ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 12
Ìfẹ́ Ń Jẹ́ Ká Lè Fara Da Ìkórìíra
“Mò ń pa àwọn nǹkan yìí láṣẹ fún yín, pé kí ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín. Tí ayé bá kórìíra yín, ẹ mọ̀ pé ó ti kórìíra mi kó tó kórìíra yín.”—JÒH. 15:17, 18.
ORIN 129 A Ó Máa Fara Dà Á Nìṣó
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *
1. Bó ṣe wà nínú Mátíù 24:9, kí nìdí tí kò fi yẹ kó yà wá lẹ́nu tí ayé bá kórìíra wa?
JÈHÓFÀ dá wa lọ́nà tó fi máa ń wù wá káwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ wa, káwa náà sì fìfẹ́ hàn sáwọn míì. Torí náà tẹ́nì kan bá kórìíra wa, ó máa ń dùn wá, kódà ó lè mú kẹ́rù máa bà wá. Bí àpẹẹrẹ, arábìnrin kan tó ń jẹ́ Georgina ní Yúróòpù sọ pé: “Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́rìnlá (14), màmá mi kórìíra mi torí pé mò ń sin Jèhófà. Èyí bà mí lọ́kàn jẹ́ gan-an, ó sì mú kí n máa ronú pé èèyàn burúkú ni mí.” * Arákùnrin kan tó ń jẹ́ Danylo sọ pé: “Ìgbà kan wà táwọn sójà lù mí, tí wọ́n rọ̀jò èébú lé mi lórí, tí wọ́n sì halẹ̀ mọ́ mi torí pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mí. Ìyẹn mú kí ẹ̀rù bà mí gan-an, kí ojú sì tì mí.” Ká sòótọ́, inú wa kì í dùn tí wọ́n bá kórìíra wa. Àmọ́ kò yà wá lẹ́nu torí Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn èèyàn máa kórìíra wa.—Ka Mátíù 24:9.
2-3. Kí nìdí táwọn èèyàn fi kórìíra àwa ọmọlẹ́yìn Jésù?
2 Àwọn èèyàn kórìíra àwa ọmọlẹ́yìn Jésù. Kí nìdí? Ìdí ni pé bíi ti Jésù, a “kì í ṣe apá kan ayé.” (Jòh. 15:17-19) Torí náà, a máa ń bọ̀wọ̀ fún ìjọba àtàwọn tó wà nípò àṣẹ, àmọ́ a kì í jọ́sìn wọn tàbí àwọn àmì tí wọ́n gbé kalẹ̀, bí àsíá àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Jèhófà nìkan là ń jọ́sìn torí a gbà pé Òun nìkan ló lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso aráyé bó tiẹ̀ jẹ́ pé Sátánì àti “ọmọ” rẹ̀ kò gbà bẹ́ẹ̀. (Jẹ́n. 3:1-5, 15) A tún ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ṣoṣo ni ìrètí tí aráyé ní àti pé láìpẹ́ Ìjọba náà máa pa gbogbo ìjọba ayé yìí run. (Dán. 2:44; ) Ìròyìn ayọ̀ lèyí jẹ́ fáwọn ọlọ́kàn tútù, àmọ́ ó máa ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá àwọn ẹni burúkú.— Ìfi. 19:19-21Sm. 37:10, 11.
3 Àwọn èèyàn tún kórìíra wa torí pé a máa ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Ọlọ́run. Àwọn ìlànà yìí mú ká yàtọ̀ sáwọn èèyàn ayé tí wọ́n jẹ́ oníwàkiwà. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí ò rí ohun tó burú nínú ìṣekúṣe, irú èyí tí Ọlọ́run tìtorí ẹ̀ pa Sódómù àti Gòmórà run. (Júùdù 7) Torí pé a máa ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì, a kì í sì í lọ́wọ́ sírú àwọn ìwàkiwà bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń fi wá ṣe yẹ̀yẹ́ pé a ò lajú.—1 Pét. 4:3, 4.
4. Kí ló máa ń fún wa lókun táwọn èèyàn bá kórìíra wa?
4 Kí lá jẹ́ ká lè fara dà á táwọn èèyàn bá kórìíra wa tí wọ́n sì ń fi wá ṣe yẹ̀yẹ́? A gbọ́dọ̀ ní ìgbàgbọ́ tó lágbára pé Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́. Ìgbàgbọ́ dà bí apata tó máa jẹ́ ká lè “paná gbogbo ọfà oníná ti ẹni burúkú náà.” (Éfé. 6:16) Yàtọ̀ sí ìgbàgbọ́, a tún nílò ìfẹ́. Kí nìdí? Ìdí ni pé ìfẹ́ “kì í tètè bínú.” Ó máa ń mú ohun gbogbo mọ́ra, ó sì máa ń fara da ìwà àìtọ́. (1 Kọ́r. 13:4-7, 13) Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká jíròrò bí ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà àtàwọn ará wa, títí kan àwọn ọ̀tá wa ṣe lè mú ká fara dà á táwọn èèyàn bá kórìíra wa.
ÌFẸ́ TÁ A NÍ FÚN JÈHÓFÀ Ń MÚ KÁ FARA DA ÌKÓRÌÍRA
5. Kí ni ìfẹ́ tí Jésù ní fún Jèhófà mú kó ṣe?
5 Nígbà tó ku ọ̀la táwọn ọ̀tá máa pa Jésù, ó sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ olóòótọ́ pé: “Mo nífẹ̀ẹ́ Baba, [torí náà] ohun tí Baba pa láṣẹ fún mi pé kí n ṣe gẹ́lẹ́ ni mò ń ṣe.” (Jòh. 14:31) Ìfẹ́ tí Jésù ní fún Jèhófà ló mú kó lè fara dà á dójú ikú. Táwa náà bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, àá lè fara da ìṣòro èyíkéyìí.
6. Kí ni Róòmù 5:3-5 sọ tó jẹ́ ká mọ bó ṣe máa ń rí lára àwa ìránṣẹ́ Jèhófà táwọn èèyàn bá kórìíra wa?
6 Ọjọ́ pẹ́ táwa ìránṣẹ́ Jèhófà ti ń fara da inúnibíni torí ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ìgbìmọ̀ Sàhẹ́ndìrìn pàṣẹ fáwọn àpọ́sítélì pé wọn ò gbọ́dọ̀ wàásù mọ́, ìfẹ́ táwọn àpọ́sítélì náà ní fún Ọlọ́run mú kí wọ́n “ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí alákòóso dípò èèyàn.” (Ìṣe 5:29; 1 Jòh. 5:3) Lónìí, irú ìfẹ́ yìí kan náà ló ń mú káwọn ará wa máa fara da inúnibíni àti ìwà ìkà táwọn aláṣẹ ń hù sí wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn kórìíra wa, a ò rẹ̀wẹ̀sì. Kàkà bẹ́ẹ̀, a kà á sí àǹfààní ńlá láti fara dà á.—Ìṣe 5:41; ka Róòmù 5:3-5.
7. Kí ló yẹ ká ṣe táwọn tó wà nínú ìdílé wa bá ń ta kò wá?
7 Ó máa ń dunni gan-an tó bá jẹ́ pé àwọn tó wà nínú ìdílé wa ló ń ta kò wá. Nígbà tá a bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, ó ṣeé ṣe káwọn kan nínú ìdílé wa ronú pé wọ́n ti ṣì wá lọ́nà, àwọn míì sì lè ronú pé a ò mọ ohun tá à ń ṣe. (Fi wé Máàkù 3:21.) Wọ́n lè sọ̀rọ̀ burúkú sí wa tàbí kí wọ́n tiẹ̀ lù wá nígbà míì. Kò yẹ kó yà wá lẹ́nu tí wọ́n bá ṣerú nǹkan bẹ́ẹ̀ sí wa. Jésù sọ pé: “Àwọn ará ilé ẹni ló máa jẹ́ ọ̀tá ẹni.” (Mát. 10:36) Àmọ́ o, ohun yòówù káwọn tó wà nínú ìdílé wa ṣe sí wa, kò yẹ ká kà wọ́n sí ọ̀tá wa. Kàkà bẹ́ẹ̀, bí ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà ṣe ń jinlẹ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ ló ṣe yẹ kí ìfẹ́ tá a ní fáwọn èèyàn náà máa jinlẹ̀ sí i. (Mát. 22:37-39) Bó ti wù kó rí, a ò ní tìtorí pé a fẹ́ múnú àwọn èèyàn dùn ká wá tẹ àwọn ìlànà Ọlọ́run lójú.
8-9. Kí ló jẹ́ kí arábìnrin kan lè fara da inúnibíni tó lágbára?
8 Georgina tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan fara da inúnibíni tó lágbára tí ìyá rẹ̀ ṣe sí i. Ó sọ pé: “Èmi àti màmá mi la jọ bẹ̀rẹ̀ sí í
kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Lẹ́yìn oṣù mẹ́fà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́, mo pinnu láti máa lọ sípàdé, àmọ́ ṣe ni ìyá mi bẹ̀rẹ̀ sí í ta kò mí. Mo wá rí i pé wọ́n ti ń tẹ́tí sáwọn apẹ̀yìndà, ìyẹn ló sì mú kí wọ́n máa ta ko ẹ̀kọ́ òtítọ́. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n máa ń bú mi, wọ́n á fa irun mi, wọ́n á fún mi lọ́rùn, kódà wọ́n máa ń da àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ mi nù. Láìfi gbogbo ìyẹn pè, mo ṣèrìbọmi nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15). Kí n má bàa sin Jèhófà mọ́, màmá mi lọ fi mí síbi tí wọ́n máa ń kó àwọn ọmọ aláìgbọràn sí, ọ̀daràn ló pọ̀ jù lára àwọn ọmọ tó wà níbẹ̀, wọ́n sì ń lo oògùn olóró. Ó máa ń ṣòro gan-an láti fara dà á tó bá jẹ́ pé ẹni tó sún mọ́ni tó sì yẹ kó nífẹ̀ẹ́ ẹni ló ń ṣàtakò.”9 Kí ló jẹ́ kí Georgina lè fara dà á? Ó sọ pé: “Ọjọ́ tí mo ka Bíbélì parí ni màmá mi bẹ̀rẹ̀ sí í ta kò mí. Àmọ́ Bíbélì tí mo kà yẹn jẹ́ kó dá mi lójú pé mo ti rí òtítọ́, ìyẹn sì jẹ́ kí n túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo máa ń gbàdúrà sí i, ó sì máa ń dáhùn àdúrà mi. Nígbà tí mo ṣì wà nílé àwọn ọmọ aláìgbọràn yẹn, arábìnrin kan ní kí n wá kí òun nílé, a sì jọ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ní gbogbo àsìkò yẹn, àwọn ará ò fi mí sílẹ̀, gbogbo ìgbà ni wọ́n máa ń fún mi níṣìírí tí mo bá lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba. Mo ti wá rí i báyìí pé Jèhófà lágbára ju gbogbo àwọn alátakò wa lọ, láìka irú ẹni tí wọ́n jẹ́ sí.”
10. Kí ló dá wa lójú pé Jèhófà máa ṣe fún wa?
10 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé kò sóhun tó máa lè “yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run tó wà nínú Kristi Jésù Olúwa wa.” (Róòmù 8:38, 39) Ìṣòro yòówù ká ní, fúngbà díẹ̀ ni. Àmọ́ ó dájú pé Jèhófà ò ní fi wá sílẹ̀, á sì fún wa lókun. Bá a ṣe rí i látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Georgina, Jèhófà tún máa ń lo àwọn ará láti ràn wá lọ́wọ́.
ÌFẸ́ TÁ A NÍ FÁWỌN ARÁ WA Ń JẸ́ KÁ FARA DA ÌKÓRÌÍRA
11. Táwọn ọmọ ẹ̀yìn bá ní irú ìfẹ́ tí Jésù sọ nínú Jòhánù 15:12, 13, kí ni wọ́n máa ṣe? Sọ àpẹẹrẹ kan.
11 Lálẹ́ ọjọ́ tó ṣáájú ikú Jésù, ó rán àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ létí pé ó ṣe pàtàkì kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn. (Ka Jòhánù 15:12, 13.) Ó mọ̀ pé tí wọ́n bá nífẹ̀ẹ́ ara wọn bí òun ṣe nífẹ̀ẹ́ wọn, wọ́n á wà níṣọ̀kan, á sì rọrùn fún wọn láti fara dà á táwọn èèyàn bá kórìíra wọn. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ àwọn Kristẹni tó wà ní ìjọ Tẹsalóníkà. Àtìgbà tí wọ́n ti dá ìjọ náà sílẹ̀ làwọn èèyàn ti ń ṣenúnibíni sí wọn. Síbẹ̀, àwọn ará yẹn fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ ní ti pé wọ́n fara dà á, wọn ò sì yéé nífẹ̀ẹ́ ara wọn. (1 Tẹs. 1:3, 6, 7) Bó ti wù kó rí, Pọ́ọ̀lù gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n túbọ̀ máa fìfẹ́ hàn. (1 Tẹs. 4:9, 10) Ìfẹ́ tí wọ́n ní yìí ló jẹ́ kí wọ́n máa tu àwọn tó sorí kọ́ nínú, kí wọ́n sì máa ran àwọn aláìlera lọ́wọ́. (1 Tẹs. 5:14) Nínú lẹ́tà kejì tí Pọ́ọ̀lù kọ sí wọn ní nǹkan bí ọdún kan lẹ́yìn náà, ó hàn pé wọ́n fi ìmọ̀ràn náà sílò. Abájọ tí Pọ́ọ̀lù fi sọ fún wọn pé: “Ìfẹ́ tí ẹ ní sí ara yín lẹ́nì kọ̀ọ̀kan àti lápapọ̀ . . . ń pọ̀ sí i.” (2 Tẹs. 1:3-5) Ìfẹ́ tí wọ́n ní ló mú kí wọ́n lè fara da ìṣòro àti inúnibíni.
12. Báwo làwọn ará ṣe fìfẹ́ hàn síra wọn lórílẹ̀-èdè kan tí wọ́n ti ń jagun?
12 Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Danylo tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan àtìyàwó ẹ̀. Nígbà tí ogun bẹ́ sílẹ̀ nílùú wọn, wọn ò yéé lọ sípàdé, wọ́n ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, wọ́n sì ń ṣàjọpín oúnjẹ tí wọ́n ní pẹ̀lú àwọn ará. Lọ́jọ́ kan, àwọn sójà tó dìhámọ́ra wá sílé Danylo. Danylo sọ pé àwọn sójà náà sọ fún mi pé: “Mi ò gbọ́dọ̀ ṣe Ajẹ́rìí mọ́. Nígbà tí mo kọ̀, wọ́n lù mí, wọ́n sì yìnbọn gba orí mi kọjá kẹ́rù lè bà mí. Kí wọ́n tó lọ, wọ́n sọ fún mi pé àwọn ń pa dà bọ̀ wá fipá bá ìyàwó mi lò pọ̀. Kíá làwọn ará ṣètò bí ọkọ̀ ojú irin ṣe máa gbé wa kúrò nílùú yẹn. Mi ò lè gbàgbé ohun táwọn ará yẹn ṣe láé. Nígbà tá a dé ìlú kejì, àwọn ará tó wà níbẹ̀ fún wa lóúnjẹ, wọ́n bá wa wá ilé, wọ́n sì bá mi wáṣẹ́! Torí náà, nígbà táwọn ará míì sá kúrò nílùú yẹn torí ogun, ó ṣeé ṣe fún wa láti gbà wọ́n sílé.” Irú àwọn ìrírí yìí jẹ́ ká rí i pé ìfẹ́ táwọn ará ń fi hàn sí wa lè jẹ́ ká fara dà á táwọn èèyàn bá kórìíra wa.
TÁ A BÁ NÍFẸ̀Ẹ́ ÀWỌN Ọ̀TÁ WA, ÀÁ LÈ FARA DA ÌKÓRÌÍRA
13. Báwo ni ẹ̀mí mímọ́ ṣe lè mú ká fara dà á lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà táwọn èèyàn bá tiẹ̀ kórìíra wa?
13 Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ pé kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá wọn. (Mát. 5:44, 45) Ṣé ìyẹn rọrùn? Rárá o! Àmọ́, ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà lè mú kó ṣeé ṣe. Ẹ̀mí mímọ́ máa jẹ́ ká ní ìfẹ́, sùúrù, inú rere, ìwà tútù àti ìkóra-ẹni-níjàánu. (Gál. 5:22, 23) Àwọn ànímọ́ yìí máa jẹ́ ká lè fara dà á táwọn èèyàn bá kórìíra wa. Ọ̀pọ̀ àwọn tó kórìíra wa tẹ́lẹ̀ ló ti yí pa dà torí pé ọkọ, ìyàwó, ọmọ tàbí aládùúgbò tó jẹ́ Kristẹni fi àwọn ànímọ́ yìí hàn. Kódà ọ̀pọ̀ àwọn alátakò yìí ló ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Torí náà, tó bá ṣòro fún ẹ láti nífẹ̀ẹ́ àwọn tó kórìíra ẹ torí pé ò ń sin Jèhófà, gbàdúrà pé kí Jèhófà fún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. (Lúùkù 11:13) Kó o sì jẹ́ kó dá ẹ lójú pé kò sígbà tó o ṣègbọràn sí Ọlọ́run tó o máa kábàámọ̀.—Òwe 3:5-7.
14-15. Báwo ni Róòmù 12:17-21 ṣe mú kí Yasmeen máa fìfẹ́ hàn sí ọkọ ẹ̀?
14 Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Yasmeen tó ń gbé ní Middle East. Nígbà tó di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ọkọ ẹ̀ sọ pé ṣe ni wọ́n ń tàn án jẹ, ó sì gbìyànjú láti mú kó jáwọ́. Yàtọ̀ síyẹn, ó rọ̀jò èébú lé e lórí, ó pe mọ̀lẹ́bí jọ nítorí ẹ̀, ó sì pe àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì àti ọkùnrin olóògùn kan láti wá halẹ̀ mọ́ ọn. Wọ́n tún fẹ̀sùn kàn án pé ó fẹ́ da ìdílé wọn rú. Kódà, ọkọ ẹ̀ lọ pariwo mọ́ àwọn ará níbi tí wọ́n ti ń ṣèpàdé! Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Yasmeen máa ń sunkún torí ìwà tí ọkọ ẹ̀ ń hù sí i.
15 Àwọn ará máa ń tu Yasmeen nínú nípàdé, wọ́n sì máa ń fún un níṣìírí. Àwọn alàgbà gbà á níyànjú pé kó fi ohun tó wà nínú Róòmù 12:17-21 sílò. (Kà á.) Yasmeen sọ pé: “Kò rọrùn rárá, àmọ́ mo bẹ Jèhófà pé kó ràn mí lọ́wọ́. Mo sì ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe láti fi ìlànà Bíbélì sílò. Tí ọkọ mi bá mọ̀ọ́mọ̀ da ìdọ̀tí sínú ilé ìdáná, mo máa ń gbá a, tó bá bú mi, mi kì í bínú, tó bá sì ṣàìsàn, mo máa ń fìfẹ́ tọ́jú ẹ̀.”
16-17. Kí lo rí kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Yasmeen?
16 Ìsapá Yasmeen lórí ọkọ ẹ̀ ò já sásán. Ó sọ pé: “Ọkọ mi bẹ̀rẹ̀ sí í fọkàn tán mi torí ó mọ̀ pé mi ò kì í parọ́. Nígbà tó yá, kì í gbaná jẹ mọ́ tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀sìn, ó sì máa ń hùwà dáadáa sí mi. Ní báyìí, tí n bá ń lọ sípàdé, ó máa ń sọ fún mi pé kí n gbádùn ìpàdé o. Inú mi dùn pé nǹkan ti yàtọ̀ gan-an nínú ìdílé wa báyìí, a sì ń gbádùn ara wa. Àdúrà mi ni pé kí ọkọ mi náà kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ ká sì jọ máa sin Jèhófà.”
17 Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Yasmeen jẹ́ ká rí i pé ìfẹ́ ‘máa ń mú ohun gbogbo mọ́ra, ó máa ń retí ohun gbogbo, ó sì máa ń fara da ohun gbogbo.’ (1 Kọ́r. 13:4, 7) Ìkórìíra burú, ó sì máa ń dunni, àmọ́ ìfẹ́ ló máa mú ká borí rẹ̀. Ó lè yí ọkàn àwọn tó kórìíra wa pa dà. Ó sì máa ń múnú Jèhófà dùn, kódà táwọn alátakò wa ò bá yí pa dà, a ṣì lè láyọ̀. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀?
A LÈ LÁYỌ̀ TÍ WỌ́N BÁ KÓRÌÍRA WA
18. Kí nìdí tá a fi lè láyọ̀ tí wọ́n bá kórìíra wa?
18 Jésù sọ pé: “Aláyọ̀ ni yín nígbàkigbà tí àwọn èèyàn bá kórìíra yín.” (Lúùkù 6:22) Kì í wù wá káwọn èèyàn kórìíra wa, inú wa kì í sì í dùn tí wọ́n bá ń ṣenúnibíni sí wa. Torí náà, kí ló máa jẹ́ ká láyọ̀ táwọn èèyàn bá kórìíra wa? Ẹ jẹ́ ká wo ìdí mẹ́ta. Àkọ́kọ́, tá a bá fara dà á, inú Jèhófà máa dùn sí wa. (1 Pét. 4:13, 14) Ìkejì, ìgbàgbọ́ wa máa túbọ̀ lágbára. (1 Pét. 1:7) Ìkẹta, Jèhófà máa fún wa lẹ́bùn iyebíye, ìyẹn ìyè àìnípẹ̀kun.—Róòmù 2:6, 7.
19. Kí ló mú kínú àwọn àpọ́sítélì máa dùn lẹ́yìn tí wọ́n nà wọ́n?
19 Kò pẹ́ lẹ́yìn tí Jésù jíǹde làwọn àpọ́sítélì bẹ̀rẹ̀ sí í nírú ayọ̀ tí Jésù sọ pé wọ́n máa ní. Lẹ́yìn táwọn aláṣẹ ti nà wọ́n, tí wọ́n sì pàṣẹ fún wọn pé wọn ò gbọ́dọ̀ wàásù mọ́, ṣe ni inú wọn ń dùn. Kí nìdí? Ìdí ni pé “a ti kà wọ́n yẹ láti jìyà nítorí orúkọ Jésù.” (Ìṣe 5:40-42) Ìfẹ́ tí wọ́n ní fún Jésù Ọ̀gá wọn ju ìbẹ̀rù tí wọ́n ní fáwọn ọ̀tá wọn lọ. Wọ́n sì fi hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ Ọ̀gá wọn bí wọ́n ṣe ń wàásù ìhìn rere náà “láìdábọ̀.” Ọ̀pọ̀ àwọn ará wa ló ń fòótọ́ inú sin Jèhófà nìṣó láìka inúnibíni sí. Wọ́n mọ̀ pé Jèhófà ò ní gbàgbé iṣẹ́ tí wọ́n ṣe àti ìfẹ́ tí wọ́n fi hàn fún orúkọ rẹ̀.—Héb. 6:10.
20. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?
20 Tí ayé burúkú yìí bá ṣì ń bá a lọ, àwọn èèyàn máa kórìíra wa. (Jòh. 15:19) Àmọ́ kò yẹ ká bẹ̀rù. Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa rí bí Jèhófà ṣe máa fún àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ ‘lókun, táá sì dáàbò bò’ wá. (2 Tẹs. 3:3) Torí náà, ẹ jẹ́ ká túbọ̀ máa nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ká nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin títí kan àwọn tó kórìíra wa. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, àá wà níṣọ̀kan, ìgbàgbọ́ wa á lágbára sí i, àá fìyìn fún Jèhófà, àá sì fi hàn pé ìfẹ́ lè ṣẹ́gun ìkórìíra.
ORIN 106 Bá A Ṣe Lè Ní Ìfẹ́
^ ìpínrọ̀ 5 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa rí bí ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà, àwọn ará wa, títí kan àwọn ọ̀tá wa ṣe lè mú ká máa sin Jèhófà nìṣó bí ayé bá tiẹ̀ kórìíra wa. Àá tún rí ìdí tí Jésù fi sọ pé a máa láyọ̀ táwọn èèyàn bá tiẹ̀ kórìíra wa.
^ ìpínrọ̀ 1 A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.
^ ìpínrọ̀ 58 ÀWÒRÁN: Lẹ́yìn táwọn sójà halẹ̀ mọ́ Danylo, àwọn ará ṣètò bóun àtìyàwó ẹ̀ ṣe kúrò nílùú yẹn, àwọn ará sì gbà wọ́n tọwọ́tẹsẹ̀ nílùú tí wọ́n lọ.
^ ìpínrọ̀ 60 ÀWÒRÁN: Ọkọ Yasmeen fojú ẹ̀ rí màbo, àmọ́ àwọn alàgbà fún un ní ìmọ̀ràn tó dáa. Ìyẹn jẹ́ kó túbọ̀ máa hùwà dáadáa sí ọkọ ẹ̀, ó sì tọ́jú ẹ̀ nígbà tó ṣàìsàn.