Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

Mo Kẹ́kọ̀ọ́ Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìsìn Jèhófà, Ó sì Ṣe Ohun Tó Yà Mí Lẹ́nu

Mo Kẹ́kọ̀ọ́ Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìsìn Jèhófà, Ó sì Ṣe Ohun Tó Yà Mí Lẹ́nu

NÍGBÀ tí mo wà ní kékeré, tí mo bá ti rí ọkọ̀ òfúrufú tó ń fò lókè, mo máa ń rò ó pé tó bá dọjọ́ kan, ó máa wu èmi náà kí n wọkọ̀ òfúrufú lọ sáwọn orílẹ̀-èdè tó gbayì. Àmọ́ lójú mi, ńṣe ló dà bí àlá tí ò lè ṣẹ.

Nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, àwọn òbí mi kúrò lórílẹ̀-èdè Estonia, wọ́n lọ sórílẹ̀-èdè Jámánì, ibẹ̀ ni wọ́n sì ti bí mi. Kò pẹ́ lẹ́yìn tí wọ́n bí mi, wọ́n tún kó lọ sórílẹ̀-èdè Kánádà. Ilé àkọ́kọ́ tá a gbé wà nítòsí Ottawa ní Kánádà, ilé náà kéré, àmọ́ à ń sin adìyẹ níbẹ̀. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé tálákà paraku ni wá, a ṣì máa ń jẹ ẹyin láràárọ̀.

Lọ́jọ́ kan, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ka Ìfihàn 21:3, 4 fún mọ́mì mi. Inú wọn dùn gan-an nígbà tí wọ́n gbọ́ ẹsẹ Bíbélì yẹn débi pé ṣe ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún. Mọ́mì mi àti dádì mi tẹ̀ síwájú gan-an, wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kò sì pẹ́ táwọn méjèèjì ṣèrìbọmi.

Àwọn òbí mi ò gbọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì dáadáa, àmọ́ wọn ò fi ìjọsìn Jèhófà ṣeré rárá. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo ọjọ́ Saturday ni dádì mi máa ń mú èmi àti Sylvia àbúrò mi obìnrin lọ wàásù, lẹ́yìn tí wọ́n ti fi gbogbo òru ṣiṣẹ́ nílé iṣẹ́ tí wọ́n ti ń yọ́ irin kan tó ń jẹ́ nickel ní Sudbury, Ontario. Ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ni gbogbo ìdílé wa máa ń kẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ pa pọ̀. Mọ́mì mi àti dádì mi kọ́ mi láti nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run. Torí náà, mo ya ara mi sí mímọ́, mo sì ṣèrìbọmi lọ́dún 1956 nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́wàá. Bí àwọn òbí mi ṣe nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gan-an ti ràn mí lọ́wọ́ láti máa sin Jèhófà nìṣó.

Lẹ́yìn tí mo parí ilé ẹ̀kọ́ girama, mi ò fi bẹ́ẹ̀ nítara mọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Mo ronú pé tí mo bá di aṣáájú-ọ̀nà, mi ò ní lówó táá jẹ́ kí n lè wọ ọkọ̀ òfúrufú lọ sáwọn orílẹ̀-èdè tó wù mí káàkiri ayé. Mo ríṣẹ́ sí iléeṣẹ́ rédíò kan tó wà lágbègbè wa, èmi ni mo máa ń gbé orin táwọn èèyàn ti kọ sáfẹ́fẹ́, mo sì nífẹ̀ẹ́ iṣẹ́ náà gan-an. Torí pé mo máa ń ṣiṣẹ́ nírọ̀lẹ́, kì í jẹ́ kí n wá sípàdé déédéé, ìyẹn sì máa ń jẹ́ kí n kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn tí ò nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Àmọ́ nígbà tó yá, ẹ̀rí ọkàn mi tí mo ti fi Bíbélì kọ́ jẹ́ kí n ṣe àwọn àyípadà tó yẹ.

Mo kó lọ sílùú Oshawa, ní agbègbè Ontario. Nígbà tí mo débẹ̀, mo pàdé Ray Norman pẹ̀lú àbúrò ẹ̀ obìnrin tó ń jẹ́ Lesli àtàwọn aṣáájú-ọ̀nà míì. Inú gbogbo wọn dùn nígbà tí wọ́n rí mi, wọ́n sì jẹ́ kára mi mọlé. Nígbà tí mo rí bí wọ́n ṣe ń láyọ̀, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ronú nípa ohun tí mo fẹ́ fayé mi ṣe. Wọ́n gbà mí níyànjú pé kí n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, mo sì ṣe bẹ́ẹ̀ ní September 1966. Látìgbà yẹn, inú mi máa ń dùn gan-an, mo sì ń gbádùn ayé mi. Mi ò mọ̀ pé àwọn nǹkan tó máa yí ìgbésí ayé mi pa dà máa tó ṣẹlẹ̀.

TÍ JÈHÓFÀ BÁ GBÉ IṢẸ́ KAN FÚN Ẹ, GBÌYÀNJÚ KÓ O ṢE É

Nígbà tí mo ṣì wà nílé ẹ̀kọ́ girama, mo gba fọ́ọ̀mù Bẹ́tẹ́lì, kí n lè lọ ṣiṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì tó wà nílùú Toronto, lórílẹ̀-èdè Kánádà. Nígbà tó yá, mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, wọ́n sì pè mí kí n wá lo ọdún mẹ́rin ní Bẹ́tẹ́lì. Àmọ́ mo nífẹ̀ẹ́ Lesli gan-an, mo wá ń bẹ̀rù pé tí mo bá lọ sí Bẹ́tẹ́lì, èmi àti ẹ̀ lè má ríra mọ́. Lẹ́yìn tí mo gbàdúrà gan-an lórí ọ̀rọ̀ náà, mo gbà láti lọ. Àmọ́ inú mi ò dùn nígbà tí mò ń dágbére fún Lesli.

Nígbà tí mo dé Bẹ́tẹ́lì, ibi tí wọ́n ti ń fọṣọ ni mo ti kọ́kọ́ ṣiṣẹ́, lẹ́yìn náà mo ṣiṣẹ́ akọ̀wé. Àsìkò yẹn náà ni Lesli di aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe ní Gatineau, Quebec. Gbogbo ìgbà ni mo máa ń ronú nípa ohun tó ń ṣe àti bóyá ìpinnu tó tọ́ lèmi náà ṣe. Kò pẹ́ sígbà yẹn, ohun kan ṣẹlẹ̀ tí mi ò lè gbàgbé láyé mi. Wọ́n pe Ray tó jẹ́ ẹ̀gbọ́n Lesli sí Bẹ́tẹ́lì, a sì jọ ń gbé níyàrá kan náà. Ìyẹn jẹ́ kémi àti Lesli tún pa dà dọ̀rẹ́. Ní February 27, 1971, ìyẹn ọjọ́ tó pé ọdún mẹ́rin tí mo ti wà ní Bẹ́tẹ́lì la ṣègbéyàwó.

Ìgbà tá a bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ alábòójútó àyíká lọ́dún 1975

Wọ́n ní kí èmi àti Lesli lọ dara pọ̀ mọ́ ìjọ kan tó ń sọ èdè Faransé ní Quebec. Lẹ́yìn ọdún díẹ̀, ó yà mí lẹ́nu gan-an nígbà tí wọ́n ní kí n máa ṣiṣẹ́ alábòójútó àyíká ní ẹni ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n (28). Mo ronú pé ọjọ́ orí mi kéré ju ẹni tó lè ṣiṣẹ́ náà, àmọ́ ohun tó wà nínú Jeremáyà 1:7, 8 ràn mí lọ́wọ́. Jàǹbá ọkọ̀ ti ṣẹlẹ̀ sí Lesli nígbà mélòó kan, kì í sì í rórun sùn. Torí náà, a ronú pé iṣẹ́ alábòójútó àyíká máa nira fún wa. Àmọ́, ìyàwó mi sọ pé, “Tí Jèhófà bá ní ká ṣe ohun kan, ṣé kò yẹ ká gbìyànjú ẹ̀ wò ni?” Bá a ṣe bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ alábòójútó àyíká nìyẹn o, ọdún mẹ́tàdínlógún (17) la sì fi gbádùn ẹ̀.

Ọwọ́ mi máa ń dí gan-an nígbà tí mò ń ṣiṣẹ́ alábòójútó àyíká, mi kì í sì í fi bẹ́ẹ̀ ráyè wà pẹ̀lú Lesli. Àmọ́ ohun kan ṣẹlẹ̀ tó jẹ́ kí n rí i pé ó yẹ kí n máa ṣe bẹ́ẹ̀. Láàárọ̀ kùtù ọjọ́ Monday kan, ẹnì kan tẹ aago ẹnu ọ̀nà wa. Nígbà tí mo jáde sẹ́nu ọ̀nà, mi ò rí ẹnì kankan níbẹ̀, àmọ́ mo rí apẹ̀rẹ̀ tí wọ́n máa ń kó nǹkan sí tí wọ́n bá fẹ́ lọ gbafẹ́. Àwọn nǹkan tó sì wà nínú ẹ̀ ni aṣọ tí wọ́n máa ń tẹ́ sórí tábìlì, èso, bọ́tà, búrẹ́dì, ìgò wáìnì kan, kọ́ọ̀bù àti ìwé kékeré tẹ́nì kan kọ ọ̀rọ̀ sínú ẹ̀ pé, “Gbé ìyàwó ẹ ṣeré jáde.” Inú wa dùn gan-an lọ́jọ́ yẹn, àmọ́ torí pé mo ní àsọyé tí mò ń múra, mo sọ fún Lesli pé a ò ní lè lọ. Ọ̀rọ̀ mi yé e, àmọ́ inú ẹ̀ ò dùn. Níbi tí mo jókòó sí, ẹ̀rí ọkàn mi ń dà mí láàmú pé mi ò gbé e jáde. Mo wá ronú nípa ohun tó wà nínú Éfésù 5:25, 28. Ẹsẹ Bíbélì yẹn jẹ́ kí n rí i pé Jèhófà fẹ́ kí n máa gba ti ìyàwó mi rò. Lẹ́yìn tí mo gbàdúrà nípa ẹ̀, mo sọ fún Lesli pé, “Ó yá, jẹ́ ká lọ,” ìyẹn sì múnú ẹ̀ dùn gan-an. A wa mọ́tò lọ sétí omi kan tó pa rọ́rọ́, a tẹ́ aṣọ tábìlì sílẹ̀, a jọ ṣeré pa pọ̀ lọ́jọ́ yẹn, a sì gbádùn ẹ̀ gan-an. Nígbà tá a pa dà délé, mo ṣì tún ráyè múra àwọn àsọyé mi.

Nígbà tá à ń ṣiṣẹ́ alábòójútó àyíká ní agbègbè British Columbia títí dé Newfoundland, a gbádùn ẹ̀ gan-an. Ní báyìí, mò ń rìnrìn àjò lọ sáwọn agbègbè tó wù mí kí n lọ láti kékeré. Ó ti pẹ́ tí mo ti máa ń ronú pé kí n gba fọ́ọ̀mù Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì, àmọ́ kò wù mí kí n lọ ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì lórílẹ̀-èdè míì. Èrò mi ni pé àwọn èèyàn pàtàkì ló ń ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì, irú mi sì kọ́ ni wọ́n ń wá níbẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, ẹ̀rù ń bà mí pé wọ́n lè rán wa lọ sí orílẹ̀-èdè kan ní Áfíríkà tí àrùn ti pọ̀, tí wọ́n sì máa ń jagun. Torí náà, Kánádà tá a wà tẹ́ wa lọ́rùn.

Ó YÀ WÁ LẸ́NU NÍGBÀ TÍ WỌ́N RÁN WA LỌ SÍ ESTONIA ÀTI AGBÈGBÈ BALTICS

Ìgbà tá à ń rìnrìn àjò káàkiri agbègbè Baltics

Lọ́dún 1992, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà láǹfààní láti tún pa dà máa wàásù láwọn orílẹ̀-èdè tí ìjọba Soviet Union ń ṣàkóso tẹ́lẹ̀. Ètò Ọlọ́run bi wá bóyá a máa lè lọ sí Estonia láti lọ ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì níbẹ̀. Ó yà wá lẹ́nu gan-an nígbà tá a gbọ́, àmọ́ a gbàdúrà nípa ẹ̀. Torí náà, a tún pa dà bi ara wa pé, ‘Tí Jèhófà bá ní ká ṣe ohun kan, ṣé kò yẹ ká gbìyànjú ẹ̀ wò ni?’ Bá a ṣe gbà láti lọ nìyẹn, mo wá sọ pé, ‘Ó ṣe tán, kì í ṣe Áfíríkà ni wọ́n rán wa lọ.’

Gbàrà tá a débẹ̀ la bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ èdè Estonia. Lẹ́yìn tá a ti lo oṣù bíi mélòó kan níbẹ̀, wọ́n ní ká bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ alábòójútó àyíká. A máa ní láti ṣèbẹ̀wò sáwọn ìjọ tó tó mẹ́rìndínláàádọ́ta (46) àtàwọn àwùjọ kan lágbègbè Baltics. Àwọn orílẹ̀-èdè mẹ́ta tó wà lágbègbè náà ni Estonia, Latvia àti Lithuania títí kan ìlú kan tó ń jẹ́ Kaliningrad ní agbègbè Rọ́ṣíà. Ó sì máa gba pé ká kọ́ èdè àwọn ará Latvia, Lithuania àti Rọ́ṣíà. Ìyẹn ò rọrùn rárá, síbẹ̀ inú àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa ń dùn pé à ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti kọ́ èdè wọn, wọ́n sì ràn wá lọ́wọ́. Lọ́dún 1999, wọ́n kọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì sí Estonia, ètò Ọlọ́run sì ní kí n wà lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka. Àwọn arákùnrin tá a jọ wà nínú ìgbìmọ̀ náà ni Toomas Edur, Lembit Reile àti Tommi Kauko.

Apá Òsì: Ìgbà tí mò ń sọ àsọyé ní àpéjọ kan ní Lithuania

Apá Ọ̀tún: Àwọn tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka Estonia nígbà tí wọ́n dá a sílẹ̀ lọ́dún 1999

A rí ọ̀pọ̀ àwọn ará tí ìjọba kó lọ sí Siberia nígbà kan. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n fìyà jẹ wọ́n lẹ́wọ̀n, tí wọn ò sì jẹ́ kí wọ́n rí ìdílé wọn, wọn ò banú jẹ́. Wọ́n ń fìtara wàásù nìṣó, wọ́n sì ń láyọ̀. Ohun tí wọ́n ṣe yìí jẹ́ ká rí i pé àwa náà lè fara da ìṣòro, ká sì máa láyọ̀.

Ọ̀pọ̀ ọdún la fi ṣiṣẹ́ kára, àmọ́ a kì í fi bẹ́ẹ̀ sinmi, torí náà ó máa ń rẹ Lesli gan-an. A ò tètè mọ̀ pé àìsàn tó ń mú kí iṣan àti ẹran ara roni ló ń ṣe é. Torí náà, a rí i pé ó yẹ ká pa dà sí Kánádà. Nígbà tí wọ́n pè wá sí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka Àtàwọn Ìyàwó Wọn ní Patterson, New York, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, mo rò pé a ò ní lè lọ. Àmọ́ lẹ́yìn tá a gbàdúrà gan-an nípa ẹ̀, a gbà láti lọ. Jèhófà sì ràn wá lọ́wọ́ nígbà tá a débẹ̀. Ìgbà tá a dé ilé ẹ̀kọ́ yẹn ni Lesli gba ìtọ́jú tó yẹ nílé ìwòsàn, ìyẹn sì jẹ́ ká máa bá iṣẹ́ wa nìṣó.

Ó YÀ WÁ LẸ́NU NÍGBÀ TÍ WỌ́N NÍ KÁ LỌ SÓRÍLẸ̀-ÈDÈ KAN NÍ ÁFÍRÍKÀ

Nírọ̀lẹ́ ọjọ́ kan lọ́dún 2008 nígbà tá a ṣì wà ní Estonia, wọ́n pè mí láti oríléeṣẹ́ wa pé ṣé àá lè lọ ṣiṣẹ́ ní orílẹ̀-èdè Kóńgò. Ó yà mí lẹ́nu gan-an, yàtọ̀ síyẹn wọ́n tún fẹ́ kí n fún àwọn lésì lọ́jọ́ kejì. Mi ò sọ fún ìyàwó mi lálẹ́ ọjọ́ yẹn torí mo mọ̀ pé kò ní rórun sùn. Àmọ́, èmi gan-an ni ò rórun sùn torí mò ń gbàdúrà sí Jèhófà nípa àwọn nǹkan tó ń bà mí lẹ́rù ní Áfíríkà.

Nígbà tó dọjọ́ kejì, mo sọ fún Lesli, a sì gbà pé “Jèhófà fẹ́ ká lọ sí Áfíríkà. Àmọ́, báwo la ṣe máa mọ̀ pé a ò ní lè ṣe é tá ò bá gbìyànjú ẹ̀ wò?” Torí náà, lẹ́yìn tá a ti lo ọdún mẹ́rìndínlógún (16) ní Estonia, a gbéra lọ sí Kinshasa, lórílẹ̀-èdè Kóńgò. Ọgbà ẹ̀ka ọ́fíìsì náà rẹwà, ó sì tura. Ọ̀kan lára ohun tí Lesli kọ́kọ́ fi sínú yàrá wa ni káàdì kan tó tọ́jú látìgbà tá a ti kúrò ní Kánádà. Ohun tó wà nínú káàdì náà ni “Máa láyọ̀ níbikíbi tó o bá wà.” Lẹ́yìn tá a ti bá àwọn ará tó wà níbẹ̀ ṣiṣẹ́, tá à ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tá a sì ń gbádùn iṣẹ́ míṣọ́nnárì wa, ayọ̀ wa ń pọ̀ sí i. Nígbà tó yá, a láǹfààní láti ṣèbẹ̀wò sí ẹ̀ka ọ́fíìsì mẹ́tàlá (13) láwọn orílẹ̀-èdè míì ní Áfíríkà. Ìyẹn jẹ́ ká rí àwọn ará tí àṣà ìbílẹ̀ wọn yàtọ̀ síra, tí wọ́n sì ń láyọ̀. Ẹ̀rù Áfíríkà ò wá bà mí mọ́, torí náà mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó rán wa wá sí Áfíríkà láti wá ṣiṣẹ́.

Nígbà tá a wà ní Kóńgò, wọ́n fún wa láwọn oúnjẹ kan, lára ẹ̀ ni àwọn kòkòrò tí mo rò pé a ò ní lè jẹ. Àmọ́ nígbà tá a rí àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó ń jẹ ẹ́, àwa náà tọ́ ọ wò, a sì gbádùn ẹ̀ dáadáa.

A rìnrìn àjò lọ sí ìlà oòrùn orílẹ̀-èdè náà láti lọ fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gba àwọn ará níyànjú, a sì tún kó àwọn ohun tí wọ́n nílò dání fún wọn. Níbẹ̀, àwọn ẹgbẹ́ tó ń ṣọ̀tẹ̀ síjọba máa ń da àwọn abúlé rú, wọ́n sì máa ń ṣe àwọn obìnrin àtàwọn ọmọdé léṣe. Ọ̀pọ̀ àwọn ará wa tó wà níbẹ̀ ló jẹ́ tálákà. Síbẹ̀, wọ́n nígbàgbọ́ tó lágbára pé àwọn òkú máa jíǹde, wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, wọn ò sì fi ètò ẹ̀ sílẹ̀. Ìyẹn wú wa lórí gan-an. Àpẹẹrẹ wọn jẹ́ ká rí i pé ó yẹ káwa náà yẹ ara wa wò, ká sì jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa nínú Jèhófà túbọ̀ lágbára. Àwọn kan lára wọn ti pàdánù ilé àti oko wọn. Ìyẹn jẹ́ kí n rí i pé nǹkan ìní lè pa run nígbàkigbà, àmọ́ àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Jèhófà máa wà títí láé. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé nǹkan ò rọrùn fáwọn ará, wọn kì í ráhùn. Bí wọn ò ṣe jẹ́ kí ìṣòro wọn bò wọ́n mọ́lẹ̀ ti jẹ́ káwa náà nígboyà láti fara da ìṣòro àti àìsàn wa.

Apá Òsì: Mò ń sọ àsọyé fún àwùjọ àwọn tó sá kúrò lórílẹ̀-èdè wọn

Apá Ọ̀tún: Ìgbà tá a kó nǹkan táwọn ará nílò àti oògùn lọ sí Dungu, ní Kóńgò

WỌ́N NÍ KÁ LỌ ṢIṢẸ́ NÍLẸ̀ ÉṢÍÀ

Ó yà wá lẹ́nu gan-an nígbà tí wọ́n ní ká máa lọ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà ní Hong Kong. Mi ò rò ó rí pé mo lè gbé ilẹ̀ Éṣíà! Àmọ́ nígbà tá a rí bí Jèhófà ṣe ràn wá lọ́wọ́ láwọn iṣẹ́ tá a ti ṣe sẹ́yìn, a gbà láti lọ. Torí náà, lọ́dún 2013, omi ń bọ́ lójú wa nígbà tá à ń fi àwọn ọ̀rẹ́ wa àtàwọn nǹkan àrà tó wà ní Áfíríkà sílẹ̀, a ò sì mọ ohun tá a máa bá pàdé níbi tá à ń lọ.

Ìyípadà ńlá gbáà ló jẹ́ nígbà tá a dé Hong Kong torí pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń gbé ìlú ńlá yìí, wọ́n sì wá láti ibi gbogbo láyé. Kò rọrùn fún wa láti kọ́ èdè Chinese torí ó le gan-an. Àwọn ará gbà wá tọwọ́tẹsẹ̀, a sì gbádùn oúnjẹ ìbílẹ̀ wọn. Iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe ní ẹ̀ka ọ́fíìsì ń pọ̀ sí i, àmọ́ owó tí wọ́n ń ta ilẹ̀ wọ́n gan-an. Torí náà, Ìgbìmọ̀ Olùdarí pinnu pé àwọn máa ta ọ̀pọ̀ lára ilẹ̀ tó wà ní ẹ̀ka ọ́fíìsì. Kò pẹ́ sígbà yẹn lọ́dún 2015, wọ́n ní ká máa lọ sí South Korea láti máa báṣẹ́ wa nìṣó níbẹ̀. Ìyẹn tún gba pé ká kọ́ èdè míì tó le, ìyẹn èdè Kòríà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ò tíì mọ èdè náà sọ dáadáa, àwọn ará fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé a máa tó mọ̀ ọ́n.

Apá Òsì: Ìgbà tá a dé Hong Kong

Apá Ọ̀tún: Ẹ̀ka ọ́fíìsì Kòríà

ÀWỌN Ẹ̀KỌ́ TÁ A KỌ́ LẸ́NU IṢẸ́ ÌSÌN JÈHÓFÀ

Kò rọrùn láti ní àwọn ọ̀rẹ́ tuntun, àmọ́ nígbà tá a gba àwọn èèyàn lálejò, ó jẹ́ ká tètè mọ̀ wọ́n. A ti rí i pé lóòótọ́, àwọ̀ àwọn ará kárí ayé lè yàtọ̀, àmọ́ ìwà wọn ò fi bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ síra àti pé Jèhófà dá wa lọ́nà tó máa ń jẹ́ ká sọ ohun tó wà lọ́kàn wa, ká sì fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn.​—2 Kọ́r. 6:11.

A ti rí i pé ojú tí Jèhófà fi ń wo àwọn èèyàn ló yẹ ká máa fi wò wọ́n, ká sì máa kíyè sí àwọn nǹkan tó fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ wa àti pé ó ń tọ́ wa sọ́nà. Nígbàkigbà tá a bá rẹ̀wẹ̀sì tàbí tá a rò pé àwọn èèyàn ò nífẹ̀ẹ́ wa, a máa ń pa dà ka àwọn káàdì àti lẹ́tà táwọn ọ̀rẹ́ wa fi fún wa níṣìírí. A ti rí bí Jèhófà ṣe dáhùn àwọn àdúrà wa, ó jẹ́ ká rí i pé òun nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì fún wa lókun ká lè máa báṣẹ́ náà nìṣó.

Látàwọn ọdún yìí wá, èmi àti Lesli ti rí i pé ó yẹ ká máa wáyè wà pa pọ̀ bí ọwọ́ wa tiẹ̀ dí. A tún ti rí i pé ó dáa bá a ṣe ń fi ara wa rẹ́rìn-ín tá a bá ṣàṣìṣe, pàápàá nígbà tá à ń kọ́ èdè tuntun. Yàtọ̀ síyẹn, alaalẹ́ la máa ń ronú nípa ohun kan tí Jèhófà ṣe fún wa ká lè dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀.

Ká sòótọ́, mi ò mọ̀ pé mo lè di míṣọ́nnárì tàbí kí n lọ gbé lórílẹ̀-èdè míì. Síbẹ̀, mo ti rí i pé Jèhófà máa ń ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe ohun tá a rò pé kò lè ṣeé ṣe, ìyẹn sì ń jẹ́ kí n láyọ̀. Mo wá rántí ọ̀rọ̀ wòlíì Jeremáyà tó sọ pé: “O ti yà mí lẹ́nu, Jèhófà.” (Jer. 20:7) Lóòótọ́, Jèhófà ti ṣe àwọn ohun tó yà wá lẹ́nu gan-an, ó sì ti bù kún wa lọ́pọ̀lọpọ̀. Jèhófà jẹ́ kọ́wọ́ mi tẹ ohun tó ti ń wù mí láti kékeré, ìyẹn bó ṣe ń wù mí láti wọkọ̀ òfúrufú lọ sáwọn orílẹ̀-èdè kan. Kódà, a wọkọ̀ òfúrufú lọ sáwọn orílẹ̀-èdè tí mi ò lérò ní kékeré pé mo lè dé, mo sì ṣèbẹ̀wò sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè. Lesli ràn mí lọ́wọ́ gan-an nínú gbogbo iṣẹ́ tí wọ́n bá ní ká ṣe, mo sì mọyì ẹ̀.

Gbogbo ìgbà la máa ń rán ara wa létí pé Jèhófà là ń ṣiṣẹ́ fún torí pé a nífẹ̀ẹ́ ẹ̀. Gbogbo ohun tá à ń gbádùn báyìí kàn jẹ́ ìtọ́wò tá a bá fi wé ohun tá a máa gbádùn nígbà tá a bá ń gbé ayé títí láé, ìyẹn ìgbà tí Jèhófà máa ‘ṣí ọwọ́ rẹ̀, tó sì máa fún gbogbo ohun alààyè ní ohun tí wọ́n ń fẹ́.’​—Sm. 145:16.