Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀yin Òbí, Ṣé Ẹ̀ Ń Ran Àwọn Ọmọ Yín Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Ṣèrìbọmi?

Ẹ̀yin Òbí, Ṣé Ẹ̀ Ń Ran Àwọn Ọmọ Yín Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Ṣèrìbọmi?

“Èé ti ṣe tí ìwọ fi ń jáfara? Dìde, kí a batisí rẹ.” ​ÌṢE 22:16.

ORIN: 51, 135

1. Kí ló yẹ káwọn òbí Kristẹni rí i dájú pé àwọn ọmọ wọn mọ̀ kí wọ́n tó ṣèrìbọmi?

BLOSSOM BRANDT sọ ohun táwọn òbí rẹ̀ ṣe nígbà tó sọ pé òun fẹ́ ṣèrìbọmi, ó ní: “Ọ̀pọ̀ oṣù ni mo fi ń sọ fún dádì àti mọ́mì mi pé mo fẹ́ ṣèrìbọmi, àmọ́ torí wọ́n fẹ́ rí i dájú pé mo mọ bí ohun tí mo fẹ́ ṣe ti ṣe pàtàkì tó, wọ́n sábà máa ń ṣàlàyé ohun tí ìrìbọmi túmọ̀ sí fún mi. Nígbà tó di December 31, 1934, mo ṣèrìbọmi.” Bákan náà lónìí, àwọn òbí Kristẹni máa ń fẹ́ ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ kí wọ́n lè ṣe ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu. Àjọṣe téèyàn ní pẹ̀lú Ọlọ́run lè bà jẹ́ téèyàn bá ń fi ìrìbọmi falẹ̀ láìnídìí tàbí tó ń fòní-dónìí fọ̀la-dọ́la. (Ják. 4:17) Síbẹ̀, àwọn òbí máa ń rí i dájú pé àwọn ọmọ wọn ti ṣe tán láti ṣe gbogbo ohun tí Ọlọ́run fẹ́ káwọn Kristẹni máa ṣe kí wọ́n tó ṣèrìbọmi.

2. (a) Kí làwọn alábòójútó àyíká kan kíyè sí? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

2 Àwọn alábòójútó àyíká kan sọ pé àwọn máa ń rí àwọn ọ̀dọ́ kan tó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pé ọmọ ogún ọdún tàbí kí wọ́n ti lé lógún ọdún síbẹ̀ tí wọn ò tíì ṣèrìbọmi bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló tọ́ wọn dàgbà. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn ọmọ náà máa ń lọ sípàdé déédéé, wọ́n ń lọ sóde ẹ̀rí, wọ́n sì gbà pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn. Síbẹ̀ fáwọn ìdí kan, wọn ò fẹ́ ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà kí wọ́n sì ṣèrìbọmi. Kí ló fà á? Nígbà míì, àwọn òbí wọn ló máa ń sọ fún wọn pé kí wọ́n ṣe sùúrù díẹ̀ ná kí wọ́n tó ṣèrìbọmi. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò àwọn nǹkan mẹ́rin tí kì í jẹ́ káwọn òbí Kristẹni kan fáwọn ọmọ wọn níṣìírí láti ṣèrìbọmi.

ṢÉ ỌMỌ MI TI DÀGBÀ TÓ?

3. Kí nìdí táwọn òbí Blossom fi ń ṣàníyàn?

3 Àwọn òbí Blossom tá a sọ̀rọ̀ wọn ní ìpínrọ̀ àkọ́kọ́ ń ṣàníyàn pé bóyá ni ọmọ àwọn ti dàgbà tó láti mọ ohun tí ìrìbọmi túmọ̀ sí àti bí ìrìbọmi ti ṣe pàtàkì tó. Báwo làwọn òbí ṣe máa mọ̀ bóyá àwọn ọmọ wọn ti tẹ̀ síwájú débi tí wọ́n fi lè ya ara wọn sí mímọ́, kí wọ́n sì ṣèrìbọmi?

4. Báwo ni àṣẹ tí Jésù pa nínú Mátíù 28:​19, 20 ṣe lè ran àwọn òbí lọ́wọ́ bí wọ́n ṣe ń kọ́ àwọn ọmọ wọn?

4 Ka Mátíù 28:​19, 20. Bá a ṣe jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, Bíbélì ò sọ bó ṣe yẹ kéèyàn dàgbà tó kó tó ṣèrìbọmi. Síbẹ̀, ó máa dáa káwọn òbí ronú nípa ohun tó túmọ̀ sí láti sọ ẹnì kan di ọmọ ẹ̀yìn. Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a tú sí ‘sọ di ọmọ ẹ̀yìn’ nínú Mátíù 28:19 túmọ̀ sí pé ká kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ kó lè di ọmọ ẹ̀yìn. Ọmọ ẹ̀yìn lẹni tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa Jésù, tó lóye ohun tó kọ́, tó sì ń fi ẹ̀kọ́ náà sílò. Torí náà, ohun tó yẹ kó jẹ àwọn òbí lógún jù ni bí wọ́n ṣe máa kọ́ àwọn ọmọ wọn láti kékeré, kí wọ́n lè ṣèrìbọmi, kí wọ́n sì di ọmọ ẹ̀yìn Kristi. Òótọ́ ni pé ọmọ tó ṣì kéré gan-an ò lè ṣèrìbọmi, síbẹ̀ Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn ọmọdé lè lóye òtítọ́, kí wọ́n sì mọyì rẹ̀.

5, 6. (a) Kí ni Bíbélì sọ nípa Tímótì, kí sì nìyẹn jẹ́ ká mọ̀ nípa ìgbà tó ṣèrìbọmi? (b) Báwo làwọn òbí tó gbọ́n ṣe lè ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́?

5 Àtikékeré ni Tímótì ti mọyì òtítọ́. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé àtọmọdé jòjòló ni Tímótì ti kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé bàbá Tímótì kì í ṣe Kristẹni, síbẹ̀ ìyá rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ àgbà kọ́ ọ ní Ìwé Mímọ́, wọ́n sì jẹ́ kó mọyì rẹ̀. Èyí mú kí ìgbàgbọ́ rẹ̀ lágbára gan-an. (2 Tím. 1:5; 3:​14, 15) Nígbà tó máa fi pé nǹkan bí ọmọ ogún ọdún, ó ti tẹ̀ síwájú débi pé ó tóótun fún àwọn àkànṣe iṣẹ́ ìsìn nínú ìjọ.​—Ìṣe 16:​1-3.

6 Òótọ́ ni pé àwọn ọmọ máa ń yàtọ̀ síra. Bí àpẹẹrẹ, òtítọ́ máa ń tètè yé àwọn ọmọ kan ju àwọn míì lọ. Bákan náà, àtikékeré ni òtítọ́ ti máa ń jinlẹ̀ lọ́kàn àwọn ọmọ kan, táá sì wù wọ́n láti ṣèrìbọmi. Àmọ́, àwọn míì lè dàgbà díẹ̀ kí wọ́n tó pinnu láti ṣèrìbọmi. Torí náà, àwọn òbí tó gbọ́n kì í ti ọmọ wọn pé kó lọ ṣèrìbọmi. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n máa ń kíyè sí ibi tí òye ọmọ kọ̀ọ̀kan mọ, wọ́n sì máa ń fìyẹn sọ́kàn tí wọ́n bá ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́. Inú àwọn òbí máa ń dùn tí ọmọ wọn bá fi ohun tó wà nínú Òwe 27:11 sọ́kàn. (Kà á.) Síbẹ̀, wọn ò gbọ́dọ̀ gbàgbé ìdí tí wọ́n fi ń kọ́ àwọn ọmọ wọn lẹ́kọ̀ọ́, ìyẹn kí wọ́n lè di ọmọ ẹ̀yìn Kristi. Ìdí nìyẹn tó fi yẹ káwọn òbí bi ara wọn pé, ‘Ṣé òtítọ́ ti jinlẹ̀ lọ́kàn ọmọ mi débi tó fi lè ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Ọlọ́run, kó sì ṣèrìbọmi?’

ṢÉ ỌMỌ MI TI NÍ ÌMỌ̀ TÓ?

7. Ṣó dìgbà tí ẹnì kan bá mọ gbogbo ohun tó wà nínú Bíbélì kó tó lè ṣèrìbọmi? Ṣàlàyé.

7 Táwọn òbí bá ń kọ́ àwọn ọmọ wọn lẹ́kọ̀ọ́, wọ́n máa ń fẹ́ kí wọ́n ní ìmọ̀ tó jinlẹ̀ táá mú kó wù wọ́n láti ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà. Síbẹ̀, kò dìgbà téèyàn bá mọ gbogbo ohun tó wà nínú Bíbélì kó tó lè ya ara rẹ̀ sí mímọ́ kó sì ṣèrìbọmi. Ìdí ni pé gbogbo Kristẹni ló yẹ kó máa gba ìmọ̀ kún ìmọ̀ lẹ́yìn tí wọ́n bá ṣèrìbọmi. (Ka Kólósè 1:​9, 10.) Torí náà, báwo ni ìmọ̀ tẹ́nì kan ní ṣe gbọ́dọ̀ tó kó tó lè ṣèrìbọmi?

8, 9. Kí la rí kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Pọ́ọ̀lù àti ẹ̀ṣọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n kan?

8 Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ìdílé kan ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní máa jẹ́ káwọn òbí mọ bí ẹnì kan ṣe gbọ́dọ̀ ní ìmọ̀ tó kó tó lè ṣẹ̀rìbọmi. (Ìṣe 16:​25-33) Nígbà tí Pọ́ọ̀lù rìnrìn-àjò míṣọ́nnárì rẹ̀ ẹ̀ẹ̀kejì, ó lọ sílùú Fílípì lọ́dún 50 Sànmánì Kristẹni. Nígbà tó débẹ̀, wọ́n fẹ̀sùn èké kan òun àti Sílà tí wọ́n jọ ń rìnrìn-àjò, wọ́n sì jù wọ́n sẹ́wọ̀n. Nígbà tó di òru, ìmìtìtì ilẹ̀ kan wáyé, ó sì mi ọgbà ẹ̀wọ̀n náà débi pé gbogbo ilẹ̀kùn ló ṣí sílẹ̀ gbayawu. Nígbà tí ẹ̀ṣọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n náà rí ohun tó ṣẹlẹ̀, ó rò pé àwọn ẹlẹ́wọ̀n náà ti sá lọ, ló bá fẹ́ pa ara rẹ̀, àmọ́ Pọ́ọ̀lù ò jẹ́ kó ṣe bẹ́ẹ̀. Pọ́ọ̀lù àti Sílà wàásù fún ọkùnrin náà àti ìdílé rẹ̀, ohun tí wọ́n gbọ́ sì wọ̀ wọ́n lọ́kàn. Àmọ́, kí lohun tí wọ́n gbọ́ yẹn mú kí wọ́n ṣe? Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni wọ́n ṣèrìbọmi. Kí la rí kọ́ nínú ìtàn yìí?

9 Ó ṣeé ṣe kí ẹ̀ṣọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n náà jẹ́ ọmọ ogun tó ti fẹ̀yìn tì. Kò mọ nǹkan kan nípa Ìwé Mímọ́. Torí náà, kó tó lè lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó gbọ́dọ̀ kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì tó wà nínú Ìwé Mímọ́, kó mọ ohun tí Jèhófà fẹ́ káwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ máa ṣe, kó sì pinnu pé òun á máa pa àwọn àṣẹ Jésù mọ́. Láàárín àsìkò díẹ̀, ó mọyì ohun tó kọ́, ìyẹn ló sì jẹ́ kó ṣèrìbọmi láìjáfara. Ó dájú pé lẹ́yìn tó ṣèrìbọmi, ó ṣì ń kẹ́kọ̀ọ́ sí i. Torí náà, tí ọmọ rẹ bá ti kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì inú Bíbélì, tó mọyì ohun tó kọ́, tó sì ṣe kedere pé ó ti mọ ohun tí ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi túmọ̀ sí, kí lo máa ṣe? O lè sọ fún un pé kó lọ rí àwọn alàgbà kí wọ́n lè gbé e yẹ̀ wò bóyá ó tóótun láti ṣèrìbọmi. * Bíi tàwa yòókù, òun náà á ṣì máa gba ìmọ̀ kún ìmọ̀ jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀, kódà títí láé láá máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà.​—Róòmù 11:​33, 34.

Ẹ̀KỌ́ WO LÓ ṢE PÀTÀKÌ JÙ?

10, 11. (a) Èrò wo làwọn òbí kan ní? (b) Kí ló yẹ kó ṣe pàtàkì jù sí àwọn òbí?

10 Àwọn òbí kan ti ronú pé ó máa dáa káwọn ọmọ wọn kọ́kọ́ lọ sílé ẹ̀kọ́ gíga tàbí kí wọ́n níṣẹ́ gidi lọ́wọ́ kí wọ́n tó ṣèrìbọmi. Lóòótọ́, ó lè jẹ́ bí nǹkan ṣe máa dáa fáwọn ọmọ náà ni wọ́n ń wá, àmọ́ ṣé ìyẹn ló máa jẹ́ káwọn ọmọ náà ní ojúlówó ayọ̀? Ìbéèrè tó ṣe pàtàkì jù ni pé, ṣé irú èrò bẹ́ẹ̀ bá Ìwé Mímọ́ mu? Kí ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ nípa rẹ̀?​—Ka Oníwàásù 12:1.

11 Ó ṣe pàtàkì ká máa rántí pé gbogbo ohun tó wà nínú ayé Èṣù yìí ló tako ohun tí Jèhófà fẹ́. (Ják. 4:​7, 8; 1 Jòh. 2:​15-17; 5:19) Àjọṣe tó dáa tí ọmọ kan ní pẹ̀lú Jèhófà ló máa dáàbò bò ó lọ́wọ́ Sátánì àti ayé búburú yìí. Tó bá jẹ́ pé bí ọmọ kan ṣe máa lọ sílé ẹ̀kọ́ gíga àti bó ṣe máa níṣẹ́ gidi lọ́wọ́ làwọn òbí rẹ̀ ń lé, irú ọmọ bẹ́ẹ̀ lè rò pé ohun tó ṣe pàtàkì jù nígbèésí ayé nìyẹn, èyí sì lè ṣàkóbá fún un. Ohun táyé yìí fẹ́ káwọn èèyàn máa rò ni pé ó dìgbà téèyàn bá wà nípò ńlá kó tó láyọ̀. Ṣé àwọn òbí tó nífẹ̀ẹ́ ọmọ wọn sì máa fẹ́ kí ọmọ wọn ní irú èrò bẹ́ẹ̀? Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, ìgbà téèyàn bá fi Jèhófà sípò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé rẹ̀ nìkan ló tó lè ní ayọ̀ tòótọ́ kó sì ṣàṣeyọrí.​—Ka Sáàmù 1:​2, 3.

TÍ ỌMỌ MI BÁ DẸ́ṢẸ̀ ŃKỌ́?

12. Kí nìdí táwọn òbí kan ò fi fẹ́ káwọn ọmọ wọn tíì ṣèrìbọmi?

12 Nígbà tí ìyá kan ń sọ ìdí tí kò fi jẹ́ kí ọmọ rẹ̀ ṣèrìbọmi, ó sọ pé: “Ìdí tí mi ò fi jẹ́ kó ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ẹ̀rù ń bà mí kí wọ́n má lọ yọ ọ́ lẹ́gbẹ́.” Bíi ti arábìnrin yìí, àwọn òbí kan ronú pé á dáa káwọn ọmọ wọn dàgbà kí ìwà ọmọdé sì ti kúrò lára wọn kí wọ́n tó ṣèrìbọmi. (Jẹ́n. 8:21; Òwe 22:15) Wọ́n lè máa ronú pé, ‘Tí ọmọ mi ò bá kúkú ṣèrìbọmi, wọn ò lè yọ ọ́ lẹ́gbẹ́.’ Kí nìdí tí èrò yìí ò fi tọ̀nà?​—Ják. 1:22.

13. Tí ẹnì kan kò bá tíì ṣèrìbọmi, ṣé ìyẹn túmọ̀ sí pé kò ní jíhìn fún Jèhófà? Ṣàlàyé.

13 Ó dájú pé àwọn òbí Kristẹni máa fẹ́ káwọn ọmọ wọn mọ ohun tó túmọ̀ sí láti ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà kí wọ́n tó ṣèrìbọmi. Síbẹ̀, àṣìṣe ló máa jẹ́ tí òbí kan bá ń ronú pé Jèhófà máa gbójú fo ẹ̀ṣẹ̀ tí ọmọ òun dá torí pé kò tíì ṣèrìbọmi. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ti pé ẹnì kan ò tíì ṣèrìbọmi kò ní kó má jíhìn fún Jèhófà, tó bá ti mọ ìyàtọ̀ láàárín ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́, ó di dandan kó jíhìn. (Ka Jákọ́bù 4:17.) Àwọn òbí tó gbọ́n máa ń sapá láti fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fáwọn ọmọ wọn, dípò tí wọ́n á fi máa ní kí wọ́n má tíì ṣèrìbọmi. Àtikékeré ni wọ́n ti máa ń kọ́ àwọn ọmọ wọn ní àwọn ìlànà Jèhófà kí wọ́n má bàa ṣìwà hù. (Lúùkù 6:40) Ìfẹ́ tí ọmọ rẹ ní fún Jèhófà á jẹ́ kó máa pa àwọn òfin Jèhófà mọ́ nígbà gbogbo.​—Aísá. 35:8.

BÁWỌN MÍÌ ṢE LÈ RAN ÀWỌN ÒBÍ LỌ́WỌ́

14. Báwo làwọn alàgbà ṣe lè ran àwọn òbí lọ́wọ́ káwọn ọmọ wọn lè tẹ̀ síwájú kí wọ́n sì ṣèrìbọmi?

14 Àwọn alàgbà náà lè ran àwọn òbí lọ́wọ́ láti kọ́ ọmọ wọn kí wọ́n lè túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Wọ́n lè ṣe bẹ́ẹ̀ tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀ nípa ayọ̀ téèyàn á rí tó bá fayé rẹ̀ sin Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, arábìnrin kan sọ pé Arákùnrin Charles T. Russell bá òun sọ̀rọ̀ nígbà tóun wà lọ́mọ ọdún mẹ́fà. Ó ní: “Ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ló fi bá mi sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tí mo lè ṣe nínú ìjọsìn Jèhófà.” Èyí sì mú kí arábìnrin yìí ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà fún ohun tó lé ní àádọ́rin [70] ọdún. Torí náà, tá a bá ń gbóríyìn fáwọn èèyàn tá a sì ń sọ̀rọ̀ ìṣírí fún wọn, ó máa ń mú kí wọ́n tẹ̀ síwájú gan-an. (Òwe 25:11) Àwọn alàgbà lè pe àwọn òbí àtàwọn ọmọ wọn tí wọ́n bá fẹ́ ṣe àwọn iṣẹ́ pàtó kan ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, kí wọ́n sì fáwọn ọmọ náà níṣẹ́ tí agbára wọn gbé.

15. Báwo ni gbogbo wa ṣe lè ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́?

15 Gbogbo wa la lè ran àwọn ọ̀dọ́ inú ìjọ lọ́wọ́ tá a bá ń fìfẹ́ hàn sí wọn. Èyí máa gba pé ká máa kíyè sí bí wọ́n ṣe ń tẹ̀ síwájú nínú ìjọ. Bí àpẹẹrẹ, ṣé o kíyè sí ọ̀dọ́ kan tó dáhùn lọ́rọ̀ ara rẹ̀ tàbí tó ṣiṣẹ́ nípàdé àárín ọ̀sẹ̀? Ṣé o ti kíyè sí ọ̀dọ́ kan tó kojú àdánwò tó sì borí tàbí tó wàásù nílé ìwé? Jẹ́ kó mọ́ ẹ lára láti máa gbóríyìn fún wọn. Ohun míì tó o lè ṣe ni pé kó o máa bá àwọn ọ̀dọ́ yìí sọ̀rọ̀ kí ìpàdé tó bẹ̀rẹ̀ àti lẹ́yìn ìpàdé, kó o sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ọ̀rọ̀ wọn jẹ ẹ́ lógún. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn ọ̀dọ́ yìí á mọ̀ pé àwọn náà wà lára “ìjọ ńlá” tí Jèhófà ń darí.​—Sm. 35:18.

RAN ỌMỌ RẸ LỌ́WỌ́ KÓ LÈ ṢÈRÌBỌMI

16, 17. (a) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kéèyàn ṣèrìbọmi? (b) Kí ló máa ń fún àwọn òbí láyọ̀ jù? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

16 Ọ̀kan lára àwọn ojúṣe pàtàkì táwọn òbí ní ni pé kí wọ́n tọ́ àwọn ọmọ wọn dàgbà nínú “ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.” (Éfé. 6:4; Sm. 127:3) Nígbà ayé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, gbàrà tí wọ́n bá ti bímọ ni ọmọ náà ti jẹ́ ti Jèhófà. Àmọ́ ọ̀rọ̀ àwa Kristẹni ò rí bẹ́ẹ̀. Ti pé àwọn òbí nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tí wọ́n sì mọyì ẹ̀kọ́ òtítọ́ kò túmọ̀ sí pé àwọn ọmọ náà máa ṣe bẹ́ẹ̀. Torí náà, gbàrà táwọn òbí bá ti bímọ ni kí wọ́n ti fi sọ́kàn pé àwọn fẹ́ kọ́mọ náà ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà, kó sì ṣèrìbọmi. Àbí kí ló tún ṣe pàtàkì ju ìyẹn lọ? Ó ṣe tán, kí ẹnì kan tó lè la ayé burúkú yìí já, ó gbọ́dọ̀ ya ara rẹ̀ sí mímọ́, kó ṣèrìbọmi, kó sì jẹ́ adúróṣinṣin sí Jéhófà.​—Mát. 24:13.

Ohun tó yẹ kó jẹ àwọn òbí lógún jù ni bí ọmọ wọn ṣe máa di ọmọ ẹ̀yìn Kristi (Wo ìpínrọ̀ 16 àti 17)

17 Nígbà tí Blossom Brandt sọ pé òun fẹ́ ṣèrìbọmi, àwọn òbí rẹ̀ fẹ́ mọ̀ bóyá lóòótọ́ ló ti ṣe tán láti gbé ìgbésẹ̀ pàtàkì yìí. Nígbà tí wọ́n sì rí i pé ó ti ṣe tán, wọ́n tì í lẹ́yìn. Ní alẹ́ tó ṣáájú ọjọ́ ìrìbọmi rẹ̀, bàbá rẹ̀ ṣe ohun kan tó múnú rẹ̀ dùn gan-an. Blossom sọ pé: “Dádì ní kí gbogbo wa kúnlẹ̀, wọ́n sì gbàdúrà. Wọ́n sọ fún Jèhófà pé inú àwọn dùn pé ọmọ àwọn ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún un.” Ní ohun tó lé ní ọgọ́ta [60] ọdún lẹ́yìn náà, Blossom sọ pé: “Mi ò lè gbàgbé alẹ́ ọjọ́ yẹn láé!” Àdúrà wa ni pé kí ẹ̀yin òbí náà ní irú ayọ̀ àti ìbàlẹ̀ ọkàn téèyàn máa ń ní táwọn ọmọ rẹ̀ bá ya ara wọn sí mímọ́, tí wọ́n ṣèrìbọmi, tí wọ́n sì ń fayọ̀ sin Jèhófà nìṣó.

^ ìpínrọ̀ 9 Ẹ̀yin òbí lè bá àwọn ọmọ yín jíròrò ohun tó wà nínú ìwé Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè​—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì, ojú ìwé 304 sí 310. Ẹ tún wo “Àpótí Ìbéèrè” tó wà nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti April 2011, ojú ìwé 2.