Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 26

Ẹ Máa Múra Sílẹ̀ De Ọjọ́ Jèhófà

Ẹ Máa Múra Sílẹ̀ De Ọjọ́ Jèhófà

“Ọjọ́ Jèhófà ń bọ̀ bí olè ní òru.”​—1 TẸS. 5:2.

ORIN 143 Tẹpá Mọ́ṣẹ́, Wà Lójúfò, Kó O sì Máa Retí

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ a

1. Kí la gbọ́dọ̀ ṣe ká má bàa pa run ní ọjọ́ Jèhófà?

 NÍGBÀ tí Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa “ọjọ́ Jèhófà,” ohun tó ń sọ ni ìgbà tó máa pa àwọn ọ̀tá ẹ̀ run, tó sì máa gba àwọn èèyàn ẹ̀ là. Nígbà àtijọ́, Jèhófà fìyà jẹ àwọn orílẹ̀-èdè kan. (Àìsá. 13:1, 6; Ìsík. 13:5; Sef. 1:8) Lákòókò tiwa yìí, “ọjọ́ Jèhófà” máa bẹ̀rẹ̀ nígbà táwọn alákòóso ayé bá pa Bábílónì Ńlá run, ó sì máa parí nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì. Tá ò bá fẹ́ wà lára àwọn tó máa pa run lọ́jọ́ yẹn, ó yẹ ká bẹ̀rẹ̀ sí í múra sílẹ̀ báyìí. Jésù kọ́ wa pé kì í ṣe ká kàn máa retí ìgbà tí “ìpọ́njú ńlá” máa bẹ̀rẹ̀, ó tún yẹ ká máa “múra sílẹ̀” de ọjọ́ yẹn.​—Mát. 24:21; Lúùkù 12:40.

2. Báwo la ṣe lè jàǹfààní nínú ohun tó wà ní 1 Tẹsalóníkà?

2 Nínú lẹ́tà àkọ́kọ́ tí ẹ̀mí Ọlọ́run darí Pọ́ọ̀lù láti kọ sáwọn ará Tẹsalóníkà, ó lo ọ̀pọ̀ àpèjúwe láti jẹ́ kí wọ́n mọ bí wọ́n ṣe máa múra sílẹ̀ de ọjọ́ ìdájọ́ Jèhófà. Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé àkókò yẹn kọ́ ni ọjọ́ Jèhófà máa dé. (2 Tẹs. 2:1-3) Síbẹ̀, ó gba àwọn ará yẹn níyànjú pé kí wọ́n máa múra sílẹ̀ bíi pé ọ̀la ló máa dé, ó sì yẹ káwa náà fi ìmọ̀ràn yẹn sílò lónìí. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká wo àlàyé tí Pọ́ọ̀lù ṣe lórí: (1) bí ọjọ́ Jèhófà ṣe máa dé, (2) àwọn tó máa pa run ní ọjọ́ yẹn àti (3) bá a ṣe lè múra sílẹ̀ ká má bàa pa run.

BÁWO NI ỌJỌ́ JÈHÓFÀ ṢE MÁA DÉ?

Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ Tẹsalóníkà kìíní, ó lo àwọn àpèjúwe tó máa ràn wá lọ́wọ́ (Wo ìpínrọ̀ 3)

3. Báwo ni ọjọ́ Jèhófà ṣe máa dé bí olè ní òru? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

3 “Bí olè ní òru.” (1 Tẹs. 5:2) Gbólóhùn yìí ni àkọ́kọ́ lára àfiwé mẹ́ta tí Pọ́ọ̀lù fi ṣàlàyé bí ọjọ́ Jèhófà ṣe máa dé. Òru làwọn olè sábà máa ń ja àwọn èèyàn lólè, wọ́n sì máa ń dé bá ẹni tí wọ́n fẹ́ jà lólè lójijì. Lọ́nà kan náà, ọjọ́ Jèhófà máa dé bá àwọn èèyàn lójijì, á sì ya ọ̀pọ̀ lẹ́nu. Kódà, ó ṣeé ṣe kó ya àwa Kristẹni tòótọ́ lẹ́nu tí ọjọ́ yẹn bá dé lójijì. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn burúkú máa pa run lọ́jọ́ yẹn, Jèhófà máa gba àwa èèyàn ẹ̀ là.

4. Báwo ni ọjọ́ Jèhófà ṣe dà bí ìgbà tí obìnrin tó lóyún bá bẹ̀rẹ̀ sí í rọbí?

4 “Bí ìgbà tí obìnrin tó lóyún bá bẹ̀rẹ̀ sí í rọbí.” (1 Tẹs. 5:3) Kò sí aláboyún kan tó lè sọ ìgbà tí òun máa bẹ̀rẹ̀ sí í rọbí. Àmọ́ ó dá a lójú pé lọ́jọ́ kan, òun á bẹ̀rẹ̀ sí í rọbí. Tó bá sì di ọjọ́ yẹn, òjijì ló máa bẹ̀rẹ̀, ìrora náà máa ń pọ̀ gan-an, kò sì ní ṣeé yẹ̀ sílẹ̀. Lọ́nà kan náà, a ò mọ ọjọ́ àti wákàtí tí ọjọ́ Jèhófà máa bẹ̀rẹ̀. Àmọ́, ó dá wa lójú pé ọjọ́ yẹn máa dé àti pé ó máa dé bá àwọn èèyàn burúkú lójijì, gbogbo wọn ló sì máa pa run.

5. Báwo ni ìpọ́njú ńlá ṣe dà bí ìgbà tí ilẹ̀ ń mọ́?

5 Bí ìgbà tí ilẹ̀ ń mọ́. Nínú àpèjúwe kẹta tí Pọ́ọ̀lù lò, ó tún mẹ́nu kan àwọn olè tó máa ń jalè lóru. Àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí, Pọ́ọ̀lù fi ọjọ́ Jèhófà wé ìgbà tí ilẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ ń mọ́. (1 Tẹs. 5:4) Ọwọ́ àwọn tó máa ń jalè lóru máa ń dí débi pé wọn kì í mọ̀ pé ilẹ̀ ti ń mọ́. Tí ilẹ̀ bá mọ́ bá wọn níbẹ̀, àṣírí wọn tú nìyẹn. Lọ́nà kan náà, ìpọ́njú ńlá máa tú àṣírí àwọn èèyàn tó ń ṣe ohun tí inú Ọlọ́run ò dùn sí, tí wọ́n dà bí olè tó ń ṣiṣẹ́ ibi nínú òkùnkùn. Tá ò bá fẹ́ fìwà jọ wọ́n, tá a sì fẹ́ fi hàn pé à ń múra sílẹ̀, a ò ní máa ṣe nǹkan tínú Jèhófà ò dùn sí, dípò bẹ́ẹ̀ “oríṣiríṣi ohun rere àti òdodo àti òtítọ́” làá máa ṣe. (Éfé. 5:8-12) Nínú àpèjúwe méjì tó tẹ̀ lé e, Pọ́ọ̀lù jẹ́ ká mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sáwọn tó máa pa run.

ÀWỌN WO LÓ MÁA PA RUN NÍ ỌJỌ́ JÈHÓFÀ?

6. Kí ló fi hàn pé àwọn èèyàn ń sùn lásìkò wa yìí? (1 Tẹsalóníkà 5:6, 7)

6 “Àwọn tó ń sùn.” (Ka 1 Tẹsalóníkà 5:6, 7.) Pọ́ọ̀lù fi àwọn tó máa pa run ní ọjọ́ Jèhófà wé àwọn tó ń sùn. Tẹ́nì kan bá ń sùn, kì í mọ ohun tó ń lọ láyìíká ẹ̀, kì í sì í mọ̀ pé àkókò ti ń lọ. Torí náà, wọn kì í mọ̀ tóhun pàtàkì kan tó yẹ kí wọ́n fiyè sí bá fẹ́ ṣẹlẹ̀. Lọ́nà kan náà, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń sùn lónìí torí pé wọn ò fiyè sí ọjọ́ Jèhófà tó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dé. (Róòmù 11:8) Wọn ò gbà pé àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ láyé báyìí fi hàn pé a ti ń gbé ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” àti pé ìpọ́njú ńlá ò ní pẹ́ bẹ̀rẹ̀. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì tó ń ṣẹlẹ̀ báyìí lè mú káwọn tí ò nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tẹ́lẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ́ ìhìn rere Ìjọba náà. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ṣì ń sùn dípò kí wọ́n wà lójúfò. Kódà, àwọn kan tó gbà pé ọjọ́ ìdájọ́ máa dé rò pé ó ṣì jìnnà. (2 Pét. 3:3, 4) Torí náà, ó ṣe pàtàkì ká máa rántí ìmọ̀ràn tí Bíbélì fún wa pé ká túbọ̀ máa wà lójúfò lójoojúmọ́ lásìkò wa yìí.

7. Báwo ni àwọn tí Ọlọ́run máa pa run ṣe dà bí àwọn tó ń mutí yó?

7 ‘Àwọn tó ń mutí yó.’ Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi àwọn tí Ọlọ́run máa pa run wé àwọn tó ń mutí yó. Tẹ́nì kan bá mutí yó, kì í tètè gbé ìgbésẹ̀ tí ohun kan bá ṣẹlẹ̀ láyìíká ẹ̀, kì í sì í ṣe ìpinnu tó dáa. Lọ́nà kan náà, àwọn èèyàn burúkú kì í fetí sí ìkìlọ̀ Ọlọ́run, kàkà bẹ́ẹ̀ ohun tó máa jẹ́ kí wọ́n pa run ni wọ́n ń ṣe. Àmọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run rọ àwa Kristẹni pé ká máa ronú bó ṣe tọ́. (1 Tẹs. 5:6) Ọ̀jọ̀gbọ́n kan tó ń ṣàlàyé Bíbélì sọ pé kéèyàn jẹ́ aláròjinlẹ̀ túmọ̀ sí “kéèyàn jẹ́ ẹni tó máa ń fara balẹ̀, tí kì í kánjú tó sì máa ń gbé ọ̀rọ̀ yẹ̀ wò dáadáa kó lè ṣèpinnu tó tọ́.” Kí nìdí tó fi yẹ ká fara balẹ̀, ká sì máa gbé ọ̀rọ̀ yẹ̀ wò dáadáa? Ìdí ni pé kò ní jẹ́ ká dá sọ́rọ̀ òṣèlú àti rògbòdìyàn tó ń lọ lágbègbè wa. Bí ọjọ́ Jèhófà ṣe túbọ̀ ń sún mọ́lé, bẹ́ẹ̀ làwọn èèyàn á túbọ̀ máa fúngun mọ́ wa pé ká dá sáwọn nǹkan yìí. Síbẹ̀, kò yẹ ká máa ṣàníyàn nípa bá a ṣe máa dá wọn lóhùn. Ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run máa jẹ́ ká fara balẹ̀ ká lè ṣe ìpinnu tó tọ́.​—Lúùkù 12:11, 12.

KÍ LA LÈ ṢE LÁTI MÚRA SÍLẸ̀ DE ỌJỌ́ JÈHÓFÀ?

Ọ̀pọ̀ èèyàn ń ṣe bíi pé ọjọ́ Jèhófà tó ń bọ̀ ò kàn wọ́n, àmọ́ àwa èèyàn Jèhófà ń múra sílẹ̀. Bá a ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé à ń gbé àwo ìgbàyà wọ̀, ìyẹn ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́, a sì ń dé akoto, ìyẹn ìrètí tá a ní (Wo ìpínrọ̀ 8, 12)

8. Báwo ni 1 Tẹsalóníkà 5:8 ṣe ṣàpèjúwe àwọn ànímọ́ tó máa jẹ́ ká wà lójúfò, ká sì máa ronú bó ṣe tọ́? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

8 ‘Gbé àwo ìgbàyà wọ̀, kí o sì dé akoto.’ Pọ́ọ̀lù fi àwa Kristẹni wé àwọn sójà tó máa ń wà lójúfò, tí wọ́n sì máa ń múra sílẹ̀ de ogun. (Ka 1 Tẹsalóníkà 5:8.) Àwọn èèyàn gbà pé ó yẹ kí sójà kan múra sílẹ̀ láti jà torí ìgbàkigbà ni ogun lè dé. Bọ́rọ̀ tiwa náà ṣe rí nìyẹn. Tá a bá fẹ́ fi hàn pé lóòótọ́ là ń múra sílẹ̀ de ọjọ́ Jèhófà, ó yẹ ká gbé àwo ìgbàyà wọ̀, ìyẹn ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́, ká sì dé akoto, ìyẹn ìrètí tá a ní.

9. Báwo ni ìgbàgbọ́ tá a ní ṣe ń dáàbò bò wá?

9 Àwo ìgbàyà máa ń dáàbò bo àyà sójà kan. Bẹ́ẹ̀ náà ni ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ ṣe máa ń dáàbò bo ọkàn ìṣàpẹẹrẹ wa. Àwọn ànímọ́ yìí máa ń jẹ́ ká sin Jèhófà nìṣó, ká sì máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù. Ìgbàgbọ́ tá a ní máa ń jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà máa san èrè fún wa tá a bá sìn ín tọkàntọkàn. (Héb. 11:6) Ó máa ń jẹ́ ká jẹ́ olóòótọ́ sí Jésù Aṣáájú wa kódà bá a tiẹ̀ ń fara da ọ̀pọ̀ ìṣòro. A lè mú kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa àpẹẹrẹ àwọn tó jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà lásìkò wa yìí bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń fara da inúnibíni tàbí ìṣòro àìlówó lọ́wọ́. Yàtọ̀ síyẹn, tá ò bá fẹ́ kó sínú ìdẹkùn kíkó ohun ìní jọ, ó yẹ ká máa fara wé àwọn tí wọ́n jẹ́ kí ohun ìní díẹ̀ tẹ́ wọn lọ́rùn kí wọ́n lè fi Ìjọba Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́. b

10. Báwo ni ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run àtàwọn èèyàn ṣe ń jẹ́ ká fara dà á lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù?

10 Ànímọ́ míì tó ṣe pàtàkì tó máa jẹ́ ká wà lójúfò, tó sì máa jẹ́ ká ronú lọ́nà tó tọ́ ni ìfẹ́. (Mát. 22:37-39) Ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run máa ń jẹ́ ká fara dà á lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù bó tiẹ̀ jẹ́ pé a máa ń bá ìṣòro pàdé. (2 Tím. 1:7, 8) Torí pé a tún nífẹ̀ẹ́ àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà, a máa ń wàásù fún wọn láwọn ìpínlẹ̀ ìwàásù wa. Kódà, a máa ń wàásù fún wọn látorí fóònù àti nípasẹ̀ lẹ́tà. A ò jẹ́ kó sú wa torí a mọ̀ pé lọ́jọ́ kan, àwọn tá à ń wàásù fún máa yí pa dà, wọ́n sì máa ṣe ohun tó tọ́.​—Ìsík. 18:27, 28.

11. Báwo ni ìfẹ́ tá a ní sáwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa ṣe máa ràn wá lọ́wọ́? (1 Tẹsalóníkà 5:11)

11 A tún nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa náà. A máa ń fi irú ìfẹ́ yẹn hàn tá a bá ń ‘fún ara wa níṣìírí, tá a sì ń gbé ara wa ró.’ (Ka 1 Tẹsalóníkà 5:11.) A máa ń fún ara wa níṣìírí bíi tàwọn sójà tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ara wọn lójú ogun. Òótọ́ ni pé sójà kan lè ṣèèṣì ṣe ẹnì kejì ẹ̀ léṣe nígbà tógun ń lọ lọ́wọ́, àmọ́ ó dájú pé kò ní mọ̀ọ́mọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀. Lọ́nà kan náà, a ò ní mọ̀ọ́mọ̀ ṣe ohun tó máa dun àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa, a ò sì ní fi búburú san búburú fún wọn. (1 Tẹs. 5:13, 15) A tún ń fi ìfẹ́ yẹn hàn tá a bá ń bọ̀wọ̀ fáwọn arákùnrin tó ń ṣàbójútó wa nínú ìjọ. (1 Tẹs. 5:12) Kò tíì pé ọdún kan tí wọ́n dá ìjọ Tẹsalóníkà sílẹ̀ tí Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà rẹ̀ sí wọn. Torí náà, àwọn alábòójútó tí wọ́n yàn síbẹ̀ lè má fi bẹ́ẹ̀ nírìírí, wọ́n sì lè ṣe àwọn àṣìṣe kan. Síbẹ̀, àwọn ará ìjọ náà ń bọ̀wọ̀ fún wọn. Bí ìpọ́njú ńlá ṣe ń sún mọ́lé, ó máa gba pé ká túbọ̀ máa ṣe ohun táwọn alàgbà ìjọ wa bá sọ fún wa ju bá a ṣe ń ṣe lọ báyìí. Ìdí ni pé ó lè má ṣeé ṣe láti kàn sí orílé iṣẹ́ wa tàbí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa mọ́ nígbà yẹn. Torí náà, ó ṣe pàtàkì pé ká nífẹ̀ẹ́, ká sì máa bọ̀wọ̀ fáwọn alàgbà ìjọ wa báyìí. Ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀, ẹ jẹ́ ká máa ronú bó ṣe tọ́. Ká má máa wo kùdìẹ̀-kudiẹ wọn. Ohun tó yẹ ká máa wò ni pé Jèhófà ti yan Kristi láti máa darí àwọn ọkùnrin olóòótọ́ yìí.

12. Báwo ni ìrètí tá a ní ṣe ń jẹ́ ká ronú lọ́nà tó tọ́?

12 Bí akoto ṣe máa ń dáàbò bo orí ọmọ ogun kan, bẹ́ẹ̀ ni ìrètí tá a ní pé Jèhófà máa gbà wá là lọ́jọ́ iwájú máa ń dáàbò bò wá ká lè máa ronú bó ṣe tọ́. Torí pé ìrètí tá a ní yìí lágbára, a mọ̀ pé kò sóhun rere kankan tí ayé yìí lè fún wa. (Fílí. 3:8) Ìrètí yìí ló ń fi wá lọ́kàn balẹ̀. Arákùnrin Wallace àti Arábìnrin Laurinda tí wọ́n ṣiṣẹ́ ìsìn ní Áfíríkà rí i pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí. Láàárín ọ̀sẹ̀ mẹ́ta, ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn pàdánù ọ̀kan lára àwọn òbí wọn. Torí àjàkálẹ̀ àrùn kòrónà tó ń jà ràn-ìn, kò ṣeé ṣe fún wọn láti lọ bá àwọn èèyàn wọn kẹ́dùn. Wallace sọ pé: “Ìrètí tí mo ní pé àwọn òkú máa jíǹde máa ń jẹ́ kí n ronú nípa bí wọ́n ṣe máa rí nígbà tí wọ́n bá jíǹde sínú ayé tuntun, kì í ṣe bí wọ́n ṣe rí kí wọ́n tó kú. Ohun tí mò ń retí yìí máa ń jẹ́ kọ́kàn mi balẹ̀ tínú mi ò bá dùn tàbí tí mo bá ń rántí pé wọ́n ti kú.”

13. Kí ló yẹ ká ṣe kí Ọlọ́run lè fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀?

13 “Ẹ má ṣe pa iná ẹ̀mí.” (1 Tẹs. 5:19) Pọ́ọ̀lù fi ẹ̀mí mímọ́ wé iná ẹ̀mí tó ń jó nínú wa. Tí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run bá wà lára wa, ó máa ń jẹ́ ká nítara láti ṣe ohun tó tọ́, ó sì máa ń jẹ́ ká lókun láti ṣe iṣẹ́ Jèhófà. (Róòmù 12:11) Kí ló yẹ ká ṣe kí Ọlọ́run lè fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀? Ó yẹ ká máa gbàdúrà pé kó fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀, ká máa ka Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ká sì wà nínú ètò rẹ̀ tí ẹ̀mí mímọ́ ń darí. Tá a bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí, a máa ní “èso ti ẹ̀mí.”​—Gál. 5:22, 23.

Bi ara ẹ pé, ‘Ṣé ohun tí mò ń ṣe fi hàn pé mo fẹ́ kí Ọlọ́run máa fún mi ní ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀?’ (Wo ìpínrọ̀ 14)

14. Kí ni ò yẹ ká ṣe tá a bá fẹ́ kí Ọlọ́run máa fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

14 Lẹ́yìn tí Ọlọ́run bá ti fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, a gbọ́dọ̀ kíyè sára ká “má ṣe pa iná ẹ̀mí.” Àwọn tí ọkàn wọn mọ́ àtàwọn tí ìwà wọn mọ́ nìkan ni Ọlọ́run máa ń fún ní ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀. Tá a bá ń ro èròkerò, tá a sì ṣe ohun tá à ń rò, Ọlọ́run ò ní fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀ mọ́. (1 Tẹs. 4:7, 8) Tá a bá fẹ́ kí Ọlọ́run máa fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀, kò tún yẹ ká “kó àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ dà nù.” (1 Tẹs. 5:20) “Àsọtẹ́lẹ̀” tí ẹsẹ Bíbélì yìí ń sọ nípa ẹ̀ ni àwọn ọ̀rọ̀ tí Jèhófà máa ń bá wa sọ nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀. Lára àwọn ọ̀rọ̀ náà ni ọjọ́ Jèhófà tí ò ní pẹ́ dé àti bí àkókò tá a wà yìí ti ṣe pàtàkì tó. Kò yẹ ká máa rò pé ọjọ́ Jèhófà tàbí Amágẹ́dọ́nì ò ní dé lákòókò wa yìí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló yẹ ká máa ṣe àwọn ohun tó fi hàn pé ọjọ́ náà ò ní pẹ́ dé, ká máa hùwà tó dáa, ká sì máa ṣe “iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run” lójoojúmọ́.​—2 Pét. 3:11, 12.

“Ẹ MÁA WÁDÌÍ OHUN GBOGBO DÁJÚ”

15. Báwo la ò ṣe ní jẹ́ kí ìkéde irọ́ àti ọ̀rọ̀ táwọn ẹ̀mí èṣù mí sí ṣì wá lọ́nà? (1 Tẹsalóníkà 5:21)

15 Láìpẹ́, àwọn tó ń ta ko Ọlọ́run máa kéde “Àlàáfíà àti ààbò!,” onírúurú ọ̀nà ni ìkéde yìí sì lè gbà wáyé. (1 Tẹs. 5:3) Àwọn ìkéde irọ́ táwọn ẹ̀mí èṣù mí sí máa gba ayé kan, á sì ṣi ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́nà. (Ìfi. 16:13, 14) Àwa ńkọ́? Wọn ò ní ṣì wá lọ́nà tá a bá ń ‘wádìí dájú tàbí dán ohun gbogbo wò.’ (Ka 1 Tẹsalóníkà 5:21.) Àwọn èèyàn máa ń lo ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà ‘wádìí dájú’ tí wọ́n bá fẹ́ mọ̀ bóyá ojúlówó ni òkúta iyebíye kan bíi wúrà tàbí fàdákà. Torí náà, ó yẹ káwa náà dán ohun tá a gbọ́ tàbí ohun tá a kà wò bóyá wọ́n jẹ́ òótọ́. Àwọn ará Tẹsalóníkà rí i pé ó ṣe pàtàkì káwọn ṣe bẹ́ẹ̀, ó sì ṣe pàtàkì pé káwa náà ṣe bẹ́ẹ̀ lónìí pàápàá bí ìpọ́njú ńlá ṣe ń sún mọ́lé. Dípò ká kàn máa gba gbogbo nǹkan táwọn èèyàn bá sọ gbọ́, ó yẹ ká máa lo làákàyè wa láti fi ohun tá a gbọ́ àtohun tá a kà wé ohun tí Bíbélì àti ètò Ọlọ́run sọ. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wọn ò ní fi ìkéde irọ́ táwọn ẹ̀mí èṣù mí sí tàn wá jẹ.​—Òwe 14:15; 1 Tím. 4:1.

16. Ohun tó dájú wo là ń retí, kí ló sì yẹ ká máa ṣe?

16 Àwa èèyàn Jèhófà lápapọ̀ máa la ìpọ́njú ńlá já. Àmọ́ a ò mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lọ́la. (Jém. 4:14) Bóyá a máa la ìpọ́njú ńlá já tàbí a máa kú kó tó bẹ̀rẹ̀, ohun tó dájú ni pé tá a bá jẹ́ olóòótọ́, a máa ní ìyè àìnípẹ̀kun. Àwọn ẹni àmì òróró máa wà pẹ̀lú Jésù lọ́run, àwọn àgùntàn mìíràn sì máa wà láyé nínú Párádísè. Torí náà, ẹ jẹ́ kí gbogbo wa gbájú mọ́ èrè tí Ọlọ́run fẹ́ fún wa, ká sì máa múra sílẹ̀ de ọjọ́ Jèhófà!

ORIN 150 Wá Ọlọ́run Kó O Lè Rí Ìgbàlà

a1 Tẹsalóníkà orí 5, a rí àwọn àpèjúwe àtàwọn àfiwé tó jẹ́ ká mọ̀ nípa ọjọ́ Jèhófà tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú. Torí náà, kí ni “ọjọ́ Jèhófà,” báwo ló sì ṣe máa dé? Àwọn wo ni ò ní pa run? Àwọn wo ló máa pa run? Báwo la ṣe lè múra sílẹ̀? Ká lè dáhùn àwọn ìbéèrè yìí, ẹ jẹ́ ká gbé ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ yẹ̀ wò.

b Wo ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ náà, “Wọ́n Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú.”