Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kí nìdí tó fi yẹ káwa Kristẹni máa ṣọ́ra tá a bá ń lo àwọn ètò ìṣiṣẹ́ tí wọ́n fi ń fọ̀rọ̀ ránṣẹ́?

Àwọn ará wa kan máa ń lo ẹ̀rọ ìgbàlódé láti kàn sí àwọn mọ̀lẹ́bí wọn àtàwọn ará míì. Àmọ́ Kristẹni kan tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀ máa fi ìmọ̀ràn Bíbélì yìí sílò pé: “Ọlọ́gbọ́n rí ewu, ó sì fara pa mọ́, àmọ́ aláìmọ̀kan kọrí síbẹ̀, ó sì jìyà rẹ̀.”​—⁠Òwe 27:⁠12.

A mọ̀ pé Jèhófà fẹ́ dáàbò bò wá. Torí náà, a kì í kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn tó ń fa ìyapa, àwọn tí wọ́n ti yọ lẹ́gbẹ́ àtàwọn tó ń gbé ẹ̀kọ́ èké lárugẹ. (Róòmù 16:17; 1 Kọ́r. 5:11; 2 Jòh. 10, 11) Bákan náà, àwọn kan nínú ìjọ lè má fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò. (2 Tím. 2:​20, 21) A máa ń yẹra fún irú àwọn bẹ́ẹ̀, a kì í sì í bá wọn ṣọ̀rẹ́. Àmọ́ ó lè má rọrùn láti dá irú wọn mọ̀ tá a bá ń lo ètò ìṣiṣẹ́ tí wọ́n fi ń fọ̀rọ̀ ránṣẹ́.

Ó ṣe pàtàkì ká kíyè sára gan-an pàápàá tá a bá wà lórí ìkànnì tí ọ̀pọ̀ èèyàn ti ń fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ síra wọn. Àwọn Kristẹni kan ti dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ tí ọ̀pọ̀ èèyàn ti ń fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ síra wọn, ohun tó yọrí sí ò sì dáa rárá. Àmọ́ ṣé ó máa rọrùn fún arákùnrin tàbí arábìnrin kan láti kíyè sára tó bá jẹ́ pé ọgọ́rọ̀ọ̀rún èèyàn ló wà nínú ẹgbẹ́ kan? Ó dájú pé kò ní ṣeé ṣe. Ìdí ni pé kò lè mọ ẹnì kọ̀ọ̀kan tó wà nínú ẹgbẹ́ náà àti ipò wọn nípa tẹ̀mí. Sáàmù 26:4 sọ pé: “Èmi kì í bá àwọn ẹlẹ́tàn kẹ́gbẹ́, mo sì máa ń yẹra fún àwọn tó ń fi ẹni tí wọ́n jẹ́ pa mọ́.” Ìyẹn fi hàn pé ohun tó máa bọ́gbọ́n mu jù ni pé àwọn tá a mọ̀ rí nìkan ló yẹ ká máa fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí.

Tí àwọn tó wà nínú ẹgbẹ́ náà ò bá tiẹ̀ pọ̀, ó ṣì yẹ kí Kristẹni kan ronú lórí àkókò tó ń lò lórí ètò ìṣiṣẹ́ náà àti ohun táwọn tó wà nínú ẹgbẹ́ náà ń sọ. Kò yẹ ká ronú pé dandan ni ká lóhùn sí ohun táwọn tó wà nínú ẹgbẹ́ náà ń sọ, yálà ohun tí wọ́n ń sọ kàn wá tàbí kò kàn wá. Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ fún Tímótì pé kó ṣọ́ra fáwọn tó ń “ṣòfófó, [tí] wọ́n sì ń tojú bọ ọ̀rọ̀ ọlọ́rọ̀.” (1 Tím. 5:13) Bákan náà lónìí, ó yẹ ká ṣọ́ra fún irú ìwà bẹ́ẹ̀ lórí ìkànnì.

Kò yẹ kí Kristẹni kan tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀ máa ṣàríwísí àwọn Kristẹni míì tàbí kó máa fọ̀rọ̀ àṣírí wọn ránṣẹ́ lórí àwọn ìkànnì yìí, kò sì yẹ kó máa fetí sí i. (Sm. 15:3; Òwe 20:19) Bákan náà, ó máa yẹra fáwọn ìròyìn táwọn èèyàn ti bù mọ́ tàbí tí kò dá a lójú. (Éfé. 4:25) A ní ọ̀pọ̀ ìsọfúnni tó dá lórí Bíbélì tó sì ń fini lọ́kàn balẹ̀ lórí ìkànnì jw.org àti lórí ètò JW Broadcasting®.

Àwọn ará wa kan máa ń lo àwọn ètò ìṣiṣẹ́ tí wọ́n fi ń fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ láti tajà tàbí rajà tàbí kí wọ́n fi wá àwọn tí wọ́n lè gbéṣẹ́ fún. Irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ ò ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú ìjọsìn Jèhófà. Kristẹni kan tí kò ní “ìfẹ́ owó” kò ní lo ètò tó wà fáwọn ará láti gbé ọjà ẹ̀ lárugẹ.​—⁠Héb. 13:⁠5.

Ṣé ó yẹ ká lo àwọn ètò ìṣiṣẹ́ tí wọ́n fi ń fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ láti béèrè owó fáwọn ará wa tó níṣòro tàbí tí àjálù dé bá? Òótọ́ ni pé ó máa ń wù wá láti ran àwọn ará wa lọ́wọ́, ká sì fún wọn níṣìírí. (Jém. 2:​15, 16) Àmọ́ tá a bá lọ ń ṣe bẹ́ẹ̀ lórí ètò ìṣiṣẹ́ tọ́pọ̀ ti ń fọ̀rọ̀ ránṣẹ́, ìyẹn lè da ètò tí ẹ̀ka ọ́fíìsì àti ìjọ ń ṣe rú. (1 Tím. 5:​3, 4, 9, 10, 16) Ó sì dájú pé kò sí ẹnikẹ́ni nínú wa táá ṣe ohun táá mú káwọn èèyàn ronú pé òun ni wọ́n yàn láti máa bójú tó àwọn èèyàn Ọlọ́run.

Ohun tó máa fògo fún Jèhófà la fẹ́ ṣe. (1 Kọ́r. 10:31) Torí náà, tó o bá fẹ́ pinnu bóyá kó o lo ètò ìṣiṣẹ́ kan tí wọ́n fi ń fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ tàbí àwọn ìkànnì àjọlò míì, á dáa kó o ronú nípa ewu tó wà níbẹ̀, kó o sì ṣọ́ra.