Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kí nìdí táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi máa ń yàwòrán Pọ́ọ̀lù bí ẹni tó pá lórí tàbí bí ẹni tó nírun díẹ̀?

Ká sòótọ́, kò sẹ́ni tó mọ bí Pọ́ọ̀lù ṣe rí gan-an torí àwọn awalẹ̀pìtàn ò tíì rí ẹ̀rí tó fìdí múlẹ̀ tó jẹ́ ká mọ bó ṣe rí. Àwọn àwòrán tó wà nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa kàn máa ń ṣàpẹẹrẹ ìrísí rẹ̀ ni.

Àmọ́, àwọn ìwé kan wà tó sọ nípa bó ti ṣeé ṣe kí Pọ́ọ̀lù rí. Bí àpẹẹrẹ, Zion’s Watch Tower ti March 1, 1902, tọ́ka sí ọ̀kan lára wọn. Ó sọ pé: “Ìwé náà ‘Acts of Paul and Thecla,’ . . . tí wọ́n kọ ní ọdún 150 A. D. ṣe àlàyé díẹ̀ nípa ìrísí Pọ́ọ̀lù, ohun tí ìwé yẹn sọ sì nítumọ̀. Ìwé yẹn sọ pé, Pọ́ọ̀lù ‘ò ga púpọ̀, ó párí, ó kẹtan, ó ki, irun ojú rẹ̀ pọ̀, imú rẹ̀ sì gùn.’”

Ìwé The Oxford Dictionary of the Christian Church (ẹ̀dà ti ọdún 1997) sọ pé: “Ó ṣeé ṣe kí àwọn àlàyé kan nínú ìwé ‘The Acts of Paul and Thecla’ jẹ́ òótọ́.” Ìdí sì ni pé ẹ̀dà rẹ̀ tí wọ́n dà kọ sí èdè Gíríìkì tó nǹkan bí ọgọ́rin [80], wọ́n sì tún túmọ̀ rẹ̀ sáwọn èdè míì. Èyí fi hàn pé àwọn èèyàn tó gbé láyé lẹ́yìn ọdún 150 Sànmánì Kristẹni kò kóyán ìwé yìí kéré. Torí náà, àwòrán àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó wà nínú àwọn ìwé wa wà níbàámu pẹ̀lú ohun táwọn ìwé àtayébáyé sọ.

Àmọ́, ẹ jẹ́ ká fi sọ́kàn pé àwọn nǹkan míì wà tó ṣe pàtàkì ju ìrísí Pọ́ọ̀lù lọ. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, àwọn alárìíwísí kan sọ pé “wíwàníhìn-ín òun alára jẹ́ aláìlera, àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò sì ní láárí.” (2 Kọ́r. 10:10) Ká má gbàgbé pé lẹ́yìn tí Jésù fara han Pọ́ọ̀lù lọ́nà ìyanu ló di Kristẹni. Síbẹ̀, ẹ wo ohun ribiribi tó gbé ṣe gẹ́gẹ́ bí ‘ohun èlò tí a ti yàn fún Kristi láti gbé orúkọ Jésù lọ sọ́dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè.’ (Ìṣe 9:​3-5, 15; 22:​6-8) Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ nǹkan la lè rí kọ́ látinú àwọn ìwé tí Jèhófà mí sí Pọ́ọ̀lù láti kọ.

Pọ́ọ̀lù ò yangàn torí ohun tó gbé ṣe kó tó di Kristẹni, kò sì sọ ohunkóhun nípa ìrísí ara rẹ̀. (Ìṣe 26:​4, 5; Fílí. 3:​4-6) Ó sọ pé: “Èmi ni mo kéré jù lọ nínú àwọn àpọ́sítélì, èmi kò sì yẹ ní ẹni tí a ń pè ní àpọ́sítélì.” (1 Kọ́r. 15:9) Nígbà tó yá ó sọ pé: “Èmi, ẹni tí ó kéré ju kékeré jù lọ nínú gbogbo ẹni mímọ́, ni a fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí yìí fún, pé kí n polongo ìhìn rere nípa àwọn ọrọ̀ tí kò ṣeé díwọ̀n ti Kristi fún àwọn orílẹ̀-èdè.” (Éfé. 3:8) Ó dájú pé ìhìn rere tí Pọ́ọ̀lù polongo yìí ṣe pàtàkì ju ìrísí rẹ̀ lọ.