Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Àmín” Wa Ṣe Pàtàkì sí Jèhófà

“Àmín” Wa Ṣe Pàtàkì sí Jèhófà

JÈHÓFÀ mọyì gbogbo ohun tá à ń ṣe nínú ìjọsìn rẹ̀. Ó máa ‘ń fiyè sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ó sì ń fetí’ sí wọn. Jèhófà máa ń kíyè sí gbogbo ohun tá à ń ṣe láti yin orúkọ rẹ̀ lógo bó ti wù kó kéré tó. (Mál. 3:16) Bí àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ká wo ọ̀rọ̀ kan tá a ti sọ láìmọye ìgbà, ìyẹn “àmín.” Ṣé Jèhófà mọyì ọ̀rọ̀ kékeré yìí? Bẹ́ẹ̀ ni, ó mọyì rẹ̀! Ká lè mọ ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká wo ohun tí ọ̀rọ̀ yìí túmọ̀ sí àti bí wọ́n ṣe lò ó nínú Bíbélì.

“GBOGBO ÈÈYÀN SÌ SỌ PÉ, ‘ÀMÍN!’”

Ọ̀rọ̀ náà “àmín” túmọ̀ sí “kó rí bẹ́ẹ̀” tàbí “dájúdájú,” ó sì wá láti inú ọ̀rọ̀ Hébérù tó túmọ̀ sí “jẹ́ olóòótọ́” tàbí “ṣeé gbọ́kàn lé.” Nígbà míì, wọ́n máa ń lo “àmín” nínú ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ òfin. Bí àpẹẹrẹ, tẹ́nì kan bá búra, ó máa sọ pé “àmín” kó lè fi hàn pé òótọ́ pọ́ńbélé lòun sọ àti pé òun máa fara mọ́ ohunkóhun tó bá tẹ̀yìn ìbúra náà yọ. (Nọ́ń. 5:22) Torí pé ó ti ṣe àmín lójú àwọn èèyàn, ìyẹn á jẹ́ kó túbọ̀ sapá láti mú ẹ̀jẹ́ rẹ̀ ṣẹ.​—Neh. 5:13.

Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lo ọ̀rọ̀ náà “àmín” lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ nínú Diutarónómì orí 27. Lẹ́yìn tí wọ́n wọ Ilẹ̀ Ìlérí, wọ́n kóra jọ sáàárín Òkè Ébálì àti Òkè Gérísímù kí wọ́n lè ka Òfin Ọlọ́run sí wọn létí. Àmọ́ kì í ṣe torí kí wọ́n lè gbọ́ Òfin yẹn nìkan ni wọ́n ṣe wá, wọ́n tún wá síbẹ̀ kí wọ́n lè fi hàn pé àwọn fara mọ́ gbogbo ohun tó wà nínú Òfin náà. Bí wọ́n ṣe ń ka ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sẹ́ni tó bá rú Òfin, gbogbo wọn ń sọ pé “Àmín!” (Diu. 27:15-26) Ẹ fojú inú wo bí ohùn wọn ṣe máa ròkè tó bí gbogbo wọn lọ́kùnrin àti lóbìnrin títí kan àwọn ọmọdé ṣe pa ohùn wọn pọ̀ láti ṣàmín! (Jóṣ. 8:30-35) Ó dájú pé wọn ò jẹ́ gbàgbé àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ lọ́jọ́ yẹn. Wọ́n sì mú ẹ̀jẹ́ wọn ṣẹ torí Bíbélì sọ pé: “Ísírẹ́lì ṣì ń sin Jèhófà ní gbogbo ọjọ́ ayé Jóṣúà àti ní gbogbo ọjọ́ ayé àwọn àgbààgbà tí wọ́n ṣẹ́ kù lẹ́yìn tí Jóṣúà kú, tí wọ́n sì ti mọ gbogbo ohun tí Jèhófà ṣe nítorí Ísírẹ́lì.”​—Jóṣ. 24:31.

Jésù náà lo “àmín” káwọn èèyàn lè mọ̀ pé òótọ́ pọ́ńbélé ló ń sọ, àmọ́ ó tún lò ó lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Dípò kó lo “àmín” (tá a tú sí “lóòótọ́”) lẹ́yìn táwọn míì bá sọ̀rọ̀ tán, ó lò ó ṣáájú ọ̀rọ̀ rẹ̀ kó lè fìdí ohun tó fẹ́ sọ múlẹ̀. Nígbà míì, ó máa ń tún un sọ, á ní “àmín àmín.” (Mát. 5:18; Jòh. 1:51) Èyí máa ń jẹ́ kó dá àwọn tó ń gbọ́rọ̀ rẹ̀ lójú pé òótọ́ pọ́ńbélé ló ń sọ. Jésù lè fi irú ìdánilójú bẹ́ẹ̀ sọ̀rọ̀ torí pé òun ni Ọlọ́run yàn láti mú gbogbo ìlérí rẹ̀ ṣẹ.​—2 Kọ́r. 1:20; Ìfi. 3:14.

“GBOGBO ÈÈYÀN SÌ SỌ PÉ, ‘ÀMÍN!’ WỌ́N SÌ YIN JÈHÓFÀ”

Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tún máa ń lo “àmín” tí wọ́n bá ń gbàdúrà sí Jèhófà tí wọ́n sì ń yìn ín. (Neh. 8:6; Sm. 41:13) Tí wọ́n bá ṣe “àmín” lẹ́yìn àdúrà, ṣe ni wọ́n ń fi hàn pé àwọn fara mọ́ ohun tẹ́ni tó gbàdúrà náà sọ. Bí gbogbo wọn sì ṣe pa ohùn wọn pọ̀ láti ṣàmín máa ń jẹ́ kí ìjọsìn náà múnú Jèhófà dùn. Ohun tó ṣẹlẹ̀ nìyẹn nígbà tí Ọba Dáfídì gbé Àpótí Jèhófà wá sí Jerúsálẹ́mù. Níbi àjọyọ̀ yẹn, Dáfídì gba àdúrà mánigbàgbé kan tá a ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ nínú 1 Kíróníkà 16:8-36. Àwọn ọ̀rọ̀ tó sọ nínú àdúrà náà wọ àwọn tó wà níbẹ̀ lọ́kàn débi pé ‘gbogbo wọn sọ pé, “Àmín!” wọ́n sì yin Jèhófà.’ Kò sí àní-àní pé bí gbogbo wọn ṣe panu pọ̀ ṣàmín mú kí ayọ̀ ọjọ́ náà gọntíọ.

Àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní náà máa ń ṣe “àmín” tí wọ́n bá ń yin Jèhófà. Kódà àwọn tó kọ Bíbélì sábà máa ń lò ó nínú àwọn lẹ́tà wọn. (Róòmù 1:25; 16:27; 1 Pét. 4:11) Ìwé Ìfihàn tiẹ̀ sọ pé àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí tó wà lọ́run ń yin Jèhófà, wọ́n sì ń sọ pé: “Àmín! Ẹ yin Jáà!” (Ìfi. 19:1, 4) Àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní sábà máa ń ṣe “àmín” lẹ́yìn tí wọ́n bá gbàdúrà nípàdé wọn. (1 Kọ́r. 14:16) Àmọ́ wọn kì í ṣe àmín láìfọkàn bá àdúrà náà lọ.

ÌDÍ TÍ “ÀMÍN” WA FI ṢE PÀTÀKÌ

Bá a ṣe ṣàyẹ̀wò bí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run nígbà àtijọ́ ṣe lo “àmín” ti jẹ́ ká rí i pé, “àmín” lọ̀rọ̀ tó dáa jù tá a lè fi parí àdúrà wa. Tá a bá sọ ọ́ lẹ́yìn àdúrà táwa fúnra wa gbà, ìyẹn á fi hàn pé ohun tá a sọ tọkàn wa wá. Tá a bá sì ṣe “àmín” yálà sínú tàbí tá a sọ ọ́ jáde lẹ́yìn àdúrà tẹ́nì kan gbà fún àwùjọ, ìyẹn á fi hàn pé a fara mọ́ ohun tẹ́ni náà sọ. Ẹ jẹ́ ká tún wo ìdí míì tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa ṣe “àmín.”

Ó fi hàn pé a pọkàn pọ̀, a sì ń kópa nínú ìjọsìn Jèhófà. Àdúrà jẹ́ apá kan ìjọsìn wa, torí náà kì í ṣe ohun tá a sọ nínú àdúrà nìkan ló ṣe pàtàkì, ohun tá à ń ṣe nígbà tí àdúrà ń lọ lọ́wọ́ náà tún ṣe pàtàkì. Tá a bá fẹ́ kí “àmín” wa ní ìtẹ́wọ́gbà, a gbọ́dọ̀ pọkàn pọ̀ ká sì máa fọkàn bá àdúrà náà lọ.

A wà níṣọ̀kan. Tá a bá ń gbàdúrà nípàdé, ohun kan náà ni gbogbo wa máa ń pọkàn pọ̀ sí lásìkò yẹn. (Ìṣe 1:14; 12:5) Tí gbogbo wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin bá wá pa ohùn wa pọ̀ láti ṣe “àmín,” ìyẹn máa ń jẹ́ ká túbọ̀ wà níṣọ̀kan. Yálà a sọ “àmín” wa jáde tàbí a sọ ọ́ sínú, bí gbogbo wa ṣe panu pọ̀ ṣàmín lè mú kí Jèhófà dáhùn àdúrà náà.

“Àmín” wa ń fògo fún Jèhófà

À ń yin Jèhófà. Jèhófà mọyì gbogbo ohun tá à ń ṣe nínú ìjọsìn rẹ̀ bó ti wù kó kéré tó. (Lúùkù 21:2, 3) Ó mọ ohun tó wà lọ́kàn wa àtohun tó ń sún wa ṣe nǹkan. Kódà tó bá tiẹ̀ jẹ́ àtorí fóònù la ti ń tẹ́tí sí ìpàdé, bá a ṣe ń ṣe “àmín” pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ará ń múnú Jèhófà dùn. Ìyẹn sì ń jẹ́ ká máa yin Jèhófà níṣọ̀kan.

Ó lè máa ṣe wá bíi pé “àmín” tá à ń ṣe ò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì, àmọ́ ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ torí Jèhófà mọyì ẹ̀ gan-an. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ kan tó ń ṣàlàyé ọ̀rọ̀ Bíbélì sọ pé, ‘Nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ kan ṣoṣo yìí, àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lè fi hàn pé àwọn ní ìgbọ́kànlé àti ìdánilójú pé Ọlọ́run á dáhùn àdúrà àwọn.’ Ǹjẹ́ kí “àmín” tá à ń ṣe túbọ̀ máa múnú Jèhófà dùn.​—Sm. 19:14.