Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

‘Fetí sí Ìbáwí Kó O sì Di Ọlọ́gbọ́n’

‘Fetí sí Ìbáwí Kó O sì Di Ọlọ́gbọ́n’

“Ẹ̀yin ọmọ, . . . ẹ fetí sí ìbáwí kí ẹ sì di ọlọ́gbọ́n.”​ÒWE 8:​32, 33.

ORIN: 56, 89

1. Báwo la ṣe lè di ọlọ́gbọ́n, àǹfààní wo la sì máa rí?

JÈHÓFÀ ni orísun ọgbọ́n, ó sì máa ń fún àwọn míì ní ọgbọ́n rẹ̀. Jákọ́bù 1:5 sọ pé: “Bí ẹnikẹ́ni nínú yín bá ṣaláìní ọgbọ́n, kí ó máa bá a nìṣó ní bíbéèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, nítorí òun a máa fi fún gbogbo ènìyàn pẹ̀lú ìwà ọ̀làwọ́.” Ọ̀nà kan tá a lè gbà ní ọgbọ́n Ọlọ́run ni pé ká máa gba ìbáwí rẹ̀. Ọgbọ́n yìí máa ń dáàbò bò wá, torí ó máa ń jẹ́ ká yẹra fáwọn nǹkan tí kò tọ́, ó sì ń mú ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. (Òwe 2:​10-12) Èyí máa jẹ́ ká lè “pa ara [wa] mọ́ nínú ìfẹ́ Ọlọ́run . . . pẹ̀lú ìyè àìnípẹ̀kun níwájú.”​—Júúdà 21.

2. Kí ló máa jẹ́ ká mọyì ìbáwí Ọlọ́run?

2 Nígbà míì, ó máa ń ṣòro fún wa láti gba ìbáwí, lára ohun tó sì ń fà á ni àìpé wa, ibi tí wọ́n ti tọ́ wa dàgbà àtàwọn nǹkan míì. Àmọ́, tá a bá gbà pé torí pé Jèhófà fẹ́ràn wa ló ṣe ń bá wa wí, èyí máa mú ká mọyì ìbáwí rẹ̀. Òwe 3:​11, 12 sọ pé: “Ìwọ ọmọ mi, má kọ ìbáwí Jèhófà, . . . nítorí pé ẹni tí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ni ó ń fi ìbáwí tọ́ sọ́nà.” Ó yẹ ká máa fi sọ́kàn nígbà gbogbo pé, ire wa ni Jèhófà ń wá. (Ka Hébérù 12:​5-11.) Torí pé Jèhófà mọ̀ wá dáadáa, ìbáwí rẹ̀ máa ń tọ́, kò sì ní bá wa wí kọjá bó ṣe yẹ. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò apá mẹ́rin míì tí ìbáwí pín sí: (1) ìkóra-ẹni-níjàánu (2) ìbáwí táwọn òbí máa ń fún àwọn ọmọ, (3) ìbáwí nínú ìjọ àti (4) ohun míì tó burú ju ẹ̀dùn ọkàn tí ìbáwí máa ń mú wá.

ẸNI TÓ Ń KÓ ARA RẸ̀ NÍJÀÁNU JẸ́ ỌLỌ́GBỌ́N

3. Báwo ni ọmọ kan ṣe lè mọ béèyàn ṣe ń kóra ẹ̀ níjàánu? Ṣàpèjúwe.

3 Ẹni tó ń kó ara rẹ̀ níjàánu máa ń kíyè sára kí èrò àti ìṣe rẹ̀ lè wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì. Yàtọ̀ síyẹn, ó tún máa ń kẹ́kọ̀ọ́ nínú àṣìṣe rẹ̀. A kì í bí ìkóra-ẹni-níjàánu mọ́ni, èèyàn máa ń kọ́ ọ ni. Bí àpẹẹrẹ, tí ọmọ kan bá fẹ́ kọ́ bí wọ́n ṣe ń gun kẹ̀kẹ́, àwọn òbí rẹ̀ máa dì í mú lórí kẹ̀kẹ́ náà kó má bàa ṣubú. Àmọ́ bí ọmọ náà ṣe ń jáfáfá sí i, àwọn òbí rẹ̀ á máa fi í lẹ̀ díẹ̀díẹ̀, tó bá sì ti mọ̀ ọ́n gùn, wọn ò ní dì í mú mọ́. Lọ́nà kan náà, táwọn òbí bá ń fi sùúrù kọ́ àwọn ọmọ wọn “nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà,” tí wọn ò sì jẹ́ kó sú wọn, ṣe nìyẹn á jẹ́ káwọn ọmọ náà mọ bí wọ́n ṣe lè kó ara wọn níjàánu, wọ́n á sì gbọ́n.​—Éfé. 6:4.

4, 5. (a) Kí nìdí tí ìkóra-ẹni-níjàánu fi ṣe pàtàkì téèyàn bá máa gbé “àkópọ̀ ìwà tuntun” wọ̀? (b) Kí nìdí tí kò fi yẹ ká sọ̀rètí nù tá a bá tiẹ̀ “ṣubú ní ìgbà méje pàápàá”?

4 Bó ṣe máa ń rí fáwọn tó ti dàgbà kí wọ́n tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ náà nìyẹn. Lóòótọ́, wọ́n lè ti ní ìkóra-ẹni-níjàánu dé ìwọ̀n àyè kan tẹ́lẹ̀, àmọ́ téèyàn bá ṣẹ̀ṣẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, bí ìkókó ló ṣe rí. Síbẹ̀, bí wọ́n ṣe ń gbé “àkópọ̀ ìwà tuntun” wọ̀, tí wọ́n sì ń sapá láti fara wé Jésù, wọ́n á túbọ̀ máa dàgbà nípa tẹ̀mí. (Éfé. 4:​23, 24) Ìkóra-ẹni-níjàánu wà lára ohun táá jẹ́ kẹ́ni náà dàgbà nípa tẹ̀mí. Ìdí ni pé ìkóra-ẹni-níjàánu máa ń jẹ́ ká “kọ àìṣèfẹ́ Ọlọ́run sílẹ̀ àti àwọn ìfẹ́-ọkàn ti ayé,” ká sì “gbé pẹ̀lú ìyèkooro èrò inú àti òdodo àti fífọkànsin Ọlọ́run nínú ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí.”​—Títù 2:12.

5 Síbẹ̀, gbogbo wa la máa ń ṣàṣìṣe. (Oníw. 7:20) Àmọ́, tẹ́nì kan bá ṣàṣìṣe, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé kò mọ nǹkan ṣe tàbí pé kò lè kó ara ẹ̀ níjàánu. Òwe 24:16 sọ pé: “Olódodo lè ṣubú ní ìgbà méje pàápàá, yóò sì dìde dájúdájú.” Kí ló máa jẹ́ kó dìde pa dà? Ẹ̀mí Ọlọ́run nìkan ló lè ràn án lọ́wọ́, kò lè dá a ṣe. (Ka Fílípì 4:13.) Ìdí sì ni pé apá kan èso ti ẹ̀mí ni ìkóra-ẹni-níjàánu.

6. Kí ló máa jẹ́ kó rọrùn fún wa láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

6 Téèyàn bá fẹ́ ní ìkóra-ẹni-níjàánu, ó tún ṣe pàtàkì pé kó máa gbàdúrà, kó máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kó sì máa ṣàṣàrò. Àmọ́, tó bá ṣòro fún ẹ láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ńkọ́? Bóyá o ò tiẹ̀ nífẹ̀ẹ́ àtimáa kàwé rárá. Rántí pé Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ tó o bá jẹ́ kó ṣe bẹ́ẹ̀. Ó lè jẹ́ kó máa wù ẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ rẹ̀. (1 Pét. 2:2) Ohun àkọ́kọ́ tó o máa ṣe ni pé kó o bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kó o lè ṣètò ara rẹ láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lẹ́yìn náà, ṣe ohun tó bá àdúrà rẹ mu, má jẹ́ kí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà gùn jù. Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, á túbọ̀ rọrùn fún ẹ láti máa kẹ́kọ̀ọ́ á sì tún máa dùn mọ́ ẹ. Inú ẹ máa dùn pé ò ń lo àkókò rẹ láti ronú nípa àwọn òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó ṣeyebíye.​—1 Tím. 4:15.

7. Báwo ni ìkóra-ẹni-níjàánu ṣe lè mú kọ́wọ́ wa tẹ àwọn àfojúsùn tẹ̀mí?

7 Ẹni tó bá ń kóra ẹ̀ níjàánu máa ní àfojúsùn tẹ̀mí, á sì lé e bá. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ bàbá kan tó kíyè sí pé ìtara tóun ní fún ìjọsìn Jèhófà ti ń jó rẹ̀yìn. Ó rí i pé àfi kóun wá nǹkan ṣe, torí náà, ó pinnu pé òun á bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Kíyẹn lè ṣeé ṣe, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ka àwọn ìtẹ̀jáde tó sọ̀rọ̀ nípa ohun tó fẹ́ ṣe, ó si tún fọ̀rọ̀ náà sádùúrà. Ohun tó ṣe yìí ràn án lọ́wọ́ gan-an, ó sì mú kó túbọ̀ ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. Ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ láwọn ìgbà tó bá lè ṣe bẹ́ẹ̀. Kí nìyẹn wá yọrí sí? Láìka gbogbo ohun tó fẹ́ dí i lọ́wọ́ sí, ó pọkàn pọ̀ sórí ohun tó fẹ́ ṣe, lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ó di aṣáájú-ọ̀nà déédéé.

Ẹ TỌ́ ÀWỌN ỌMỌ YÍN DÀGBÀ NÍNÚ ÌBÁWÍ JÈHÓFÀ

Àwọn ọmọdé kì í mọ ìyàtọ̀ láàárín ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́, wọ́n nílò ìtọ́sọ́nà (Wo ìpínrọ̀ 8)

8-10. Kí ló máa ran àwọn òbí lọ́wọ́ láti tọ́ àwọn ọmọ wọn kí wọ́n lè sin Jèhófà? Ṣàlàyé.

8 Àǹfààní ńlá làwọn òbí ní láti tọ́ àwọn ọmọ wọn dàgbà “nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.” (Éfé. 6:4) Ìyẹn ò sì rọrùn rárá nínú ayé burúkú yìí. (2 Tím. 3:​1-5) Lóòótọ́, àwọn ọmọdé máa ń ní ẹ̀rí ọkàn, àmọ́ wọn kì í mọ ìyàtọ̀ láàárín ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́. Torí náà, kí ẹ̀rí ọkàn wọn tó lè máa ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ, àwọn òbí gbọ́dọ̀ máa tọ́ wọn sọ́nà kí wọ́n sì máa bá wọn wí. (Róòmù 2:​14, 15) Ìwé kan tó ń ṣàlàyé Bíbélì sọ pé ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a tú sí “ìbáwí” lè túmọ̀ sí “títọ́ ọmọ dàgbà.”

9 Ọkàn àwọn ọmọ tí wọ́n bá ń fìfẹ́ bá wí máa ń balẹ̀. Wọ́n mọ̀ pé òmìnira àwọn ní ààlà àti pé gbogbo ohun táwọn bá ṣe ló máa yọrí sí nǹkan kan, yálà sí rere tàbí búburú. Ẹ ò rí i bó ti ṣe pàtàkì tó pé kí àwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni máa bẹ Jèhófà pé kó tọ́ àwọn sọ́nà. Ẹ má sì gbàgbé pé bí wọ́n ṣe ń tọ́ ọmọ yàtọ̀ láti ibì kan sí òmíì, ó sì máa ń yí pa dà látìgbàdégbà. Ó máa ń rọrùn fáwọn òbí tó bá ń tẹ́tí sí Ọlọ́run láti tọ́ àwọn ọmọ wọn yanjú torí pé ọgbọ́n Ọlọ́run ni wọ́n ń gbára lé, kì í ṣe òye tara wọn tàbí ìmọ̀ràn tí ayé ń fúnni lórí ọ̀rọ̀ ọmọ títọ́.

10 Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Nóà. Nígbà tí Jèhófà ní kó kan ọkọ̀ áàkì, Nóà ò gbára lé òye tirẹ̀. Torí pé Nóà ò tíì kan ọkọ̀ rí, ó gbára lé Jèhófà, ó sì ṣe gbogbo ohun tí Jèhófà ní kó ṣe, kódà Bíbélì ní: “Ó ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́.” (Jẹ́n. 6:22) Kí nìyẹn wá yọrí sí? Nóà rí ọkọ̀ náà kàn, ó sì gba gbogbo ìdílé rẹ̀ là. Yàtọ̀ síyẹn, Nóà tún tọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ yanjú. Kí ló jẹ́ kó ṣàṣeyọrí? Ó gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run pé ó máa fún òun ní ọgbọ́n tóun nílò. Àwọn ọmọ Nóà gbẹ̀kọ́ torí pé òun náà fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fún wọn, ìyẹn ò sì rọrùn rárá nínú ayé burúkú tó ṣáájú Ìkún Omi yẹn.​—Jẹ́n. 6:5.

11. Báwo làwọn òbí ṣe lè fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fáwọn ọmọ wọn, kí sì nìdí tíyẹn fi ṣe pàtàkì?

11 Báwo lẹ̀yin òbí náà ṣe lè “ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́” lójú Jèhófà? Ẹ máa tẹ́tí sí Jèhófà. Ẹ máa ka Ọ̀rọ̀ rẹ̀ kẹ́ ẹ sì máa fi àwọn ìtọ́ni tí ètò rẹ̀ ń fún wa sílò. Tó bá yá, àwọn ọmọ yín náà máa dúpẹ́ lọ́wọ́ yín pé ẹ ṣe bẹ́ẹ̀. Arákùnrin kan sọ pé: “Inú mi dùn gan-an fún bí àwọn òbí mi ṣe tọ́ mi. Gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe ni wọ́n ṣe kí òtítọ́ lè wọ̀ mí lọ́kàn. Àwọn ló jẹ́ kọ́wọ́ mi tẹ púpọ̀ lára àwọn ohun tí mò ń gbé ṣe nínú ètò Ọlọ́run báyìí.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn òbí kan máa ń sapá gan-an, síbẹ̀ àwọn ọmọ wọn ṣì máa ń fi Jèhófà sílẹ̀. Àmọ́, àwọn òbí tó ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe kí òtítọ́ lè wọ àwọn ọmọ wọn lọ́kàn máa ń ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́, wọ́n sì máa ń retí pé lọ́jọ́ kan, ọmọ àwọn máa pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà.

12, 13. (a) Báwo làwọn òbí ṣe lè fi hàn pé àwọn jẹ́ onígbọràn tí wọ́n bá yọ ọmọ wọn lẹ́gbẹ́? (b) Báwo ni ìgbọràn ṣe ṣe ìdílé kan láǹfààní?

12 Ọ̀kan lára ohun tó máa ń le jù fáwọn òbí ni bí wọ́n ṣe máa ṣègbọràn sí Jèhófà tí wọ́n bá yọ ọmọ wọn lẹ́gbẹ́. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ ìyá kan tí wọ́n yọ ọmọ rẹ̀ lẹ́gbẹ́, tí ọmọ náà sì kúrò nílé. Ìyá yẹn sọ pé: “Mo máa ń wá àwọn ìtẹ̀jáde wa kí n lè rí ìsọfúnni tí màá fi kẹ́wọ́ pé òun ló mú kí n máa bá ọmọ mi àti ọmọ ọmọ mi sọ̀rọ̀. Àmọ́, ọkọ mi jẹ́ kí n mọ̀ pé ọwọ́ Jèhófà lọmọ wa wà, àti pé ó ṣì ń bá a wí lọ́wọ́, torí náà a ò gbọ́dọ̀ ṣe ohunkóhun tó máa tako ìtọ́ni Jèhófà.”

13 Ní ọdún díẹ̀ lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n gba ọmọ náà pa dà. Ìyá yẹn sọ pé: “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ojoojúmọ́ ló ń pè mí, ó sì bọ̀wọ̀ fún èmi àti ọkọ mi gan-an torí ó mọ̀ pé a ṣègbọràn sí Ọlọ́run. A ti wá sún mọ́ra gan-an báyìí.” Tó o bá ní ọmọ tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́, ṣé wàá “fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà,” àbí òye tìrẹ lo máa gbára lé? (Òwe 3:​5, 6) Máa fi sọ́kàn pé ìfẹ́ tí kò lẹ́gbẹ́ tí Jèhófà ní sí wa ló ń mú kó bá wa wí, àti pé ọgbọ́n rẹ̀ ò láfiwé. Má sì gbàgbé pé gbogbo wa ló fi Ọmọ rẹ̀ rà pa dà, títí kan ọmọ rẹ, Ọlọ́run ò sì fẹ́ kí ẹnikẹ́ni ṣègbé. (Ka 2 Pétérù 3:9.) Torí náà, gbà pé ìbáwí àti ìtọ́sọ́nà Jèhófà ló dáa jù. Kódà, tí ìbáwí náà bá tiẹ̀ kó ẹ̀dùn ọkàn bá ìwọ òbí ọmọ náà, ohun tí Jèhófà fẹ́ ni kó o ṣe. Má kọ ìbáwí Jèhófà sílẹ̀, ṣe ni kó o tẹ́wọ́ gbà á.

ÌBÁWÍ NÍNÚ ÌJỌ

14. Báwo làwọn ìtọ́ni tí Jèhófà ń fún wa nípasẹ̀ “olóòótọ́ ìríjú náà” ṣe ń ṣe wá láǹfààní?

14 Jèhófà ti ṣèlérí pé òun máa bójú tó ìjọ òun, òun máa dáàbò bò ó, òun á sì máa kọ́ ọ. Ọ̀pọ̀ ọ̀nà ló sì ń gbà ṣe bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Jésù Ọmọ rẹ̀ ló ní kó máa darí ìjọ, Jésù náà sì ti yan “olóòótọ́ ìríjú” kan táá máa pèsè oúnjẹ tẹ̀mí lákòókò tó bẹ́tọ̀ọ́ mu. (Lúùkù 12:42) À ń rí ìtọ́ni àti ìbáwí látinú àwọn oúnjẹ tẹ̀mí tí wọ́n ń pèsè fún wa. Torí náà, bi ara rẹ pé, ‘Ṣé àwọn àsọyé tá à ń gbọ́ nípàdé àtàwọn àpilẹ̀kọ inú àwọn ìtẹ̀jáde wa máa ń mú kí n ṣe àwọn àyípadà tó yẹ nínú ìwà mi àti bí mo ṣe ń ronú?’ Tó bá rí bẹ́ẹ̀, a bá ẹ yọ̀! Ìyẹn túmọ̀ sí pé ò ń jẹ́ kí Jèhófà mọ ẹ́, kó sì bá ẹ wí kó o lè ṣe ara rẹ láǹfààní.​—Òwe 2:​1-5.

15, 16. (a) Báwo la ṣe lè jàǹfààní látinú ohun táwọn “ẹ̀bùn [tí ó jẹ́] ènìyàn” ń ṣe? (b) Báwo la ṣe lè mú kí iṣẹ́ àwọn alàgbà túbọ̀ rọrùn?

15 Jésù tún pèsè àwọn “ẹ̀bùn [tí ó jẹ́] ènìyàn” fún ìjọ, ìyẹn àwọn alàgbà kí wọ́n lè máa bójú tó agbo Ọlọ́run. (Éfé. 4:​8, 11-13) Báwo la ṣe lè jàǹfààní látinú ohun táwọn alàgbà yìí ń ṣe? Ọ̀nà kan tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ká máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ wọn, ká sì máa fara wé àwọn àpẹẹrẹ dáadáa tí wọ́n ń fi lélẹ̀. Ọ̀nà míì ni pé, tí wọ́n bá gbà wá nímọ̀ràn látinú Bíbélì, ká ṣe ohun tí wọ́n sọ. (Ka Hébérù 13:​7, 17.) Ẹ máa rántí pé àwọn alàgbà nífẹ̀ẹ́ wa, wọ́n sì fẹ́ ká túbọ̀ ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, tí wọ́n bá kíyè sí pé à ń pa ìpàdé jẹ tàbí pé ìtara tá a ní ti ń dín kù, ó dájú pé wọ́n á tètè wá bí wọ́n á ṣe ràn wá lọ́wọ́. Wọ́n máa tẹ́tí sí wa, wọ́n á sì fún wa níṣìírí àti ìmọ̀ràn látinú Ìwé Mímọ́. Tí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀ fún ẹ, ṣé wàá gbà pé ọ̀nà kan tí Jèhófà ń gbà fìfẹ́ hàn sí ẹ nìyẹn?

16 Ẹ má gbàgbé pé ó lè má fi bẹ́ẹ̀ rọrùn fáwọn alàgbà láti wá sọ ibi tá a kù sí fún wa. Bí àpẹẹrẹ, ẹ wo bó ṣe máa ṣòro tó fún wòlíì Nátánì láti lọ bá Ọba Dáfídì sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ṣẹ̀ tó dá tó sì fẹ́ bò mọ́lẹ̀. (2 Sám. 12:​1-14) Yàtọ̀ síyẹn, nígbà kan tí Pétérù tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àpọ́sítélì méjìlá ń ṣe ojúsàájú sáwọn tí kì í ṣe Júù, ó dájú pé ìgboyà gidi ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lò nígbà tó fẹ́ tún ojú ìwòye rẹ̀ ṣe. (Gál. 2:​11-14) Torí náà, kí lo lè ṣe táá jẹ́ kí iṣẹ́ àwọn alàgbà tó wà níjọ yín rọrùn? Jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, jẹ́ ẹni tó ṣeé sún mọ́, kó o sì jẹ́ ẹni tó ń moore. Tí wọ́n bá pe àfiyèsí ẹ sáwọn nǹkan kan, gbà pé ṣe ni Jèhófà ń tipa bẹ́ẹ̀ fìfẹ́ hàn sí ẹ. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá jàǹfààní, àwọn alàgbà náà á sì túbọ̀ gbádùn iṣẹ́ wọn.

17. Báwo làwọn alàgbà ṣe ran arábìnrin kan lọ́wọ́?

17 Ó ṣòro fún arábìnrin kan láti tún nífẹ̀ẹ́ Jèhófà torí àwọn nǹkan tó ti ṣe sẹ́yìn. Ó sọ pé. “Nígbàkigbà tí mo bá ro àròkàn nípa àwọn nǹkan tí mo ti ṣe sẹ́yìn, mo mọ̀ pé àwọn alàgbà lè tù mí nínú, mo sì máa ń lọ bá wọn sọ̀rọ̀. Wọn kì í kàn mí lábùkù tàbí bẹnu àtẹ́ lù mí, kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe ni wọ́n ń gbé mi ró tí wọ́n sì ń fún mi lókun. Kò sí bí ọwọ́ àwọn alàgbà ṣe dí tó, tá a bá parí ìpàdé ó kéré tán ọ̀kan lára wọn máa wá béèrè àlàáfíà mi. Ṣe ló máa ń ṣe mí bíi pé Ọlọ́run ò lè nífẹ̀ẹ́ mi torí àwọn nǹkan tí mo ti ṣe sẹ́yìn. Léraléra ni Jèhófà ti lo àwọn ará inú ìjọ àtàwọn alàgbà láti jẹ́ kí n mọ̀ pé òun nífẹ̀ẹ́ mi gan-an. Mo gbà á ládùúrà pé kí n má fi Jèhófà sílẹ̀ láé.”

KÍ LÓ BURÚ JU Ẹ̀DÙN ỌKÀN TÍ ÌBÁWÍ MÁA Ń MÚ WÁ?

18, 19. Kí ló burú ju ẹ̀dùn ọkàn tí ìbáwí máa ń mú wá? Ṣàlàyé.

18 Òótọ́ ni pé ìbáwí máa ń dunni, àmọ́ téèyàn ò bá gba ìbáwí, ohun tó máa ń yọrí sí máa ń burú jùyẹn lọ. (Héb. 12:11) Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Kéènì àti Ọba Sedekáyà. Nígbà tí Kéènì kórìíra Ébẹ́lì débi pé ó ń ronú bó ṣe máa pa á, Ọlọ́run gbà á níyànjú pé: “Èé ṣe tí ìbínú rẹ fi gbóná, èé sì ti ṣe tí ojú rẹ fi rẹ̀wẹ̀sì? Bí ìwọ bá yíjú sí ṣíṣe rere, ara rẹ kò ha ní yá gágá bí? Ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá yíjú sí ṣíṣe rere, ẹ̀ṣẹ̀ lúgọ sí ẹnu ọ̀nà, ìfàsí-ọkàn rẹ̀ sì wà fún ọ; ní tìrẹ, ìwọ yóò ha sì kápá rẹ̀ bí?” (Jẹ́n. 4:​6, 7) Kéènì ò tẹ́tí sí Jèhófà, ó kó sínú ẹ̀ṣẹ̀ náà, jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀ ló sì fi jìyà ohun tó ṣe yẹn. (Jẹ́n. 4:​11, 12) Ká sọ pé ó gba ìbáwí tí Jèhófà fun un ni, kò bá má jìyà tóyẹn.

19 Ìgbà tí nǹkan burú gan-an ní Jerúsálẹ́mù ni Ọba Sedekáyà ṣàkóso. Dọ̀bọ̀sìyẹsà ni Ọba Sedekáyà, ó sì burú. Léraléra ni wòlíì Jeremáyà ń rọ Sedekáyà pé kó yí pa dà kúrò nínú àwọn ohun burúkú tó ń ṣe, àmọ́ ṣe ló kọ etí ikún, kò sì gba ìbáwí. Ohun tíyẹn yọrí sí ò dáa rárá torí ṣe ló kan ìdin nínú iyọ̀. (Jer. 52:​8-11) Ẹ ò rí bí Jèhófà ṣe ń kọ́ wa ká má bàa kàgbákò bíi tàwọn tá a sọ tán yìí!​—Ka Aísáyà 48:​17, 18.

20. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sáwọn tí kò gba ìbáwí Jèhófà, ìbùkún wo sì làwọn tó ń gba ìbáwí Jèhófà máa rí?

20 Nínú ayé lónìí, àwọn èèyàn kì í fẹ́ gba ìbáwí wọn ò sì ní ìkóra-ẹni-níjàánu. Àmọ́ láìpẹ́, gbogbo àwọn èèyàn burúkú ló máa jèrè iṣẹ́ ọwọ́ wọn torí àṣegbé kan ò sí, àṣepamọ́ ló wà. (Òwe 1:​24-31) Torí náà, ẹ jẹ́ ká ‘fetí sí ìbáwí ká lè di ọlọ́gbọ́n.’ Òwe 4:13 gbà wá nímọ̀ràn pé: “Di ìbáwí mú; má ṣe jẹ́ kí ó lọ. Fi ìṣọ́ ṣọ́ ọ, nítorí òun ni ìwàláàyè rẹ.”