ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ
Mo Bá Àwọn Ọlọ́gbọ́n Rìn, Mo sì Kẹ́kọ̀ọ́ Lára Wọn
LÁÀÁRỌ̀ ọjọ́ kan nílùú Brookings ní South Dakota, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ojú ọjọ́ tutù ringindin, gbogbo nǹkan sì pa rọ́rọ́. Ó jẹ́ kí n mọ̀ pé òjò yìnyín kò ní pẹ́ máa rọ̀. Ó lè yà yín lẹ́nu pé inú òtútù yẹn làwa mélòó kan dúró sí nínú abà kan, tá à ń gbọ̀n pẹ̀pẹ̀ torí pé kò sí ohun tó máa mú kí ibẹ̀ móoru. A dúró síwájú ayọ́ gbàràmù-gbaramu kan tí wọ́n pọn omi dé ìlàjì rẹ̀, omi inú rẹ̀ sì tutù bíi yìnyín. Ẹ lè máa wò ó pé kí là ń wá níbí, ẹ jẹ́ kí n sọ ìtàn ara mi fún yín.
ILÉ TÍ MO TI WÁ
March 7, 1936 ni wọ́n bí mi, èmi sì ni àbígbẹ̀yìn nínú ọmọ mẹ́rin táwọn òbí wa bí. Ilé kékeré kan là ń gbé nínú oko kan lápá ìlà oòrùn ìlú South Dakota. Iṣẹ́ àgbẹ̀ ni ìdílé wa ń ṣe, a sì nífẹ̀ẹ́ iṣẹ́ wa gan-an, àmọ́ ìyẹn kọ́ ló ṣe pàtàkì jù sí wa. Ohun tó ṣe pàtàkì jù sí wa ni ìjọsìn Jèhófà. Lẹ́yìn táwọn òbí mi ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà Baba wa ọ̀run, wọ́n ṣèrìbọmi lọ́dún 1934, wọ́n sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nígbà kan, bàbá mi tó ń jẹ́ Clarence ni ìránṣẹ́ ìjọ tá à ń dara pọ̀ mọ́ nílùú Conde, ní South Dakota, lẹ́yìn náà ni ẹ̀gbọ́n bàbá mi tó ń jẹ́ Alfred wá di ìránṣẹ́ ìjọ. Ìránṣẹ́ ìjọ là ń pè ní Olùṣekòkáárí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà báyìí.
Ìdílé wa máa ń lọ sípàdé déédéé, a sì máa ń wàásù láti ilé dé ilé nígbà gbogbo ká lè sọ ìhìn rere nípa ọjọ́ ọ̀la aláyọ̀ tá a ní fáwọn èèyàn. Àpẹẹrẹ táwọn òbí mi fi lélẹ̀ ran àwa ọmọ wọn lọ́wọ́ gan-an. Ẹ̀gbọ́n mi obìnrin tó ń jẹ́ Dorothy di akéde Ìjọba Ọlọ́run nígbà tó pé ọmọ ọdún mẹ́fà, èmi náà sì ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́fà. Lọ́dún 1943, mo di ọmọ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀.
Àkókò alárinrin ni ìgbà àpéjọ àyíká àti àgbègbè máa ń jẹ́ fún wa. Ní àpéjọ àgbègbè kan tá a ṣe
lọ́dún 1949 nílùú Sioux Falls, ní South Dakota, Arákùnrin Grant Suiter ni olùbánisọ̀rọ̀ tí ètò Ọlọ́run rán wá. Mo ṣì rántí àkòrí àsọyé náà tó sọ pé, “Ọjọ́ Ti Lọ Ju Bó O Ṣe Rò Lọ!” Ó jẹ́ kó ṣe kedere pé ó yẹ kí gbogbo àwọn tó ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà máa pòkìkí ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run tó ti ń ṣàkóso. Lẹ́yìn àsọyé yẹn, mo ya ara mi sí mímọ́ fún Jèhófà. Àpéjọ àyíká tá a ṣe lẹ́yìn ìyẹn nílùú Brookings ni mo sì ti ṣèrìbọmi. Ohun tó gbé mi dénú abà tí mo sọ lẹ́ẹ̀kan nìyẹn. Àwa mẹ́rin la fẹ́ ṣe ìrìbọmi lọ́jọ́ yẹn, inú ayọ́ gbàràmù-gbaramu yẹn làwa mẹ́rẹ̀ẹ̀rin sì ti ṣèrìbọmi ní November 12, 1949.Lẹ́yìn ìyẹn mo pinnu pé màá di aṣáájú-ọ̀nà. Nígbà tó sì di January 1, 1952, mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà lọ́mọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15]. Mo fi ohun tí Bíbélì sọ sọ́kàn pé: “Ẹni tí ó bá ń bá àwọn ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n,” mo sì ní ọ̀pọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n nínú ìdílé wa tí wọ́n tì mí lẹ́yìn láti di aṣáájú-ọ̀nà. (Òwe 13:20) Ẹni ọgọ́ta [60] ọdún ni ẹ̀gbọ́n bàbá mi tó ń jẹ́ Julius, èmi àtàwọn la sì jọ ń ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé gbọ̀ọ̀rọ̀-gbọọrọ ni wọ́n fi jù mí lọ, a jọ máa ń gbádùn iṣẹ́ ìwàásù gan-an. Mo rọ́gbọ́n kọ́ látinú àwọn ìrírí wọn gan-an. Nígbà tó yá, Dorothy náà di aṣáájú-ọ̀nà.
ÀWỌN ALÁBÒÓJÚTÓ ÀYÍKÁ MÚ MI BÍ ỌMỌ
Nígbà tí mo wà lọ́dọ̀ọ́, àwọn òbí mi máa ń ní káwọn alábòójútó àyíká àtàwọn ìyàwó wọn dé sílé wa. Tọkọtaya kan tó ń jẹ́ Jesse àti Lynn Cantwell sì ràn mí lọ́wọ́ gan-an. Kódà, wọ́n wà lára àwọn tó gbà mí níyànjú láti di aṣáájú-ọ̀nà. Ìfẹ́ tí wọ́n fi hàn sí mi jẹ́ kí n pinnu pé màá fi ayé mi sin Jèhófà. Tí wọ́n bá ń bẹ àwọn ìjọ tó wà nítòsí wò, wọ́n máa ń pè mí pé kí n wá bá àwọn jáde lọ wàásù. Àwọn nǹkan tí wọ́n ṣe yẹn gbé mi ró, ó sì fún mi lókun.
Arákùnrin Bud Miller àti ìyàwó rẹ̀ tó ń jẹ́ Joan ló bẹ̀ wá wò lẹ́yìn Arákùnrin Cantwell. Mo ti pé ọmọ ọdún méjìdínlógún [18] nígbà yẹn, ìjọba sì ti ní kí n wá wọṣẹ́ ológun. Kódà, àjọ tí ń gbani sí iṣẹ́ ológun nílùú wa ti kọ orúkọ mi mọ́ àwọn tó máa ṣiṣẹ́ ológun. Àmọ́, ìyẹn ò bá ẹ̀rí ọkàn mi mu torí Jésù sọ pé àwọn ọmọlẹ́yìn òun kò gbọ́dọ̀ lọ́wọ́ sí ogun tàbí òṣèlú. Yàtọ̀ síyẹn, ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ni mo fẹ́ máa sọ fáwọn èèyàn. (Jòh. 15:19) Mo wá bẹ àjọ tí ń gbani sí iṣẹ́ ológun pé kí wọ́n kà mí mọ́ àwọn òjíṣẹ́ Ọlọ́run.
Inú mi dùn gan-an nígbà tí Arákùnrin Miller sọ pé àwọn máa tẹ̀ lé mi lọ sí ibi ìgbẹ́jọ́ náà. Arákùnrin
Miller máa ń yá mọ́ọ̀yàn gan-an, kì í sì í bẹ̀rù. Ọkàn mi balẹ̀ pé àwọn ló tẹ̀ lé mi. Lẹ́yìn ìgbẹ́jọ́ yẹn lọ́dún 1954, àjọ náà gbà pé òjíṣẹ́ Ọlọ́run ni mí. Ìyẹn ló sì jẹ́ kọ́wọ́ mi tẹ nǹkan míì tí mo fẹ́ ṣe nínú ètò Ọlọ́run.Àsìkò yẹn ni ètò Ọlọ́run pè mí wá sí Bẹ́tẹ́lì, wọ́n sì ní kí n máa sìn ní Oko Watchtower tó wà nílùú Staten Island, ìpínlẹ̀ New York. Nǹkan bí ọdún mẹ́ta ni mo fi sìn níbẹ̀. Ìyẹn sì tún jẹ́ kí n túbọ̀ ní ọ̀pọ̀ ìrírí torí pé mo bá àwọn ọlọ́gbọ́n pàdé, mo sì bá wọn ṣiṣẹ́.
IṢẸ́ ÌSÌN NÍ BẸ́TẸ́LÌ
Ilé iṣẹ́ rédíò àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tá à ń pè ní WBBR náà wà nínú oko yẹn. A lò ó láti ọdún 1924 sí 1957. Àwa mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sí ogún lára ìdílé Bẹ́tẹ́lì ni wọ́n ní kó máa ṣiṣẹ́ nínú oko yẹn. Ọ̀dọ́ ló pọ̀ jù lára àwa tá a wà níbẹ̀, a ò sì fi bẹ́ẹ̀ nírìírí. Àmọ́, Arákùnrin Eldon Woodworth wà pẹ̀lú wa, wọ́n ti dàgbà, ẹni àmì òróró sì ni wọ́n. Olọ́gbọ́n èèyàn ni arákùnrin náà, wọ́n máa ń gbà wá nímọ̀ràn bíi bàbá, èyí sì mú ká túbọ̀ ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú Jèhófà. Nígbà míì tí èdèkòyédè bá wáyé, Arákùnrin Woodworth á sọ pé, “Àwọn ohun ribiribi ni Olúwa ń gbé ṣe lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀ bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn aláìpé ló ń lò.”
Arákùnrin Frederick W. Franz náà wà pẹ̀lú wa níbẹ̀. Ọlọ́gbọ́n ni wọ́n, wọ́n sì ní ìmọ̀ Bíbélì gan-an. Èyí mú kí wọ́n máa ran gbogbo wa lọ́wọ́, wọ́n sì ń fìfẹ́ hàn sí wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. Harry Peterson ló ń se oúnjẹ fún wa, àmọ́ ó máa ń rọ̀ wá lọ́rùn ká pè wọ́n ní Peterson ju ká pe Papargyropoulos tí wọ́n ń jẹ́. Ẹni àmì òróró làwọn náà, wọ́n sì nítara fún iṣẹ́ ìsìn. Òṣìṣẹ́ kára ni Arákùnrin Peterson ní Bẹ́tẹ́lì, síbẹ̀ wọn ò fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú iṣẹ́ ìwàásù. Ọgọ́ọ̀rọ̀rún ìwé ìròyìn wa ni wọ́n máa ń fi síta lóṣooṣù. Wọ́n lóye Ìwé Mímọ́ gan-an, inú wọn sì máa ń dùn láti dáhùn àwọn ìbéèrè wa.
MO KẸ́KỌ̀Ọ́ LÁRA ÀWỌN ARÁBÌNRIN TÓ DÀGBÀ DÉNÚ
Mo tún máa ń ṣiṣẹ́ nínú oko nígbà míì. Lẹ́yìn tá a bá ti kórè oko, a máa kó wọn sínú agolo. Ohun tó ju ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogójì lítà èso àti ewébẹ̀ la máa ń kó ságolo lọ́dọọdún fún ìdílé Bẹ́tẹ́lì. Mo láǹfààní láti bá Arábìnrin Etta Huth ṣiṣẹ́ níbẹ̀. Ọlọ́gbọ́n lòun náà, òun ló sì máa ń bójú tó àwọn nǹkan tá à ń lò fún kíkó oúnjẹ ságolo. Tó bá ti di àsìkò tá a fẹ́
kó àwọn oúnjẹ ságolo, àwọn arábìnrin tó wà níjọ àdúgbò máa ń wá ràn wá lọ́wọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ ribiribi ni Etta ń ṣe nínú kíkó àwọn oúnjẹ sínú agolo, síbẹ̀ ó máa ń bọ̀wọ̀ fáwọn arákùnrin tó ń múpò iwájú ní oko náà. Àpẹẹrẹ àtàtà ló jẹ́ tó bá di pé ká bọ̀wọ̀ fáwọn tó ń múpò iwájú nínú ètò Ọlọ́run.Angela Romano wà lára àwọn arábìnrin tó máa ń wá bá wa ṣiṣẹ́ níbẹ̀. Etta ló ran Angela lọ́wọ́ nígbà tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Bí mo ṣe tún pàdé ọlọ́gbọ́n míì nìyẹn, èmi àti ẹ̀ sì ti jọ wà fún ọdún méjìdínlọ́gọ́ta [58] báyìí. Èmi àti Angie ṣègbéyàwó ní April 1958, a sì ti jọ gbádùn iṣẹ́ ìsìn pa pọ̀. Bí Angie ṣe jẹ́ adúróṣinṣin látọdún yìí wá ti mú ká túbọ̀ mọwọ́ ara wa. Kò sí bí ìṣòro kan ṣe lè le tó, ọkàn mi máa ń balẹ̀ pé mo rẹ́ni fẹ̀hìn tì.
A DI MÍṢỌ́NNÁRÌ ÀTI ALÁBÒÓJÚTÓ ARÌNRÌN-ÀJÒ
Nígbà tí ètò Ọlọ́run ta ilé iṣẹ́ rédíò WBBR lọ́dún 1957, mo lọ sìn ní Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Brooklyn fúngbà díẹ̀. Lẹ́yìn témi àti Angie ṣègbéyàwó, mo kúrò ní Bẹ́tẹ́lì, a sì ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà fún nǹkan bí ọdún mẹ́ta nílùú Staten Island. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tí mo bá àwọn tó ra ilé iṣẹ́ rédíò yẹn ṣiṣẹ́, orúkọ tí wọ́n sì pè é ni WPOW.
Èmi àti Angie jẹ́ kí ìwọ̀nba ohun ìní díẹ̀ tẹ́ wa lọ́rùn, a sì ṣe tán láti sìn níbikíbi tí ètò Ọlọ́run bá ti nílò wa. Torí náà, nígbà tó di ọdún 1961, wọ́n sọ wá di aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe nílùú Falls City, ní ìpínlẹ̀ Nebraska. Kò pẹ́ sígbà yẹn, wọ́n tún ní ká wá sí Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́, oṣù kan la sì fi gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ nílùú South Lansing, New York. A gbádùn ilé ẹ̀kọ́ náà gan-an, a sì ń fojú sọ́nà láti pa dà sí Nebraska, ká lè lo àwọn ohun tá a ti kọ́. Àmọ́, ó yà wá lẹ́nu gan-an pé ńṣe ni wọ́n ní ká lọ sórílẹ̀-èdè Kàǹbódíà, ká lọ máa ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì! Apá Gúúsù Ìlà Oòrùn Éṣíà lorílẹ̀-èdè yìí wà. Àwọn nǹkan tá a rí, tá a gbọ́, tá a sì jẹ yàtọ̀ pátápátá sóhun tá a ti mọ̀ tẹ́ lẹ̀. Ṣe ló ń ṣe wá bíi ká ti wàásù fún gbogbo èèyàn tó wà níbẹ̀.
Nígbà tó yá, ọ̀rọ̀ òṣèlú dá wàhálà sílẹ̀ nílùú, torí náà, ó di dandan pé ká kó lọ sórílẹ̀-èdè South Vietnam. Àmọ́, a ò tíì lò tó ọdún méjì níbẹ̀ tí mo ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàìsàn tó le gan-an. Torí náà, wọ́n rọ̀ wá pé ká pa dà sílùú ìbílẹ̀ wa. Ó gba àkókò díẹ̀ kí ara mi tó le, àmọ́, nígbà tí ara mi yá, a tún bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ alákòókò kíkún.
Ní March 1965, a bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ àwọn ìjọ wò. Ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n [33] ni èmi àti Angie fi ṣiṣẹ́ arìnrìn-àjò, a sì tún máa ń ṣètò àpéjọ àgbègbè. Iṣẹ́ ńlá la máa ń ṣe káwọn àpéjọ àgbègbè náà tó bẹ̀rẹ̀ àti tí wọ́n bá ń lọ lọ́wọ́. Ìgbà alárinrin ni ìgbà àpéjọ àgbègbè máa ń jẹ́ fún mi, torí náà inú mi máa ń dùn láti ṣètò àwọn àpéjọ náà, kí gbogbo nǹkan lè lọ dáadáa. Àgbègbè New York City la wà fún bí ọdún mélòó kan, ọ̀pọ̀ ìgbà ló sì jẹ́ pé Yankee Stadium la máa ń lò.
MO PA DÀ SÍ BẸ́TẸ́LÌ, MO SÌ TÚN BÓJÚ TÓ ÀWỌN ILÉ Ẹ̀KỌ́ ÈTÒ ỌLỌ́RUN
Àwọn àyípadà tó ń ṣẹlẹ̀ sáwọn tó wà nínú àkànṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún ò yọ èmi àti Angie sílẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún 1995, ètò Ọlọ́run ní kí n wá máa kọ́ àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ tó wá sí Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ (ìyẹn MTS). Ọdún mẹ́ta lẹ́yìn náà, wọ́n ní ká máa
bọ̀ ní Bẹ́tẹ́lì. Inú mi dùn gan-an torí ibẹ̀ ni mo ti bẹ̀rẹ̀ àkànṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún mi lógójì ọdún ṣáájú ìgbà yẹn. Nígbà kan, mo ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ìsìn, mo sì tún ń kọ́ àwọn tó wá sáwọn ilé ẹ̀kọ́ ètò Ọlọ́run lẹ́kọ̀ọ́. Nígbà tó di ọdún 2007, Ìgbìmọ̀ Olùdarí dá ẹ̀ka kan sílẹ̀, ìyẹn Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ilé Ẹ̀kọ́ Ètò Ọlọ́run, wọ́n ní kí ẹ̀ka yìí máa ṣe kòkáárí gbogbo ilé ẹ̀kọ́ tó wà ní Bẹ́tẹ́lì, wọ́n sì fi mí ṣe alábòójútó ẹ̀ka tuntun yẹn fún ọdún mélòó kan.Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ètò Ọlọ́run ṣe àwọn ìyípadà kan nínú àwọn ilé ẹ̀kọ́ tí wọ́n ní. Lọ́dún 2008, wọ́n dá Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Alàgbà Ìjọ sílẹ̀. Ní ọdún méjì péré, ó lé ní ẹgbẹ̀rún méjìlá [12,000] àwọn alàgbà tí wọ́n dá lẹ́kọ̀ọ́ ní Bẹ́tẹ́lì tó wà nílùú Patterson àtèyí tó wà ní Brooklyn. Ọ̀pọ̀ ibi la ti ń ṣe ilé ẹ̀kọ́ náà báyìí, àwọn olùkọ́ tí wọ́n ń sìn ní pápá ló sì ń dáni lẹ́kọ̀ọ́ láwọn ilé ẹ̀kọ́ yìí kárí ayé. Lọ́dún 2010, ètò Ọlọ́run yí orúkọ Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ (MTS) sí Ilé Ẹ̀kọ́ Bíbélì fún Àwọn Àpọ́n, nígbà tó sì yá wọ́n dá ilé ẹ̀kọ́ tuntun míì sílẹ̀, ìyẹn Ilé Ẹ̀kọ́ Bíbélì fún Àwọn Tọkọtaya.
Níbẹ̀rẹ̀ ọdún iṣẹ́ ìsìn 2015, ètò Ọlọ́run pa ilé ẹ̀kọ́ méjèèjì pọ̀, wọ́n sì pè é ní Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere Ìjọba Ọlọ́run. Àwọn tó ń wá síbẹ̀ lè jẹ́ tọkọtaya, wọ́n sì lè jẹ́ àwọn arákùnrin tàbí arábìnrin tí kò tíì ṣègbéyàwó. Ìdùnnú ṣubú layọ̀ fáwọn ará kárí ayé nígbà tí wọ́n gbọ́ pé ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè la ti máa ṣe ilé ẹ̀kọ́ yìí. Inú mi sì dùn pé àǹfààní ti wá ṣí sílẹ̀ fún ọ̀pọ̀ àwọn ará láti lọ sí ilé ẹ̀kọ́ yìí, mo sì tún mọyì bí mo ṣe láǹfààní láti mọ ọ̀pọ̀ lára wọn.
Tí mo bá ń ronú bí mo ṣe lo ayé mi nínú ìjọsìn Ọlọ́run látìgbà tí mo ti ṣèrìbọmi nínú ayọ́ gbàràmù-gbaramu yẹn títí di báyìí, mo máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó jẹ́ kí n bá àwọn ọlọ́gbọ́n rìn, àwọn ló sì fi ẹsẹ̀ mi lé ọ̀nà òtítọ́. Kì í ṣe gbogbo àwọn tí mò ń sọ yìí lọmọ ìlú mi, ọjọ́ orí wa sì yàtọ̀ síra. Àmọ́, ìjọsìn Ọlọ́run jẹ gbogbo wọn lógún. Ìfẹ́ tí wọ́n ní fún Jèhófà hàn nínú ìwà àti ìṣe wọn. Téèyàn bá ní kóun ka àwọn ọlọ́gbọ́n téèyàn lè bá rìn nínú ètò Ọlọ́run, ilẹ̀ á ṣú. Èmi ti bá wọn rìn, wọ́n sì ti ràn mí lọ́wọ́.