Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Kí nìdí tí Jósẹ́fù àti Màríà ò fi kúrò ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù lẹ́yìn tí wọ́n bí Jésù, kí wọ́n sì pa dà sí Násárẹ́tì?
Bíbélì ò sọ fún wa. Àmọ́ ó ṣàlàyé àwọn ohun tó ṣeé ṣe kó fà á tí wọ́n fi pinnu pé àwọn ò ní pa dà sí Násárẹ́tì.
Áńgẹ́lì kan sọ fún Màríà pé ó máa lóyún, ó sì máa bímọ. Nígbà tí áńgẹ́lì yẹn wá jíṣẹ́ fún Màríà, Násárẹ́tì tó jẹ́ ìlú ìbílẹ̀ Jósẹ́fù ní Gálílì ni Màríà àti Jósẹ́fù ń gbé. (Lúùkù 1:26-31; 2:4) Lẹ́yìn náà, nígbà tí wọ́n kúrò ní Íjíbítì, wọ́n pa dà sí Násárẹ́tì. Ibẹ̀ ni Jésù dàgbà sí, ó sì di ará Násárẹ́tì. (Mát. 2:19-23) Ìdí nìyẹn tá a fi máa ń mẹ́nu kan Násárẹ́tì tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa Jésù, Jósẹ́fù àti Màríà.
Màríà ní mọ̀lẹ́bí kan tó ń gbé Júdà, Èlísábẹ́tì lorúkọ ẹ̀. Èlísábẹ́tì ni ìyàwó Sekaráyà àlùfáà, òun náà sì ni ìyá Jòhánù Arinibọmi. (Lúùkù 1:5, 9, 13, 36) Màríà lọ kí Èlísábẹ́tì ní Júdà, ó sì lo oṣù mẹ́ta lọ́dọ̀ ẹ̀. Nígbà tó yá, ó pa dà sí Násárẹ́tì. (Lúùkù 1:39, 40, 56) Ìdí nìyẹn tí Màríà fi mọ Júdà àti agbègbè ẹ̀.
Lẹ́yìn ìyẹn, ìjọba ní káwọn èèyàn “lọ forúkọ sílẹ̀,” Jósẹ́fù náà sì ṣe bẹ́ẹ̀. Torí náà, Jósẹ́fù kúrò ní Násárẹ́tì lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù tó jẹ́ “ìlú Dáfídì,” tó sì tún jẹ́ ìlú tí wọ́n ti sọ tẹ́lẹ̀ pé wọ́n máa bí Mèsáyà sí. (Lúùkù 2:3, 4; 1 Sám. 17:15; 20:6; Míkà 5:2) Lẹ́yìn tí Màríà bí Jésù sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, Jósẹ́fù ò fẹ́ kó gbé ọmọ tuntun yẹn rìnrìn àjò ọ̀nà jíjìn pa dà sí Násárẹ́tì. Torí náà, wọ́n dúró sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù tó fi nǹkan bíi kìlómítà mẹ́sàn-án jìnnà sí Jerúsálẹ́mù. Ìyẹn máa jẹ́ kó rọrùn fún wọn láti gbé ọmọ náà lọ sí tẹ́ńpìlì, kí wọ́n sì rú ẹbọ tó yẹ.—Léf. 12:2, 6-8; Lúùkù 2:22-24.
Áńgẹ́lì Jèhófà ti sọ fún Màríà tẹ́lẹ̀ pé Ọlọ́run máa fún ọmọ ẹ̀ ní “ìtẹ́ Dáfídì,” ó sì “máa jẹ Ọba.” Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe kí Jósẹ́fù àti Màríà ti mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì káwọn bí Jésù sí ìlú Dáfídì? (Lúùkù 1:32, 33; 2:11, 17) Tó bá rí bẹ́ẹ̀, wọ́n lè máa rò ó pé á dáa káwọn dúró síbẹ̀ títí dìgbà tí Jèhófà máa sọ nǹkan táwọn máa ṣe.
A ò mọ bí wọ́n ṣe pẹ́ tó ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù káwọn awòràwọ̀ yẹn tó dé. Àmọ́ lásìkò yẹn, inú ilé kan ni wọ́n ń gbé, “ọmọ kékeré” náà sì ti dàgbà díẹ̀, kì í ṣe ọmọ jòjòló mọ́. (Mát. 2:11) Kàkà kí wọ́n pa dà sí Násárẹ́tì, ó jọ pé wọ́n pẹ́ gan-an ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, wọ́n sì sọbẹ̀ dilé.
Hẹ́rọ́dù pàṣẹ pé kí wọ́n pa “gbogbo ọmọkùnrin ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù . . . láti ọmọ ọdún méjì sí ìsàlẹ̀.” (Mát. 2:16) Áńgẹ́lì Jèhófà kìlọ̀ fún Jósẹ́fù nípa ohun tó fẹ́ ṣẹlẹ̀ yìí, torí náà Jósẹ́fù àti Màríà gbé Jésù sá lọ sí Íjíbítì, wọ́n sì wà níbẹ̀ títí Hẹ́rọ́dù fi kú. Nígbà tó yá, Jósẹ́fù kó ìdílé ẹ̀ lọ sí Násárẹ́tì. Kí nìdí tí wọn ò fi pa dà sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù nígbà tí wọ́n kúrò ní Íjíbítì? Ìdí ni pé Ákíláọ́sì ọmọ Hẹ́rọ́dù ló ń ṣàkóso ní Jùdíà, ìkà sì ni. Ohun míì ni pé áńgẹ́lì Jèhófà ti kìlọ̀ fún Jósẹ́fù pé kí wọ́n má lọ síbẹ̀. Násárẹ́tì ló máa dáa jù fún Jósẹ́fù láti tọ́jú Jésù, kó sì di olùjọsìn Ọlọ́run.—Mát. 2:19-22; 13:55; Lúùkù 2:39, 52.
Ó jọ pé Jósẹ́fù ti kú kí Jésù tó ṣí àǹfààní sílẹ̀ fáwọn èèyàn láti lọ sọ́run. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ayé ni Jósẹ́fù máa jíǹde sí. Ọ̀pọ̀ èèyàn máa láǹfààní láti rí Jósẹ́fù kí wọ́n sì béèrè ìdí tóun àti Màríà fi dúró sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù lẹ́yìn tí wọ́n bí Jésù.