran tó máa fi rúbọ. Gídíónì ò bá Jèhófà jiyàn, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló ṣe ohun tí Jèhófà sọ. Bákan náà lónìí, ètò Ọlọ́run máa ń kọ lẹ́tà sáwọn alàgbà, wọ́n máa ń fi ìfilọ̀ ránṣẹ́, wọ́n sì máa ń fún wọn láwọn ìlànà tó yẹ kí wọ́n tẹ̀ lé nínú ìjọsìn Ọlọ́run àti láwọn apá ìgbésí ayé wa. A nífẹ̀ẹ́ àwọn alàgbà yìí gan-an torí tọkàntọkàn ni wọ́n ń ṣe ohun tí ètò Ọlọ́run sọ fún wọn. Gbogbo ìjọ ló sì ń jàǹfààní ẹ̀.​—Sm. 119:112.

12. Báwo lẹ̀yin alàgbà ṣe lè tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tó wà nínú Hébérù 13:17, tí ohun tí ètò Ọlọ́run ní kẹ́ ẹ ṣe bá yí pa dà?

12 Ṣe tán láti ṣàtúnṣe. Ẹ má gbàgbé pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo ọmọ ogun Gídíónì ni Jèhófà ní kó dá pa dà sílé, àwọn tó kù ò sì tó nǹkan rárá. (Oníd. 7:8) Ó ṣeé ṣe kó ronú pé: ‘Ṣé dandan ni kí wọ́n pa dà sílé ni? Ṣé ìwọ̀nba àwọn tó kù yìí máa lè jagun ṣẹ́gun?’ Èyí ó wù ó jẹ́, Gídíónì ṣègbọràn. Lónìí, àwọn alàgbà náà lè fara wé Gídíónì. Tí àyípadà bá dé bá ohun tí ètò Ọlọ́run ní kí wọ́n ṣe, ó yẹ kí wọ́n ṣe é. (Ka Hébérù 13:17.) Bí àpẹẹrẹ lọ́dún 2014, Ìgbìmọ̀ Olùdarí bẹ̀rẹ̀ sí í san èyí tó pọ̀ jù nínú owó tá a fi ń kọ́ àwọn Ilé Ìpàdé àtàwọn Gbọ̀ngàn Àpéjọ wa. (2 Kọ́r. 8:12-14) Tẹ́lẹ̀, ètò Ọlọ́run máa ń yá àwọn ìjọ lówó láti fi kọ́ Ilé Ìpàdé fún wọn, wọ́n á sì san án pa dà, àmọ́ àtìgbà yẹn ni ìjọ ò ti yáwó mọ́. Dípò bẹ́ẹ̀, gbogbo ìjọ kárí ayé ló máa ń fowó ṣètìlẹyìn, ètò Ọlọ́run á wá fi kọ́ Ilé Ìpàdé àtàwọn Gbọ̀ngàn Àpéjọ sáwọn ibi tí wọ́n bá rí i pé ó yẹ kí wọ́n ti ṣe bẹ́ẹ̀, kódà tí owó táwọn ìjọ bẹ́ẹ̀ bá fi ṣètìlẹyìn ò bá pọ̀. Nígbà tí Arákùnrin José gbọ́ nípa ẹ̀, kò gbà pé àyípadà yẹn máa ṣiṣẹ́. Ó wá ń ronú pé: ‘Bóyá lètò Ọlọ́run máa rówó kọ́ Ilé Ìpàdé ẹyọ kan ṣoṣo. Mi ò rò pé àyípadà yìí máa ṣiṣẹ́ lọ́dọ̀ wa níbí.’ Kí ló ran José lọ́wọ́ láti fara mọ́ ohun tí ètò Ọlọ́run sọ? Ó ní: “Mo rántí ohun tó wà nínú Òwe 3:5, 6 tó ní kí n gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Mo sì rí i pé Jèhófà bù kún àyípadà náà! Yàtọ̀ sí pé ètò Ọlọ́run ti kọ́ Ilé Ìpàdé tó pọ̀ sí i, gbogbo wa la tún ń ṣètìlẹyìn lónírúurú ọ̀nà kí iṣẹ́ náà lè di ṣíṣe.”

Tí wọ́n bá tiẹ̀ fòfin de iṣẹ́ wa lórílẹ̀-èdè tó ò ń gbé, o ṣì lè fìgboyà wàásù fáwọn èèyàn (Wo ìpínrọ̀ 13)

13. (a)  Kí ló dá Gídíónì lójú? (b) Báwo lẹ̀yin alàgbà ṣe lè fara wé Gídíónì? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

13 Ẹ máa fìgboyà ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́. Iṣẹ́ tí Jèhófà gbé fún Gídíónì ò rọrùn, ẹ̀rù sì ń bà á, síbẹ̀ ó ṣègbọràn. (Oníd. 9:17) Lẹ́yìn tí Jèhófà sọ fún Gídíónì pé òun máa wà pẹ̀lú ẹ̀, ó dá Gídíónì lójú pé Jèhófà máa ran òun lọ́wọ́ láti dáàbò bo àwọn èèyàn Ọlọ́run. Torí náà, ó yẹ kẹ́yin alàgbà tó ń gbé láwọn ibi tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ wa fara wé Gídíónì. Ẹ sì lè ṣe bẹ́ẹ̀ táwọn ará bá ń rí i tẹ́ ẹ̀ ń bójú tó ìpàdé, tẹ́ ẹ sì ń fìgboyà wàásù pẹ̀lú wọn, bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn aláṣẹ ìjọba lè mú yín, wọ́n lè fọ̀rọ̀ wá yín lẹ́nu wò, iṣẹ́ lè bọ́ lọ́wọ́ yín, wọ́n sì lè gbéjà kò yín. c Nígbà ìpọ́njú ńlá, ẹ̀yin alàgbà gbọ́dọ̀ nígboyà tí ètò Ọlọ́run bá ní kẹ́ ẹ ṣe àwọn nǹkan kan, kódà tí nǹkan náà bá léwu. Bí àpẹẹrẹ, ètò Ọlọ́run lè sọ bá a ṣe máa wàásù ìdájọ́ tó dà bí òkúta yìnyín àtohun tá a máa ṣe ká lè là á já nígbà tí Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù bá gbéjà kò wá.​—Ìsík. 38:18; Ìfi. 16:21.

TÓ BÁ NIRA FÚN Ẹ LÁTI FARA DÀ Á

14. Kí ló lè mú kó nira fún Gídíónì láti fara dà á?

14 Torí pé onídàájọ́ ni Gídíónì, ó máa ń ṣiṣẹ́ àṣekára. Nígbà táwọn ará Mídíánì sá lọ ní alẹ́ tí Gídíónì gbéjà kò wọ́n, Gídíónì lé wọn láti Àfonífojì Jésírẹ́lì títí dé Odò Jọ́dánì, ó sì ṣeé ṣe kí igbó pọ̀ níbẹ̀. (Oníd. 7:22) Ṣé Odò Jọ́dánì ni Gídíónì ti pa dà? Rárá o! Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ti rẹ òun àti ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) ọkùnrin tó wà pẹ̀lú ẹ̀, wọ́n sọdá odò náà, wọ́n sì ń lé àwọn ọ̀tá náà lọ. Nígbà tó yá, wọ́n lé àwọn ará Mídíánì náà bá, wọ́n sì ṣẹ́gun wọn.​—Oníd. 8:4-12.

15. Kí ló lè mú kó nira fún alàgbà kan láti fara dà á?

15 Nígbà míì, ó lè rẹ alàgbà kan débi pé kò ní lè bójú tó àwọn iṣẹ́ tó yẹ kó ṣe nínú ìjọ àti ìdílé ẹ̀. Tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, báwo lẹ̀yin alàgbà ṣe lè fara wé Gídíónì?

Àwọn alàgbà tó nífẹ̀ẹ́ àwọn ará máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́, wọ́n sì máa ń fún wọn lókun (Wo ìpínrọ̀ 16-17)

16-17. Kí ló ran Gídíónì lọ́wọ́ láti fara dà á, kí nìyẹn sì fi dá ẹ̀yin alàgbà lójú? (Àìsáyà 40:28-31) (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

16 Fọkàn tán Jèhófà pé ó máa fún ẹ lókun. Gídíónì fọkàn tán Jèhófà pé ó máa fún òun lókun, Jèhófà ò sì já a kulẹ̀. (Oníd. 6:14, 34) Ìgbà kan wà tí Gídíónì àtàwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú ẹ̀ fẹsẹ̀ sáré lé àwọn ọba Mídíánì méjì kan tó ṣeé ṣe kí wọ́n gun ràkúnmí. (Oníd. 8:12, 21) Síbẹ̀, torí pé Gídíónì àtàwọn èèyàn ẹ̀ ò jẹ́ kó rẹ̀ wọ́n, Jèhófà ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣẹ́gun. Ó yẹ kẹ́yin alàgbà náà gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà tí ‘kì í rẹ̀, tí okun rẹ̀ kì í sì í tán.’ Torí náà, ó dájú pé ó máa fún yín lókun nígbà tẹ́ ẹ nílò ẹ̀ gan-an.​—Ka Àìsáyà 40:28-31.

17 Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Arákùnrin Matthew tó wà lára Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn. Kí ló jẹ́ kó fara dà á? Ó sọ pé: “Mo ti rí i pé òótọ́ lohun tí Fílípì 4:13 sọ. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló máa ń rẹ̀ mí tí mi ò sì ní lókun mọ́ rárá. Torí náà, mo máa ń gbàdúrà gan-an sí Jèhófà pé kó ràn mí lọ́wọ́ kí n lè ní okun àti ọgbọ́n tí màá fi ran àwọn ará lọ́wọ́. Láwọn àsìkò yẹn, Jèhófà fún mi lókun nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀, ìyẹn ló sì ń jẹ́ kí n fara dà á.” Bíi ti Gídíónì, àwọn alàgbà náà máa ń ṣiṣẹ́ kára láti bójú tó àwa èèyàn Jèhófà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé kì í fìgbà gbogbo rọrùn fún wọn. Ká sòótọ́, ó yẹ káwọn alàgbà mọ̀wọ̀n ara wọn, kí wọ́n sì mọ̀ pé kì í ṣe gbogbo nǹkan làwọn máa lè ṣe. Síbẹ̀, ó yẹ kí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé ó máa gbọ́ àdúrà wọn, ó sì máa fún wọn lókun láti fara dà á.​—Sm. 116:1; Fílí. 2:13.

18. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, kí lẹ̀yin alàgbà rí kọ́ lára Gídíónì?

18 Ọ̀pọ̀ nǹkan lẹ̀yin alàgbà lè kọ́ lára Gídíónì tó máa ràn yín lọ́wọ́ lásìkò wa yìí. Ó yẹ kẹ́yin alàgbà mọ̀wọ̀n ara yín, kẹ́ ẹ sì nírẹ̀lẹ̀ kẹ́ ẹ má bàa gba iṣẹ́ tó ju agbára yín lọ, ó sì yẹ kẹ́ ẹ máa ṣọ́ra táwọn èèyàn bá ṣàríwísí yín tàbí tí wọ́n bá yìn yín. Ẹ gbọ́dọ̀ jẹ́ onígbọràn, kẹ́ ẹ sì nígboyà pàápàá bí òpin ṣe ń sún mọ́lé. Ó sì yẹ kó dá yín lójú pé ìṣòro yòówù kó dé bá yín, Ọlọ́run máa fún yín lókun, ó sì máa ràn yín lọ́wọ́. A mọyì àwọn alàgbà tó ń ṣiṣẹ́ kára láti bójú tó wa yìí, a sì máa ń “ka irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ sí ẹni ọ̀wọ́n.”​—Fílí. 2:29.

ORIN 120 Jẹ́ Oníwà Tútù Bíi Kristi

a Jèhófà yan Gídíónì láti máa bójú tó àwọn èèyàn ẹ̀, kó sì máa dáàbò bò wọ́n lásìkò tí nǹkan nira lórílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. Nǹkan bí ogójì (40) ọdún ni Gídíónì fi ṣe iṣẹ́ náà tọkàntọkàn. Àmọ́, ọ̀pọ̀ ìṣòro ló bá pàdé nígbà tó ń ṣe iṣẹ́ náà. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa nǹkan tẹ́yin alàgbà lè kọ́ lára Gídíónì tí ohun kan bá ṣẹlẹ̀ tó dán yín wò.

b Ìrẹ̀lẹ̀ àti ìmọ̀wọ̀n ara ẹni jọra. Tá a bá mọ̀wọ̀n ara wa, a ò ní máa ro ara wa ju bó ṣe yẹ lọ, àá sì gbà pé àwọn nǹkan kan wà tá ò lè ṣe. Tá a bá nírẹ̀lẹ̀, a ò ní máa ṣe bíi pé a mọ nǹkan ṣe ju àwọn míì lọ. (Fílí. 2:3) Ká sòótọ́, ẹni tó mọ̀wọ̀n ara ẹ̀ máa ń nírẹ̀lẹ̀.

c Wo àpilẹ̀kọ náà “Máa Sin Jèhófà Nìṣó Tí Wọ́n Bá Tiẹ̀ Fòfin De Iṣẹ́ Wa” nínú Ilé Ìṣọ́ July 2019, ojú ìwé 10-11, ìpínrọ̀ 10-13.