Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìrìbọmi​—Ohun Tó Yẹ Kí Gbogbo Kristẹni Ṣe

Ìrìbọmi​—Ohun Tó Yẹ Kí Gbogbo Kristẹni Ṣe

“Èyí ni ó ń gbà yín là nísinsìnyí pẹ̀lú, èyíinì ni, ìbatisí.”​1 PÉT. 3:21.

ORIN: 52, 41

1, 2. (a) Àwọn ìbéèrè wo làwọn òbí máa ń bi ara wọn táwọn ọmọ wọn bá sọ pé àwọn fẹ́ ṣèrìbọmi? (b) Kí nìdí tí wọ́n fi máa ń béèrè lọ́wọ́ àwọn tó fẹ́ ṣèrìbọmi bóyá wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

ÀWỌN òbí ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Maria ń wò ó bí òun àtàwọn míì tí wọ́n jọ fẹ́ ṣèrìbọmi ṣe dìde dúró. Ojú wọn ò kúrò lára rẹ̀ bó ṣe ń dáhùn àwọn ìbéèrè méjì tí alásọyé ń béèrè lọ́wọ́ àwọn tó fẹ́ ṣèrìbọmi. Lẹ́yìn ìyẹn, Maria ṣèrìbọmi.

2 Inú àwọn òbí Maria dùn gan-an torí pé ọmọ wọn ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà, ó sì fẹ́ ṣèrìbọmi. Síbẹ̀, ìyá rẹ̀ láwọn ìbéèrè kan tó ń jẹ ẹ́ lọ́kàn. Bí àpẹẹrẹ, ó máa ń bi ara rẹ̀ pé: ‘Ṣé Maria ò kéré jù láti ṣèrìbọmi báyìí? Ṣé ó mọ ìjẹ́pàtàkì ohun tó fẹ́ ṣe yìí? Ǹjẹ́ kò ní dáa kó dàgbà ju báyìí lọ kó tó ṣèrìbọmi?’ Àwọn ìbéèrè yìí wà lára ìbéèrè táwọn òbí máa ń bi ara wọn táwọn ọmọ wọn bá láwọn fẹ́ ṣèrìbọmi. (Oníw. 5:5) Ó ṣe tán, ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi ni ìgbésẹ̀ tó ṣe pàtàkì jù nígbèésí ayé àwa Kristẹni.​—Wo àpótí náà “ Ṣé O Ti Ya Ara Rẹ Sí Mímọ́ fún Jèhófà?

3, 4. (a) Báwo ni Pétérù ṣe jẹ́ ká mọ bí ìrìbọmi ti ṣe pàtàkì tó? (b) Kí nìdí tá a fi lè fi ìrìbọmi wé bí Nóà ṣe kan ọkọ̀ áàkì?

3 Nígbà tí àpọ́sítélì Pétérù ń sọ̀rọ̀ nípa ìrìbọmi, ó tọ́ka sí bí Nóà ṣe kan ọkọ̀ áàkì. Ó ní: “Èyíinì tí ó ṣe rẹ́gí pẹ̀lú èyí ni ó ń gbà yín là nísinsìnyí pẹ̀lú, èyíinì ni, ìbatisí.” (Ka 1 Pétérù 3:​20, 21.) Áàkì tí Nóà kàn mú kó ṣe kedere sáwọn èèyàn pé ìfẹ́ Ọlọ́run ni Nóà fi ìgbésí ayé rẹ̀ ṣe. Nóà fi tọkàntọkàn ṣe iṣẹ́ tí Jèhófà gbé fún un. Àwọn ohun tí Nóà ṣe fi hàn pé ó ní ìgbàgbọ́, ìyẹn sì jẹ́ kóun àti ìdílé rẹ̀ rí ìgbàlà. Kí wá ni Pétérù fẹ́ ká mọ̀?

4 Áàkì yẹn jẹ́ ẹ̀rí tó ṣeé fojú rí pé Nóà nígbàgbọ́ nínú Jèhófà. Lọ́nà kan náà, ìrìbọmi jẹ́ ẹ̀rí tó ṣeé fojú rí pé ẹnì kan ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà torí ìgbàgbọ́ tó ní nínú Jésù Kristi. Bíi ti Nóà, àwọn tó ya ara wọn sí mímọ́ máa ń ṣe iṣẹ́ tí Jèhófà gbé fún wọn. Bí Jèhófà ṣe dá ẹ̀mí Nóà sí nígbà Ìkún Omi, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe máa dáàbò bo ẹni tó ṣèrìbọmi tó sì jẹ́ adúróṣinṣin nígbà ìparun ayé búburú yìí. (Máàkù 13:10; Ìṣí. 7:​9, 10) Èyí mú kó ṣe kedere pé ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi ṣe pàtàkì gan-an. Torí náà, tẹ́nì kan bá lọ ń fòní dónìí, fọ̀la dọ́la lórí ìrìbọmi láìnídìí, ìyè àìnípẹ̀kun rẹ̀ ló ń fi ṣeré yẹn!

5. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

5 Ní báyìí tó ti ṣe kedere pé ìrìbọmi ṣe pàtàkì gan-an, ẹ jẹ́ ká wá ìdáhùn sáwọn ìbéèrè mẹ́ta yìí. Kí ni Bíbélì sọ nípa ìrìbọmi? Àwọn nǹkan wo lẹnì kan gbọ́dọ̀ ṣe kó tó lè ṣèrìbọmi? Tí Kristẹni kan bá ń kọ́ ẹnì kan tàbí ọmọ rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kí nìdí tó fi yẹ kó máa rántí pé ìrìbọmi ṣe pàtàkì?

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ NÍPA ÌRÌBỌMI

6, 7. (a) Kí nìdí tí Jòhánù fi ṣèrìbọmi fáwọn èèyàn? (b) Ìrìbọmi tó ṣàrà ọ̀tọ̀ wo ni Jòhánù ṣe? Kí nìdí tó fi ṣàrà ọ̀tọ̀?

6 Ìrìbọmi àkọ́kọ́ tí Bíbélì mẹ́nu kàn lèyí tí Jòhánù Oníbatisí ṣe fáwọn èèyàn. (Mát. 3:​1-6) Ìdí táwọn èèyàn sì fi wá ṣèrìbọmi ni pé wọ́n fẹ́ fi hàn pé àwọn ti ronú pìwà dà ẹ̀ṣẹ̀ táwọn dá lòdì sí Òfin Mósè. Àmọ́, ìrìbọmi kan wà tí Jòhánù ṣe tó gba àfíyèsí tó sì ṣàrà ọ̀tọ̀, ìyẹn ìrìbọmi tó ṣe fún Jésù, Ọmọ Ọlọ́run. (Mát. 3:​13-17) Ẹni pípé ni Jésù, kò dá ẹ̀ṣẹ̀ kankan, kò sì nílò ìrònúpìwàdà. (1 Pét. 2:22) Torí náà, ṣe ni ìrìbọmi rẹ̀ fi hàn pé ó ti ṣe tán láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run.​—Héb. 10:7.

7 Lásìkò tí Jésù ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ náà ṣèrìbọmi fáwọn èèyàn. (Jòh. 3:22; 4:​1, 2) Bíi ti ìrìbọmi tí Jòhánù ṣe, ìrìbọmi táwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ṣe fáwọn èèyàn jẹ́ ẹ̀rí pé àwọn èèyàn náà ti ronú pìwà dà ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá lòdì sí Òfin Mósè. Àmọ́ lẹ́yìn tí Jésù kú tó sì jíǹde, ìdí táwọn tó fẹ́ di ọmọlẹ́yìn Jésù fi máa ṣèrìbọmi á yàtọ̀ síyẹn.

8. (a) Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, àṣẹ wo ló pa fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀? (b) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kẹ́ni tó bá máa di Kristẹni ṣèrìbọmi?

8 Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde lọ́dún 33 Sànmánì Kristẹni, ó fara han àwọn èèyàn tó lé ní ọgọ́rùn-ún márùn-ún [500] lọ́kùnrin àti lóbìnrin, kódà ó ṣeé ṣe káwọn ọmọdé náà wà níbẹ̀. Ó lè jẹ́ ìgbà yẹn ló sọ pé: “Nítorí náà, ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́, ẹ máa kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun tí mo ti pa láṣẹ fún yín mọ́.” (Mát. 28:​19, 20; 1 Kọ́r. 15:6) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn ọmọlẹ́yìn ló wà níbẹ̀ nígbà tí Jésù pàṣẹ pé kí wọ́n máa sọ àwọn míì di ọmọ ẹ̀yìn. Jésù fi hàn pé ó ṣe pàtàkì kí gbogbo àwọn tó bá máa di Kristẹni ṣèrìbọmi. (Mát. 11:​29, 30) Ẹni tó bá máa jọ́sìn Ọlọ́run lọ́nà tó tọ́ gbọ́dọ̀ gbà pé Jésù ni Jèhófà ń lò láti mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ, ẹ̀yìn ìyẹn lonítọ̀hún lè ṣèrìbọmi. Irú ìrìbọmi yìí nìkan ni Jèhófà fọwọ́ sí. Àkọsílẹ̀ Bíbélì fi hàn pé àwọn tó di ọmọlẹ́yìn Jésù ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní mọ bó ti ṣe pàtàkì tó pé káwọn ṣèrìbọmi. Torí náà, wọn ò fi ìrìbọmi falẹ̀ rárá.​—Ìṣe 2:41; 9:18; 16:​14, 15, 32, 33.

MÁ FI FALẸ̀

9, 10. Kí la rí kọ́ látinú ìrìbọmi tí ọkùnrin ará Etiópíà kan ṣe àti èyí tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe?

9 Ka Ìṣe 8:​35, 36Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ ọkùnrin ará Etiópíà kan tó jẹ́ onísìn Júù. Lẹ́yìn tó jọ́sìn tán ní Jerúsálẹ́mù, ohun kan ṣẹlẹ̀ sí i nígbà tó ń pa dà sí ìlú rẹ̀. Áńgẹ́lì Jèhófà ní kí Fílípì lọ “polongo ìhìn rere nípa Jésù” fún ọkùnrin náà. Kí ni ọkùnrin náà wá ṣe? Torí pé ohun tó kọ́ yé e dáadáa tó sì mọyì rẹ̀, kíá ló sọ pé kí wọ́n ṣèrìbọmi fún òun. Ìyẹn fi hàn pé ó múra tán láti ṣe ohun tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu.

10 Àpẹẹrẹ kejì ni ti ọkùnrin Júù kan tó ti máa ń ṣenúnibíni sáwọn Kristẹni. Orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì tí Ọlọ́run yà sí mímọ́ fún ara rẹ̀ ni wọ́n bí i sí. Àmọ́ nígbà tó yá, àwọn Júù pàdánù àjọṣe wọn pẹ̀lú Jèhófà. Ọkùnrin tá à ń wí yìí nítara gan-an fún ìsìn àwọn Júù, àmọ́ nǹkan máa tó yé e. Jésù Kristi tó ti wà lọ́run ló wàásù fún un. Kí lọkùnrin náà wá ṣe? Ó gbà kí Ananíà tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù ran òun lọ́wọ́. Nígbà tí Bíbélì ń ròyìn ohun tí ọkùnrin náà ṣe, ó ní: “Ó dìde, a sì batisí rẹ̀.” (Ìṣe 9:​17, 18; Gál. 1:14) Ó dájú pé ẹ mọ ẹni tá à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀, àbí? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ni. Àmọ́ ṣé ẹ rántí ohun tó ṣe ní gbàrà tó lóye ipa tí Jésù kó láti mú ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ? Kíá ló ṣèrìbọmi.​—Ka Ìṣe 22:​12-16.

11. (a) Kí ló máa ń mú káwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣèrìbọmi? (b) Báwo ló ṣe máa ń rí lára wa táwọn ẹni tuntun bá ṣèrìbọmi?

11 Irú ìgbésẹ̀ táwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lónìí máa ń gbé nìyẹn, yálà wọ́n jẹ́ ọmọdé tàbí àgbà. Tí òtítọ́ Bíbélì bá yé ẹnì kan dáadáa tó sì nígbàgbọ́, ó máa yá a lára láti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ kó sì ṣèrìbọmi. Láwọn àpéjọ àyíká àtàwọn àpéjọ àgbègbè wa, a máa ń fojú sọ́nà fún àsọyé tí wọ́n dìídì ṣètò fáwọn tó fẹ́ ṣèrìbọmi. Inú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń dùn tẹ́ni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bá nífẹ̀ẹ́ òtítọ́, tó tẹ̀ síwájú, tó sì ṣèrìbọmi. Ẹ̀yin òbí, ǹjẹ́ inú yín kì í dùn tẹ́ ẹ bá ń wo ọmọ yín láàárín àwọn tó fẹ́ ṣèrìbọmi? Lọ́dún iṣẹ́ ìsìn 2017, àwọn tó ní “ìtẹ̀sí-ọkàn títọ́” tí wọ́n sì ṣèrìbọmi láti fi hàn pé àwọn ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún méjì àti mẹ́rìnlélọ́gọ́rin [284,000]. (Ìṣe 13:48) Kò sí àní-àní pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn tuntun yẹn mọ̀ pé ó yẹ káwọn ṣèrìbọmi káwọn tó lè di Kristẹni. Àwọn nǹkan wo ni wọ́n ṣe kí wọ́n tó ṣèrìbọmi?

12. Àwọn nǹkan wo lẹni tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì gbọ́dọ̀ ṣe kó tó lè ṣèrìbọmi?

12 Kí ẹnì kan tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó lè ṣèrìbọmi, ó gbọ́dọ̀ gbé àwọn ìgbésẹ̀ pàtàkì kan. Ó gbọ́dọ̀ ní ìmọ̀ tó péye nípa Ọlọ́run, ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe fún aráyé àtohun tí Ọlọ́run ti ṣe láti gba aráyé là, ìmọ̀ tó ní yìí ló máa jẹ́ kó ní ìgbàgbọ́. (1 Tím. 2:​3-6) Ìgbàgbọ́ tó ní máa jẹ́ kó jáwọ́ nínú àwọn ìwà tí inú Ọlọ́run ò dùn sí, á sì máa ṣe àwọn nǹkan tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu. (Ìṣe 3:19) Ó ṣe kedere pé bí ẹnì kan bá ṣì ń lọ́wọ́ sáwọn ìwà tó lè mú kéèyàn pàdánù Ìjọba Ọlọ́run, kò lè sọ pé òun ti ya ara òun sí mímọ́. (1 Kọ́r. 6:​9, 10) Yàtọ̀ sí pé kéèyàn jáwọ́ nínú àwọn nǹkan tí inú Jèhófà ò dùn sí, ó tún yẹ kẹ́ni tó fẹ́ ṣèrìbọmi máa wá sípàdé déédéé, kó máa wàásù, kó sì máa sọ àwọn èèyàn di ọmọlẹ́yìn, torí Jésù sọ pé iṣẹ́ táwọn ọmọlẹ́yìn òun á máa ṣe nìyẹn. (Ìṣe 1:8) Ẹ̀yìn ìgbà yẹn ló tó lè ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà nínú àdúrà, kó sì wá ṣèrìbọmi.

OHUN TÓ YẸ KẸ́NI TÓ Ń KẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ ṢE

Ṣé o máa ń rántí ìdí tí ìrìbọmi fi ṣe pàtàkì, ṣé o sì máa ń jẹ́ káwọn tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mọ ìdí tó fi ṣe pàtàkì? (Wo ìpínrọ̀ 13)

13. Kí nìdí tó fi yẹ kẹ́ni tó ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì máa fi sọ́kàn pé ó ṣe pàtàkì kéèyàn ṣèrìbọmi kó tó di Kristẹni tòótọ́?

13 Bá a ṣe ń ran àwọn ọmọ wa àtàwọn míì tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ láti gbé àwọn ìgbésẹ̀ pàtàkì yìí, kò yẹ ká gbàgbé pé ó dìgbà tí wọ́n bá ṣèrìbọmi kí wọ́n tó di Kristẹni tòótọ́. Ìyẹn máa jẹ́ kó rọrùn fún wa láti jẹ́ kí wọ́n mọ bí ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi ti ṣe pàtàkì tó, àá sì mọ àsìkò tó yẹ ká bá wọn sọ ọ́. Ohun tó yẹ ká ṣe nìyẹn torí gbogbo wa la fẹ́ káwọn ọmọ wa àtàwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣèrìbọmi.

14. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká fipá mú ẹnikẹ́ni láti ṣèrìbọmi?

14 Kò yẹ ká máa fipá mú àwọn ọmọ wa, àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ tàbí àwọn míì nínú ìjọ pé kí wọ́n ṣèrìbọmi, ìdí sì ni pé Jèhófà kì í fipá mú ẹnikẹ́ni láti wá sin òun. (1 Jòh. 4:8) Dípò ìyẹn, ṣe ni ká jẹ́ kí wọ́n mọ ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí wọ́n ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. Tí wọ́n bá lóye ohun tí wọ́n kọ́, tí wọ́n sì ṣe tán láti ṣe ohun tí Ọlọ́run ní káwọn Kristẹni máa ṣe, ìyẹn máa jẹ́ kó wù wọ́n láti ṣèrìbọmi.​—2 Kọ́r. 5:​14, 15.

15, 16. (a) Ṣé èèyàn gbọ́dọ̀ pé iye ọdún kan pàtó kó tó lè ṣèrìbọmi? Ṣàlàyé. (b) Kí nìdí tó fi yẹ kẹ́ni tó ti ṣèrìbọmi nínú ẹ̀sìn tó ń ṣe tẹ́lẹ̀ tún ṣèrìbọmi lẹ́yìn tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́?

15 Bíbélì ò sọ pé èèyàn gbọ́dọ̀ pé iye ọdún kan pàtó kó tó lè ṣèrìbọmi. Àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yàtọ̀ síra, ìtẹ̀síwájú wọn ò sì lè dọ́gba. Àwọn kan lè ṣèrìbọmi nígbà tí wọ́n ṣì kéré, kí wọ́n sì máa fòótọ́ sin Jèhófà nìṣó. Àwọn míì á sì ti dàgbà kódà wọ́n lè ti lé lẹ́ni ọgọ́rùn-ún [100] ọdún kí wọ́n tó ṣèrìbọmi.

16 Obìnrin àgbàlagbà kan béèrè lọ́wọ́ ẹni tó ń kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pé ṣé ó di dandan kóun tún ṣèrìbọmi. Ìdí tó fi béèrè ni pé ó ti ṣèrìbọmi nínú àwọn ẹ̀sìn tó ń ṣe tẹ́lẹ̀. Ẹni tó ń kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ jíròrò àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan pẹ̀lú rẹ̀, ó sì wá lóye ohun tí Bíbélì sọ. Kò pẹ́ sígbà yẹn ni obìnrin náà ṣèrìbọmi. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pé ẹni ọgọ́rin [80] ọdún, ó mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì pé kóun ṣèrìbọmi. Ìwé Mímọ́ jẹ́ ká mọ̀ pé kéèyàn tó ṣèrìbọmi, ó gbọ́dọ̀ ní ìmọ̀ tó péye nípa Jèhófà àtohun tó fẹ́ ṣe. Torí náà, àwọn ẹni tuntun gbọ́dọ̀ ṣèrìbọmi kódà tí wọ́n bá ti ṣe bẹ́ẹ̀ nínú ẹ̀sìn tí wọ́n ń ṣe tẹ́lẹ̀.​—Ka Ìṣe 19:​3-5.

17. Kí ló yẹ kẹ́nì kan ronú lé lọ́jọ́ tó bá ṣèrìbọmi?

17 Kò sí àní-àní pé ọjọ́ ayọ̀ lọjọ́ ìrìbọmi, síbẹ̀ ó tún yẹ kẹ́ni tó ṣèrìbọmi ronú lórí ohun tí ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi tó ṣe túmọ̀ sí. Ó máa gba ìsapá ká tó lè ṣe ohun tí Jèhófà ní ká ṣe. Ìdí nìyẹn tí Jésù fi sọ pé àwọn ọmọlẹ́yìn òun gbọ́dọ̀ gba àjàgà òun. Àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ò gbọ́dọ̀ “tún wà láàyè fún ara wọn mọ́, bí kò ṣe fún ẹni tí ó kú fún wọn, tí a sì gbé dìde.”​—2 Kọ́r. 5:15; Mát. 16:24.

18. Àwọn ìbéèrè wo la máa dáhùn nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?

18 Àwọn kókó tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ jíròrò tán yìí ni ìyá Maria ń rò nígbà tó ń béèrè àwọn ìbéèrè tá a mẹ́nu bà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí. Tó o bá jẹ́ òbí, ó ṣeé ṣe kó o máa ronú pé: ‘Ṣé lóòótọ́ lọmọ mi ti ṣe tán láti ṣèrìbọmi? Ṣé ó ti ní ìmọ̀ tó péye tó yẹ kéèyàn ní kó tó ya ara rẹ̀ sí mímọ́? Ṣó yẹ kí ọmọ mi lọ sílé ẹ̀kọ́ gíga kó sì níṣẹ́ gidi lọ́wọ́ kó tó ṣèrìbọmi? Tọ́mọ mi bá ṣàṣìṣe lẹ́yìn tó ti ṣèrìbọmi ńkọ́?’ A máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a sì tún máa jíròrò bí àwọn òbí ṣe lè ní èrò tó tọ́ nípa ìrìbọmi.