Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Aájò Àlejò Ṣe Pàtàkì Gan-An

Aájò Àlejò Ṣe Pàtàkì Gan-An

“Ẹ ní ẹ̀mí aájò àlejò fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì láìsí ìráhùn.” ​1 PÉT. 4:9.

ORIN: 100, 87

1. Báwo ni nǹkan ṣe rí fáwọn Kristẹni ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní?

LÁÀÁRÍN ọdún 62 sí 64 Sànmánì Kristẹni, àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé sáwọn “olùgbé fún ìgbà díẹ̀ tí wọ́n tú ká káàkiri ní Pọ́ńtù, Gálátíà, Kapadókíà, Éṣíà, àti Bítíníà.” (1 Pét. 1:1) Onírúurú ẹ̀yà làwọn Kristẹni tó wà láwọn ìjọ ní Éṣíà Kékeré, wọ́n sì nílò ìṣírí àti ìtọ́sọ́nà. Ìdí ni pé àwọn èèyàn ń takò wọ́n gan-an, wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ burúkú sí wọn, kódà wọ́n fojú winá àdánwò tó le. Nǹkan ò rọgbọ rárá lásìkò yẹn, Pétérù tiẹ̀ sọ pé: “Òpin ohun gbogbo ti sún mọ́lé.” Bọ́rọ̀ sì ṣe rí nìyẹn torí pé kò pé ọdún mẹ́wàá lẹ́yìn ìgbà yẹn tí Jerúsálẹ́mù pa run. Kí ló máa ran àwọn Kristẹni níbi gbogbo lọ́wọ́ lásìkò tí nǹkan ò dẹrùn yìí?​—1 Pét. 4:​4, 7, 12.

2, 3. Kí nìdí tí Pétérù fi gba àwọn Kristẹni níyànjú pé kí wọ́n ní ẹ̀mí aájò àlejò? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

2 Nígbà tí Pétérù ń gba àwọn Kristẹni yẹn níyànjú, ó ní: “Ẹ ní ẹ̀mí aájò àlejò fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì.” (1 Pét. 4:9) Lédè Gíríìkì, ọ̀rọ̀ náà “aájò àlejò” túmọ̀ sí “ká fìfẹ́ hàn tàbí ká ṣe inúure sí àwọn tá ò mọ̀ rí.” Àmọ́, ẹ kíyè sí i pé Pétérù gba àwọn Kristẹni yẹn níyànjú pé kí wọ́n ní ẹ̀mí aájò àlejò sí ‘ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì,’ ìyẹn sí àwọn tí wọ́n mọ̀ rí, tí wọ́n sì jọ ń ṣe nǹkan pa pọ̀. Tí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, báwo nìyẹn ṣe máa ṣe wọ́n láǹfààní?

3 Ó máa jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ sún mọ́ra wọn. Ìwọ ńkọ́? Ṣé ẹnì kan ti gbà ẹ́ lálejò rí? Ṣé inú rẹ kì í dùn tó o bá ń rántí ọjọ́ náà? Nígbà tíwọ náà gba àwọn ará kan láti ìjọ yín lálejò, ó dájú pé ìyẹn mú kí àárín yín wọ̀ dáadáa, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Tá a bá ń gba ara wa lálejò, ìyẹn á jẹ́ ká túbọ̀ mọ ara wa dáadáa ju bá a ṣe lè mọ ara wa nípàdé tàbí lóde ẹ̀rí. Ó yẹ káwọn Kristẹni ìgbà yẹn túbọ̀ sún mọ́ra gan-an torí bí nǹkan ṣe túbọ̀ ń burú sí i. Bó sì ṣe yẹ káwa náà máa ṣe nìyẹn láwọn “ọjọ́ ìkẹyìn” yìí.​—2 Tím. 3:1.

4. Àwọn ìbéèrè wo la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

4 Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà fi ẹ̀mí aájò àlejò hàn sí ‘ara wa lẹ́nì kìíní-kejì’? Àwọn nǹkan wo ló lè mú kó ṣòro fún wa láti gba ara wa lálejò, báwo la sì ṣe lè borí wọn? Kí ló yẹ ká ṣe tẹ́nì kan bá ní ká wá sílé òun?

ÀWỌN Ọ̀NÀ TÁ A LÈ GBÀ FI Ẹ̀MÍ AÁJÒ ÀLEJÒ HÀN

5. Báwo la ṣe lè fẹ̀mí aájò àlejò hàn nípàdé?

5 Nípàdé: Gbogbo àwọn tó bá wá sípàdé la máa ń gbà tọwọ́tẹsẹ̀ torí pé àlejò ni gbogbo wa. Jèhófà àti ètò rẹ̀ ló sì gbà wá lálejò. (Róòmù 15:7) Táwọn ẹni tuntun bá wá sípàdé, ó yẹ káwa náà fi ẹ̀mí aájò àlejò hàn sí wọn. A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá fọ̀yàyà kí wọn láìka irú aṣọ tí wọ́n wọ̀ tàbí bí wọ́n ṣe múra sí. (Ják. 2:​1-4) Tá a bá rí i pé ẹni tuntun kan dá jókòó, a lè lọ jókòó tì í tàbí ká ní kó wá jókòó tì wá. Ó dájú pé inú ẹ̀ máa dùn tó bá rẹ́ni bá a ṣí Bíbélì kó lè máa fọkàn bá ìpàdé náà lọ. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ṣe là ń “tẹ̀ lé ipa ọ̀nà aájò àlejò.”​—Róòmù 12:13.

6. Àwọn wo ló yẹ ká máa pè wá sílé wa jù?

6 A lè pè wọ́n wá jẹun: Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, ọ̀nà kan tí wọ́n máa ń gbà ṣàlejò ni pé kí wọ́n pe ẹnì kan wá jẹun nílé wọn. (Jẹ́n. 18:​1-8; Oníd. 13:15; Lúùkù 24:​28-30) Tá a bá pe ẹnì kan wá jẹun, ṣe là ń fi hàn pé a fẹ́ kẹ́ni náà di ọ̀rẹ́ wa, ká sì jọ wà ní àlàáfíà. Àwọn wo ló yẹ ká máa pè wá sílé wa jù? Àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin nínú ìjọ ni. Ó ṣe tán, tíṣòro bá dé, ṣebí àwọn ará yìí náà ló máa dúró tì wá? Ká sòótọ́, gbogbo àwọn ará ló yẹ kó jẹ́ ọ̀rẹ́ wa, ká sì wà ní àlàáfíà pẹ̀lú wọn. Ká lè mọ bó ti ṣe pàtàkì tó, aago méje ku ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ni ìdílé Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Amẹ́ríkà máa ń ṣe Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ tẹ́lẹ̀. Àmọ́ nígbà tó dọdún 2011, Ìgbìmọ̀ Olùdarí yí àkókò yẹn pa dà sí aago mẹ́fà kọjá ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún. Kí nìdí? Ìdí ni pé tí ìpàdé náà bá tètè parí, àwọn tó wà ní Bẹ́tẹ́lì á túbọ̀ ráyè máa gba ara wọn lálejò. Kò pẹ́ táwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì míì náà fi ṣe ìyípadà yẹn. Èyí sì ti mú káwọn tó wà ní Bẹ́tẹ́lì túbọ̀ mọ ara wọn sí i.

7, 8. Báwo la ṣe lè fi ẹ̀mí aájò hàn sáwọn arákùnrin tó wá bẹ̀ wá wò?

7 Inú wa máa ń dùn táwọn arákùnrin kan bá wá sọ àsọyé níjọ wa. Wọ́n lè jẹ́ àlejò láti ìjọ míì, alábòójútó àyíká tàbí aṣojú tí ẹ̀ka ọ́fíìsì rán wá. A máa ń lo àwọn àǹfààní yẹn láti ṣe àwọn arákùnrin yìí lálejò. (Ka 3 Jòhánù 5-8.) A lè ṣètò ìpápánu tàbí ká tiẹ̀ dáná fún wọn pàápàá. Ṣé ìwọ náà lè ṣe bẹ́ẹ̀?

8 Arábìnrin kan lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Ọjọ́ pẹ́ témi àtọkọ mi ti máa ń gba àwọn arákùnrin tó bá wá sọ àsọyé àtàwọn ìyàwó wọn lálejò. Kò sígbà tá a gbà wọ́n lálejò tí inú wa kì í dùn, a máa ń gbádùn ara wa gan-an, ní pàtàkì, ó máa ń jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára. A ò kábàámọ̀ rí pé a gbà wọ́n lálejò.”

9, 10. (a) Àwọn wo ló lè nílò ibi tí wọ́n máa dé sí? (b) Ṣé àwọn tí ilé wọn kéré lè gba àwọn míì sílé? Sọ àpẹẹrẹ kan.

9 Àwọn àlejò ọlọ́jọ́ pípẹ́: Láyé àtijọ́, ọ̀nà míì tí wọ́n máa ń gbà ṣàlejò ni pé kí wọ́n ṣètò ibi tí àlejò kan máa dé sí. (Jóòbù 31:32; Fílém. 22) Bákan náà lónìí, àwọn ará wa máa ń nílò ibi tí wọ́n lè dé sí. Bí àpẹẹrẹ, àwọn alábòójútó àyíká nílò ibi tí wọ́n máa dé sí tí wọ́n bá ń bẹ ìjọ wò. Bákan náà, àwọn tó bá wá fún àwọn ilé ẹ̀kọ́ ètò Ọlọ́run àtàwọn tó ń ṣiṣẹ́ ìkọ́lé máa ń nílò ibi tí wọ́n máa dé sí. Nígbà míì sì rèé, àjálù lè ba ilé àwọn ará wa kan jẹ́, kí wọ́n sì nílò ibi tí wọ́n lè forí pamọ́ sí títí wọ́n á fi tún ilé wọn ṣe. Kò yẹ ká máa ronú pé àwọn tí ilé wọn tóbi nìkan ló lè gba irú àwọn bẹ́ẹ̀ sílé, ohun kan ni pé, wọ́n lè ti ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà. Ṣé ìwọ náà lè gbà wọ́n sílé kódà tó bá jẹ́ pé ilé rẹ ò tóbi? Ó ṣe tán, àwọn kan máa ń ní tí ìfẹ́ bá wà, kòròfo ìṣáná gba èèyàn mẹ́fà.

10 Inú arákùnrin kan lórílẹ̀-èdè South Korea máa ń dùn tó bá rántí ìgbà tó gba àwọn tó wá fún ilé ẹ̀kọ́ ètò Ọlọ́run sílé. Ó ní: “Mi ò kọ́kọ́ fẹ́ gbà wọ́n torí pé mo ṣẹ̀ṣẹ̀ gbéyàwó ni àti pé ilé wa kéré. Àmọ́ inú wa dùn gan-an pé a gbà wọ́n. Èmi àtìyàwó mi rí i pé tí àwọn tọkọtaya bá jọ ń sin Jèhófà, tí wọ́n sì ní àfojúsùn kan náà, wọ́n á láyọ̀.”

11. Kí nìdí tó fi yẹ kó o ṣaájò àwọn tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ dé ìjọ yín?

11 Àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé inú ìjọ: Nígbà míì, àwọn kan lè kó wá sádùúgbò yín. Ó lè jẹ́ pé wọ́n wá sìn níbi tí àìní gbé pọ̀ lágbègbè yín tàbí kó jẹ́ pé ètò Ọlọ́run ló rán àwọn aṣáájú-ọ̀nà kan wá sí ìjọ yín. Irú àwọn ìyípadà bẹ́ẹ̀ kì í rọrùn torí pé àgbègbè tuntun náà lè má tètè mọ́ wọn lára, kára wọn má sì tètè mọlé níjọ yín. Kódà, ó lè gba pé kí wọ́n kọ́ èdè tàbí àṣà tuntun. Tá a bá pè wọ́n wá sílé wa tàbí tá a jọ gbafẹ́ jáde, ìyẹn á jẹ́ kára wọn tètè mọlé kí wọ́n sì láwọn ọ̀rẹ́ tuntun.

12. Ìrírí wo ló jẹ́ ká rí i pé kò dìgbà tá a bá filé pọntí ká tó lè ṣàlejò?

12 Kò dìgbà tá a bá filé pọntí fọ̀nà rokà ká tó lè gba ẹnì kan lálejò. (Ka Lúùkù 10:​41, 42.) Arákùnrin kan sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ míṣọ́nnárì, ó ní: “Èmí àtìyàwó mi ṣì kéré nígbà yẹn, a ò fi bẹ́ẹ̀ nírìírí, àárò ilé sì máa ń sọ wá. Nírọ̀lẹ́ ọjọ́ kan, ó tiẹ̀ ṣe ìyàwó mi bíi pé ká pa dà sílé, àmọ́ gbogbo bí mo ṣe gbìyànjú tó láti mára tù ú, pàbó ló já sí. Nígbà tó di nǹkan bí aago méje ààbọ̀, ẹnì kan kan ilẹ̀kùn. Obìnrin kan tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ló wá kí wa, ó sì kó ọsàn mẹ́ta dání fún wa. A ní kó wọlé, a sì fún un lómi. Lẹ́yìn náà, a po tíì fún un, a sì fún un ní ṣokoléètì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò tíì gbọ́ èdè Swahili tí obìnrin náà ń sọ, òun náà ò sì gbọ́ òyìnbó, síbẹ̀ ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ yẹn ló mú kára wa bẹ̀rẹ̀ sí í mọlé, ká sì láwọn ọ̀rẹ́ nínú ìjọ.”

BÁ A ṢE LÈ BORÍ ÀWỌN NǸKAN TÓ LÈ MÚ KÓ ṢÒRO LÁTI GBÀLEJÒ

13. Àǹfààní wo la máa rí tá a bá ń gbàlejò?

13 Ṣé ìgbà kan wà tó yẹ kó o gba ẹnì kan lálejò, àmọ́ tí o kò ṣe bẹ́ẹ̀? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, á jẹ́ pé àǹfààní kan lo gbé sọnù yẹn. Torí pé tá a bá ń gbàlejò, ó máa jẹ́ ká gbádùn àjọṣe pẹ̀lú àwọn míì, àá sì láwọn ọ̀rẹ́ tó ń báni kalẹ́. Ohun kan tó sì lè jẹ́ ká borí ìdánìkanwà ni pé ká máa gbàlejò. Àmọ́, o lè máa ronú pé, ‘Kí ló máa ń fà á táwọn kan kì í fẹ́ gbàlejò?’ Ẹ jẹ́ ká wo díẹ̀ lára wọn.

14. Kí la lè ṣe tó bá dà bíi pé a ò lè ráyè gbàlejò tàbí ká lọ kí àwọn míì?

14 Ó máa ń gba àkókò àti ìsapá: Ọwọ́ àwa ìránṣẹ́ Jèhófà máa ń dí gan-an torí pé ọ̀pọ̀ nǹkan la máa ń ṣe. Èyí máa ń mú káwọn kan ronú pé àwọn ò lè ráyè gbàlejò tàbí pé àwọn ò lè ṣe wàhálà ẹ̀. Tíwọ náà bá ń ronú bẹ́ẹ̀, á dáa kó o ṣàyẹ̀wò àwọn nǹkan tó ò ń ṣe báyìí. Ǹjẹ́ o lè ṣe àwọn ìyípadà táá jẹ́ kó o lè gbàlejò tàbí táá mú kó o ráyè lọ kí àwọn míì? Ó ṣe tán, Ìwé Mímọ́ gbà wá níyànjú pé ká máa gbàlejò. (Héb. 13:2) Torí náà, kò burú tá a bá ń wáyè gbàlejò, kódà ohun tó yẹ ká máa ṣe ni. Ìyẹn lè gba pé kó o dín àwọn nǹkan tó o fẹ́ ṣe kù tàbí kó o sún wọn sígbà míì.

15. Kí ló mú káwọn kan rò pé àwọn ò lè gbàlejò?

15 Èrò tó o ní nípa ara rẹ: Ṣé ó máa ń wù ẹ́ láti gbàlejò àmọ́ kó máa ṣe ẹ́ bíi pé kì í ṣe irú ẹ ló ń gbàlejò? Àwọn kan máa ń tijú, wọ́n sì máa ń ronú pé kò sí nǹkan táwọn máa bá ẹni náà sọ. Àwọn míì ò lówó lọ́wọ́, wọ́n sì máa ń ronú pé àwọn ò lè tọ́jú àlejò bíi tàwọn míì nínú ìjọ. Síbẹ̀, ó yẹ ká fi sọ́kàn pé, kì í ṣe bí ilé wa ṣe rẹwà tó ló ṣe pàtàkì jù, bí kò ṣe pé kó wà ní mímọ́, kó bójú mu, kó sì tuni lára.

16, 17. Kí ni kò ní jẹ́ kẹ́rù máa bà wá láti gbàlejò?

16 Ọ̀pọ̀ làyà wọn máa ń já láti gbàlejò, torí náà táyà ẹ bá ń já, fọkàn balẹ̀. Alàgbà kan nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì sọ pé: “Lóòótọ́, àyà èèyàn lè máa já tó bá fẹ́ gbàlejò. Àmọ́ bíi tàwọn nǹkan míì tá à ń ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, ayọ̀ téèyàn máa ń rí tó bá gbàlejò pọ̀ ju ohun tó ń náni lọ. Mo máa ń gbádùn kí n kàn jókòó pẹ̀lú àlejò, ká máa sọ̀rọ̀, ká sì máa mu kọfí.” Ká rántí pé ohun tó dáa jù ni pé ká jẹ́ kọ́rọ̀ àwọn àlejò wa jẹ wá lógún. (Fílí. 2:4) Ọ̀pọ̀ wa la máa ń fẹ́ sọ àwọn ìrírí tá a ti ní fáwọn míì. Torí náà, ó lè jẹ́ ìgbà tá a bá gbàlejò tàbí tá a lọ kí àwọn èèyàn làwọn míì máa lè gbọ́ àwọn ìrírí wa. Alàgbà míì sọ pé: “Tí mo bá gba àwọn míì nínú ìjọ lálejò, ó máa ń jẹ́ kí n túbọ̀ mọ̀ wọ́n ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, ó sì máa ń jẹ́ kí n mọ bí wọ́n ṣe kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́.” Tá a bá fìfẹ́ hàn sáwọn àlejò wa, gbogbo wa la máa gbádùn ara wa.

17 Arábìnrin aṣáájú-ọ̀nà kan tó máa ń gba àwọn tó wá fún ilé ẹ̀kọ́ ètò Ọlọ́run sílé sọ pé: “Mi ò kọ́kọ́ fẹ́ gbà wọ́n torí pé mi ò ní àwọn nǹkan amáyédẹrùn nílé, kódà àwọn àlòkù àga àti tábìlì ni mo ní. Àmọ́, ìyàwó ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ náà fi mí lọ́kàn balẹ̀. Ó sọ fún mi pé ọ̀sẹ̀ táwọn máa ń gbádùn jù lẹ́nu iṣẹ́ arìnrìn-àjò làwọn ọ̀sẹ̀ táwọn lò lọ́dọ̀ àwọn tí ò fi bẹ́ẹ̀ ní lọ́wọ́ àmọ́ tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, tí wọ́n sì ń gbé ìgbésí ayé ṣe-bó-o-ti-mọ. Èyí mú kí n rántí ohun tí màmá mi máa ń sọ fún wa ní kékeré, wọ́n á ní: ‘Ó sàn kéèyàn jẹ ewébẹ̀, níbi tí ìfẹ́ wà.’ ” (Òwe 15:17) Torí náà, tá a bá nífẹ̀ẹ́ àwọn míì, á rọrùn fún wa láti gbà wọ́n lálejò, a ò sì ní máa ṣàníyàn.

18, 19. Tá a bá ń gba àwọn míì lálejò, báwo nìyẹn ṣe máa jẹ́ kí àárín wa túbọ̀ gún?

18 Èrò tó o ní nípa àwọn míì: Ṣé ẹnì kan wà nínú ìjọ rẹ tó máa ń múnú bí ẹ? O lè má gba ti ẹni yẹn, tó ò bá sì ṣọ́ra, o lè bẹ̀rẹ̀ sí í fojú burúkú wò ó. O lè má fẹ́ pe irú ẹni bẹ́ẹ̀ wá sílé rẹ torí pé o ò gba tiẹ̀. Ó sì lè jẹ́ pé ẹnì kan ti ṣẹ̀ ẹ́ nígbà kan rí, o ò sì gbàgbé ohun tó ṣe fún ẹ.

19 Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé tá a bá ń gba àwọn míì lálejò, àárín wa á túbọ̀ gún, kódà ó lè pẹ̀tù sọ́kàn àwọn tó dà bí ọ̀tá wa. (Ka Òwe 25:​21, 22.) Tá a bá ń fi ẹ̀mí aájò àlejò hàn sẹ́nì kan tó múnú bí wa, ó lè jẹ́ ká gbé ọ̀rọ̀ náà kúrò lọ́kàn. Ó sì lè jẹ́ ká rí àwọn ibi tẹ́ni náà dáa sí, ìyẹn àwọn nǹkan tí Jèhófà rí tó fi fa ẹni náà wá sínú òtítọ́. (Jòh. 6:44) Tá a bá fìfẹ́ pe ẹnì kan tí kò rò pé a lè pe òun wá sílé wa, ìyẹn lè jẹ́ ká dọ̀rẹ́, kí àárín wa sì wọ̀. Kí la lè ṣe tí ìfẹ́ náà á fi tọkàn wa wá? Ohun kan tá a lè ṣe ni pé ká fi ìmọ̀ràn tó wà nínú Fílípì 2:3 sọ́kàn, pé: “Pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, kí ẹ máa kà á sí pé àwọn ẹlòmíràn lọ́lá jù yín lọ.” Ó yẹ ká máa ronú nípa àwọn ọ̀nà táwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa gbà sàn jù wá lọ, ìyẹn á jẹ́ ká lè kẹ́kọ̀ọ́ lára wọn. Bí àpẹẹrẹ, a lè kẹ́kọ̀ọ́ látinú ìfaradà, ìgbàgbọ́, ìgboyà àtàwọn ànímọ́ Kristẹni míì tí wọ́n ní. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn á jẹ́ ká nífẹ̀ẹ́ wọn, á sì mú kó rọrùn fún wa láti gbà wọ́n lálejò.

OHUN TÓ YẸ KÁ ṢE TẸ́NÌ KAN BÁ GBÀ WÁ LÁLEJÒ

Àwọn tó fẹ́ gbàlejò sábà máa ń ṣètò nǹkan sílẹ̀ fún àlejò wọn (Wo ìpínrọ̀ 20)

20. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká yẹ àdéhùn tá a ti bá ẹnì kan ṣe?

20 Dáfídì béèrè pé: “Jèhófà, ta ni yóò jẹ́ àlejò nínú àgọ́ rẹ?” (Sm. 15:1) Ó wá ṣàlàyé àwọn ànímọ́ tí Jèhófà máa ń fẹ́ káwọn tó bá máa jẹ́ àlejò rẹ̀ ní. Bí àpẹẹrẹ, ó sọ pé tí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ bá jẹ́jẹ̀ẹ́, wọn kì í yẹhùn kódà tí kò bá rọrùn fún wọn. (Sm. 15:4) Tá a bá ti sọ fẹ́nì kan pé a máa wá sọ́dọ̀ rẹ̀, kò yẹ ká yẹ àdéhùn wa. Ẹni tó fẹ́ gbà wá lálejò lè ti ṣètò ọ̀pọ̀ nǹkan sílẹ̀ fún wa, tá ò bá lọ, gbogbo ìsapá ẹ̀ máa já sásán. (Mát. 5:37) Àwọn kan ti yẹ àdéhùn tí wọ́n ṣe pẹ̀lú ẹnì kan torí pé wọ́n fẹ́ lọ sọ́dọ̀ ẹlòmíì tó dà bíi pé ó sàn ju ẹni tó kọ́kọ́ pè wọ́n. Àmọ́, ṣé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ dáa? Dípò tá a fi máa ṣe bẹ́ẹ̀, ṣe ló yẹ ká lọ sọ́dọ̀ ẹni tá a ti bá ṣàdéhùn, ká sì mọrírì ohunkóhun tó bá fún wa. (Lúùkù 10:7) Àmọ́ o, tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ lohun kan ṣẹlẹ̀ tá ò fi ní lè lọ, ó yẹ ká tètè sọ fún ẹni tó fẹ́ gbà wá lálejò.

21. Kí ló yẹ ká fi sọ́kàn tá a bá fẹ́ múnú ẹni tó gbà wá lálejò dùn?

21 Àwọn kan máa ń sọ pé ‘báyìí là ń ṣe nílẹ̀ wa, èèwọ̀ ibòmíì ni.’ Òótọ́ sì ni torí pé láwọn àṣà ìbílẹ̀ kan, kò sóhun tó burú tẹ́nì kan bá lọ sílé ẹlòmíì láìsọ tẹ́lẹ̀, àmọ́ wọn ò nífẹ̀ẹ́ sírú ẹ̀ níbòmíì. Láwọn ilẹ̀ kan, ohun tó dáa jù ni wọ́n fi máa ń ṣàlejò, àmọ́ láwọn ibòmíì, ohun kan náà ni onílé àtàlejò máa jẹ. Láwọn ibì kan, àwọn àlejò kì í ṣánwọ́ wá, àmọ́ láwọn ibòmíì, wọn ò retí kí àlejò gbé nǹkan kan wá. Bákan náà, láwọn ibì kan, ó dìgbà tí wọ́n bá pe ẹnì kan lẹ́ẹ̀mejì sí ẹ̀ẹ̀mẹta kó tó lè gbà láti wá, àmọ́ níbòmíì, ìwà àrífín ni tẹ́nì kan bá kọ̀. Torí náà, ó yẹ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti múnú ẹni tó gbà wá lálejò dùn.

22. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa fi ‘ẹ̀mí aájò àlejò hàn sí ara wa lẹ́nì kìíní-kejì’?

22 Ju gbogbo ẹ̀ lọ, “òpin ohun gbogbo ti sún mọ́lé” ju ti ìgbàkígbà rí lọ. (1 Pét. 4:7) Láìpẹ́, ìpọ́njú ńlá tírú ẹ̀ ò ṣẹlẹ̀ rí máa bẹ̀rẹ̀. Bí nǹkan sì ṣe ń le sí i nínú ayé yìí, ó pọn dandan pé ká ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fáwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin. Àkókò yìí gan-an ló yẹ ká fi ìmọ̀ràn Pétérù sílò, pé: “Ẹ ní ẹ̀mí aájò àlejò fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì.” Ohun pàtàkì tó ń fúnni láyọ̀ ni, àá sì máa gba ara wa lálejò títí láé kódà wọnú ayé tuntun.​—1 Pét. 4:9.