Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

Jèhófà Ò Já Mi Kulẹ̀ Rí

Jèhófà Ò Já Mi Kulẹ̀ Rí

Nígbà kan tí Adolf Hitler wá bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀, mo wà lára àwọn mẹ́rin tí wọ́n yàn pé kó fún un ní òdòdó. Kí nìdí tí wọ́n fi yàn mí? Ìdí ni pé bàbá mi wà nínú ẹgbẹ́ òṣèlú Násì, àwọn sì ni awakọ̀ fún olórí ẹgbẹ́ òṣèlú náà lágbègbè yẹn. Kátólíìkì ni màmá mi, wọ́n sì fẹ́ràn ẹ̀sìn náà gan-an, torí náà wọ́n fẹ́ kí n di ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé, bàbá mi sì fẹ́ kí n dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú Násì. Àmọ́, kò sí èyí tí mo ṣe nínú méjèèjì. Ẹ jẹ́ kí n sọ ìdí tọ́rọ̀ fi rí bẹ́ẹ̀.

ÌLÚ Graz lórílẹ̀-èdè Austria ni wọ́n ti tọ́ mi dàgbà. Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún méje, wọ́n mú mi lọ sílé ìwé tí wọ́n ti ń kọ́ni nípa ẹ̀sìn. Àmọ́, ìṣekúṣe táwọn àlùfáà àtàwọn obìnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé ń bá ara wọn ṣe ò ṣe é fẹnu sọ. Torí náà, mi ò lò tó ọdún kan tí màmá mi fi mú mi kúrò níbẹ̀.

Fọ́tò ìdílé wa rèé níbi tí bàbá mi ti wọṣọ ológun

Nígbà tó yá, wọ́n mú mi lọ síléèwé kan, ibẹ̀ ni mo sì ń gbé. Lálẹ́ ọjọ́ kan, bàbá mi wá mú mi kúrò nílé ìwé torí pé wọ́n ti ń rọ̀jò bọ́ǹbù sílùú Graz. Ìlú Schladming la sá lọ. Àmọ́ bá a ṣe sọdá afárá kan tán báyìí ni wọ́n ju bọ́ǹbù sórí afárá náà. Kódà ìgbà kan tiẹ̀ wà tó ku díẹ̀ kí ìbọn ba èmi àti ìyá mi àgbà nínú ọgbà ilé wa. Nígbà tí ogun yẹn parí, a wá rí i pé ṣọ́ọ̀ṣì àti ìjọba ti já wa kulẹ̀.

MO KẸ́KỌ̀Ọ́ ÒTÍTỌ́

Nígbà tó fi máa dọdún 1950, obìnrin Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ màmá mi lẹ́kọ̀ọ́. Mo máa ń tẹ́tí sílẹ̀ tí wọ́n bá ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́, mo sì máa ń tẹ̀ lé màmá mi lọ sípàdé. Ó dá wọn lójú pé òtítọ́ Bíbélì làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kọ́, torí náà màmá mi ṣèrìbọmi lọ́dún 1952.

Lójú mi, ṣe ni ìjọ tá à ń dara pọ̀ mọ́ nígbà yẹn dà bí ìjọ àwọn arúgbó torí àwọn ìyá arúgbó ló pọ̀ jù níbẹ̀. Nígbà tó yá, a lọ ṣèpàdé níjọ míì, àmọ́ ìjọ yẹn ò jọ ìjọ àwọn arúgbó torí àwọn ọ̀dọ́ ló pọ̀ jù níbẹ̀. Nígbà tá a pa dà sí ìlú Graz, mo bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí gbogbo ìpàdé, kò sì pẹ́ rárá tí mo fi mọ̀ pé òtítọ́ ni mò ń kọ́. Yàtọ̀ síyẹn, mo tún wá mọ̀ pé Jèhófà Ọlọ́run kì í já àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ kulẹ̀. Kódà láwọn ìgbà tá a kojú ìṣòro tó le gan-an, kò fi wá sílẹ̀.​—Sm. 3:​5, 6.

Ó wù mí gan-an pé kí n sọ òtítọ́ yìí fáwọn míì. Ọ̀dọ̀ àwọn ẹ̀gbọ́n mi àtàbúrò mi sì ni mo ti bẹ̀rẹ̀. Nígbà yẹn, àwọn ẹ̀gbọ́n mi obìnrin mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ti kúrò nílé lọ ṣiṣẹ́ olùkọ́ láwọn abúlé míì. Àmọ́ mo wá wọn lọ sáwọn abúlé yẹn torí mo fẹ́ kí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Inú mi dùn pé gbogbo àwọn ẹ̀gbọ́n mi àtàbúrò mi ló kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wọ́n sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Ní ọ̀sẹ̀ kejì tí mo bẹ̀rẹ̀ ìwàásù ilé-dé-ilé, mo pàdé obìnrin kan tó ti lé lẹ́ni ọgbọ̀n ọdún, ó sì gbà kí n máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ tẹ̀ síwájú débi pé ó ṣèrìbọmi, nígbà tó sì yá, ọkọ rẹ̀ àtàwọn ọmọkùnrin rẹ̀ méjèèjì náà ṣèrìbọmi. Ìkẹ́kọ̀ọ́ yẹn mú kí ìgbàgbọ́ tèmi náà lágbára gan-an. Ìdí ni pé kò sẹ́ni tó jókòó kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Torí náà, kí n tó lọ ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ yẹn, màá kọ́kọ́ múra sílẹ̀ dáadáa, kí n lè kọ́ ara mi kí n tó lọ kọ́ àwọn míì. Èyí mú kí n túbọ̀ mọyì òtítọ́. Ní April 1954, mo ya ara mi sí mímọ́, mo sì ṣèrìbọmi.

“A ṢE INÚNIBÍNI SÍ WA, ṢÙGBỌ́N A KÒ FI WÁ SÍLẸ̀”

Lọ́dún 1955, mo lọ sáwọn àpéjọ àgbáyé tá a ṣe ní ilẹ̀ Jámánì, Faransé àti England. Nígbà tí mo wà nílùú London, mo pàdé Arákùnrin Albert Schroeder tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì, tó sì di ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí nígbà tó yá. Nígbà tá à ń rìn yíká ibi ìkóhun ìṣẹ̀ǹbáyé sí ti British Museum, Arákùnrin Schroeder fi àwọn Bíbélì àtijọ́ tí wọ́n fọwọ́ kọ hàn wá. A rí orúkọ Ọlọ́run tí wọ́n kọ lédè Hébérù, Arákùnrin Schroeder sì ṣàlàyé bí àwọn ìwé àfọwọ́kọ yẹn ti ṣe pàtàkì tó fún wa. Ọ̀rọ̀ yẹn wọ̀ mí lọ́kàn gan-an, ó sì mú kí n túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Mo wá pinnu pé gbogbo ohun tí n bá lè ṣe ni màá ṣe kí n lè kéde òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì fáwọn èèyàn.

Èmi rèé lápá òsì pẹ̀lú arábìnrin tá a jọ ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe ní Mistelbach, Austria

Mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà ní January 1, 1956. Oṣù mẹ́rin lẹ́yìn náà, ètò Ọlọ́run sọ mí di aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe, wọ́n sì rán mi lọ sórílẹ̀-èdè Austria. Nígbà yẹn, kò sí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kankan nílùú Mistelbach tí wọ́n rán mi lọ. Àmọ́ nǹkan kan wà tó kọ́kọ́ ṣòro fún mi. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo nǹkan lèmi àti arábìnrin tí wọ́n rán lọ síbẹ̀ fi yàtọ̀ síra. Bí àpẹẹrẹ, mo ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pé ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19], ìgboro sì ni mo ti wá, àmọ́ ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] ni arábìnrin yìí, abúlé ló sì ti wá. Èmi máa ń pẹ́ sùn, mo sì máa ń pẹ́ jí, àmọ́ òun máa ń fẹ́ tètè sùn, ó sì máa ń tètè jí. Láìka àwọn nǹkan yìí sí, àwa méjèèjì fi ìlànà Bíbélì sílò, èyí mú kí àjọgbé wa wọ̀, a sì gbádùn bá a ṣe jọ ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀.

Kí n sòótọ́, ojú wa rí tó níbẹ̀, kódà wọ́n ṣe inúnibíni sí wa, àmọ́ Jèhófà “kò fi wá sílẹ̀.” (2 Kọ́r. 4:​7-9) Mo rántí ọjọ́ kan tá à ń ṣiṣẹ́ lábúlé kan, ṣe làwọn tó wà níbẹ̀ tú àwọn ajá wọn sílẹ̀. Ká tó ṣẹ́jú pẹ́, àwọn ajá ńláńlá ti yí wa ká, wọ́n sì ń gbó burúkú-burúkú. Làwa méjèèjì bá di ọwọ́ ara wa mú, a sì ń gbàdúrà pé, “Jèhófà, táwọn ajá yìí bá ya wá jẹ, jọ̀ọ́ jẹ́ ká tètè kú!” Nígbà táwọn ajá yẹn sún mọ́ wa, wọ́n kàn ṣàdédé dúró, wọ́n wá ń ju ìrù wọn, wọ́n sì bá tiwọn lọ. A gbà pé Jèhófà ló dáàbò bò wá. Lẹ́yìn náà, a wàásù nínú abúlé yẹn, ó yà wá lẹ́nu pé àwọn tó wà níbẹ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ wa, èyí sì múnú wa dùn gan-an. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ẹnu yà wọ́n nígbà tí wọ́n rí i pé àwọn ajá yẹn ò bù wá jẹ, àti pé a ṣì ń wàásù lọ láìka ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn sí. Kódà àwọn kan lábúlé yẹn di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Nǹkan míì tún ṣẹlẹ̀ tó bà wá lẹ́rù gan-an. Lọ́jọ́ kan, bàbá onílé wa mutí yó, ló bá ń lérí pé òun máa pa wá torí pé à ń yọ àwọn ará àdúgbò lẹ́nu. Ìyàwó ẹ̀ tiẹ̀ gbìyànjú láti bá a sọ̀rọ̀, àmọ́ ṣe ló yarí. Gbogbo bó ṣe ń pariwo yẹn là ń gbọ́ láti yàrá wa lókè. La bá sáré fi àga dí ẹnu ọ̀nà yàrá wa, a sì bẹ̀rẹ̀ sí í kó ẹrù wa. Nígbà tá a yọjú lẹ́nu ọ̀nà, a rí ọ̀bẹ ńlá kan lọ́wọ́ bàbá onílé wa. Bá a ṣe sáré gbẹ̀yìn jáde nìyẹn pẹ̀lú gbogbo ẹrù wa, a ò sì pa dà sílé yẹn mọ́.

Lẹ́yìn ìyẹn, a lọ gba yàrá ní òtẹ́ẹ̀lì kan, a sì fẹ́rẹ̀ẹ́ lò tó ọdún kan níbẹ̀. Èyí mú kí iṣẹ́ ìwàásù wa túbọ̀ méso jáde. Lọ́nà wo? Ìdí ni pé àárín ìlú ni òtẹ́ẹ̀lì yẹn wà, àwọn kan tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sì fẹ́ ká máa ṣèkẹ́kọ̀ọ́ àwọn níbẹ̀. Kò pẹ́ sígbà yẹn la bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé ìjọ àti ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ nínú yàrá wa, àwọn bíi mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] ló sì ń dara pọ̀ mọ́ wa.

Ó lé lọ́dún kan tá a lò nílùú Mistelbach. Nígbà tó yá, ètò Ọlọ́run tún rán mi lọ sílùú Feldbach. Èmi àti arábìnrin míì ni wọ́n rán lọ síbẹ̀, bíi ti ìlú Mistelbach, kò sí ìjọ kankan nílùú Feldbach. Inú yàrá kékeré kan ní àjà kejì ilé onígi kan là ń gbé. Atẹ́gùn tó ń gba àárín igi náà wọlé máa ń yọ wá lẹ́nu, torí náà, a fi bébà dí àwọn àlàfo tó wà láàárín wọn. Yàtọ̀ síyẹn, ìdí kànga kan la ti máa ń pọnmi. Síbẹ̀ Jèhófà fèrè sí iṣẹ́ wa. Láàárín oṣù mélòó kan, a ti ní àwùjọ kan níbẹ̀. A tún kọ́ ìdílé kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àwọn bí ọgbọ̀n [30] látinú ìdílé yẹn sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Àwọn ìrírí yìí fún ìgbàgbọ́ mi lókun, ó sì jẹ́ kí n rí i pé téèyàn bá fi ire Ìjọba náà sípò àkọ́kọ́ láyé rẹ̀, Jèhófà kò ní fi í sílẹ̀. Kódà tó bá dà bíi pé kò sẹ́ni tá a lè yíjú sí, ká mọ̀ pé Jèhófà máa dúró tì wá.​—Sm. 121:​1-3.

JÈHÓFÀ FI “ỌWỌ́ Ọ̀TÚN ÒDODO” RẸ̀ DÌ WÁ MÚ

Ètò Ọlọ́run ṣètò àpéjọ àgbáyé kan lọ́dún 1958 ní Yankee Stadium àti ní Polo Grounds nílùú New York City. Mo wá kọ̀wé sí ẹ̀ka ọ́fíìsì ti Austria pé ó wù mí láti lọ, ẹ̀ka ọ́fíìsì wá bi mí bóyá màá fẹ́ lọ sí kíláàsì kejìlélọ́gbọ̀n [32] ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. Mi ò tiẹ̀ rò ó pé ẹ̀ẹ̀mejì rárá tí mo fi dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni!”

Ẹ̀gbẹ́ Arákùnrin Martin Poetzinger ni mo jókòó sí ní ilé ẹ̀kọ́ náà. Ojú tiẹ̀ náà rí màbo ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ìjọba Násì. Nígbà tó yá, òun náà di ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí. Nígbà míì tá a bá wà ní kíláàsì, Arákùnrin Martin máa bi mí kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ pé, “Erika, báwo la ṣe máa sọ̀rọ̀ yìí lédè Jámánì?”

Lẹ́yìn tá a lo oṣù díẹ̀ nílé ẹ̀kọ́ yẹn, Arákùnrin Nathan Knorr sọ ibi tí ètò Ọlọ́run máa rán wa lọ. Orílẹ̀-èdè Paraguay ni wọ́n rán mi lọ. Àmọ́ torí pé mo ṣì kéré, bàbá mi gbọ́dọ̀ fọwọ́ sí i kí n tó lè wọ orílẹ̀-èdè náà. Lẹ́yìn tí bàbá mi fọwọ́ sí i, mo lọ sí Paraguay ní March 1959. Ilé àwọn míṣọ́nnárì tó wà ní ìlú Asunción ni wọ́n ní kí n máa gbé, èmi àti arábìnrin kan là á sì jọ máa ṣiṣẹ́.

Kò pẹ́ sígbà yẹn ni mo pàdé Arákùnrin Walter Bright, míṣọ́nnárì lòun náà, kíláàsì ọgbọ̀n [30] ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì ló sì lọ. Nígbà tó yá, a ṣègbéyàwó, inú mi sì dùn pé mo rẹ́ni bí ọkàn mi. Tá a bá kojú ìṣòro kan tó le, àá ka ìlérí Jèhófà nínú Aísáyà 41:10 tó ní: “Má fòyà, nítorí mo wà pẹ̀lú rẹ. Má wò yí ká, nítorí èmi ni Ọlọ́run rẹ. Dájúdájú, èmi yóò fi okun fún ọ.” Ọ̀rọ̀ yìí máa ń fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé tá a bá jẹ́ olóòótọ́, tá a sì fi Ìjọba Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́, Jèhófà ò ní já wa kulẹ̀ láé.

Nígbà tó yá, wọ́n rán wa lọ sí àgbègbè kan nítòsí ibodè orílẹ̀-èdè Brazil. Nígbà tá a débẹ̀, àlùfáà tó wà ládùúgbò yẹn sọ fáwọn ọ̀dọ́ kan pé kí wọ́n máa ju òkò lu ilé wa, ilé ọ̀hún ò sì gbádùn tẹ́lẹ̀. Kò pẹ́ sígbà yẹn ni ọkọ mi bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ọ̀gá àwọn ọlọ́pàá lẹ́kọ̀ọ́. Ọ̀gá ọlọ́pàá yẹn wá ní káwọn ọlọ́pàá mélòó kan wá dúró sí ìtòsí ilé wa fún ọ̀sẹ̀ kan, àwọn èèyàn náà ò sì yọ wá lẹ́nu mọ́. Nígbà tó yá, a kó lọ sílé míì tó tura ní òdìkejì ibodè Brazil. Apá ibi tá a kó lọ yìí dáa gan-an torí pé ó jẹ́ kó rọrùn fún wa láti máa ṣèpàdé ní Paraguay àti ní Brazil. Nígbà tá a fi máa kúrò níbẹ̀, ìjọ méjì ló ti wà lágbègbè yẹn.

Èmi àti Walter nígbà tá à ń ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì ní Asunción, Paraguay

JÈHÓFÀ Ò FI MÍ SÍLẸ̀

Àwọn dókítà ti sọ fún mi tẹ́lẹ̀ pé mi ò ní lè bímọ, àmọ́ nígbà tó dọdún 1962, ó yà wá lẹ́nu nígbà tí wọ́n sọ fún wa pé mo ti lóyún! Torí náà, a kó lọ sílùú Hollywood, ní ìpínlẹ̀ Florida, nítòsí àwọn ẹbí ọkọ mi. Fún bí ọdún mélòó kan, èmi àtọkọ mi ò lè ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà torí pé a gbọ́dọ̀ bójú tó ìdílé wa. Síbẹ̀, ìjọsìn Jèhófà la jẹ́ kó gbawájú láyé wa.​—Mát. 6:33.

Nígbà tá a dé Florida ní November 1962, ó yà wá lẹ́nu pé àwọn tó wà lágbègbè yẹn kì í fẹ́ káwọn èèyàn dúdú àtàwọn aláwọ̀ funfun jọ da nǹkan pọ̀. Torí náà, àwọn èèyàn dúdú àtàwọn aláwọ̀ funfun kì í ṣèpàdé pa pọ̀, kódà àgbègbè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n ti ń wàásù. Àmọ́ Jèhófà ò fàyè gba ìwà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà nínú ìjọ, torí náà, kò pẹ́ tí nǹkan fi yí pa dà tí gbogbo wọn sì jọ ń ṣèpàdé pa pọ̀. A rí ọwọ́ Jèhófà nínú ọ̀rọ̀ yìí torí pé ìjọ tó wà lágbègbè yẹn ti pọ̀ gan-an báyìí.

Ìbànújẹ́ sorí mi kodò nígbà tí àrùn jẹjẹrẹ inú ọpọlọ pa ọkọ mi lọ́dún 2015. Ọkọ àtàtà ni, mo sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an ní gbogbo ọdún márùndínlọ́gọ́ta [55] tá a fi jọ wà pọ̀. Ọkọ mi nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ó sì ran ọ̀pọ̀ àwọn ará lọ́wọ́. Ṣe ló ń ṣe mí bíi pé káyé tuntun ti dé kí n lè rí ọkọ mi lẹ́ẹ̀kan sí i.​—Ìṣe 24:15.

Inú mi dùn pé ohun tó lé lógójì [40] ọdún ni mo ti lò lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún báyìí, ayọ̀ àti ìbùkún tí mo sì ń rí níbẹ̀ kọjá àfẹnusọ. Bí àpẹẹrẹ, mẹ́rìndínlógóje [136] lára àwọn tá a kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ló ṣèrìbọmi lójú wa. Òótọ́ ni pé a kojú àwọn ìṣòro kan, síbẹ̀ a ò rẹ̀wẹ̀sì, a ò sì ṣíwọ́ sísin Jèhófà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe la túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, a sì gbẹ́kẹ̀ lé e pé tó bá tó àsìkò lójú ẹ̀, ó máa yanjú àwọn ìṣòro wa lọ́nà tó tọ́. Ohun tó sì ṣe nìyẹn.​—2 Tím. 4:​16, 17.

Àárò ọkọ mi máa ń sọ mí gan-an, àmọ́ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà tí mò ń ṣe ń fún mi lókun. Inú mi máa ń dùn tí mo bá ń kọ́ àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́, tí mo sì ń sọ̀rọ̀ nípa àjíǹde fún wọn. Kí n sòótọ́, Jèhófà ò fi mí sílẹ̀ rí, àwọn ìbùkún tí mo sì ti rí gbà kọjá àfẹnusọ. Jèhófà mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ lóòótọ́, torí pé ó ń fún mi lókun, ó ń dúró tì mí, ó sì ń fi “ọwọ́ ọ̀tún òdodo” rẹ̀ dì mí mú.​—Aísá. 41:10.