Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 28

Wàá Jàǹfààní Tó O Bá Ń Bẹ̀rù Ọlọ́run

Wàá Jàǹfààní Tó O Bá Ń Bẹ̀rù Ọlọ́run

“Ẹni tó ń rìn nínú ìdúróṣinṣin ń bẹ̀rù Jèhófà.”​—ÒWE 14:2.

ORIN 122 Ẹ Fẹsẹ̀ Múlẹ̀ Ṣinṣin!

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ a

1-2. Ìṣòro wo làwa Kristẹni ń bá pàdé lónìí tó jọ ti ìgbà ayé Lọ́ọ̀tì?

 TÁ A bá wo bí ìwàkiwà ṣe kún inú ayé lónìí, ó dájú pé bí nǹkan ṣe rí lára Lọ́ọ̀tì náà ló rí lára wa. Bíbélì sọ pé ó “banú jẹ́ gidigidi nítorí ìwà àìnítìjú àwọn arúfin èèyàn” torí ó mọ̀ pé Baba wa ọ̀run kórìíra ìwà burúkú. (2 Pét. 2:7, 8) Kí nìdí tí Lọ́ọ̀tì fi kórìíra ìwà burúkú ìgbà ayé ẹ̀? Ìdí ni pé ó bẹ̀rù Ọlọ́run, ó sì nífẹ̀ẹ́ ẹ̀. Bákan náà lónìí, ìwà burúkú ló gba ayé kan torí pé àwọn èèyàn ò bẹ̀rù Ọlọ́run. Bó ti wù kó rí, àwa Kristẹni ṣì lè jẹ́ oníwà mímọ́ tá a bá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, tá a sì ń bẹ̀rù ẹ̀ tọkàntọkàn.​—Òwe 14:2.

2 Kíyẹn lè ṣeé ṣe, Jèhófà jẹ́ kí wọ́n kọ àwọn ohun tó yẹ ká ṣe àtàwọn ohun tí ò yẹ ká ṣe sínú ìwé Òwe, ó sì rọ̀ wá pé ká máa ṣe ohun tó tọ́. Torí náà, gbogbo àwa Kristẹni pátápátá lọ́mọdé lágbà, lọ́kùnrin àti lóbìnrin la máa jàǹfààní tá a bá ń fi ìmọ̀ràn inú ẹ̀ sílò.

ÌBẸ̀RÙ ỌLỌ́RUN MÁA Ń DÁÀBÒ BÒ WÁ

Níbiiṣẹ́ wa, kò yẹ ká máa bá àwọn tí kì í tẹ̀ lé ìlànà Jèhófà ṣọ̀rẹ́, kò sì yẹ ká gbà tí wọ́n bá ní ká ṣe ohun tí inú Ọlọ́run ò dùn sí (Wo ìpínrọ̀ 3)

3.Òwe 17:3 ṣe sọ, kí nìdí tó fi yẹ ká máa kíyè sí ohun tó wà lọ́kàn wa? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

3 Ìdí pàtàkì tó fi yẹ ká máa kíyè sí ohun tó wà lọ́kàn wa ni pé Jèhófà máa ń ṣàyẹ̀wò ọkàn. Ìyẹn ni pé arínúróde ni Jèhófà, ó sì mọ̀ wá ju báwọn èèyàn ṣe mọ̀ wá lọ. (Ka Òwe 17:3.) Tá a bá ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n tí Jèhófà ń fún wa, ó máa nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì máa jẹ́ ká wà láàyè títí láé. (Jòh. 4:14) Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a ò ní ṣèṣekúṣe, a ò sì ní hùwà ìbàjẹ́ tí Sátánì àtàwọn èèyàn ayé ń fẹ́. (1 Jòh. 5:18, 19) Bá a bá ṣe ń sún mọ́ Jèhófà, bẹ́ẹ̀ làá túbọ̀ máa nífẹ̀ẹ́ ẹ̀, tí àá sì máa bọ̀wọ̀ fún un. Torí pé a ò fẹ́ ṣe ohun tó máa dun Baba wa ọ̀run, a ò ní máa ro èròkerò tó lè mú ká dẹ́ṣẹ̀. Torí náà, tó bá ń ṣe wá bíi pé ká ṣe ohun tí ò tọ́, ó yẹ ká bi ara wa pé, ‘Ṣé ó yẹ kí n mọ̀ọ́mọ̀ ṣe ohun tó máa dun Ẹni tó nífẹ̀ẹ́ mi gan-an?’​—1 Jòh. 4:9, 10.

4. Báwo ni ìbẹ̀rù Jèhófà ò ṣe jẹ́ kí arábìnrin kan ṣèṣekúṣe?

4 Ìgbà kan wà tó máa ń ṣe Arábìnrin Marta tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Croatia bíi pé kó ṣèṣekúṣe, ó sọ pé: “Ó máa ń wù mí láti ṣèṣekúṣe, kò sì rọrùn fún mi láti borí èrò burúkú yìí. Àmọ́ torí pé mo bẹ̀rù Jèhófà, mi ò ṣèṣekúṣe.” b Báwo ni ìbẹ̀rù Ọlọ́run ṣe ran Arábìnrin Marta lọ́wọ́? Ó sọ pé òun máa ń ronú lórí ibi tọ́rọ̀ náà máa já sí torí òun mọ̀ pé ìgbẹ̀yìn ẹ̀ ò ní dáa. Bó ṣe yẹ káwa náà máa ronú nìyẹn. Èyí tó burú jù níbẹ̀ ni pé tá a bá ṣèṣekúṣe, inú Jèhófà ò ní dùn sí wa, ó sì lè má tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wa mọ́.​—Jẹ́n. 6:5, 6.

5. Kí lo kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Leo?

5 Tá a bá bẹ̀rù Jèhófà lóòótọ́, kò yẹ ká máa kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn tó ń hùwàkiwà. Arákùnrin Leo tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Kóńgò rí i pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí. Lẹ́yìn ọdún mẹ́rin tó ṣèrìbọmi, ó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́gbẹ́kẹ́gbẹ́. Ó gbà pé tóun ò bá ṣáà ti ṣe ohun tí ò dáa, òun ò ṣẹ Jèhófà. Àmọ́ kò sí kí àgùntàn tó ń bájá rìn má jẹ̀gbẹ́. Torí náà, kò pẹ́ tí àwọn tó ń bá kẹ́gbẹ́ fi mú kó bẹ̀rẹ̀ sí í mutí yó, kó sì ṣèṣekúṣe. Ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í ronú lórí ohun táwọn òbí ẹ̀ tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti kọ́ ọ àti bó ṣe máa ń láyọ̀ tẹ́lẹ̀. Kí nìyẹn wá mú kó ṣe? Ó ronú pìwà dà, àwọn alàgbà sì ràn án lọ́wọ́ láti pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà. Ní báyìí, ó ti di alàgbà, aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe sì ni.

6. Àwọn obìnrin méjì wo la máa sọ̀rọ̀ nípa wọn báyìí?

6 Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa Òwe orí 9, níbi tí Bíbélì ti fi ọgbọ́n àti ìwà òmùgọ̀ wé obìnrin méjì. (Fi wé Róòmù 5:14; Gálátíà 4:24.) Bá a ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀, ká má gbàgbé pé ìṣekúṣe àti ìwòkuwò ti mọ́ àwọn èèyàn lára nínú ayé tí Sátánì ń darí yìí. (Éfé. 4:19) Torí náà, ó ṣe pàtàkì pé ká máa bẹ̀rù Ọlọ́run, ká sì máa sá fún ìwà burúkú. (Òwe 16:6) Gbogbo wa pátápátá lọ́kùnrin àti lóbìnrin la máa jàǹfààní nínú ohun tó wà nínú ìwé Òwe orí kẹsàn-án. Bíbélì sọ pé àwọn obìnrin méjì yìí ń pe àwọn aláìmọ̀kan, ìyẹn “àwọn tí kò ní làákàyè” pé kí wọ́n wá. Kálukú wọn ló ń sọ pé, ‘Wá sílé mi kó o wá jẹun.’ (Òwe 9:1, 5, 6, 13, 16, 17) Àmọ́, ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn tó lọ sọ́dọ̀ obìnrin àkọ́kọ́ yàtọ̀ pátápátá sóhun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn tó lọ sọ́dọ̀ obìnrin kejì.

MÁ LỌ SỌ́DỌ̀ ÒMÙGỌ̀ OBÌNRIN

“Òmùgọ̀ obìnrin” ń pe àwọn èèyàn pé kí wọ́n wá ṣe ohun tó máa jẹ́ kí wọ́n kàgbákò (Wo ìpínrọ̀ 7)

7. Kí ni Òwe 9:13-18 sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ sáwọn tó bá lọ sọ́dọ̀ òmùgọ̀ obìnrin yẹn? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

7 Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí “òmùgọ̀ obìnrin” náà ń sọ. (Ka Òwe 9:13-18.) Gbogbo ẹnu ló fi ń pe àwọn tí kò ní làákàyè pé ẹ “Wọlé síbí,” kẹ́ ẹ wá jẹun. Kí ló ṣẹlẹ̀ sáwọn tó lọ? Bíbélì sọ pé: “Àwọn tí ikú ti pa wà níbẹ̀.” Ó ṣeé ṣe kó o rántí pé ìwé Òwe ti sọ irú ọ̀rọ̀ yìí tẹ́lẹ̀. Ó kìlọ̀ fún wa nípa “obìnrin oníwàkiwà” àti “obìnrin oníṣekúṣe.” Bíbélì sọ fún wa pé: “Ilé rẹ̀ ń rini sínú ikú.” (Òwe 2:11-19) Òwe 5:3-10 tún kìlọ̀ fún wa nípa “obìnrin oníwàkiwà” tí “ẹsẹ̀ rẹ̀ lọ sí ikú.”

8. Ìpinnu wo la gbọ́dọ̀ ṣe?

8 Àwọn tó ń gbọ́ ohun tí “òmùgọ̀ obìnrin” yẹn ń sọ máa ní láti ṣe ìpinnu: Ṣé wọ́n máa lọ sọ́dọ̀ ẹ̀ àbí wọn ò ní lọ? Àwa náà gbọ́dọ̀ pinnu ohun tá a máa ṣe tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀ sí wa. Torí náà, kí la máa ṣe tẹ́nì kan bá fi ìṣekúṣe lọ̀ wá? Tí àwòrán ìṣekúṣe bá sì jáde lórí tẹlifíṣọ̀n tàbí nígbà tá a wà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, kí la máa ṣe?

9-10. Kí nìdí tí ò fi yẹ ká ṣèṣekúṣe?

9 Ìdí pàtàkì wà tí ò fi yẹ ká ṣèṣekúṣe. Bíbélì ní “òmùgọ̀ obìnrin” ń sọ pé: “Omi tí a jí gbé máa ń dùn.” Kí ni “omi tí a jí gbé”? Bíbélì sọ pé ìbálòpọ̀ tó wà láàárín tọkọtaya dà bí omi tó ń tuni lára. (Òwe 5:15-18) Ọkùnrin àti obìnrin tó ti ṣègbéyàwó sì máa ń gbádùn ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ara wọn tí wọ́n bá ṣe é lọ́nà tó tọ́. Ẹ ò rí i pé ìyẹn yàtọ̀ pátápátá sí “omi tí a jí gbé,” tó ṣeé ṣe kó jẹ́ ìbálòpọ̀ tí ò bófin mu tó ń wáyé láàárín àwọn tí ò bá ara wọn ṣègbéyàwó. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ kì í jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé wọ́n ń bára wọn lò pọ̀. Ṣe ló dà bí olè tí kì í jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ tó bá fẹ́ jí nǹkan. “Omi tí a jí gbé” máa ń dùn lẹ́nu àwọn tó ń mu ún torí wọ́n rò pé wọn ò ní jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Ẹ ò rí i pé wọ́n ń tan ara wọn jẹ ni! Jèhófà ń rí gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe. Kò sí nǹkan tó korò tó kéèyàn pàdánù ojú rere Jèhófà, torí náà kò sí adùn kankan níbẹ̀. (1 Kọ́r. 6:9, 10) Àmọ́, àwọn jàǹbá míì wà tí ìṣekúṣe máa ń fà.

10 Tó o bá ṣèṣekúṣe, ó lè kó ìtìjú bá ẹ. O ò ní níyì lójú ara ẹ mọ́. Ó lè jẹ́ kó o gboyún àpàpàǹdodo, ó sì lè tú ìdílé ká. Ká sòótọ́, ìwà ọgbọ́n ni tá ò bá lọ sí “ilé” òmùgọ̀ obìnrin. Yàtọ̀ sí pé àwọn tó ń ṣèṣekúṣe máa ń pàdánù àjọṣe wọn pẹ̀lú Jèhófà, wọ́n tún máa ń kó àrùn tó lè mú kí wọ́n kú láìtọ́jọ́. (Òwe 7:23, 26) Ọ̀rọ̀ tó parí Òwe orí 9 ẹsẹ 18 sọ pé: “Àwọn àlejò rẹ̀ wà ní ìsàlẹ̀ Isà Òkú.” Àmọ́, kí wá nìdí tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi ń lọ sílé obìnrin náà, tí wọ́n sì ń kàgbákò?​—Òwe 9:13-18.

11. Kí nìdí tó fi léwu gan-an téèyàn bá ń wo fíìmù àti àwòrán ìṣekúṣe?

11 Lónìí, fíìmù àti àwòrán ìṣekúṣe gbòde kan, ó sì yẹ ká sá fún un. Èrò àwọn kan ni pé téèyàn bá ń wò wọ́n, kò lè ṣe ìpalára kankan. Àmọ́ irọ́ gbáà nìyẹn torí ó máa ń pani lára, kì í jẹ́ kéèyàn níyì, ó sì máa ń ṣòro láti jáwọ́ níbẹ̀. Téèyàn bá ń wo àwòrán ìṣekúṣe, ó máa ń pẹ́ gan-an kí onítọ̀hún tó gbàgbé ẹ̀. Èyí tó burú jù níbẹ̀ ni pé ó máa ń jẹ́ kó wu èèyàn láti ṣèṣekúṣe. (Kól. 3:5; Jém. 1:14, 15) Òótọ́ kan ni pé àwọn tó bá ń wo ìwòkuwò máa ń ṣèṣekúṣe tó bá yá.

12. Tá a bá rí àwòrán tó lè mú ká ro èròkerò, kí ló yẹ ká ṣe?

12 Kí ló yẹ ká ṣe tí àwòrán ìṣekúṣe bá ṣàdédé jáde lórí fóònù tàbí kọ̀ǹpútà wa? Ṣe ló yẹ ká gbé ojú wa kúrò lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Ohun tó máa jẹ́ ká ṣe bẹ́ẹ̀ ni tá a bá rántí pé àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà ló ṣeyebíye jù lọ. Kódà, àwọn àwòrán kan wà tí kì í ṣe àwòrán ìṣekúṣe tó lè mú ká máa ro èròkerò. Kí nìdí tí ò fi yẹ ká máa wo irú àwọn àwòrán bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé ó lè mú ká ṣàgbèrè nínú ọkàn wa, a ò sì ní fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀. (Mát. 5:28, 29) Alàgbà kan tó ń jẹ́ David lórílẹ̀-èdè Thailand sọ pé: “Mo máa ń bi ara mi pé, ‘Tí àwòrán kan kì í bá tiẹ̀ ṣe àwòrán ìṣekúṣe, ṣé inú Jèhófà máa dùn sí mi tí mo bá ń wò ó?’ Ìbéèrè tí mo máa ń bi ara mi yìí kì í jẹ́ kí n wo irú àwọn àwòrán bẹ́ẹ̀.”

13. Kí ló máa jẹ́ ká ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́?

13 Tá a bá ń bẹ̀rù Jèhófà tọkàntọkàn, a ò ní ṣe ohun tí ò fẹ́. Ìbẹ̀rù Ọlọ́run ni “ìbẹ̀rẹ̀” tàbí ìpìlẹ̀ “ọgbọ́n.” (Òwe 9:10) A ṣàpèjúwe ẹ̀ dáadáa ní ìbẹ̀rẹ̀ Òwe orí kẹsàn-án níbi tá a ti pe obìnrin kejì ní “ọgbọ́n tòótọ́.”

LỌ SỌ́DỌ̀ “ỌGBỌ́N TÒÓTỌ́”

14. Bó ṣe wà nínú Òwe 9:1-6, ta ló ní ká wá sọ́dọ̀ òun?

14 Ka Òwe 9:1-6. Nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí, Jèhófà pè wá pé ká wá torí pé òun ni Ẹlẹ́dàá wa, ọ̀dọ̀ ẹ̀ sì ni ọgbọ́n tòótọ́ ti ń wá. (Òwe 2:6; Róòmù 16:27) Bíbélì yìí mẹ́nu kan ilé ńlá kan tó ní òpó méje. Ìyẹn jẹ́ ká rí i pé Jèhófà ń fún wa ní ọ̀pọ̀ nǹkan, ó sì fẹ́ ká wá kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ òun ká lè di ọlọ́gbọ́n.

15. Kí ni Ọlọ́run ní ká wá ṣe?

15 Jèhófà lawọ́ gan-an torí ó máa ń fún wa lọ́pọ̀ nǹkan. Obìnrin tá a fi “ọgbọ́n tòótọ́” wé nínú ìwé Òwe orí kẹsàn-án jẹ́ ká rí i pé ohun tí Jèhófà máa ń ṣe gan-an nìyẹn. Ẹsẹ kejì sọ pé obìnrin yẹn ti ṣètò gbogbo ẹran rẹ̀, ó ti po wáìnì rẹ̀, ó sì ti tẹ́ tábìlì nínú ilé rẹ̀. (Òwe 9:2) Yàtọ̀ síyẹn, ẹsẹ 4 àti 5 sọ pé: “Ó [ìyẹn ọgbọ́n] sọ fún àwọn tí kò ní làákàyè pé: ‘Ẹ wá, ẹ jẹ oúnjẹ mi.’ ” Kí nìdí tó fi yẹ ká wá sílé ọgbọ́n tòótọ́, ká sì jẹ oúnjẹ ẹ̀? Jèhófà fẹ́ káwọn ọmọ ẹ̀ gbọ́n, ká má bàa kàgbákò. Jèhófà ò fẹ́ kí aburú kankan ṣẹlẹ̀ sí wa ká tó gbọ́n. Ìdí nìyẹn tó fi “ń to ọgbọ́n tó gbéṣẹ́ jọ fún àwọn adúróṣinṣin.” (Òwe 2:7) Tá a bá ń bẹ̀rù Jèhófà tọkàntọkàn, àá máa ṣe ìfẹ́ ẹ̀. Torí náà, a máa ń fetí sí ìmọ̀ràn Jèhófà, inú wa sì máa ń dùn bá a ṣe ń fi sílò.​—Jém. 1:25.

16. Báwo ni ìbẹ̀rù Jèhófà ṣe jẹ́ kí Alain ṣe ìpinnu tó tọ́, ohun rere wo ló sì tibẹ̀ jáde?

16 Ẹ jẹ́ ká wo bí ìbẹ̀rù Ọlọ́run ṣe ran Alain lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu tó tọ́. Alàgbà ni nínú ìjọ, ó sì tún jẹ́ olùkọ́ nílé ìwé. Ó sọ pé: “Ọ̀pọ̀ lára àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ gbà pé fíìmù ìṣekúṣe wà lára ohun tó yẹ káwọn máa wò, káwọn lè mọ̀ nípa ìbálòpọ̀.” Àmọ́ Alain ò jẹ́ kí wọ́n tan òun jẹ. Ó sọ pé: “Torí pé mo bẹ̀rù Jèhófà, mo kọ̀, mi ò wo àwọn fíìmù náà. Mo tún ṣàlàyé ìdí tí mi ò fi wò wọ́n fáwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́.” Ìmọ̀ràn “ọgbọ́n tòótọ́” ló tẹ̀ lé, ìyẹn ló sì mú kó“máa rìn ní ọ̀nà òye nìṣó.” (Òwe 9:6) Ohun tí Alain ṣe yìí jọ àwọn kan tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ lójú, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wọ́n sì ń wá sípàdé.

Tá a bá lọ sọ́dọ̀ obìnrin tó ṣàpẹẹrẹ “ọgbọ́n tòótọ́,” a máa rí ìyè (Wo ìpínrọ̀ 17-18)

17-18. Àwọn ohun rere wo làwọn tó lọ sọ́dọ̀ “ọgbọ́n tòótọ́” ń gbádùn, èrè wo ni wọ́n sì máa gbà? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

17 Jèhófà ní kí wọ́n ṣàkọsílẹ̀ àwọn obìnrin méjì tó ṣàpẹẹrẹ ìwà òmùgọ̀ àti ọgbọ́n tòótọ́ sínú Bíbélì ká lè ṣe ohun tó máa jẹ́ ká láyọ̀. Ìṣekúṣe táwọn tó lọ sọ́dọ̀ “òmùgọ̀ obìnrin” tó ń kígbe pè wọ́n fẹ́ ‘gbádùn’ ló jẹ́ kí wọ́n lọ síbẹ̀. Ká sòótọ́, ṣe ni wọ́n ń jayé òní, wọn ò mọ̀ pé àgbákò ló máa gbẹ̀yìn ẹ̀. Ibi tí wọ́n ti máa bá ara wọn ni “ìsàlẹ̀ Isà Òkú.”​—Òwe 9:13, 17, 18.

18 Àmọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn tó lọ sọ́dọ̀ obìnrin tó ṣàpẹẹrẹ “ọgbọ́n tòótọ́” yàtọ̀ pátápátá! Nígbà tí wọ́n débẹ̀, wọ́n gbádùn oúnjẹ aṣaralóore tó gbé fún wọn, ìyẹn àwọn nǹkan tó jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. (Àìsá. 65:13) Jèhófà gbẹnu wòlíì Àìsáyà sọ pé: “Ẹ tẹ́tí sí mi dáadáa, kí ẹ sì jẹ ohun tó dáa, ohun tó dọ́ṣọ̀ sì máa mú inú yín dùn gidigidi.” (Àìsá. 55:1, 2) Torí náà, ó yẹ ká nífẹ̀ẹ́ ohun tí Jèhófà fẹ́, ká sì kórìíra àwọn ohun tí ò fẹ́. (Sm. 97:10) Yàtọ̀ síyẹn, inú wa máa ń dùn láti pe àwọn èèyàn pé káwọn náà wá jàǹfààní lára “ọgbọ́n tòótọ́.” Ṣe ló dà bí ìgbà tá à ń “ké jáde látorí àwọn ibi gíga ìlú pé: ‘Kí ẹni tó bá jẹ́ aláìmọ̀kan wọlé síbí.’ ” Àwa àtàwọn tó ń fetí sí wa máa jàǹfààní báyìí àti lọ́jọ́ iwájú. Ìyẹn lá jẹ́ ká “wà láàyè” títí láé bá a ṣe ń “rìn ní ọ̀nà òye nìṣó.”​—Òwe 9:3, 4, 6.

19. Kí ni Oníwàásù 12:13, 14 sọ pé ká pinnu láti ṣe? (Tún wo àpótí náà, “ Ìbẹ̀rù Ọlọ́run Ń Ṣe Wá Láǹfààní.”)

19 Ka Oníwàásù 12:13, 14. Àdúrà wa ni pé kí ìbẹ̀rù Ọlọ́run mú ká máa ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́ nínú ayé burúkú yìí, kó sì mú ká máa hùwà mímọ́ ká lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. Ìbẹ̀rù tó tọ́ yẹn á jẹ́ ká máa pe ọ̀pọ̀ èèyàn pé káwọn náà máa wá “ọgbọ́n tòótọ́,” kó sì ṣe wọ́n láǹfààní.

ORIN 127 Irú Èèyàn Tó Yẹ Kí N Jẹ́

a Ó yẹ káwa Kristẹni bẹ̀rù Ọlọ́run, ká má sì ṣe ohun tó máa múnú bí i. Ìbẹ̀rù yìí ò ní jẹ́ ká ṣèṣekúṣe, a ò sì ní máa wo ìwòkuwò títí kan fíìmù tàbí àwòrán ìṣekúṣe. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn obìnrin ìṣàpẹẹrẹ méjì tí ìwé Òwe orí 9 sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀, tó jẹ́ ká rí ìyàtọ̀ láàárín ọgbọ́n àti ìwà òmùgọ̀. Ó dájú pé àwọn ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n tó wà nínú orí yìí máa ṣe wá láǹfààní báyìí àti lọ́jọ́ iwájú.

b A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.