GBÓLÓHÙN KAN LÁTINÚ BÍBÉLÌ
Ṣé O Nígbàgbọ́ Tó Lágbára?
A gbọ́dọ̀ nígbàgbọ́ ká tó lè múnú Jèhófà dùn. Síbẹ̀, Bíbélì sọ pé “ìgbàgbọ́ kì í ṣe ohun ìní gbogbo èèyàn.” (2 Tẹs. 3:2) Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó ń ta kò ó, ó pè wọ́n ní “àwọn ẹni ibi àti èèyàn burúkú,” ó sì ní kí Jèhófà gba òun sílẹ̀ lọ́wọ́ wọn. Àmọ́ ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ nípa ìgbàgbọ́ kan àwọn ẹlòmíì. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan ò gbà pé Ọlọ́run wà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀rí wà tó fi hàn pé Ẹlẹ́dàá wà lóòótọ́. (Róòmù 1:20) Àwọn kan lè sọ pé ẹlòmíì tàbí nǹkan míì làwọn ń sìn. Ká sòótọ́, irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ò nígbàgbọ́.
Ó yẹ kó dá wa lójú pé Ọlọ́run wà àti pé “òun ló ń san èrè” fáwọn tó nígbàgbọ́ tó lágbára nínú ẹ̀. (Héb. 11:6) Ìgbàgbọ́ wà lára nǹkan tí ẹ̀mí Ọlọ́run máa ń jẹ́ ká ní. Tá a bá gbàdúrà sí Jèhófà, ó máa fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀. (Lúùkù 11:9, 10, 13) Àmọ́, ọ̀kan lára ọ̀nà pàtàkì tá a lè gbà rí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run gbà ni pé ká máa ka Bíbélì déédéé. Lẹ́yìn náà, ó ṣe pàtàkì ká ṣàṣàrò lórí ohun tá a kà, ká sì ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti fi í sílò. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, á fi hàn pé à ń jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa gbé ìgbé ayé wa lọ́nà tó fi hàn pé a nígbàgbọ́.