Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ṣé “àwọn tí ìyà ń jẹ” (ẹsẹ 5) tàbí “àwọn ọ̀rọ̀ Jèhófà” (ẹsẹ 6) ni gbólóhùn náà “Wàá máa ṣọ́ wọn,” tó wà ní Sáàmù 12:7 ń sọ nípa ẹ̀?

Àwọn ọ̀rọ̀ tó wà ṣáájú àti ọ̀rọ̀ tó tẹ̀ lé Sáàmù 12:7 fi hàn pé àwọn èèyàn ni gbólóhùn yẹn ń sọ nípa ẹ̀.

Sáàmù 12:1-4 sọ pé “àwọn olóòótọ́ ti pòórá láàárín àwọn èèyàn.” Ní Sáàmù 12:5-7, ó wá sọ pé:

“‘Nítorí ìnira àwọn tí ìyà ń jẹ,

Nítorí ìkérora àwọn aláìní,

Màá dìde láti gbé ìgbésẹ̀,’ ni Jèhófà wí.

‘Màá gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn tó kórìíra wọn.’

Àwọn ọ̀rọ̀ Jèhófà mọ́;

Wọ́n dà bíi fàdákà tí a yọ́ mọ́ nínú iná ìléru tí wọ́n fi amọ̀ ṣe, èyí tí a yọ́ mọ́ ní ìgbà méje.

Jèhófà, wàá máa ṣọ́ wọn;

Wàá dáàbò bo kálukú wọn lọ́wọ́ ìran yìí títí láé.”

Ẹsẹ 5 sọ ohun tí Ọlọ́run máa ṣe fún “àwọn tí ìyà ń jẹ.” Ó sọ pé ó máa gbà wọ́n sílẹ̀.

Ẹsẹ 6 wá sọ pé “àwọn ọ̀rọ̀ Jèhófà mọ́, wọ́n dà bíi fàdákà tí a yọ́ mọ́.” Àwa tá à ń sin Jèhófà tọkàntọkàn gbà pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí.—Sm. 18:30; 119:140.

Ẹ jẹ́ ká wá wo ohun tí Sáàmù 12:7 sọ, ó ní: “Jèhófà, wàá máa ṣọ́ wọn; wàá dáàbò bo kálukú wọn lọ́wọ́ ìran yìí títí láé.” Àwọn wo ni “wọn” tí ẹsẹ Bíbélì yìí ń sọ?

Lẹ́yìn tí ẹsẹ 6 sọ̀rọ̀ nípa “àwọn ọ̀rọ̀ Jèhófà,” ẹsẹ 7 wá sọ pé Jèhófà á máa ṣọ́ wọn. Torí náà, àwọn kan lè rò pé ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni “wọn” tó wà níbẹ̀ ń tọ́ka sí. A mọ̀ pé Ọlọ́run ti dáàbò bo Bíbélì bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn alátakò ti ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti fòfin dè é, kí wọ́n sì pa á run.—Àìsá. 40:8; 1 Pét. 1:25.

Àmọ́ òótọ́ lohun tí ẹsẹ 5 yẹn sọ torí Jèhófà ti ran “àwọn tí ìyà ń jẹ” lọ́wọ́ àtàwọn tí ‘wọ́n ń ni lára,’ ó máa ń gbà wọ́n sílẹ̀, á sì máa ṣe bẹ́ẹ̀ nìṣó.—Jóòbù 36:15; Sm. 6:4; 31:1, 2; 54:7; 145:20.

Torí náà, kí ni “wọn” tó wà ní ẹsẹ 7 ń sọ nípa ẹ̀?

Tá a bá wo Sáàmù yẹn dáadáa, àá rí i pé àwọn èèyàn ni “wọn” yẹn ń sọ nípa ẹ̀.

Sáàmù 12:1, 2, Dáfídì sọ̀rọ̀ nípa “àwọn olóòótọ́” ìránṣẹ́ Jèhófà táwọn èèyàn burúkú ti parọ́ fún. Àmọ́ ẹsẹ tó tẹ̀ lé e jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà máa gbéjà ko àwọn tó ń sọ ohun tí ò dáa nípa àwọn èèyàn. Sáàmù yẹn fi dá wa lójú pé a lè fọkàn tán Jèhófà pé ó máa gba àwọn èèyàn ẹ̀ sílẹ̀ torí pé àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀ mọ́.

Torí náà, ohun tí ẹsẹ 7 ń sọ ni pé Jèhófà máa dáàbò bò ‘wọ́n,’ á sì gbà wọ́n sílẹ̀, ìyẹn àwọn èèyàn táwọn ẹni burúkú ń fìyà jẹ.

Ọ̀rọ̀ náà “wọn” tó wà nínú ẹsẹ Bíbélì yìí náà ni wọ́n lò nínú ìwé Másórétì lédè Hébérù. Ẹ̀ẹ̀mejì ni Ìwé Mímọ́ tí wọ́n kọ́kọ́ tú láti èdè Hébérù sí èdè Gíríìkì lo ọ̀rọ̀ náà “wa” ní ẹsẹ 7, àwọn olóòótọ́ tí wọ́n ń fìyà jẹ, tí wọ́n sì ń ni lára ló ń sọ. Ọ̀rọ̀ tó parí ẹsẹ 7 wá sọ pé Jèhófà máa dáàbò bo “kálukú” àwọn olóòótọ́ èèyàn náà “lọ́wọ́ ìran yìí,” ìyẹn àwọn èèyàn burúkú tí wọ́n ń “gbé ìwà ìbàjẹ́ lárugẹ.” (Sm. 12:7, 8) Nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù tí wọ́n tú sí èdè Árámáíkì, ẹsẹ 7 sọ pé: “OLUWA, ìwọ yóò dáàbò bo olódodo, ìwọ yóò ṣọ́ wọn nítorí àwọn èèyàn burúkú títí láé. Àwọn èèyàn burúkú ń yan kiri bíi kòkòrò mùjẹ̀mùjẹ̀ tó ń mùjẹ̀ àwọn èèyàn.” Ọ̀rọ̀ inú ẹsẹ Bíbélì yìí jẹ́ ká rí i pé àwọn èèyàn ni Sáàmù 12:7 ń sọ nípa ẹ̀.

Torí náà, ńṣe ni ẹsẹ yìí ń jẹ́ kí “àwọn olóòótọ́” nírètí pé Ọlọ́run máa gba àwọn sílẹ̀.